ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 15
Ohun Tá A Rí Kọ́ Nínú Àwọn Ọ̀rọ̀ Tí Jésù Sọ Kẹ́yìn
“Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà. Ẹ fetí sí i.”—MÁT. 17:5.
ORIN 17 “Mo Fẹ́ Bẹ́ẹ̀”
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1-2. Kí ló ṣẹlẹ̀ tó mú kí Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ kẹ́yìn kó tó kú?
NÍ NÍSÀN 14, 33 S.K., wọ́n fẹ̀sùn èké kan Jésù, wọ́n sì dá a lẹ́jọ́ pé ó jẹ̀bi ohun tí ò ṣe. Lẹ́yìn náà, wọ́n fi Jésù ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n fìyà jẹ ẹ́, wọ́n tún kàn án mọ́ òpó igi oró, kó lè jẹ̀rora títí táá fi kú. Ẹ wo bí ìrora Jésù ṣe máa pọ̀ tó bí wọ́n ṣe ń gbá ìṣó mọ́ ọn ní ọwọ́ àti ẹsẹ̀, ó dájú pé ara á máa ni ín bó ṣe ń mí, tó sì ń sọ̀rọ̀. Láìka ìrora yẹn sí, àwọn nǹkan pàtàkì kan wà tí Jésù gbọ́dọ̀ sọ.
2 Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn nǹkan tí Jésù sọ bó ṣe ń jẹ̀rora lórí òpó igi oró, àá sì wo àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ nínú wọn. Lédè míì, ẹ jẹ́ ká “fetí sí i.”—Mát. 17:5.
“BABA, DÁRÍ JÌ WỌ́N”
3. Àwọn wo ló ṣeé ṣe kí Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Baba, dárí jì wọ́n”?
3 Kí ni Jésù sọ? Bí Jésù ṣe ń jẹ̀rora lórí òpó igi oró, ó gbàdúrà pé: “Baba, dárí jì wọ́n.” Dárí ji ta ni? Ohun tó sọ tẹ̀ lé e jẹ́ ká mọ àwọn tó ní lọ́kàn, ó ní: “Wọn ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” (Lúùkù 23:33, 34) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun Róòmù tó kan ìṣó mọ́ ọn lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀ ló ní lọ́kàn. Ìdí ni pé wọn ò mọ ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an. Ó tún ṣeé ṣe kó jẹ́ torí àwọn kan tó fọwọ́ sí i pé kí wọ́n pa á àmọ́ tí wọ́n ṣì máa nígbàgbọ́ nínú rẹ̀. (Ìṣe 2:36-38) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà ìkà ni wọ́n hù sí Jésù, kò bínú tàbí kó máa dá àwọn tó pa á lẹ́bi. (1 Pét. 2:23) Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló bẹ Jèhófà pé kó dárí ji àwọn tó pa òun.
4. Kí la rí kọ́ látinú bí Jésù ṣe dárí ji àwọn tó hùwà ìkà sí i?
4 Kí la rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ? Bíi ti Jésù, a gbọ́dọ̀ múra tán láti máa dárí ji àwọn míì. (Kól. 3:13) Àwọn èèyàn títí kan àwọn mọ̀lẹ́bí wa lè máa ta kò wá torí pé ohun tá a gbà gbọ́ ò yé wọn àti pé ìwà wa yàtọ̀ sí tiwọn. Wọ́n lè parọ́ mọ́ wa, kí wọ́n dójú tì wá níṣojú àwọn míì, kí wọ́n da àwọn ìwé wa nù tàbí kí wọ́n tiẹ̀ halẹ̀ mọ́ wa pé àwọn á lù wá. Dípò ká máa bínú sí wọn, a lè bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ káwọn tó ń ta kò wá lóye òtítọ́. (Mát. 5:44, 45) Nígbà míì, ó lè ṣòro fún wa láti dárí jì wọ́n, pàápàá tó bá jẹ́ pé wọ́n hùwà ìkà sí wa. Àmọ́ tá a bá kọ̀ tá ò dárí jì wọ́n, ó lè ṣàkóbá fún wa. Arábìnrin kan sọ pé: “Tí mo bá ń dárí ji àwọn míì, kò túmọ̀ sí pé mò ń gba ìgbàkugbà láyè tàbí pé mò ń jẹ́ káwọn èèyàn rẹ́ mi jẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni mo máa ń gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, mo sì máa ń jẹ́ kó tán nínú mi.” (Sm. 37:8) Tá a bá ń dárí jini, ìyẹn fi hàn pé a ò jẹ́ kí ohun táwọn èèyàn ṣe sí wa mú ká máa bínú, a sì fẹ́ kọ́rọ̀ náà tán nínú wa.—Éfé. 4:31, 32.
“O MÁA WÀ PẸ̀LÚ MI NÍ PÁRÁDÍSÈ”
5. Ìlérí wo ni Jésù ṣe fún ọ̀kan lára àwọn ọ̀daràn tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, kí sì nìdí tó fi ṣèlérí náà?
5 Kí ni Jésù sọ? Wọ́n kan àwọn ọ̀daràn méjì mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù. Níbẹ̀rẹ̀, àwọn méjèèjì ń fi Jésù ṣe yẹ̀yẹ́. (Mát. 27:44) Àmọ́ nígbà tó yá, ọ̀kan nínú wọn ò fi Jésù ṣe yẹ̀yẹ́ mọ́. Ìdí ni pé ó gbà pé Jésù ò ṣe “nǹkan kan tó burú.” (Lúùkù 23:40, 41) Ó fi hàn pé òun nígbàgbọ́ pé Jésù máa jíǹde àti pé ó máa di ọba lọ́jọ́ kan. Ó sọ pé: “Jésù, rántí mi tí o bá dé inú Ìjọba rẹ.” (Lúùkù 23:42) Àbí ẹ ò rí i pé ọkùnrin yẹn nígbàgbọ́! Jésù wá dá a lóhùn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, o máa wà pẹ̀lú mi ní Párádísè,” kì í ṣe nínú Ìjọba náà. (Lúùkù 23:43) Ẹ kíyè sí i pé Jésù lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi “mo,” “o” àti “mi” láti jẹ́ kó dá ọkùnrin náà lójú pé òun gan-an lòun ṣèlérí fún. Jésù ṣe ìlérí tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ fún ọkùnrin yìí torí ó mọ̀ pé aláàánú ni Jèhófà.—Sm. 103:8.
6. Kí la kọ́ nínú ohun tí Jésù sọ fún ọ̀daràn yẹn?
6 Kí la rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ? Jésù fìwà jọ Bàbá rẹ̀ láìkù síbì kan. (Héb. 1:3) Ó máa ń wu Jèhófà láti fàánú hàn sí wa, kó sì dárí jì wá. Àmọ́ kí Jèhófà tó lè dárí jì wá, a gbọ́dọ̀ kábàámọ̀ ohun tá a ṣe ká sì nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. (1 Jòh. 1:7) Ó máa ń ṣe àwọn kan bíi pé Jèhófà ò lè dárí jì wọ́n láé. Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn, rántí pé Jésù fàánú hàn sí ọ̀daràn kan tó bẹ̀rẹ̀ sí í nígbàgbọ́ nígbà tó ku díẹ̀ kó kú. Tí irú ọ̀daràn bẹ́ẹ̀ bá lè rí àánú gbà, ó dájú pé Jèhófà máa fàánú hàn sáwa ìránṣẹ́ rẹ̀ tá à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́!—Sm. 51:1; 1 Jòh. 2:1, 2.
“WÒ Ó! ỌMỌ RẸ! . . . WÒ Ó! ÌYÁ RẸ!”
7. Kí ni Jésù sọ fún Màríà àti Jòhánù nínú Jòhánù 19:26, 27, kí sì nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀?
7 Kí ni Jésù sọ? (Ka Jòhánù 19:26, 27.) Ó wu Jésù pé kó tọ́jú ìyá rẹ̀ tó ṣeé ṣe kó ti di opó. Kò sí àní-àní pé ó yẹ káwọn àbúrò Jésù lè pèsè ohun tí ìyá wọn nílò nípa tara. Àmọ́ ta ló máa pèsè ohun tó nílò nípa tẹ̀mí? Lásìkò yẹn, kò jọ pé àwọn àbúrò Jésù ti di ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Àmọ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ Jésù ni Jòhánù, ó sì tún jẹ́ àpọ́sítélì tó ṣeé fọkàn tán. Àwọn tó ń sin Jèhófà ni Jésù kà sí ìdílé rẹ̀ nípa tẹ̀mí. (Mát. 12:46-50) Jésù nífẹ̀ẹ́ Màríà gan-an, ó sì fẹ́ rí i dájú pé ó rí àbójútó tó yẹ. Ìdí nìyẹn tó fi fa Màríà lé Jòhánù lọ́wọ́ torí ó mọ̀ pé Jòhánù máa bójú tó o nípa tẹ̀mí. Ó sọ fún Màríà pé: “Wò ó! Ọmọ rẹ!” Ó sì sọ fún Jòhánù pé: “Wò ó! Ìyá rẹ!” Àtọjọ́ yẹn ni Jòhánù ti mú Màríà sọ́dọ̀, ó sì tọ́jú rẹ̀ bíi pé ìyá ẹ̀ gangan ni. Ẹ ò rí i pé Jésù nífẹ̀ẹ́ ìyá rẹ̀ ọ̀wọ́n, ó sì dájú pé kò gbàgbé bí ìyá rẹ̀ ṣe fìfẹ́ bójú tó o ní kékeré, tó sì tún dúró tì í nígbà tó máa kú!
8. Kí la rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún Màríà àti Jòhánù?
8 Kí la rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ? Nígbà míì, àjọṣe tó wà láàárín àwa àtàwọn ará máa ń lágbára ju àjọṣe tó wà láàárín àwa àti ìdílé wa lọ. Àwọn mọ̀lẹ́bí wa lè máa ta kò wá tàbí kí wọ́n tiẹ̀ pa wá tì, àmọ́ Jésù ṣèlérí pé tá ò bá fi Jèhófà àti ètò rẹ̀ sílẹ̀, a máa “gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100)” ohun tá a pàdánù. A máa rí ọ̀pọ̀ àwọn tó máa dà bí ọmọ fún wa, àwọn táá dà bí ẹ̀gbọ́n, àbúrò, ìyá àti bàbá. (Máàkù 10:29, 30) Báwo ló ṣe rí lára ẹ pé o wà nínú ẹgbẹ́ ará tó wà níṣọ̀kan torí pé wọ́n nígbàgbọ́, wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn?—Kól. 3:14; 1 Pét. 2:17.
“ỌLỌ́RUN MI, KÍ LÓ DÉ TÍ O FI KỌ̀ MÍ SÍLẸ̀?”
9. Kí ni ohun tí Jésù sọ nínú Mátíù 27:46 jẹ́ ká mọ̀?
9 Kí ni Jésù sọ? Kí Jésù tó kú, ó ké jáde pé: “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?” (Mát. 27:46) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò sọ ìdí tí Jésù fi sọ bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí ọ̀rọ̀ náà jẹ́ ká mọ̀. Ohun kan ni pé Jésù mú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Sáàmù 22:1 ṣẹ nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ yìí.b Bákan náà, ohun tí Jésù sọ fi hàn pé Jèhófà ò ṣe “ọgbà yí i ká láti dáàbò” bò ó. (Jóòbù 1:10) Ó yé Jésù pé ṣe ni Jèhófà yọ̀ǹda pé káwọn ọ̀tá dán òun wò dé góńgó, kódà kò sẹ́ni tó tíì kojú àdánwò bẹ́ẹ̀ rí. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fi hàn pé ọrùn ẹ̀ mọ́ pátápátá, kò sì jẹ̀bi ẹ̀sùn kankan.
10. Kí la rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún Bàbá rẹ̀?
10 Kí la rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ? Ẹ̀kọ́ kan ni pé a ò gbọ́dọ̀ retí pé ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa dáàbò bò wá ká má bàa kojú àdánwò. Bí Jèhófà ṣe fàyè gba àwọn ọ̀tá láti dán Jésù wò dé góńgó, àwa náà gbọ́dọ̀ ṣe tán láti jẹ́ olóòótọ́ kódà títí dójú ikú. (Mát. 16:24, 25) Àmọ́, ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní jẹ́ kí wọ́n dán wa wò kọjá ohun tá a lè mú mọ́ra. (1 Kọ́r. 10:13) Ẹ̀kọ́ míì ni pé bíi ti Jésù, wọ́n lè fìyà jẹ wá láìṣẹ̀ láìrò. (1 Pét. 2:19, 20) Kì í ṣe torí pé a hùwà àìdáa ni wọ́n ṣe ń ta kò wá. Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a kì í ṣe apá kan ayé, a sì ń jẹ́rìí sí òtítọ́. (Jòh. 17:14; 1 Pét. 4:15, 16) Jésù mọ ìdí tí Jèhófà fi fàyè gba pé kóun jìyà. Àmọ́ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan béèrè ìbéèrè kí wọ́n lè mọ ìdí tí Jèhófà fi fàyè gba àwọn nǹkan kan. (Háb. 1:3) Torí pé aláàánú àti onísùúrù ni Jèhófà, kò wò wọ́n bí ẹni tí ò nígbàgbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó mọ̀ pé ṣe ni wọ́n fẹ́ kí òun tu àwọn nínú.—2 Kọ́r. 1:3, 4.
“ÒÙNGBẸ Ń GBẸ MÍ”
11. Kí nìdí tí Jésù fi sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Jòhánù 19:28?
11 Kí ni Jésù sọ? (Ka Jòhánù 19:28.) Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé: “Òùngbẹ ń gbẹ mí”? Ó sọ bẹ́ẹ̀ “kí ìwé mímọ́ lè ṣẹ,” ìyẹn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Sáàmù 22:15 tó sọ pé: “Okun mi ti tán, mo dà bí èéfọ́ ìkòkò; ahọ́n mi lẹ̀ mọ́ ẹran ìdí eyín mi.” Bákan náà, ó dájú pé òùngbẹ ń gbẹ ẹ́ gan-an torí wọ́n ti fìyà jẹ ẹ́, ó sì ń joró lórí òpó igi. Ìdí nìyẹn tó fi ní kí wọ́n fún òun lómi.
12. Kí la rí kọ́ látinú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé “òùngbẹ ń gbẹ mí”?
12 Kí la rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ? Jésù gbà pé kò sóhun tó burú láti sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀. Torí náà, ó yẹ káwa náà máa sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa. Lọ́pọ̀ ìgbà, a kì í fẹ́ sọ ohun tó ń ṣe wá fáwọn míì, àmọ́ tọ́rọ̀ bá dójú ẹ̀, tá a sì rí i pé a nílò ìrànlọ́wọ́, kò yẹ ká dé ọ̀rọ̀ náà mọ́ra. Ó ṣe tán wọ́n ní téèyàn bá dákẹ́, tara ẹ̀ á bá a dákẹ́. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé àgbàlagbà ni wá tàbí pé ara wa ò yá, a lè bẹ ọ̀rẹ́ wa kan pé kó gbé wa lọ síbi tá a ti fẹ́ rajà tàbí ilé ìwòsàn. Tá a bá rẹ̀wẹ̀sì, a lè fọ̀rọ̀ lọ alàgbà kan tàbí Kristẹni míì tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀ kó lè fi “ọ̀rọ̀ rere” gbé wa ró. (Òwe 12:25) Rántí pé àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin nífẹ̀ẹ́ ẹ, wọ́n sì ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ ní “ìgbà wàhálà.” (Òwe 17:17) Àmọ́, wọn ò lè rí ọkàn ẹ, wọn ò sì lè mọ̀ pé o nílò ìrànlọ́wọ́ àfi tó o bá sọ fún wọn.
“A TI ṢE É PARÍ!”
13. Kí ni Jésù ṣe parí bó ṣe jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú?
13 Kí ni Jésù sọ? Ní nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán Nísàn 14, Jésù ké jáde pé: “A ti ṣe é parí!” (Jòh. 19:30) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ó parí gbogbo ohun tí Jèhófà fẹ́ kó ṣe. Jésù ṣàṣeparí àwọn nǹkan kan bó ṣe jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú. Lákọ̀ọ́kọ́, Jésù fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé èèyàn pípé lè jẹ́ olóòótọ́ láìka ohun yòówù kí Sátánì ṣe fún un. Ìkejì, Jésù fi ẹ̀mí ẹ̀ ṣe ìràpadà. Bó ṣe fẹ̀mí ẹ̀ rà wá pa dà mú kó ṣeé ṣe fáwa èèyàn aláìpé láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, ká sì nírètí àtiwà láàyè títí láé lọ́jọ́ iwájú. Ìkẹta, Jésù fi hàn pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run, ó sì mú gbogbo ẹ̀gàn tí wọ́n mú bá orúkọ Bàbá rẹ̀ kúrò.
14. Kí ló yẹ ká pinnu láti máa ṣe lójoojúmọ́ ayé wa? Ṣàlàyé.
14 Kí la rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ? A gbọ́dọ̀ pinnu láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà lójoojúmọ́ ayé wa. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Arákùnrin Maxwell Friend tó ti fìgbà kan rí jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì sọ. Ní àpéjọ àgbáyé kan, Arákùnrin Friend sọ àsọyé tó dá lórí ìṣòtítọ́, ó ní: “Ṣe ohun tó bá yẹ lásìkò, má ṣe máa fòní dónìí, fọ̀la dọ́la. Ìdí ni pé kò sẹ́ni tó mọ ilẹ̀ tó máa mọ́ lọ́la. Torí náà, máa lo ọjọ́ kọ̀ọ̀kan bíi pé ọjọ́ kan tó kù fún ẹ nìyẹn láti fi hàn pé o yẹ lẹ́ni tí Jèhófà máa jẹ́ kó gbé títí láé nínú ayé tuntun.” Bí Arákùnrin Friend ṣe sọ, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa lo ọjọ́ kọ̀ọ̀kan bíi pé ọjọ́ kan tó kù fún wa nìyẹn láti jẹ́ adúróṣinṣin! Tí ikú bá sì dé, ọkàn wa á balẹ̀ láti sọ pé “Jèhófà, mo ti ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti jẹ́ olóòótọ́, mo ti fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì, mo ti sọ orúkọ rẹ di mímọ́, mo sì ti fi hàn pé ìwọ ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run!”
“ỌWỌ́ RẸ NI MO FI Ẹ̀MÍ MI LÉ”
15. Kí ni Lúùkù 23:46 sọ pé ó dá Jésù lójú?
15 Kí ni Jésù sọ? (Ka Lúùkù 23:46.) Jésù nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà, ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Baba, ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.” Jésù mọ̀ pé Jèhófà nìkan ló lè jí òun dìde, ó sì dá a lójú pé Jèhófà ò ní gbàgbé òun.
16. Kí lo rí kọ́ nínú ohun tí ọ̀dọ́kùnrin kan sọ?
16 Kí la rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ? Ó yẹ kí ìwọ náà ṣe tán láti fi ẹ̀mí rẹ sọ́wọ́ Jèhófà. Kó o tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, o gbọ́dọ̀ “fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.” (Òwe 3:5) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) kan tó ń jẹ́ Joshua nígbà tó ní àìsàn gbẹ̀mí-gbẹ̀mí. Ó kọ̀ jálẹ̀ nígbà táwọn dókítà fẹ́ tọ́jú ẹ̀ lọ́nà tí kò bá ìlànà Bíbélì mu. Nígbà tó ku díẹ̀ kó kú, ó sọ fún màmá rẹ̀ pé: “Màámi, Jèhófà máa bójú tó mi. . . . Ó dá mi lójú pé kò ní fi mí sílẹ̀. Mo mọ̀ pé Jèhófà máa jí mi dìde. Ó rí ọkàn mi, ó sì mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ òun.”c Torí náà, ó yẹ kí kálukú wa bi ara ẹ̀ pé, ‘Tí mo bá dojú kọ àdánwò tó lè gbẹ̀mí mi, ṣé màá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé kò ní gbàgbé mi, ó sì máa jí mi dìde?’
17-18. Kí la ti kọ́? (Tún wo àpótí náà “Kí La Rí Kọ́ Nínú Àwọn Ọ̀rọ̀ Tí Jésù Sọ Kẹ́yìn?”)
17 Ẹ ò rí i pé àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì la rí kọ́ látinú àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ kẹ́yìn! A ti rí i pé ó yẹ ká máa dárí ji àwọn míì, kó sì dá àwa náà lójú pé Jèhófà máa dárí jì wá. Bákan náà, a ní àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó yí wa ká, tí wọ́n sì ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a nílò ìrànlọ́wọ́ wọn. Yàtọ̀ síyẹn, a mọ̀ pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò èyíkéyìí tó bá dé bá wa. A sì rí ìdí tó fi yẹ kí gbogbo wa máa lo ọjọ́ kọ̀ọ̀kan bíi pé ọjọ́ kan tó kù fún wa nìyẹn láti jẹ́ adúróṣinṣin torí ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní gbàgbé wa.
18 Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè kọ́ nínú ohun tí Jésù sọ bó ṣe ń jẹ̀rora lórí òpó igi oró. Tá a bá ń fi àwọn ẹ̀kọ́ tó wà níbẹ̀ sílò, ṣe là ń ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa Ọmọ rẹ̀ pé: “Ẹ fetí sí i.”—Mát. 17:5.
ORIN 126 Wà Lójúfò, Dúró Gbọn-in, Jẹ́ Alágbára
a Mátíù 17:5 jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ ká máa fetí sí Ọmọ òun. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun tá a lè kọ́ látinú àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nígbà tó wà lórí òpó igi oró.
b Tó o bá fẹ́ àlàyé nípa ohun tó ṣeé ṣe kó mú kí Jésù sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 22:1, wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.
c Wo àpilẹ̀kọ náà “Ìgbàgbọ́ Joshua—Ìṣẹ́gun fún Ẹ̀tọ́ Àwọn Ọmọdé” nínú Jí! January 22, 1995.