ORÍ 120
Béèyàn Ṣe Lè Dà Bí Ẹ̀ka Tó Ń So Èso, Kó sì Di Ọ̀rẹ́ Jésù
ÀJÀRÀ TÒÓTỌ́ ÀTI Ẹ̀KA RẸ̀
BÉÈYÀN ṢE LÈ DÚRÓ NÍNÚ ÌFẸ́ JÉSÙ
Ó ti ṣe díẹ̀ tí Jésù ti ń fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nímọ̀ràn, ó sì ń fìfẹ́ báwọn sọ̀rọ̀ látọkàn wá. Ilẹ̀ ti ṣú báyìí, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí wọ́n ti wà ní àárín òru. Jésù wá sọ àpèjúwe kan fún wọn kó lè fún wọn níṣìírí, ó sọ pé:
“Èmi ni àjàrà tòótọ́, Baba mi sì ni ẹni tó ń dáko.” (Jòhánù 15:1) Àpèjúwe yìí jọ ohun táwọn wòlíì Jèhófà sọ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn nípa orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, wọ́n pe orílẹ̀-èdè náà ní ọgbà àjàrà Jèhófà. (Jeremáyà 2:21; Hósíà 10:1, 2) Àmọ́ ní báyìí, Jèhófà fẹ́ pa orílẹ̀-èdè yẹn tì. (Mátíù 23:37, 38) Torí náà Jésù jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ ètò tuntun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun dà bí ọgbà àjàrà, àtìgbà tí Baba sì ti fẹ̀mí yan òun lọ́dún 29 S.K. ni Baba ti ń bójú tó o. Àmọ́, Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun nìkan kọ́ ni ọgbà àjàrà yẹn dúró fún, ó sọ pé:
“[Baba mi] ń mú gbogbo ẹ̀ka tí kì í so èso nínú mi kúrò, ó sì ń wẹ gbogbo èyí tó ń so èso mọ́, kó lè so èso púpọ̀ sí i. . . . Bí ẹ̀ka ò ṣe lè dá so èso àfi tó bá dúró lára àjàrà, ẹ̀yin náà ò lè ṣe bẹ́ẹ̀, àfi tí ẹ bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi. Èmi ni àjàrà náà; ẹ̀yin ni ẹ̀ka.”—Jòhánù 15:2-5.
Jésù ti ṣèlérí fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́ pé tí òun bá lọ, òun máa rán olùrànlọ́wọ́ kan sí wọn, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́. Ní ọjọ́ mọ́kànléláàádọ́ta (51) lẹ́yìn náà, nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bà lé àwọn àpọ́sítélì àtàwọn míì tó wà níbi tí wọ́n kóra jọ sí, wọ́n di ẹ̀ka igi àjàrà. Gbogbo “ẹ̀ka” igi àjàrà yẹn ló sì gbọ́dọ̀ wà níṣọ̀kan pẹ̀lú Jésù. Kí nìdí tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ wà níṣọ̀kan?
Jésù ṣàlàyé pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, tí mo sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, ẹni yìí ń so èso púpọ̀; torí láìsí èmi, ẹ ò lè ṣe ohunkóhun.” “Ẹ̀ka” yìí dúró fún àwọn tó ń fi òótọ́ inú tẹ̀ lé Jésù, wọ́n máa so èso tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, tí wọ́n sì ń fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, kí wọ́n lè sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Àmọ́, kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí ẹnì kan ò bá wà níṣọ̀kan pẹ̀lú Jésù, tí kò sì so èso? Jésù ṣàlàyé pé: “Tí ẹnikẹ́ni ò bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, a máa sọ ọ́ nù.” Lẹ́yìn náà, Jésù wá sọ pé: “Tí ẹ bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, tí àwọn ọ̀rọ̀ mi sì wà nínú yín, ẹ béèrè ohunkóhun tí ẹ bá fẹ́, ó sì máa rí bẹ́ẹ̀ fún yín.”—Jòhánù 15:5-7.
Ìgbà méjì ni Jésù ti bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa pa àwọn àṣẹ òun mọ́, ó tún wá mẹ́nu bà á lẹ́ẹ̀kan sí i. (Jòhánù 14:15, 21) Jésù ṣàlàyé nǹkan pàtàkì tí wọ́n á máa ṣe tó máa fi hàn pé wọ́n ń pa àṣẹ òun mọ́, ó ní: “Tí ẹ bá ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́, ẹ máa dúró nínú ìfẹ́ mi, bí mo ṣe pa àwọn àṣẹ Baba mọ́ gẹ́lẹ́, tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.” Àmọ́, wọ́n tún gbọ́dọ̀ ṣe kọjá kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀. Jésù sọ pé: “Àṣẹ mi nìyí, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín. Kò sí ẹni tí ìfẹ́ rẹ̀ ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ọ̀rẹ́ mi ni yín, tí ẹ bá ń ṣe ohun tí mò ń pa láṣẹ fún yín.”—Jòhánù 15:10-14.
Ní wákàtí díẹ̀ sí i, Jésù máa fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn tó bá nígbàgbọ́ nínú òun, torí ó máa fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wọn. Ó yẹ kí àpẹẹrẹ Jésù mú kó máa wu àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti fi ẹ̀mí ara wọn lélẹ̀ nítorí àwọn míì. Jésù sì ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ pé ìfẹ́ ló máa jẹ́ káwọn èèyàn dá wọn mọ̀, ó ní: “Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.”—Jòhánù 13:35.
Ó yẹ káwọn àpọ́sítélì yẹn ronú lórí bí Jésù ṣe pè wọ́n ní “ọ̀rẹ́.” Jésù sọ ohun tó mú kó pè wọ́n bẹ́ẹ̀, ó ní: “Mo pè yín ní ọ̀rẹ́, torí pé mo ti jẹ́ kí ẹ mọ gbogbo ohun tí mo gbọ́ látọ̀dọ̀ Baba mi.” Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá nìyẹn fún wọn láti ní àjọṣe tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Jésù, kí wọ́n sì mọ ohun tí Baba rẹ̀ sọ fún un! Àmọ́ kí wọ́n lé máa gbádùn irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó, wọ́n gbọ́dọ̀ “máa so èso.” Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí wọ́n bá ń so èso? Jésù sọ pé: “Tí ẹ bá béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, ó máa fún yín.”—Jòhánù 15:15, 16.
Tí ìfẹ́ bá wà láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó dúró fún “ẹ̀ka” yẹn, ó máa ṣeé ṣe fún wọn láti fara da ohunkóhun tó bá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Jésù wá kìlọ̀ fún wọn pé ayé máa kórìíra wọn, àmọ́ ó sọ ohun kan tó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Tí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé ó ti kórìíra mi kó tó kórìíra yín. Tí ẹ bá jẹ́ apá kan ayé, ayé máa nífẹ̀ẹ́ ohun tó jẹ́ tirẹ̀. Torí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, . . . torí èyí ni ayé ṣe kórìíra yín.”—Jòhánù 15:18, 19.
Jésù ṣàlàyé ìdí tí ayé fi máa kórìíra wọn, ó ní: “Wọ́n máa ṣe gbogbo nǹkan yìí sí yín nítorí orúkọ mi, torí pé wọn ò mọ Ẹni tó rán mi.” Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé àwọn tó kórìíra òun jẹ̀bi torí pé wọn ò ronú nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tóun ṣe, ó ní: “Ká ní mi ò ṣe àwọn iṣẹ́ tí ẹnì kankan ò ṣe rí láàárín wọn ni, wọn ò ní ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan; àmọ́ ní báyìí wọ́n ti rí mi, wọ́n sì ti kórìíra èmi àti Baba mi.” Bí wọ́n ṣe kórìíra Jésù yìí mú kí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ.—Jòhánù 15:21, 24, 25; Sáàmù 35:19; 69:4.
Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jésù tún ṣèlérí pé òun máa rán olùrànlọ́wọ́ kan sí wọn, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́. Gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni ẹ̀mí mímọ́ yìí wà fún, òun ló máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa so èso, kí wọ́n sì máa “jẹ́rìí” nípa Jésù.—Jòhánù 15:27.