Jẹ́ Kí Àwọn Èèyàn Mọ Òtítọ́ Nípa Jésù
1 Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn àgùntàn mìíràn tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn, “ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù.” (Ìṣí. 12:17) Iṣẹ́ tá a gbé fún wọn yìí ṣe pàtàkì gan-an ni, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ Jésù nìkan ni ìgbàlà fi lè ṣeé ṣe.—Jòh. 17:3; Ìṣe 4:12.
2 ‘Ọ̀nà, Òtítọ́, àti Ìyè’: Jésù sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòh. 14:6) Àyàfi nípasẹ̀ Jésù nìkan, ẹni tí í ṣe “ọ̀nà,” la fi lè tọ Ọlọ́run lọ nínú àdúrà ká sì ní àjọṣe tó ní ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú Rẹ̀. (Jòh. 15:16) Jésù ni “òtítọ́” nítorí pé òun ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àti òjìji àwọn nǹkan tí ń bọ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù nímùúṣẹ sí lára. (Jòh. 1:17; Kól. 2:16, 17) Ní ti gidi, lájorí ète tí àsọtẹ́lẹ̀ tòótọ́ wà fún ni láti túbọ̀ tànmọ́lẹ̀ sí ipa pàtàkì tí Jésù kó nínú mímú ète Ọlọ́run ṣẹ. (Ìṣí. 19:10) Síwájú sí i, Jésù ni “ìyè.” Láti rí ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun gbà, gbogbo wa gbọ́dọ̀ lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà rẹ̀.—Jòh. 3:16, 36; Héb. 2:9.
3 Olórí àti Ọba Tí Ń Jọba: Àwọn èèyàn tún gbọ́dọ̀ mọ bí ọlá àṣẹ àti agbára ńlá tí Jèhófà fi síkàáwọ́ Ọmọ rẹ̀ ṣe gbòòrò tó. A ti fi Jésù jẹ Ọba Ìjọba Ọlọ́run—‘òun sì ni ìgbọràn àwọn ènìyàn jẹ́ tirẹ̀.’ (Jẹ́n. 49:10) Láfikún sí i, Jèhófà ti yàn án sípò gẹ́gẹ́ bí Orí ìjọ. (Éfé. 1:22, 23) Ó ṣe pàtàkì pé ká ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ láti lóye ọ̀nà tí Jésù ń gbà darí ìjọ àti bó ṣe ń lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà láti pèsè “oúnjẹ [tẹ̀mí] ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.”—Mát. 24:45-47.
4 Àlùfáà Àgbà Tó Láàánú: Nítorí pé Jésù ti fojú winá àdánwò tó sì ti jìyà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn, “ó lè wá ṣe àrànṣe fún àwọn tí a ń dán wò.” (Héb. 2:17, 18) Ẹ ò rí i pé ohun tó ń mọ́kàn yọ̀ ló jẹ́ fún àwọn ẹ̀dá èèyàn aláìpé láti mọ̀ pé Jésù ń bá wọn kẹ́dùn nítorí àwọn àìlera wọn àti pé ó ń fi tàánútàánú bẹ̀bẹ̀ fún wọn! (Róòmù 8:34) Lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù àtàwọn ohun tó ń ṣe gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà, a lè tọ Jèhófà lọ “pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ,” kó lè ṣeé ṣe fún wa láti rí “ìrànlọ́wọ́ [gbà] ní àkókò tí ó tọ́.”—Héb. 4:15, 16.
5 A gbàdúrà pé kí àwọn ìsapá wa láti sọ òtítọ́ nípa Jésù fún àwọn ẹlòmíràn sún wọn láti ṣègbọràn sí i àti láti sìn ín pa pọ̀ pẹ̀lú wa.—Jòh. 14:15, 21.