Fara Wé Àánú Jèhófà
“Ẹ máa bá a lọ ní dídi aláàánú, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba yín ti jẹ́ aláàánú.”—LÚÙKÙ 6:36.
1. Báwo ni àwọn Farisí ṣe fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí aláìláàánú?
BÍ Ó tilẹ̀ jẹ́ pé a dá ènìyàn ní àwòrán Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ẹ̀dá ènìyàn kì í fara wé àánú rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Bí àpẹẹrẹ, gbé àwọn Farisí yẹ̀ wò. Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, wọ́n kọ̀ láti dunnú sí fífi tí Jésù fi àánú wo ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ rọ sàn ní ọjọ́ Sábáàtì. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n dìtẹ̀ mọ́ Jésù “kí wọ́n lè pa á run.” (Mátíù 12:9-14) Ní àkókò mìíràn, Jésù wo ọkùnrin kan tí a bí ní afọ́jú sàn. Lẹ́ẹ̀kan sí i, “àwọn kan lára àwọn Farisí” kò rí ìdí kankan fún dídunnú sí ìyọ́nú tí Jésù fi hàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣàròyé pé: “Èyí kì í ṣe ọkùnrin kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, nítorí pé kò pa Sábáàtì mọ́.”—Jòhánù 9:1-7, 16.
2, 3. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nípa gbólóhùn náà, “Ẹ . . . ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí”?
2 Ìwà òṣónú tí àwọn Farisí hù jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ sí aráyé àti sí Ọlọ́run. (Jòhánù 9:39-41) Pẹ̀lú ìdí rere, Jésù kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ . . . ṣọ́ra fún ìwúkàrà” àwọn ọ̀tọ̀kùlú yìí àti àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn, irú bí àwọn Sadusí. (Mátíù 16:6) A lo ìwúkàrà nínú Bíbélì láti dúró fún ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ìwà ìbàjẹ́. Nítorí náà, Jésù ń sọ pé ẹ̀kọ́ ‘àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí’ lè ba ìjọsìn mímọ́ gaara jẹ́. Lọ́nà wo? Ní ti pé ó kọ́ àwọn ènìyàn láti máa wo Òfin Ọlọ́run lọ́nà tí wọ́n gbà ń wo àwọn àdábọwọ́ àṣẹ àti ààtò tiwọn, kí wọ́n má sì ka “àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ” sí, títí kan àánú. (Mátíù 23:23) Irú ẹ̀sìn tí ó kún fún ààtò yìí mú kí jíjọ́sìn Ọlọ́run di ẹrù ìnira tí kò ṣeé fara dà.
3 Nínú apá kejì àkàwé Jésù nípa ọmọ onínàákúnàá, ó tú èrò ìbàjẹ́ àwọn aṣáájú ìsìn Júù fó. Nínú àkàwé náà, baba tí ó dúró fún Jèhófà, hára gàgà láti dárí jí ọmọ rẹ̀ tí ó ronú pìwà dà. Ṣùgbọ́n ìmọ̀lára ẹ̀gbọ́n ọmọ náà, tí ó dúró fún “àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé òfin,” yàtọ̀ pátápátá lórí ọ̀ràn náà.—Lúùkù 15:2.
Ìrunú Ẹ̀gbọ́n Rẹ̀
4, 5. Ọ̀nà wo ni ẹ̀gbọ́n ọmọ onínàákúnàá náà gbà “sọnù”?
4 “Wàyí o, ọmọkùnrin rẹ̀ àgbà wà nínú pápá; bí ó sì ti dé, tí ó sì sún mọ́ ilé, ó gbọ́ ohùn orin àwọn òṣèré àti ijó. Nítorí náà, ó pe ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí ohun tí nǹkan wọ̀nyí túmọ̀ sí. Ó wí fún un pé, ‘Arákùnrin rẹ ti dé, baba rẹ sì dúńbú àbọ́sanra ẹgbọrọ akọ màlúù, nítorí tí ó rí i gbà padà ní ara líle.’ Ṣùgbọ́n ó kún fún ìrunú, kò sì fẹ́ láti wọlé.”—Lúùkù 15:25-28.
5 Ó ṣe kedere pé, nínú àkàwé Jésù, kì í ṣe ọmọ onínàákúnàá náà nìkan ni ó ní ìṣòro. Ìwé ìtọ́kasí kan sọ pé, “Àwọn ọmọ méjèèjì tí a sọ̀rọ̀ wọn níhìn-ín ni wọ́n sọnù, ọ̀kan sọnù nítorí àìṣòdodo tí ó rẹ̀ ẹ́ nípò wálẹ̀, èkejì nítorí jíjẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀ èyí tí kò jẹ́ kí ó mọ ohun tí ó tọ́.” Ẹ ṣàkíyèsí pé, kì í ṣe pé ẹ̀gbọ́n ọmọ onínàákúnàá náà kọ̀ láti yọ̀ nìkan ni, ṣùgbọ́n “ó kún fún ìrunú” pẹ̀lú. Gbòǹgbò ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà fún “ìrunú” kò fi bẹ́ẹ̀ túmọ̀ sí ìbínú rangbọndan, bí kò ṣe ọ̀ràn kan tí kò tán lọ́kàn ẹni. Ó ṣe kedere pé, ẹ̀gbọ́n ọmọ onínàákúnàá náà di kùnrùngbùn jíjinlẹ̀ sínú, nítorí náà, ó rò pé kò yẹ láti ṣayẹyẹ pípadà tí ẹnì kan tí kò yẹ kí ó filé sílẹ̀ rárá padà wálé.
6. Ta ni ẹ̀gbọ́n ọmọ onínàákúnàá náà dúró fún, èé sì ti ṣe?
6 Ẹ̀gbọ́n ọmọ onínàákúnàá náà lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú dúró fún àwọn tí kò dunnú sí ìyọ́nú àti àfiyèsí tí Jésù fi hàn sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Àánú ti Jésù fi hàn kò jọ àwọn tí ó jẹ́ olódodo lójú ara wọn wọ̀nyí lójú rárá; bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò fi ayọ̀ tí ó máa ń wà ní ọ̀run nígbà tí a bá dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ kan hàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, àánú Jésù fa ìrunú wọn yọ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í “ro àwọn ohun burúkú” nínú ọkàn-àyà wọn. (Mátíù 9:2-4) Nígbà kan, inú bí àwọn Farisí kan tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọ́n fi fàṣẹ pe ọkùnrin kan tí Jésù mú lára dá, lẹ́yìn náà, wọ́n sì “sọ ọ́ síta” sínágọ́gù—ní kedere wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́! (Jòhánù 9:22, 34) Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n ọmọ onínàákúnàá náà, tí ‘kò fẹ́ wọlé,’ àwọn aṣáájú ìsìn Júù rojú kókó nígbà tí wọ́n láǹfààní láti “yọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń yọ̀.” (Róòmù 12:15) Bí Jésù ti ń bá àkàwé rẹ̀ lọ, ó túbọ̀ tú èrò ibi wọn fó.
Ìrònú Tí Ó Mẹ́hẹ
7, 8. (a) Lọ́nà wo ni ẹ̀gbọ́n ọmọ onínàákúnàá náà kò fi mọ ohun tí jíjẹ́ ọmọ túmọ̀ sí? (b) Ọ̀nà wo ni ọmọkùnrin àgbà kò fi jọ baba rẹ̀?
7 “Nígbà náà ni baba rẹ̀ jáde wá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pàrọwà fún un. Ní ìfèsìpadà, ó wí fún baba rẹ̀ pé, ‘Ọ̀pọ̀ ọdún nìyí tí mo ti ń sìnrú fún ọ, n kò sì tíì ré àṣẹ rẹ kọjá lẹ́ẹ̀kan rí, síbẹ̀síbẹ̀, ìwọ kò tíì fi ọmọ ewúrẹ́ kan fún mi lẹ́ẹ̀kan rí kí èmi lè gbádùn ara mi pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi. Ṣùgbọ́n gbàrà tí ọmọkùnrin rẹ yìí, tí ó jẹ àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé rẹ tán pẹ̀lú àwọn aṣẹ́wó dé, ìwọ dúńbú àbọ́sanra ẹgbọrọ akọ màlúù fún un.’”—Lúùkù 15:28-30.
8 Pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ẹ̀gbọ́n ọmọ onínàákúnàá náà mú kí ó ṣe kedere pé òun kò mọ ohun tí jíjẹ́ ọmọ túmọ̀ sí. Ó sin baba rẹ̀ lọ́nà tí ẹnì kan tí a gbà síṣẹ́ gbà ń sin ọ̀gá rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wí fún baba rẹ̀: “Mo ti ń sìnrú fún ọ.” Lóòótọ́, ọmọkùnrin àgbà yìí kò tíì filé sílẹ̀ tàbí kí ó ré òfin baba rẹ̀ kọjá rí. Ṣùgbọ́n, ṣé ìfẹ́ ni ó sún un láti ṣègbọràn? Ǹjẹ́ sísin baba rẹ̀ tilẹ̀ fún un ní ayọ̀ tòótọ́, àbí ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó ti mú ẹ̀mí èyí-mo-ṣe-náà-níí-jóhun dàgbà, tí ó sì wá gbà lójú ara rẹ̀ pé ọmọ dáadáa lòun, kìkì nítorí pé ó ṣe iṣẹ́ rẹ̀ “nínú pápá”? Bí ó bá jẹ́ ọmọ tí ó ti fara rẹ̀ jin baba rẹ̀ lóòótọ́, èé ṣe tí kò fi ní irú ẹ̀mí tí baba rẹ̀ ní? Nígbà tí a fún un láǹfààní láti fi àánú hàn sí àbúrò rẹ̀, èé ṣe tí kò fi lẹ́mìí fífi ìyọ́nú hàn rárá?—Fi wé Sáàmù 50:20-22.
9. Ṣàlàyé bí àwọn aṣáájú ìsìn Júù ṣe dà bí ọmọkùnrin àgbà.
9 Àwọn aṣáájú ìsìn Júù dà bí ọmọkùnrin àgbà yìí. Wọ́n gbà pé àwọn jẹ́ adúróṣinṣin ti Ọlọ́run nítorí pé wọ́n rinkinkin mọ́ àwọn àkójọ òfin. Lóòótọ́, ìgbọràn ṣe kókó. (1 Sámúẹ́lì 15:22) Ṣùgbọ́n kíkà tí wọ́n ka iṣẹ́ òfin sí ohun tí ó ṣe pàtàkì jù sọ ìjọsìn Ọlọ́run di ti àfaraṣe-máfọkànṣe, ìfọkànsìn ojú ayé lásán tí kò fi jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí hàn. Òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ni ó gbà wọ́n lọ́kàn. Kò sí ìfẹ́ lọ́kàn wọn rárá. Họ́wù, wọ́n ka àwọn gbáàtúù sí ìdọ̀tí tí ó wà ní àtẹ́lẹsẹ̀ wọn, wọ́n sì ń fi tẹ̀gàntẹ̀gàn pè wọ́n ní “ẹni ègún.” (Jòhánù 7:49) Ní tòótọ́, báwo ni iṣẹ́ irú àwọn aṣáájú bẹ́ẹ̀ se lè dùn mọ́ Ọlọ́run nínú nígbà tí ó jẹ́ pé ọkàn-àyà wọn jìnnà réré sí i?—Mátíù 15:7, 8.
10. (a) Èé ṣe tí ọ̀rọ̀ náà, “Àánú ni èmi fẹ́, kì í sì í ṣe ẹbọ” fi jẹ́ ìmọ̀ràn yíyẹ? (b) Báwo ni ìwà àìláàánú ṣe jẹ́ ọ̀ràn tí ó wúwo gan-an?
10 Jésù sọ fún àwọn Farisí láti “lọ . . . kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí èyí túmọ̀ sí, ‘Àánú ni èmi fẹ́, kì í sì í ṣe ẹbọ.’” (Mátíù 9:13; Hóséà 6:6) Wọn kò mọ èyí tí wọn ì bá ṣe, nítorí láìsí àánú gbogbo ìrúbọ wọn yóò já sí asán. Ọ̀ràn ńlá lèyí jẹ́, nítorí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ka àwọn “aláìláàánú” sí àwọn tí wọ́n “yẹ fún ikú.” (Róòmù 1:31, 32) Nítorí náà, kò yani lẹ́nu pé Jésù sọ pé a ti kádàrá ìparun ayérayé fún àwọn aṣáájú ìsìn gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan. Ó ṣe kedere pé, ìwà àìláàánú wọn wà lára ohun tí ó mú kí wọ́n gba ìdájọ́ yìí. (Mátíù 23:33) Ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe láti ran ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó wà nínú ẹgbẹ́ yìí lọ́wọ́. Ní ìparí àkàwé rẹ̀, Jésù tiraka láti tún ojú ìwòye àwọn Júù bẹ́ẹ̀ ṣe nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí baba náà sọ fún ọmọkùnrin rẹ̀ àgbà. Ẹ jẹ́ kí a wo ọ̀nà tí ó gbà ṣe é.
Àánú Baba
11, 12. Ọ̀nà wo ni baba inú òwe Jésù fi gbìyànjú láti fèrò wérò pẹ̀lú ọmọkùnrin rẹ̀ àgbà, kí sì ni ìjẹ́pàtàkì lílò tí baba náà lo àpólà ọ̀rọ̀ náà “arákùnrin rẹ”?
11 “Nígbà náà ni ó wí fún un pé, ‘Ọmọ, nígbà gbogbo ni ìwọ wà pẹ̀lú mi, gbogbo ohun tí ó jẹ́ tèmi jẹ́ tìrẹ; ṣùgbọ́n àwa sáà ní láti gbádùn ara wa, kí a sì yọ̀, nítorí pé arákùnrin rẹ yìí kú, ó sì wá sí ìyè, ó sọnù a sì rí i.’”—Lúùkù 15:31, 32.
12 Ṣàkíyèsí pé baba náà lo gbólóhùn náà, “arákùnrin rẹ.” Èé ṣe? Ó dáa, ẹ rántí pé nígbà tí ẹ̀gbọ́n náà ń bá baba rẹ̀ sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kan, ó pe ọmọ onínàákúnàá náà ní “ọmọkùnrin rẹ”—kò sọ pé “arákùnrin mi.” Ó dà bí ẹni pé kò gbà pè okùn àjọbí so òun àti àbúrò òun pọ̀. Nítorí náà, ohun tí baba náà ń sọ fún èyí ẹ̀gbọ́n ni pé: ‘Ẹni yìí kì í wulẹ̀ ṣe ọmọkùnrin mi. Arákùnrin rẹ ni, ara àti ẹ̀jẹ̀ tìrẹ ni. Kò sí ìdí kankan tí kò fi yẹ kí o kún fún ayọ̀ nítorí tí ó padà wálé!’ Ó dájú pé ìhìn iṣẹ́ Jésù yóò ti yé àwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyẹn kedere. Ní tòótọ́, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n tẹ́ńbẹ́lú jẹ́ “àwọn arákùnrin” tiwọn alára. Ní tòótọ́, “kò sí olódodo kankan ní ilẹ̀ ayé tí ń ṣe rere tí kì í dẹ́ṣẹ̀.” (Oníwàásù 7:20) Nítorí náà, kò sí ìdí kankan tí àwọn Júù tí wọ́n jẹ́ olókìkí kò fi ní kún fún ayọ̀ nígbà tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ronú pìwà dà.
13. Ìbéèrè tí ó gba àròjinlẹ̀ wo ni àkàwé tí Jésù parí láìròtẹ́lẹ̀ fi sílẹ̀ fún wa?
13 Lẹ́yìn ìpàrọwà baba náà, àkàwé náà wá sí ìparí láìròtẹ́lẹ̀. Àfi bíi pé Jésù ń ké sí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ láti parí ìtàn náà fúnra wọn. Ohun yòówù kí ó jẹ́ ìhùwàpadà ẹ̀gbọ́n náà, olùgbọ́ kọ̀ọ̀kan dojú kọ ìbéèrè náà pé, ‘Ìwọ yóò ha nípìn-ín nínú ayọ̀ tí ó máa ń wà ní ọ̀run nígbà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà bí?’ Àwọn Kristẹni lónìí pẹ̀lú ní àǹfààní láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè náà. Lọ́nà wo?
Fífarawé Àánú Ọlọ́run Lónìí
14. (a) Nígbà tí ó bá kan ọ̀ràn àánú, báwo ni a ṣe lè fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tí a rí nínú Éfésù 5:1 sílò? (b) Àṣìlóye wo nípa àánú Ọlọ́run ni ó yẹ kí a ṣọ́ra fún?
14 Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Éfésù níyànjú pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” (Éfésù 5:1) Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, ó yẹ kí a mọrírì àánú Ọlọ́run, kí a jẹ́ kí ó jinlẹ̀ nínú ọkàn-àyà wa, kí a sì fi ànímọ́ yìí hàn nínú ìbálò wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n, ó ń béèrè ìṣọ́ra. Kò yẹ kí a ṣi àánú Ọlọ́run lóye pé ó jẹ́ fífojú kéré ẹ̀ṣẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lè fi ẹ̀mí àìbìkítà ronú pé, ‘Bí mo bá dẹ́ṣẹ̀, mo lè gbàdúrà sí Ọlọ́run fún ìdáríjì, yóò sì fi àánú hàn sí mi.’ Irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ ni ohun tí òǹkọ̀wé Bíbélì náà Júúdà pè ní ‘sísọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run wa di àwáwí fún ìwà àìníjàánu.’ (Júúdà 4) Bí Jèhófà tilẹ̀ jẹ́ aláàánú, “lọ́nàkọnà, kì í dáni sí láìjẹni-níyà” nígbà tí ó bá ń bá oníwà àìtọ́ kan tí kò ronú pìwà dà lò.—Ẹ́kísódù 34:7; fi wé Jóṣúà 24:19; 1 Jòhánù 5:16.
15. (a) Èé ṣe tí àwọn alàgbà ní pàtàkì fi ní láti ní ojú ìwòye tí ó wà déédéé nípa àánú? (b) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alàgbà kò fàyè gba mímọ̀ọ́mọ̀ hùwà àìtọ́, kí ni ó yẹ kí wọ́n sakun láti ṣe, èé sì ti ṣe?
15 Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, a tún gbọ́dọ̀ ṣọ́ra láti má ṣe ṣàṣejù níhà kejì—ìtẹ̀sí dídi aláìgbatẹnirò àti aṣèdájọ́ àwọn tí wọ́n bá fi ìrònúpìwàdà tòótọ́ àti ìbànújẹ́ fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn hàn ní ọ̀nà ti Ọlọ́run. (2 Kọ́ríńtì 7:11) Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àwọn alàgbà ni a fa àbójútó àgùntàn Jèhófà lé lọ́wọ́, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n ní ojú ìwòye tí ó wà déédéé lórí ọ̀ràn yìí, pàápàá nígbà tí wọ́n bá ń bójú tó ọ̀ràn ìdájọ́. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìjọ Kristẹni wà ní mímọ́, ó sì bá Ìwé Mímọ́ mu láti “mú ènìyàn burúkú náà kúrò” nípa ìyọlẹ́gbẹ́. (1 Kọ́ríńtì 5:11-13) Lọ́wọ́ kan náà, ó dára láti nawọ́ àánú síni nígbà tí ìdí tí ó ṣe kedere bá wà. Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alàgbà kì í fàyè gba ìwà àìtọ́ tí a mọ̀ọ́mọ̀ hù, wọ́n ń làkàkà láti fi ìfẹ́ àti àánú báni lò, wọn kò sì ní ré ìlànà ìdájọ́ òdodo kọjá. Wọ́n mọ ìlànà Bíbélì náà dunjú pé: “Ẹni tí kò bá sọ àánú ṣíṣe dàṣà yóò gba ìdájọ́ rẹ̀ láìsí àánú. Àánú a máa yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ìdájọ́.”—Jákọ́bù 2:13; Òwe 19:17; Mátíù 5:7.
16. (a) Ní lílo Bíbélì, fi hàn bí Jèhófà ṣe fi òótọ́ fẹ́ pé kí àwọn tí ó ti ṣìnà padà wá sọ́dọ̀ rẹ̀? (b) Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé àwa pẹ̀lú fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba pípadà tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó ronú pìwà dà padà?
16 Àkàwé ọmọ onínàákúnàá náà mú un ṣe kedere pé Jèhófà fẹ́ kí àwọn tí ó ti ṣìnà padà wá sọ́dọ̀ òun. Ní tòótọ́, ó ń nawọ́ ìkésíni náà sí wọn títí di ìgbà tí wọ́n bá fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò lẹ́mìí ìrònúpìwàdà mọ́ rárá. (Ìsíkíẹ̀lì 33:11; Málákì 3:7; Róòmù 2:4, 5; 2 Pétérù 3:9) Bí ti baba ọmọ onínàákúnàá náà, Jèhófà ń buyì fún àwọn tí wọ́n bá padà, ó ń gbà wọ́n padà gẹ́gẹ́ bí ojúlówó mẹ́ńbà ìdílé náà. Ǹjẹ́ ìwọ ń fara wé Jèhófà lọ́nà yìí bí? Nígbà tí a bá gba onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ kan, tí a ti yọ lẹ́gbẹ́ nígbà kan padà, báwo ni ìwọ ṣe ń hùwà padà? A ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé “ìdùnnú . . . wà ní ọ̀run.” (Lúùkù 15:7) Ṣùgbọ́n ṣé ìdùnnú wà lórí ilẹ̀ ayé, ṣé ó wà nínú ìjọ rẹ, àní nínú ọkàn-àyà rẹ pàápàá? Àbí, gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin ẹ̀gbọ́n inú àkàwé náà, o ha di kùnrùngbùn sínú, bí pé kò tilẹ̀ yẹ kí a fi tayọ̀tayọ̀ gba ẹni náà padà, ẹni tí kò yẹ kí ó fi agbo Ọlọ́run sílẹ̀ tẹ́lẹ̀?
17. (a) Ipò wo ni ó jẹ yọ ní Kọ́ríńtì ọ̀rúndún kìíní, báwo sì ni Pọ́ọ̀lù ṣe gba àwọn tí ó wà nínú ìjọ náà nímọ̀ràn láti yanjú ọ̀ràn náà? (b) Èé ṣe tí ọ̀rọ̀ ìyànjú Pọ́ọ̀lù fi ṣeé mú lò, báwo sì ni a ṣe lè lò ó lónìí? (Tún wo àpótí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún.)
17 Láti lè jẹ́ kí a yẹ ara wa wò nínú ọ̀ràn yìí, gbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 55 Sànmánì Tiwa ní Kọ́ríńtì yẹ̀ wò. Níbẹ̀, ọkùnrin kan tí a ti yọ lẹ́gbẹ́ tún ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe pátápátá lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Kí wá ni àwọn ará yóò ṣe báyìí o? Ṣé kí wọ́n máa ṣiyèméjì nípa ìrònúpìwàdà rẹ̀ ni, kí wọ́n sì túbọ̀ máa yẹra fún un? Ní òdìkejì sí èyí, Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Ẹ fi inú rere dárí jì í, kí ẹ sì tù ú nínú, pé lọ́nà kan ṣáá, kí ìbànújẹ́ rẹ̀ tí ó pàpọ̀jù má bàa gbé irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ mì. Nítorí náà, mo gbà yín níyànjú pé kí ẹ fìdí òtítọ́ ìfẹ́ yín fún un múlẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 2:7, 8) Lọ́pọ̀ ìgbà, ìtìjú àti àìnírètí kì í jẹ́ kí àwọn oníwà àìtọ́ tí wọ́n ti ronú pìwà dà gbádùn. Nítorí náà, ó yẹ kí a mú un dá wọn lójú pé àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àti Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ wọn. (Jeremáyà 31:3; Róòmù 1:12) Èyí ṣe pàtàkì. Èé ṣe?
18, 19. (a) Báwo ni àwọn ará Kọ́ríńtì ṣe kọ́kọ́ fi hàn pé wọ́n gbọ̀jẹ̀gẹ́? (b) Báwo ni ìwà àìláàánú ṣe mú kí àwọn ará Kọ́ríńtì di ẹni tí ‘Sátánì fi ọgbọ́n àyínìke borí’?
18 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń gba àwọn ará Kọ́ríńtì níyànjú láti máa dárí jini, ọ̀kan lára àwọn ìdí tí ó fúnni ni pé, “kí Sátánì má bàa fi ọgbọ́n àyínìke borí wa, nítorí àwa kò ṣe aláìmọ àwọn ète-ọkàn rẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 2:11) Kí ni ó ní lọ́kàn? Ó dáa, ṣáájú àkókò yìí, Pọ́ọ̀lù ti bá ìjọ Kọ́ríńtì wí fún gbígbọ̀jẹ̀gẹ́. Wọ́n ti fàyè gba ọkùnrin kan náà yìí láti máa dá ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lọ láìbá a wí. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ìjọ—ní pàtàkì àwọn alàgbà rẹ̀—kó sọ́wọ́ Sátánì, nítorí ohun tí ó fẹ́ ni láti kó àbààwọ́n ba orúkọ ìjọ náà.—1 Kọ́ríńtì 5:1-5.
19 Bí wọ́n bá tún wá fì sí ìhà kejì, tí wọ́n kọ̀ láti dárí ji ẹni tí ó ronú pìwà dà, Sátánì á fi ọgbọ́n àyínìke borí wọn lọ́nà mìíràn. Lọ́nà wo? Ní ti pé ó lè lo àǹfààní àìgbatẹnirò àti àìláàánú wọn. Bí ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó ronú pìwà dà náà bá di ẹni tí ‘ìbànújẹ́ rẹ̀ tí ó pàpọ̀jù gbé mì’—tàbí gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ Today’s English Version ti sọ ọ́, bí ó bá “banú jẹ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi juwọ́ sílẹ̀ pátápátá”—ẹ wo bí ẹ̀bi àwọn alàgbà náà yóò ṣe pọ̀ tó níwájú Jèhófà! (Fi wé Ìsíkíẹ̀lì 34:6; Jákọ́bù 3:1.) Pẹ̀lú ìdí rere, lẹ́yìn tí Jésù kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa ṣíṣọ́ra fún mímú “ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí” kọsẹ̀, ó wí pé: “Ẹ fiyè sí ara yín. Bí arákùnrin rẹ bá dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, fún un ní ìbáwí mímúná, bí ó bá sì ronú pìwà dà, dárí jì í.”a—Lúùkù 17:1-4.
20. Lọ́nà wo ni ìdùnnú fi máa ń wà ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà?
20 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún tí ń padà sínú ìjọsìn mímọ́ gaara lọ́dọọdún ń dúpẹ́ fún àánú tí Jèhófà ti fi hàn sí wọn. Arábìnrin kan tí ó jẹ́ Kristẹni sọ nípa gbígbà tí a gbà á padà pé: “N kò rántí àkókò kan nínú ìgbésí ayé mi tí inú mi dùn tó bẹ́ẹ̀ rí.” Dájúdájú, àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú bá a yọ̀. Ǹjẹ́ kí àwa pẹ̀lú dara pọ̀ nínú ‘ìdùnnú tí ó wà ní ọ̀run,’ èyí tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà. (Lúùkù 15:7) Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a óò máa fara wé àánú Jèhófà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jọ pé a gba oníwà àìtọ́ tí ó wà ní ìjọ Kọ́ríńtì padà láàárín àkókò kúkúrú, a kò ní láti lo èyí gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá ìdiwọ̀n fún gbogbo ìyọlẹ́gbẹ́. Ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan máa ń yàtọ̀ síra. Àwọn oníwà àìtọ́ kan máa ń fi ìrònúpìwàdà tòótọ́ hàn ní kété lẹ́yìn tí a bá ti yọ wọ́n lẹ́gbẹ́. Àwọn mìíràn sì rèé, ó máa ń pẹ́ díẹ̀ kí wọ́n tó fi irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ hàn. Ṣùgbọ́n, ní gbogbo ọ̀ràn, àwọn tí a bá gbà padà ti gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ fi ẹ̀rí ìbànújẹ́ ní ọ̀nà ti Ọlọ́run hàn, níbi tí ó bá sì ti ṣeé ṣe, wọ́n ti gbọ́dọ̀ fi iṣẹ́ tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà hàn.—Ìṣe 26:20; 2 Kọ́ríńtì 7:11.
Àtúnyẹ̀wò
◻ Ọ̀nà wo ni ẹ̀gbọ́n ọmọ onínàákúnàá náà fi dà bí àwọn aṣáájú ìsìn Júù?
◻ Ọ̀nà wo ni ẹ̀gbọ́n ọmọ onínàákúnàá náà kò fi mọ ohun tí jíjẹ́ ọmọ túmọ̀ sí?
◻ Ní fífi àánú Ọlọ́run hàn, àṣejù ní ìhà méjì wo ni a ní láti yẹra fún?
◻ Báwo ni a ṣe lè fara wé àánú Ọlọ́run lónìí?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]
“Ẹ FÌDÍ ÒTÍTỌ́ ÌFẸ́ YÍN FÚN UN MÚLẸ̀”
Ní ti oníwà àìtọ́ náà tí a yọ lẹ́gbẹ́ tó sì ti fi ìrònúpìwàdà hàn, Pọ́ọ̀lù sọ fún ìjọ Kọ́ríńtì pé: “Mo gbà yín níyànjú pé kí ẹ fìdí òtítọ́ ìfẹ́ yín fún un múlẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 2:8) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a tú sí “fìdí . . . múlẹ̀” jẹ́ ọ̀rọ̀ òfin tó túmọ̀ sí láti “mú lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kí àwọn tí wọ́n ronú pìwà dà tí a sì ti gbà padà mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn àti pé a tún ti fi tayọ̀tayọ̀ gbà wọ́n lẹ́ẹ̀kan sí i gẹ́gẹ́ bí mẹ́ńbà ìjọ.
Àmọ́ ṣá o, a gbọ́dọ̀ rántí pé, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn mẹ́ńbà ìjọ ni kò mọ ipò nǹkan náà tí ó mú kí a yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́ tàbí tó mú kí a gbà á padà. Ní àfikún sí i, àwọn kan lè wà tí ìwà àìtọ́ tí ẹni tí ó ronú pìwà dà náà hù ti bà lọ́kàn jẹ́ tàbí bí nínú gidigidi—bóyá fún ìgbà pípẹ́ pàápàá. Nítorí náà, bí a ti ń gba ìmọ̀lára àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ rò lórí ọ̀ràn yìí, yóò dára kí a pa ayọ̀ wa mọ́ra nígbà tí a bá kéde ìgbàpadà onítọ̀hún, a lè jẹ́ kí ó di ìgbà tó bá ku àwa pẹ̀lú rẹ̀ nìkan.
Ẹ wo bí ó ti ń fún ìgbàgbọ́ àwọn tí a gbà padà lókun tó láti mọ̀ pé a fi tayọ̀tayọ̀ kí wọn káàbọ̀ gẹ́gẹ́ bí mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni! A lè fún irú àwọn tí ó ronú pìwà dà bẹ́ẹ̀ níṣìírí nípa jíjíròrò pẹ̀lú wọn àti nípa gbígbádùn ìfararora pẹ̀lú wọn ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, àti ní àwọn ibòmíràn tí ó bá yẹ. Nípa fífìdí òtítọ́ ìfẹ́ wa múlẹ̀, tàbí mímú kí ìfẹ́ wa lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹni ọ̀wọ́n wọ̀nyí, a kò tíì ṣe ohunkóhun tí ó fi hàn pé a fojú kéré bí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá ti wúwo tó. Kàkà bẹ́ẹ̀, papọ̀ pẹ̀lú àwọn ogun ọ̀run, inú wa dùn ní ti pé wọ́n ti kọ ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ wọn sílẹ̀, wọ́n sì ti padà wá sọ́dọ̀ Jèhófà.—Lúùkù 15:7.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ọmọkùnrin àgbà kọ̀ láti yọ̀ fún pípadà tí arákùnrin rẹ̀ padà wálé