ORÍ 18
Jòhánù Ń Dín Kù, Àmọ́ Jésù Ń Pọ̀ Sí I
MÁTÍÙ 4:12 MÁÀKÙ 6:17-20 LÚÙKÙ 3:19, 20 JÒHÁNÙ 3:22–4:3
ÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN JÉSÙ ṢE ÌRÌBỌMI FÁWỌN ÈÈYÀN
WỌ́N JU JÒHÁNÙ ARINIBỌMI SẸ́WỌ̀N
Lẹ́yìn Àjọyọ̀ Ìrékọjá tí wọ́n ṣe nígbà ìrúwé ọdún 30 S.K., Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kúrò ní Jerúsálẹ́mù. Àmọ́, wọn ò pa dà sílé wọn ní Gálílì ní tààràtà. Jùdíà ni wọ́n lọ, ibẹ̀ ni wọ́n sì ti ṣèrìbọmi fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Ó ti tó nǹkan bí ọdún kan tí Jòhánù Arinibọmi ti ń ṣe irú iṣẹ́ yìí, àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣì wà pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àfonífojì Odò Jọ́dánì ni wọ́n wà.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò ṣèrìbọmi fún ẹnikẹ́ni, àmọ́ ó pàṣẹ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ṣe bẹ́ẹ̀. Lásìkò yìí, ohun kan náà ni Jésù àti Jòhánù ń ṣe, wọ́n ń kọ́ àwọn Júù tó ti ronú pìwà dà ní Òfin Ọlọ́run.—Ìṣe 19:4.
Àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù bẹ̀rẹ̀ sí í jowú, wọ́n sì fi ẹjọ́ Jésù sun Jòhánù pé: “Ọkùnrin [Jésù] tó wà lọ́dọ̀ rẹ . . . ń ṣèrìbọmi fún àwọn èèyàn, gbogbo èèyàn sì ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.” (Jòhánù 3:26) Ṣùgbọ́n Jòhánù ò jowú. Inú ẹ̀ dùn fún àṣeyọrí tí Jésù ṣe, kódà ó fẹ́ kí inú àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun náà dùn. Jòhánù wá rán wọn létí pé: “Ẹ̀yin fúnra yín jẹ́rìí sí i pé mo sọ pé, ‘Èmi kọ́ ni Kristi, àmọ́ a ti rán mi jáde ṣáájú ẹni yẹn.’” Ó wá ṣàlàyé lọ́nà tó máa gbà yé gbogbo wọn, ó ní: “Ẹnikẹ́ni tó bá ni ìyàwó ni ọkọ ìyàwó. Àmọ́ tí ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó bá dúró, tó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, inú rẹ̀ máa dùn gan-an torí ohùn ọkọ ìyàwó. Torí náà, ayọ̀ mi ti kún rẹ́rẹ́.”—Jòhánù 3:28, 29.
Bíi ti ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó yẹn, inú Jòhánù dùn bó ṣe ń fi ojú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ Jésù ní oṣù díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn. Àwọn kan lára wọn di ọmọlẹ́yìn Jésù, wọn ò sì ní pẹ́ di ẹni àmì òróró. Jòhánù tún fẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa tẹ̀ lé Jésù. Kódà, ńṣe ni Jòhánù wá kó lè múra àwọn èèyàn sílẹ̀ de iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristi. Jòhánù ṣàlàyé pé: “Ẹni yẹn gbọ́dọ̀ máa pọ̀ sí i, àmọ́ èmi gbọ́dọ̀ máa dín kù.”—Jòhánù 3:30.
Jòhánù míì tó ti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù tẹ́lẹ̀ wá ṣe àkọsílẹ̀ nípa ibi tí Jésù ti wá àti bó ṣe mú kí ìgbàlà aráyé ṣeé ṣe, ó ní: “Ẹni tó wá láti òkè ga ju gbogbo àwọn yòókù lọ. . . . Baba nífẹ̀ẹ́ Ọmọ, ó sì ti fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀. Ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun; ẹni tó bá ń ṣàìgbọràn sí Ọmọ kò ní rí ìyè, àmọ́ ìbínú Ọlọ́run wà lórí rẹ̀.” (Jòhánù 3:31, 35, 36) Ẹ ò rí i pé òtítọ́ pàtàkì tó yẹ kí gbogbo èèyàn mọ̀ nìyẹn!
Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Jòhánù Arinibọmi sọ pé ojúṣe àti iṣẹ́ òun máa dín kù ni Ọba Hẹ́rọ́dù fi í sẹ́wọ̀n. Hẹ́rọ́dù mú Hẹrodíà tó jẹ́ ìyàwó Fílípì àbúrò rẹ̀, ó sì fi ṣe aya. Nígbà tí Jòhánù tú àṣírí àgbèrè tí Ọba Hẹ́rọ́dù ṣe, inú bí i gan-an ó sì ju Jòhánù sẹ́wọ̀n. Nígbà tí Jésù gbọ́ pé wọ́n ti ju Jòhánù sẹ́wọ̀n, òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kúrò ní Jùdíà, wọ́n sì “lọ sí Gálílì.”—Mátíù 4:12; Máàkù 1:14.