ORÍ 68
Ọmọ Ọlọ́run Ni “Ìmọ́lẹ̀ Ayé”
JÉSÙ ṢÀLÀYÉ NÍPA ẸNI TÍ ỌMỌ JẸ́
BÁWO LÀWỌN JÚÙ ṢE JẸ́ ẸRÚ?
Ní ọjọ́ keje Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ Ìjọsìn, ìyẹn lọ́jọ́ tí wọ́n máa parí àjọyọ̀ náà, Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn níbì kan tí wọ́n ń pè ní “ibi ìṣúra” nínú tẹ́ńpìlì. (Jòhánù 8:20; Lúùkù 21:1) Ó ṣeé ṣe kí ibi ìṣúra náà wà ní Àgbàlá Àwọn Obìnrin táwọn èèyàn ti máa ń ṣètọrẹ.
Alaalẹ́ ni ìmọ́lẹ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ máa ń wà níbi àgbàlá náà nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àjọyọ̀. Ọ̀pá fìtílà mẹ́rin tó tóbi, tó sì gùn ló máa ń wà níbẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fìtílà yìí ló ní ibi tí wọ́n máa ń bu òróró sí. Àwọn fìtílà náà mọ́lẹ̀ débi pé ṣe ni wọ́n máa ń mú kí gbogbo àyíká àgbàlá náà mọ́lẹ̀ rekete. Torí náà, ó ṣeé ṣe kí ohun tí Jésù sọ rán àwọn olùgbọ́ rẹ̀ létí bí àgbàlá náà ṣe máa ń rí nígbà tó sọ pé: “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ó dájú pé ẹnikẹ́ni tó bá ń tẹ̀ lé mi kò ní rìn nínú òkùnkùn, àmọ́ ó máa ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”—Jòhánù 8:12.
Làwọn Farisí tó wà níbẹ̀ bá ta ko Jésù, wọ́n sọ fún un pé: “Ò ń jẹ́rìí nípa ara rẹ; ẹ̀rí rẹ kì í ṣe òótọ́.” Jésù dá wọn lóhùn pé: “Tí mo bá tiẹ̀ jẹ́rìí nípa ara mi, òótọ́ ni ẹ̀rí mi, torí mo mọ ibi tí mo ti wá àti ibi tí mò ń lọ. Àmọ́ ẹ̀yin ò mọ ibi tí mo ti wá àti ibi tí mò ń lọ.” Ó wá fi kún un pé: “A kọ ọ́ sínú Òfin yín pé: ‘Òótọ́ ni ẹ̀rí ẹni méjì.’ Mò ń jẹ́rìí nípa ara mi, Baba tó rán mi sì ń jẹ́rìí nípa mi.”—Jòhánù 8:13-18.
Àwọn Farisí náà ò gba ohun tó sọ gbọ́, ni wọ́n bá bi í pé: “Ibo ni Baba rẹ wà?” Jésù ò tiẹ̀ fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ fún wọn, ó dá wọn lóhùn pé: “Ẹ ò mọ̀ mí, ẹ ò sì mọ Baba mi. Ká ní ẹ mọ̀ mí ni, ẹ̀ bá mọ Baba mi náà.” (Jòhánù 8:19) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa mú Jésù, kò sẹ́ni tó jẹ́ fọwọ́ kàn án.
Jésù wá tún ohun tó ti sọ ṣáájú ìgbà yẹn sọ fún wọn, ó ní: “Mò ń lọ, ẹ sì máa wá mi, síbẹ̀ inú ẹ̀ṣẹ̀ yín lẹ máa kú sí. Ẹ ò lè wá sí ibi tí mò ń lọ.” Ọ̀rọ̀ yìí ò yé wọn rárá, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó láàárín ara wọn pé: “Kò ní pa ara rẹ̀, àbí ó máa ṣe bẹ́ẹ̀? Torí ó sọ pé, ‘Ẹ ò lè wá sí ibi tí mò ń lọ.’” Wọn ò lóye ohun tí Jésù ń sọ torí wọn ò mọ ibi tó ti wá. Jésù wá sọ fún wọn pé: “Ìsàlẹ̀ ni ẹ̀yin ti wá; èmi wá láti òkè. Inú ayé yìí lẹ ti wá; èmi ò wá látinú ayé yìí.”—Jòhánù 8:21-23.
Bẹ́ẹ̀ sì rèé ọ̀rọ̀ nípa bí Jésù ṣe wà lọ́run tẹ́lẹ̀ àti bó ṣe jẹ́ pé òun ni Mèsáyà tàbí Kristi tó yẹ káwọn aṣáájú ẹ̀sìn yìí máa retí ló ń bá wọn sọ. Ṣe ni wọ́n tún fìbínú bi í pé: “Ta ni ọ́?”—Jòhánù 8:25.
Níwọ̀n bí àwọn èèyàn náà ò ti yéé ta ko Jésù, ó dá wọn lóhùn pé: “Kí ni mo tiẹ̀ ń bá yín sọ̀rọ̀ fún?” Àmọ́, torí pé Jésù fẹ́ kí wọ́n ronú nípa Baba òun àti ìdí tó fi yẹ kí wọ́n tẹ́tí sí òun tòun jẹ́ ọmọ rẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Olóòótọ́ ni Ẹni tó rán mi, àwọn ohun tí mo sì gbọ́ látọ̀dọ̀ rẹ̀ ni mò ń sọ nínú ayé.”—Jòhánù 8:25, 26.
Jésù wá sọ ohun tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́ nínú Baba rẹ̀, tí ìyẹn sì mú kó yàtọ̀ sáwọn Júù tó ń bá sọ̀rọ̀, ó sọ pé: “Lẹ́yìn tí ẹ bá ti gbé Ọmọ èèyàn sókè, ìgbà yẹn lẹ máa wá mọ̀ pé èmi ni àti pé mi ò dá ṣe nǹkan kan lérò ara mi; àmọ́ bí Baba ṣe kọ́ mi gẹ́lẹ́ ni mò ń sọ àwọn nǹkan yìí. Ẹni tó rán mi wà pẹ̀lú mi; kò pa mí tì lémi nìkan, torí gbogbo ìgbà ni mo máa ń ṣe ohun tó wù ú.”—Jòhánù 8:28, 29.
Torí pé àwọn kan lára àwọn Júù náà nígbàgbọ́ nínú Jésù, ó sọ fún wọn pé: “Tí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín lóòótọ́, ẹ ó mọ òtítọ́, òtítọ́ á sì sọ yín di òmìnira.”—Jòhánù 8:31, 32.
Ó ya àwọn kan lẹ́nu nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa òmìnira, torí náà wọ́n dá a lóhùn pé: “Ọmọ Ábúráhámù ni wá, a ò sì ṣe ẹrú ẹnikẹ́ni rí. Kí ló dé tí o wá sọ pé, ‘Ẹ máa di òmìnira’?” Lóòótọ́, àwọn Júù yẹn mọ̀ pé ìgbà kan wà tí orílẹ̀-èdè míì ń ṣàkóso wọn, síbẹ̀ wọn ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pe àwọn ní ẹrú. Àmọ́ Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ẹrú ṣì ni wọ́n, ó sọ pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni gbogbo ẹni tó bá ń dẹ́ṣẹ̀.”—Jòhánù 8:33, 34.
Ó léwu gan-an báwọn Júù yẹn ò ṣe gbà pé ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ làwọn. Jésù wá ṣàlàyé pé: “Ẹrú kì í wà nínú ilé títí láé, àmọ́ ọmọ máa ń wà níbẹ̀ títí láé.” (Jòhánù 8:35) Ẹrú ò ní ẹ̀tọ́ sí ogún èyíkéyìí nínú ilé ọ̀gá rẹ̀, ìgbàkigbà ni wọ́n sì lè lé e jáde. Kìkì ọmọ tí ọ̀gá bí tàbí èyí tó gbà tọ́ nìkan ló máa wà nínú ilé ọ̀gá náà “títí láé,” ìyẹn ní gbogbo ìgbà tí ọmọ náà bá fi wà láàyè.
Torí náà, òtítọ́ nípa Ọmọ ló lè mú kí ẹnì kan wà lómìnira kúrò lọ́wọ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ títí láé. Jésù wá sọ fún wọn pé: “Torí náà, tí Ọmọ bá sọ yín di òmìnira, ẹ máa di òmìnira lóòótọ́.”—Jòhánù 8:36.