‘Ẹ Máa So Eso Púpọ̀’
‘Ẹ máa so èso púpọ̀ kí ẹ sì fi ara yín hàn ní ọmọ ẹ̀yìn mi.’—JÒHÁNÙ 15:8.
1. (a) Kí lohun tí Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé ó pọn dandan láti ṣe téèyàn bá fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn? (b) Ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?
Ọ̀RÀN náà ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀. Jésù ti lo ọ̀pọ̀ àkókò láti fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níṣìírí nípa sísọ ohun tí wọ́n gbọ́dọ́ ṣe fún wọn. Ó ti di ààjìn òru báyìí, àmọ́ ìfẹ́ tí Jésù ní sáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtàtà yìí mú kó máa ba ọ̀rọ̀ tó ń sọ lọ. Láàárín ìjíròrò ọ̀hún ló ti rán wọn létí ohun kan tó kù tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè máa jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nìṣó. Ó sọ pé: “A yin Baba mi lógo nínú èyí, pé ẹ ń bá a nìṣó ní síso èso púpọ̀, tí ẹ sì fi ara yín hàn ní ọmọ ẹ̀yìn mi.” (Jòhánù 15:8) Ǹjẹ́ àwa náà lónìí ń ṣe ohun pàtàkì yìí láti jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn? Kí ló túmọ̀ sí láti máa ‘so èso púpọ̀’? Láti mọ ohun tó túmọ̀ sí, ẹ jẹ́ ká gbé ìjíròrò wọn lálẹ́ ọjọ́ náà yẹ̀ wò.
2. Àpèjúwe wo ni Jésù sọ nípa èso lálẹ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀?
2 Ìmọ̀ràn náà láti máa so èso wà lára àkàwé tí Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Ó sọ pé: “Èmi ni àjàrà tòótọ́, Baba mi sì ni aroko. Gbogbo ẹ̀ka tí ń bẹ nínú mi tí kì í so èso ni ó ń mú kúrò, gbogbo èyí tí ó sì ń so èso ni ó ń wẹ̀ mọ́, kí ó lè so èso púpọ̀ sí i. Ẹ ti mọ́ nísinsìnyí nítorí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín. Ẹ dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, àti èmi ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú yín. Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kò ti lè so èso fúnra rẹ̀ láìjẹ́ pé ó dúró nínú àjàrà, lọ́nà kan náà ni ẹ̀yin náà kò lè ṣe bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé ẹ dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi. Èmi ni àjàrà náà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. . . . A yin Baba mi lógo nínú èyí, pé ẹ ń bá a nìṣó ní síso èso púpọ̀, tí ẹ sì fi ara yín hàn ní ọmọ ẹ̀yìn mi. Gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti nífẹ̀ẹ́ mi, tí èmi sì nífẹ̀ẹ́ yín, ẹ dúró nínú ìfẹ́ mi. Bí ẹ bá pa àwọn àṣẹ mi mọ́, ẹ óò dúró nínú ìfẹ́ mi.”—Jòhánù 15:1-10.
3. Kí làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n bà a lè máa so èso?
3 Nínú àpèjúwe yìí, Jèhófà ni aroko, Jésù ni àjàrà, àwọn àpọ́sítélì tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ sì ni ẹ̀ka. Níwọ̀n ìgbà táwọn àpọ́sítélì náà bá ṣì “wà ní ìrẹ́pọ̀” pẹ̀lú Jésù, wọ́n á máa so èso. Nígbà náà ni Jésù wá ṣàlàyé bí àwọn àpọ́sítélì náà ṣe lè ṣe é tí wọ́n á fi ní ìrẹ́pọ̀ pàtàkì yìí. Ó sọ pé: “Bí ẹ bá pa àwọn àṣẹ mi mọ́, ẹ óò dúró nínú ìfẹ́ mi.” Àpọ́sítélì Jòhánù ṣì kọ irú ọ̀rọ̀ yìí sáwọn Kristẹni bíi tirẹ̀. Ohun tó kọ rèé: “Ẹni tí ó bá ń pa àwọn àṣẹ [Kristi] mọ́ dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.”a (1 Jòhánù 2:24; 3:24) Nítorí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa pípa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, ìrẹ́pọ̀ yìí ló sì máa jẹ́ kí wọ́n máa so èso. Irú èso wo ló yẹ ká máa so?
Ìtẹ̀síwájú Ò Lópin
4. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú òtítọ́ náà pé gbogbo igi tí ò bá so èso ni Jèhófà á “gé kúrò”?
4 Nínú àkàwé àjàrà náà, Jèhófà “gé” ẹ̀ka tí ò bá so èso “kúrò.” Kí lèyí ń sọ fún wa? Ó ń sọ fún wa pé ó pọn dandan kí gbogbo ọmọ ẹ̀yìn máa so èso, ó sì tún jẹ́ ká mọ̀ pé kò sẹ́ni tí ò lè ṣe bẹ́ẹ̀ láìka ipò èyíkéyìí tó bá wà tàbí ibi tágbára rẹ̀ mọ sí. Ká sòótọ́, ó máa lòdì sí ọ̀nà onífẹ̀ẹ́ Jèhófà láti “gé” ọmọ ẹ̀yìn Kristi èyíkéyìí “kúrò” tàbí kó sọ pé kò tóótun nítorí pé kò lè ṣe ohun tágbára rẹ̀ ò ká.—Sáàmù 103:14; Kólósè 3:23; 1 Jòhánù 5:3.
5. (a) Báwo ni àkàwé Jésù ṣe fi hàn pé a lè tẹ̀ síwájú nínú síso èso? (b) Irú oríṣi èso méjì wo la máa gbé yẹ̀ wò?
5 Àkàwé àjàrà tí Jésù ṣe tún fi hàn wá pé dé àyè tí ipò wa bá yọ̀ǹda, a gbọ́dọ̀ máa wá ọ̀nà láti tẹ̀ síwájú nínú ìgbòkègbodò wa gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn. Kíyè sí ọ̀nà tí Jésù gbà sọ ọ́ pé: “Gbogbo ẹ̀ka tí ń bẹ nínú mi tí kì í so èso ni ó ń mú kúrò, gbogbo èyí tí ó sì ń so èso ni ó ń wẹ̀ mọ́, kí ó lè so èso púpọ̀ sí i.” (Jòhánù 15:2) Ní apá ìparí àkàwé náà, Jésù rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa so “èso púpọ̀.” (Ẹsẹ 8) Kí lèyí ń sọ fún wa? Ohun tó ń sọ ni pé gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn, a ò gbọ́dọ̀ dẹra nù. (Ìṣípayá 3:14, 15, 19) Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ wá àwọn ọ̀nà tá a lè gbà máa tẹ̀ síwájú nínú síso èso. Irú èso wo ló yẹ ká sapá láti túbọ̀ máa so? Oríṣi méjì ni, (1) “èso ti ẹ̀mí” àti (2) èso Ìjọba Ọlọ́run.—Gálátíà 5:22, 23; Mátíù 24:14.
Èso Ànímọ́ Kristẹni
6. Báwo ni Jésù Kristi ṣe tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì èyí tá a kọ́kọ́ dárúkọ nínú èso ti ẹ̀mí?
6 Ìfẹ́ la kọ́kọ́ dárúkọ láàárín àwọn “èso ti ẹ̀mí.” Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló ń mú kí ìfẹ́ wà láàárín àwọn Kristẹni, nítorí pé wọ́n ń ṣègbọràn sí àṣẹ tí Jésù fún wọn ṣáájú kó tó sọ àkàwé igi àjàrà eléso náà. Ó sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (Jòhánù 13:34) Kódà, jálẹ̀ gbogbo ìjíròrò Jésù lálẹ́ tó gbẹ̀yìn ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ló fi ń tẹ̀ ẹ́ mọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ létí pé ó di dandan kí wọ́n ní ìfẹ́.—Jòhánù 14:15, 21, 23, 24; 15:12, 13, 17.
7. Báwo ni àpọ́sítélì Pétérù ṣe fi hàn pé síso èso ní í ṣe pẹ̀lú níní àwọn ànímọ́ irú èyí tí Kristi ní?
7 Pétérù tó wà níbẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ náà lóye rẹ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi tòótọ́ gbọ́dọ̀ ní irú ìfẹ́ tí Kristi ní àtàwọn ànímọ́ mìíràn tó tan mọ́ ọn. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Pétérù gba àwọn Kristẹni níyànjú láti ní àwọn ànímọ́ bí ìkóra-ẹni-níjàánu, ìfẹ́ni ará àti ìfẹ́. Ó tiẹ̀ fi kún un pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ ká “di aláìṣiṣẹ́ tàbí aláìléso.” (2 Pétérù 1:5-8) Ipò yòówù ká wà, níní àwọn èso tẹ̀mí kò kọjá agbára wa. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká sapá láti fi ìfẹ́, inú rere, ìwà tútù àtàwọn ànímọ́ mìíràn irú èyí tí Kristi ní hàn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, nítorí pé “kò sí òfin kankan lòdì sí irú nǹkan báwọ̀nyí.” (Gálátíà 5:23) Àní sẹ́, ẹ jẹ́ ká máa so “èso púpọ̀ sí i.”
Síso Èso Ìjọba Náà
8. (a) Ọ̀nà wo ni èso ti ẹ̀mí àti èso Ìjọba náà gbà bára tan? (b) Ìbéèrè wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò?
8 Àwọn èso igi tó jojú ní gbèsè tó sì ṣe rùmúrùmú máa ń fún igi lẹ́wà. Àmọ́, ìwúlò irú àwọn èso bẹ́ẹ̀ kò wulẹ̀ mọ sídìí bíbu ẹwà kún igi. Inú èso la ti máa ń rí kóró tá a fi ń ṣe irúgbìn kí irú igi náà bàa lè pọ̀ sí i. Lọ́nà kan náà, ohun tí èso tẹ̀mí ń ṣe kọjá bíbu ẹwà kún ànímọ́ Kristẹni wa. Àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ ń sún wa láti tan ìhìn Ìjọba náà tó dà bí irúgbìn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kálẹ̀. Ṣàkíyèsí bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe tẹnu mọ́ bí èyí ṣe so kọ́ra. Ó sọ pé: “Àwa pẹ̀lú lo ìgbàgbọ́ [ọ̀kan lára èso ti ẹ̀mí] àti nítorí náà a sọ̀rọ̀.” (2 Kọ́ríńtì 4:13) Lọ́nà yìí, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé síwájú sí i pé à ń “rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyíinì ni, èso ètè”—oríṣi èso kejì tó yẹ ká so. (Hébérù 13:15) Ǹjẹ́ àwọn àǹfààní tá a fi lè túbọ̀ so èso wà nínú ìgbésí ayé wa, àní láti so “èso púpọ̀,” gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run?
9. Ṣé ohun kan náà ni síso èso àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn? Ṣàlàyé.
9 Tá a bá fẹ́ dáhùn ìbéèrè yìí bó ṣe tọ́, ó yẹ ká kọ́kọ́ mọ ohun tí èso Ìjọba náà túmọ̀ sí. Ǹjẹ́ ó tọ̀nà láti sọ pé ohun tí síso èso túmọ̀ si ni sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn? (Mátíù 28:19) Ṣé àwọn èèyàn tá à ń ràn lọ́wọ́ láti di olùjọsìn Jèhófà tó ti ṣèrìbọmi nìkan ni èso tá a ní ka so ń tọ́ka sí? Rárá o. Ká ní bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn rí ni, ìjákulẹ̀ ńlá gbáà ni ì bá jẹ́ fún gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí àtàtà tí wọ́n ti fi òótọ́ polongo ìhìn Ìjọba náà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún láwọn ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn ò ti fi bẹ́ẹ̀ fetí sílẹ̀. Àní, ká sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun nìkan ni èso Ìjọba tá à ń so dúró fún ni, ńṣe ni irú àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń ṣiṣẹ́ kára bẹ́ẹ̀ ì bá dà bí àwọn ẹ̀ka tí kò so èso nínú àkàwé Jésù! Àmọ́ ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀. Nígbà náà, kí wá ni èso Ìjọba náà dìídì túmọ̀ sí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
Síso Èso Nípa Títan Irúgbìn Ìjọba Náà Kálẹ̀
10. Báwo ni àkàwé Jésù nípa afúnrúgbìn àti oríṣiríṣi ilẹ̀ ṣe jẹ́ ká mọ ohun tí èso Ìjọba náà jẹ́ àti ohun tí kò jẹ́?
10 Àkàwé tí Jésù ṣe nípa afúnrúgbìn àti oríṣiríṣi ilẹ̀ dáhùn ìbéèrè yìí—afúnni-níṣìírí gidi ni ìdáhùn yìí jẹ́ fáwọn tó ń wàásù láwọn ìpínlẹ̀ tí ò fi bẹ́ẹ̀ méso jáde. Jésù sọ pé ìhìn Ìjọba náà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni irúgbìn náà, àti pé ilẹ̀ dúró fún ọkàn ìṣàpẹẹrẹ ti ẹ̀dá èèyàn. Àwọn irúgbìn kan “bọ́ sórí erùpẹ̀ rere, àti pé, lẹ́yìn rírújáde, ó mú èso jáde.” (Lúùkù 8:8) Irú èso wo nìyẹn? Tí kóró àlìkámà bá ti hù jáde tó sì ti dàgbà dáadáa, ó di pé kó so èso, èso yìí kì í ṣe èèhù pòròpórò bí kò ṣe kóró tuntun. Lọ́nà kan náà, Kristẹni máa ń so èso, kò pọn dandan kí èso yìí jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn tuntun àmọ́ èso tuntun ti Ìjọba náà.
11. Báwo la ṣe túmọ̀ èso Ìjọba náà?
11 Nítorí náà, èso tá à ń sọ nínú ọ̀ràn yìí kì í ṣe àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe àwọn ànímọ́ dáradára ti Kristẹni. Nígbà tó ti jẹ́ pé ọ̀rọ̀ Ìjọba náà ni irúgbìn tá a gbìn, èso rẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba náà tó ti wá pọ̀ sí i. Síso èso lọ́nà yìí túmọ̀ sí sísọ̀rọ̀ nípa Ìjọba náà. (Mátíù 24:14) Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún wa láti máa so èso Ìjọba náà lọ́nà yẹn—ìyẹn pípolongo ìhìn rere Ìjọba náà—láìka ipò èyíkéyìí tó wù ká wà sí? Bẹ́ẹ̀ ni o, ó ṣeé ṣe! Nínú àkàwé kan náà, Jésù ṣàlàyé ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.
Sísa Gbogbo Ipá Wa fún Ògo Ọlọ́run
12. Ǹjẹ́ gbogbo Kristẹni ló lè so èso Ìjọba náà? Ṣàlàyé.
12 Jésù sọ pé: “Èyí tí a fún sórí erùpẹ̀ àtàtà, ń mú èso jáde, eléyìí ìlọ́po ọgọ́rùn-ún, èyíinì ọgọ́ta, òmíràn ọgbọ̀n.” (Mátíù 13:23) Ọ̀nà táwọn kóró irúgbìn téèyàn gbìn sóko fi ń so máa ń yàtọ̀ síra. Lọ́nà kan náà, ohun tá a lè ṣe láti fi polongo ìhìn rere náà lè yàtọ̀ síra, ó sinmi lórí ipò olúkúlùkù, Jésù fúnra rẹ̀ sì mọ èyí. Àwọn kan lè láǹfààní tó ju tàwọn tó kù lọ; ara àwọn mìíràn lè dá ṣáṣá kí wọ́n sì lókun. Ìdí rèé tó fi jẹ́ pé ohun tá a lè ṣe lè kéré sí tàwọn tó kù tàbí kó pọ̀ ju tiwọn lọ. Àmọ́ tó bá sáà ti jẹ ibi tágbára wa mọ nìyẹn, inú Jèhófà á dùn sí i. (Gálátíà 6:4) Kódà ká sọ pé ara tó ti ń dara àgbà tàbí àìsàn kò jẹ́ ká lè ṣe tó báa ṣe ń ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù náà tẹ́lẹ̀ mọ́, ó dájú pé Jèhófà, Baba wa oníyọ̀ọ́nú á ṣì kà wá mọ́ àwọn tó ń so “èso púpọ̀.” Kí nìdí? Ìdí ni pé ‘gbogbo ohun tá a ní’ là ń fún un—ìyẹn iṣẹ́ ìsìn tá à ń ṣe tọkàntọkàn.b—Máàkù 12:43, 44; Lúùkù 10:27.
13. (a) Kí ni lájorí ìdí tá a fi ń “bá a lọ” ní síso èso Ìjọba náà? (b) Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti máa so èso láwọn ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn ò ti ń fi bẹ́ẹ̀ tẹ́tí sí ìhìn wa? (Wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 21)
13 Ibi yòówù kí agbára wa gbé e dé láti máa so èso Ìjọba náà, tá a bá fi ìdí tá a fi ń ṣe é sọ́kàn, èyí á sún wa láti “máa bá a lọ àti láti máa so èso.” (Jòhánù 15:16) Jésù sọ lájorí ìdí tá a fi ń so èso, ó ní: “A yin Baba mi lógo nínú èyí, pé ẹ ń bá a nìṣó ní síso èso púpọ̀.” (Jòhánù 15:8) Bẹ́ẹ̀ ni o, iṣẹ́ ìwàásù wa ń sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́ lọ́dọ̀ gbogbo ẹ̀dá èèyàn. (Sáàmù 109:30) Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Honor, ti lé lẹ́ni àádọ́rin ọdún. Ó sọ pé: “Kódà láwọn ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn ò ti ń fi bẹ́ẹ̀ tẹ́tí sí ìhìn wa, àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti ṣojú fún Ẹni Gíga Jù Lọ náà.” Nígbà tá a béèrè ohun tó mú kí Claudio tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí onítara láti ọdún 1974, ṣì máa bá iṣẹ́ ìwàásù nìṣó pẹ̀lú báwọn èèyàn ò ṣe ń fi bẹ́ẹ̀ tẹ́tí sí ìhìn náà ní ìpínlẹ̀ rẹ̀, ìwé Jòhánù 4:34 ló tọ́ka sí, níbi tá a ti ka àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.” Claudio tún sọ pé: “Bíi ti Jésù, mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pípòkìkí Ìjọba náà tá a yàn fún mi kí n sì parí rẹ̀.” (Jòhánù 17:4) Èrò kan náà ló wà lọ́kàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé.—Wo àpótí náà “Bá A Ṣe Lè ‘So Èso Pẹ̀lú Ìfaradà,’” ní ojú ìwé 21.
Láti Wàásù àti Láti Kọ́ni
14. (a) Ọ̀nà méjì wo ni iṣẹ́ Jòhánù Olùbatisí àti ti Jésù pín sí? (b) Báwo lo ṣe máa ṣàpèjúwe ìgbòkègbodò Kristẹni lóde òní?
14 Jòhánù Olùbatisí ni olùpòkìkí Ìjọba náà tá a kọ́kọ́ dárúkọ rẹ̀ nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere. (Mátíù 3:1, 2; Lúùkù 3:18) Olórí ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ ni pé kó “jẹ́rìí,” ó sì fi ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ ṣe iṣẹ́ yìí pẹ̀lú ìrètí pé “kí onírúurú ènìyàn gbogbo bàa lè gbà gbọ́.” (Jòhánù 1:6, 7) Láìsí àní-àní, àwọn kan lára àwọn tí Jòhánù wàásù fún di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (Jòhánù 1:35-37) Ìdí rèé tí Jòhánù fi jẹ́ oníwàásù tó sì tún ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn. Jésù náà jẹ́ oníwàásù àti olùkọ́ni. (Mátíù 4:23; 11:1) Abájọ nígbà náà tí Jésù ò fi pàṣẹ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun wàásù ìhìn Ìjọba náà nìkan àmọ́ tó tún ní kí wọ́n ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti gba ìhìn náà kí wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 28:19, 20) Nítorí náà, iṣẹ́ wa lónìí jẹ́ àpapọ̀ iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni.
15. Báwo ni ọ̀nà táwọn èèyàn fi gba iṣẹ́ ìwàásù náà ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa ṣe bá tòde òní mu?
15 Nínú àwọn tó gbọ́ ìwàásù ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Pọ́ọ̀lù ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, “àwọn kan . . . bẹ̀rẹ̀ sí gba àwọn ohun tí ó sọ gbọ́; àwọn mìíràn kò sì gbà gbọ́.” (Ìṣe 28:24) Bákan náà lọ̀ràn ṣe rí lóde òní. Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ irúgbìn Ìjọba náà ló ń bọ́ sórí ilẹ̀ tí kò dára. Síbẹ̀, àwọn irúgbìn kan wà tí wọ́n ṣì ń bọ́ sórí ilẹ̀ tó dára, tí wọ́n ń ta gbòǹgbò tí wọ́n sì ń hù jáde gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀. Àní, kárí ayé, ìpíndọ́gba èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] ló ń di ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Kristi ní ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan! Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun yìí ‘gba àwọn ohun tá a sọ gbọ́,’ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni ò ṣe bẹ́ẹ̀. Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ tí ọkàn wọn fi gba ìhìn Ìjọba náà? Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ìfẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí fi hàn sáwọn èèyàn yìí—tó dà bíi bíbomirin irúgbìn téèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ gbìn—ló ń mú kí wọ́n gba ìhìn náà. (1 Kọ́ríńtì 3:6) Mélòó la fẹ́ kà nínú irú àwọn àpẹẹrẹ báwọ̀nyí, àmọ́ gbé méjì péré yẹ̀ wò lára wọn.
Fífi Ìfẹ́ Hàn Ń Mú Káwọn Èèyàn Fetí sí Ìhìn Rere
16, 17. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé ká fi ìfẹ́ hàn sáwọn tá a bá bá pàdé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
16 Ní Belgium, ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Karolien lọ wàásù fun obìnrin àgbàlagbà kan tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn Ìjọba náà. Báńdéèjì tó wà lọ́wọ́ obìnrin yìí mú kí Karolien àti ẹnì kejì rẹ̀ ní káwọn ran obìnrin yìí lọ́wọ́, àmọ́ obìnrin náà fàáké kọ́rí pé kí wọ́n máa lọ. Ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà, àwọn Ẹlẹ́rìí yìí tún padà sọ́dọ̀ obìnrin yìí wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣé àjíǹde ara ń jẹ́. Karolien sọ pé “Èyí ló mú kí obìnrin náà fetí sí ìhìn rere náà. Ó yà á lẹ́nu láti rí i pé a nífẹ̀ẹ́ òun gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan. Ó ní ká wọlé, a sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀.”
17 Sandi, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, máa ń fìfẹ́ hàn sáwọn tó ń wàásù fún. Ó máa ń wo inú ìwé ìròyìn tí wọ́n ti máa ń kéde àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ ládùúgbò rẹ̀, ẹ̀yìn èyí ni yóò mú Iwe Itan Bibeli Mic lọ fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ náà. Bó ṣe jẹ́ pé àwọn obìnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ kì í kúrò nílé tínú wọn sì máa ń dùn láti fi ìkókó wọn han àwọn tó bá wá kí wọn, èyí máa ń mú kí ìjíròrò bẹ̀rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Sandi sọ pé: “Mo máa ń bá àwọn òbí náà sọ̀rọ̀ nípa bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n máa kàwé fún ìkókó náà kí àjọṣe tó dán mọ́rán lè wà láàárín wọn. Tó bá yá, màá wá sọ fún wọn nípa àwọn ìṣòro tó wé mọ́ ọmọ títọ́ láyé tá a wà yìí.” Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, irú àbẹ̀wò yìí ti mú kí ìyá kan àtàwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́fà bẹ̀rẹ̀ sí sin Jèhófà. Lílo ìdánúṣe àti fífi ìfẹ́ hàn lè mú kí àwa náà ní irú àbájáde aláyọ̀ bẹ́ẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
18. (a) Kí nìdí tí a fi mọ̀ pé ‘síso èso púpọ̀’ kò kọjá agbára wa? (b) Àwọn ohun mẹ́ta wo lo ti pinnu láti ṣe, tí Ìhìn Rere Jòhánù sọ pé ó pọn dandan téèyàn bá fẹ́ jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn?
18 Ó ń fúnni níṣìírí gan-an láti mọ̀ pé ‘síso èso púpọ̀’ kò kọjá agbára wa! Yálà a jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà, yálà ara wa dá ṣáṣá tàbí àìsàn ti sọ wá di hẹ́gẹhẹ̀gẹ, yálà àwọn èèyàn ń tẹ́tí sí ìhìn iṣẹ́ náà ní ìpínlẹ̀ wa tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbogbo wa la lè so èso púpọ̀. Lọ́nà wo? Nípa níní èso ti ẹ̀mí débi tó yẹ ká ní i dé àti nípa sísọ ìhìn Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn débi tí agbára wa bá dé. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ká gbìyànjú láti ‘dúró nínú ọ̀rọ̀ Jésù’ ká sì ‘ní ìfẹ́ láàárín ara wa.’ Dájúdájú, tá a bá ń ṣe àwọn ohun mẹ́ta tá a kọ sínú Ìhìn Rere Jòhánù pé ó pọn dandan kéèyàn ṣe tó bá fẹ́ jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn, ńṣe là ń fi hàn pé ‘ọmọ ẹ̀yìn Kristi ni wá ní ti tòótọ́.’—Jòhánù 8:31; 13:35.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lóòótọ́ ni àwọn ẹ̀ka àjàrà náà ń tọ́ka sí àwọn àpọ́sítélì Jésù àtàwọn Kristẹni mìíràn tí wọ́n máa nípìn-ín nínú Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run, àmọ́ gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi lóde òní ló lè jàǹfààní nínú òtítọ́ tó wà nínú àkàwé náà.—Jòhánù 3:16; 10:16.
b Àwọn tí wọn ò lè jáde nílé nítorí ọjọ́ ogbó tàbí àìsàn lè wàásù nípa kíkọ lẹ́tà, tàbí tó bá ṣeé ṣe nípa lílo tẹlifóònù, wọ́n tiẹ̀ lè wàásù ìhìn rere náà fáwọn tó bá wá bẹ̀ wọ́n wò pàápàá.
c Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
• Irú àwọn èso wo la gbọ́dọ̀ túbọ̀ máa so lọ́pọ̀ yanturu sí i?
• Èé ṣe tí ‘síso èso púpọ̀’ kò fi kọjá agbára wa?
• Àwọn ohun mẹ́ta wo la ti jíròrò nínú Ìhìn Rere Jòhánù pé ó pọn dandan téèyàn bá fẹ́ jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
BÁ A ṢE LÈ “SO ÈSO PẸ̀LÚ ÌFARADÀ”
KÍ LÓ ràn ọ́ lọ́wọ́ tó o fi ń fi tinútinú bá wíwàásù Ìjọba náà lọ láwọn ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn ò ti ń fi bẹ́ẹ̀ tẹ́tí sí ìhìn wa? Àwọn ìdáhùn bíi mélòó kan rèé tó lè ranni lọ́wọ́.
“Mímọ̀ ti mo mọ̀ pé Jésù wà lẹ́yìn mi gbágbáágbá ló jẹ́ kí n lẹ́mìí pé nǹkan ń bọ̀ wá dára tí mo sì ń forí tì í, láìka ohunkóhun táwọn èèyàn bá ṣe ní ìpínlẹ̀ mi sí.”—Harry, ẹni ọdún méjìléláàádọ́rin; ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1946.
“Gbogbo ìgbà lohun tó wà ní 2 Kọ́ríńtì 2:17 máa ń fún mi níṣìírí. Ó sọ pé à ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ‘ní iwájú Ọlọ́run, ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi.’ Tí mo bá wà lóde ẹ̀rí, mo máa ń gbádùn wíwà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n jù lọ.”—Claudio, ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì; ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1974.
“Ní tòdodo, iṣẹ́ ìwàásù ò rọrùn fún mi rárá. Àmọ́, mo ti rí i pé òótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ tó wà ní Sáàmù 18:29, tó kà pé: ‘Nípasẹ̀ Ọlọ́run mi, mo lè gun ògiri.’”—Gerard, ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin; ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1955.
“Kódà kó jẹ́ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan péré ni mo kà lóde ẹ̀rí, ó máa ń mú inú mi dùn pé Bíbélì ti ṣàyẹ̀wò ọkàn ẹnì kan nìyẹn.”—Eleanor, ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n: ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1989.
“Onírúurú ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ ni mo gbìyànjú wò. Ó tiẹ̀ wá pọ̀ débi pé mi ò lè lo gbogbo wọn tán nínú ìyókù ọjọ́ ayé mi.”—Paul, ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin; ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1940.
“Ńṣe ni mo máa ń kọ etí dídi sọ́rọ̀ kòbákùngbé táwọn èèyàn bá sọ sí mi. Mo máa ń gbìyànjú láti bá wọn sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́, mo máa ń bá wọn fèrò wérò mo sì máa ń tẹ́tí sí èrò wọn.”—Daniel, ẹni ọdún márùnléláàádọ́rin; ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1946.
“Mo ti ráwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi tí wọ́n sọ fún mi pé iṣẹ́ ìwàásù mi wà lára ohun tó mú kí wọ́n di Ẹlẹ́rìí. Mi ò mọ̀, àṣé lẹ́yìn tí mo ti wàásù fún wọn ni ẹlòmíràn wá kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú. Ó máa ń fún mi láyọ̀ láti mọ̀ pé igi kan kì í dágbó ṣe lọ̀rọ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.”—Joan, ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rin; ó ṣèrìbọmi lọ́dún 1954.
Kí ló ń ràn ọ́ lọ́wọ́ láti “so èso pẹ̀lú ìfaradà”?—Lúùkù 8:15.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
À ń so èso púpọ̀ nípa níní àwọn èso ti ẹ̀mí àti nípa pípolongo ìhìn Ìjọba náà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: ‘Ẹ máa so èso púpọ̀’?