Ẹ̀KỌ́ 16
Kí Ni Jésù Ṣe Nígbà Tó Wà Láyé?
Táwọn kan bá gbọ́ orúkọ náà Jésù, ohun tó máa ń wá sí wọn lọ́kàn ni ọmọ ọwọ́ tó wà ní ibùjẹ ẹran, àwọn kan gbà pé wòlíì ọlọ́gbọ́n ni, nígbà táwọn míì ń wò ó bí ọkùnrin kan tó ń kú lọ lórí òpó igi. Àmọ́, ṣé a lè túbọ̀ mọ Jésù tá a bá fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó ṣe gbe ìgbésí ayé rẹ̀ nígbà tó wà láyé? Nínú ẹ̀kọ́ yìí, a máa sọ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù lọ tí Jésù ṣe àti bí wọ́n ṣe lè ṣe ẹ́ láǹfààní.
1. Iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ wo ni Jésù ṣe?
Iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tí Jésù ṣe ni pé ó “kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.” (Ka Lúùkù 4:43.) Ìhìn rere tí Jésù wàásù ni pé Ọlọ́run máa gbé ìjọba tàbí àkóso kan kalẹ̀ tó máa yanjú gbogbo ìṣòro aráyé.a Ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ ni Jésù fi ṣiṣẹ́ kára, tó sì ń wàásù ìhìn rere náà fáwọn èèyàn.—Mátíù 9:35.
2. Kí nìdí tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ ìyanu?
Bíbélì sọ ọ̀pọ̀ “àwọn iṣẹ́ agbára àti àwọn ohun ìyanu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ àmì tí Ọlọ́run ṣe nípasẹ̀ [Jésù].” (Ìṣe 2:22) Agbára Ọlọ́run ni Jésù fi kápá ìjì àti òkun tó ń ru gùdù, agbára yẹn kan náà ló fi bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn, tó fi wo àwọn èèyàn sàn, tó sì tún fi jí àwọn òkú dìde. (Mátíù 8:23-27; 14:15-21; Máàkù 6:56; Lúùkù 7:11-17) Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run ló rán an. Àwọn iṣẹ́ ìyanu náà tún fi hàn pé Jèhófà ní agbára láti yanjú gbogbo ìṣòro wa.
3. Kí la rí kọ́ nínú ìgbé ayé Jésù?
Ìgbà gbogbo ni Jésù máa ń ṣègbọràn sí Jèhófà. (Ka Jòhánù 8:29.) Ọ̀pọ̀ àtakò ni Jésù dojú kọ, àmọ́ ó fòótọ́ ṣe gbogbo ohun tí Bàbá rẹ̀ ní kó ṣe títí tó fi kú. Ó fi hàn gbangba pé èèyàn lè sin Ọlọ́run, bó tiẹ̀ ń kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro. Nípa báyìí, Jésù fi ‘àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa kí a lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.’—1 Pétérù 2:21.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìhìn rere tí Jésù wàásù fáwọn èèyàn àtàwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe.
4. Jésù wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn
Jésù fẹsẹ̀ rin ọ̀pọ̀ máìlì lójú ọ̀nà eléruku, ó sì wàásù ìhìn rere fún ọ̀pọ̀ èèyàn. Ka Lúùkù 8:1, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Ṣé àwọn tó kóra jọ sọ́dọ̀ Jésù nìkan ló wàásù fún?
Iṣẹ́ àṣekára wo ni Jésù ṣe kó lè rí àwọn èèyàn wàásù fún?
Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà máa sọ ìhìn rere fáwọn èèyàn. Ka Àìsáyà 61:1, 2, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ṣẹ sí Jésù lára?
Ṣé o rò pé ó yẹ káwọn èèyàn gbọ́ ìhìn rere náà lóde òní?
5. Jésù kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ tó ṣeyebíye
Yàtọ̀ sí pé Jésù wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ó tún kọ́ni láwọn ẹ̀kọ́ tó wúlò gan-an. Wo àwọn àpẹẹrẹ kan nínú Ìwàásù Orí Òkè táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa. Ka Mátíù 6:14, 34 àti 7:12, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Àwọn ìmọ̀ràn tó dáa wo ni Jésù fúnni nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí?
Ṣé o rò pé àwọn ìmọ̀ràn náà ṣì wúlò lóde òní?
6. Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu
Jèhófà fún Jésù lágbára láti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu. Wo àpẹẹrẹ kan, ka Máàkù 5:25-34 tàbí kó o wo FÍDÍÒ yìí. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Nínú fídíò yẹn, kí ló dá obìnrin yẹn lójú?
Kí ló wú ẹ lórí nínú iṣẹ́ ìyanu yẹn?
Ka Jòhánù 5:36, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí ni àwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù “ń jẹ́rìí sí” tàbí kí ni wọ́n fi hàn nípa rẹ̀?
Ǹjẹ́ o mọ̀?
Èyí tó pọ̀ jù nínú ohun tá a mọ̀ nípa Jésù ló wà nínú ìwé Bíbélì mẹ́rin tá à ń pè ní Ìwé Ìhìn Rere, ìyẹn Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó kọ Ìwé Ìhìn Rere sọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan tó yàtọ̀ síra nípa Jésù. Àwọn nǹkan tó yàtọ̀ síra táwọn ìwé náà sọ ló jẹ́ ká mọ ìtàn ìgbésí ayé Jésù dáadáa.
MÁTÍÙ
Òun ló kọ ìwé àkọ́kọ́ nínú Ìwé Ìhìn Rere. Ó jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ni, ní pàtàkì, ẹ̀kọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run.
MÁÀKÙ
Òun ló kọ ìwé tó kéré jù nínú Ìwé Ìhìn Rere. Ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ amóríyá.
LÚÙKÙ
Ó jẹ́ ká rí i pé ọwọ́ pàtàkì ni Jésù fi mú àdúrà àti pé ó máa ń ṣìkẹ́ àwọn obìnrin.
JÒHÁNÙ
Ó ṣàkọsílẹ̀ púpọ̀ lára ọ̀rọ̀ tí Jésù bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ àtàwọn èèyàn míì sọ, èyí sì jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ìwà àti ìṣe Jésù.
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Èèyàn dáadáa ni Jésù lóòótọ́, àmọ́ kì í ṣe Olùgbàlà aráyé.”
Kí lèrò tìẹ?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Jésù wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ó ṣiṣẹ́ ìyanu, ìgbà gbogbo ló sì máa ń ṣègbọràn sí Jèhófà.
Kí lo rí kọ́?
Iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ wo ni Jésù ṣe?
Kí làwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe fi hàn?
Àwọn ẹ̀kọ́ tó wúlò wo ni Jésù kọ́ni?
ṢÈWÁDÌÍ
Kí ni ọ̀rọ̀ Jésù sábà máa ń dá lé?
“Ìjọba Ọlọ́run—Kí Nìdí Tó fi Ṣe Pàtàkì Gan-an sí Jésù?” (Ilé Ìṣọ́ October 1, 2014)
Ka ìwé yìí kó o lè rí ìdí tó fi yẹ ká gbà pé òótọ́ ni Jésù ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu.
“Àwọn Iṣẹ́ Ìyanu Jésù—Kí Lo Lè Rí Kọ́ Látinú Wọn?” (Ilé Ìṣọ́, July 15, 2004)
Ka ìwé yìí kó o lè rí bí ọkùnrin kan ṣe yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa àpẹẹrẹ rere tí Jésù fi lélẹ̀.
Wo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù bí wọ́n ṣe tò tẹ̀ léra.
“Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Jésù” (Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, Àfikún A7)
a Nínú ẹ̀kọ́ 31 sí 33, a máa jíròrò kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run.