“Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun”
1-4. (a) Ninu apá-ẹ̀ka aworan òde wa wo ni iwọ yoo gbadun ṣiṣe ajọpin? (b) Ifojusọna-ireti ológo wo ni a nawọ́ rẹ̀ si ọ níhìn-ín? (c) Awọn ẹsẹ-iwe Bibeli wo ni ó pese itilẹhin fun irúfẹ́ ireti kan bẹẹ?
WÒ AWỌN eniyan alayọ tí ó wà ní òde iwe-pẹlẹbẹ yii. Iwọ yoo ha fẹ́ lati jẹ́ ọ̀kan lara wọn bi? ‘Họọwu, bẹẹni,’ ni iwọ wí. Nitori níhìn-ín ni a rí alaafia ati ibaramuṣọkan tí gbogbo araye ní ifẹ-ọkan sí. Awọn eniyan lati inu ẹya-iran gbogbo—dúdú, funfun, ìyeyè—ni wọn dàpọ̀ gẹgẹ bi idile kan. Idunnu-nla yii mà kọyọyọ o! Iṣọkan naa mà kọyọyọ o! Lọna tí ó hàn gbangba awọn eniyan wọnyi kò ṣe wahala nipa àjálù bomb atomik tabi ìhalẹ̀ idayafoni. Ọkọ̀ ogun ofuurufu ayára-bí-àṣá kò ṣe ìfọ́túútúú alaafia oju-ọrun tí ó wà loke ọgbà-ìtura ẹlẹwa wiwuni daradara yii. Kò si awọn jagunjagun, kò si awọn kẹ̀kẹ́-ogun nla, kò si awọn ìbọn. Àní kóńdó awọn ọlọpaa gan-an ni a kò tilẹ nílò lati pa aṣẹ-itọni mọ́. Ogun ati iwa-ọdaran kò tilẹ sí. Kò sì sí àìtó ile-gbígbé, nitori olukuluku ni ó ní ibugbe ẹlẹwa kan lati pè ní tirẹ̀.
2 Tilẹ wò awọn ọmọde wọnyẹn ná! Eré tí wọn nṣe jẹ́ onidunnu-nla kan lati wò. Awọn ẹranko niyii lati bá ṣere! A kò nilo àkámọ́ awọn ọ̀pá irin ninu ọgbà-ìtura yii, nitori gbogbo awọn ẹranko ni wọn wà ní alaafia pẹlu araye ati pẹlu araawọn ẹnikinni ẹnikeji. Àní kinniun paapaa ati ọ̀dọ́-agutan ti di ọ̀rẹ́. Wò awọn ẹyẹ aláwọ̀ dídányanran wọnni bi wọn ti ńfò síhìn-ín sọ́hùn-ún, ki o sì gbọ́ awọn orin dídùn yùngbà wọn tí ó dàpọ̀ mọ́ ẹ̀rín awọn ọmọde tí ó gbalẹ̀kan. Kò si awọn àhámọ́ kẹ̀? Rara, nitori pe nibi gbogbo ni ominira ati idunnu-nla alaini ikalọwọko wà ninu pápá-àkóso yii. Tilẹ gbóòórùn ìtasánsán awọn òdòdó wọnyi, gbọ́ ìró ìṣàn odò wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́, nimọlara ooru tí ńwọ̀ akinyẹmi ara lati inu oòrùn. Óò, bi ẹnipe ki èèyàn tọ́ eso inu apẹ̀rẹ̀ yẹn wò, nitori ó jẹ́ eyi tí ó darajulọ tí ilẹ yẹn lè mú jade, eyi tí ó darajulọ gan-an, bi ohun gbogbo tí eniyan lè rí ki ó sì gbadun ninu ọgbà-ọ̀gbìn tí ó dabi ọgbà-ìtura ológo yii.
3 ‘Ṣugbọn duro ná,’ ni ẹnikan wí, ‘nibo ni awọn arugbo eniyan wà? Kò ha yẹ ki, awọn pẹlu, ṣajọpin ninu ẹgbẹ-oun-ọgba alayọ yii bi?’ Niti gàsíkíá, awọn arugbo eniyan wà nibẹ gan-an, ṣugbọn wọn ndagba pada sẹhin di ọmọde ni. Ninu pápá-ìtura yii kò si ẹnikan tí ó ńkú lati inu ọjọ́-ogbó. Awọn ọ̀dọ́ nisinsinyi ndagba dé ipo idagba-di-gende ọkunrin tí wọn kò sì dagba darugbo. Yala ẹni 20 ọdun tabi 200 ọdun lọ́jọ́-orí, olukuluku awọn million eniyan tí wọn ńgbé ninu pápá-itura yii ńyọ̀ ayọ-nla ninu ìjẹ̀gbádùn ara yíyágágá igba igbesi-aye ọ̀dọ́, ninu ilera pípé. Awọn million mà ni o pè é? Bẹẹni, awọn million, nitori pe pápá-itura yii ni a ńmú gbilẹ sii dé gbogbo ilẹ. Yoo kún fun iwalaaye, alaafia, ati ẹwà, titi dé awọn opin ilẹ-aye wa, lati Fuji titi dé Andes, lati Hong Kong titi dé Mediterranean. Nitori gbogbo ilẹ-aye ni a nyipada-patapata si pápá-itura paradise kan. Yoo jẹ́ Paradise tí a mú padabọsipo jakejado ilẹ-aye.
4 ‘Kò-ṣeé-gbàgbọ́,’ ni iwọ wí kẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, bi ó ti wù ki ó rí, gbé awọn otitọ-iṣẹlẹ naa yẹ̀wò gẹgẹ bi àmì-ẹ̀rí. Ó ṣeeṣe fun iwọ ati idile rẹ lati là eto-igbekalẹ awọn nǹkan oníjọ̀ngbọ̀n ti nkọja lọ yii já ki o sì bọ́ sinu paradise tí a ṣàwòrán-ẹ̀dàya rẹ̀ si òde iwe wa yii.a
Iwe naa Tí Ó Ṣalaye Paradise
5. (a) Iwe wo ni ó ṣalaye awọn nǹkan wọnyi? (b) Ní awọn ọna wo ni ó fi jẹ́ iwe tí ó wà ní ipo titayọ julọ?
5 Gbogbo awọn nǹkan ológo wọnyi, ati idaniloju wọn, ni a ṣalaye ninu iwe kan, iwe tí ó kún fun kayefi julọ tí a tíì kọ rí. Bibeli ni a ńpè é. Ó jẹ́ iwe igbaani gan-an, tí a kọ apakan rẹ̀ ní nǹkan bii 3,500 ọdun sẹhin. Sibẹ, ó jẹ́ iwe kan tí ó bá igba mu julọ lati funni ní imọran tí ó yekooro, tí ó sì ṣeémúlò fun igbesi-aye ode-oni. Awọn asọtẹlẹ rẹ̀ nru ireti mímọ́lẹ̀yòò soke fun ọjọ-ọla. Oun ni iwe tí ó tà julọ ninu ọrọ-itan, ẹ̀dà tí ó jù 2,000,000,000 odindi Bibeli tabi apá tí ó pọ̀ julọ rẹ̀ ni a ti pínkiri ní nǹkan bii 1,810 ede.
6. Kinni ó mú Bibeli dá yatọ si awọn iwe miiran tí a kàsí mímọ́?
6 Kò tún si iwe mímọ́ miiran tí a tíì pinkiri yika tobẹẹ, tí awọn tí ó pọ̀ julọ miiran kò sì sunmọ ọn niti ọjọ-ori. Koran ti isin Islam kere sí 1,400 ọdun ní ọjọ-ori. Awọn onisin Buddha ati Confucius gbé ayé ní nǹkan bii 2,500 ọdun sẹhin, tí iwe-kikọ wọn sì bẹrẹ lati akoko yẹn. Ìwémímọ́-ìsìn Shinto ni a ṣètòkójọ ní bi wọn ṣe wà nisinsinyi ní nǹkan tí kò jù 1,200 ọdun sẹhin. Iwe awọn onisin Mormon jẹ́ kiki 160 ọdun ní ọjọ-ori. Kò si ọ̀kankan ninu awọn iwe mímọ́ wọnyi tí ó lè tọpasẹ ọrọ-itan ẹda-eniyan pada sẹhin jálẹ̀ 6,000 ọdun lọna pípéye, gẹgẹ bi Bibeli ti ṣe. Nigba naa, lati loye isin ipilẹṣẹ, a gbọdọ lọ sinu Bibeli. Oun ni iwe kanṣoṣo naa tí ó ní ìhìn-iṣẹ́ agbaye fun gbogbo araye.
7. Kinni awọn onironu eniyan ti sọ nipa Bibeli?
7 Ọgbọn ati ẹwà ìhìn-iṣẹ́ Bibeli ni awọn eniyan onironu lati orilẹ-ede gbogbo ati oniruuru ipo igbesi-aye ti fi ìyìn-ìtẹ́wọ́gbà fun. Ìjìmì onimọ-ijinlẹ ati oluṣawari ofin òòfà-ilẹ̀, Sir Isaac Newton, sọ pe: “Kò si imọ-ijinlẹ kankan tí a lè fi ẹ̀rí-ìjóòótọ́ tí ó daraju fun jù Bibeli lọ.” Patrick Henry, ara America aṣaaju ẹgbẹ awọn oniyiipada igbalode tí a mọ̀ ní àmọ̀dunjú fun awọn ọrọ tí ó gbadun lati maa lò naa “Fun mi ní ominira-idasilẹ, tabi ki o kúkú pa mi,” pẹlu kede pe: “Bibeli níláárí jù gbogbo awọn iwe miiran tí a tíì tẹ̀ lọ.” Àní ọlọgbọn Hindu nla naa Mohandas K. Gandhi paapaa sọ nigba kan fun adelé ọba ilẹ Gẹẹsi ní ilẹ India pe: “Nigba tí ilẹ-orilẹ-ede rẹ ati temi yoo bá jumọ fohunṣọkan pọ̀ lori awọn ẹkọ tí Kristi fi lélẹ̀ ninu Iwaasu yii lori Oke, nigba naa ni awa yoo tó lè wá-ojútùú si awọn ọran-iṣoro gbogbo, kii ṣe ti awọn ilẹ-orilẹ-ede tiwa nikan ṣugbọn ti gbogbo ayé lapapọ.” Gandhi nsọrọ nipa Matthew ori-iwe 5 si 7 ninu Bibeli. Iwọ naa kà awọn ori-iwe wọnyi funraarẹ ki o sì ríi bi iwọ kò bá ní ní irusoke imọlara si ìhìn-iṣẹ́ alagbara wọn.
Bibeli—Iwe kan fun Awọn Ara Gábàsì
8, 9. (a) Eeṣe tí ó fi lodi lati pè Bibeli ní iwe Iwọ-oorun kan? (b) Bawo ni a ṣe kọ Bibeli, sáà akoko wo ni a sì fi kọ ọ́ tán? (c) Eeṣe tí a fi lè pè Bibeli ní àkójọpọ̀ iwe kan? (d) Awọn ọkunrin meloo ni a lò lati fi kọ Bibeli? (e) Kinni gbolohun-ẹri tí diẹ lara awọn ọkunrin wọnyi pese nipa Orisun Bibeli?
8 Lodisi igbagbọ tí ó gbajumọ, Bibeli kii ṣe imujade ọ̀làjú ti Iwọ-oorun, bẹẹ ni kò ṣe ìlàjú yẹn ní ògo. Ó fẹrẹẹ jẹ́ gbogbo Bibeli patapata ni a kọ ní awọn ilẹ-orilẹ-ede Gábàsì, awọn ọkunrin tí wọn ṣe akọsilẹ rẹ̀ ni gbogbo wọn jẹ́ ara Gábàsì. Ẹgbẹrun ọdun ṣaaju isin Buddha, ní 1513 B.C.E., Moses, ẹni tí ó gbé ní Aarin Ila-oorun Ayé, ni Ọlọrun misi lati kọ iwe akọkọ ninu Bibeli, tí a ńpè ní Genesis. Lati ibẹrẹ atetekọṣe yii, ni Bibeli ti ntẹle ẹṣin-ọrọ kanṣoṣo tí ó wà ní ibaramuṣọkandélẹ̀ titi dé ipari iwe Iṣipaya. Bibeli ni a pari kikọ rẹ̀ patapata ní 98 C.E., nǹkan bii 600 ọdun lẹhin Buddha. Ǹjẹ́ o mọ̀ pe 66 awọn iwe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó wà ninu Bibeli? Bẹẹni, Bibeli jẹ́ akojọpọ-iwe kan ninu araarẹ̀!
9 Nipa bayii, fun sáà kan tí ó gùn tó 1,600 ọdun lati igba Moses wá, nǹkan bii ogoji awọn ọkunrin ti ṣajọpin ninu kikọ akọsilẹ Bibeli onibaramuṣọkan naa. Wọn kedejẹrii pe iwe-kikọ wọn ni a misi nipasẹ agbara kan tí ó rekọja ti ẹni kíkú kan fiofio. Kristian apostle Paul kọwe pe: “Gbogbo Ìwé-mímọ́ tí ó ní imisi Ọlọrun ni ó sì ní èrè fun ẹkọ, fun ibaniwi, fun itọni, fun ikọni tí ó wà ninu ododo.”b (2 Timothy 3:16) Lẹhin naa ni apostle Peter ṣalaye pe: “Kò si ọ̀kan ninu asọtẹlẹ inu Ìwé-mímọ́ tí ó ní itumọ ìkọ̀kọ̀. Nitori asọtẹlẹ kan kò ti ipa ifẹ eniyan wá rí; ṣugbọn awọn eniyan nsọrọ lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun bi a ti ndari wọn lati ọwọ́ ẹmi mimọ.”—2 Peter 1:20, 21; 2 Samuel 23:2; Luke 1:70.
10. (a) Bawo ni Bibeli ṣe wà titi di ọjọ tiwa? (b) Eeṣe tí a fi lè ní idaniloju pe awa ṣì ní ọrọ ẹsẹ Bibeli ipilẹṣẹ tí a misi?
10 Eyi tí ó pẹtẹrí julọ, pẹlu, ni ọna tí Bibeli ti gbà wà titi di ọjọ-oni. Fun ẹgbẹẹgbẹrun ọdun, titi di igba tí a hùmọ̀ ọna itẹwe ní nǹkan bii 500 ọdun sẹhin, awọn ẹ̀dà Bibeli ni a nfi ọwọ́ ṣe. Kò si iṣẹ iwe ṣiṣe ti akoko igbaani miiran tí a fi pẹlu aápọn ṣe adakọ ati adakọ-adakọ rẹ̀. Leralera ni a ṣe adakọ rẹ̀, ṣugbọn pẹlu iṣọra titobi nigba gbogbo. Iwọnba awọn aṣiṣe keekeeke ni awọn adàwékọ naa ṣe, ati pe ifiwera awọn wọnyi ti fidi Ìwémímọ́-ìsìn ipilẹṣẹ tí a misi lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun mulẹ. Alaṣẹ òléwájú kan lori awọn iwe afọwọkọ Bibeli, Sir Frederic Kenyon, sọ pe: “Ipilẹ tí ó gbẹhin fun iyemeji eyikeyi naa pe Ìwémímọ́-ìsìn ti dé ọ̀dọ̀ wa gan-an gẹgẹ bi a ti kọ wọn ní ojulowo ni a ti mú kuro nisinsinyi.” Lonii, awọn ẹ̀dà Bibeli tabi apakan rẹ̀ alafọwọkọ bii 16,000 ni ó ṣì wà sibẹ, tí awọn kan tilẹ ti laaja lati ọ̀rúndún keji ṣaaju Kristi. Jù bẹẹ lọ, awọn itumọ pipeye ni a ti ṣe lati inu ede Hebrew, Aramaic, ati Greek ní eyi tí a fi kọ Bibeli ní ipilẹṣẹ si ohun tí ó fẹrẹẹ jẹ́ gbogbo ede tí ó wà lori ilẹ-aye.
11. Awọn awari ode-oni wo ni ó wà ní ibaramu pẹlu akọsilẹ Bibeli?
11 Awọn kan ti gbiyanju lati ṣaika Bibeli kún nipasẹ sisọ pe kò pépérépéré. Bi ó ti wù ki ó rí, ní awọn ọdun lọọlọọ yii awọn awalẹpitan ti walẹ̀ jinlẹ ninu awọn ilu-nla igbaani tí a parun-bajẹ ní awọn ilẹ Bibeli tí wọn sì ti rí awọn akọle ati awọn ẹri-ami tí njẹriifihan pẹlu ipari-ero naa pe awọn eniyan ati awọn ibi gbogbo tí a mẹnukan àní ninu akọsilẹ Bibeli tí ó jẹ́ ogbologboo julọ paapaa ni wọn ti wà rí niti gidi. Wọn ti ṣawari ọpọlọpọ ẹri-ami tí ntọkasi àkúnya-omi kárí-ayé, eyi tí Bibeli sọ pe ó sẹlẹ ní eyi tí ó jù 4,000 ọdun sẹhin, ní ọjọ Noah. Lori koko yii, Ọmọ-alade Mikasa awalẹpitan kan tí a mọ̀ dunjú, sọ pe: “Ǹjẹ́ Ikun-omi kan ha sẹlẹ niti gidi bi? . . . Koko-ọran naa pe ikun-omi naa sẹlẹ niti gàsíkíá ni a ti fi ami-ẹri muni gbagbọ pẹlu idaniloju.”c
Ọlọrun Bibeli
12. (a) Kinni awọn olùrẹ́rìn-ín-ẹlẹ́yà kan sọ nipa Ọlọrun? (b) Eeṣe tí Bibeli fi tọkasi Ọlọrun gẹgẹ bi Baba kan? (c) Kinni ohun ti Bibeli fihan pe ó jẹ́ orukọ Ọlọrun?
12 Gẹgẹ bi awọn eniyan kan ti rẹ́rìn-ín-ẹlẹ́yà nipa Bibeli, awọn miiran ńrẹ́rìn-ín-ẹlẹ́yà nipa wíwà Ọlọrun Olodumare kan. (2 Peter 3:3-7) Wọn nsọ pe, ‘Bawo ni mo ṣe lè gbagbọ ninu Ọlọrun, niwọn bi emi kò ti lè rí i? Ami-ẹri ha wà pe Ẹlẹdaa alaiṣeefojuri kan, tí ó gaju eniyan lọ, wà niti gidi bi? Kii ha ṣe pe Ọlọrun ńgbé ninu ohun gbogbo ni bi?’ Awọn miiran nsọ pe, ‘Kò si Ọlọrun kankan tabi Buddha.’ Bi ó ti wù ki ó rí, Bibeli fihan pe gẹgẹ bi gbogbo wa ti gbà iwalaaye nipasẹ baba kan lori ilẹ-aye, bẹẹ ni awọn babanla wa ipilẹ gbà iwalaaye lati ọ̀dọ̀ Baba kan, tabi Ẹlẹdaa kan ní ọrun, ẹni tí orukọ ara-ẹni rẹ̀ ńjẹ́ Jehofah.—Psalm 83:18; 100:3; Isaiah 12:2; 26:4.
13. Ní awọn ọna meji wo ni Jehofah ti ṣí araarẹ̀ payá fun araye?
13 Jehofah ti ṣipaya araarẹ̀ fun araye ní awọn ọna titayọ meji. Ọna naa tí ó ṣe pataki julọ jẹ́ nipasẹ Bibeli, eyi tí ó nsọ otitọ ati awọn ete ayeraye rẹ̀ di mímọ̀. (John 17:17; 1 Peter 1:24, 25) Ọna miiran jẹ́ nipasẹ iṣẹda rẹ̀. Nipasẹ fifiṣọrakiyesi awọn ohun tí ó kún fun kayefi tí ó yí wọn ká, ọpọlọpọ awọn eniyan ti wá mọriri pe Ọlọrun-Ẹlẹdaa kan nilati wà ẹni tí a ṣàgbéyọfihàn akopọ-animọ-iwa rẹ̀ atobilọla ninu awọn iṣẹ rẹ̀.—Iṣipaya 15:3, 4.
14. Kinni ohun tí Bibeli sọ fun wa nipa Jehofah?
14 Jehofah Ọlọrun ni Onṣewe Bibeli. Oun ni Ẹmi Titobi naa, tí ó wà jalẹ gbogbo ayeraye. (John 4:24; Psalm 90:1, 2) Orukọ rẹ̀ “Jehofah” pe afiyesi si ete rẹ̀ fun awọn iṣẹda rẹ̀. Ete rẹ̀ ni lati dá orukọ titobi yẹn lare nipasẹ pipa awọn olubi run ki ó sì gbà awọn wọnni tí wọn nifẹẹ rẹ̀ silẹ ki wọn lè maa gbé ninu paradise kan lori ilẹ-aye. (Exodus 6:2-8; Isaiah 35:1, 2) Niwọn bi oun ti jẹ́ Ọlọrun Olodumare, oun ní agbara lati ṣe eyi. Gẹgẹ bi Ẹlẹdaa gbogbo agbaye, oun ga fiofio jù awọn ọlọrun yẹpẹrẹ ati awọn oriṣa iṣẹdalẹ gbogbo lọ.—Isaiah 42:5, 8; Psalm 115:1, 4-8.
15. Ikẹkọọ Iṣẹda nipasẹ awọn eniyan ọlọgbọn-òye ti ṣamọna si awọn ipari-ero wo?
15 Ní awọn ọ̀rúndún lọọlọọ yii, awọn eniyan onimọ-ijinlẹ ti fi akoko tí ó pọ̀ fun ikẹkọọ iwadii awọn iṣẹ iṣẹda. Kinni ipari-ero wọn? Ọ̀kan lara awọn aṣaaju-ọna ninu pápá ẹkọ iná mànàmáná, ọmọ ilẹ Gẹẹsi onimọ-ijinlẹ tí a mọ̀ dunju naa Lord Kelvin, kede pe: “Mo gbagbọ pe bi a bá ti farabalẹ kẹkọọ iwadii ọgbọn ijinlẹ tí ó sì yéni yékéyéké tó bẹẹ ni yoo mú wa jinna-réré si ohunkohun tí ó farajọ aigbagbọ pe Ọlọrun wà.” Onimọ-ijinlẹ ọmọ ibilẹ Europe naa Albert Einstein, bi ó tilẹ jẹ́ pe ó ní ìfùsì fun jíjẹ́ alaigbagbọ pe Ọlọrun wà, jẹwọ pe: “Ó ti tó gẹ́ẹ́ fun mi lati . . . ronúsíwásẹ́hìn lori ọna igbekalẹ yiyanilẹnu agbaye, eyi tí a lè wòye lọna kan tí ó ṣe bàìbàì, ki a sì fi pẹlu irẹlẹ gbiyanju lati finúmòye ani diẹ bín-ín-tín ninu apakan ọgbọ́n-òye tí ó farahan ninu àdánidá.” Onimọ-ijinlẹ America ati agbẹ̀bùn Nobel Arthur Holly Compton ti sọ wipe: “Agbaye kan tí nṣipaya funni létòlétò yii nkedejẹrii si otitọ gbolohun-ọrọ ọlọla nla julọ tí a tíì sọ jade rí—‘Ní ibẹrẹ-atetekọṣe Ọlọrun.’” Oun ńfà awọn ọrọ iṣaaju inu Bibeli yọ.
16. Bawo ni agbaye ṣe gbé ògo ọgbọ́n ati agbara iṣẹda Ọlọrun ga?
16 Awọn alakooso awọn orilẹ-ede alagbara-nla lè ṣogo lori ọgbọ́n-òye ati aṣepari imọ-ijinlẹ wọn ninu iṣẹgun gbalasa ojude ofuurufu. Ṣugbọn bawo ni awọn satellite wọn ṣe jẹ́ ohun yẹpẹrẹ nigba tí a bá fiwera pẹlu oṣupa tí ó ńyí ilẹ-aye po, ati awọn planet tí ó ńyí oòrùn po! Bawo ni awọn aṣeyọri awọn ẹni kíkú wọnyi ti jẹ́ tẹwurẹ ní ifiwera pẹlu iṣẹda Jehofah ti awọn ọpọlọpọ billion ìṣupọ̀-ìràwọ̀ tí ó wà ní oju-ọrun, tí ọkọọkan ninu wọn ní ọpọ billion oòrùn bii iru tiwa, ati kíkó tí oun kó wọn jọ tí ó sì ṣeto wọn ninu gbalasa ofuurufu fun akoko tí kò ṣeé díwọ̀n! (Psalm 19:1, 2; Job 26:7, 14) Kò ṣeni ní kayefi pe Jehofah kà awọn eniyan sí ẹlẹ́ǹgà lasan, ati awọn orilẹ-ede alagbara-nla “gẹgẹ bi ohun aisi.”—Isaiah 40:13-18, 22.
17. Eeṣe tí ó fi bọgbọnmu lati gbagbọ ninu Ẹlẹdaa kan?
17 Ṣé inu ile kan ni iwọ ńgbé? Boya iwọ tikaraarẹ̀ kọ́ ni ẹni tí ó kọ́ ile naa, bẹẹ ni iwọ kò mọ̀ ẹni tí ó kọ́ ọ. Bi ó ti wù ki ó rí, otitọ-isẹlẹ naa pe iwọ kò mọ̀ ẹni tí ó kọ́lé kò ní ṣe idiwọ fun ọ lati gbà wipe ọlọgbọn-òye eniyan kan ni ó ti kọ́ ọ. Lati wòyeronú pe ile naa ni ó kọ́ araarẹ̀ yoo jẹ́ ìwà-òmùgọ̀ gan-an! Niwọn bi agbaye titobi naa, ati ohun gbogbo tí nbẹ ninu rẹ̀, ti beere fun ọlọgbọn-òye titobi lọpọlọpọ jù fun igbekalẹ rẹ̀, kii ha ṣe ohun tí ó bọgbọnmu lati dé ori ipari-ero naa pe Ẹlẹdaa Ọlọgbọn-òye kan nilati wà? Loootọ, àfi òpònú nikan naa ni ó lè wí ninu ọkàn-àyà rẹ̀ pe, “Kò si Jehofah.”—Psalm 14:1, NW; Hebrew 3:4.
18. Kinni ó fihan pe Ọlọrun jẹ́ ẹnikan, tí ó sì yẹ lati yìn?
18 Awọn ohun kayefi ológo tí ó yí wa ká naa—awọn òdòdó, awọn ẹyẹ, awọn ẹranko, iṣẹda tí ó kún fun iyanu tí a ńpè ní eniyan, iṣẹ-iyanu iwalaaye ati ti ọmọ bíbí—gbogbo iwọnyi nkede-jẹrii si Ọ̀gá Onírònúmòye kan tí a kò lè fojuri tí ó mú wọn jade wá. (Rome 1:20) Nibi tí ìrònúmòye bá wà, ero-inu wà nibẹ. Nibi tí ero-inu bá sì wà, ẹnikan wà nibẹ. Ìrònúmòye gigajulọ naa ni ti Ẹni Gigajulọ naa, Ẹlẹdaa ohun gbogbo tí nbẹ laaye, Ojúsun ìyè gan-an funraarẹ̀. (Psalm 36:9) Ẹlẹdaa naa dajudaju yẹ fun gbogbo ìyìn ati ọ̀wọ̀ jijinlẹ.—Psalm 104:24; Iṣipaya 4:11.
19. (a) Eeṣe tí orilẹ-ede eyikeyi lonii kò fi lè jẹ́wọ́sọ pe oun rí ìjagunmólú ninu ogun lati ọ̀dọ̀ Ọlọrun? (b) Eeṣe tí Ọlọrun kò fi ní ipa ninu awọn ogun orilẹ-ede?
19 Awọn kan wà tí iriri lilekoko Ogun Agbaye Keji ti mì igbagbọ wọn ninu Ọlọrun tìtì. Ní akoko yẹn olukuluku ilẹ-orilẹ-ede ni nkepe “Ọlọrun” rẹ̀, yala wọn jẹ́ ti awọn onisin Catholic tabi Protestant tabi awọn isin ti Gábàsì. A ha lè sọ pe “Ọlọrun” fun awọn kan lara awọn orilẹ-ede wọnyi ní ìjagunmólú tí ó sì yọnda awọn miiran lati di ẹni tí a ṣẹ́gunṣẹ́tẹ̀? Bibeli fihan pe kò si ọ̀kankan ninu awọn orilẹ-ede wọnyi tí nkede Ọlọrun otitọ. Kii ṣe Jehofah Ọlọrun, Ẹlẹdaa ọrun ati ilẹ-aye, ni yoo dahun fun ẹru-iṣẹ fun idarudapọ ati awọn ogun laarin awọn orilẹ-ede.(1 Corinth 14:33) Awọn èrò rẹ̀ ga fiofio jù ti awọn orilẹ-ede olóṣèlú ati oníjàgídíjàgan jagunjagun ilẹ-aye yii lọ. (Isaiah 55:8, 9) Bẹẹ gẹgẹ, isin tootọ ati ijọsin Jehofah kò ní ipa kankan ninu awọn ogun orilẹ-ede. Jehofah ga fiofio jù awọn Ọlọrun onifẹẹ orilẹ-ede-ẹni. Ó sì jẹ́ alailẹgbẹ ní jíjẹ́ Ọlọrun awọn ọkunrin ati obinrin olùfẹ́ alaafia ní gbogbo awọn orilẹ-ede. Gẹgẹ bi Bibeli ti sọ: “Ọlọrun kii ṣe ojúsàájú eniyan, ṣugbọn ní gbogbo orilẹ-ede ẹni tí ó bá bẹru rẹ̀, tí ó sì nṣiṣẹ ododo, ẹni itẹwọgba ni lọdọ rẹ̀.” (Iṣe 10:34, 35) Awọn eniyan onitẹsi ododo ní gbogbo awọn orilẹ-ede ni wọn nkẹkọọ Bibeli nisinsinyi tí wọn sì ńgbá ijọsin ‘Ọlọrun otitọ tí nfunni ní alaafia,’ Ẹlẹdaa gbogbo araye naa mọra.—Rome 16:20; Iṣe 17:24-27.
20. Kinni ó fihan pe Kristendom kii ṣe Kristian, ati pe wọn sì jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun?
20 Awọn eniyan kan ntọkasi ipinya ati agabagebe ninu awọn isin Kristendom, tí wọn jẹ́wọ́sọ pe awọn ntẹle Bibeli. Won tún sọ pẹlu pe, ‘Bawo ni mo ṣe lè ní igbagbọ ninu Ọlọrun Bibeli, nigba tí awọn orilẹ-ede tí wọn ní Bibeli wà lara awọn wọnni tí wọn ńkó ohun-ija olóró atomik jọ lọna tí ó ńmúnigbọnriri?’ Otitọ-iṣẹlẹ naa ni pe, nigba tí Bibeli duro bi otitọ nigba gbogbo, awọn orilẹ-ede Kristendom ti yasọtọ jinna-réré kuro ninu isin Kristian ti Bibeli gẹgẹ bi Ipẹkun Ariwa ti jinna-réré si Ipẹkun Guusu. Wọn jẹ́ alagabagebe ninu fífẹnujẹ́wọ́ isin Kristian. Wọn ní Bibeli, ṣugbọn wọn kò ṣègbọ́ràn si awọn ẹkọ rẹ̀. Ààrẹ ilẹ America tí ó paṣẹ jíjù bomb atomik akọkọ lé ori Hiroshima ṣe sáàfúla nigba kan pe: “Óò à bá jẹ́ lè rí Isaiah tabi St. Paul kan!”—lati ṣamọna awọn eniyan ninu rúgúdù ayé yii. Ki a sọ pe oun ti fohunṣọkan pẹlu Isaiah Bibeli ni, oun kìbá ti jù bomb atomik naa, nitori Isaiah ṣe alágbàwí nipa ‘fifi awọn idà rọ abẹ-ohun-eelo-ìtúlẹ̀ ati ọ̀kọ̀ rọ dòjé.’ Jù bẹẹ lọ, Paul inu Bibeli ni ó kede wipe: “Awa kò jagun nipa ti ara, nitori ohun-ija wa kii ṣe ti ara.” (Isaiah 2:4; 2 Corinth 10:3, 4) Bi ó ti wù ki ó rí, dipo titẹle imọran ọlọgbọn Bibeli, awọn orilẹ-ede Kristendom ti kówọnú eré-ìje kíkó awọn ohun-ija tí npani jọ. Awọn ìjẹ́wọ́sọ eyikeyi tí wọn lè ṣe pe awọn jẹ́ Kristian onigbagbọ ninu Bibeli jẹ́ eke. Wọn nilati dojukọ idajọ Ọlọrun fun kikuna lati ṣe ifẹ-inu rẹ̀.—Matthew 7:18-23; Zephaniah 1:17, 18.
Awọn Iṣẹda ati Iṣẹ-iyanu Jehofah
21. Eeṣe tí ó fi bọgbọnmu lati maṣe ṣiyemeji nipa awọn iṣẹ-iyanu Ọlọrun?
21 Jehofah nṣẹda, ó sì ńmú awọn iṣẹ-iyanu ṣe. Iwọ ha ti ṣe kayefi rí nipa sisọ omi di ẹjẹ, pípín Òkun Pupa níyà, ìbí Jesu nipasẹ wundia naa, ati awọn iṣẹ-iyanu miiran tí a ṣakọsilẹ rẹ̀ sinu Bibeli? Niwọn bi ó ti jẹ́ pe agbara ọgbọn-òye eniyan ti ní ààlà, ó ṣeeṣe ki oun má loye bi diẹ ninu awọn iṣẹ-iyanu wọnyi ṣe ṣẹlẹ lae, bakan naa gẹgẹ bi oun kò ti lè loye iṣẹ-iyanu ríràn ati wíwọ̀ oòrùn lọ́jọ́ kọọkan lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́. Iṣẹ-iyanu ni iṣẹda eniyan jẹ́. Eniyan ode-oni kò rí iṣẹ-iyanu yẹn, ṣugbọn ó mọ̀ pe ó ṣẹlẹ, nitori oun walaaye lonii lati fihan pẹlu ami-ẹri. Nitootọ, gbogbo iwalaaye ati gbogbo agbaye parapọ jẹ́ iṣẹ-iyanu kan tí ó ńbáa lọ titilọ-kánrin. Nitori naa ó ha yẹ ki awa ṣiyemeji nigba tí Ọrọ Ọlọrun, Bibeli, sọ pe oun mú awọn iṣẹ-iyanu pàtó kan ṣe níṣẹ́ fun awọn akoko pàtó kan, bi ó tilẹ jẹ́ pe kò si idi fun awọn iṣẹ-iyanu kan naa lonii?
22. Ṣapejuwe iṣẹ iṣẹda akọkọ tí Ọlọrun ṣe.
22 Gbogbo iṣẹda Jehofah ni ó kún fun iṣẹ-iyanu ati kayefi! Àmọ́ ṣáá o, iṣẹda rẹ̀ akọkọ gan-an ni ó jẹ́ yiyanilẹnu julọ ninu gbogbo awọn iṣẹda rẹ̀. Eyiyii ni iṣẹda Ọmọkunrin ẹmi kan, “akọbi” rẹ̀. (Colossae 1:15) Ọmọkunrin ọrun yii ni a sọ orukọ rẹ̀ ní “Ọrọ naa.” Ní awọn sanmanni tí kò níye lẹhin iṣẹda rẹ̀, oun wá si ori ilẹ-aye yii tí a sì pe orukọ rẹ̀ ní “ọkunrin naa Kristi Jesu.” (1 Timothy 2:5) Lẹhin naa ni a sọ nipa rẹ̀ pe: “Ọrọ naa sì di ara, oun sì ńbá wa gbé, awa sì ńwò ogo rẹ̀, ògo bii ti ọmọ bíbí kanṣoṣo lati ọ̀dọ̀ Baba wá, ó kún fun oore-ọfẹ ati otitiọ.”—John 1:14.
23. (a) Bawo ni a ṣe lè ṣalaye ipo-ibatan tí ó wà laarin Ọlọrun ati Ọmọkunrin rẹ̀? (b) Nipasẹ Ọmọkunrin rẹ̀, kinni ohun tí Jehofah dá?
23 Ipo-ibatan tí ó wà laarin Jehofah ati Ọmọkunrin rẹ̀ ni a lè fiwera pẹlu eyi tí ó wà laarin olubojuto-oni-nǹkan ati ọmọkunrin rẹ̀ ninu ìsọ̀-iṣẹ́ kan, nibi tí ọmọkunrin naa ti nṣe iranlọwọ ṣiṣe awọn nǹkan tí baba rẹ̀ ti ṣe iṣẹ-ọnà wọn. Nipasẹ Ọmọkunrin rẹ́ akọbi ati oṣiṣẹ olubakẹgbẹ yii, Jehofah dá ọpọlọpọ awọn iṣẹda ti ẹmi miiran, awọn ọmọkunrin Ọlọrun. Lẹhin naa, awọn wọnyi yọ̀ ayọ-nla lati rí Ọmọkunrin Jehofah, Ọ̀gá ońṣẹ́ rẹ̀, tí ńmú awọn ọrun ati ilẹ-aye lori eyi tí awa ńgbé jade wá. Iwọ ha nṣiyemeji wipe dídá ni a dá awọn nǹkan wọnyi bi? Ní ẹgbẹẹgbẹrun ọdun lẹhin naa, Jehofah beere lọwọ ọkunrin oloootọ kan pe: “Nibo ni iwọ wà nigba tí mo fi ipilẹ ayé sọlẹ̀? Wí bi iwọ bá mòye! Nigba tí awọn irawọ owurọ jumọ kọrin pọ̀, ti gbogbo awọn [ọmọkunrin] Ọlọrun hó ìhó-ayọ̀?”—Job 38:4, 7; John 1:3.
24. (a) Awọn iṣẹda ori ilẹ-aye wo tí Jehofah ṣe ní ó tayọ, lọna wo sì ni? (b) Eeṣe tí kò fi bọgbọnmu lati sọ pe eniyan dagba-jade lati inu awọn ẹranko?
24 Kò pẹ́ kò jinna lẹhin naa, Jehofah dá awọn ohun alaaye, awọn ohun ti ara ori ilẹ-aye yii, awọn planet, awọn igi, awọn òdòdó, awọn ẹja, awọn ẹyẹ, ati awọn ẹranko. (Genesis 1:11-13, 20-25) Lẹhin naa ni Ọlọrun sọ fun Ọ̀gá Oṣiṣẹ rẹ̀ pe: “Jẹ́ ki a dá eniyan ní aworan wa, gẹgẹ bi ìrí wa . . . Bẹẹ ni Ọlọrun dá eniyan ní aworan rẹ̀, ní aworan Ọlọrun ni a dá a; ati akọ ati abo ni a dá wọn.” (Genesis 1:26, 27) Niti dídá tí a dá a ní aworan ati jijọ Ọlọrun pẹlu awọn animọ titobi Ọlọrun ti ifẹ, ọgbọn, idajọ-ododo, ati agbara, ọkunrin ipilẹṣẹ naa ní ọla tí ó gaju ti awọn ẹranko lọ. Eniyan wà ní ipo kan tí ó yatọ gédégédé si ti awọn ẹranko niti pe ó ṣeeṣe fun eniyan lati fòyeronú, ó lè wewee fun ọjọ-ọla, tí ó sì ní agbara-àyè lati jọsin Ọlọrun. Awọn ẹranko kò ní ìrònúmòye lati fi wòyeronú, ṣugbọn wọn ńgbé nipasẹ ìtẹ̀sí-ìwà-àdánidá. Bawo ni ó ṣe jẹ́ ailọgbọn-ninu tó lati sọ pe kò si Ẹlẹdaa ṣugbọn pe awọn ẹda-eniyan tí a fi ọgbọn-oye fun lọpọlọpọ rọra dagba jade lati inu awọn ẹranko rirẹlẹ alailọgbọn-oye!—Psalm 92:6, 7; 139:14.
25, 26. (a) Ifojusọna-ireti atobilọla wo ni a gbeka iwaju eniyan? (b) Eeṣe tí ki yoo fi si ọran-iṣoro àkúnya iye-eniyan lori ilẹ-aye?
25 Ọlọrun fi eniyan sinu “ọgba kan ninu Eden, lọna apá ìhà ila-oorun.” Ó jẹ́ ọgbà-ọ̀gbìn onidunnu kan, gẹgẹ bi ọgbà-ọ̀gbìn tí ó wà ní òde iwe wa yii, bi ó tilẹ jẹ́ pe ẹda-eniyan meji péré ni ó ṣì wà nibẹ sibẹ, Adam ati iyawo rẹ̀. Paradise ipilẹṣẹ yii kò sí mọ́ nisinsinyi, nitori pe a ti pa á run ninu Ikun-omi ọjọ Noah. Ṣugbọn apá ibi tí ó ṣeeṣe ki ó wà ní ìhà Aarin Ila-oorun ni a mọ̀ dunjú, nitori awọn odò kan bayii tí a darukọ ninu Bibeli pe wọn ńṣàn là inu rẹ̀ kọja wà sibẹ titi di òní-olónìí. (Genesis 2:7-14) Eniyan ní ire-anfaani titobilọla lati lò ọgbà-ọ̀gbìn yii gẹgẹ bi aarin ibi tí wọn yoo ti tankalẹ ki wọn sì ro gbogbo ilẹ-aye, ní sisọ ọ di paradise kan yika òbìrìkìtì ayé.—Isaiah 45:12, 18.
26 Gẹgẹ bi Ọlọrun ati Ọmọkunrin rẹ̀ ti jẹ́ oṣiṣẹ, bẹẹ gẹgẹ pẹlu ni Ọlọrun fun eniyan ní iṣẹ níhìn-ín lori ilẹ-aye. (John 5:17) Fun Adam ati Efa, ọkunrin ati obinrin ekinni naa ni ó wipe: “Ẹ maa bisii, ki ẹ sì maa rẹ̀, ki ẹ sì gbilẹ̀, ki ẹ sì ṣe ìkáwọ́ rẹ̀; ki ẹ sì maa jọba lori ẹja òkun, ati lori ẹyẹ oju-ọrun, ati lori ohun alaaye gbogbo tí ńrákò lori ilẹ.” (Genesis 1:28) Eyi ha tumọsi pe eniyan nilati di pupọ sii, ki wọn kún ilẹ-aye, ki wọn sì maa baa nìṣó lati maa di pupọ sii titi ilẹ-aye yoo fi kún dé àkúnya? Rara. Nigba tí ẹnikan bá sọ fun ọ ki o rọ tea kún ife, iwọ kò ní maa rọ ọ́ sinu rẹ̀ titi tea naa yoo fi kún àkúndàsílẹ̀ ninu ife naa tí yoo sì bẹrẹsii dànù si ori tabili. Iwọ yoo rọ ife naa kún nigba naa ni iwọ yoo sì dáwọ́dúró. Ní ọna kan naa ofin-aṣẹ Jehofah fun eniyan, “Kún ori ilẹ-aye,” ṣe itọkafihan ete rẹ̀ lati fi eniyan kún ilẹ-aye pẹlu ìrọ̀rùn, lẹhin naa ki ó sì wá dá ìmúrú-ẹ̀dá-jáde ti ẹda-eniyan duro níhìn-ín lori ilẹ-aye. Eyi kò ní gbé ọran-iṣoro kankan dide ninu ẹgbẹ-oun-ọgba ẹda-eniyan pípé kan. Ninu ayé ode-oni ti araye aláìpé nikan ni àkúnya iye-eniyan ti lè gbé ọran-iṣoro kan dide.
Awọn Ohun Buburu—Eeṣe Tí Ọlọrun Nyọọda Wọn?
27. Awọn ibeere wo ni ó nbeere fun idahun nisinsinyi?
27 Bi ó bá jẹ́ ete Ọlọrun ni lati kọ́ paradise ori ilẹ-aye kan, bawo ni ó ṣe wá jẹ́ pe ile-aye naa lonii ti wá kún fun iwa-buburu, ijiya, ati ìkárísọ? Bi Ọlọrun bá jẹ́ Olodumare, eeṣe tí oun fi yọọda awọn ipo wọnyi fun igba gígùn tobẹẹ? Ireti ha wà pe opin yoo débá gbogbo awọn ìjọ̀ngbọ̀n wa? Kinni ohun tí Bibeli wi?
28. Bawo ni ọ̀tẹ̀ ṣe wọ̀ inu ọgbà-ọ̀gbìn Paradise naa?
28 Bibeli fihan pe awọn ìjọ̀ngbọ̀n araye bẹre nigba tí ọ̀kan lara awọn ọmọkunrin ẹmi Ọlọrun ṣọ̀tẹ̀ lodisi jíjẹ́ ọba-alaṣẹ, tabi aṣẹ-iṣakoso Jehofah. (Rome 1:20; Psalm 103:22, NW Ref. Bi., alaye eti-iwe.) Laisi aniani angeli yii wà lara awọn wọnni tí wọn yọ̀ ayọ-nla nigba tí wọn rí iṣẹ iṣẹda eniyan. Ṣugbọn ṣá ojukokoro ati igberaga kówọnú ọkàn-àyà rẹ̀, a sì ré e lọ nipasẹ ifẹ-ọkan naa lati mú ki Adam ati Efa maa jọsin oun dipo Ẹlẹda wọn, Jehofah. Nigba tí ó nsọrọ nipasẹ ejo-nla kan, gẹgẹ bi ọlọ́sanyìn kan ti nsọrọ nipasẹ ère kan, angeli yii rọ̀ Efa lọ́kàn lati ṣe aigbọran si Ọlọrun Olodumare. Ọkọ rẹ̀ Adam lẹhin naa tẹle e sinu ṣiṣẹ aigbọran.—Genesis 2:15-17; 3:1-6; James 1:14, 15.
29. (a) Awọn arinyanjiyan wo ni ó dide fun ironupinnu? (b) Bawo ni Ọlọrun ṣe bojuto ipenija naa? (c) Bawo ni iwọ ṣe lè ṣajọpin ninu pipese idahun si iṣaata Satan?
29 Angeli ọlọ̀tẹ̀ nì ni a wá mọ̀ sí “ejo laelae nì.” (Iṣipaya 12:9; 2 Corinth 11:3) A tún ńpè é ní Satan, tí ó tumọsi “Alatako,” ati Eṣu, tí ó tumọsi “Agbadùlúmọ̀.” Ó gbé ọran-ariyanjiyan dide si ẹ̀tọ́ ati ododo agbara-iṣakoso Jehofah lori ilẹ-aye, ó sì pè Ọlọrun níjà pe oun Satan, nisinsinyi, lè yí gbogbo araye kuro ninu ijọsin tootọ. Ọlọrun ti yọnda 6,000 ọdun fun Satan lati gbiyanju lati fi ami-ẹri ipenija rẹ̀ hàn, ki a lè yanju ọran-ariyanjiyan lori ipo-ọba-alaṣẹ Jehofah titi laelae. Iṣakoso eniyan ní ìdádúrólómìnira kuro lọdọ Ọlọrun ti kuna báḿbáḿ. Ṣugbọn awọn ọkunrin ati obinrin onigbagbọ, lara awọn ẹni tí Jesu ti jẹ́ apẹẹrẹ titayọ, ti pa ìwàtítọ́ mọ́ si Ọlọrun labẹ awọn àdánwò kikankikan, ní dídá Jehofah lárejóòótọ́ ati fifihan pẹlu àmì-ẹ̀rí pe Eṣu jẹ́ òpùrọ́ kan. (Luke 4:1-13; Job 1:7-12; 2:1-6; 27:5) Iwọ, pẹlu, lè jẹ́ olùpàwàtítọ́mọ́ kan. (Owe 27:11) Ṣugbọn Satan nikan kọ́ ni ọ̀tá kanṣoṣo naa tí ó ńpọ́n wa lójú. Ọ̀tá miiran wo ni ó tún wà?
Ọ̀tá naa—Iku
30. Kinni ohun tí Ìwémímọ́-ìsìn sọ nipa sẹ̀ríà tí a dá fun eniyan nitori aigbọran rẹ̀?
30 Ọlọrun ti dá sẹ̀ríà fun aigbọran—iku. Ní sisọ idajọ rẹ̀ jade sori obinrin kìn-ín-ní naa, Jehofah wipe: “Emi yoo sọ ipọnju ati irora ìlóyún rẹ di pupọ. Ninu irora ipọnju ni iwọ yoo maa bimọ, lọdọ ọkọ rẹ sì ni ifẹ rẹ yoo maa fàsí, oun ni yoo sì maa ṣe olori rẹ.” Fun ọkunrin naa Adam ni oun wipe: “Ní òógùn oju rẹ ni iwọ yoo maa jẹun titi iwọ yoo fi pada si ilẹ, nitori lati inu rẹ̀ ni a ti mú ọ jade wá. Erupẹ sáà ni iwọ, iwọ yoo sì pada di erupẹ.” (Genesis 3:16-19) Awọn tọkọtaya alaigbọran naa ni a lé jade kuro ninu Paradise alayọ naa sinu ilẹ tí a kò tíì ro. Nigba tí ó ṣe wọn kú.—Genesis 5:5.
31. Kinni ẹṣẹ, kinni ó sì ti jẹ́ abajade rẹ̀ fun araye?
31 Ẹhin igba tí Adam ati Efa ṣubu kuro ninu àmì-ìlà ijẹpipe ni wọn tó bẹrẹsii mú awọn ọmọ jade. Gbogbo awọn eniyan ayé lonii jẹ́ atọmọdọmọ wọn ninu àìpé, ati nitori naa ni gbogbo wọn fi ńkú. Akọwe Bibeli kan làdí rẹ̀ yéni bayii pe: “Nitori gẹgẹ bi ẹṣẹ ti ti ipa ọ̀dọ̀ eniyan kan wọ̀ ayé, ati iku nipa ẹṣẹ; bẹẹ ni iku sì kọja sori eniyan gbogbo, lati ọ̀dọ̀ ẹni tí gbogbo eniyan ti dẹṣẹ.” Kinni “ẹṣẹ” yii? Ó jẹ́ ṣiṣubu kuro ninu àmì-ìlà ijẹpipe tabi ìjẹ́pípépérépéré. Jehofah Ọlọrun kii fọwọsi-tẹwọgba tabi pa ohunkohun tí ó jẹ́ aláìpé mọ́ láàyè. Niwọn bi gbogbo eniyan ti jogún ẹṣẹ ati àìpé lati ọ̀dọ̀ ọkunrin akọkọ naa Adam, iku ti “jọba” lori gbogbo wọn. (Rome 5:12, 14) Eniyan ẹlẹsẹ ńkú, lọna kan naa tí awọn ẹranko ńgbà kú.—Oniwaasu 3:19-21.
32. Bawo ni Bibeli ṣe ṣalaye iku tí a jogun?
32 Kinni “iku” yii? Iku ni odikeji ìyè. Ọlọrun ti gbé ifojusọna-ireti rere ti ìyè ainipẹkun lori ilẹ-aye siwaju eniyan bi ó bá ṣe igbọran. Àmọ́ ṣáá o, oun ṣe aigbọran, sẹ̀ríà naa sì ni iku, ainimọlara, àìsíláàayè. Ọlọrun kò sọ ohunkohun nipa ṣíṣí ipo iwalaaye eniyan pada si ilẹ-ọba awọn ẹda ẹmi tabi sinu “hell” oníná bi oun bá ṣe aigbọran tí ó sì kú. Oun ti kilọ fun eniyan pe: “Kíkú ni iwọ yoo kú.” Eṣu olùpànìyàn naa ni ẹni tí ó purọ tí ó wipe: “Ẹyin ki yoo kú ikúkíkú kan.” (Genesis 2:17; 3:4; John 8:44) Ohun tí gbogbo eniyan ti jogún lọdọ Adam ni iku gẹgẹ bi erupẹ lasan.—Oniwaasu 9:5, 10; Psalm 115:17; 146:4.
33. (a) Ọjọ-ọla ológo wo ni ó ndurode araye ati ilẹ-aye yii? (b) Awọn ohun pataki mẹta wo ni Jehofah ṣe aṣeyọri nipasẹ Ọmọkunrin rẹ̀?
33 Nigba naa, eyi ha tumọsi pe kò si ọjọ-ọla kankan fun eniyan tí ńkú bi? Ọjọ-ọla yiyanilẹnu kan wà! Bibeli fihan pe ete Ọlọrun fun paradise ori ilẹ-aye kan fun gbogbo araye, tí ó ní ninu awọn wọnni tí wọn ti kú nisinsinyi, ni ki yoo kuna lae. Jehofah wipe: “Ọrun ni ìtẹ́ mi, ayé sì ni apoti ìtìsẹ̀ mi.” “Emi yoo ṣe ibi ẹsẹ mi lógo.” (Isaiah 66:1; 60:13) Lati inu ọpọlọpọ yanturu ifẹ rẹ̀, Jehofah rán Ọmọkunrin rẹ̀, Ọrọ, wá si ori ilẹ-aye yii, ki ayé araye lè jèrè ìyè nipasẹ rẹ̀. (John 3:16; 1 John 4:9) Awọn nǹkan pataki mẹta ni ó wà tí a nilati jiroro lélórí nisinsinyi, awọn ohun tí Jehofah ti ṣe aṣeyọri wọn nipasẹ Ọmọkunrin rẹ̀, awọn naa ni, (1) pipese ìtúsílẹ̀ kuro ninu agbara iku; (2) imupadabọsipo awọn òkú si ìyè niti gidi; ati (3) fifi idi ijọba-akoso pípé kan mulẹ lori gbogbo araye.
Itusilẹ Kuro ninu Iku
34, 35. (a) Kìkì lọna wo ni a fi lè rà eniyan pada kuro ninu iku? (b) Kinni irapadan kan?
34 Lati igba atijọ ni awọn wolii Ọlọrun ti sọ ìgbọ́kànlé wọn jade, kii ṣe ninu aileeku eniyan ṣugbọn ninu ireti naa pe Ọlọrun yoo ‘mú wọn pada’ kuro ninu iku. (Hosea 13:14) Ṣugbọn bawo ni a ṣe lè tú eniyan silẹ kuro ninu awọn ìdè iku? Idajọ-ododo pípé Jehofah beere fun ‘ọkàn fun ọkàn, ojú fun ojú, ehín fun ehín.’ (Deuteronomy 19:21) Nitori naa, niwọn bi Adam ti mú iku ajogunba wá fun gbogbo araye nipasẹ mímọ̀ọ́mọ̀ ṣaigbọran si Ọlọrun tí ó sì padanu ìjẹ́pípé iwalaaye ẹda-eniyan, ẹda-eniyan pípé miiran nilati dípò Adam ní sisan iwalaaye rẹ̀ pípé, lati rà ohun tí Adam ti sọnu pada.
35 Ilana-ipilẹ bíbá idajọ-ododo mu ti fifi ‘ohun tí ó jọ ohun gbà iru rẹ̀’ ni a ti tẹwọgba yika ayé jalẹ gbogbo ọrọ-itan. Ọrọ-isọjade tí a saba maa ńlò ni “sisan irapada kan.” Kinni irapada? Oun ni “iye-owo kan tí a san lati mú ẹnikan tabi ohun kan pada kuro lọdọ ẹnikan tí ó dá ẹni yẹn tabi ohun yẹn duro-hámọ́lé ninu oko-ẹrú. Nitori bẹẹ awọn ẹlẹ́wọ̀n tí a kó lójú ogun tabi awọn ẹrú ni a maa nsọ pe a rapada nigba tí a bá sọ wọn dominira ní ìpààrọ̀ fun ìgbéyẹ̀wò kan tí ó ṣe iyebiye. . . . Ohunkohun tí a fi dipo tabi pààrọ̀ ní isanfidipo fun apakan naa jẹ́ irapada rẹ̀.”d Lati igba tí Adam ti dẹṣẹ, gbogbo araye ti dabi ẹlẹwọn tí a kó lójú ogun tabi awọn ẹrú, tí a fi àìpé ati iku dè. Lati tú wọn silẹ, irapada kan ni a nilati pese. Lati yẹra fun ariyanjiyan eyikeyi nisinsinyi tabi lẹhin-ọ̀la niti àìṣègbè iye-owo irapada naa, yoo pọndandan lati fi iwalaaye ẹda-eniyan pípé kan rubọ, iyẹn ni pe, ibaṣedeedee Adam gan-an.
36. Bawo ni Jehofah ṣe pese iwalaaye ẹda-eniyan pípé gẹgẹ bi irapada?
36 Àmọ́ ṣáá o, nibo ni a ti lè rí iru iwalaaye ẹda-eniyan pípé kan bẹẹ? Gbogbo eniyan, gẹgẹ bi awọn ìran-àtẹ̀lé Adam ẹni pípé naa, ni a ti bí ní aláìpé. “Kò si ọ̀kan ninu wọn bi ó ti wù ki ó ṣe tí ó lè rà arakunrin rẹ̀, bẹẹ ni kò lè san owó irapada fun Ọlọrun nitori rẹ̀.” (Psalm 49:7) Ní didahun si aini naa, Jehofah, tí a sún nipasẹ ifẹ jijinlẹ rẹ̀ fun araye, pese Ọmọkunrin rẹ̀ “akọbi” oniyebiye lati wá di ẹbọ tí ó yẹ naa. Ó ṣí iwalaaye pípé Ọmọkunrin ẹmi yii, Ọrọ naa, nípòpadà sinu ilé-ọlẹ̀ wundia Jew kan, Mary. Ọdọmọbinrin naa lóyún laipẹ ọjọ ó sì bí ọmọkunrin kan, ẹni tí a pè orukọ rẹ̀ ní “Jesu.” (Matthew 1:18-25) Ẹlẹdaa iwalaaye naa ni yoo ṣeeṣe fun ní ọna-ọgbọn-ironu lati mú irúfẹ́ iṣẹ-iyanu yiyanilẹnu bẹẹ ṣe níṣẹ́.
37. Bawo ni Jesu ṣe fi ifẹ rẹ̀ hàn fun gbogbo ẹda-eniyan tí wọn fi ọkàn-ìfẹ́ hàn fun iwalaaye?
37 Jesu dagba di géńdé ọkunrin, ó sì fi araarẹ̀ fun Jehofah, a sì baptisi rẹ̀. Nigba naa ni Ọlọrun faṣẹfun un lati ṣe ifẹ-inu Rẹ̀. (Matthew 3:13, 16, 17) Niwọn bi iwalaaye Jesu lori ilẹ-aye ti wá lati ọrun tí oun sì jẹ́ ẹni pípé, oun lè fi iwalaaye ẹda-eniyan pípé rẹ̀ rubọ, ní lílò ó lati tú araye silẹ kuro ninu iku. (Rome 6:23; 5:18, 19) Gẹgẹ bi oun ti wi pe: “Mo wá ki wọn lè ní ìyè ki wọn sì ní in lọpọlọpọ.” “Kò si ẹnikan tí ó ní ifẹ tí ó tobiju eyi lọ, pé ẹnikan fi ẹmi rẹ̀ lélẹ̀ nitori awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (John 10:10; 15:13) Nigba tí Satan mú ki a pa Jesu lori igi-oro, Jesu juwọsilẹ-tẹriba fun iku oníwà-ìkà yii, ní mímọ̀ pe awọn ẹda-eniyan tí wọn bá ńlò igbagbọ yoo jèrè ìyè nipasẹ ipese irapada yii.—Matthew 20:28; 1 Timothy 2:5, 6.
Imupadabọsipo si Ìyè
38. Bawo ni a ṣe mú iwalaaye Ọmọkunrin Ọlọrun padabọsipo, kinni ohun tí ó sì jẹrii fi eyi hàn?
38 Bi awọn ọ̀tá rẹ̀ tilẹ pa á, Ọmọkunrin Ọlọrun kò padanu ẹ̀tọ́ rẹ̀ sí iwalaaye ẹda-eniyan pípé, nitori oun ti pa ìwàtítọ́ sí Ọlọrun mọ́. Ṣugbọn, niwọn bi oun ti wà ninu ipo òkú ninu ibojì, bawo ni Jesu ṣe lè lò ohun iyebiye yii, ẹ̀tọ́ sí iwalaaye ẹda-eniyan, fun ire iran-araye? Níhìn-ín yii ni Jehofah tún ti mú iṣẹ-iyanu miiran ṣe, eyi tí ó jẹ́ ekinni tí kò sí iru rẹ̀ rí. Ní ọjọ kẹta tí Jesu ti wà ninu ibojì, Jehofah jí i dide kuro ninu iku gẹgẹ bi ẹda ẹmi, alaileeku kan. (Rome 6:9; 1 Peter 3:18) Lati fi idi igbagbọ ninu ajinde mulẹ, Jesu gbé ara ẹda-eniyan wọ̀ ó sì farahan ní awọn akoko-iṣẹlẹ tí ó yatọsira fun 500 ati awọn tí ó jù bẹẹ lọ ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. Kò si eyikeyi ninu awọn wọnyi, ati apostle Paul tí ifarahan Jesu tí a ṣelogo fọ́ lójú, tí ó ní idi eyikeyi lati ṣiyemeji nipa iṣẹ-iyanu ajinde rẹ̀.—1 Corinth 15:3-8; Iṣe 9:1-9.
39. (a) Bawo ni Jesu ṣe lò ìtóye irapada rẹ̀, ati ní akọkọ fun ire awọn wo? (b) Iṣẹ-iyanu nla miiran wo ni Jesu tún sọrọ nipa rẹ̀?
39 Lẹhin ogoji ọjọ, Jesu tí a ti jí dide naa goke lọ siwaju Ọlọrun gan-an ninu ọrun, lati gbé ìtóye ẹbọ ẹda-eniyan pípé rẹ̀ kalẹ gẹgẹ bi itusilẹ fun araye. “Ṣugbọn ọkunrin yii rú ẹbọ kanṣoṣo fun ẹṣẹ titilae ó sì jokoo lọwọ ọ̀tún Ọlọrun lati igba naa wá ó nduro titi a ó fi sọ awọn ọ̀tá rẹ̀ di apoti ìtìsẹ̀ rẹ̀.” (Hebrew 10:12, 13) Awọn ẹni akọkọ lati tusilẹ nipasẹ irapada yii ni “agbo kekere” kan ti awọn Kristian oloootọ tí “wọn jẹ́ ti Kristi.” (Luke 12:32; 1 Corinth 15:22, 23) Awọn wọnyi ni “a rapada laarin araye,” ati nitori naa nigba ajinde wọn yoo di olubakẹgbẹ Kristi nipa tẹmi ninu ọrun. (Iṣipaya 14:1-5) Àmọ́ ṣáá o, kinni ti ìkójọpọ̀ nla araye naa tí wọn ti di oku ninu ibojì wọn? Nigba tí ó wà lori ilẹ-aye, Jesu sọ pe Baba oun ti fun oun ní aṣẹ lati ṣe idajọ ki ó sì funni ní ìyè. Ó fikun un pe: “Ki eyi ki ó maṣe yà yin lẹnu, nitori pe wakati ńbọ̀, ninu eyi tí gbogbo awọn tí ó wà ninu isà-òkú yoo gbọ́ ohùn rẹ̀ wọn yoo sì jade wá, . . . si ajinde.” (John 5:26-29) Oun yoo mú awọn wọnyẹn padabọsipo si ìyè ninu Paradise lori ilẹ-aye.
40, 41. (a) Ṣalaye ohun tí “ajinde” jẹ́ niti gidi. (b) Eeṣe tí a fi lè ní igbagbọ ninu ileri Ọlọrun fun ajinde?
40 Sạkiyesi awọn ọrọ Jesu, “Ki eyi ki ó maṣe yà yin lẹ́nu.” Bi ó tilẹ rí bẹẹ, bawo ni ẹnikan tí ó ti kú tipẹtipẹ ṣe lè di ẹni tí a tusilẹ kuro lọwọ iku ki a sì mú un pada di alaaye? Ṣèbí araarẹ̀ ti pada di erupẹ? Awọn egunrín diẹdiẹ tí ó parapọ di ara rẹ̀ ti di eyi tí a mú lọ sinu awọn nǹkan alaaye miiran, iru bii awọn ohun ọ̀gbìn ati awọn ẹranko. Bi ó ti wù ki ó rí, ajinde kò tumọsi mímú awọn èròjà ohun-ipilẹ kan naa papọ pada wá lẹẹkeji. Ó tumọsi pe Ọlọrun ṣe àtúndá eniyan kan naa pẹlu akopọ-animọ-iwa kan naa. Ó mú ara titun wá lati inu awọn ohun-ipilẹ ilẹ, ninu ara yẹn ni oun fi awọn àbùdá kan naa, awọn animọ-iwa yiyatọ-ketekete kan naa, agbara-iranti kan naa, àwòkọ́ṣe igbesi-aye kan naa tí oluwarẹ̀ ti gbéró ṣaaju akoko iku rẹ̀ sí.
41 Ó ti lè jẹ́ iriri rẹ pe ile rẹ tí o fẹran pupọ ni a ti fi iná jó. Bi ó ti wù ki ó rí, ó rọrun fun ọ lati tún iru ile kan naa kọ́, nitori tí àwòkọ́ṣe gbogbo awọn kúlẹ̀kúlẹ̀ bi a ti ṣe kọ́ ọ wà kedere ninu iranti rẹ. Dajudaju, nigba naa, Ọlọrun ẹni tí ó jẹ́ Olupilẹṣẹ agbara-iranti lè ṣe àtúndá awọn eniyan tí oun ti fi pamọ sinu iranti rẹ̀ nitori oun fẹran wọn. (Isaiah 64:8) Idi rẹ̀ niyii tí Bibeli fi lò ọrọ naa ‘awọn ibojì iranti.’ Nigba tí akoko Ọlọrun bá tó lati mú awọn òkú pada wá si ìyè lẹẹkan sii, oun yoo mú iṣẹ-iyanu naa ṣe níṣẹ́, gẹgẹ bi oun ti mú iṣẹ-iyanu kan ṣe níṣẹ́ ní dídá eniyan akọkọ, kiki pe ní akoko yii oun yoo mú un ṣe níṣẹ́ ní ìlọ́po tí ó pọ̀ lọpọlọpọ rekọja.—Genesis 2:7; Iṣe 24:15.
42. Eeṣe tí ìyè ayeraye lori ilẹ-aye fi ṣeeṣe tí ó sì daju?
42 Ọlọrun yoo mú araye padabọ wá si ìyè, pẹlu ifojusọna-ireti pe wọn kò ní kú mọ́ titi kuro lori ilẹ-aye. Ṣugbọn bawo ni ìyè ainipẹkun lori ilẹ-aye ṣe lè ṣeeṣe? Ó ṣeeṣe dajudaju nitori pe ó jẹ́ ifẹ-inu ati ete atọrunwa. (John 6:37-40; Matthew 6:10) Idi kanṣoṣo tí eniyan fi ńkú kuro lori ilẹ-aye lonii ni pe ó ti jogun iku lati ọ̀dọ̀ Adam. Ṣugbọn nigba tí a bá ronu nipa oriṣiriṣi awọn nǹkan yiyanilẹnu tí kò níye tí ó wà lori ilẹ-aye tí a fẹ́ ki eniyan maa gbadun, iwalaaye kukuru tí kò tó ọgọrun ọdun ti kuru jù pupọ! Ní fifi ilẹ-aye yii fun awọn ọmọ eniyan, Ọlọrun ti pete pe ki eniyan maa walaaye titilọ lati maa gbadun awọn ògo-ẹwà iṣẹda Rẹ̀, kii ṣe fun bii ọgọrun ọdun kan lasan tabi bii ẹgbẹrun ọdun kan paapaa, ṣugbọn titi laelae!—Psalm 115:16; 133:3.
Ijọba-Akoso Pípé Alalaafia
43. (a) Aini wo ni ó wà fun ijọba-akoso pípé kan? (b) Kinni ohun tí Jehofah pètepèrò lori eyi?
43 Nitori ṣíṣá tí awọn obi wa akọkọ ṣá ofin Ọlọrun tì, ijọba-akoso ẹda-eniyan di eyi tí ó bọ́ si abẹ́ ìkáḿbà Satan. Lọna tí ó ṣe kòńgẹ́ Bibeli pè Satan ní “ọlọrun eto-igbekalẹ awọn nǹkan yii.” (2 Corinth 4:4, NW) Awọn ogun, ìwà-ìkà, idibajẹ, ati aiduro deedee awọn ijọba-akoso eniyan jẹriifihan pe oun ni. Imulẹ Awọn Orilẹ-ede ati Iparapọ Awọn Orilẹ-ede ti kuna lati mú alaafia jade ninu idarudapọ naa. Araye nkigbe fun ijọba-akoso alalaafia kan. Kò ha bọgbọnmu pe ki Ẹlẹdaa naa, ẹni tí ó ti pete lati mú Paradise padabọsipo lori ilẹ-aye yii, ki ó pese ijọba-akoso pípé kan fun Paradise yẹn? Eyiiyi gan-an ni ohun tí Jehofah ti pete lati ṣe. Ọba naa tí nṣoju fun Un ninu ijọba-akoso yii ni “Ọmọ-alade Alaafia” rẹ̀, Kristi Jesu, ati “nipa ibisi iṣakoso ọmọ-alade naa ati alaafia rẹ̀ kò ní sí opin.”—Isaiah 9:6, 7, NW.
44. (a) Nibo ni ijọba-akoso yii yoo wà? (b) Bawo ni a ó ṣe ṣe akojọpọ rẹ̀?
44 Bibeli fihan pe ijọba-akoso pípé naa yoo wà ní ọrun. Lati ori ipo-anfaani yii, ni Jesu Kristi Ọba naa yoo ti maa ṣakoso gbogbo ori ilẹ-aye lọna gbígbéṣẹ́ ní ododo. Jù bẹẹ lọ, oun yoo ní awọn alakooso olubakẹgbẹ ninu ijọba ọrun tí a kò lè fojuri, ijọba-akoso ti ọrun. Awọn wọnyi ni a yàn laarin awọn ẹda-eniyan oloootọ, awọn ọmọlẹhin Jesu tí wọn ti duro tì í jálẹ̀ awọn àdánwò rẹ̀ ati awọn wọnni tí oun wí fun pe: “Mo ti bá yin dá majẹmu pẹlu gẹgẹ bi Baba mi ti bá mi dá majẹmu, fun ijọba kan.” (Luke 22:28, 29) Awọn diẹ ninu awọn iran-araye ni a ńmú lọ si ọrun lati bá Kristi Jesu jọba. Ó rí bakan naa bii ti awọn orilẹ-ede ọjọ́-òní, nibi tí a ti ńyàn awọn diẹ lati ṣakoso ní ile-igbimọ tabi ajọ nla. Bibeli fihan pe Kristi Jesu yoo ní 144,000 awọn alakooso olubakẹgbẹ. Nitori naa Ijọba Ọlọrun, tabi ijọba-akoso ọrun, ní ninu Kristi Jesu ati 144,000 awọn eniyan tí a mú lati ori ilẹ-aye lọ si ọrun. (Iṣipaya 14:1-4; 5:9, 10) Kinni nipa ti ilẹ-aye? Psalm 45:16 mẹnukan án pe Ọba naa yoo yàn “awọn ọmọ-alade lori ilẹ-aye gbogbo” sípò. “Awọn ọmọ-alade” ẹda-eniyan, tabi awọn alaboojuto ijọba-akoso, ni a ó yànsípò lati ọrun nitori ifọkansin jijinlẹ wọn fun awọn ilana-ipilẹ ododo.—Fiwe Isaiah 32:1.
45, 46. (a) Kinni ẹṣin-ọrọ pataki iwaasu Jesu lori ilẹ-aye? (b) Eeṣe tí a kò fi fidi ijọba-akoso pípé naa mulẹ lẹsẹkẹsẹ? (c) Bawo ni ọdun 1914 C.E. ṣe jẹ́ ọdun titayọ kan ninu asọtẹlẹ ati ninu awọn iṣẹlẹ ayé?
45 Nigba wo ati bawo ni a ṣe fi idi ijọba-akoso pípé naa mulẹ? Nigba tí Jesu wà lori ilẹ-aye Ijọba yii ni ẹṣin-ọrọ pataki iwaasu rẹ̀. (Matthew 4:17; Luke 8:1) Bi ó ti wù ki ó rí, oun kò fidii Ijọba naa mulẹ ní akoko yẹn. Tabi nigba ajinde rẹ̀. (Iṣe 1:6-8) Àní nigba tí ó tún goke rè ọrun lẹẹkeji paapaa, oun ṣì nilati duro sibẹ dè akoko tí Jehofah yànkalẹ̀. (Psalm 110:1, 2; Hebrew 1:13) Asọtẹlẹ Bibeli fihan pe akoko tí a yànkalẹ̀ yẹn dé ní 1914 C.E. Àmọ́ ṣáá o, ẹnikan lè beere pe, ‘Kàkà kí ijọba-akoso pípé wà, kii ha ṣe pe 1914 sami si ibẹrẹ ibisi awọn ègbé ayé?’ Kókó naa gan-an niyẹn! Isopọ timọtimọ wà laarin dídé Ijọba Ọlọrun ati awọn iṣẹlẹ àjálù ti awọn ọdun lọọlọọ, gẹgẹ bi awa yoo ti ríi nisinsinyi.
46 Fun nǹkan bii 35 ọdun ṣaaju 1914, ni Ilé-ìṣọ́nà (iwe-irohin isin tí a npinfunni ní gbàràgàdà-gbaragada julọ ní ayé nisinsinyi) ti ńpè afiyesi sí 1914 gẹgẹ bi ọdun kan tí a sami si ninu asọtẹlẹ Bibeli. Awọn asọtẹlẹ wọnyi bẹrẹsii ní imuṣẹ tí ó pẹtẹrí kan ní 1914. Ọ̀kan ninu iwọnyi ni asọtẹlẹ Jesu paapaa funraarẹ̀, tí ó sọjade ní 1,900 ọdun sẹhin, nipa “ami” naa tí yoo farahan ní opin eto-igbekalẹ awọn nǹkan eyi tí yoo sì jẹriifihan pe oun ti wà níhìn-ín láìṣeéfojúrí pẹlu agbara ọlọ́ba. Ní idahun si ibeere awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nipa “ami,” oun wipe: “Orilẹ-ede yoo dide si orilẹ-ede ati ijọba si ijọba, àìtó ounjẹ yoo sì wà ati awọn ìsẹ̀lẹ̀ ní ibikan tẹle omiran. Gbogbo nǹkan wọnyi jẹ́ ibẹrẹ awọn irora hílàhílo.” (Matthew 24:3, 7, 8, NW) Ninu imuṣẹ tí ńfà afiyesi, ekinni ninu awọn ogun agbaye bẹrẹ ní 1914, tí iparun tí ó bá a rìn pọ̀ pupọ ní ilọpo meje jù apapọ 900 awọn ogun tí ó ti jà ní iwọn bii 2,500 ọdun ṣaaju lọ! Irora hílàhílo sì ti ńbáa nìṣó lati igba naa gan-an. Iwọ ha ti ní iriri iparun ogun, àìtó ounjẹ-jijẹ, tabi eyikeyi ninu awọn ìsẹ̀lẹ̀ nla tí ó ti mú-ìyọnu-àjàkálẹ̀-bá ilẹ-aye lati 1914? Bi ó bá rí bẹẹ iwọ naa jẹ́ ẹlẹrii tí ó fojuri “ami” naa ti “akoko opin” eto-igbekalẹ awọn nǹkan yii.—Daniel 12:4.
47. Bawo ni awọn iṣẹlẹ imuṣẹ “ami” naa ṣe ńpeléke sii ní awọn ọdun lọọlọọ yii?
47 “Awọn irora hílàhílo” naa ti tubọ peleke sii jalẹ Ogun Agbaye Keji, eyi tí iparun rẹ̀ jẹ́ ilọpo mẹrin iparun Ogun Agbaye Kìn-ín-ní, tí ó sì ńbáa nìṣó titi di sanmanni ti bomb atomik, eyi tí ó tubọ jẹ́ imuṣẹ asọtẹlẹ Jesu siwaju sii pe: “Lori ilẹ-aye idaamu awọn orilẹ-ede, láìmọ̀ ọna abajade . . . , nigba tí awọn eniyan yoo maa dákú lati inu ibẹru ati ifojusọna fun awọn ohun tí ńbọ̀ wá sori ilẹ-aye tí a ńgbé.” (Luke 21:25, 26, NW) Ibisi ninu iwa-ọdaran ati iwa-buruku, ninu iwa-aigbọran ati ìyapòkíì laarin awọn ọmọde, ati idagbasoke ninu àìmọ̀ Ọlọrun ati ìwàpálapàla—awọn idagbasoke tí ńmúnitagìrì wọnyi ni a sọtẹlẹ pẹlu gẹgẹ bi ohun tí yoo sami si “awọn ọjọ ikẹhin” ti eto-igbekalẹ ibi yii.—2 Timothy 3:1-5; Matthew 24:12.
48. Tani orisun okunfa awọn ègbé ori ilẹ-aye, eesitiṣe tí wọn fi ńpọ̀ sii lati 1914?
48 Àmọ́ ṣáá o, bi a bá ti fi idi ijọba-akoso ti ọrun naa mulẹ ní 1914, eeṣe tí ọpọlọpọ idaamu wọnyi fi dé si ilẹ-aye? Satan Eṣu orisun okunfa rẹ̀. Nigba tí Kristi gbà agbara Ijọba, igbesẹ tí ó kọ́kọ́ gbé ni lati gbogunti Satan ninu ọrun nibi tí a kò lè fojuri. Ní iyọrisi rẹ̀, Satan, “tí ńṣì gbogbo ilẹ-aye tí a ńgbé lọ́nà,” wá di ẹni tí a fi sọ̀kò si sàkáání ilẹ-aye pẹlu awọn angeli rẹ̀. Ní mímọ̀ pe iparun oun nsunmọle, oun ńdá ìjọ̀ngbọ̀n nlanla silẹ lori ilẹ-aye. “Ègbé ni fun ilẹ-aye ati fun òkun, nitori pe Eṣu ti sọkalẹ tọ̀ yin wá, ó ní ibinu nla, ní mímọ̀ pe igba akoko kukuru ni oun ní.”—Iṣipaya 12:7-9, 12, NW.
49. (a) Kinni yoo ṣẹlẹ si awọn wọnni tí wọn ‘npa ilẹ-aye run’? (b) Bawo ni Jehofah yoo ṣe mú ‘ipinnu idajọ’ ìfìyà-ikú-jẹni rẹ̀ wá sori awọn orilẹ-ede?
49 Opin yoo ha dé si awọn ègbé wọnyi bi? Bẹẹni!—nigba tí ijọba-akoso ọrun funraarẹ̀, Ijọba Ọlọrun Olodumare, bá bẹrẹ ogun lati “run awọn tí npa ayé run.” (Iṣipaya 11:18; Daniel 2:44) Ki yoo tún ṣẹlẹ mọ́ lae pe Ọlọrun yọnda awọn agbara eto iṣẹlu, awọn eke Kristian, tabi ẹni yowu ki ó jẹ́ miiran lati pa iṣẹ-ọwọ rẹ̀, ilẹ-aye run, pẹlu ìpète-ẹ̀rọ bomb atomik wọn. Kàkà bẹẹ, oun polongo pe: “Ipinnu mi ni lati kó awọn orilẹ-ede jọ, ki emi ki ó lè kó awọn ilẹ-ọba jọ, lati dà ìrunú mi si ori wọn, àní gbogbo ibinu mi gbigbona: nitori a ó fi iná owú mi jẹ gbogbo ayé run.” (Zephaniah 3:8) Jehofah, nipasẹ Kristi rẹ̀, yoo lò ipa nla tí oun ńṣèkáwọ́ ninu agbaye lati mú iparun tí nbonimọlẹ wá sori gbogbo awọn tí ntẹle Satan lori ilẹ-aye. Eyi yoo jẹ́ lọna tí ó kárí ilẹ-aye, tí ó farajọ Ikun-omi ọjọ Noah ní titobi.—Jeremiah 25:31-34; 2 Peter 3:5-7, 10.
50. (a) Kinni “Armageddon”? (b) Kìkì awọn wo ni yoo là Armageddon já?
50 Ninu Bibeli iparun awọn orilẹ-ede buruku yii ni a pè ní ìjà-ogun Ọlọrun ti Armageddon. (Iṣipaya 16:14-16) Kìkì awọn oninu-tutu eniyan, awọn wọnni tí ńwá-ọ̀nà Jehofah ati ododo, lè là Armageddon já bọ́ sinu eto-igbekalẹ titun alalaafia ti Ọlọrun. (Zephaniah 2:3; Isaiah 26:20, 21) Nipa awọn nǹkan wọnyi ni Bibeli sọ bayii pe: “Ṣugbọn awọn ọlọkantutu ni yoo jogun ayé, wọn yoo sì maa ṣe inudidun ninu ọpọlọpọ alaafia.” (Psalm 37:11) Iṣẹ atobilọla ti mímú Paradise ori ilẹ-aye padabọsipo yoo pilẹṣẹbẹrẹ lẹhin naa!
Imọ-Ẹkọ fun Wíwọ̀ inu Paradise
51. Eeṣe tí ó fi pọndandan fun ọ lati gbégbèésẹ̀ nisinsinyi?
51 Iwọ yoo ha fẹ́ lati maa gbé ninu Paradise bi? Bi idahun rẹ bá jẹ́ ‘Bẹẹni,’ a ó ru imọlara rẹ soke lati mọ̀ pe nigba tí Jesu sọrọ nipa eto-igbekalẹ ode-oni tí ìjọ̀ngbọ̀n débá ati “ami” naa ti isunmọle iparun rẹ̀, oun fikun un pe, “Iran-eniyan yii ki yoo kọja lọ lọnakọna titi gbogbo nǹkan wọnyi yoo fi ṣẹlẹ.” Awọn diẹ, ó kerepin, ninu iran-eniyan naa.tí wọn rí “ibeṛẹ irora hílàhílo” ní 1914 yoo walaaye lati rí imupadabọsipo Paradise lori ilẹ-aye. (Matthew 24:3-8, 34, NW) Bi ó ti wù ki ó rí, ó jẹ́ otitọ-iṣẹlẹ kan tí ó banininujẹ pe awọn eniyan tí ó pọ̀ julọ lonii ni wọn wà ní ọna fífẹ̀ naa tí ó nsinni lọ si iparun. (Matthew 7:13, 14) Iwọnba akoko ni ó ṣẹ́kù fun wọn lati yipada. Bawo ni iwọ ṣe nilati kún fun ọpẹ́ tó pe Jehofah ti pese ikilọ ní akoko! Nitori Jehofah ńfẹ́ ki iwọ ní ìyè, oun yoo ràn ọ lọwọ lati gbé awọn igbesẹ tí ó tọ́.—2 Peter 3:9; Ezekiel 18:23.
52. Kinni ohun tí o nilo ki iwọ lè ṣe yíyàn ọlọgbọn niti ọran isin?
52 Aini rẹ kanjukanju nisinsinyi ni imọ pipeye. (1 Timothy 2:4; John 17:3) Nibo ni iwọ ti lè rí eyi? A ha lè rí i ninu isin eyikeyi bi? Awọn eniyan kan nsọ pe gbogbo isin nsinni lọ si gongo-ilepa kan naa, gẹgẹ bi gbogbo ipa-ọna lori oke kan ti nsinni lọ si téńté rẹ̀. Bawo ni wọn ti ṣe aṣiṣẹ tó! Lati lè rí ipa-ọna tí ó tọ́ naa, awọn tí ńpọ́n oke a maa lò awọn aworan-ilẹ, wọn a sì maa háyà awọn amọ̀nà. Bẹẹ gẹgẹ, isin otitọ kanṣoṣo ní ó wà tí ó lè ṣamọna si ìyè ayeraye, a sì nílò amọ̀nà lati rí i.—Iṣe 8:26-31.
53. (a) Lati jèrè ìyè ainipẹkun, kinni iwọ nilati maa báa lọ lati ṣe? (b) Awọn idanwo wo lati ọ̀dọ̀ Satan ni iwọ yoo nilati bori?
53 Iwe-pẹlẹbẹ yii ni a ti pese lati ọwọ́ awọn Ẹlẹrii Jehofah lati ràn ọ lọwọ. Ṣaaju ná ó ti ràn ọ lọwọ lati loye awọn idi-ipilẹ otitọ Bibeli diẹ, àbí kò ṣe bẹẹ? Laisi aniani iwọ ti fidii rẹ̀ mulẹ ṣinṣin funraarẹ pe koko kọọkan ni a gbeka ori Ọrọ Ọlọrun tí a misi. Nisinsinyi, lati tẹsiwaju si gongo-ilepa rẹ, iwọ nilati maa báa nìṣó lati kẹkọọ. Gẹgẹ bi imọ-ẹkọ ti ayé tí ó tọ́ kan ti pọndandan lati mú ki ẹnikan yẹ fun ibikan ninu ẹgbẹ-oun-ọgba ọjọ́-dé-ọjọ́, bẹẹ gẹgẹ ni imọ-ẹkọ Bibeli tí ó tọsúnà jẹ́ ohun tí ó pọndandan lati mú ẹnikan gbaradì fun wíwọ̀ inu ẹgbẹ-oun-ọgba tí yoo laaja lati maa gbé ninu Paradise ori ilẹ-aye. (2 Timothy 3:16, 17) Satan lè gbiyanju lati pín ọkàn-àyà rẹ níyà nipasẹ ṣiṣokunfa awọn olubakẹgbẹ timọtimọ lati ṣàtakò si ọ tabi nipasẹ dídán ọ wò lati kó sinu ifẹ imọtara-ẹni-nikan ti ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì tabi awọn ọna oníwàpálapàla. Maṣe juwọsilẹ fun Satan. Ipo-aisewu rẹ ati gbogbo ọjọ-ọla rẹ ati ti idile rẹ sinmi lori ikẹkọọ rẹ ninu Bibeli siwaju sii.—Matthew 10:36; 1 John 2:15-17.
54. Awọn ipese siwaju sii wo fun imọ-ẹkọ ni Jehofah ti ṣe ní adugbo rẹ?
54 Ní afikun si bíbá ikẹkọọ Bibeli rẹ ti lọwọlọwọ nìṣó, ọna miiran tún wà lati gbà kẹkọọ. Awọn eniyan tí wọn wà ní adugbo rẹ tí wọn ní ọkàn-ìfẹ́ si imọ-ẹkọ Bibeli a maa pésẹ̀ deedee si awọn ipade Gbọngan Ijọba adugbo. Gbogbo awọn tí wọn ńpésẹ̀ sibẹ ni wọn nṣe bẹẹ lati gbà itọni lati inu Bibeli tí wọn sí nfi pẹlu otitọ-inu gbiyanju lati di awọn eniyan tí ó daraju. Wọn ṣetan lati gbá awọn ẹni titun mọra, ní sisọ pe, “Ẹ wá, [ẹyin eniyan] ẹ jẹ́ ki a lọ si oke [Jehofah, iyẹn ni ibi ijọsin rẹ̀], . . . oun yoo sì kọ́ wa ní ọna rẹ̀, awa yoo sì maa rìn ní ipa-ọna rẹ̀.” (Isaiah 2:3) Awọn idi rere fun pípésẹ̀ si awọn ipade Bibeli ni a ṣalaye ninu Hebrew 10: 24, 25 (NW), eyi tí ó kà pe: “Ẹ sì jẹ́ ki a gbà ti araawa rò lati runisoke si ifẹ ati awọn iṣẹ rere, ki a má maa kọ̀ ipejọpọ araawa silẹ, bii awọn ẹlomiran ti ní àṣà naa, ṣugbọn ki a maa gbà araawa niyanju, paapaa julọ bi ẹyin ti rí ọjọ naa tí nsunmọtosi.”
55. (a) Ní awọn ọna wo ni eto-ajọ Jehofah fi yatọ si awọn miiran? (b) Bawo ni awọn Ẹlẹrii Jehofah ṣe wà ní iṣọkan laini àfiwé ninu awọn eniyan miiran?
55 Bi iwọ ti nkẹgbẹ pẹlu eto-ajọ Jehofah, iwọ yoo ríi pe ipo-ayika naa yatọ gidigidi si ti inu awọn temple ati ṣọọsi. Kò si igbá ẹ̀bẹ̀ fun owó, isọrọ-ẹni-lẹhin tabi ṣiṣe aáwọ̀, kò tún sí ifiyatọsi nitori ipo atẹhinwa tabi ipo iṣunna-owo idile. Animọ-iwa titayọ julọ laarin awọn Ẹlẹrii Jehofah jẹ́ ifẹ. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wọn nifẹẹ Jehofah, ati lẹhin naa, wọn nifẹẹ awọn eniyan miiran. Iwọnyi jẹ́ awọn ami-akiyesi ti awọn Kristian tootọ. (Matthew 22:37-39; John 13:35) Ó yẹ ki o lọ si awọn ipade wọn ki o sì fidi eyiini mulẹ gbọnyingbọnyin funraarẹ̀. Laisi aniani iṣọkan wọn yoo wọ̀ ọ́ lọ́kàn ṣinṣin. Ó jù million mẹta awọn Ẹlẹrii lọ tí ó wà yika ayé ní awọn ilẹ tí ó lé ní 200. Sibẹ, awọn Ẹlẹrii jakejado ilẹ-aye ntẹle awọn itolẹsẹẹsẹ kan naa ní awọn ipade wọn. Ati nitori ọna itẹwe ẹlẹsẹkẹsẹ ní ọpọlọpọ ede, nibi awọn ipade wọn ọsọọsẹ eyi tí ó pọ̀ julọ lara awọn Ẹlẹrii Jehofah jakejado ayé yoo kẹkọọ koko-ẹkọ Iwe-mimọ kan naa laarin awọn wakati diẹ si araawọn. Iṣọkan tí ó wà ninu eto-ajọ Jehofah jẹ́ iṣẹ-iyanu ode-oni kan ninu ayé tí ó pinya yii.
56. (a) Awọn èrè-anfaani wo ni iwọ lè rí gbà lati inu ibakẹgbẹ pẹlu eto-ajọ Jehofah? (b) Nigba tí awọn ọran-iṣoro bá dide, bawo ni iwọ ṣe nilati huwapada?(c) Eeṣe tí ó fi ṣe pataki fun ọ lati ṣe iyasimimọ igbesi-aye rẹ fun Jehofah?
56 Bi iwọ ti nkẹgbẹ deedee pẹlu awọn eniyan Jehofah, yoo jẹ́ ohun tí ó yẹ fun ọ lati fi “akopọ-animọ-iwa titun naa” ṣe aṣọ bora ki o sì mú eso ti ẹmi Ọlọrun dagba—“ifẹ, idunnu-nla, alaafia, ipamọra, inurere, iwarere-iṣẹun, igbagbọ, iwapẹlẹ, ìkóra-ẹni-níjàánu.” (Colossae 3:10, 12-14; Galatia 5:22, 23) Eyi yoo fun ọ ní ẹmi-itẹlọrun jijinlẹ. Iwọ lè ní awọn ọran-iṣoro lati bori lati igba dé igba nitori iwọ ńgbé ninu ayé kan tí ó ti dibajẹ ati pẹlu nitori awọn aipe tirẹ funraarẹ̀. Ṣugbọn Jehofah yoo ràn ọ lọwọ. Ọrọ Rẹ̀ mú un daju fun awọn wọnni tí wọn nfi pẹlu otitọ-inu gbiyanju lati wù ú: “Ẹ maṣe ṣaniyan lori ohunkohun, ṣugbọn ninu ohun gbogbo nipa adura ati adura-ẹ̀bẹ̀ papọ pẹlu idupẹ ẹ jẹ́ ki awọn ibeere-ẹ̀bẹ̀ yin di mímọ̀ fun Ọlọrun; alaafia Ọlọrun tí ó ta gbogbo ironu yọ yoo sì ṣọ́ ọkàn-àyà yin ati agbara ero-ori yin nipasẹ Kristi Jesu.” (Philippi 4:6, 7, NW) A ó fà ọ mọra nipasẹ ifẹ Jehofah, tí iwọ yoo fi fẹ́ lati sìn ín. Awọn Ẹlẹrii Jehofah yoo layọ lati fihan ọ bi iwọ ṣe lè yà igbesi-aye rẹ si mímọ́ fun Ọlọrun onifẹẹ yii, ki o sì di ọ̀kan lara awọn olùyẹ fun anfaani jíjẹ́ ẹlẹrii rẹ̀. (Psalm 104:33; Luke 9:23) Bẹẹni, anfaani kan ni ó jẹ́. Wulẹ ronu ná! Gẹgẹ bi olujọsin Jehofah, iwọ lè nàgà sí gongo-ilepa ìyè ayeraye ninu paradise níhìn-ín lori ilẹ-aye.—Zephaniah 2:3; Isaiah 25:6, 8.
57. (a) Ninu eto-igbekalẹ titun, ipo-ibatan timọtimọ wo ni yoo wà laarin Ọlọrun ati araye? (b) Kinni diẹ lara awọn ibukun tí iwọ yoo gbadun nigba naa?
57 Maa báa nìṣó, nigba naa, lati kẹkọọ ki o sì maa dagba ninu ifẹ ati imọriri fun Jehofah Ọlọrun, Ọmọkunrin rẹ̀, ati ijọba-akoso ododo ti ọrun. Ní ṣiṣapejuwe ijọba-akoso Ọlọrun ati awọn ibukun tí oun yoo rọ̀jò rẹ̀ si ori araye, asọtẹlẹ Bibeli naa sọ pe: “Wò ó! àgọ́ Ọlọrun wà pẹlu araye, oun yoo sì maa bá wọn gbé, wọn yoo sì jẹ́ eniyan rẹ̀. Ọlọrun funraarẹ̀ yoo sì wà pẹlu wọn.” “Ọlọrun funraarẹ̀,” ẹni tí a gbega fiofio rekọja iṣakoso eniyan oniparun-bajẹ, onimọtara-ẹni-nikan ti ode-oni yii, ni yoo sunmọ wa pẹ́kípẹ́kí gẹgẹ bi Baba oninuure kan si gbogbo awọn wọnni tí wọn nifẹẹ rẹ̀ tí wọn sì njọsin in ninu eto-igbekalẹ titun yẹn. Dajudaju, isin kanṣoṣo péré ni yoo wà, ijọsin tootọ ti Jehofah Ọlọrun, tí awọn olujọsin rẹ̀ yoo sì gbadun ipo-ibatan oníbàárẹ́-tímọ́tímọ́ bi awọn ọmọ si Baba. Iru Baba onifẹẹ wo ni yoo fi araarẹ̀ hàn pe oun jẹ́ fun wọn! “Oun yoo sì nù omije gbogbo nù kuro ní oju-iriran wọn, iku ki yoo sì sí mọ́, bẹẹ ni ọ̀fọ̀ tabi igbe tabi irora ki yoo sí mọ́. Awọn ohun atijọ ti kọja lọ.”—Iṣipaya 21:3, 4, NW.
58. Eeṣe tí iwọ fi lè ní idaniloju pe Jehofah yoo ‘sọ ohun gbogbo di ọ̀tun’?
58 Bayii ni iṣẹ-iyanu nla naa ti fifi idi paradise ilẹ-aye mulẹ labẹ ijọba-akoso pípé ti ọrun yoo di eyi tí a ṣe aṣepari rẹ̀. Ó daju hán-ún-hán-ún gẹgẹ bi oòrùn tí yoo ràn tí yoo sì wọ̀ ní ọ̀la. Nitori awọn ileri Jehofah Ọlọrun, Ẹlẹdaa ọrun oun ilẹ-aye, naa jẹ́ “ododo ati otitọ” laelae. Oun naa ni ó sì polongo lati ori ìtẹ́ rẹ̀ ni ọrun pe: “Sawo o! emi nsọ ohun gbogbo di ọtun.”—Iṣipaya 21:5.
Ní ṣiṣe atunyẹwo iwe-pẹlẹbẹ yii, bawo ni iwọ yoo ṣe dahun awọn ibeere tí ó tẹle e yii?
Ní awọn ọna wo ni Bibeli gbà tayọ?
Kinni ohun tí o kẹkọọ nipa Ọlọrun?
Tani Kristi Jesu?
Tani Satan Eṣu?
Eeṣe tí Ọlọrun yọọda iwa-buruku?
Eeṣe tí eniyan fi ńkú?
Ipo wo ni awọn òkú wà?
Kinni irapada naa?
Nibo ati bawo ni ajinde yoo ṣe ṣẹlẹ
Kinni Ijọba naa, kinni yoo sì ṣe aṣepari rẹ̀?
Kinni “ami” naa ti “ipari-opin eto-igbekalẹ awọn nǹkan”?
Bawo ni iwọ ṣe lè mura fun ìyè ayeraye ninu Paradise?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Awọn itọkasi Bibeli ní itilẹhin si awọn ìpínrọ̀ oke yii: (1) Iṣe 17:26; Psalm 46:9; Micah 4:3, 4; Isaiah 65:21-23; (2) Isaiah 65:25; 11:6-9; 55:12, 13; Psalm 67:6, 7; (3) Job 33:25; Isaiah 35:5, 6; 33:24; Psalm 104:24; (4) Isaiah 55:11.
b Ayafi bi a bá tọkafihan pe òmíràn ni, awọn ẹsẹ Ìwémímọ́-ìsìn tí a fàyọ ninu itẹjade yii jẹ́ lati inu itumọ Bibeli ti ede Yoruba. Nibi tí a bá ti fi NW hàn tẹle ẹsẹ-iwemimọ-ìsìn kan tí a fàyọ, ó fihan pe a ti tumọ ẹsẹ naa lati inu Bibeli ede Gẹẹsi ti New World Translation of the Holy Scriptures, itẹjade titun ti 1984.
c Iwe Monarchs and Tombs and Peoples—The Dawn of the Orient, oju-iwe 25.
d Cyclopedia of Biblical, Theological, and Ecclesiastical Literature, lati ọwọ J. McClintock ati J. Strong, Idipọ 8, oju-iwe 908.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Gẹgẹ bi iṣẹda kan, eniyan galọla fiofio jù ẹranko lọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jesu dọgba pẹlu Adam ọkunrin pípé naa