Ẹ Máa Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Tí Jésù Fi Lélẹ̀
“Mo fi àwòṣe lélẹ̀ fún yín, pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fún yín, ni kí ẹ máa ṣe pẹ̀lú.”—JÒHÁNÙ 13:15.
1. Kí nìdí tí Jésù fi jẹ́ àpẹẹrẹ tó dára fáwọn Kristẹni láti fara wé?
NÍNÚ gbogbo èèyàn pátá, ẹnì kan ṣoṣo ni kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan látìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ títí dópin. Jésù ni ẹni náà. Yàtọ̀ sí Jésù, “kò sí ènìyàn tí kì í dẹ́ṣẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 8:46; Róòmù 3:23) Ìdí nìyẹn táwọn ojúlówó Kristẹni fi gbà pé Jésù ni àpẹẹrẹ pípé tó yẹ káwọn máa fara wé. Kódà, nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù kú ní Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ó fúnra rẹ̀ sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa fara wé òun. Ó sọ pé: “Mo fi àwòṣe lélẹ̀ fún yín, pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fún yín, ni kí ẹ máa ṣe pẹ̀lú.” (Jòhánù 13:15) Ní alẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn yẹn, ó mẹ́nu kan àwọn ọ̀nà tó yẹ káwọn Kristẹni gbà máa fara wé òun. A ó gbé díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà náà yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí.
Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Ní Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀
2, 3. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ àpẹẹrẹ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó yẹ ká máa tẹ̀ lé?
2 Nígbà tí Jésù sọ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa fara wé àpẹẹrẹ tóun fi lélẹ̀, ọ̀rọ̀ nípa ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ló ń sọ ní pàtó. Kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan kì í ṣe ẹ̀ẹ̀méjì tó ti gba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Nígbà tó sì di alẹ́ Nísàn 14, ó tún fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí òun fúnra rẹ̀ ní hàn nípa wíwẹ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Jésù wá sọ fún wọn pé: “Bí èmi, tí ó tilẹ̀ jẹ́ Olúwa àti Olùkọ́, bá wẹ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa wẹ ẹsẹ̀ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (Jòhánù 13:14) Ó wá sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé kí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ òun. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ga nìyẹn!
3 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún wa pé kí Jésù tó wá sí ayé, ó “ní ìrísí Ọlọ́run.” Síbẹ̀, ó sọ̀ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì di ènìyàn. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ó tún “rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró.” (Fílípì 2:6-8) Ẹ jẹ́ ká ronú lórí ìyẹn díẹ̀ ná. Lẹ́yìn Ọlọ́run, Jésù lẹni tó tún ga jù lọ láyé àti lọ́run, síbẹ̀ ó gbà láti di ẹni tó rẹlẹ̀ ju àwọn áńgẹ́lì lọ, ó sì gbà kí wọ́n bí òun ní ọmọ ọwọ́ jòjòló, ó bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà ó sì ń ṣègbọràn sáwọn òbí rẹ̀ tó jẹ́ èèyàn aláìpé, nígbà tó sì yá ó kú bí ọ̀daràn lásánlàsàn. (Kólósè 1:15, 16; Hébérù 2:6, 7) Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yẹn mà ga o! Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti ní irú “ẹ̀mí ìrònú” yẹn ká sì tún ní irú “ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú” bẹ́ẹ̀? (Fílípì 2:3-5) Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe, àmọ́ kò rọrùn.
4. Kí làwọn nǹkan tó máa ń mú káwọn èèyàn gbéra ga, kí sì nídìí tí ìgbéraga fi léwu?
4 Òdìkejì ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ni ìgbéraga. (Òwe 6:16-19) Ìgbéraga ló mú kí Sátánì ṣubú. (1 Tímótì 3:6) Ẹ̀mí ìgbéraga yìí kì í sì í pẹ́ ta gbòǹgbò nínú ọkàn èèyàn, tó bá sì ti lè ta gbòǹgbò, kì í rọrùn láti fà tu. Àwọn èèyàn máa ń gbéra ga nítorí irú orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá, irú ẹ̀yà tí wọ́n jẹ́, ọrọ̀ tí wọ́n ní, bí wọ́n ṣe kàwé tó, àwọn ohun tí wọ́n gbé ṣe, ipò tí wọ́n wà láwùjọ, ìrísí wọn, eré ìdárayá tí wọ́n lè ṣe àti ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn. Síbẹ̀, kò sí èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan wọ̀nyẹn tó ṣe pàtàkì lójú Jèhófà. (1 Kọ́ríńtì 4:7) Bí àwọn nǹkan wọ̀nyẹn bá sì sọ wá di agbéraga, àárín àwa àti Jèhófà bà jẹ́ nìyẹn. “Jèhófà ga, síbẹ̀síbẹ̀, ó ń rí onírẹ̀lẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbé ara rẹ̀ ga fíofío ni òun mọ̀ kìkì láti òkèèrè.”—Sáàmù 138:6; Òwe 8:13.
Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Láàárín Àwọn Arákùnrin Wa
5. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn alàgbà jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?
5 Kò yẹ ká jẹ́ kí ipa tá à ń kó nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà àtàwọn àṣeyọrí tá a ní nínú iṣẹ́ ìsìn náà sọ wá di agbéraga rárá bẹ́ẹ̀ ni kò sì yẹ ká máa yangàn nítorí ipò tá a dì mú nínú ìjọ. (1 Kíróníkà 29:14; 1 Tímótì 6:17, 18) Ká sòótọ́, bí iṣẹ́ tá à ń bójú tó nínú ìjọ bá ṣe pọ̀ tó ló ṣe yẹ ká túbọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tó. Àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn alàgbà níyànjú pé kí wọ́n má máa “jẹ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run lórí, ṣùgbọ́n kí [wọ́n] di àpẹẹrẹ fún agbo.” (1 Pétérù 5:3) Ńṣe la yan àwọn alàgbà láti jẹ́ ìránṣẹ́ àti àpẹẹrẹ fún ìjọ, kì í ṣe pé kí wọ́n wá sọ ara wọn di olúwa àti ọ̀gá lé ìjọ lórí.—Lúùkù 22:24-26; 2 Kọ́ríńtì 1:24.
6. Àwọn ibo la ti nílò ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bí Kristẹni?
6 Kì í ṣe àwọn alàgbà nìkan ló yẹ kó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ o. Pétérù kọ̀wé sáwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n lè máa yangàn nítorí pé wọ́n máa ń tètè lóye nǹkan àti nítorí pé ara wọn le ju tàwọn àgbà lọ, ó ní: “Ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú di ara yín lámùrè sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” (1 Pétérù 5:5) Bẹ́ẹ̀ ni o, ó ṣe pàtàkì kí gbogbo wa ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Kristi. Èèyàn gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kó tó lè wàásù ìhìn rere náà, àgàgà nígbà tá a bá pàdé àwọn tí ò fẹ́ gbọ́ ìwàásù rárá àtàwọn tó ń ta ko iṣẹ́ wa. A tún gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ká tó lè gbàmọ̀ràn ká sì tó lè ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ìwọnba ohun tá a ní, ká lè túbọ̀ ráyè kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Láfikún sí i, a nílò ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, ìgboyà àti ìgbàgbọ́, ká lè ní ìfaradà nígbà táwọn èèyàn bá gbé ìròyìn èké jáde nípa wa, tàbí nígbà tí wọ́n bá fòfin de iṣẹ́ wa, tàbí tí wọ́n ṣe inúnibíni líle koko sí wa.—1 Pétérù 5:6.
7, 8. Báwo la ṣe lè dẹni tó ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀?
7 Báwo lẹnì kan ṣe lè borí ẹ̀mí ìgbéraga, kó sì máa hùwà “pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí [ó] máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù” òun lọ. (Fílípì 2:3) Ojú tí Jèhófà fi ń wo onítọ̀hún ló yẹ kó máa fi wo ara rẹ̀. Jésù ṣàlàyé irú ẹ̀mí tó yẹ kírú ẹni bẹ́ẹ̀ ní nígbà tó sọ pé: “Bákan náà ni ẹ̀yin, pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá ti ṣe gbogbo ohun tí a yàn lé yín lọ́wọ́ tán, ẹ wí pé, ‘Àwa jẹ́ ẹrú tí kò dára fún ohunkóhun. Ohun tí ó yẹ kí a ṣe ni a ṣe.’” (Lúùkù 17:10) Ẹ rántí pé kò sóhun tá a lè ṣe tó lè tó èyí tí Jésù ṣe. Síbẹ̀, Jésù lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀.
8 Síwájú sí i, a tún lè sọ pé kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe jọ ara wa lójú jù. A lè gbàdúrà bíi ti onísáàmù nì, tó sọ pé: “Kọ́ mi ní ìwà rere, ìlóyenínú àti ìmọ̀ pàápàá, nítorí pé mo ti lo ìgbàgbọ́ nínú àwọn àṣẹ rẹ.” (Sáàmù 119:66) Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe jọ ara wa lójú, yóò sì bù kún wa nítorí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tá a ní. (Òwe 18:12) Jésù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó rẹ̀ sílẹ̀, ẹnì yòówù tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga.”—Mátíù 23:12.
Ojú Tó Yẹ Ká Máa Fi Wo Ohun Tó Tọ́ Àtèyí Tí Kò Tọ́
9. Ojú wo ni Jésù fi wo ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́?
9 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé odindi ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ni Jésù fi gbé láàárín àwọn èèyàn aláìpé, síbẹ̀ “kò ní ẹ̀ṣẹ̀.” (Hébérù 4:15) Àní, nígbà tí onísáàmù náà ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà, ó sọ pé: “Ìwọ nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà àìlófin.” (Sáàmù 45:7; Hébérù 1:9) Àwọn Kristẹni ń sapá láti fara wé Jésù nínú èyí pẹ̀lú. Kì í ṣe pé wọ́n mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́ nìkan ni, wọ́n tún kórìíra ohun tí kò tọ́ wọ́n sì fẹ́ràn ohun tó tọ́. (Ámósì 5:15) Èyí ló ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbógun ti ẹ̀ṣẹ̀ tá a bí mọ́ wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 8:21; Róòmù 7:21-25.
10. Tá a bá ń ṣe “ohun búburú” láìronúpìwàdà, irú ẹ̀mí wo là ń fi hàn yẹn?
10 Jésù sọ fún Nikodémù tó jẹ́ Farisí pé: “Ẹni tí ó bá ń fi ohun búburú ṣe ìwà hù kórìíra ìmọ́lẹ̀, kì í sì í wá sínú ìmọ́lẹ̀, kí a má bàa fi ìbáwí tọ́ iṣẹ́ rẹ̀ sọ́nà. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe nǹkan tí ó jẹ́ òótọ́ máa ń wá sínú ìmọ́lẹ̀, kí a bàa lè fi àwọn iṣẹ́ rẹ̀ hàn kedere gẹ́gẹ́ bí èyí tí a ti ṣe ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run.” (Jòhánù 3:20, 21) Ìwọ wò ó ná: Jòhánù sọ pé Jésù ni “ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ tí ń fi ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo onírúurú ènìyàn.” (Jòhánù 1:9, 10) Síbẹ̀, Jésù sọ pé tá a bá ń fi “ohun búburú” ṣèwà hù, ìyẹn tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan tí kò tọ́, tí inú Ọlọ́run ò dùn sí, a jẹ́ pé a kórìíra ìmọ́lẹ̀ nìyẹn. Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣeé gbọ́ pé èèyàn kórìíra Jésù àtàwọn ìlànà rẹ̀? Síbẹ̀, ohun táwọn tó ń dá ẹ̀ṣẹ̀ láìronúpìwàdà ń ṣe nìyẹn. Bóyá wọn ò mọ̀ pé ohun tí ìwà àwọn ń fi hàn nìyẹn, àmọ́ Jésù gbà pé ńṣe ni wọ́n kórìíra òun àtàwọn ìlànà òun.
Bá A Ṣe Lè Ní Irú Èrò Tí Jésù Ní Nípa Ohun Tó Tọ́ Àtèyí Tí Kò Tọ́
11. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ ní irú èrò tí Jésù ní nípa ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́?
11 Ó yẹ ká túbọ̀ lóye ohun tí Jèhófà sọ pé ó tọ́ àtèyí tó sọ pé kò tọ́. Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nìkan la lè fi ní irú òye yẹn. Tá a bá sì fẹ́ bẹ̀rẹ̀ irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀, a ní láti gbàdúrà bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà; kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ.” (Sáàmù 25:4) Àmọ́ ṣá o, ẹ rántí pé ẹlẹ̀tàn ni Sátánì. (2 Kọ́ríńtì 11:14) Ó lè jẹ́ kí ohun tí kò tọ́ dà bí èyí tó tọ́ lójú Kristẹni tí kò bá fura. Nítorí náà, a ní láti máa ṣe àṣàrò tó jinlẹ̀ lórí ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ ká sì máa fi ìmọ̀ràn “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” sílò. (Mátíù 24:45-47) Ìkẹ́kọ̀ọ́, àdúrà gbígbà, àti ṣíṣe àṣàrò lórí àwọn ohun tá à ń kọ́ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dàgbà dénú ká sì wà lára àwọn tí wọ́n “tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:14) Ìgbà yẹn la máa lè kórìíra ohun tí kò tọ́ tí a óò sì fẹ́ràn ohun tó tọ́.
12. Ìmọ̀ràn Bíbélì wo ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ohun tí kò tọ́?
12 Tá a bá kórìíra ohun tí kò tọ́, a ò ní gba èròkérò láyè nínú ọkàn wa. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ikú Jésù, àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ ayé, ìfẹ́ fún Baba kò sí nínú rẹ̀; nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé.”—1 Jòhánù 2:15, 16.
13, 14. (a) Kí nìdí tó fi léwu táwọn Kristẹni bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé? (b) Báwo la ṣe lè yẹra fún nínífẹ̀ẹ́ àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé?
13 Àwọn kan lè ronú pé kì í ṣe gbogbo ohun tó wà nínú ayé ló burú. Bó tiẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká mọ̀ pé ayé àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ lè pín ọkàn wa níyà nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà. Kò sì sí nǹkan kan nínú ayé yìí tó lè mú kéèyàn túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Nítorí náà, tá a bá lọ nífẹ̀ẹ́ àwọn ohun tí ń bẹ̀ nínú ayé, bí àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ò tiẹ̀ burú, ọ̀nà tó léwu là ń tọ̀ yẹn o. (1 Tímótì 6:9, 10) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ohun tó wà nínú ayé ló burú, tó sì lè sọni dìbàjẹ́. Tá a bá ń wo sinimá tàbí àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n tó ń fi ìwà ipá, ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, tàbí ìṣekúṣe hàn, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ràn àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ká sì fẹ́ máa fi wọ́n ṣèwà hù. Tó bá jẹ́ pé àwọn tí kì í ronú nǹkan míì ju bí ohun ìní wọn ṣe máa pọ̀ sí i tàbí bí wọ́n ṣe máa rí iṣẹ́ tó ń mówó ńlá wọlé ṣe là ń bá kẹ́gbẹ́, àwa náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ló ṣe pàtàkì jù.—Mátíù 6:24; 1 Kọ́ríńtì 15:33.
14 Àmọ́, tí inú wa bá ń dùn sí Ọ̀rọ̀ Jèhófà, a ó kórìíra “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.” Ìyẹn nìkan kọ́ o, tá a bá ń bá àwọn tó fi ire Ìjọba Ọlọ́run ṣáájú nínú ìgbésí ayé wọn kẹ́gbẹ́, a óò dà bíi wọn, a óò fẹ́ràn ohun tí wọ́n fẹ́ràn, a óò sì yẹra fún ohun tí wọ́n yẹra fún.—Sáàmù 15:4; Òwe 13:20.
15. Báwo ni nínífẹ̀ẹ́ òdodo àti kíkórìíra ìwà ta-ni-yóò-mú-mi ṣe lè fún wa lókun láti ṣèfẹ́ Ọlọ́run bíi ti Jésù?
15 Nítorí pé Jésù kórìíra ìwà ta-ni-yóò-mú-mi ó sì nífẹ̀ẹ́ òdodo ló jẹ́ kó lè fọkàn sí “ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀.” (Hébérù 12:2) Àwa náà lè ṣe bíi tirẹ̀. A mọ̀ pé “ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.” Adùn èyíkéyìí téèyàn bá rí nínú ayé yìí kò lè tọ́jọ́ rárá. Àmọ́, “ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:17) Nítorí pé Jésù ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá ènìyàn láti jèrè ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú. (1 Jòhánù 5:13) Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa fara wé e, ká lè jàǹfààní oore ńlá tó ṣe fún wa yìí.
Fífarada Inúnibíni
16. Kí nìdí tí Jésù fi rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn?
16 Jésù tún mẹ́nu kan ọ̀nà mìíràn táwọn ọmọ ẹ̀yìn òun lè gbà fara wé òun, ó ní: “Èyí ni àṣẹ mi, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín.” (Jòhánù 15:12, 13, 17) Ìdí tó fi yẹ káwọn Kristẹni nífẹ̀ẹ́ ara wọn pọ̀ gan-an. Mímọ̀ tí Jésù sì mọ̀ pé ayé máa kórìíra wọn ló mú kó sọ ọ̀rọ̀ yẹn. Ó ní: “Bí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé ó ti kórìíra mi kí ó tó kórìíra yín. . . . Ẹrú kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ. Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú.” (Jòhánù 15:18, 20) Bẹ́ẹ̀ ni o, ńṣe ni inúnibíni táwọn Kristẹni ń fojú winá rẹ̀ fi hàn pé wọ́n dà bíi Jésù. Wọ́n gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ tó lágbára láàárín ara wọn kí wọ́n lè fara da inúnibíni.
17. Kí nìdí tí ayé fi kórìíra àwọn Kristẹni tòótọ́?
17 Kí nìdí tí ayé fi máa kórìíra àwọn Kristẹni? Ìdí ni pé wọn “kì í ṣe apá kan ayé,” bí Jésù kì í ti í ṣe apá kan ayé. (Jòhánù 17:14, 16) Wọn kì í dá sí ọ̀ràn ogun tàbí ọ̀ràn ìṣèlú, wọ́n ń pa àwọn ìlànà Bíbélì mọ́, ẹ̀mí èèyàn jọ wọ́n lójú gan-an, wọ́n sì máa ń hùwà ọmọlúwàbí. (Ìṣe 15:28, 29; 1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Nǹkan tẹ̀mí ni wọ́n gbájú mọ́ kì í ṣe nǹkan tara. Inú ayé ni wọ́n ń gbé o, àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ, wọn ò ‘lò [ayé] dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.’ (1 Kọ́ríńtì 7:31) Lóòótọ́, ìwà ọmọlúàbí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń hù wu àwọn kan, àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí ò kì í ṣe ohun táwọn èèyàn fẹ́ káyé lè gba tiwọn. Ìdí nìyẹn tí ọ̀rọ̀ wọn ò fi yé ọ̀pọ̀ èèyàn, tí ọ̀pọ̀ sì kórìíra wọn.
18, 19. Báwo làwọn Kristẹni ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nígbà tí wọ́n bá ń fojú winá inúnibíni àti àtakò?
18 Àwọn àpọ́sítélì Jésù rí bí ìkórìíra náà ṣe pọ̀ tó nígbà táwọn èèyàn wá mú Jésù tí wọ́n sì pa á, wọ́n sì tún rí bí Jésù ṣe ṣe lákòókò náà. Inú ọgbà Gẹtisémánì làwọn tó ń ta kò Jésù lórí ọ̀ràn ìsìn ti wá mú un. Pétérù fẹ́ fi idà gbèjà rẹ̀, àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mátíù 26:52; Lúùkù 22:50, 51) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti máa ń fi idà bá àwọn ọ̀tá wọn jà tẹ́lẹ̀ rí. Àmọ́ kò sọ́rọ̀ pé à ń fi idà jà mọ́ báyìí, nítorí pé Ìjọba Ọlọ́run “kì í ṣe apá kan ayé yìí,” kò sì yan orílẹ̀-èdè kankan láàyò. (Jòhánù 18:36) Láìpẹ́ sí àkókò yẹn, Pétérù á di ara orílẹ̀-èdè tẹ̀mí kan, tó jẹ́ pé ọ̀run ni wọ́n ń lọ. (Gálátíà 6:16; Fílípì 3:20, 21) Nítorí náà, látìgbà yẹn lọ, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ò ní bẹ̀rù, wọn ò sì ní jà nígbà táwọn èèyàn bá kórìíra wọn tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí wọn. Wọ́n á fi ọ̀ràn náà lè Jèhófà lọ́wọ́ láìmikàn, wọ́n á sì gbára lé e pé á fún àwọn lókun láti fara dà á.—Lúùkù 22:42.
19 Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́gbà Gẹtisémánì yẹn, Pétérù kọ̀wé pé: “Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí. . . . Nígbà tí a ń kẹ́gàn rẹ̀, kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà. Nígbà tí ó ń jìyà, kò bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ni, ṣùgbọ́n ó ń bá a nìṣó ní fífi ara rẹ̀ lé ọwọ́ ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.” (1 Pétérù 2:21-23) Lóòótọ́, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ, àwọn Kristẹni ti fojú winá inúnibíni líle koko láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá. Àpẹẹrẹ Jésù làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní àti ti àkókò tiwa yìí ń tẹ̀ lé, wọ́n ní ìfaradà, èyí sì fi hàn pé wọ́n ń pa ìwà títọ́ wọn mọ́ láìbá ẹnikẹ́ni fàjọ̀gbọ̀n. (Ìṣípayá 2:9, 10) Nítorí náà, ẹ jẹ́ káwa náà lẹ́nìkọ̀ọ̀kan máa ṣe bíi tiwọn nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro.—2 Tímótì 3:12.
“Ẹ Gbé Olúwa Jésù Kristi Wọ̀”
20-22. Ọ̀nà wo làwọn Kristẹni gbà “gbé Olúwa Jésù Kristi wọ̀”?
20 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ tó wà ní Róòmù pé: “Ẹ gbé Olúwa Jésù Kristi wọ̀, ẹ má sì máa wéwèé tẹ́lẹ̀ fún àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara.” (Róòmù 13:14) Ńṣe làwọn Kristẹni gbé Jésù wọ̀ bí aṣọ. Wọ́n ń sapá láti ní irú àwọn ànímọ́ tí Jésù ní, wọ́n sì ń fara wé e débi pé wọ́n ti wá dà bí Ọ̀gá wọn bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wọ́n.—1 Tẹsalóníkà 1:6.
21 A lè “gbé Olúwa Jésù Kristi wọ̀” tá a bá mọ ọ̀nà tí Jésù gbà gbé ìgbésí ayé rẹ̀ tá a sì sapá láti gbé ìgbésí ayé tiwa bíi tirẹ̀. Jésù lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó nífẹ̀ẹ́ òdodo, ó kórìíra ìwà ta-ni-yóò-mú-mi, ó nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin rẹ̀, kì í ṣe apá kan ayé, ó sì máa ń fi sùúrù fara da inúnibíni. Àwa náà sì ń fara wé e nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí. A ò kì í “wéwèé tẹ́lẹ̀ fún àwọn ìfẹ́ ọkàn ti ẹran ara,” ìyẹn ni pé a ò kì í jẹ́ kí bá a ṣe máa rí ṣe láyé tàbí bí gbogbo ohun tá a fẹ́ ṣe máa tẹ̀ wá lọ́wọ́ jẹ́ olórí ohun tá à ń lé. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu kan tàbí tá a bá wà nínú ìṣòro kan, a máa ń béèrè pé: ‘Tí Jésù bá wà nírú ipò yìí, kí ló máa ṣe? Kí ló máa fẹ́ kí n ṣe?’
22 Paríparì rẹ̀, à ń fara wé Jésù nípa jíjẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú iṣẹ́ ‘ìwàásù ìhìn rere.’ (Mátíù 4:23; 1 Kọ́ríńtì 15:58) Àwọn Kristẹni tún ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ nínú ọ̀nà tó gbà ṣe iṣẹ́ yẹn. Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò jẹ́ ká mọ ọ̀nà náà.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí Kristẹni kan lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?
• Báwo la ṣe lè ní èrò tó tọ̀nà nípa ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́?
• Ọ̀nà wo làwọn Kristẹni gbà ń fara wé Jésù nínú bí wọ́n ṣe ń kojú àtakò àti inúnibíni?
• Báwo lèèyàn ṣe lè “gbé Olúwa Jésù Kristi wọ̀”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Jésù fi àpẹẹrẹ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí ò láfiwé lélẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Gbogbo ohun táwọn Kristẹni ń ṣe, títí kan iṣẹ́ ìwàásù, ló gba pé kéèyàn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Sátánì lè mú kí eré ìnàjú tí kò bójú mu dà bí ohun tó dára lójú Kristẹni kan
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ìfẹ́ táwọn ará ní sí wa ò ní jẹ́ kí àtakò borí wa