ORÍ 14
Jésù Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ní Ọmọ Ẹ̀yìn
ÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN TÍ JÉSÙ KỌ́KỌ́ NÍ TẸ̀ LÉ E
Lẹ́yìn tí Jésù lo ogójì (40) ọjọ́ nínú aginjù, ó lọ sọ́dọ̀ Jòhánù Arinibọmi kó tó pa dà sí Gálílì. Bí Jésù ṣe ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀, Jòhánù nawọ́ sí i, ó sì fi ìdùnnú sọ fáwọn tó wà níbẹ̀ pé: “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run tó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ! Ẹni yìí ni mo sọ nípa rẹ̀ pé: ‘Ọkùnrin kan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ó ti lọ níwájú mi, torí ó wà ṣáájú mi.’” (Jòhánù 1:29, 30) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jòhánù ju Jésù lọ díẹ̀, ó mọ̀ pé Jésù ti wà ṣáájú òun torí pé áńgẹ́lì alágbára ni lọ́run kó tó wá sáyé.
Ọ̀sẹ̀ mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn, nígbà tí Jésù wá ṣèrìbọmi, kò dá Jòhánù lójú pé Jésù ni Mèsáyà. Jòhánù sọ pé: “Èmi gan-an ò mọ̀ ọ́n, àmọ́ ìdí tí mo fi wá, tí mò ń fi omi batisí ni pé ká lè fi í hàn kedere fún Ísírẹ́lì.”—Jòhánù 1:31.
Jòhánù wá sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fáwọn èèyàn náà nígbà tó ṣèrìbọmi fún Jésù, ó ní: “Mo rí i tí ẹ̀mí ń sọ̀ kalẹ̀ bí àdàbà láti ọ̀run, ó sì bà lé e. Èmi gan-an ò mọ̀ ọ́n, àmọ́ Ẹni tó rán mi láti fi omi batisí sọ fún mi pé: ‘Ẹnikẹ́ni tí o bá rí tí ẹ̀mí ń sọ̀ kalẹ̀, tó sì bà lé, òun ni ẹni tó ń fi ẹ̀mí mímọ́ batisí.’ Mo ti rí i, mo sì ti jẹ́rìí pé ẹni yìí ni Ọmọ Ọlọ́run.”—Jòhánù 1:32-34.
Lọ́jọ́ kejì, Jòhánù wà pẹ̀lú méjì nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ni Jésù bá tún yọ lọ́ọ̀ọ́kán. Jòhánù sọ pé: “Ẹ wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run!” (Jòhánù 1:36) Bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù Arinibọmi méjì yìí ṣe tẹ̀ lé Jésù nìyẹn. Áńdérù lorúkọ ọ̀kan nínú wọn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹni tó ṣàkọsílẹ̀ ìtàn yìí lẹnì kejì, Jòhánù lòun náà sì ń jẹ́. Ó jọ pé ìbátan Jésù ni Jòhánù yìí torí pé Sàlómẹ̀ ni ìyá rẹ̀. Sébédè ni ọkọ Sàlómẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kí Sàlómẹ̀ jẹ́ arábìnrin Màríà.
Nígbà tí Jésù wẹ̀yìn, ó rí i pé Áńdérù àti Jòhánù ń tẹ̀ lé òun, ó bi wọ́n pé: “Kí lẹ̀ ń wá?”
Wọ́n bi í pé: ‘Rábì, ibo lò ń gbé?’
Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ máa bọ̀, kí ẹ wá wò ó.”—Jòhánù 1:37-39.
Láti nǹkan bí aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́, Áńdérù àti Jòhánù wà lọ́dọ̀ Jésù ṣúlẹ̀ ọjọ́ yẹn. Inú Áńdérù dùn gan-an débi pé ó lọ bá Símónì arákùnrin rẹ̀ tó tún ń jẹ́ Pétérù, ó sì sọ fún un pé: “A ti rí Mèsáyà náà.” (Jòhánù 1:41) Áńdérù mú Pétérù lọ bá Jésù. Ó jọ pé nígbà tó yá, Jòhánù náà lọ pe Jémíìsì arákùnrin rẹ̀, ó sì mú un lọ bá Jésù, àmọ́ Jòhánù ò kọ apá yẹn sínú àkọsílẹ̀ rẹ̀.
Lọ́jọ́ kejì, Jésù rí Fílípì tó wá láti Bẹtisáídà. Ìlú yìí wà nítòsí etíkun, ní apá àríwá Òkun Gálílì, ibẹ̀ sì ni Áńdérù àti Pétérù ti wá. Jésù sọ fún Fílípì pé: “Máa tẹ̀ lé mi.”—Jòhánù 1:43.
Fílípì wá rí Nàtáníẹ́lì tó tún ń jẹ́ Bátólómíù, ó sì sọ pé: “A ti rí ẹni tí Mósè, nínú Òfin àti àwọn Wòlíì kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: Jésù, ọmọ Jósẹ́fù, láti Násárẹ́tì.” Àmọ́ Nàtáníẹ́lì ṣiyèméjì, ó sì sọ fún Fílípì pé: “Ṣé ohun rere kankan lè wá láti Násárẹ́tì?”
Fílípì rọ̀ ọ́ pé: “Wá wò ó.” Jésù rí i tí Nàtáníẹ́lì ń bọ̀, ó sì sọ pé: “Wò ó, ní tòótọ́, ọmọ Ísírẹ́lì tí ẹ̀tàn kankan ò sí nínú rẹ̀.”
Nàtáníẹ́lì bi í pé: “Báwo lo ṣe mọ̀ mí?”
Jésù dá a lóhùn pé: “Kí Fílípì tó pè ọ́, nígbà tí o wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́, ni mo ti rí ọ.”
Ó ya Nàtáníẹ́lì lẹ́nu, ó sì sọ pé: “Rábì, ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run, ìwọ ni Ọba Ísírẹ́lì.”
Jésù bi í pé: “Ṣé torí pé mo sọ fún ọ pé mo rí ọ lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ lo ṣe gbà gbọ́? O máa rí àwọn nǹkan tó tóbi ju ìwọ̀nyí lọ.” Jésù wá ṣèlérí pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹ máa rí i tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, tí àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ń gòkè, tí wọ́n sì ń sọ̀ kalẹ̀ sọ́dọ̀ Ọmọ èèyàn.”—Jòhánù 1:45-51.
Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kó jọ kúrò ní Àfonífojì Jọ́dánì, tí wọ́n sì rìnrìn àjò lọ sí Gálílì.