Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ìgbà wo ni àwọn awòràwọ̀ lọ sọ́dọ̀ Jésù?
Mátíù sọ fún wa nínú Ìhìn Rere tó kọ pé “àwọn awòràwọ̀ láti àwọn apá ìlà-oòrùn” wá sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n sì mú àwọn ẹ̀bùn wá fún un. (Mátíù 2:1-12) Bíbélì kò sọ iye àwọn awòràwọ̀ tàbí “amòye” tí wọ́n wá sọ́dọ̀ Jésù nígbà tó wà lọ́mọdé. Èrò ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé àwọn mẹ́ta ni, àmọ́ kò sí ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ tó ti èrò yìí lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ sì ni a kò dárúkọ wọn nínú ìtàn Bíbélì náà.
Nígbà tí Bíbélì New International Version Study Bible ń sọ̀rọ̀ nípa Mátíù 2:11, ó ní: “Èrò ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé àwọn amòye lọ sọ́dọ̀ Jésù ní ibùjẹ ẹran lóru ọjọ́ tí wọ́n bí i, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀, àwọn olùṣọ́ àgùntàn ló lọ síbẹ̀. Ó tó oṣù díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà kí àwọn amòye tó wá bá a, inú ‘ilé’ ni wọ́n sì ti wá bá a nígbà tó ṣì jẹ́ ‘ọmọdé.’” A rí ẹ̀rí èyí nínú ohun tí Hẹ́rọ́dù ṣe nígbà tó ń wá ọ̀nà láti pa ọmọ náà, ó pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọmọdékùnrin tí wọ́n wà ní ọmọ ọdún méjì sí ìsàlẹ̀ ní gbogbo Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti àgbègbè rẹ̀. Ó fojú bu ọjọ́ orí yẹn nípa ṣíṣírò rẹ̀ “ní ìbámu pẹ̀lú àkókò tí ó ti fẹ̀sọ̀ wádìí dájú lọ́wọ́ àwọn awòràwọ̀ náà.”—Mátíù 2:16.
Tó bá jẹ́ pé àwọn awòràwọ̀ yìí ti wá sọ́dọ̀ Jésù lóru ọjọ́ tí wọ́n bí i tí wọ́n sì mú wúrà àtàwọn ẹ̀bùn iyebíye míì wá fún un, kò jọ pé ní ogójì ọjọ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn Màríà á fi kìkì ẹyẹ méjì rúbọ nígbà tó gbé Jésù wá sí tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. (Lúùkù 2:22-24) Èyí jẹ́ ètò kan nínú Òfin Mósè tó wà fáwọn tálákà tí kò bá lè mú ẹgbọrọ àgbò wá. (Léfítíkù 12:6-8) Àmọ́, àwọn ẹ̀bùn iyebíye yìí lè ti jẹ́ àrànṣe tó bọ́ sákòókò, èyí tó ṣeé ṣe kí ìdílé Jésù lò láti fi gbọ́ bùkátà ara wọn lásìkò tí wọ́n fi wà ní Íjíbítì.—Mátíù 2:13-15.
Kí nìdí tó fi gba Jésù ní ọjọ́ mẹ́rin gbáko kó tó lè dé ibi ibojì Lásárù?
Tá a bá ní ká sọ bó ṣe jẹ́ gan-an, ó jọ pé Jésù mọ̀ọ́mọ̀ ṣètò rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Gbé àkọsílẹ̀ tó wà ní Jòhánù orí kọkànlá yẹ̀ wò.
Nígbà tí Lásárù ará Bẹ́tánì tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Jésù ń ṣàìsàn gan-an, àwọn arábìnrin rẹ̀ ránṣẹ́ sí Jésù. (Jòhánù 11:1-3) Nígbà yẹn, ibi tí Jésù wà tó nǹkan bí ìrìn àjò ọjọ́ méjì sí Bẹ́tánì. (Jòhánù 10:40) Ẹ̀rí fi hàn pé kò pẹ́ sígbà tí ìròyìn kan Jésù lára pé Lásárù ń ṣàìsàn ni Lásárù kú. Kí ni Jésù ṣe? Ó “dúró . . . fún ọjọ́ méjì ní ibi tí ó wà,” lẹ́yìn náà, ó fibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí Bẹ́tánì. (Jòhánù 11:6, 7) Nítorí náà, bó ṣe dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ méjì tó sì tún rìnrìn àjò fún ọjọ́ méjì mìíràn mú kí ó dé ibi ibojì náà ní ọjọ́ mẹ́rin lẹ́yìn tí Lásárù ti kú.—Jòhánù 11:17.
Ṣáájú igbà yẹn, Jésù ti jí àwọn èèyàn méjì dìde. Ó jí ẹni àkọ́kọ́ dìde kété lẹ́yìn tí ẹni náà kú, ó sì jí ẹnì kejì dìde lọ́jọ̀ kan náà tó kú, àmọ́ ó ṣeé ṣe kó pẹ́ díẹ̀ lẹ́yìn tó kú. (Lúùkù 7:11-17; 8:49-55) Ǹjẹ́ Jésù lè jí ẹni tó ti kú lọ́jọ́ mẹ́rin sẹ́yìn dìde, tí ara onítọ̀hún ti bẹ̀rẹ̀ sí í jẹrà? (Jòhánù 11:39) Ohun kan tó gbàfiyèsí ni pé ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì sọ pé láàárín àwọn Júù, ìgbàgbọ́ kan wà pé “kò sí ìrètí kankan fún ẹni tó ti kú fún ọjọ́ mẹ́rin; nígbà yẹn ó hàn gbangba pé ara rẹ̀ á ti máa jẹrà, àti pé ọkàn tí wọ́n lérò pé ó máa ń rà bàbà lórí òkú fún ọjọ́ mẹ́ta ti lọ.”
Bí àwọn kan lára àwọn tó wà níbi ibojì náà bá ń ṣiyèméjì, wọ́n ò ní pẹ́ rí agbára tí Jésù ní lórí ikú. Bí Jésù ti dúró níbi ibojì náà, ó ké lóhùn rara pé: “Lásárù, jáde wá!” Lẹ́yìn náà, “ọkùnrin tí ó ti kú náà jáde wá.” (Jòhánù 11:43, 44) Nítorí náà, àjíǹde ni ìrètí gidi tó wà fún àwọn tó ti kú, kì í ṣe ìgbàgbọ́ èké tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní, pé ọkàn èèyàn máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú.—Ìsíkíẹ́lì 18:4; Jòhánù 11:25.