Mọ Jehofa Nipasẹ Òrọ̀ Rẹ̀
“Ìyè ainipẹkun naa sì ni eyi, ki wọn ki o lè mọ̀ ọ́, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹni ti iwọ rán.”—JOHANNU 17:3.
1, 2. (a) Ki ni itumọ “mọ̀” ati “ìmọ̀” gẹgẹ bi a ti ṣe lò ó ninu Iwe Mimọ? (b) Awọn apẹẹrẹ wo ni wọn mú itumọ yii ṣe kedere?
LATI mọ ẹnikan gẹgẹ bi ojulumọ kan lasan tabi lati ní ìmọ̀ nipa ohun kan ni ọ̀nà oréfèé kéré si itumọ awọn ọ̀rọ̀ naa “mọ̀” ati “ìmọ̀” gẹgẹ bi a ti ṣe lò ó ninu Iwe Mimọ. Ninu Bibeli eyi wémọ́ “mímọ̀ nipasẹ iriri,” ìmọ̀ kan ti ń fi “ipo-ibatan igbẹkẹle laaarin awọn eniyan” hàn. (The New International Dictionary of New Testament Theology) Iyẹn wémọ́ mímọ Jehofa nipasẹ gbigbe awọn iṣe rẹ̀ kan pàtó yẹwo, gẹgẹ bi o ti rí ninu ọpọlọpọ ọ̀ràn ninu iwe Esekieli nibi ti Ọlọrun ti mú idajọ ṣẹ lodisi awọn oniwa-aitọ, ni pipolongo pe: ‘Ẹyin ó sì mọ̀ pe emi ni Jehofa.’—Esekieli 38:23.
2 Oniruuru ọ̀nà ti a lè gbà lo “mọ̀” ati “ìmọ̀” ni a lè mú ṣe kedere pẹlu awọn apẹẹrẹ diẹ. Fun ọpọlọpọ ti ń jẹwọ pe awọn ti huwa ni orukọ rẹ̀, Jesu sọ pe, “Emi kò mọ̀ yin rí”; ó ní i lọkan pe oun kò tíì ní ohunkohun ṣe pẹlu wọn rí. (Matteu 7:23) Korinti Keji 5:21 sọ pe Kristi “kò mọ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀.” Iyẹn kò tumọ si pe oun kò mọ̀ pe ẹṣẹ wà ṣugbọn, dipo bẹẹ, pe oun funraarẹ kò lọwọ ninu rẹ̀. Bakan naa, nigba ti Jesu sọ pe: “Ìyè ainipẹkun naa sì ni eyi, ki wọn ki o lè mọ̀ ọ́, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹni ti iwọ rán,” ohun pupọ ni ó wémọ́ ọn ju wiwulẹ mọ ohun kan nipa Ọlọrun ati Kristi lọ.—Fiwe Matteu 7:21.
3. Ki ni o fẹ̀rí hàn pe Jehofa fi àmì idanimọ fun Ọlọrun tootọ hàn?
3 Ọpọ ninu awọn ànímọ́-ìwà Jehofa ni a lè mọ̀ nipasẹ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli. Ọ̀kan ninu wọn ni agbára rẹ̀ lati sọtẹlẹ pẹlu ìpéye. Eyi ni ami kan ti o jẹ́ ti Ọlọrun otitọ: “Jẹ ki wọn mú wọn jade wá, ki wọn sì fi ohun ti yoo ṣe hanni: jẹ ki wọn fi ohun iṣaaju hàn, bi wọn ti jẹ́, ki awa ki o lè rò wọn, ki a sì mọ igbẹhin wọn; tabi ki wọn sọ ohun wọnni ti ń bọ̀ fun wa. Fi ohun ti ń bọ̀ lẹhin eyi hàn, ki awa ki o lè mọ pe ọlọrun ni ẹyin.” (Isaiah 41:22, 23) Ninu Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Jehofa sọ awọn ohun akọkọ nipa iṣẹda ori ilẹ̀-ayé ati awọn ohun alaaye ti o wà lori rẹ̀. Ó sọ awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ lẹhin naa ati eyi ti o ti kọja tipẹ ṣaaju akoko. Ati nisinsinyi paapaa ó ń “sọ ohun wọnni ti ń bọ̀ fun wa,” ni pataki awọn ohun ti yoo ṣẹlẹ ni “ikẹhin ọjọ” wọnyi.—2 Timoteu 3:1-5, 13; Genesisi 1:1-30; Isaiah 53:1-12; Danieli 8:3-12, 20-25; Matteu 24:3-21; Ìfihàn 6:1-8; 11:18.
4. Bawo ni Jehofa ti ṣe lo ànímọ́-ìwà rẹ̀ ti agbára, bawo ni yoo si ti lò ó?
4 Ànímọ́-ìwà miiran ti Jehofa ni agbára. Ó hàn gbangba ninu awọn ọ̀run nibi ti awọn irawọ ti ń ṣiṣẹ gẹgẹ bi idipọ awọn ìléru tí ń tú ìmọ́lẹ̀ ati ooru jade. Nigba ti awọn ọlọtẹ ọkunrin tabi awọn angẹli pe ipo ọba-alaṣẹ Jehofa nija, ó lo agbára rẹ̀ gẹgẹ bi “akin ọkunrin ogun,” ni gbigbeja orukọ rere ati awọn ọpa-idiwọn òdodo rẹ̀. Ni awọn akoko bẹẹ oun kò lọ́tìkọ̀ lati lo agbára ni ọ̀nà aṣèparun, gẹgẹ bi o ti rí nigba Ikun-omi ọjọ Noa, ninu iparun Sodomu ati Gomorra, ati ninu dídá Israeli nídè la Òkun Pupa já. (Eksodu 15:3-7; Genesisi 7:11, 12, 24; 19:24, 25) Laipẹ, Ọlọrun yoo lò ó lati “tẹ Satani mọlẹ ni atẹlẹsẹ yin.”—Romu 16:20.
5. Papọ pẹlu agbára rẹ̀, animọ wo ni Jehofa tun ní?
5 Sibẹ, àní pẹlu gbogbo agbára ti kò láàlà yii, ìrẹ̀lẹ̀ wà. Orin Dafidi 18:35, 36 sọ pe: “Iwapẹlẹ [“Ìrẹ̀lẹ̀,” NW] rẹ sọ mi di ńlá. Iwọ sọ irin ẹsẹ mi di ńlá nisalẹ mi.” Irẹlẹ Ọlọrun mú ki o ṣeeṣe fun un lati “rẹ araarẹ̀ silẹ lati wo ọ̀run ati ilẹ̀-ayé ni gbígbé ẹni rírẹlẹ̀ dide lati inu eruku gan-an; ó gbé òtòṣì ga lati inu kòtò-eérú fúnraarẹ̀ wá.”—Orin Dafidi 113:6, 7, NW.
6. Animọ Jehofa wo ni ó jẹ́ agbẹmila?
6 Àánú Jehofa ninu bíbá eniyan lò jẹ́ agbẹmila. Ẹ wo iru àánú ti a fihàn si Manasse nigba ti a dariji i, àní bi o tilẹ jẹ pe ó ti hu awọn iwa ìkà-òǹrorò bibanilẹru! Jehofa sọ pe: “Nigba ti emi wi fun eniyan buburu pe, Kiku ni iwọ ó ku; bi oun bá yipada kuro ninu ẹṣẹ rẹ̀, ti o sì ṣe eyi ti o tọ́ ti o sì yẹ; a kì yoo ṣe iranti gbogbo ẹṣẹ rẹ̀ ti o ti ń dá fun un: oun ti ṣe eyi ti o tọ́ ti o sì yẹ; oun ó yè nitootọ.” (Esekieli 33:14, 16; 2 Kronika 33:1-6, 10-13) Jesu ń fi animọ Jehofa hàn nigba ti ó rọni lati dariji fun ìgbà 77, àní ìgbà 7 ni ọjọ kan!—Orin Dafidi 103:8-14; Matteu 18:21, 22; Luku 17:4.
Ọlọrun kan ti O Ní Imọlara
7. Bawo ni Jehofa ṣe yatọ si awọn ọlọrun Griki, anfaani ṣiṣeyebiye wo ni ó sì ṣí silẹ fun wa?
7 Awọn ọlọgbọn-imọ-ọran Griki, iru bii awọn Epikurei, gbagbọ ninu ọpọ ọlọrun ṣugbọn wọn wò wọn gẹgẹ bi ẹni ti o jinna si ilẹ̀-ayé lati ni ọkàn-ìfẹ́ eyikeyii ninu eniyan tabi ki awọn imọlara eniyan nípa lori wọn. Ipo-ibatan laaarin Jehofa ati awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ oluṣotitọ ti yatọ tó! “Oluwa ṣe inudidun si awọn eniyan rẹ̀.” (Orin Dafidi 149:4) Awọn eniyan buburu ṣaaju Ikun-omi mú ki o nimọlara àbámọ̀ wọn sì “bà á ninu jẹ́.” Israeli nipasẹ aiṣotitọ rẹ̀ mú irora ati ìbàlọ́kànjẹ́ wá fun Jehofa. Awọn Kristian nipasẹ aigbọran wọn lè mú ẹmi Jehofa binu; nipasẹ iṣotitọ wọn, bi o ti wu ki o ri, wọn lè mú ayọ wá fun un. Ó ti yanilẹnu tó lati ronu pe eniyan kikere bin-in-tin lori ilẹ̀-ayé lè mú ki Ẹlẹdaa agbaye nimọlara ìbàlọ́kànjẹ́ tabi ayọ̀! Ni oju-iwoye gbogbo ohun ti ó ń ṣe fun wa, ó ti jẹ́ agbayanu tó pe a ni anfaani ṣiṣeyebiye ti fifun un ni itẹlọrun!—Genesisi 6:6; Orin Dafidi 78:40, 41; Owe 27:11; Isaiah 63:10; Efesu 4:30.
8. Bawo ni Abrahamu ṣe lo ominira ọrọ-sisọ rẹ̀ pẹlu Jehofa?
8 Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fihàn pe ifẹ Jehofa fun wa ni “ominira ọrọ-sisọ” ńlá. (1 Johannu 4:17, NW) Ṣakiyesi ọ̀ràn ti Abrahamu nigba ti Jehofa wá pa Sodomu run. Abrahamu sọ fun Jehofa pe: “Iwọ o ha run olódodo pẹlu eniyan buburu? Boya aadọta olódodo yoo wà ninu ìlú naa: iwọ ó ha run ún, iwọ kì yoo ha dá ibẹ̀ naa si nitori aadọta olódodo ti ó wà ninu rẹ̀? . . . [Ki a má rí i]: Onidaajọ gbogbo ayé kì yoo ha ṣe eyi ti o tọ́?” Awọn ọ̀rọ̀ wọnyi tán sí Ọlọrun! Sibẹ Jehofa gbà lati dá Sodomu sí bi a bá rí 50 olódodo eniyan nibẹ. Abrahamu ń baa lọ ó sì mú ki iye naa dín lati ori 50 si 20. Ẹ̀rù bẹrẹ sii bà á pe oun ti lè maa pin ín lẹmii. Ó sọ pe: “Jọ̀ọ́, ki inu ki o maṣe bí OLUWA, ẹẹkanṣoṣo yii ni emi ó sì wí mọ. Boya a o rí mẹwaa nibẹ.” Lẹẹkan sii Jehofa gbà pe: “Emi kì yoo run un nitori mẹwaa.”—Genesisi 18:23-33.
9. Eeṣe ti Jehofa fi faaye gba Abrahamu lati sọrọ gẹgẹ bi ó ti ṣe, ki ni a sì lè kẹkọọ rẹ̀ lati inu eyi?
9 Eeṣe ti Jehofa fi yọnda iru ominira ọrọ-sisọ bẹẹ fun Abrahamu ki o baa lè sọrọ ni ọ̀nà yii? Fun ohun kan, Jehofa mọ̀ nipa imọlara ibanujẹ Abrahamu. Ó mọ̀ pe ibatan Abrahamu Loti ń gbé ni Sodomu, ti àníyàn nipa aabo rẹ̀ sì jẹ Abrahamu lọkan. Pẹlupẹlu, ọ̀rẹ́ Ọlọrun ni Abrahamu jẹ́. (Jakọbu 2:23) Nigba ti ẹnikan bá bá wa sọrọ lọna ti kò dara, awa ha ń gbiyanju lati foye mọ imọlara ti o wà lẹhin awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ki a sì gba ti awọn ipo amọ́rànfúyẹ́ wọnyẹn rò, ni pataki bi oun bá jẹ́ ọ̀rẹ́ kan ti o wà labẹ iru ikimọlẹ ero-imọlara kan? Kò ha tunininu lati rí i pe Jehofa yoo lóye lílò ti a ń lo ominira ọrọ-sisọ, gẹgẹ bi oun ti ṣe pẹlu Abrahamu?
10. Bawo ni ominira ọrọ-sisọ ṣe ràn wá lọwọ ninu adura?
10 Ni pataki nigba ti a bá ń wá a gẹgẹ bi “Olùgbọ́ adura” ni a maa ń fẹ́ ominira ọrọ-sisọ yii lati tú ọkàn wa jade fun un, nigba ti ọkàn wa bá bajẹ gidigidi ti a sì wà ninu ìdàlọ́kànrú niti ero-imọlara. (Orin Dafidi 51:17; 65:2, 3) Àní ni awọn ìgbà wọnni nigba ti a lè má mọ ohun ti a o sọ, “ẹmi tikaraarẹ ń fi irora ti a kò lè fi ẹnu sọ bẹbẹ fun wa,” Jehofa sì ń fetisilẹ. Oun lè mọ awọn èrò wa: “Iwọ ti mọ ìrò mi ni ọ̀nà jijin réré. Nitori ti kò si ọ̀rọ̀ kan ni ahọ́n mi, kiyesi i, Oluwa, iwọ mọ̀ ọ́n patapata.” Àní bi o tilẹ rí bẹẹ, a nilati maa baa lọ ni bibeere, wíwákiri, kíkànkùn.—Romu 8:26; Orin Dafidi 139:2, 4; Matteu 7:7, 8.
11. Bawo ni a ṣe fihàn pe Jehofa bikita nipa wa niti gidi?
11 Jehofa bikita. Ó ń pese fun ẹ̀dá ti ó dá. “Oju gbogbo eniyan ń wò ọ́; iwọ sì fun wọn ni ounjẹ wọn ni akoko rẹ̀. Iwọ ṣí ọwọ rẹ, iwọ sì tẹ́ ifẹ gbogbo ohun alaaye lọrun.” (Orin Dafidi 145:15, 16) A késí wa lati wo bi ó ṣe ń bọ́ awọn ẹyẹ ninu ìgbẹ́. Ẹ wo awọn lílì ti o wà ni pápá, bi o ti fi ẹwà wọ̀ wọn tó. Jesu fikun un pe Ọlọrun yoo ṣe ohun ti ó tubọ pọ̀ fun wa ju ohun ti o ń ṣe fun wọn lọ. Nitori naa eeṣe ti awa yoo fi maa ṣaniyan? (Deuteronomi 32:10; Matteu 6:26-32; 10:29-31) Peteru Kìn-ín-ní 5:7 késí ọ lati “kó gbogbo aniyan [rẹ] lé e; nitori ti oun ń ṣe itọju [rẹ].”
“Aworan Oun Tìkaraarẹ̀”
12, 13. Ni afikun si rírí Jehofa nipasẹ iṣẹda ati awọn iṣe rẹ̀ ti a kọsilẹ ninu Bibeli, ọ̀nà miiran wo ni a lè gbà rí i ki a sì gbọ́ ọ?
12 A lè rí Jehofa Ọlọrun nipasẹ iṣẹda rẹ̀; a lè rí i nipa kika awọn iṣe rẹ̀ ninu Bibeli; a tun lè rí i nipa awọn ọ̀rọ̀ ati iṣe ti a kọsilẹ nipa Jesu Kristi. Jesu fúnraarẹ̀ sọ bẹẹ, ni Johannu 12:45 pe: “Ẹni ti o bá si rí mi, o ri ẹni ti ó rán mi.” Lẹẹkan sii, ni Johannu 14:9 pe: “Ẹni ti ó bá ti rí mi, ó ti rí Baba.” Kolosse 1:15 sọ pe: “[Jesu ni] aworan Ọlọrun ti a kò rí.” Heberu 1:3 polongo pe: “[Jesu ni] itanṣan ògo [Ọlọrun], ati aworan oun tikaraarẹ.”
13 Jehofa rán Ọmọkunrin rẹ̀ kìí ṣe kìkì lati pese irapada nikan ni ṣugbọn lati fi apẹẹrẹ ti a nilati ṣafarawe pẹlu lelẹ, ninu ọ̀rọ̀ ati ni ìṣe. Jesu sọ awọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ó sọ ni Johannu 12:50 pe: “Ohun wọnni ti mo bá wí, gẹgẹ bi Baba ti sọ fun mi, bẹẹ ni mo wí.” Kò ṣe ohun ti araarẹ̀, ṣugbọn ó ṣe awọn ohun ti Ọlọrun sọ fun un pe ki o ṣe. Ni Johannu 5:30 ó sọ pe: “Emi kò lè ṣe ohun kan fun ara mi.”—Johannu 6:38.
14. (a) Awọn iran wo ni ó mú ki aanu ṣe Jesu? (b) Eeṣe ti ọ̀nà igbasọrọ Jesu fi mú ki awọn eniyan dà yìì lati gbọ́ ọ?
14 Jesu rí awọn eniyan ti wọn jẹ́ adẹ́tẹ̀, abirùn, aditi, afọju, ati awọn ti ẹmi eṣu ń yọlẹnu ati awọn wọnni ti wọn ń ṣọfọ awọn eniyan wọn ti o ti kú. Bi aanu ti ṣe é, ó wo alaisan sàn ó sì jí òkú dide. Ó ri awọn ogunlọgọ naa ti a ti jẹ kan egungun ti wọn sì ń tàràkà nipa tẹmi, ó sì bẹrẹ sii kọ́ wọn ni ohun pupọ. Kìí ṣe pe ó kọni pẹlu awọn ọ̀rọ̀ titọna nikan ni ṣugbọn pẹlu awọn ọ̀rọ̀ alárinrin lati inu ọkan-aya rẹ̀ ti o lọ taarata si ọkan-aya awọn ẹlomiran, ti o fà wọn súnmọ́n-ọn, ti ó mú wọn wá ni kutukutu sinu tẹmpili lati gbọ́ ọ, ti o mú ki wọn tẹpẹlẹ mọ fifetisilẹ si i, lati fetisilẹ sí i pẹlu igbadun. Wọn dà yìì wá lati gbọ́ ọ, ni pipolongo pe ‘kò si ọkunrin miiran ti o tii sọrọ bi eyi rí.’ Ẹnu yà wọn gidigidi si ọ̀nà ìgbàkọ́ni rẹ̀. (Johannu 7:46; Matteu 7:28, 29; Marku 11:18; 12:37; Luku 4:22; 19:48; 21:38) Nigba ti awọn ọ̀tá rẹ̀ sì wá ọ̀nà lati kẹ́dẹ mú un pẹlu awọn ibeere, ó yi ọ̀ràn pada fun wọn bírí, nipa mímú ki kẹ́kẹ́ pa mọ́ wọn lẹnu.—Matteu 22:41-46; Marku 12:34; Luku 20:40.
15. Ki ni pataki ẹṣin-ọrọ iwaasu Jesu, dé ipo aaye wo ni ó sì gbà mú ki awọn ẹlomiran lọwọ ninu títàn án kalẹ?
15 Ó polongo pe “ijọba ọ̀run kù si dẹdẹ,” o si rọ awọn olufetisilẹ lati “tètè maa wá ijọba” naa. Ó rán awọn miiran lọ lati waasu pé “ijọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀,” lati “sọ awọn eniyan orilẹ-ede gbogbo di ọmọ-ẹhin,” lati jẹ́ ẹlẹ́rìí Kristi “titi dé opin ilẹ̀-ayé.” Lonii iye ti o fẹrẹẹ tó million mẹrin ati aabọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni wọn ń rìn ni ipasẹ rẹ̀, ni ṣiṣe awọn nǹkan wọnni.—Matteu 4:17; 6:33; 10:7; 28:19, NW; Iṣe 1:8.
16. Bawo ni a ṣe fi ànímọ́-ìwà Jehofa ti ifẹ sabẹ idanwo mimuna, ṣugbọn ki ni ó ṣaṣepari rẹ̀ fun araye?
16 “Ọlọrun jẹ́ ifẹ,” ni a sọ fun wa ni 1 Johannu 4:8 (NW). Ànímọ́-ìwà titayọ rẹ̀ yii ni a fi sinu idanwo ríronilára-gógó julọ ti a lè ronuwoye nigba ti ó rán Ọmọkunrin bíbí-kanṣoṣo rẹ̀ si ilẹ̀-ayé lati kú. Ijẹrora ti Ọmọkunrin aayo-olufẹ yii jiya rẹ̀ ati ẹ̀bẹ̀ ti o rawọ́ rẹ̀ si Baba rẹ̀ ọ̀run gbọdọ ti ṣokunfa ọpọ irora ati ìbanilọ́kànjẹ́ fun Jehofa, àní bi o tilẹ jẹ pe Jesu fi ipenija Satani pé Jehofa kò lè ní awọn eniyan lori ilẹ̀-ayé ti wọn yoo di iwatitọ wọn mú si I labẹ idanwo mimuna hàn gẹgẹ bi èké. A tun nilati mọriri itobilọla ẹbọ Jesu, nitori ti Ọlọrun rán an sihin-in lati kú fun wa. (Johannu 3:16) Eyi kìí ṣe iku kan ti o rọrùn, ti o sì yára. Lati mọriri iye ti ó ná Ọlọrun ati Jesu ki a sì tipa bẹẹ mọ itobilọla ẹbọ wọn fun wa, ẹ jẹ ki a ṣayẹwo akọsilẹ Bibeli nipa igbesẹ naa.
17-19. Bawo ni Jesu ṣe ṣapejuwe idanwo líle ti ó wà niwaju rẹ̀?
17 Ó keretan nigba mẹrin, Jesu ṣapejuwe fun awọn aposteli rẹ̀ nipa ohun ti o wà niwaju. Ni ẹnu iwọnba ọjọ diẹ ṣaaju ki ó tó ṣẹlẹ, ó sọ pe: “Awa ń goke lọ si Jerusalemu, a o sì fi Ọmọ-eniyan lé awọn olori alufaa, ati awọn akọwe lọwọ; wọn ó sì dá a lẹbi iku, wọn ó sì fi í lé awọn Keferi lọwọ: Wọn ó sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọn ó sì nà án, wọn ó sì tutọ sí i lára, wọn ó sì pa á.”—Marku 10:33, 34.
18 Jesu nimọlara ikimọlẹ ohun ti o wà niwaju rẹ̀, ni mímọ jìnnìjìnnì ẹ̀rù nínà awọn ará Romu. Pàṣán kòbókò aláwọ ti a ń lò fun nínani ní awọn irin ati eegun agutan diẹ ti a hunpọ̀ mọ wọn; nitori naa bi ìnàlọ́rẹ́ naa ti ń baa lọ, ẹhin ati awọn ẹsẹ rẹ̀ di ẹran-ara ẹlẹ́jẹ̀ jálajàla. Ni ọpọ oṣu ṣaaju, Jesu fi ìgalára ti ero-imọlara tí idanwo líle ti o wà niwaju ń fà fun un hàn, ni sísọ gẹgẹ bi a ti kà ni Luku 12:50 pe: “Ṣugbọn emi ni baptism kan ti a o fi baptisi mi; ara ti ń ni mi tó titi yoo fi pari!”
19 Ikimọlẹ naa ń ga sii bi akoko ti ń tubọ sunmọle. Ó sọ nipa rẹ̀ fun Baba rẹ̀ ọ̀run pe: “Nisinsinyi ni a ń pọ́n ọkàn mi loju; ki ni emi ó sì wí? Baba, gbà mi kuro ninu wakati yii: ṣugbọn nitori eyi ni mo ṣe wá si wakati yii.” (Johannu 12:27) Ẹ wo bi ẹ̀bẹ̀ lati ọ̀dọ̀ Ọmọkunrin bíbí-kanṣoṣo rẹ̀ yii ti gbọdọ nipa lori Jehofa tó! Ní Getsemane, ní kìkì iwọnba wakati diẹ ṣaaju iku rẹ̀, Jesu di ẹni ti a dàláàmú gidigidi ó sì sọ fun Peteru, Jakọbu, ati Johannu pe: “Ọkàn mi bajẹ gidigidi titi dé ikú.” Ni ọpọ iṣẹju lẹhin ìgbà naa ó gba adura rẹ̀ ikẹhin lori koko-ọrọ yii jade si Jehofa pe: “Baba, bi iwọ bá fẹ́, gba ago yii lọwọ mi: ṣugbọn ifẹ ti emi kọ́, bikoṣe tirẹ ni ki a ṣe. Bi o sì ti wà ni ìwàyá-ìjà ó ń gbadura sii kikankikan: òógùn rẹ̀ sì dabi ìró ẹ̀jẹ̀ ńlá, ó ń kán silẹ.” (Matteu 26:38; Luku 22:42, 44) Eyi lè ti jẹ́ ohun ti a mọ̀ lọna iṣegun gẹgẹ bi hematidrosis (ìsunjáde ẹ̀jẹ̀ tabi ohun aláwọ̀ pupa bi ẹ̀jẹ̀ lati inu awọ ara). Ó ṣọ̀wọ́n ṣugbọn ó lè ṣẹlẹ ninu awọn ipo elero-imọlara giga.
20. Ki ni ó ran Jesu lọwọ lati la idanwo lìle rẹ̀ já?
20 Nipa akoko yii ni Getsemane, Heberu 5:7 sọ pe: “Ẹni [Kristi] nigba ọjọ rẹ̀ ninu ara, ti o fi ẹkún rara ati omije gbadura, ti o sì bẹ̀bẹ̀ lọdọ ẹni ti o lè gbà á silẹ lọwọ ikú, a sì gbohun rẹ̀ nitori ẹmi ọ̀wọ̀ rẹ̀.” Niwọn bi a kò ti gbà á silẹ kuro lọwọ iku nipasẹ “ẹni ti o lè gbà á silẹ lọwọ iku,” ni ero itumọ wo ni a gbà fi ojurere gbọ́ adura rẹ̀? Luku 22:43 dahun pe: “Angẹli kan sì yọ sí i lati ọ̀run wá, ó ń gbà á ni iyanju.” Adura naa ni a dahun niti pe angẹli ti Ọlọrun rán fun Jesu ní okun lati farada labẹ idanwo líle naa.
21. (a) Ki ni ó fihàn pe Jesu la idanwo líle rẹ̀ kọja pẹlu ayọ̀ iṣẹgun? (b) Nigba ti awọn idanwo wa bá ń ga sii, bawo ni awa yoo ṣe fẹ́ lati sọrọ?
21 Eyi ṣe kedere lati inu abajade naa. Nigba ti ijakadi inu lọhun-un pari tan, Jesu gbéra-ńlẹ̀ o pada, lọ bá Peteru, Jakọbu, ati Johannu, ó sì sọ pe: “Ẹ dide, ki a maa lọ.” (Marku 14:42) Niti gasikiya oun ti o ń sọ ni pe, ‘Ẹ jẹ ki n lọ di ẹni ti a fihàn pẹlu ifẹnukonilẹnu, lati di ẹni ti a faṣẹ ọba mú lati ọwọ́ awujọ awọn eniyankeniyan, lati jẹ́jọ́ laibofinmu, lati di ẹni ti a dalẹbi lọna ti kò tọ́. Ẹ jẹ ki n lọ lati di ẹni ti a fi ṣe ẹlẹ́yà, tu itọ́ sí lara, nà lórẹ́, ti a sì kàn mọ́ òpó-igi ìdálóró.’ Fun wakati mẹfa a so ó rọ̀ sibẹ, ninu irora gógó, ní fifarada a titi de opin. Bi ó ti ń kú, ó ké jade ni ayọ-iṣẹgun pe: “Ó pari.” (Johannu 19:30) Ó ti wà ni iduroṣinṣin ó sì ti fi ẹ̀rí iwatitọ rẹ̀ hàn ninu didi ipo ọba-alaṣẹ Jehofa mú. Gbogbo ohun ti Jehofa ti rán an wá sori ilẹ̀-ayé lati ṣe ni o ti pari. Nigba ti a bá kú tabi nigba ti Armageddoni bá bẹ́ silẹ, awa yoo ha lè sọ nipa iṣẹ-aṣẹ wa lati ọ̀dọ̀ Jehofa pe: “Ó pari” bi?
22. Ki ni ó fi ìwọ̀n itankalẹ ìmọ̀ nipa Jehofa hàn?
22 Ni ọ̀nà eyikeyii, a lè ni idaniloju pe ni akoko Jehofa ti o fẹrẹẹ tó ti ń yára kankan sunmọle, gbogbo “ayé yoo kún fun ìmọ̀ Oluwa gẹgẹ bi omi ti bo òkun.”—Isaiah 11:9.
Iwọ Ha Ranti Bi?
◻ Ki ni o tumọsi lati mọ̀ ati lati ní ìmọ̀?
◻ Bawo ni a ṣe fi aanu ati idariji Jehofa hàn fun wa ninu Ọ̀rọ̀ rẹ̀?
◻ Bawo ni Abrahamu ṣe lo ominira ọrọ-sisọ pẹlu Jehofa?
◻ Eeṣe ti a fi lè wo Jesu ki a sì rí awọn animọ Jehofa lara rẹ̀?