KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ WÀÁ GBA Ẹ̀BÙN ỌLỌ́RUN TÓ DÁRA JÙ?
Kí Nìdí Tí Ẹ̀bùn Yìí Fi Ṣe Iyebíye Gan-an?
Kí ló lè mú kí ẹ̀bùn kan ṣeyebíye gan-an sí ẹ? Nǹkan mẹ́rin yìí lè fà á: (1) ẹni tó fún ẹ lẹ́bùn náà, (2) ìdí tó fi fún ẹ, (3) ohun tó yọ̀ǹda láti lè fún ẹ lẹ́bùn náà, àti (4) tí ẹ̀bùn náà bá bọ̀ sí àkókò tí o nílò rẹ̀. Tá a bá ronú lórí nǹkan mẹ́rin yìí, á jẹ́ ká túbọ̀ mọ rírì ìràpadà, ìyẹn ẹ̀bùn Ọlọ́run tó dára jù lọ.
ẸNI TÓ FÚN WA
Àwọn ẹ̀bùn kan máa ń jọ wá lójú torí pé ẹnì kan tó wà nípò àṣẹ tàbí èèyàn pàtàkì kan ló fún wa. Àwọn ẹ̀bùn míì lè má jẹ́ olówó ńlá, àmọ́ a mọyì rẹ̀ torí pé mọ̀lẹ́bí wa kan tàbí ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ ló fún wa. Irú ẹ̀bùn yẹn ni Russell fún Jordan tá a mẹ́nù kan nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú. Báwo ni èyí ṣe kan ẹ̀bùn ìràpadà?
Ìkíní, Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀.” (1 Jòhánù 4:9) Èyí mú kí ẹ̀bùn ìràpadà jẹ́ ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù lọ. Ọlọ́run ni aláṣẹ tó ju gbogbo aláṣẹ lọ. Ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù tiẹ̀ sọ nípa Ọlọ́run pé: “Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 83:18) Kò sẹ́ni gíga míì tó lè fún wa nírú ẹ̀bùn yìí.
Ìkejì, Ọlọ́run ni “Baba wa.” (Aísáyà 63:16) Lọ́nà wo? Òun ló dá wa. Láfikún sí i, ó máa ń bójú tó wa bí bàbá tó mọṣẹ rẹ̀ níṣẹ́ ṣe máa ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀. Nígbà tí Ọlọ́run ń bá àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ láyé ìgbàànì, ó pè wọ́n ní Éfúráímù, ó wá bi wọ́n pé: “Ọmọ àtàtà ha ni Éfúráímù jẹ́ sí mi, tàbí ọmọ tí a hùwà sí lọ́nà ìfẹ́ni? . . . Ìdí nìyẹn tí ìfun mi fi di èyí tí ó ru gùdù fún un. Dájúdájú, èmi yóò ṣe ojú àánú sí i.” (Jeremáyà 31:20) Bí ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní ṣe rí lára rẹ̀ náà nìyẹn. Kì í ṣe pé ó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa nìkan ni, àmọ́ ó tún jẹ́ Bàbá wa àti Ọ̀rẹ́ wa. Fún ìdí yìí, ǹjẹ́ kò yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀bùn èyíkéyìí tó bá fún wa?
ÌDÍ TÓ FI FÚN WA
A máa ń ka àwọn ẹ̀bùn kan sí pàtàkì nítorí pé ìfẹ́ àtọkànwá tí ẹnì náà ní ló mú kó fún wa, kì í ṣe torí pé ó jẹ́ dandan fún un. Ẹni tó bá sì fi tinútinú fúnni ni nǹkan kì í retí pé kí wọ́n sán-an pa dà fún òun.
Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa ló mú kó fún wa ní ọmọ rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Nípa èyí ni a fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn tiwa, nítorí Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde.” Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? “Kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ.” (1 Jòhánù 4:9) Ṣé dandan ni kí Ọlọ́run ṣe bẹ́ẹ̀ ni? Rárá o! “Ìràpadà tí Kristi Jésù san” jẹ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà fi “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” hàn sí wa.—Róòmù 3:24.
Kí nìdí tí ẹ̀bùn Ọlọ́run fi jẹ́ “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí”? Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ṣùgbọ́n Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Róòmù 5:8) Ìfẹ́ tòótọ́ tí Ọlọ́run ní ló mú kó ṣèrànwọ́ fún àwa èèyàn tá a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, tí a ò ní olùrànlọ́wọ́, tá a sì tún jẹ́ aláìlera. A ò ṣiṣẹ́ fún ìfẹ́ yẹn, a ò sì lè san-án pa dà fún Ọlọ́run. Ẹ̀bùn tó fún wa yìí ni ìfẹ́ tó ga jù lọ nínú ìtàn aráyé.
OHUN TÓ YỌ̀ǸDA
Àwọn ẹ̀bùn kan máa ń ṣeyebíye sí wa torí pé ẹni tó fún wa yọ̀ǹda ọ̀pọ̀ nǹkan kó tó lè fún wa. Tí ẹnì kan bá fi tinútinú yọ̀ǹda ohun tó kà sí pàtàkì gan-an fún wa, a máa ń mọyì irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ dáadáa.
Bíbélì sọ pé Ọlọ́run “fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni.” (Jòhánù 3:16) Èyí fi hàn pé ààyò ọmọ ni Jésù jẹ́ fún Ọlọ́run. Ní gbogbo àìmọye ọdún tí Ọlọ́run fi ṣẹ̀dá ayé àtọ̀run, Jésù ṣiṣẹ́ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì di “ẹni tí [Ọlọ́run] ní ìfẹ́ni sí lọ́nà àkànṣe.” (Òwe 8:30) Jésù ni “Ọmọ tí [Ọlọ́run] fẹ́ràn,” ó sì jẹ́ “àwòrán Ọlọ́run tí a kò le rí.” (Kólósè 1:13-15, BMY) Kò tíì sí irú àjọṣe tímọ́tímọ́ báyìí rí láàárín àwọn ẹlòmíì.
Síbẹ̀, Ọlọ́run “kò dá Ọmọ tirẹ̀ pàápàá sí.” (Róòmù 8:32) Ẹni tí Jèhófà fẹ́ràn jù ló fún wa. Kò sí ẹ̀bùn tó ná Ọlọ́run ní ohun tó pọ̀ bí èyí.
ÀKÓKÒ TÍ O NÍLÒ RẸ̀
Àwọn ẹ̀bùn míì máa ń jọ wá lójú torí pé ó bá bọ́ sí àkókò tá a nílò rẹ̀ lójú méjèèjì. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ẹnì kan ń ṣàìsàn tó lè ṣekú pá a tí kò bá rí ìtọ́jú tó yẹ kíákíá, kò sì lówó tó lè fi tọjú ara rẹ̀. Ó dájú pé ó máa mọyì rẹ̀ gan-an tí ẹnì kan bá san owó ìtọ́jú náà! Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
“Gan-an gẹ́gẹ́ bí gbogbo ènìyàn ti ń kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni a ó sọ gbogbo ènìyàn di ààyè nínú Kristi.” (1 Kọ́ríńtì 15:22) Gbogbo wa là ń “kú” torí pé àtọmọdọ́mọ Ádámù ni wá. A ò sì lè gba ara wa lọ́wọ́ àìsàn àti ikú, bákan náà ni a ò lè mú ara wa pa dà bá Ọlọ́run rẹ́ ká sì bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀. Síwájú sí i, torí pé èèyàn lásán ni wá, a ò lè mú ara wa tàbí ẹlòmíì wà ‘láàyè.’ Bíbélì fi hàn pé: “Kò sí ọkùnrin tí o le ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀ padà tàbí san owó ìràpadà fún Ọlọ́run . . . kò sì sí iye owó tó tó fún sísan rẹ̀.” (Sáàmù 49:7, 8, BMY) A nílò ìrànlọ́wọ́ lójú méjèèjì, torí pé a ò lè san owó ìràpadà fún Ọlọ́run. Tá a bá fi dídàá wa, kò sí ohun tá a lè ṣe.
Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, tinútinú ló fi pèsè ìràpadà fún wa, kí ‘gbogbo ènìyàn báa lè di ààyè’ nípasẹ̀ Jésù. Báwo ni ìràpadà ṣe mú ká di ààyè? Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀jẹ̀ Jésù Ọmọ rẹ̀ sì ń wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀.” Èyí fi hàn pé tá a bá nígbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ tí Jésù ta sílẹ̀, Ọlọ́run á dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, àá sì tún ní ìyè àìnípẹ̀kun. (1 Jòhánù 1:7; 5:13) Àǹfààní wo ni ìràpadà máa ṣe fún àwọn èèyàn wa tó ti kú? “Níwọ̀n bí ikú ti wá nípasẹ̀ ènìyàn kan, àjíǹde òkú pẹ̀lú wá nípasẹ̀ ènìyàn kan [Jésù].”—1 Kọ́ríńtì 15:21.a
Ìrúbọ tí Jésù ṣe ni ẹ̀bùn tó dára jù tí Ọlọ́run tó jẹ́ aláṣẹ gíga jù lọ fún wa, ìfẹ́ tó jìnlẹ̀ tó ní sí wa ló mú kó fún wa lẹ́bùn yìí. Jèhófà Ọlọ́run nìkan lẹni tó yọ̀ǹda ohun tó kà sí pàtàkì jù fún wa. Kò sì tíì sí ẹ̀bùn tó bọ́ sí àkókò tá a nílò rẹ̀ gan-an tó dà bí ìràpadà tó gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Dájúdájú, kò sí ẹ̀bùn tá a lè fi wé ẹ̀bùn ìràpadà tó jẹ́ aláìṣeé-ṣàpèjúwe.
a Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa jí awọn òkú dìde, ka orí 7 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, ó sì wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo.