ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 12
Máa Gba Tàwọn Míì Rò
‘Kí gbogbo yín máa bára yín kẹ́dùn.’—1 PÉT. 3:8.
ORIN 90 Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Bó ṣe wà nínú 1 Pétérù 3:8, kí nìdí tó fi máa ń wù wá pé ká wà pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ wa tí wọ́n sì ń gba tiwa rò?
INÚ wa máa ń dùn tá a bá wà pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ wa tí wọ́n sì ń gba tiwa rò. Ìdí sì ni pé wọ́n máa ń fi ara wọn sí ipò wa kí wọ́n lè mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa àti bí nǹkan ṣe rí lára wa. Wọ́n máa ń fòye mọ ohun tá a nílò, ìgbà míì sì wà tí wọ́n máa ń pèsè ẹ̀ kódà ká tó béèrè. A máa ń mọyì àwọn tí ọ̀rọ̀ wa jẹ lọ́kàn tí wọ́n sì ń ‘bá wa kẹ́dùn.’b—Ka 1 Pétérù 3:8.
2. Kí nìdí tó fi yẹ ká sapá láti máa gba tàwọn míì rò?
2 Ó yẹ kí gbogbo àwa Kristẹni máa gba tàwọn míì rò. Àmọ́ ká sòótọ́, ó lè gba pé ká túbọ̀ sapá ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Ìdí kan ni pé aláìpé ni wá. (Róòmù 3:23) Torí pé aláìpé ni wá, tara wa nìkan la sábà máa ń rò. Yàtọ̀ síyẹn, kì í rọrùn fáwọn kan láti gba tàwọn míì rò torí bí wọ́n ṣe tọ́ wọn dàgbà tàbí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn rí. Ohun míì tún ni pé ìwà àwọn tó yí wa ká lè ràn wá. Bí àpẹẹrẹ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, wọn kì í gba tàwọn míì rò rárá. (2 Tím. 3:1, 2) Kí ló máa jẹ́ ká borí àwọn nǹkan yìí ká sì máa gba tàwọn míì rò?
3. (a) Kí lá jẹ́ ká túbọ̀ máa gba tàwọn míì rò? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Tá a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀, àá túbọ̀ mọ bá a ṣe lè máa gba tàwọn míì rò. Ọlọ́run ìfẹ́ ni Jèhófà, òun ló sì fi àpẹẹrẹ tó ga jù lọ lélẹ̀ tó bá di pé ká báni kẹ́dùn. (1 Jòh. 4:8) Jésù náà fìwà jọ Baba rẹ̀ láìkù síbì kan. (Jòh. 14:9) Nígbà tó wà láyé, ó jẹ́ ká rí bá a ṣe lè máa fàánú hàn sáwọn míì. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa kọ́kọ́ jíròrò bí Jèhófà àti Jésù ṣe máa ń gba tàwọn èèyàn rò. Lẹ́yìn náà, a máa wá sọ bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn.
BÍ JÈHÓFÀ ṢE GBA TÀWỌN MÍÌ RÒ
4. Báwo ni Àìsáyà 63:7-9 ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà jẹ ẹ́ lógún?
4 Bíbélì kọ́ wa pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo bó ṣe rí lára Jèhófà nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ ń jìyà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Nínú gbogbo ìdààmú wọn, ìdààmú bá òun náà.” (Ka Àìsáyà 63:7-9.) Nígbà tó yá, Jèhófà sọ nípasẹ̀ wòlíì Sekaráyà pé tí wọ́n bá ń fìyà jẹ àwọn èèyàn òun, ṣe ló máa ń dà bíi pé òun ni wọ́n ń fìyà jẹ. Ó ní: “Ẹni tó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.” (Sek. 2:8) Ohun tí Jèhófà sọ yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ jẹ ẹ́ lọ́kàn gan-an.
5. Sọ àpẹẹrẹ kan nípa bí Jèhófà ṣe gbé ìgbésẹ̀ láti ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ń jìyà lọ́wọ́.
5 Kì í ṣe pé àánú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń ṣe é nìkan ni, ó tún máa ń gbé ìgbésẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jìyà ní Íjíbítì, Jèhófà mọ bí ìyà tí wọ́n ń jẹ ṣe rí lára wọn débi pé ó gbé ìgbésẹ̀ láti dá wọn sílẹ̀. Ó sọ fún Mósè pé: “Mo ti rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn mi . . . , mo sì ti gbọ́ igbe wọn . . . mo mọ̀ dáadáa pé wọ́n ń jẹ̀rora. Màá lọ gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì.” (Ẹ́kís. 3:7, 8) Àánú tí Jèhófà ní ló mú kó dá àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ lóko ẹrú. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, àìmọye ìgbà làwọn ọ̀tá gbéjà kò wọ́n. Kí ni Jèhófà wá ṣe? Bíbélì sọ pé: “Jèhófà ṣàánú wọn torí pé àwọn tó ń ni wọ́n lára àtàwọn tó ń fìyà jẹ wọ́n mú kí wọ́n máa kérora.” Torí pé Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe rí lára àwọn èèyàn rẹ̀, ó ràn wọ́n lọ́wọ́, ó sì lo àwọn onídàájọ́ láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.—Oníd. 2:16, 18.
6. Sọ bí Jèhófà ṣe gba ti Jónà rò bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò ronú lọ́nà tó tọ́.
6 Jèhófà máa ń gba tàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ rò, kódà tí wọn ò bá tiẹ̀ ronú lọ́nà tó tọ́. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jónà. Ọlọ́run rán wòlíì yìí pé kó lọ kéde ìdájọ́ sórí àwọn ará ìlú Nínéfè. Nígbà táwọn èèyàn náà gbọ́ ìkéde yìí, wọ́n yí pa dà, Ọlọ́run sì pinnu pé òun ò ní pa wọ́n run. Àmọ́, inú Jónà ò dùn sí ohun tí Jèhófà ṣe yẹn rárá. Kódà, ‘inú bí i gan-an’ torí pé ìparun tó sọ tẹ́lẹ̀ kò nímùúṣẹ. Síbẹ̀, Jèhófà mú sùúrù fún Jónà, ó sì ràn án lọ́wọ́ kó lè tún èrò rẹ̀ ṣe. (Jónà 3:10–4:11) Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Jónà lóye ìdí tí Jèhófà ò fi pa ìlú yẹn run, nígbà tó sì yá, Jèhófà ní kó kọ ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn sílẹ̀ fún àǹfààní wa.—Róòmù 15:4.c
7. Tá a bá ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò nígbà àtijọ́, ìdánilójú wo nìyẹn máa ń mú ká ní?
7 Bí Jèhófà ṣe bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò láyé àtijọ́ jẹ́ kó dá wa lójú pé ó máa ń gba tàwa ìránṣẹ́ rẹ̀ rò. Ó mọ ibi tí bàtà ti ń ta kálukú lẹ́sẹ̀. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà mọ ohun tó ń da ọkàn wa láàmú. (2 Kíró. 6:30) Ó mọ àwọn ohun tó ń gbé wa lọ́kàn sókè, bí nǹkan ṣe rí lára wa àti ibi tá a kù sí. Yàtọ̀ síyẹn, kò “ní jẹ́ kí a dán [wa] wò kọjá ohun tí [a] lè mú mọ́ra.” (1 Kọ́r. 10:13) Àwọn ọ̀rọ̀ yìí mà tuni nínú o!
BÍ JÉSÙ ṢE GBA TÀWỌN MÍÌ RÒ
8-10. Àwọn nǹkan wo ló mú kí Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn kó sì gba tiwọn rò?
8 Nígbà tí Jésù wà láyé, ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ ẹ́ lọ́kàn gan-an. Ó kéré tán, ohun mẹ́ta ló mú kí Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn kó sì máa gba tiwọn rò. Ohun àkọ́kọ́ ni pé Jésù fìwà jọ Baba rẹ̀ láìkù síbì kan. Bíi ti Jèhófà, Jésù náà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo nǹkan tí Jèhófà tipasẹ̀ rẹ̀ dá ló fẹ́ràn, síbẹ̀ Jésù “fẹ́ràn àwọn ọmọ èèyàn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.” (Òwe 8:31) Ìfẹ́ ló mú kí ọ̀rọ̀ àwọn míì jẹ Jésù lọ́kàn.
9 Ohun kejì ni pé bíi ti Jèhófà, Jésù náà lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwa èèyàn. Ó lè mọ ohun tó ń sún wa ṣe nǹkan àti bí nǹkan ṣe ń rí lára wa. (Mát. 9:4; Jòh. 13:10, 11) Torí náà, tí Jésù bá fòye mọ̀ pé ẹnì kan ní ìdààmú ọkàn, ìfẹ́ máa ń mú kó tù ú nínú.—Àìsá. 61:1, 2; Lúùkù 4:17-21.
10 Ohun kẹta ni pé Jésù fúnra rẹ̀ kojú àwọn ìṣòro kan náà táwa èèyàn máa ń ní. Bí àpẹẹrẹ, inú ìdílé tí wọn ò ti fi bẹ́ẹ̀ rí jájẹ ni Jésù dàgbà sí, iṣẹ́ alágbára tó sì ń tánni lókun ni Jésù kọ́ lọ́dọ̀ Jósẹ́fù tó jẹ́ alágbàtọ́ rẹ̀. (Mát. 13:55; Máàkù 6:3) Ó jọ pé Jósẹ́fù kú kí Jésù tó parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé Jésù náà mọ bó ṣe máa ń rí lára téèyàn ẹni bá kú. Yàtọ̀ síyẹn, Jésù tún mọ bó ṣe máa ń rí téèyàn bá ń gbé nínú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. (Jòh. 7:5) Ó dájú pé àwọn nǹkan tí Jésù kojú yìí á jẹ́ kó lóye ohun tójú àwọn èèyàn ń rí àti bí nǹkan ṣe ń rí lára wọn.
11. Àwọn nǹkan wo ló jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere pé Jésù mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwa èèyàn? Ṣàlàyé. (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
11 Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ kó túbọ̀ ṣe kedere pé Jésù mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwa èèyàn. Kì í ṣe torí pé ó pọn dandan fún Jésù láti ṣe iṣẹ́ ìyanu ló fi ń ṣe é. Dípò bẹ́ẹ̀, àánú àwọn tó ń jìyà ló máa ń ṣe é, á sì ràn wọ́n lọ́wọ́. (Mát. 20:29-34; Máàkù 1:40-42) Bí àpẹẹrẹ, ó mú ọkùnrin adití kan kúrò láàárín èrò, ó sì wò ó sàn. Yàtọ̀ síyẹn, ó jí ọmọ kan ṣoṣo tí opó kan ní dìde. (Máàkù 7:32-35; Lúùkù 7:12-15) Kò sí àní-àní pé Jésù bá wọn kẹ́dùn, ìdí nìyẹn tó fi ràn wọ́n lọ́wọ́.
12. Bó ṣe wà nínú Jòhánù 11:32-35, kí ni Jésù ṣe tó fi hàn pé ó mọ bí nǹkan ṣe rí lára Màtá àti Màríà?
12 Jésù fi hàn pé òun mọ bí nǹkan ṣe rí lára Màtá àti Màríà. Nígbà tí Jésù rí bí wọ́n ṣe ń ṣọ̀fọ̀ Lásárù arákùnrin wọn tó kú, ṣe ló “bẹ̀rẹ̀ sí í da omi lójú.” (Ka Jòhánù 11:32-35.) Kì í ṣe torí pé ó ń ṣàárò ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló ṣe ń sunkún. Ó ṣe tán, ó mọ̀ pé òun máa jí i dìde. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìdí tí Jésù fi sunkún ni pé ó mọ bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe dun Màtá àti Màríà tó.
13. Kí nìdí tí inú wa fi dùn pé Jésù máa ń bá àwa èèyàn kẹ́dùn?
13 Inú wa dùn gan-an bá a ṣe mọ̀ pé Jésù máa ń bá àwọn èèyàn kẹ́dùn torí ó mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì í ṣe ẹni pípé bíi Jésù, síbẹ̀ a mọyì bó ṣe fìfẹ́ bá àwọn míì lò. (1 Pét. 1:8) Inú wa dùn pé òun ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó sì ti ń ṣàkóso báyìí. Láìpẹ́, ó máa fòpin sí gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé. Torí pé Jésù ti gbé lórí ilẹ̀ ayé rí tó sì ti fara da onírúurú ìṣòro, òun ló wà ní ipò tó dáa jù láti gba aráyé là kúrò nínú wàhálà tí Sátánì dà sí wa lágbada. A mà dúpẹ́ o pé a ní Ọba tó “lè bá wa kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa.”—Héb. 2:17, 18; 4:15, 16.
TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ JÈHÓFÀ ÀTI JÉSÙ
14. Bó ṣe wà nínú Éfésù 5:1, 2, kí la máa ṣe tá a bá ń ronú nípa àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù?
14 Tá a bá ń ronú nípa àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù, á wù wá pé ká máa gba tàwọn míì rò ká sì máa bá wọn kẹ́dùn. (Ka Éfésù 5:1, 2.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè rí ohun tó wà lọ́kàn àwọn míì, síbẹ̀ a lè fòye mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn àti ohun tí wọ́n nílò. (2 Kọ́r. 11:29) Òótọ́ ni pé àwọn tí kò mọ̀ ju tara wọn nìkan ló kúnnú ayé yìí, àmọ́ ní tiwa a máa ń sapá láti “wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe [tiwa] nìkan.”—Fílí. 2:4.
15. Àwọn wo ní pàtàkì ló yẹ kó máa gba tàwọn míì rò?
15 Ó ṣe pàtàkì gan-an káwọn alàgbà lẹ́mìí ìgbatẹnirò. Ìdí ni pé wọ́n máa jíhìn fún Jèhófà nípa bí wọ́n ṣe bójú tó àwọn àgùntàn tó fi síkàáwọ́ wọn. (Héb. 13:17) Kí àwọn alàgbà tó lè ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn lọ́wọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ máa gba tiwọn rò. Báwo ni wọ́n ṣe lè ṣe é?
16. Kí làwọn alàgbà tó lẹ́mìí ìgbatẹnirò máa ń ṣe? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?
16 Alàgbà tó ń báni kẹ́dùn tó sì ń gba tàwọn ará rò máa ń lo àkókò pẹ̀lú wọn. Ó máa ń béèrè bí nǹkan ṣe ń lọ, ó sì máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn. Ìyẹn ṣe pàtàkì gan-an tí ẹnì kan nínú ìjọ bá fẹ́ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ àmọ́ tí kò mọ bó ṣe fẹ́ sọ ọ́. (Òwe 20:5) Tí alàgbà kan bá ń lo àkókò pẹ̀lú àwọn ará, àwọn ará á fọkàn tán an, wọ́n á nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, àjọṣe tó wà láàárín wọn á sì túbọ̀ gún régé.—Ìṣe 20:37.
17. Ànímọ́ wo làwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin sọ pé ó ṣe pàtàkì jù káwọn alàgbà ní? Sọ àpẹẹrẹ kan.
17 Ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló sọ pé ànímọ́ táwọn fẹ́ràn jù lára àwọn alàgbà ni bí wọ́n ṣe ń báni kẹ́dùn tí wọ́n sì ń gba tẹni rò. Kí nìdí tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀? Arábìnrin Adelaide sọ pé: “Ó rọrùn láti bá wọn sọ̀rọ̀ torí mo mọ̀ pé ọ̀rọ̀ mi máa yé wọn. Bí wọ́n ṣe ń fèsì jẹ́ kí n mọ̀ pé wọ́n lóye bí nǹkan ṣe rí lára mi.” Arákùnrin kan tó mọyì ohun tí alàgbà kan ṣe fún un sọ pé: “Mo rí i pé omi lé ròrò sí i lójú nígbà tí mò ń sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi. Mi ò lè gbàgbé ọjọ́ yẹn láé.”—Róòmù 12:15.
18. Kí lá jẹ́ ká lẹ́mìí ìgbatẹnirò?
18 Àwọn alàgbà nìkan kọ́ ló yẹ kó lẹ́mìí ìgbatẹnirò. Gbogbo wa ló yẹ ká máa gba tàwọn míì rò. Ọ̀nà wo la lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Gbìyànjú láti mọ ohun táwọn tó wà nínú ìdílé rẹ ń kojú àti ìṣòro táwọn ará ìjọ ń bá yí. Yàtọ̀ síyẹn, kó àwọn ọ̀dọ́ mọ́ra, títí kan àwọn tó ń ṣàìsàn, àwọn àgbàlagbà àtàwọn tó ti pàdánù àwọn èèyàn wọn. Máa béèrè bí nǹkan ṣe ń lọ sí, kó o sì fara balẹ̀ tẹ́tí sí ohun tí wọ́n bá sọ. Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o lóye ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn, kó o sì ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń fi hàn pé ìfẹ́ tá a ní sí wọn kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán.—1 Jòh. 3:18.
19. Kí nìdí tó fi yẹ ká lo ìfòyemọ̀ tá a bá fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́?
19 Ó yẹ ká máa lo ìfòyemọ̀ tá a bá fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun táwọn èèyàn máa ń ṣe tí wọ́n bá ń kojú ìṣòro máa ń yàtọ̀ síra. Ó máa ń yá àwọn kan lára láti sọ̀rọ̀, àmọ́ àwọn míì kì í fẹ́ sọ ohun tó ń ṣe wọ́n fún ẹlòmíì. Lóòótọ́ a fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́, síbẹ̀ a ò gbọ́dọ̀ tojú bọ ọ̀rọ̀ wọn tàbí ká máa béèrè àwọn ìbéèrè tó lè kó ìtìjú bá wọn. (1 Tẹs. 4:11) Kódà táwọn míì bá tiẹ̀ sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fún wa, a lè má fara mọ́ èrò wọn. Síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé bó ṣe rí lára wọn ni wọ́n ṣe sọ ọ́ yẹn. Torí náà, ó yẹ ká yára láti gbọ́rọ̀, ká sì lọ́ra láti sọ̀rọ̀.—Mát. 7:1; Jém. 1:19.
20. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
20 Kì í ṣe inú ìjọ nìkan ló yẹ ká ti máa gba tàwọn èèyàn rò, ó tún yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ lóde ẹ̀rí. Báwo la ṣe lè fi ànímọ́ yìí hàn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
ORIN 130 Ẹ Máa Dárí Jini
a Ọ̀rọ̀ wa jẹ Jèhófà àti Jésù lọ́kàn, wọ́n sì máa ń gba tiwa rò. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ohun tá a lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ wọn. A tún máa sọ ìdí tó fi yẹ ká máa gba tàwọn míì rò àti bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀.
b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Tá a bá sọ pé ẹnì kan ń ‘báni kẹ́dùn,’ ó túmọ̀ sí pé ó ń sapá láti fi ara ẹ̀ sípò àwọn míì kó lè mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn. (Róòmù 12:15) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, ohun kan náà ni ká ‘báni kẹ́dùn’ àti ká gba tẹni rò túmọ̀ sí.
c Jèhófà tún fàánú hàn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ míì tó ní ìdààmú ọkàn. Lára wọn ni Hánà (1 Sám. 1:10-20), Èlíjà (1 Ọba 19:1-18) àti Ebedi-mélékì (Jer. 38:7-13; 39:15-18).
d ÀWÒRÁN: A máa ń láǹfààní láti ran àwọn ará lọ́wọ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. (1) Alàgbà kan ń bá ọ̀dọ́ kan àti ìyá rẹ̀ sọ̀rọ̀, (2) bàbá kan àti ọmọ rẹ̀ ń ran màmá àgbàlagbà kan lọ́wọ́ láti wọnú mọ́tò, (3) àwọn alàgbà méjì ń bá arábìnrin kan tó nílò ìtọ́sọ́nà sọ̀rọ̀.