ORÍ 106
Àpèjúwe Méjì Nípa Ọgbà Àjàrà
MÁTÍÙ 21:28-46 MÁÀKÙ 12:1-12 LÚÙKÙ 20:9-19
ÀPÈJÚWE NÍPA ỌMỌ MÉJÌ
ÀPÈJÚWE NÍPA ÀWỌN TÓ BÓJÚ TÓ ỌGBÀ ÀJÀRÀ KAN
Nígbà tí Jésù wà nínú tẹ́ńpìlì, àwọn olórí àlùfáà àtàwọn àgbààgbà béèrè ẹni tó fún un ní àṣẹ tó fi ń ṣe nǹkan. Ìdáhùn tí Jésù fún wọn mú kí ọ̀rọ̀ náà dà rú mọ́ wọn lójú. Ni wọ́n bá gbẹ́nu dákẹ́. Lẹ́yìn náà, Jésù sọ àpèjúwe kan tó jẹ́ ká túbọ̀ mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ ní ti gidi.
Jésù sọ pé: “Ọkùnrin kan ní ọmọ méjì. Ó lọ bá àkọ́kọ́, ó sọ pé, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà lónìí.’ Ọmọ náà fèsì pé, ‘Mi ò lọ,’ àmọ́ lẹ́yìn náà, ó pèrò dà, ó sì lọ. Ó lọ bá ìkejì, ó sọ ohun kan náà fún un. Ọmọ náà sì fèsì pé, ‘Màá lọ Sà,’ àmọ́ kò lọ. Èwo nínú àwọn méjèèjì ló ṣe ìfẹ́ bàbá rẹ̀?” (Mátíù 21:28-31) Ìdáhùn ìbéèrè yẹn ò lọ́jú pọ̀ rárá, torí pé ọmọ tí bàbá yẹn kọ́kọ́ bá sọ̀rọ̀ ló pa dà ṣe ohun tí bàbá yẹn fẹ́.
Jésù wá sọ fáwọn alátakò rẹ̀ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, àwọn agbowó orí àti àwọn aṣẹ́wó máa ṣáájú yín lọ sínú Ìjọba Ọlọ́run.” Níbẹ̀rẹ̀ àwọn agbowó orí àtàwọn aṣẹ́wó ò sin Jèhófà. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n ṣe bíi ti ọmọ àkọ́kọ́, wọ́n ronú pìwà dà, wọ́n sì ti wá ń sin Ọlọ́run báyìí. Àmọ́ ní ti àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn, ṣe lọ̀rọ̀ wọn dà bíi ti ọmọ kejì. Wọ́n ń sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run, àmọ́ wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Jésù wá sọ pé: “Jòhánù [Arinibọmi] wá sọ́dọ̀ yín ní ọ̀nà òdodo, àmọ́ ẹ ò gbà á gbọ́. Ṣùgbọ́n àwọn agbowó orí àti àwọn aṣẹ́wó gbà á gbọ́, kódà nígbà tí ẹ rí èyí, ẹ ò pèrò dà lẹ́yìn náà kí ẹ lè gbà á gbọ́.”—Mátíù 21:31, 32.
Jésù tún sọ àpèjúwe míì lẹ́yìn ìyẹn. Lọ́tẹ̀ yìí, Jésù fi hàn pé ohun táwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn ṣe kọjá pé wọn ò sin Ọlọ́run. Ìkà burúkú ni wọ́n. Jésù sọ pé: “Ọkùnrin kan gbin àjàrà, ó sì ṣe ọgbà yí i ká, ó gbẹ́ ẹkù sí ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì, ó sì kọ́ ilé gogoro kan; ó wá gbé e fún àwọn tó ń dáko, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè. Nígbà tí àsìkò tó, ó rán ẹrú kan lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń dáko náà pé kó gbà lára àwọn èso ọgbà àjàrà náà lọ́wọ́ wọn. Àmọ́ wọ́n mú un, wọ́n lù ú, wọ́n sì ní kó máa lọ lọ́wọ́ òfo. Ó tún rán ẹrú míì sí wọn àmọ́ wọ́n lù ú ní orí, wọ́n sì kàn án lábùkù. Ó rán ẹlòmíì, wọ́n sì pa á, ó tún rán ọ̀pọ̀ àwọn míì, wọ́n lu àwọn kan nínú wọn, wọ́n sì pa àwọn míì.”—Máàkù 12:1-5.
Ṣé àpèjúwe yìí máa yé àwọn èèyàn? Ó ṣeé ṣe kí wọ́n rántí ohun tí wòlíì Àìsáyà sọ nígbà tó ń dẹ́bi fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ilé Ísírẹ́lì ni ọgbà àjàrà Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun; àwọn èèyàn Júdà sì ni oko tó fẹ́ràn. Ó ń retí ìdájọ́ òdodo, àmọ́ wò ó! ìrẹ́jẹ ló wà.” (Àìsáyà 5:7) Ohun tí Àìsáyà sọ yìí jọra pẹ̀lú àpèjúwe Jésù yẹn. Jèhófà ló gbin àjàrà, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ló dà bí ọgbà àjàrà náà, Òfin Ọlọ́run ló dà bí ọgbà tó yí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ká, tó sì ń dáàbò bò wọ́n. Jèhófà rán àwọn wòlíì sí wọn láti tọ́ wọn sọ́nà, kí wọ́n lè máa so èso tó dáa.
Ṣùgbọ́n, “àwọn tó ń dáko” ṣe àwọn “ẹrú” tí wọ́n rán sí wọn ṣúkaṣùka, wọ́n sì pa wọ́n. Jésù wá ṣàlàyé pé: “Ẹnì kan tó ṣẹ́ kù [fún ẹni tó ni ọgbà àjàrà yẹn] ni ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. Òun ló rán sí wọn gbẹ̀yìn, ó ní, ‘Wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún ọmọ mi.’ Àmọ́ àwọn tó ń dáko náà sọ fún ara wọn pé, ‘Ẹni tó máa jogún rẹ̀ nìyí. Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká pa á, ogún rẹ̀ sì máa di tiwa.’ Torí náà, wọ́n mú un, wọ́n [sí] pa á.”—Máàkù 12:6-8.
Jésù wá bi wọ́n pé: “Kí ni ẹni tó ni ọgbà àjàrà náà máa ṣe?” (Máàkù 12:9) Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn dá a lóhùn pé: “Torí pé èèyàn burúkú ni wọ́n, ó máa mú ìparun tó lágbára wá sórí wọn, ó sì máa gbé ọgbà àjàrà náà fún àwọn míì tó ń dáko, tí wọ́n máa fún un ní èso nígbà tí àkókò bá tó.”—Mátíù 21:41.
Láìmọ̀, ṣe ni wọ́n ń dá ara wọn lẹ́jọ́, torí wọ́n wà lára “àwọn tó ń dáko” tí Jèhófà ní kó máa bójú tó orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó jẹ́ “ọgbà àjàrà” rẹ̀. Ọ̀kan lára èso tí Jèhófà ń retí látọ̀dọ̀ wọn ni pé kí wọ́n nígbàgbọ́ nínú Ọmọ rẹ̀, ìyẹn Mèsáyà. Jésù wá kọjú sáwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn, ó sì sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ ò ka ìwé mímọ́ yìí rí ni, pé: ‘Òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀, òun ló wá di olórí òkúta igun ilé. Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni èyí ti wá, ó sì jẹ́ ìyanu lójú wa’?” (Máàkù 12:10, 11) Lẹ́yìn náà, Jésù ṣàlàyé fún wọn pé: “Ìdí nìyí tí mo fi sọ fún yín pé, a máa gba Ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a sì máa fún orílẹ̀-èdè tó ń mú èso rẹ̀ jáde.”—Mátíù 21:43.
Àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn olórí àlùfáà rí i pé ‘àwọn ni Jésù ń fi àpèjúwe yìí bá wí.’ (Lúùkù 20:19) Torí pé Jésù ló “máa jogún” olóko yẹn, àwọn aṣáájú ìsìn yìí túbọ̀ ń wá bí wọ́n ṣe máa pa á. Àmọ́ wọ́n ń bẹ̀rù àwọn èèyàn tó wà lọ́dọ̀ Jésù, torí àwọn èèyàn yẹn gbà pé wòlíì ni Jésù. Torí náà wọn ò lè pa á níbẹ̀.