Wọ́n Retí Mèsáyà
“Àwọn eniyan ń retí, gbogbo wọn ń rò ninu ọkàn wọn bí Johanu bá ni Mesaya.”—LÚÙKÙ 3:15, ÌRÒHÌN AYỌ̀.
1. Kí ni áńgẹ́lì sọ fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn kan?
ILẸ̀ ti ṣú. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn wà níta wọ́n ń ṣọ́ agbo àgùntàn wọn. Ẹnu ti ní láti yà wọ́n gan-an nígbà tí wọ́n rí i tí áńgẹ́lì Jèhófà dúró sítòsí wọn tí ògo Ọlọ́run sì yí wọn ká! Gbọ́ ná! Áńgẹ́lì náà polongo ohun kan tó mú wọn lọ́kàn yọ̀. Ó ní: “Ẹ má bẹ̀rù, nítorí, wò ó! Èmi ń polongo fún yín ìhìn rere ti ìdùnnú ńlá kan tí gbogbo ènìyàn yóò ní, nítorí pé a bí Olùgbàlà kan fún yín lónìí, ẹni tí í ṣe Kristi Olúwa,” ẹni tó máa jẹ́ Mèsáyà. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn náà lè rí ọmọdé jòjòló yìí níbi tó wà nínú ibùjẹ ẹran, ní ìlú kan tó wà nítòsí wọn. Lójijì, “ògìdìgbó ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run” bẹ̀rẹ̀ sí í yin Jèhófà pé: “Ògo fún Ọlọ́run ní àwọn ibi gíga lókè, àti lórí ilẹ̀ ayé àlàáfíà láàárín àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà.”—Lúùkù 2:8-14.
2. Kí ni “Mèsáyà” túmọ̀ sí, báwo làwọn èèyàn sì ṣe lè dá a mọ̀?
2 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn yẹn ti ní láti máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ta ni Mèsáyà náà?’ Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn Júù tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn yẹn mọ̀ pé ohun tí “Mèsáyà” túmọ̀ sí ni “Ẹni Àmì Òróró” Ọlọ́run. (Ẹ́kís. 29:5-7) Àmọ́, báwo ni wọ́n ṣe lè mú kí àwọn míì gbà gbọ́ pé ọmọ tí áńgẹ́lì náà sọ ló máa jẹ́ Mèsáyà tí Jèhófà yàn? Ó yẹ kí wọ́n kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ nípa Mèsáyà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, lẹ́yìn náà, kí wọ́n wá kíyè sí i bóyá àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ní ìmúṣẹ nínú ìgbésí ayé ọmọ náà.
Kí Nìdí Táwọn Èèyàn Fi Ń Retí Mèsáyà?
3, 4. Báwo ni Dáníẹ́lì 9:24, 25 ṣe ní ìmúṣẹ?
3 Nígbà tí Jòhánù Oníbatisí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ àti àwọn ohun tó ṣe mú kí àwọn kan máa rò pé bóyá Mèsáyà náà ti dé. (Ka Lúùkù 3:15.) Àsọtẹ́lẹ̀ kan ti wà nípa “àádọ́rin ọ̀sẹ̀” èyí tó dá lórí Mèsáyà náà. Ó sì ṣeé ṣe kí àwọn kan ti lóye àsọtẹ́lẹ̀ yìí dáadáa. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, èyí lè jẹ́ kí wọ́n mọ ìgbà tí Mèsáyà máa fara hàn. Díẹ̀ rèé lára àsọtẹ́lẹ̀ náà: “Láti ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà láti mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́ títí di ìgbà Mèsáyà Aṣáájú, ọ̀sẹ̀ méje yóò wà, àti ọ̀sẹ̀ méjì-lé-lọ́gọ́ta.” (Dán. 9:24, 25) Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé ló gbà pé àwọn ọ̀sẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ àwọn ọ̀sẹ̀ ọdún. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì Revised Standard Version sọ pé: “Àádọ́rin ọ̀sẹ̀ ti ọdún ni a fi àṣẹ gbé kalẹ̀.”
4 Lónìí, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà mọ̀ pé àwọn ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin [69] náà, tàbí ọ̀rìn-lé-nírínwó ó lé mẹ́ta [483] ọdún tí ìwé Dáníẹ́lì 9:25 sọ bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 455 ṣáájú Sànmánì Kristẹni nígbà tí Atasásítà Ọba Páṣíà fún Nehemáyà láṣẹ láti mú Jerúsálẹ́mù pa dà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́. (Neh. 2:1-8) Àwọn ọ̀sẹ̀ yẹn dópin ní ọ̀rìn-lé-nírínwó ó lé mẹ́ta [483] ọdún lẹ́yìn náà, ìyẹn ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni nígbà tí Jòhánù ṣèrìbọmi fún Jésù ará Násárétì, tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yàn án, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ di Mèsáyà.—Mát. 3:13-17.a
5. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo la máa gbé yẹ̀ wò báyìí?
5 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ míì nípa Mèsáyà, èyí tó ní ìmúṣẹ nígbà tí wọ́n bí Jésù, nígbà tó wà lọ́mọdé àti nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ó dájú pé èyí máa túbọ̀ jẹ́ ká nígbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run. Ó sì tún máa jẹ́ ká rí ẹ̀rí tó ṣe kedere pé Jésù ni Mèsáyà tí ọ̀pọ̀ ti ń retí láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.
Bíbélì Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ìgbà Ọmọdé Rẹ̀
6. Ṣàlàyé bí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 49:10 ṣe ní ìmúṣẹ.
6 Inú ẹ̀yà Júdà ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì ni wọ́n ti máa bí Mèsáyà. Nígbà tí Jékọ́bù ń súre fáwọn ọmọ rẹ̀ kó tó kú, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ọ̀pá aládé kì yóò yà kúrò lọ́dọ̀ Júdà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá àṣẹ kì yóò yà kúrò ní àárín ẹsẹ̀ rẹ̀, títí Ṣílò yóò fi dé; ìgbọràn àwọn ènìyàn yóò sì máa jẹ́ tirẹ̀.” (Jẹ́n. 49:10) Púpọ̀ lára àwọn ọ̀mọ̀wé Júù ìgbà yẹn ló gbà pé Mèsáyà ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn máa ṣẹ sí lára. Látìgbà tí Dáfídì Ọba tó wá látinú ẹ̀yà Júdà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ni ọ̀pá aládé (ipò àṣẹ gẹ́gẹ́ bí ọba) àti ọ̀pá àṣẹ (agbára láti pàṣẹ) kò ti kúrò nínú ẹ̀yà Júdà. “Ṣílò” túmọ̀ sí “Oní-nǹkan; Ẹni Tí Nǹkan Tọ́ Sí.” Ìlà ìdílé àwọn ọba látinú ẹ̀yà Júdà máa dópin nígbà tí “Ṣílò” tó jẹ́ Ajogún tí ipò ọba tọ́ sí títí gbére bá dé, torí Ọlọ́run sọ fún Sedekáyà tó jẹ́ ọba tó jẹ kẹ́yìn ní ìlà Júdà pé a óò fi ìṣàkóso fún ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí i lọ́nà òfin. (Ìsík. 21:26, 27) Lẹ́yìn Sedekáyà, Jésù nìkan ni àtọmọdọ́mọ Dáfídì tí Ìwé Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa jọba. Ṣáájú ìbí Jésù, áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ fún Màríà pé: “Jèhófà Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, kì yóò sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.” (Lúùkù 1:32, 33) Torí náà, Ṣílò ní láti jẹ́ Jésù Kristi tí í ṣe àtọmọdọ́mọ Júdà àti Dáfídì.—Mát. 1:1-3, 6; Lúùkù 3:23, 31-34.
7. Ibo ni wọ́n bí Mèsáyà sí, kí sì nìdí tí ìyẹn fi ṣe pàtàkì?
7 Ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n máa bí Mèsáyà sí. Wòlíì Míkà sọ pé: “Ìwọ, Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Éfúrátà, ẹni tí ó kéré jù láti wà lára àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún Júdà, inú rẹ ni ẹni tí yóò di olùṣàkóso Ísírẹ́lì yóò ti jáde tọ̀ mí wá, ẹni tí orírun rẹ̀ jẹ́ láti àwọn àkókò ìjímìjí, láti àwọn ọjọ́ tí ó jẹ́ àkókò tí ó lọ kánrin.” (Míkà 5:2) Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ìlú kan tó wà ní ilẹ̀ Júdà ni wọ́n máa bí Mèsáyà sí, ó sì dájú pé Éfúrátà ni orúkọ ìlú yìí tẹ́lẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú Násárétì ni Màríà, ìyá Jésù àti Jósẹ́fù, alágbàtọ́ rẹ̀ ń gbé, wọ́n ní láti lọ sí ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù torí pé àwọn alákòóso ìlú Róòmù pàṣẹ pé kí wọ́n lọ fórúkọ sílẹ̀ níbẹ̀. Ibẹ̀ sì ni wọ́n bí Jésù sí ní ọdún 2 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Mát. 2:1, 5, 6) Bó ṣe di pé wọ́n bí Jésù sí ibi tí àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé wọ́n máa bí i sí nìyẹn!
8, 9. Kí ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìbí Mèsáyà àtàwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá bí i?
8 Wúńdíá ló máa bí Mèsáyà. (Ka Aísáyà 7:14.) Ọ̀rọ̀ tó túmọ̀ sí “wúńdíá” lédè Hébérù ni bethu·lahʹ. Àmọ́ ọ̀rọ̀ Hébérù mìíràn (ʽal·mahʹ) fara hàn nínú ìwé Aísáyà 7:14. A sọ tẹ́lẹ̀ níbẹ̀ pé “omidan náà [ha·ʽal·mahʹ]” yóò bí ọmọkùnrin kan. Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà, ʽal·mahʹ fún omidan náà Rèbékà, kó tó di pé ó relé ọkọ. (Jẹ́n. 24:16, 43) Ọlọ́run mí sí Mátíù láti lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “wúńdíá” (par·theʹnos) nígbà tó ń fi hàn pé asọtẹ́lẹ̀ inú Aísáyà 7:14 ní ìmúṣẹ nígbà tí wọ́n bí Jésù. Àwọn òǹkọ̀wé Ìhìn Rere náà, Mátíù àti Lúùkù sọ pé wúńdíá ni Màríà ó sì lóyún nípasẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run.—Mát. 1:18-25; Lúùkù 1:26-35.
9 Wọ́n máa pa àwọn ọmọdé lẹ́yìn ìbí Mèsáyà. Ohun tó fara jọ èyí ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú, nígbà tí Fáráò ọba ilẹ̀ Íjíbítì pàṣẹ pé kí wọ́n máa ju gbogbo àwọn ọmọdékùnrin táwọn Hébérù bá bí sínú Odò Náílì. (Ẹ́kís. 1:22) Àmọ́, ó ṣe pàtàkì ká kíyè sí ìwé Jeremáyà 31:15, 16, tó sọ pé Rákélì ń sunkún nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n kó lọ sí “ilẹ̀ ọ̀tá.” Àwọn ará Rámà tó ń gbé níbi tó jìn, ní ìpínlẹ̀ Bẹ́ńjámínì tó wà ní àríwá Jerúsálẹ́mù, gbọ́ ìdárò rẹ̀. Mátíù fi hàn pé ìgbà tí Hẹ́rọ́dù Ọba pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọmọdékùnrin tó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti àgbègbè rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Jeremáyà yìí ní ìmúṣẹ. (Ka Mátíù 2:16-18.) Ìbànújẹ́ tó dé bá àwọn èèyàn ní àgbègbè yẹn á mà pọ̀ gan-an ni o!
10. Ṣàlàyé bí Hóséà 11:1 ṣe ṣẹ sí Jésù lára.
10 Bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì, a óò pe Mèsáyà láti Íjíbítì. (Hós. 11:1) Kó tó di pé Hẹ́rọ́dù pàṣẹ pé kí wọ́n lọ pa àwọn ọmọ ọwọ́, áńgẹ́lì kan ti sọ fún Jósẹ́fù pé kí òun, Màríà àti Jésù lọ sí Íjíbítì. Ibẹ̀ ni wọ́n sì wà “títí di ìgbà tí Hẹ́rọ́dù di olóògbé, kí a lè mú èyíinì tí Jèhófà sọ nípasẹ̀ [Hóséà] wòlíì rẹ̀ ṣẹ, pé: ‘Láti Íjíbítì ni mo ti pe ọmọkùnrin mi.’” (Mát. 2:13-15) Ó dájú pé kò lè ṣeé ṣe fún Jésù láti fi ọwọ́ ara rẹ̀ to gbogbo bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìbí rẹ̀ àtàwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tó wà lọ́mọdé ṣe ní ìmúṣẹ.
Mèsáyà Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Tí Ọlọ́run Rán An!
11. Báwo la ṣe palẹ̀ ọ̀nà mọ́ de Ẹni Àmì Òróró Jèhófà?
11 A ó palẹ̀ ọ̀nà mọ́ de Ẹni Àmì Òróró Ọlọ́run. Málákì sọ tẹ́lẹ̀ pé ‘wòlíì Èlíjà’ máa palẹ̀ ọ̀nà mọ́ de ẹni àmì òróró Ọlọ́run nípa mímúra ọkàn-àyà àwọn èèyàn sílẹ̀ de dídé Mèsáyà. (Ka Málákì 4:5, 6.) Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé Jòhánù Oníbatisí ni “Èlíjà” náà. (Mát. 11:12-14) Máàkù tún ṣàlàyé pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jòhánù mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Aísáyà ṣẹ. (Aísá. 40:3; Máàkù 1:1-4) Jésù kọ́ ló rán Jòhánù pé kó wá ṣe irú iṣẹ́ tí Èlíjà ṣe láti palẹ̀ ọ̀nà mọ́ de Òun. Iṣẹ́ tí “Èlíjà” tí Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ yìí gbé ṣe wà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tó wu Ọlọ́run pé kó gbà fi ẹni tó máa jẹ́ Mèsáyà hàn.
12. Iṣẹ́ wo la fi dá Mèsáyà mọ̀?
12 Iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé Mèsáyà lọ́wọ́ la fi dá a mọ̀. Nígbà tí Jésù wà nínú sínágọ́gù ní ìlú Násárétì tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà, ó ka àkájọ ìwé Aísáyà ó sì sọ pé òun ni àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣẹ sí lára. Àwọn ọ̀rọ̀ náà kà pé: “Ẹ̀mí Jèhófà ń bẹ lára mi, nítorí tí ó fòróró yàn mí láti polongo ìhìn rere fún àwọn òtòṣì, ó rán mi jáde láti wàásù ìtúsílẹ̀ fún àwọn òǹdè àti ìtúnríran fún àwọn afọ́jú, láti rán àwọn tí a ni lára lọ pẹ̀lú ìtúsílẹ̀, láti wàásù ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà.” Torí pé Jésù gangan ni Mèsáyà, ó tọ̀nà fún un láti sọ pé: “Lónìí, ìwé mímọ́ tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ tán yìí ní ìmúṣẹ.”—Lúùkù 4:16-21.
13. Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ní Gálílì?
13 Ìwé Mímọ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Mèsáyà ní Gálílì. Aísáyà kọ̀wé nípa “ilẹ̀ Sébúlúnì àti ilẹ̀ Náfútálì . . . Gálílì àwọn orílẹ̀-èdè,” pé: “Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá. Ní ti àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ ibú òjìji, àní ìmọ́lẹ̀ ti tàn sórí wọn.” (Aísá. 9:1, 2) Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní ìlú Gálílì, ó sì ń gbé ní Kápánáúmù, níbi tí ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń gbé ní ilẹ̀ Sébúlúnì àti ilẹ̀ Náfútálì ti jàǹfààní ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tó mú tọ̀ wọ́n lọ. (Mát. 4:12-16) Ìlú Gálílì ni Jésù ti ṣe Ìwàásù Orí Òkè, èyí tó mú káwọn tó tẹ́tí sí i ronú jinlẹ̀, ibẹ̀ ló ti yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ibẹ̀ ló ti kọ́kọ́ ṣe iṣẹ́ ìyanu, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ibẹ̀ náà ló ti fara han ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn tó jíǹde. (Mát. 5:1–7:27; 28:16-20; Máàkù 3:13, 14; Jòh. 2:8-11; 1 Kọ́r. 15:6) Nípa báyìí, Jésù mú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣẹ nígbà tó wàásù ní “ilẹ̀ Sébúlúnì àti ilẹ̀ Náfútálì.” Àmọ́ ṣá o, Jésù tún lọ wàásù Ìjọba Ọlọ́run láwọn ibòmíràn nílẹ̀ Ísírẹ́lì.
Bíbélì Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Àwọn Nǹkan Míì Tí Mèsáyà Máa Ṣe
14. Báwo ni Sáàmù 78:2 ṣe ní ìmúṣẹ?
14 Mèsáyà máa lo àwọn àkàwé tàbí àpèjúwe láti sọ̀rọ̀. Nínú orin tí onísáàmù náà, Ásáfù kọ, ó sọ pé: “Èmi yóò la ẹnu mi nínú ọ̀rọ̀ òwe.” (Sm. 78:2) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jésù ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ sí lára? Ohun tí Mátíù sọ ló jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tó ti sọ̀rọ̀ nípa bí Jésù ṣe fi hóró músítádì àti ìwúkàrà ṣàpèjúwe Ìjọba Ọlọ́run, ó sọ pé: “[Jésù] kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láìsí àpèjúwe; kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì náà bàa lè ṣẹ, ẹni tí ó wí pé: ‘Ṣe ni èmi yóò la ẹnu mi pẹ̀lú àwọn àpèjúwe, èmi yóò kéde àwọn ohun tí a fi pa mọ́ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní gbangba.’” (Mát. 13:31-35) Lára ohun tó mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn lóye òtítọ́ tí Jésù fi kọ́ wọn nípa Jèhófà ni pé ó lo àwọn ọ̀rọ̀ òwe tàbí àkàwé.
15. Ṣàlàyé bí Aísáyà 53:4 ṣe ní ìmúṣẹ.
15 Mèsáyà máa ru àwọn àìlera wa. Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Lóòótọ́, àwọn àìsàn wa ni òun fúnra rẹ̀ gbé; àti pé ní ti ìrora wa, ó rù wọ́n.” (Aísá. 53:4) Mátíù ṣàlàyé pé lẹ́yìn tí Jésù ti mú ìyá ìyàwó Pétérù lára dá, ó wo àwọn mìíràn sàn “kí a lè mú ohun tí a sọ nípasẹ̀ Aísáyà wòlíì ṣẹ, pé: ‘Òun fúnra rẹ̀ gba àwọn àìsàn wa, ó sì ru àwọn òkùnrùn wa.’” (Mát. 8:14-17) Ọ̀kan lèyí jẹ́ lára ọ̀pọ̀ ìmúláradá tí Bíbélì sọ pé Jésù ṣe.
16. Báwo ni ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ ṣe fi hàn pé Jésù ni Aísáyà 53:1 ṣẹ sí lára?
16 Láìka gbogbo ohun rere tí Mèsáyà máa ṣe sí, ọ̀pọ̀ èèyàn kò ní ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. (Ka Aísáyà 53:1.) Láti fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ, àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé [Jésù] ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì níwájú wọn, wọn kì í ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí ọ̀rọ̀ Aísáyà wòlíì fi ṣẹ tí ó wí pé: ‘Jèhófà, ta ni ó ti lo ìgbàgbọ́ nínú ohun tí a gbọ́? Ní ti apá Jèhófà, ta sì ni a ti ṣí i payá fún?’” (Jòh. 12:37, 38) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, díẹ̀ làwọn èèyàn tó ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere tó dá lórí Jésù, tí í ṣe Mèsáyà.—Róòmù 10:16, 17.
17. Báwo ní Sáàmù 69:4 ṣe ní ìmúṣẹ?
17 Àwọn èèyàn máa kórìíra Mèsáyà láìnídìí. (Sm. 69:4) Àpọ́sítélì Jòhánù sọ ohun tó gbọ́ lẹ́nu Jésù, ó ní: “Ká ní èmi kò ti ṣe àwọn iṣẹ́ tí ẹlòmíràn kankan kò ṣe láàárín [àwọn èèyàn náà] ni, wọn kì bá ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan; ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọ́n ti rí, wọ́n sì ti kórìíra èmi àti Baba mi. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ láti lè mú ọ̀rọ̀ tí a kọ sínú Òfin wọn ṣẹ pé, ‘Wọ́n kórìíra mi láìnídìí.’” (Jòh. 15:24, 25) Lọ́pọ̀ ìgbà “Òfin” túmọ̀ sí àpapọ̀ àwọn ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́. (Jòh. 10:34; 12:34) Àwọn Ìwé Ìhìn rere fi hàn pé àwọn èèyàn kórìíra Jésù, pàápàá àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù. Síwájú sí i, Kristi sọ pé: “Ayé kò ní ìdí kankan láti kórìíra yín, ṣùgbọ́n ó kórìíra mi, nítorí mo ń jẹ́rìí nípa rẹ̀ pé àwọn iṣẹ́ rẹ̀ burú.”—Jòh. 7:7.
18. Kí la máa gbé yẹ̀ wò síwájú sí i tó máa mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jésù ni Mèsáyà?
18 Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní ọ̀rúndún kìíní gbà pé Jésù ni Mèsáyà torí pé ó ṣe kedere pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ṣẹ sí i lára. (Mát. 16:16) Gẹ́gẹ́ bí a sì ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ nígbà tí Jésù ará Násárétì wà lọ́mọdé àti nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì tó dá lórí Mèsáyà. Tá a bá ronú lé wọn lórí tàdúràtàdúrà, ó máa túbọ̀ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jésù Kristi gangan ni Mèsáyà tí Jèhófà, Baba wa ọ̀run yàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa “àádọ́rin ọ̀sẹ̀” náà, wo orí 11 nínú ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì!
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ mọ́ ìbí Jésù wo ló ní ìmúṣẹ?
• Báwo la ṣe palẹ̀ ọ̀nà mọ́ de Mèsáyà?
• Àsọtẹ́lẹ̀ inú Aísáyà orí 53 wo ló ṣẹ sí Jésù lára?