ORÍ 81
Ọ̀kan Ni Jésù àti Baba, Àmọ́ Jésù Kì Í Ṣe Ọlọ́run
“ÈMI ÀTI BABA JẸ́ Ọ̀KAN”
JÉSÙ JÁ IRỌ́ ÀWỌN TÓ FẸ̀SÙN KÀN ÁN PÉ Ó Ń PE ARA Ẹ̀ NÍ ỌLỌ́RUN
Jésù wá sí Jerúsálẹ́mù fún Àjọyọ̀ Ìyàsímímọ́ (tàbí, Hanukkah). Wọ́n máa ń ṣe ayẹyẹ yìí láti rántí bí wọ́n ṣe tún tẹ́ńpìlì Ọlọ́run yà sí mímọ́. Torí ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún (100) ọdún sẹ́yìn, Ọba Síríà tó ń jẹ́ Áńtíókọ́sì Kẹrin (ìyẹn Epiphanes) kọ́ pẹpẹ míì sórí pẹpẹ ńlá tó wà nínú tẹ́ńpìlì yẹn. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn ọmọ àlùfáà kan gba ìlú Jerúsálẹ́mù pa dà, wọ́n sì tún tẹ́ńpìlì Jèhófà yà sí mímọ́. Àtìgbà yẹn ni wọ́n ti máa ń ṣe ayẹyẹ yìí lọ́dọọdún ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) oṣù Kísíléfì, ìyẹn oṣù tó wà láàárín ìparí November sí ọwọ́ ìbẹ̀rẹ̀ December.
Àsìkò òtútù ti dé nígbà yẹn. Jésù ń rìn nínú tẹ́ńpìlì ní àgbàlá Sólómọ́nì, làwọn Júù kan bá wá bá a. Wọ́n bi í pé: “Títí dìgbà wo lo fẹ́ fi wá sínú òkùnkùn? Tó bá jẹ́ ìwọ ni Kristi náà, sọ fún wa ní tààràtà.” (Jòhánù 10:22-24) Báwo ni Jésù ṣe wá dá wọn lóhùn? Ó ní: “Mo ti sọ fún yín, síbẹ̀ ẹ ò gbà gbọ́.” Lóòótọ́ Jésù ò sọ fún wọn ní tààràtà pé òun ni Kristi náà, bó ṣe sọ fún obìnrin ará Samáríà tó wá pọnmi nídìí kànga. (Jòhánù 4:25, 26) Síbẹ̀, ó ti jẹ́ kí wọ́n mọ irú ẹni tóun jẹ́ nígbà tó sọ pé: “Kí Ábúráhámù tó wà, èmi ti wà.”—Jòhánù 8:58.
Jésù fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ fúnra wọn pé òun ni Kristi náà, ìyẹn tí wọ́n bá fi ohun tó ń ṣe wéra pẹ̀lú ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ pé Kristi máa ṣe. Ìdí nìyẹn tó fi máa ń sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni pé òun ni Mèsáyà. Jésù wá sọ ní tààràtà fáwọn Júù burúkú yẹn pé: “Àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe ní orúkọ Baba mi ń jẹ́rìí nípa mi. Àmọ́ ẹ ò gbà gbọ́.”—Jòhánù 10:25, 26.
Kí nìdí tí wọn ò fi gbà pé Jésù ni Kristi náà? Ó sọ pé: “Ẹ ò gbà gbọ́, torí ẹ kì í ṣe àgùntàn mi. Àwọn àgùntàn mi máa ń fetí sí ohùn mi, mo mọ̀ wọ́n, wọ́n sì ń tẹ̀ lé mi. Mo fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun, ó sì dájú pé wọn ò ní pa run láé, ẹnikẹ́ni ò sì ní já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ mi. Ohun tí Baba mi ti fún mi tóbi ju gbogbo nǹkan míì lọ.” Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù sọ bí àárín òun àti Baba rẹ̀ ṣe wọ̀ tó, ó ní: “Èmi àti Baba jẹ́ ọ̀kan.” (Jòhánù 10:26-30) Jésù wà láyé, Baba rẹ̀ sì wà ní ọ̀run, torí náà kò lè jẹ́ pé Jésù ń sọ pé ọ̀kan ṣoṣo náà ni òun àti Baba òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Jésù ń sọ ni pé ohun kan náà ni òun àti Baba òun ń ṣe, àwọn méjèèjì sì wà níṣọ̀kan.
Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí bí àwọn Júù yẹn nínú débi pé wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí í mú òkúta nílẹ̀, wọ́n sì fẹ́ sọ ọ́ lu Jésù. Ohun tí wọ́n ṣe yìí ò tiẹ̀ jọ Jésù lójú, ṣe ló sọ pé: “Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ rere ni mo fi hàn yín látọ̀dọ̀ Baba. Torí èwo nínú àwọn iṣẹ́ yìí lẹ ṣe fẹ́ sọ mí lókùúta?” Wọ́n dáhùn pé: “Kì í ṣe torí iṣẹ́ rere la ṣe fẹ́ sọ ọ́ lókùúta, torí ọ̀rọ̀ òdì ni; torí pé o ti sọ ara rẹ di ọlọ́run.” (Jòhánù 10:31-33) Kò sígbà kankan tí Jésù sọ pé ọlọ́run ni òun, kí wá nìdí tí wọ́n fi ń fẹ̀sùn yìí kàn án?
Bóyá torí ohun tí Jésù sọ pé òun ní irú agbára tó ṣàrà ọ̀tọ̀ kan, táwọn Júù yẹn sì gbà pé Ọlọ́run nìkan ló nírú ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa “àgùntàn,” ó ní: “Mo fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun,” bẹ́ẹ̀ sì rèé kò sí èèyàn kankan tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. (Jòhánù 10:28) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù jẹ́ káwọn Júù yẹn mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Baba òun lòun ti gba àṣẹ, wọn ò gbà á gbọ́.
Kí Jésù lè já irọ́ wọn, ó béèrè pé: “Ṣebí a kọ ọ́ sínú Òfin yín [ìyẹn nínú Sáàmù 82:6] pé, ‘Mo sọ pé: “ọlọ́run ni yín”’? Tó bá pe àwọn tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lòdì sí ní ‘ọlọ́run,’ . . . ṣé èmi tí Baba sọ di mímọ́, tó sì rán wá sí ayé lẹ wá ń sọ fún pé, ‘O sọ̀rọ̀ òdì,’ torí mo sọ pé, ‘Ọmọ Ọlọ́run ni mí’?”—Jòhánù 10:34-36.
Bẹ́ẹ̀ ni, Ìwé Mímọ́ pàápàá pe àwọn èèyàn tó ń dájọ́ lọ́nà àìtọ́ ní “ọlọ́run.” Kí wá nìdí táwọn Júù yìí fi ń dá Jésù lẹ́bi torí pé ó pe ara ẹ̀ ní ‘Ọmọ Ọlọ́run’? Jésù sọ ohun kan tó yẹ kó yí èrò wọn pa dà, ó ní: “Tí mi ò bá ṣe àwọn iṣẹ́ Baba mi, ẹ má gbà mí gbọ́. Àmọ́ tí mo bá ń ṣe é, bí ẹ ò tiẹ̀ gbà mí gbọ́, ẹ gba àwọn iṣẹ́ náà gbọ́, kí ẹ lè wá mọ̀, kí ẹ sì túbọ̀ máa mọ̀ pé Baba wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, mo sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Baba.”—Jòhánù 10:37, 38.
Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí ò ríbi dúró sí lára wọn rárá, ni wọ́n bá gbìyànjú láti rá a mú, àmọ́ Jésù tún bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Bí Jésù ṣe fi Jerúsálẹ́mù sílẹ̀ nìyẹn tó sì lọ sí òdìkejì Odò Jọ́dánì, níbi tí Jòhánù ti bẹ̀rẹ̀ sí í ri àwọn èèyàn bọmi ní nǹkan bí ọdún mẹ́rin sẹ́yìn. Ó dájú pé ibi tí Jésù lọ yìí ò jìnnà sí apá gúúsù Òkun Gálílì.
Ọ̀pọ̀ èèyàn wá sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n sì ń sọ pé: “Jòhánù ò ṣe iṣẹ́ àmì kankan, àmọ́ òótọ́ ni gbogbo ohun tí Jòhánù sọ nípa ọkùnrin yìí.” (Jòhánù 10:41) Torí náà, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló nígbàgbọ́ nínú Jésù.