Ori 8
Nínípìn-ín Ninu “Ayọ̀” “Ọmọ-Aládé Alaafia” Naa
1. (a) Nitori idi wo ni ọkunrin kan ṣe rìnrìn àjò lọ si ilu okeere? (b) Ki ni ohun ti owe Jesu dọgbọn tumọsi, bi o tilẹ jẹ pe a kò mẹnuba a ní taarata?
NINU owe Jesu ti awọn talenti, ọkunrin naa ti ó ní talenti fadaka mẹjọ kò rin ìrìn àjò lọ si ilu okeere lati wulẹ̀ lọ jẹ faaji bi ẹni najú lọ wo awọn ibi àṣàyàn. O ní idi ti ó ṣe gunmọ kan fun rírin ìrìn àjò si ilu okeere; o fẹ lọ gba ohun iyebiye kan. Oun re àjò si ilu okeere, bi owe naa ti fihan, lati jere “ayọ̀” pataki kan, papọ pẹlu “ohun pupọ.” (Matteu 25:21) Nipa bẹẹ oun nilati rìrìn àjò lọ si ọna jijin, ti ó gba akoko gigun, ki ó ba lè beere lọwọ ẹni naa ti ó lè fi ayọ̀ pato naa jinki rẹ̀.
2. (a) Ninu ọran ti Jesu, ki ni ìrìn àjò si ilu okeere ọkunrin ọlọ́rọ̀ naa duro fun, si ọdọ ta ni o sì lọ? (b) Ki ni Oluwa naa mu bọ̀?
2 Niwọn bi ọkunrin ọlọ́rọ̀ inu owe naa ti duro fun Jesu Kristi, ìrìn àjò ọkunrin naa si ilu okeere ṣapẹẹrẹ lilọ Jesu si ọdọ Orisun kanṣoṣo naa fun ayọ̀ akanṣe ti oun ti ń fojusun. Ọdọ ta ni oun lọ nigba naa? Heberu 12:2 (NW) sọ fun wa pe: “A . . . ń tẹjumọ Olori Aṣoju ati Alaṣepe igbagbọ wa, Jesu. Nitori ayọ̀ ti a gbe ka iwaju rẹ̀, ó farada igi oro o tẹmbẹlu itiju, ó sì ti jokoo ní ọwọ́ ọtun itẹ Ọlọrun.” Bẹẹni, niti tootọ, Jehofa Ọlọrun ni Orisun ayọ̀ yẹn. Ọdọ rẹ̀ ni Jesu lọ, ti ó sì fi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ oluṣotitọ silẹ nihin-in lori ilẹ̀-ayé pẹlu “talenti” rẹ̀ ti o fi si ìkáwọ́ wọn. Oluwa naa padabọ pẹlu “ohun pupọ” ti oun kò ní tẹlẹ nigba ti ó pin talenti fadaka mẹjọ naa fun awọn ẹrú rẹ̀ mẹta. Owe iṣaaju kan ti Jesu pa, owe “mina mẹwaa,” sọ ọ́ ní pato pe oun pada wà pẹlu agbara “ijọba.”—Luku 19:12-15.
3. Iru akoko wo ni Sekariah 9:9 bẹrẹsii ní imuṣẹ ní ọrundun kìn-ín-ní C.E.?
3 Bi a ba ṣẹṣẹ gbe ọba kan gun ori itẹ, o ní idi lati kun fun ayọ̀, bakan naa ni awọn ọmọ-abẹ rẹ̀ aduroṣinṣin pẹlu. A tun mu akoko iṣẹlẹ ìgbà ti Ọmọkunrin Ọlọrun gun kẹtẹkẹte wọ Jerusalemu lati mu asọtẹlẹ Sekariah 9:9 ṣẹ wa si iranti. Niti imuṣẹ asọtẹlẹ yẹn, a kọwe rẹ̀ pe: “Ọpọ ijọ eniyan tẹ́ aṣọ wọn si ọna; ẹlomiran ṣẹ́ ẹka igi wẹ́wẹ́, wọn sì fún wọn si ọna. Ijọ eniyan ti ń lọ niwaju, ati eyi ti ń tọ̀ wọn lẹhin, ń kigbe wi pe: Hosanna fun Ọmọ Dafidi: Olubukun ni ẹni ti ó ń bọwa ní orukọ Oluwa [“Jehofa,” NW]; Hosanna loke ọ̀run. Nigba ti ó de Jerusalemu, gbogbo ilu mì tìtì, wi pe, Ta ni yi?”—Matteu 21:4-10; tun wo Luku 19:36-38.
4. Lẹhin ti a ti gbe e ka ori itẹ gẹgẹ bi Ọba, eeṣe ti Jesu Kristi fi ní idi pataki fun kikesi “awọn ẹrú” oluṣotitọ rẹ̀ wá sinu ipo alayọ kan?
4 Bi o ba jẹ́ pe, nigba naa, o jẹ́ akoko iṣẹlẹ alayọ nla nigba ti ó kàn wulẹ fi araarẹ̀ han fun awọn olugbe Jerusalemu bi ẹni naa ti a fi àmì ororo ti ẹmi Jehofa yàn lati jọba, bawo ni ki yoo ti jẹ́ eyi ti ó pọ̀ ju bẹẹ lọ nigba ti a diidi gbe e ka ori itẹ gẹgẹ bi Ọba ní opin Akoko Awọn Keferi ní 1914? Eyi jẹ́ akoko iṣẹlẹ alayọ nla gidi gan-an fun un. Nigba yẹn, nitootọ, oun wọnu ayọ̀ kan eyi ti oun kò tii ní iriri rẹ̀ rí. Nigba ṣiṣe iṣiro, oun lè sọ nigba naa fun awọn ọmọ-ẹhin ti oun kà yẹ si “rere ati oloootọ” pe: “Iwọ ṣe oloootọ, ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pupọ; iwọ bọ́ sinu ayọ̀ Oluwa rẹ.” (Matteu 25:21) Ayọ̀ titun miiran ti delẹ nisinsinyi ninu eyi ti awọn “ẹrú” rẹ̀ ti oun tẹwọgba yoo ṣajọpin. Ere ẹsan yii mà pọ̀ o!
5. (a) Aposteli Paulu jẹ́ “ikọ̀” kan fun Kristi ní igba wo ninu iṣẹlẹ? (b) Ṣugbọn lonii àṣẹ́kù ẹni-ami-ororo jẹ́ awọn “ikọ̀” fun Kristi lẹhin idagbasoke wo?
5 Ní 1919 awọn ẹni-ami-ororo ọmọ-ẹhin Ọba ti ń ṣakoso naa, Jesu Kristi, wọ inu ipo itẹwọgba nitootọ, ayọ̀ nlanla ni eyi sì mu wa fun wọn. Ní ọgọrun-un ọdun 19 ṣaaju, aposteli Paulu kọwe si awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ lati sọ fun wọn nipa ipo wọn giga pe: “Nitori naa awa ni ikọ̀ fun Kristi.” (2 Korinti 5:20) A kọ eyi nigba ti Jesu wulẹ ṣì jẹ́ arole ti a kò lè rọnipo pẹlu ifojusọna fun titẹwọgba “ijọba ọ̀run.” (Matteu 25:1) Nitori naa, nigba naa, o ṣì ń beere pe ki o jokoo ní ọwọ́ ọtun Ọlọrun, ki o sì duro nibẹ de ọjọ ifijoye. Ṣugbọn nisinsinyi, lati 1919, àṣẹ́kù naa ti a ti tẹwọgba jẹ́ awọn “ikọ̀” ti a rán jade lati ọwọ́ Ẹni naa gan-an ti ó ti ń ṣakoso gẹgẹ bi Ọba. (Heberu 10:12, 13) Otitọ yii ni a pe wá si afiyesi awọn International Bible Students lọna akanṣe ní apejọpọ Cedar Point, Ohio, ní 1922.
6. Awọn isapa ọdun ẹhin ogun ti awọn wọnni ti wọn ti gba “talenti” naa ni a kọkọ dari si iru iṣẹ wo?
6 Ní 1919 wọn ti ní ohun ti ó ṣe deedee pẹlu “talenti” Ọba naa ti ń ṣakoso, Jesu Kristi ní ikawọ. Eyi ti gbooro siwaju sii nigba iṣeṣiro wọn fun Ọba wọn ti ń ṣakoso. Lati ibẹrẹ, awọn isapa wọn lẹhin ogun ni a ti dari rẹ̀ si iṣẹ “ikore” kan, ti kíkó ẹgbẹ “alikama” jọ. (Matteu 13:24-30) Niwọn bi, gẹgẹ bi Jesu ti sọ ọ, “ìparí eto-igbekalẹ awọn nǹkan” ni ikore, ọdun ẹhin ogun naa 1919 ni akoko tó fun ikore “awọn ọmọ ijọba” ẹni bi alikama, àṣẹ́kù ẹni-ami-ororo oluṣotitọ, lati bẹrẹ.—Matteu 13:37-39, NW.
7. (a) Inu iru akoko wo ni awọn olukore naa bọ́ si pẹlu Oluwa wọn? (b) Sinu iru ipo wo ni Jehofa mu ki awọn olukore naa wà, awọn ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ wo ni wọn sì gbà bii tiwọn?
7 Akoko alayọ ni akoko ikore jẹ́ fun awọn olukore, bi Oluwa ikore naa ti ń gbadun akoko iṣẹlẹ naa pẹlu wọn. (Orin Dafidi 126:6) Akoko ikore yii ni a ti mu ki ó dọ́ṣọ̀ pupọ sii nipa awọn ẹri ti ń ga pelemọ sii pe Ijọba Ọlọrun nipasẹ Jesu Kristi ni a ti gbekalẹ ní ọ̀run ní 1914 ati pe Jehofa mú iduro ododo padabọ wá fun awọn eniyan rẹ̀ ti ó ń fi tọkantọkan ṣiṣẹsin in lori ilẹ̀-ayé. Gẹgẹ bi ẹgbẹ kan, wọn gba awọn ọ̀rọ̀ Isaiah 61:10 (NW) bii tiwọn: “Lai kuna emi yoo yọ̀ gidigidi ninu Jehofa. Ọkan mi yoo yọ̀ ninu Ọlọrun mi. Nitori o ti fi agbada ìgbàlà wọ̀ mi; o ti fi aṣọ awọleke ododo bò mí.”
Kíkó “Ogunlọgọ Nla” Awọn Oluṣajọpin “Ayọ̀” Jọpọ̀
8. Ayọ̀ ti àṣẹ́kù ẹni-ami-ororo naa kò reti rẹ̀ tẹlẹ wo ni yoo jẹ́ ipin tiwọn ní opin ikojọpọ awọn ajogun Ijọba naa?
8 Àṣẹ́kù ẹni-ami-ororo naa ti ó wọnu “ayọ̀” Oluwa wọn kò mọ̀ pe bi ikojọpọ awọn mẹmba ikẹhin ti awọn ajogun Ijọba ọ̀run naa bá ti ń lọ si opin, ayọ̀ miiran yoo tun wà, ohun kan ti a kò reti rẹ̀ tẹlẹ. Eyi yoo jẹ́ ikowọle ẹgbẹ ti ori ilẹ̀-ayé kan ti yoo gbé ninu Paradise ilẹ̀-ayé labẹ Iṣakoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun ti Jesu Kristi. Awọn miiran wo bi kii ba ṣe awọn eniyan lati inu ẹgbẹ ti ori ilẹ̀-ayé yii ni ó tun yẹ lati kesi wá gbọ́ ohun ti yoo jẹ́ iṣipaya akọkọ nipa isọfunni naa ti ó kan wọn?
9. Awọn wo ni a pè wá lọna akanṣe si apejọpọ ti Washington, D.C., ní 1935, isọfunni ti ó si ba akoko mu gẹẹ wo ni a ṣipaya fun wọn nibẹ?
9 Bẹẹ ni ó sì ri pe, ní idahunpada si ikesini ti a tẹjade ninu Ilé-Ìṣọ́nà (Gẹẹsi),a ọgọrọọrun awọn ti ń wá ibatan pẹlu Jehofa, ní ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu awọn eniyan ti ń jẹ́ orukọ rẹ̀, lọ si apejọpọ gbogbogboo ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Washington, D.C., May 30 si June 2, 1935. Ní apejọpọ yẹn, a ru wọn soke de isalẹ ọkan lati kẹkọọ pe “ogunlọgọ nla” naa ti a riran rẹ̀ tẹ̀lẹ́ ninu Ìfihàn 7:9-17 jẹ́ ẹgbẹ ti ori ilẹ̀-ayé kan.
10, 11. Fun awọn wo ní ọ̀run ni eyi yoo ti jẹ́ akoko fun akanṣe ayọ̀?
10 Ẹ wo iru ayọ̀ nla ti ṣiṣe apejọpọ naa ní Washington, D.C., ti ní lati jẹ́ fun Ọlọrun Giga Julọ naa, Jehofa! Ẹ wo iru ayọ̀ nla ti eyi ti nilati tun jẹ́ fun Ọmọkunrin rẹ̀ gẹgẹ bi Oluṣọ-Agutan Rere naa ti yoo wa bẹrẹsii kó “awọn agutan miiran” wọnyi jọ sinu “agbo kan” yẹn!—Johannu 10:16.
11 Bi a ti ń dà wọn lọ ti wọn sì ń jẹko, ki a sọ ọ lọna apẹẹrẹ, awọn mẹmba àṣẹ́kù naa ati “ogunlọgọ” ti “awọn agutan miiran” ti ń pọ sii ń dàpọ̀ mọ́ araawọn pẹlu alaafia ati ifẹ. Ọkan-aya “oluṣọ agutan-kanṣoṣo” wọn ti gbọdọ kúnfọ́fọ́ fun ayọ̀ nisinsinyi nitori níní iru “agbo” nla bẹẹ nitosi “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan” isinsinyi.
Awọn Ikọ̀ “Ọmọ-Aládé Alaafia” Naa
12, 13. (a) Awọn wo ni a ti kesi lati ṣajọpin pẹlu àṣẹ́kù ẹni-ami-ororo ninu ayọ̀ Oluwa naa ti ó ti padabọ, ki si ni idi fun eyi? (b) “Ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran” ń ṣiṣẹsin fun ire “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa ní ipo àyè wo?
12 Awọn ẹni bi agutan wọnyẹn ti wọn parapọ jẹ́ “ogunlọgọ nla” naa ní ipin gigadabu nisinsinyi ninu ayọ̀ Oluwa naa, Jesu Kristi. Eyi ní ọna pupọ jẹ́ nitori pe wọn ń nipin-in alaapọn ninu mimu awọn wọnni ti a ń fẹ wọle fun mimu “ogunlọgọ nla” naa pe perepere, eyi ti a kò fi iye pato kan diwọn ninu Ìfihàn 7:9.
13 Iṣẹ ikojọpọ naa tí “awọn agutan miiran” ń lọwọ ninu rẹ̀ ti yara tan kalẹ kárí-ayé, jinna rekọja ohun ti àṣẹ́kù ẹni-ami-ororo naa ti ń kere sii niye lè ṣèkáwọ́ rẹ̀. Nitori naa, o ti wá di dandangbọn sii fun “awọn agutan miiran” ti iye wọn tubọ ń pọ sii lati ní ipin pupọ sii ju ti igbakigba ri lọ ninu mimu “awọn agutan miiran” pupọ sii ti wọn ní ireti ori ilẹ̀-ayé wọle. Nipa bayii “awọn agutan miiran” ń ṣiṣẹsin bi awọn ikọ̀ oluṣotitọ fun “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa. Owe 25:13 fikun un pe: “Bi otutu òjò-dídì ní ìgbà ikore, bẹẹ ni oloootọ ikọ̀ si awọn ti ó ran an: nitori o tu awọn oluwa rẹ̀ ninu.”
14. (a) Ki ni awọn agutan iṣapẹẹrẹ ti inu owe Jesu ninu Matteu 25:31-46 jogun rẹ̀? (b) Bawo ni a ti ṣe pese Ijọba naa silẹ fun wọn “lati ọjọ ìwà”?
14 Ninu owe awọn agutan ati ewurẹ, awọn agutan iṣapẹẹrẹ naa ni awọn ẹni ti Ọba naa Jesu Kristi wi fun pe: “Ẹ wa, ẹyin alabukun fun Baba mi, ẹ jogun ijọba, ti a ti pese silẹ fun yin lati ọjọ ìwà.” (Matteu 25:31-46) Wọn jogun ilẹ-akoso ti ori ilẹ̀-ayé tí Ijọba ọ̀run yoo jọba lé lori nigba iṣakoso Ẹgbẹrun Ọdun ti Kristi. Lati igba Abeli oluṣotitọ, Jehofa ti ń mura ilẹ-akoso yii silẹ fun ayé araye ti ó ṣe e rapada.—Luku 11:50, 51.
15, 16. (a) “Ọla” ọba wo, bi Solomoni ti mẹnukan an, ni Oluwa naa ní lonii laika iṣakoso rẹ̀ laaarin awọn ọta rẹ̀ si? (b) Ní iru ọna wo ni Ọba naa ti ń ṣakoso gba fi ní “ọla” rẹ̀ lonii? (c) Ki ni ohun ti awọn wọnni ti wọn parapọ jẹ́ “ọla” rẹ̀ yii ti ṣe?
15 Ọlọgbọn Ọba Solomoni ti Israeli igbaani kọwe pe: “Ninu ọpọlọpọ eniyan ni ọla ọba.” (Owe 14:28) Ọba Oluwa tòní, Kristi Jesu, ti ó jẹ́ oṣiṣẹ oloye ti ó ga rekọja Ọba Solomoni ti ori ilẹ̀-ayé, ní iru “ọla” bẹẹ niti “ọpọlọpọ eniyan.” Eyi jẹ́ otitọ àní nisinsinyi paapaa ṣaaju ibẹrẹ iṣakoso rẹ̀ ẹlẹgbẹrun ọdun, bẹẹni, nigba ti ó ń jọba laaarin awọn ọta rẹ̀ ori ilẹ̀-ayé, lori awọn ti Satani Eṣu jẹ́ ọba alaiṣeefojuri ti agbara rẹ̀ ju ti eniyan lọ.—Matteu 4:8, 9; Luku 4:5, 6.
16 “Ọla” ti ode-oni ti ó yẹ oṣiṣẹ oloye giga kan ti ó ní ipo ọba ni a rí nisinsinyi ninu iye “awọn agutan miiran” rẹ̀ ti ń búrẹ́kẹ sii ti wọn parapọ jẹ́ “ogunlọgọ nla.” Pẹlu ìhó ayọ̀ wọn ń kigbe soke ní iṣọkan pe: “Igbala ni ti Ọlọrun wa ti ó jokoo lori itẹ, ati ti Ọdọ-Agutan.” (Ìfihàn 7:9, 10) Wọn ti ní iriri igbala kuro ninu eto-igbekalẹ awọn nǹkan ti a ti dalẹbi, eyi tí Satani Eṣu jẹ́ “ọlọrun” fun. (2 Korinti 4:4) Ki a sọ ọ ní ede apejuwe, wọn ti “fọ aṣọ wọn . . . ninu ẹjẹ Ọdọ-Agutan naa” wọn sì ti sọ wọn di funfun ki wọn baa lè jẹ́ alailabawọn niwaju Jehofa Ọlọrun, Onidaajọ naa.—Ìfihàn 7:14.
17. (a) Igbala wo ni “ogunlọgọ nla” ń fojusọna fun sibẹ? (b) Anfaani wo ni wọn yoo gbadun rẹ̀ laaarin Iṣakoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun ti “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa?
17 Sibẹ wọn ń fojusọna fun ipese igbala atọrunwa ti wọn yoo ní iriri rẹ̀ nigba aṣepari iṣẹgun Jehofa ní “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare” ni Har–mageddoni. Iṣẹgun agbayanu rẹ̀ nibẹ yoo yọrisi idalare ipo ọba-alaṣẹ agbaye rẹ̀, wọn yoo sì wá jẹ́ ẹlẹ́rìí ti ọran ṣoju rẹ̀ lori ilẹ̀-ayé nitori ti a ti pa wọn mọ́ laaye la opin bibanilẹru ti ayé buburu yii já. (Ìfihàn 16:14; 2 Peteru 3:12) Ẹ wo iru anfaani ṣiṣeyebiye ti eyi jẹ́! Ẹ si wo iru ayọ̀ nla ti “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa yoo wá ṣajọpin pẹlu “ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran” rẹ̀ aduroṣinṣin ti o laaja!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Oju-iwe 2 ti awọn itẹjade Ilé-Ìṣọ́nà (Gẹẹsi) ti April 1 ati 15, May 1 ati 15, 1935.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 71]
Ọkan-aya Oluṣọ-Agutan Rere naa ti gbọdọ kun fun ayọ̀ nisinsinyi nitori nini ọpọlọpọ “awọn agutan miiran” rẹpẹtẹ