Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
“Mo Ti Gbà Gbọ́”
MÀTÁ ń fojú inú wo ibojì arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n fi òkúta dí ẹnu ọ̀nà rẹ̀. Ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ pọ̀ lápọ̀jù. Ó ṣòro fún un gan-an láti gbà pé Lásárù tí òun fẹ́ràn gidigidi ti kú. Látọjọ́ mẹ́rin sẹ́yìn tí Lásárù ti kú, ni gbogbo nǹkan ti tójú sú Màtá, tí àwọn èèyàn ń bá a ṣọ̀fọ̀, táwọn àlejò ń rọ́ wá, tí wọ́n sì ń tù ú nínú.
Àmọ́ ní báyìí, Jésù tó jẹ́ ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ fún Lásárù wá sọ́dọ̀ Màtá. Ẹ̀dùn ọkàn Màtá túbọ̀ pọ̀ sí i nígbà tó rí Jésù, nítorí òun ni ẹnì kan ṣoṣo láyé yìí tí ì bá ti ṣe é kí Lásárù má ṣe kú. Síbẹ̀, Màtá rí ìtùnú díẹ̀ gbà bí Jésù ṣe wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní Bẹ́tánì, ìyẹn ìlú kékeré kan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè. Ní àkókò díẹ̀ tí Màtá lò pẹ̀lú Jésù, Màtá túra ká nítorí pé Jésù fi àánú hàn sí i, ó tún fi ìgbatẹnirò sọ̀rọ̀ ìṣírí fún un. Jésù bi Màtá láwọn ìbéèrè tó mú kó ronú lórí ìgbàgbọ́ rẹ̀ àti ohun tó gbà gbọ́ nípa àjíǹde. Ọ̀rọ̀ tó bá Màtá sọ mú kí Màtá sọ ọ̀kan lára ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ tó tíì sọ rí, ó ní: “Mo ti gbà gbọ́ pé ìwọ ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run, Ẹni tí ń bọ̀ wá sí ayé.”—Jòhánù 11:27.
Màtá jẹ́ obìnrin kan tó ní ìgbàgbọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ohun díẹ̀ tí Bíbélì sọ fún wa nípa rẹ̀ kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì táá mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára. Láti rí bí èyí ṣe rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká wo ibi tí Bíbélì ti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa Màtá.
“Ìwọ Ń Ṣàníyàn, O sì Ń Ṣèyọnu”
Ní nǹkan bí oṣù mélòó kan ṣáájú. Lásárù ṣì wà láàyè, ara rẹ̀ sì le. Jésù Kristi tó jẹ́ ẹni pàtàkì jù lọ láyé yìí, fẹ́ wá sí ilé Lásárù ní ìlú Bẹ́tánì. Lásárù, Màtá àti Màríà, jẹ́ ìdílé kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ọmọ ìyá làwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ́n sì ti dàgbà, àmọ́ ẹ̀rí fi hàn pé inú ilé kan náà ni wọ́n ń gbé. Àwọn kan tó máa ń ṣe ìwádìí sọ pé ó lè jẹ́ Màtá ló dàgbà jù lọ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, nítorí pé ó jọ pé òun ló gbàlejò náà, òun sì ni wọ́n kọ́kọ́ máa ń dárúkọ nígbà míì. (Jòhánù 11:5) Kò sí ẹ̀rí pé èyíkéyìí nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣègbéyàwó rí. Èyí ó wù kó jẹ́, wọ́n di ọ̀rẹ́ Jésù tímọ́tímọ́. Nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù ní ilẹ̀ Jùdíà, níbi tí àwọn èèyàn ti ta kò ó gan-an, tí wọ́n sì hàn án léèmọ̀, ilé wọn ló máa ń dé sí. Kò sí àní-àní pé Jésù mọyì ibi àlàáfíà tó máa ń dé sí yìí àti ìtìlẹ́yìn tó ń rí gbà níbẹ̀.
Màtá máa ń ṣe ohun púpọ̀ láti mú kí ilé wọn tu àwọn èèyàn lára. Ọwọ́ rẹ̀ máa ń dí, ó sì máa ń ṣiṣẹ́ kára, ó jọ pé bó ṣe ń kúrò lẹ́nu iṣẹ́ kan ló máa ń bọ́ sídìí òmíràn. Ohun kan náà ni Màtá ṣe nígbà tí Jésù wá kí wọn. Kò pẹ́ tó fi múra láti se oríṣiríṣi àkànṣe oúnjẹ fún àlejò pàtàkì náà àtàwọn kan lára àwọn tó bá a wá. Nígbà yẹn, wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú ṣíṣe àwọn èèyàn lálejò. Nígbà tí àlejò bá dé, wọ́n á fẹnu kò ó lẹ́nu, wọ́n á bọ́ bàtà rẹ̀, wọ́n á fi omi fọ ẹsẹ̀ rẹ̀, wọ́n á sì fi òróró onílọ́fínńdà pa orí rẹ̀. (Lúùkù 7:44-47) Wọ́n á pèsè oúnjẹ àti ibi tó dáa tó máa dé sí.
Màtá àti Màríà ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tí wọ́n máa ṣe láti bójú tó àlejò wọn pàtàkì yìí. Wọ́n sọ pé Màríà nígbà míì máa ń ronú jinlẹ̀, ó sì máa ń ṣaájò àwọn èèyàn ju arábìnrin rẹ̀ lọ, kò sí àní-àní pé Màríà ti ran arábìnrin rẹ̀ lọ́wọ́ kí àlejò wọn tó dé. Àmọ́ nígbà tí Jésù dé, nǹkan yí pa dà. Jésù ka àkókò náà sí àkókò láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, ó sì kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ lóòótọ́! Jésù kò dà bí àwọn olórí ìsìn ti ìgbà ayé rẹ̀, ó bọ̀wọ̀ fún àwọn obìnrin, ó sì kọ́ wọn nípa Ìjọba Ọlọ́run, ìjọba yìí ni ìwàásù rẹ̀ dá lé. Inú Màríà dùn gan-an sí àǹfààní tó ní yìí, ó jókòó níbi ẹsẹ̀ Jésù, ó sì ń gbọ́ ohun tí Jésù ń sọ.
A lè fojú inú wo ohun tí Màtá á máa rò lọ́kàn. Nítorí oríṣiríṣi oúnjẹ tó fẹ́ sè àti gbogbo iṣẹ́ tó máa ṣe láti tọ́jú àwọn àlejò rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn, ọkàn rẹ̀ sì pínyà. Bó ṣe ń lọ tó ń bọ̀, tó sì rí arábìnrin rẹ̀ tó jókòó tí kò ṣe nǹkan kan láti ran òun lọ́wọ́, ṣé ó bójú jẹ́, ṣé ó mí kanlẹ̀ hùn-ùn tàbí fajú ro? Kò ní yani lẹ́nu tó bá ṣe bẹ́ẹ̀. Kò lè dá ṣe gbogbo iṣẹ́ yẹn!
Nígbà tó yá, Màtá kò lè pá ọ̀ràn náà mọ́ra mọ́. Ó já lu ọ̀rọ̀ Jésù, ó ní: “Olúwa, kò ha jámọ́ nǹkan kan fún ọ pé arábìnrin mi ti fi èmi nìkan sílẹ̀ láti bójú tó àwọn nǹkan? Sọ fún un, nígbà náà, kí ó dara pọ̀ ní ríràn mí lọ́wọ́.” (Lúùkù 10:40) Àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ yìí le. Ìtúmọ̀ àwọn Bíbélì kan ti túmọ̀ ìbéèrè Màtá báyìí pé: “Olúwa, ṣé o kò bìkítà ni . . . ?” Lẹ́yìn náà, ó ní kí Jésù sọ fún Màríà pé kó pa dà sẹ́nu iṣẹ́.
Ìdáhùn Jésù ti lè ya Màtá lẹ́nu, bó ṣe ya ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń ka Bíbélì láti ìgbà tí ọ̀rọ̀ náà ti ṣẹlẹ̀ lẹ́nu. Jésù rọra sọ pé: “Màtá, Màtá, ìwọ ń ṣàníyàn, o sì ń ṣèyọnu nípa ohun púpọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, nǹkan díẹ̀ tàbí ẹyọ kan ṣoṣo ni a nílò. Ní tirẹ̀, Màríà yan ìpín rere, a kì yóò sì gbà á kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 10:41, 42) Kí ni Jésù ní lọ́kàn? Ṣé ohun tó ń sọ ni pé Màtá nífẹ̀ẹ́ ohun ìní tára ni? Ṣé ó ń sọ pé iṣẹ́ àṣekára tí Màtá ń ṣe láti gbọ́únjẹ aládùn kò wúlò ni?
Rárá o. Jésù rí i kedere pé ọkàn Màtá mọ́, ìfẹ́ tó ní sí àwọn èèyàn ló mú kó máa ṣe ohun tó ń ṣe. Síwájú sí i, Jésù kò sọ pé ṣíṣe àwọn èèyàn lálejò rẹpẹtẹ burú. Ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù lọ sí “àsè ìṣenilálejò rẹpẹtẹ” tí Mátíù ṣe nítorí rẹ̀. (Lúùkù 5:29) Àmọ́ nínú ọ̀ràn yìí, oúnjẹ tí Màtá ń ṣe kọ́ ni ìṣòro, àwọn ohun tí Màtá fi sí ipò àkọ́kọ́ ni ìṣòro náà. Oúnjẹ rẹpẹtẹ tó ń sè ló gbájú mọ́ títí tó fi gbàgbé ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ. Kí ni ohun náà?
Jésù Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Jèhófà Ọlọ́run wà nílé Màtá láti kọ́ wọn ní òtítọ́. Kò sí ohun tó lè ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ, oúnjẹ tó ń fìfẹ́ pèsè àtàwọn nǹkan míì tó ń ṣe pàápàá kò ṣe pàtàkì tó ìyẹn. Kò sí àní-àní pé inú Jésù kò dùn rárá pé Màtá ń pàdánù àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ tó ní yìí láti mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára sí i, ṣùgbọ́n ó jẹ́ kí Màtá yan ohun tó fẹ́. Àmọ́ ṣá o, kò yẹ kí Màtá ní kí Jésù sọ fún Màríà pé kó dìde kí Màríà náà tún pàdánù àǹfààní yẹn.
Nítorí náà, ó rọra tọ́ Màtá sọ́nà, ó sì pe orúkọ rẹ̀ lápètúnpè láti mú kí ara rẹ̀ wálẹ̀, ó mú kó dá a lójú pé kò sídìí láti ‘máa ṣàníyàn, kó sì máa ṣèyọnu nípa ohun púpọ̀.’ Oúnjẹ ráńpẹ́ kan tí kò ju oríṣi kan tàbí méjì lọ ti tó, pàápàá tó bá ti tó àkókò láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nítorí náà, Jésù kò ní gba “ìpín rere” tí Màríà ti yàn kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, ìyẹn ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ lọ́dọ̀ Jésù.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé Màtá yìí jẹ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ fún àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi lónìí. A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ bíbójútó “àìní [wa] nípa tẹ̀mí.” (Mátíù 5:3) Bí a ṣe fẹ́ máa tẹ̀ lẹ́ àpẹẹrẹ Màtá nínú ìwà ọ̀làwọ́ àti iṣẹ́ àṣekára, kò yẹ ká ‘máa ṣàníyàn, ká sì máa ṣèyọnu’ nípa ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì nígbà tá a bá ń ṣe àwọn èèyàn lálejò, ká má bàa pàdánù ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ. Kì í ṣe nítorí ká bàa lè fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ní oúnjẹ aládùn la ṣe ń gbà wọ́n lálejò kì í sì í ṣe torí ká lè rí irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ jẹ lọ́dọ̀ wọn la ṣe ń lọ kí wọn, àmọ́ ó jẹ́ nítorí ká lè fún ara wa ní ìṣírí, ká sì lè jọ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń gbéni ró. (Róòmù 1:11, 12) Ó lè jẹ́ pé oúnjẹ ráńpẹ́ la nílò nírú ìkórajọ tó ń gbéni ró yẹn.
Wọ́n Pàdánù Arákùnrin Tí Wọ́n Fẹ́ràn Gidigidi, Wọ́n sì Rí I Pa Dà
Ǹjẹ́ Màtá gba ìbáwí tó tuni lára tí Jésù fún un, kó sì kẹ́kọ̀ọ́ látinú rẹ̀? Kò yẹ ká máa ṣiyèméjì nípa ìyẹn. Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù bẹ̀rẹ̀ ìtàn alárinrin nípa Lásárù arákùnrin Màtá, ó sọ pé: “Wàyí o, Jésù nífẹ̀ẹ́ Màtá àti arábìnrin rẹ̀ àti Lásárù.” (Jòhánù 11:5) Oṣù mélòó kan ti kọjá látìgbà ìbẹ̀wò Jésù sí ìlú Bẹ́tánì, èyí tá a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lókè yìí. Ó hàn gbangba pé Màtá kò ní ìkùnsínú sí Jésù nítorí àmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tó fún Màtá. Ó fi àmọ̀ràn náà sọ́kàn. Nínú ọ̀ràn yìí bákan náà, Màtá fi àpẹẹrẹ tó dára jù lọ nípa ìgbàgbọ́ lélẹ̀ fún wa, nítorí, ta ni nínú wa ni kò nílò ìtọ́sọ́nà díẹ̀díẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan?
Nígbà tí arákùnrin Màtá ń ṣàìsàn, ó tẹra mọ́ títọ́jú rẹ̀. Ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti mú ìtura bá a kí ara rẹ̀ lè yá. Síbẹ̀, ńṣe ni àìsàn Lásárù ń le sí i. Bí wákàtí tí ń lọ, tí ọjọ́ ń gorí ọjọ́, àwọn arábìnrin rẹ̀ méjèèjì dúró tì í, wọ́n ń tọ́jú rẹ̀. Ẹ wo bí Màtá á ṣe máa wojú arákùnrin rẹ̀ tó ti joro, tó ń rántí ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti jọ wà, tó ń rántí àkókò ayọ̀ àti ìbànújẹ́ tí wọ́n ti jọ lò!
Nígbà tí Màtá àti Màríà rí i pé kò sí nǹkan táwọn lè ṣe láti ran Lásárù lọ́wọ́ mọ́, ni wọ́n bá ránṣẹ́ sí Jésù. Ibi tó ti ń wàásù jìnnà tó ìrìn àjò ọjọ́ méjì síbi tí wọ́n wà. Iṣẹ́ tí wọ́n rán sí Jésù ṣe kedere, wọ́n ní: “Olúwa, wò ó! ẹni tí ìwọ ní ìfẹ́ni fún ń ṣàìsàn.” (Jòhánù 11:1, 3) Wọ́n mọ̀ pé Jésù nífẹ̀ẹ́ arákùnrin wọn, wọ́n sì nígbàgbọ́ pé á ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ran ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́. Ǹjẹ́ wọ́n ṣì nírètí pé Jésù máa dé kó tó pẹ́ jù? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ìrètí wọ́n ti já sófo. Lásárù ti kú.
Màtá àti Màríà ń ṣọ̀fọ̀ arákùnrin wọn, wọ́n ń múra sílẹ̀ fún ìsìnkú rẹ̀, àwọn àlejò sì ń wá kí wọn láti Bẹ́tánì àti àgbègbè rẹ̀. Síbẹ̀, wọ́n kò gbọ́ nǹkan kan nípa Jésù. Bí àkókò ti ń lọ, ọ̀ràn náà túbọ̀ tojú sú Màtá. Níkẹyìn, Màtá gbọ́ pé Jésù ti sún mọ́ ìlú wọn, ìyẹn lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin tí Lásárù ti kú. Akínkanjú obìnrin ni Màtá, àní lákòókò yìí tí gbogbo nǹkan ti tojú sú u pàápàá, ó dìde, kò sọ fún Màríà, ó sì sáré jáde lọ pàdé Jésù.—Jòhánù 11:20.
Nígbà tí Màtá rí Ọ̀gá rẹ̀, ó sọ ohun tó ń dun òun àti Màríà láti ọjọ́ yẹn wá, ó ní: “Olúwa, ká ní o ti wà níhìn-ín ni, arákùnrin mi kì bá kú.” Síbẹ̀, ìrètí àti ìgbàgbọ́ tí Màtá ní ṣì lágbára. Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Síbẹ̀, nísinsìnyí mo mọ̀ pé gbogbo nǹkan tí o bá béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò fún ọ.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ Jésù sọ ohun kan tó fún ìrètí rẹ̀ lágbára, ó ní: “Arákùnrin rẹ yóò dìde.”—Jòhánù 11:21-23.
Màtá rò pé Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde ọjọ́ iwájú, nítorí náà, ó dáhùn pé: “Mo mọ̀ pé yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” (Jòhánù 11:24) Ìgbàgbọ́ tí Màtá ní nínú àjíǹde kàmàmà. Àwọn kan lára àwọn aṣáájú ìsìn Júù, tí wọ́n ń pè ní Sadusí sọ pé kò sí àjíǹde, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀kọ́ tó ṣe kedere yìí wà nínú Ìwé Mímọ́ tó ní ìmísí Ọlọ́run. (Dáníẹ́lì 12:13; Máàkù 12:18) Àmọ́, Màtá mọ̀ pé Jésù ti kọ́ni pé àwọn òkú máa jíǹde, ó tiẹ̀ ti jí àwọn òkú dìde pàápàá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ko tíì jí òkú tó pẹ́ bíi ti Lásárù dìde rí. Màtá kò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀.
Jésù wá sọ ọ̀rọ̀ mánigbàgbé kan, ó ní: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè.” Lóòótọ́, Jèhófà Ọlọrun ti fún Ọmọ rẹ̀ ní àṣẹ láti jí òkú dìde jákèjádò ayé lọ́jọ́ iwájú. Jésù bi Màtá pé: “Ìwọ ha gba èyí gbọ́ bí?” Nígbà náà ni Màtá sọ ìdáhùn tá a jíròrò níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Ó gbà gbọ́ pé Jésù ni Kristi tàbí Mèsáyà, pé Jésù ni Ọmọ Jèhófà Ọlọ́run àti pé àwọn wòlíì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa wá sí ayé.—Jòhánù 5:28, 29; 11:25-27.
Ṣé Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi fojú iyebíye wo irú ìgbàgbọ́ tí Màtá ní yẹn? Àwọn ohun tí Màtá rí lẹ́yìn náà dáhùn ìbéèrè yìí lọ́nà tó ṣe kedere jù lọ. Ó sáré lọ pe arábìnrin rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó rí i pé Jésù ní ẹ̀dùn ọkàn nígbà tó ń bá Màríà àti ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń bá a ṣọ̀fọ̀ sọ̀rọ̀. Ó rí i bí ẹ̀dùn ọkàn ṣe mú kí Jésù da omi lójú nítorí ìrora tí ikú máa ń fà. Ó gbọ́ nígbà tí Jésù sọ pé kí wọ́n yí òkúta kúrò lẹ́nu ibojì arákùnrin rẹ̀.—Jòhánù 11:28-39.
Ohun tó bọ́gbọ́n mú ni Màtá máa ń ṣe, nítorí náà, ó sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣí ibojì náà nítorí òkú náà ti pé ọjọ́ mẹ́rin, á sì ti máa rùn. Jésù rán an létí pé: “Èmi kò ha sọ fún ọ pé bí ìwọ bá gbà gbọ́, ìwọ yóò rí ògo Ọlọ́run?” Ó gbà gbọ́ lóòótọ́, ó sì rí ògo Jèhófà Ọlọ́run. Lójú ẹsẹ̀ níbẹ̀, Ọlọ́run fún Ọmọ rẹ̀ lágbára láti jí Lásárù dìde sí ìyè! Kíyè sí àwọn nǹkan tí Màtá kò ní gbàgbé títí gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀, àwọn ohun náà rèé: Bí Jésù ṣe pàṣẹ pé, “Lásárù jáde wá!”, ìró tó rọra ń dún nínú ibojì nígbà tí Lásárù dìde pẹ̀lú àwọn ọ̀já ìdìkú lára rẹ̀ tó sì rọra sún mọ́ ẹnu ilẹ̀kùn ibojì náà, àti àṣẹ tí Jésù pa pé, “ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ” àti ìdùnnú tó ṣubú lu ayọ̀ nígbà tí Màtá àti Màríà gbá Lásárù mọ́ra. (Jòhánù 11:40-44) Ìbànújẹ́ ọkàn Màtá fò lọ!
Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fi hàn pé àjíǹde àwọn òkú kì í ṣe àlá tí kò lè ṣẹ, pé ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń mú ọkàn ẹni yọ̀ ni àti pé, ó jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn òkú ti jíǹde láwọn ìgbà kan rí. Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ láti san èrè fún àwọn tó ní ìgbàgbọ́, bó ṣe san èrè fún, Màtá, Màríà àti Lásárù. Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ yóò fún ìwọ náà nírú èrè yìí tó o bá ní ìgbàgbọ́ tó lágbára bíi ti Màtá.a
‘Màtá Ń Ṣèránṣẹ́’
Bíbélì tún mẹ́nu kan Màtá lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó jẹ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ tí Jésù lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé. Bí Jésù ti mọ̀ dáadáa pé ìyà wà níwájú fún òun, ó tún yàn láti máa gbé ní ìlú Bẹ́tánì ní ibi àlàáfíà tó máa ń dé sí. Ó sì máa ń rin kìlómítà mẹ́ta láti ibẹ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù. Jésù àti Lásárù ń jẹun nílé Símónì adẹ́tẹ̀, ibẹ̀ ni a sì ti gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa Màtá kẹ́yìn pé: “Màtá sì ń ṣèránṣẹ́.”—Jòhánù 12:2.
Ẹ ò rí i pé òṣìṣẹ́kára ni obìnrin yìí lóòótọ́! Nígbà tá a kọ́kọ́ kà nípa rẹ̀ nínu Bíbélì, iṣẹ́ ló ń ṣe, nígbà tá a sì tún kà nípa rẹ̀ kẹ́yìn, iṣẹ́ ló ṣì ń ṣe, ó ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti tọ́jú àwọn tó wà láyìíká rẹ̀. Ìbùkún ńlá ló jẹ́ fún àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi lóde òní láti ní àwọn obìnrin tó dà bíi Màtá, tí wọ́n jẹ́ onígboyà àti ọ̀làwọ́, tí wọ́n ń fi ìgbàgbọ́ wọn hàn nípa ohun tí wọ́n ń ṣe fún àwọn èèyàn. Ìyẹn gan-an ló jọ pé Màtá ń ṣe. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, Màtá hùwà ọgbọ́n, nítorí pé àwọn ìṣòro kan ṣì máa dojú kọ ọ́.
Láàárín ọjọ́ mélòó kan, Màtá fara da ìbànújẹ́ ńláǹlà nítorí ikú Jésù Ọ̀gá rẹ̀ tó fẹ́ràn gidigidi. Bákan náà, àwọn apààyàn alágàbàgebè tí wọ́n pa Jésù tún fẹ́ pa Lásárù náà, nítorí pé àjíǹde Lásárù mú kí ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn túbọ̀ lágbára sí i. (Jòhánù 12:9-11) Àmọ́ níkẹyìn, ikú já okùn ìfẹ́ tó so Màtá àti àwọn ọmọ ìyá rẹ̀ pọ̀. A kò mọ ìgbà tó ṣẹlẹ̀ àti bó ṣe ṣẹlẹ̀, àmọ́ ohun tó dá wa lójú ni pé, Ìgbàgbọ́ tó ṣeyebíye tí Màtá ní ràn án lọ́wọ́ láti fara dà á dópin. Ìdí nìyẹn tó fi dára kí àwọn Kristẹni lóde òní máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Màtá.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti mọ̀ púpọ̀ sí i nípa ẹ̀kọ́ Bíbélì nípa àjíǹde, ka orí 7 ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Nígbà tí Màtá ń ṣọ̀fọ̀ pàápàá, ó jẹ́ kí Jésù tọ́ òun sọ́nà láti máa ronú lórí àwọn ohun tó lè fún ìgbàgbọ́ òun lókun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Màtá ‘ń ṣàníyàn tó sì ń ṣèyọnu,’ ó fìrẹ̀lẹ̀ gba ìtọ́sọ́nà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Nítorí ìgbàgbọ́ tí Màtá ní nínú Jésù, arákùnrin rẹ̀ jíǹde, ìyẹn sì ni èrè tó rí gbà