Orí Kẹsàn-án
Agbára Ìrètí Àjíǹde
1. Bí kò bá sí ìrètí àjíǹde, irú ọjọ́ iwájú wo ni ì bá wà fún àwọn òkú?
ṢÉ O láwọn èèyàn tó ti kú? Bí kò bá sí àjíǹde ni, ì bá máà sí ìrètí kankan pé a óò tún padà rí wọn mọ́ láé. Wọn ì bá máà kúrò nípò tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé: “Ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá, . . . nítorí pé kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù [isà òkú], ibi tí ìwọ ń lọ.”—Oníwàásù 9:5, 10.
2. Àgbàyanu ìfojúsọ́nà wo ni àjíǹde mú kó ṣeé ṣe?
2 Nínú àánú rẹ̀, Jèhófà ti ṣí àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ sílẹ̀ fún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó ti kú láti padà wá sí ìyè nípasẹ̀ àjíǹde kí wọ́n sì gbádùn ìyè ayérayé. Èyí túmọ̀ sí pé, o lè ní ìrètí tí ń mọ́kàn yọ̀ náà pé lọ́jọ́ kan, nínú ayé tuntun Ọlọ́run, ìwọ àtàwọn ìbátan rẹ tó ti sùn nínú ikú á tún wà pa pọ̀.—Máàkù 5:35, 41, 42; Ìṣe 9:36-41.
3. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni àjíǹde gbà ṣe pàtàkì fún mímú ète Jèhófà ṣẹ? (b) Ìgbà wo ní pàtàkì ni ìrètí àjíǹde máa ń jẹ́ orísun okun fún wa?
3 Nítorí pé àjíǹde wà, kò sídìí tó fi yẹ ká máa gbọ̀n jìnnìjìnnì nítorí ikú. Jèhófà lè gba Sátánì láyè láti pa gbogbo itú ọwọ́ rẹ̀ lórí àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ òun bó ṣe ń gbìyànjú láti ti ẹ̀sùn burúkú tó fi kan Ọlọ́run lẹ́yìn pé, “ohun gbogbo tí ènìyàn bá ní ni yóò fi fúnni nítorí ọkàn rẹ̀.” Síbẹ̀ Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí ìpalára tó máa wà títí lọ gbére ṣẹlẹ̀ sí wọn. (Jóòbù 2:4) Nítorí pé Jésù ṣe olóòótọ́ sí Ọlọ́run títí dé ojú ikú ni Ọlọ́run ṣe jí i dìde sí ìwàláàyè ti ọ̀run. Fún ìdí yìí, ó ṣeé ṣe fún Jésù láti gbé ìtóye ẹbọ ẹ̀dá ènìyàn pípé rẹ̀ kalẹ̀ níwájú ìtẹ́ Bàbá rẹ̀ ní ọ̀run, èyí tó máa ṣiṣẹ́ fún ìgbàlà ẹ̀mí wa. Níwọ̀n bí àwọn tí wọn jẹ́ ara “agbo kékeré” ti jẹ́ ajogún pẹ̀lú Kristi, wọ́n ní ìrètí wíwà pẹ̀lú rẹ̀ nínú Ìjọba ọ̀run nípasẹ̀ àjíǹde. (Lúùkù 12:32) Ní ti àwọn èèyàn tó kù, àjíǹde sí ìwàláàyè ayérayé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé ni ìrètí tiwọn. (Sáàmù 37:11, 29) Gbogbo àwọn Kristẹni ló mọ̀ pé orísun okun “tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” ni ìrètí àjíǹde jẹ́ nígbà tí wọ́n bá ń kojú àwọn ìdánwò tó lè yọrí sí ikú.—2 Kọ́ríńtì 4:7.
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì fún Ìgbàgbọ́ Kristẹni
4. (a) Ọ̀nà wo ni àjíǹde gbà jẹ́ “àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́”? (b) Kí ni àjíǹde túmọ̀ sí fún aráyé lápapọ̀?
4 Gẹ́gẹ́ bí ìwé Hébérù 6:1, 2 ṣe sọ, “àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́” ni àjíǹde jẹ́. Ó wà lára ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ tó jẹ́ pé bí a ò bá ní in, a ò lè di Kristẹni tó dàgbà dénú. (1 Kọ́ríńtì 15:16-19) Síbẹ̀, ẹ̀kọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni nípa àjíǹde yàtọ̀ pátápátá sí èrò gbogbo aráyé lápapọ̀. Nítorí pé wọn kì í ṣe ẹni tẹ̀mí, ńṣe ni àwọn èèyàn tó ń wo ìwàláàyè yìí bíi pé òun nìkan ni ìwàláàyè téèyàn ní túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Ìdí nìyẹn tó jẹ́ pé ìgbádùn ni wọ́n ń fi gbogbo ìgbésí ayé wọn wá kiri. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan wà tó jẹ́ pé àwọn ìsìn àbáláyé ni wọ́n gbà gbọ́. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kún inú ìsìn Kristẹni aláfẹnujẹ́ àtàwọn ìsìn míì, ìyẹn àwọn tó gbà pé nǹkan kan wà nínú èèyàn tí kì í kú. Àmọ́, ìgbàgbọ́ yẹn kò bá ẹ̀kọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni nípa àjíǹde mu, níwọ̀n bí àjíǹde kò ti ní í wúlò bó bá jẹ́ pé èèyàn ní ọkàn tí kò lè kú. Ńṣe ni gbígbìyànjú láti mú àwọn ẹ̀kọ́ yìí bára mu túbọ̀ máa ń dani lọ́kàn rú dípò kó fúnni nírètí. Báwo la ṣe lè ran àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n fẹ́ mọ òtítọ́ lọ́wọ́?
5. (a) Kí ẹnì kan tó lè mọyì àjíǹde, kí ló yẹ kó mọ̀? (b) Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni wàá lò láti fi ṣàlàyé ọkàn? ipò tí àwọn òkú wà? (d) Kí lo lè ṣe bó bá dà bíi pé ìtumọ̀ Bíbélì tí ẹnì kan ń lò kò jẹ́ kí òtítọ́ hàn kedere?
5 Kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tó lè lóye pé ìṣètò tí kò lẹ́gbẹ́ ni àjíǹde jẹ́, ohun tí ọkàn jẹ́ àti ipò táwọn òkú wà gbọ́dọ̀ yé wọn yékéyéké. Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ díẹ̀ ti tó láti mú kí kókó yìí ṣe kedere sí ẹnì kan tí ebi òtítọ́ Bíbélì ń pa. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7; Sáàmù 146:3, 4; Ísíkíẹ́lì 18:4) Àmọ́ o, àwọn ìtumọ̀ Bíbélì òde òní kan àtàwọn tí wọ́n ti tún ọ̀rọ̀ inú wọn kọ kò jẹ́ kí ohun tí ọkàn jẹ́ fara hàn kedere. Nípa bẹ́ẹ̀ ó lè pọn dandan láti ṣàyẹ̀wò àwọn gbólóhùn tí wọ́n lò nínú èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì níbẹ̀rẹ̀.
6. Báwo lo ṣe lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti mọ ohun tí ọkàn jẹ́?
6 Ìtumọ̀ Ayé Tuntun wúlò gan-an fún ṣíṣe èyí nítorí pé látòkèdélẹ̀, ó lo ọ̀rọ̀ Hébérù náà neʹphesh, àti ti Gíríìkì tó bá a mu náà psy·khe, fún “ọkàn.” Nínú àsomọ́ tó wà lẹ́yìn ìtumọ̀ Bíbélì yìí, a lè rí ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ níbi táwọn ọ̀rọ̀ yìí ti fara hàn. Ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn ni kò pe ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà ní “ọkàn” látìbẹ̀rẹ̀ dópin, àmọ́ wọ́n lè pe ọ̀rọ̀ yìí kan náà ní “ẹ̀dá,” “ẹni ààyè,” “ẹnì kan,” àti “ìwàláàyè.” Wọ́n lè lo “èmi” fún “neʹphesh mi,” àti “ìwọ” fún “neʹphesh rẹ.” Fífi àwọn ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn wéra pẹ̀lú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun yóò ran akẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ́ mọ òtítọ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ pé àti èèyàn àti ẹranko ni àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò níbẹ̀rẹ̀ fún “ọkàn” ń tọ́ka sí. Àmọ́ kò sígbà kankan tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ohun kan tí kò ṣeé fojú rí, tí kò ṣeé dì mú, tó máa ń jáde nínú ara nígbà ikú tá á sì wá lọ máa gbé níbòmíràn.
7. Báwo ni wàá ṣe fi Bíbélì ṣàlàyé ipò àwọn tó wà nínú Ṣíọ́ọ̀lù? nínú Hédíìsì? nínú Gẹ̀hẹ́nà?
7 Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tún bára mu látòkèdélẹ̀ nípa lílo ọ̀rọ̀ náà “Ṣìọ́ọ̀lù” fún ọ̀rọ̀ Hébérù náà sheʼohl, àti “Hédíìsì” fún ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà haiʹdes, ó sì tún lo “Gẹ̀hẹ́nà” fún ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, geʹen·na. Nǹkan kan náà ni “Ṣìọ́ọ̀lù” àti “Hédíìsì” túmọ̀ sí. (Sáàmù 16:10; Ìṣe 2:27) Bíbélì mú un ṣe kedere pé isà òkú gbogbo aráyé ni Ṣìọ́ọ̀lù àti Hédíìsì ń tọ́ka sí, ọ̀ràn ikú ló tan mọ́ kì í ṣe ọ̀ràn ìwàláàyè. (Sáàmù 89:48; Ìṣípayá 20:13) Ìwé Mímọ́ tún jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣeé ṣe láti padà wá látinú isà òkú nípasẹ̀ àjíǹde. (Jóòbù 14:13; Ìṣe 2:31) Ní ìdàkejì sí èyí, kò sí ìrètí ìwàláàyè ọjọ́ iwájú kankan fún àwọn tó lọ sí Gẹ̀hẹ́nà, bẹ́ẹ̀ ni a ò sì sọ ọ́ níbì kankan rí pé ọkàn máa ń wà láàyè níbẹ̀.—Mátíù 10:28.
8. Báwo ni lílóye àjíǹde ní kíkún ṣe lè nípa lórí ìwà àti ìṣesí ẹnì kan?
8 Lẹ́yìn tá a bá ti ṣàlàyé àwọn ọ̀ràn yìí lọ́nà tó máa gbà yé ẹnì kan, a lè ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ràn án lọ́wọ́ láti lóye bí àjíǹde ṣe lè ṣàǹfààní fún un. Ó lè wá bẹ̀rẹ̀ sí í mọrírì ìfẹ́ tí Jèhófà ní, èyí tó mú un ṣe irú ètò aláìlẹ́gbẹ́ bẹ́ẹ̀. Ìbànújẹ́ tó ń dorí àwọn tí èèyàn wọn kú kodò lè dín kù bí wọ́n ti ń fi tayọ̀tayọ̀ fojú sọ́nà láti tún wà pẹ̀lú àwọn èèyàn wọn nínú ayé tuntun Ọlọ́run. Lílóye àwọn kókó yìí ṣe pàtàkì gan-an ká tó lè lóye ohun tí ikú Kristi túmọ̀ sí. Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní mọ̀ pé, òpómúléró ni àjíǹde Jésù Kristi jẹ́ fún ìgbàgbọ́ Kristẹni, pé òun ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àjíǹde àwọn mìíràn. Tìtaratìtara ni wọ́n fi wàásù àjíǹde Jésù àti ìrètí tó ń fúnni. Bákan náà ló rí lónìí, àwọn tó lóye àjíǹde tí wọ́n sì mọrírì rẹ̀ máa ń hára gàgà láti jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn mọ̀ nípa òtítọ́ ṣíṣeyebíye yìí.—Ìṣe 5:30-32; 10:42, 43.
Lílo ‘Kọ́kọ́rọ́ Hédíìsì’
9. Báwo ni Jésù ṣe kọ́kọ́ lo “kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti Hédíìsì”?
9 Gbogbo àwọn tó máa wà pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba rẹ̀ ọ̀run ló máa kú bópẹ́ bóyá. Àmọ́ ẹ̀rí ìdánilójú tó fún wọn yé wọn yékéyéké nígbà tó sọ pé: “Mo . . . ti di òkú tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n, wò ó! mo wà láàyè títí láé àti láéláé, mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti Hédíìsì lọ́wọ́.” (Ìṣí. 1:18) Kí ló ní lọ́kàn? Ó ń sọ nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí òun fúnra rẹ̀. Ó ti kú rí. Àmọ́ Ọlọ́run kò fi í sílẹ̀ sínú Hédíìsì. Ní ọjọ́ kẹta, Jèhófà fúnra rẹ̀ jí i dìde sí ìyè ti ẹ̀mí ó sì gbé àìleèkú wọ̀ ọ́. (Ìṣe 2:32, 33; 10:40) Ní àfikún sí ìyẹn, Ọlọ́run fún un ní “kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti Hédíìsì” láti dá àwọn òkú mìíràn sílẹ̀ kúrò nínú isà òkú aráyé àti kúrò lọ́wọ́ àwọn ìyọrísí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù. Nítorí pé Jésù ní àwọn kọ́kọ́rọ́ wọ̀nyẹn lọ́wọ́, ó ṣeé ṣe fún un láti jí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́ dìde kúrò nínú òkú. Àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ara ìjọ rẹ̀ ló kọ́kọ́ jí dìde, ó sì fún wọn ní ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye ti ìyè àìleèkú ní ọ̀run, bí Bàbá rẹ̀ ṣe fún un.—Róòmù 6:5; Fílípì 3:20, 21.
10. Ìgbà wo ni àjíǹde àwọn Kristẹni olóòótọ́ tá a fẹ̀mí yàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀?
10 Ìgbà wo ni àwọn Kristẹni olóòótọ́ tá a fẹ̀mí yàn yóò bẹ̀rẹ̀ sí í gba àjíǹde ti ọ̀run yẹn? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ó ti bẹ̀rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé ‘ìgbà wíwàníhìn-ín Jésù’ la máa jí wọn dìde, ọdún 1914 sì ni èyí bẹ̀rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 15:23) Bí àwọn olóòótọ́ tá a fẹ̀mí yàn bá ṣe ń kú lákòókò wíwàníhìn-ín rẹ̀ yìí, wọ́n ò ṣẹ̀ṣẹ̀ nílò láti wà nínú ikú títí di àkókò ìpadàbọ̀ Olúwa wọn. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n bá ti ń kú báyìí ni à ń jí wọn dìde ní ẹni ẹ̀mí, wọ́n ń di ẹni táá ‘yí padà, ní ìṣẹ́jú kan, ní ìpajúpẹ́.’ Ayọ̀ wọn mà pọ̀ jọjọ o, níwọ̀n bí iṣẹ́ rere tí wọ́n ṣe ti “ń bá wọn lọ ní tààràtà”!—1 Kọ́ríńtì 15:51, 52; Ìṣípayá 14:13.
11. Irú àjíǹde wo ló máa wà fún gbogbo èèyàn lápapọ̀, ìgbà wo ló sì máa bẹ̀rẹ̀?
11 Àmọ́ ṣá, àjíǹde àwọn ajogún Ìjọba sí ọ̀run nìkan kọ́ ni àjíǹde tó máa ṣẹlẹ̀ o. Pípè tá a pè é ní “àjíǹde èkíní” nínú Ìṣípayá 20:6 fi hàn pé àjíǹde mìíràn gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé e. Àwọn tó bá jàǹfààní látinú àjíǹde tó kẹ́yìn yìí yóò ní ìrètí aláyọ̀ ti wíwàláàyè títí lọ gbére nínú Párádísè ilẹ̀ ayé. Ìgbà wo nìyẹn máa ṣẹlẹ̀? Ìwé Ìṣípayá jẹ́ ká mọ̀ pé yóò jẹ́ lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá ti mú “ilẹ̀ ayé àti ọ̀run” kúrò, ìyẹn ètò àwọn nǹkan búburú ti ìsinsìnyí, tòun ti àwọn alákòóso rẹ̀. Òpin tó ń bọ̀ sórí ètò àwọn nǹkan ògbólógbòó yìí ti sún mọ́lé gan-an. Lẹ́yìn èyí, lákòókò tí Ọlọ́run ti yàn, ni àjíǹde ti orí ilẹ̀ ayé á wá bẹ̀rẹ̀.—Ìṣípayá 20:11, 12.
12. Àwọn wo ni yóò wà lára àwọn olóòótọ́ tí a óò jí dìde sí ìyè lórí ilẹ̀ ayé, kí ló sí mú kí ìyẹn jẹ́ ohun àgbàyanu láti máa wọ̀nà fún?
12 Àwọn wo ló máa wà lára àwọn tá a máa jí dìde sí ilẹ̀ ayé? Àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà láti ìgbà ìjímìjí máa wà lára wọn. Ìyẹn àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tí ìgbàgbọ́ wọn nínú àjíǹde múná débi pé “wọn kò jẹ́ tẹ́wọ́ gba ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà kankan.” Èyí túmọ̀ sí pé, wọn ò juwọ́ sílẹ̀ nínú ìṣòtítọ́ wọn sí Ọlọ́run nítorí kí wọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ ikú oró, ikú àìtọ́jọ́. Ẹ ò rí i pé nǹkan ìdùnnú gbáà ló máa jẹ́ fún wa láti rí wọn lójúkojú ká sì gbọ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé látẹnu àwọn fúnra wọn nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu bà lóréfèé! Àwọn mìíràn tí Ọlọ́run yóò tún jí dìde sí ìwàláàyè orí ilẹ̀ ayé ni Ébẹ́lì, ẹlẹ́rìí adúróṣinṣin àkọ́kọ́ fún Jèhófà; Énọ́kù àti Nóà, tí wọ́n kéde ìkìlọ̀ Ọlọ́run láìbẹ̀rù ṣáájú Àkúnya Omi; Ábúráhámù àti Sárà, tí wọ́n ṣe àwọn áńgẹ́lì lálejò; Mósè ẹni tí Ọlọ́run ti ipasẹ̀ rẹ̀ fúnni ní Òfin náà lórí Òkè Sínáì. Àwọn wòlíì onígboyà bíi Jeremáyà, tí ìparun Jerúsálẹ́mù ṣojú rẹ̀ ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa; àti Jòhánù Oníbatisí, tó gbọ́ nígbà tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ pe Jésù ní Ọmọ Òun. Ní àfikún sí àwọn yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn adúróṣinṣin lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n kú láwọn ọjọ́ ikẹyìn ti ètò àwọn nǹkan búburú yìí yóò tún jí dìde.—Hébérù 11:4-38; Mátíù 11:11.
13, 14. (a) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Hédíìsì àtàwọn òkú inú rẹ̀? (b) Àwọn wo ni yóò wà lára àwọn tí a óò jí dìde, fún ìdí wo sì ni?
13 Bí àkókò ti ń lọ, a óò tún jí àwọn mìíràn yàtọ̀ sáwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run dìde, tí ẹnì kankan kò sì ní í ṣẹ́ kù sínú isà òkú aráyé. Bí iye àwọn òkú tó máa jáde wá látinú isà òkú yẹn ṣe máa pọ̀ tó ni a lè rí nínú ọ̀nà tí Jésù máa gbà lo ‘kọ́kọ́rọ́ Hédíìsì’ náà fún aráyé. Èyí hàn nínú ìran kan tá a fi han àpọ́sítélì Jòhánù, níbi tó ti rí i tá a fi Hédíìsì “sọ̀kò sínú adágún iná.” (Ìṣípayá 20:14) Kì lèyí túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé a pa Hédíìsì, isà òkú aráyé run yán-ányán-án. Kò ní í sí mọ́, a óò sọ ọ́ di òfìfo, òkú kankan kò ní sí nínú rẹ̀ mọ́. Ìdí ni pé, yàtọ̀ sí pé Jésù yóò jí gbogbo àwọn olóòótọ́ olùjọ́sìn Jèhófà dìde, nínú àánú rẹ̀, yóò tún mú àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ padà sí ìyè. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Ìṣe 24:15.
14 A kò jí ọ̀kankan nínú àwọn aláìṣòdodo yìí dìde láti tún dá wọn lẹ́bi ikú padà. Níwọ̀n bí òdodo yóò ti gbilẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, ńṣe la máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mú ìgbésí ayé wọn bá àwọn ọ̀nà Jèhófà mu. Ìran náà fi hàn pé a óò ṣí “àkájọ ìwé ìyè” sílẹ̀. Nítorí náà, wọ́n á ní àǹfààní láti jẹ́ kí orúkọ wọn di èyí tá a kọ sínú rẹ̀. A ó “ṣèdájọ́ wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn” èyí tí wọ́n ṣe lẹ́yìn àjíǹde wọn. (Ìṣípayá 20:12, 13) Nípa bẹ́ẹ̀, tá a bá fojú ohun tó máa jẹ́ àbájáde ìkẹyìn wò ó, “àjíǹde ìyè” ni àjíǹde wọn máa jẹ́, kò ní jẹ́ “àjíǹde [ìdálẹ́bi] ìdájọ́” rárá.—Jòhánù 5:28, 29.
15. (a) Àwọn wo ni a kò ní jí dìde? (b) Báwo ló ṣe yẹ kí ìmọ̀ tòótọ́ tá a ní nípa àjíǹde máa sún wa hùwà?
15 Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo àwọn tó ti gbé ayé rí tí wọ́n sì ti kú la máa jí dìde o. Àwọn kan dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò sí nínú Hédíìsì, inú Gẹ̀hẹ́nà ni wọ́n wà, níbi tí wọ́n ti wà nínú ìparun ayérayé. Àwọn mìíràn tí yóò tún wà lára àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí Ọlọ́run máa pa run nígbà “ìpọ́njú ńlá,” èyí tó ti sún mọ́lé báyìí. (Mátíù 12:31, 32; 23:33; 24:21, 22; 25:41, 46; 2 Tẹsalóníkà 1:6-9) Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà fi àánú àrà ọ̀tọ̀ hàn nípa dídá àwọn òkú sílẹ̀ kúrò nínú Hédíìsì, ìrètí àjíǹde kò sọ pé ká wá máa gbé ìgbésí ayé wa bó ṣe wù wá. Kò ní sí àjíǹde kankan fún àwọn tó bá mọ̀ọ́mọ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ. Ńṣe ló yẹ kí ìmọ̀ yìí sún wa láti fi hàn pé a mọrírì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run gan-an, nípa gbígbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu.
Ìrètí Àjíǹde Ń fún Wa Lókun
16. Báwo ni ìrètí àjíǹde ṣe lè jẹ́ orísun okun ńlá?
16 Àwa tí ìgbàgbọ́ wa nínú ìrètí àjíǹde dúró sán-ún lè rí okun ńlá nínú rẹ̀. Lákòókò tá a wà yìí, tí ọjọ́ ogbó bá ti ń dé, a mọ̀ pé ìgbàkigbà ni ikú lè dé—láìka irú ìtọ́jú tá a lè máa gbà sí. (Oníwàásù 8:8) Tá a bá ti fi ìdúróṣinṣin sin Jèhófà pẹ̀lú ètò àjọ rẹ̀, a lè máa wo ọjọ́ iwájú pẹ̀lú ìgbọ́kànlé kíkún. A mọ̀ pé nípasẹ̀ àjíǹde, àá tún padà gbádùn ìgbésí ayé lẹ́ẹ̀kan sí i nígbà tí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run. Ìgbésí ayé gidi nìyẹn á mà jẹ́ o! “Ìyè tòótọ́” ni, gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe pè é.—1 Tímótì 6:19; Hébérù 6:10-12.
17. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá a lọ ní jíjẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà?
17 Mímọ̀ pé àjíǹde wà àti mímọ Ẹni tó jẹ́ orísun rẹ̀ ń jẹ́ ká di alágbára nínú ìgbàgbọ́. Èyí ń fún wa lókun láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run kódà bí àwọn tó ń ṣe inúnibíni kíkorò sí wa tilẹ̀ ń fi ikú dẹ́rù bà wá. Ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti ń fi ìbẹ̀rù ikú àìtọ́jọ́ de àwọn èèyàn nígbèkùn. Àmọ́ Jésù kò ní irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ rárá. Ó ṣe olóòótọ́ sí Jèhófà títí dé ojú ikú. Jésù tipasẹ̀ ẹbọ ìràpadà rẹ̀ pèsè ọ̀nà láti sọ àwọn ẹlòmíràn di òmìnira kúrò nínú irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀.—Hébérù 2:14, 15.
18. Kí ló ti ran àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́wọ́ láti ní àkọsílẹ̀ tó dára gan-an fún jíjẹ́ olùpàwàtítọ́mọ́?
18 Nítorí ìgbàgbọ́ táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní nínú ìpèsè ẹbọ ìràpadà Kristi àti nínú àjíǹde, wọ́n ti ní àkọsílẹ̀ tó dára gan-an pé wọ́n jẹ́ olùpàwàtítọ́mọ́. Nígbà tí wọ́n bá bára wọn nínú ìṣòro, wọ́n ti fi hàn pé àwọn ‘kò nífẹ̀ẹ́ ọkàn àwọn’ ju báwọn ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lọ. (Ìṣípayá 12:11) Wọ́n jẹ́ ọlọgbọ́n ní ti pé, wọn kì í fọwọ́ rọ́ àwọn ìlànà Kristẹni sẹ́yìn nítorí àtidá ìwàláàyè wọn ìsinsìnyí sí. (Lúùkù 9:24, 25) Wọ́n mọ̀ pé bí àwọ́n tilẹ̀ pàdánù ìwàláàyè àwọn ìsinsìnyí nítorí pé àwọ́n ń fi ìdúróṣinṣin rọ̀ mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, yóò san èrè fáwọn nípa jíjí àwọn dìde. Ṣé o ní irú ìgbàgbọ́ yẹn? O lè ní in tó o bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lóòótọ́ tó o sì mọrírì ohun tí ìrètí àjíǹde túmọ̀ sí.
Ìjíròrò fún Àtúnyẹ̀wò
• Ìdí wo lẹ́nì kan fi gbọ́dọ̀ mọ ohun tí ọkàn jẹ́, kí ó sì lóye ipò táwọn òkú wà, kó tó ó lè ní ìmọrírì fún àjíǹde?
• Àwọn wo ni a óò jí dìde kúrò nínú òkú, báwo ló sì ṣe yẹ kí èyí máa sún wa hùwà?
• Ọ̀nà wo ni ìrètí àjíǹde ń gbà fún wa lókun?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwés 84, 85]
Jèhófà ṣèlérí pé àjíǹde àwọn olódodo àtàwọn aláìṣòdodo yóò wà