ORÍ 15
Jésù Ṣe Iṣẹ́ Ìyanu Àkọ́kọ́
ÌGBÉYÀWÓ TÓ WÁYÉ NÍ KÁNÀ
JÉSÙ SỌ OMI DI WÁÌNÌ
Ó ti pé ọjọ́ mẹ́ta báyìí tí Nàtáníẹ́lì ti di ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí Jésù kọ́kọ́ ní. Díẹ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tẹ̀ lé e lọ sí agbègbè Gálílì, nílùú ìbílẹ̀ wọn. Ìlú Kánà ni wọ́n ń lọ, ìyẹn ìlú ìbílẹ̀ Nàtáníẹ́lì. Àárín àwọn òkè lápá àríwá Násárẹ́tì tí Jésù dàgbà sí ni Kánà wà. Kí ni wọ́n fẹ́ lọ ṣe ní Kánà? Wọ́n pè wọ́n síbi àsè ìgbéyàwó kan níbẹ̀ ni.
Màríà ìyá Jésù náà wá síbi ìgbéyàwó yẹn. Torí pé ọ̀rẹ́ ni Màríà jẹ́ sí ìdílé àwọn tó ń ṣègbéyàwó, ó ṣeé ṣe kó wà lára àwọn tó ń bójú tó àwọn àlejò rẹpẹtẹ tó wà níbẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi tètè kíyè sí i pé wáìnì ti fẹ́ tán. Ló bá pe Jésù, ó sì sọ fún un pé: “Wọn ò ní wáìnì kankan.”—Jòhánù 2:3.
Ṣe ni Màríà ń dọ́gbọ́n sọ fún Jésù pé kó bá wọn wá nǹkan ṣe sí wáìnì tí ò tó yẹn. Jésù fi àkànlò èdè kan dá ìyá rẹ̀ lóhùn láti fi hàn pé òun ò fara mọ́ ohun tó sọ, ó ní: “Obìnrin yìí, báwo ni ìyẹn ṣe kan èmi àti ìwọ?” (Jòhánù 2:4) Jésù ni Ọba tí Ọlọ́run yàn, torí náà, Baba rẹ̀ ọ̀run ló yẹ kó máa darí ohun tó ń ṣe, kì í ṣe àwọn mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́. Màríà hùwà ọgbọ́n, ó sì fi ọmọ rẹ̀ sílẹ̀, ó wá sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tó ń pín jíjẹ mímu pé: “Ẹ ṣe ohunkóhun tó bá ní kí ẹ ṣe.”—Jòhánù 2:5.
Ìṣà tàbí ìkòkò omi mẹ́fà tí wọ́n fi òkúta ṣe wà níbẹ̀, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan máa gbà ju gálọ́ọ̀nù omi mẹ́wàá lọ. Jésù sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tó ń pín jíjẹ mímu pé: “Ẹ pọn omi kún inú àwọn ìṣà náà.” Ó wá sọ pé: “Ó yá, ẹ bu díẹ̀, kí ẹ sì gbé e lọ fún alága àsè.”—Jòhánù 2:7, 8.
Ó wú alága náà lórí pé wáìnì yẹn dáa gan-an, àmọ́ kò mọ̀ pé ọ̀nà ìyanu ni wáìnì náà gbà jáde. Ó pe ọkọ ìyàwó, ó sì sọ pé: “Wáìnì tó dáa ni gbogbo èèyàn máa ń kọ́kọ́ gbé jáde, tí àwọn èèyàn bá sì ti yó, wọ́n á gbé gbàrọgùdù jáde. Wáìnì tó dáa lo gbé pa mọ́ títí di àkókò yìí.”—Jòhánù 2:10.
Iṣẹ́ ìyanu tí Jésù kọ́kọ́ ṣe nìyí. Nígbà tí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rí iṣẹ́ ìyanu yìí, ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára. Lẹ́yìn náà, Jésù, ìyá rẹ̀, àtàwọn àbúrò rẹ̀ rìnrìn àjò lọ sílùú Kápánáúmù tó wà ní bèbè Òkun Gálílì.