ORÍ 71
Àwọn Farisí Gbọ́ Tẹnu Ọkùnrin Afọ́jú Náà
ÀWỌN FARISÍ GBỌ́RỌ̀ LẸ́NU ỌKÙNRIN TÓJÚ Ẹ̀ FỌ́ TẸ́LẸ̀
“AFỌ́JÚ” NI ÀWỌN AṢÁÁJÚ Ẹ̀SÌN
Àwọn Farisí ò gbà pé Jésù ló jẹ́ kí ọkùnrin tí wọ́n bí ní afọ́jú náà ríran, torí náà wọ́n ránṣẹ́ pe àwọn òbí rẹ̀. Àwọn òbí ọkùnrin náà mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n lé àwọn “kúrò nínú sínágọ́gù.” (Jòhánù 9:22) Tíyẹn bá sì ṣẹlẹ̀, àwọn Júù tó kù ò ní bá wọn da nǹkan pọ̀ mọ́, ìyẹn sì máa kó bá ọrọ̀ ajé ìdílé náà.
Àwọn Farisí béèrè ìbéèrè méjì lọ́wọ́ àwọn òbí ọkùnrin náà, wọ́n ní: “Ṣé ọmọ yín tí ẹ sọ pé ẹ bí ní afọ́jú nìyí? Báwo ló ṣe wá ń ríran?” Àwọn òbí ọmọ náà fèsì pé: “A mọ̀ pé ọmọ wa nìyí, afọ́jú la sì bí i. Àmọ́ bó ṣe wá di pé ó ń ríran báyìí, àwa ò mọ̀; a ò sì mọ ẹni tó la ojú rẹ̀.” Ó ṣeé ṣe kí ọkùnrin náà ti ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ fáwọn òbí rẹ̀, àmọ́ wọ́n ń ṣọ́ bí wọ́n ṣe máa fèsì. Torí náà wọ́n sọ pé: “Ẹ bi í. Kì í ṣe ọmọdé. Ẹ jẹ́ kó fi ẹnu ara rẹ̀ sọ ọ́.”—Jòhánù 9:19-21.
Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn Farisí tún pe ọkùnrin náà, wọ́n sì gbìyànjú láti fúngun mọ́ ọn torí àwọn ẹ̀rí tí wọ́n ní lòdì sí Jésù. Wọ́n sọ pé: “Fi ògo fún Ọlọ́run; a mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọkùnrin yìí.” Ọkùnrin náà sọ ohun tó fi hàn pé kò gba ohun tí wọ́n sọ gbọ́, ó ní: “Èmi ò mọ̀ bóyá ẹlẹ́ṣẹ̀ ni o. Ohun kan tí mo mọ̀ ni pé, afọ́jú ni mí tẹ́lẹ̀, àmọ́ mo ti ń ríran báyìí.”—Jòhánù 9:24, 25.
Gbogbo ohun tọ́kùnrin náà sọ ò nítumọ̀ létí àwọn Farisí, ni wọ́n bá tún bi í pé: “Kí ló ṣe fún ọ? Báwo ló ṣe la ojú rẹ?” Ọkùnrin náà fìgboyà dáhùn pé: “Mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, àmọ́ ẹ ò fetí sílẹ̀. Kí lẹ tún fẹ́ gbọ́ ọ fún? Àbí ẹ̀yin náà fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni?” Làwọn Farisí bá fìbínú sọ pé: “Ìwọ ni ọmọ ẹ̀yìn ọkùnrin yẹn, ọmọ ẹ̀yìn Mósè ni àwa. A mọ̀ pé Ọlọ́run bá Mósè sọ̀rọ̀, àmọ́ ní ti ọkùnrin yìí, a ò mọ ibi tó ti wá.”—Jòhánù 9:26-29.
Ohun tí wọ́n sọ yẹn ṣàjèjì sí ọkùnrin náà, ló bá sọ pé: “Ọ̀rọ̀ yìí yà mí lẹ́nu o, pé ẹ ò mọ ibi tó ti wá, síbẹ̀ ó la ojú mi.” Ọkùnrin náà wá sọ ọ̀rọ̀ kan tó gba àròjinlẹ̀ nípa ohun tó máa ń mú kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ẹnì kan kó sì máa gbọ́ tiẹ̀, ó ní: “Àwa mọ̀ pé Ọlọ́run kì í tẹ́tí sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá ń bẹ̀rù Ọlọ́run, tó sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ó máa ń tẹ́tí sí ẹni yìí. Látìgbà láéláé, a ò gbọ́ ọ rí pé ẹnì kankan la ojú ẹni tí wọ́n bí ní afọ́jú.” Ó wá fi kún un pé: “Ká ní kì í ṣe ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí ti wá ni, kò ní lè ṣe nǹkan kan rárá.”—Jòhánù 9:30-33.
Torí pé àwọn Farisí ò rí nǹkan kan sọ sí ọ̀rọ̀ tó mọ́gbọ́n dání tí alágbe náà sọ, wọ́n sọ fún un pé: “Ṣé ìwọ tí wọ́n bí sínú ẹ̀ṣẹ̀ lódindi yìí lo tún fẹ́ máa kọ́ wa?” Ni wọ́n bá jù ú síta.—Jòhánù 9:34.
Nígbà tí Jésù gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó lọ bá ọkùnrin náà, ó sì bi í pé: “Ṣé o ní ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ èèyàn?” Ọkùnrin náà dáhùn pé: “Ọ̀gá, ta ni onítọ̀hún, kí n lè ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀?” Láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, Jésù sọ pé: “O ti rí i, kódà, òun ló ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí.”—Jòhánù 9:35-37.
Ọkùnrin náà fèsì pé: “Mo ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, Olúwa.” Kí ọkùnrin náà lè fi hàn pé òun nígbàgbọ́ nínú Jésù àti pé òun bọ̀wọ̀ fún un, ó tẹrí ba. Jésù wá sọ ọ̀rọ̀ kan tó gbàfiyèsí, ó ní: “Torí ìdájọ́ yìí ni mo ṣe wá sí ayé yìí, kí àwọn tí kò ríran lè ríran, kí àwọn tó ríran sì lè di afọ́jú.”—Jòhánù 9:38, 39.
Àwọn Farisí tó wà níbẹ̀ mọ̀ pé ojú àwọn ń ríran. Àmọ́ torí pé ojú wọn làwọn èèyàn ń wò láti gba ìtọ́ni látinú Ìwé Mímọ́, wọn ò sì fẹ́ káwọn èèyàn fojú kéré ipò yìí, wọ́n sọ ohun kan láti gbèjà ara wọn, wọ́n ní: “Àwa náà ò fọ́jú, àbí a fọ́jú?” Jésù fèsì pé: “Ká ní ẹ fọ́jú ni, ẹ ò ní dẹ́ṣẹ̀ kankan. Àmọ́ ní báyìí, ẹ sọ pé: ‘Àwa ríran.’ Ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣì ni yín.” (Jòhánù 9:40, 41) Ká ní wọn kì í ṣe olùkọ́ ní Ísírẹ́lì ni, a ò bá sọ pé abájọ tí wọn ò ṣe gbà pé Jésù ni Mèsáyà. Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo Òfin tí wọ́n mọ̀, ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì ni wọ́n dá bí wọ́n ṣe kọ Jésù.