Jẹ́nẹ́sísì
24 Ábúráhámù ti wá darúgbó, ó ti lọ́jọ́ lórí, Jèhófà sì ti bù kún Ábúráhámù ní gbogbo ọ̀nà.+ 2 Ábúráhámù sọ fún ìránṣẹ́ tó dàgbà jù nínú agbo ilé rẹ̀, tó sì ń bójú tó gbogbo ohun ìní+ rẹ̀ pé: “Jọ̀ọ́, fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi, 3 mo fẹ́ kí o fi Jèhófà, Ọlọ́run ọ̀run àti Ọlọ́run ayé búra, pé o ò ní fẹ́ ìyàwó fún ọmọ mi nínú àwọn ọmọbìnrin Kénáánì tí mò ń gbé+ láàárín wọn. 4 Àmọ́ kí o lọ sí ilẹ̀ tí mo ti wá, lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí+ mi, kí o sì mú ìyàwó wá fún Ísákì ọmọ mi.”
5 Ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ náà bi í pé: “Tí obìnrin náà ò bá fẹ́ bá mi wá sí ilẹ̀ yìí ńkọ́? Ṣé kí n mú ọmọ rẹ pa dà sí ilẹ̀ tí o ti wá+ ni?” 6 Ni Ábúráhámù bá fèsì pé: “O ò gbọ́dọ̀ mú ọmọ mi lọ síbẹ̀+ o. 7 Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run, ẹni tó mú mi kúrò ní ilé bàbá mi àti ilẹ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí+ mi, ẹni tó bá mi sọ̀rọ̀, tó sì búra fún mi+ pé: ‘Ọmọ*+ rẹ ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ yìí,’+ yóò rán áńgẹ́lì rẹ̀ lọ ṣáájú rẹ,+ ó sì dájú pé wàá mú ìyàwó wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀.+ 8 Àmọ́ tí obìnrin náà ò bá fẹ́ bá ọ wá, ìwọ yóò bọ́ nínú ìbúra yìí. O ò gbọ́dọ̀ mú ọmọ mi lọ síbẹ̀ o.” 9 Ìránṣẹ́ náà wá fi ọwọ́ rẹ̀ sí abẹ́ itan Ábúráhámù ọ̀gá rẹ̀, ó sì búra fún un nípa ọ̀rọ̀ yìí.+
10 Torí náà, ìránṣẹ́ náà mú mẹ́wàá lára ràkúnmí ọ̀gá rẹ̀, ó sì lọ. Ó mú oríṣiríṣi nǹkan tó dára dání látọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀. Ó wá forí lé Mesopotámíà, ó lọ sí ìlú Náhórì. 11 Ó mú kí àwọn ràkúnmí náà kúnlẹ̀ síbi kànga omi kan lẹ́yìn ìlú náà. Ó jẹ́ nǹkan bí ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, ní àsìkò tí àwọn obìnrin máa ń lọ fa omi. 12 Ó wá sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run ọ̀gá mi Ábúráhámù, jọ̀ọ́, jẹ́ kí n ṣàṣeyọrí lónìí, kí o sì fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí Ábúráhámù ọ̀gá mi. 13 Ibi ìsun omi ni mo wà báyìí, àwọn ọmọbìnrin ìlú yìí sì ti ń jáde wá fa omi. 14 Jẹ́ kó ṣẹlẹ̀ pé ọ̀dọ́bìnrin tí mo bá sọ fún pé, ‘Jọ̀ọ́, sọ ìṣà omi rẹ kalẹ̀, kí n lè mu omi,’ tó sì fèsì pé, ‘Gba omi, màá sì tún fún àwọn ràkúnmí rẹ lómi,’ kí ó jẹ́ ẹni tí wàá yàn fún Ísákì ìránṣẹ́ rẹ; kí èyí sì jẹ́ kí n mọ̀ pé o ti fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí ọ̀gá mi.”
15 Kó tó sọ̀rọ̀ tán, Rèbékà ti ń jáde bọ̀, ó sì gbé ìṣà omi rẹ̀ lé èjìká. Òun ni ọmọ Bẹ́túẹ́lì,+ ọmọ Mílíkà+ ìyàwó Náhórì,+ arákùnrin Ábúráhámù. 16 Ọmọbìnrin náà rẹwà gan-an, wúńdíá ni; ọkùnrin kankan ò bá a lò pọ̀ rí. Ó sọ̀ kalẹ̀ wá síbi ìsun omi náà, ó pọn omi kún ìṣà rẹ̀, ó sì gòkè pa dà. 17 Ni ìránṣẹ́ náà bá sáré lọ bá a, ó sì sọ pé: “Jọ̀ọ́, fún mi ní omi díẹ̀ mu látinú ìṣà omi rẹ.” 18 Ó fèsì pé: “Gba omi, olúwa mi.” Ló bá yára sọ ìṣà omi rẹ̀ sọ́wọ́, ó sì fún un ní omi mu. 19 Nígbà tó fún un ní omi tán, ó sọ pé: “Màá tún fa omi fún àwọn ràkúnmí rẹ títí wọ́n á fi mumi tẹ́rùn.” 20 Ló bá yára da omi tó wà nínú ìṣà rẹ̀ sínú ọpọ́n ìmumi, ó ń sáré lọ sáré bọ̀ síbi kànga náà kó lè fa omi, ó sì ń fa omi kó lè fún gbogbo àwọn ràkúnmí náà lómi. 21 Ní gbogbo àkókò yìí, ọkùnrin náà dákẹ́, ó sì ń wò ó tìyanutìyanu, ó ń wò ó bóyá Jèhófà ti mú kí ohun tí òun bá wá yọrí sí rere tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.
22 Nígbà tí àwọn ràkúnmí náà mumi tán, ọkùnrin náà mú òrùka wúrà tí wọ́n ń fi sí imú, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ìlàjì ṣékélì* àti ẹ̀gbà ọwọ́ méjì tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì* mẹ́wàá, ó sì fún obìnrin náà, 23 ó wá bi í pé: “Jọ̀ọ́ sọ fún mi, ọmọ ta ni ọ́? Ṣé yàrá kankan wà ní ilé bàbá rẹ tí a lè sùn mọ́jú?” 24 Ló bá fèsì pé: “Èmi ni ọmọbìnrin Bẹ́túẹ́lì,+ ọmọkùnrin tí Mílíkà bí fún Náhórì.”+ 25 Ó tún sọ pé: “A ní pòròpórò àti oúnjẹ ẹran tó pọ̀, a sì ní ibi tí ẹ lè sùn mọ́jú.” 26 Ọkùnrin náà wá tẹrí ba, ó wólẹ̀ síwájú Jèhófà, 27 ó nì: “Ìyìn yẹ Jèhófà, Ọlọ́run ọ̀gá mi Ábúráhámù, torí ó ṣì nífẹ̀ẹ́ tí kì í yẹ̀ sí ọ̀gá mi, ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí i. Jèhófà ti darí mi wá sí ilé àwọn mọ̀lẹ́bí ọ̀gá mi.”
28 Ọmọbìnrin náà sì sáré lọ sí agbo ilé ìyá rẹ̀ láti sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wọn. 29 Rèbékà ní arákùnrin kan tó ń jẹ́ Lábánì.+ Lábánì wá sáré lọ bá ọkùnrin náà níta níbi ìsun omi. 30 Nígbà tó rí òrùka imú àti ẹ̀gbà ọwọ́ ní ọwọ́ arábìnrin rẹ̀, tó sì gbọ́ ohun tí Rèbékà arábìnrin rẹ̀ sọ pé, “Ohun tí ọkùnrin náà sọ fún mi nìyí,” ó wá bá ọkùnrin náà níbi tó ṣì dúró sí lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ràkúnmí níbi ìsun omi. 31 Ló bá sọ pé: “Máa bọ̀, ìwọ ẹni tí Jèhófà bù kún. Kí ló dé tí o fi dúró síta níbí? Mo ti ṣètò ibi tí wàá dé sí nínú ilé àti ibi tí àwọn ràkúnmí rẹ máa wà.” 32 Ọkùnrin náà bá wá sínú ilé, ó* tú ìjánu àwọn ràkúnmí, ó sì fún àwọn ràkúnmí náà ní pòròpórò àti oúnjẹ ẹran, ó tún fún ọkùnrin náà ní omi láti fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ àti ẹsẹ̀ àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ wá. 33 Àmọ́, nígbà tí wọ́n gbé oúnjẹ fún un, ó ní: “Mi ò ní jẹun títí màá fi sọ ohun tí mo fẹ́ sọ fún ọ.” Lábánì fèsì pé: “Ó yá, mò ń gbọ́!”
34 Ó wá sọ pé: “Ìránṣẹ́+ Ábúráhámù ni mí. 35 Jèhófà sì ti bù kún ọ̀gá mi gan-an, ó ti mú kó lọ́rọ̀ gidigidi torí ó fún un ní àwọn àgùntàn àti màlúù, fàdákà àti wúrà, àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, àwọn ràkúnmí àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.+ 36 Lẹ́yìn tí Sérà ìyàwó ọ̀gá mi darúgbó,+ ó bí ọmọkùnrin kan fún ọ̀gá mi, ọmọ yìí ni yóò sì jogún gbogbo ohun tí ọ̀gá mi ní.+ 37 Torí náà, ọ̀gá mi mú kí n búra, ó sọ pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ fẹ́ ìyàwó fún ọmọ mi láàárín àwọn ọmọ Kénáánì tí mò ń gbé+ ní ilẹ̀ wọn. 38 Àmọ́ kí o lọ sí ilé bàbá mi, sí ọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí+ mi, kí o sì mú ìyàwó fún ọmọ+ mi níbẹ̀.’ 39 Àmọ́ mo bi ọ̀gá mi pé: ‘Tí obìnrin náà ò bá fẹ́ bá mi wá+ ńkọ́?’ 40 Ó sọ fún mi pé: ‘Jèhófà, ẹni tí mò ń bá rìn+ máa rán áńgẹ́lì+ rẹ̀ pé kó wà pẹ̀lú rẹ, á mú kí ìrìn àjò rẹ yọrí sí rere, kí o sì mú ìyàwó fún ọmọ mi látọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí mi, ní ilé bàbá+ mi. 41 Ìwọ yóò bọ́ nínú ìbúra tí o ṣe fún mi, tí o bá lọ sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí mi àmọ́ tí wọn ò fún ọ ní obìnrin náà. Ìyẹn ló máa mú kí o bọ́ nínú ìbúra+ tí o ṣe.’
42 “Nígbà tí mo dé ibi ìsun omi lónìí, mo sọ pé: ‘Jèhófà Ọlọ́run ọ̀gá mi Ábúráhámù, tí o bá mú kí ohun tí mo bá wá yọrí sí rere, 43 níbi ìsun omi tí mo dúró sí yìí, jẹ́ kó ṣẹlẹ̀ pé tí ọmọbìnrin+ kan bá wá fa omi, màá sọ fún un pé: “Jọ̀ọ́, fún mi ní omi díẹ̀ mu látinú ìṣà omi rẹ,” 44 kí ó fèsì pé: “Gba omi, màá sì tún fa omi fún àwọn ràkúnmí rẹ.” Kí obìnrin yẹn jẹ́ ẹni tí Jèhófà yàn fún ọmọ ọ̀gá+ mi.’
45 “Kí n tó gbàdúrà tán nínú ọkàn mi, Rèbékà ti ń jáde bọ̀, ó gbé ìṣà omi rẹ̀ lé èjìká, ó sọ̀ kalẹ̀ lọ síbi ìsun omi náà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fa omi. Mo wá sọ fún un pé: ‘Jọ̀ọ́,+ fún mi lómi mu.’ 46 Ló bá yára sọ ìṣà omi rẹ̀ kúrò ní èjìká, ó sì sọ pé: ‘Gba omi,+ màá sì tún fún àwọn ràkúnmí rẹ lómi.’ Ni mo bá mu omi, ó sì fún àwọn ràkúnmí náà lómi. 47 Lẹ́yìn náà, mo bi í pé, ‘Ọmọ ta ni ọ́?’ Ó fèsì pé, ‘Èmi ni ọmọbìnrin Bẹ́túẹ́lì, ọmọkùnrin tí Mílíkà bí fún Náhórì.’ Mo bá fi òrùka náà sí imú rẹ̀, mo sì fi àwọn ẹ̀gbà ọwọ́ náà sí ọwọ́ rẹ̀.+ 48 Mo wá tẹrí ba, mo wólẹ̀ síwájú Jèhófà, mo sì yin Jèhófà, Ọlọ́run ọ̀gá mi Ábúráhámù,+ ẹni tó darí mi sí ọ̀nà tó tọ́, kí n lè mú ọmọ mọ̀lẹ́bí ọ̀gá mi lọ fún Ísákì ọmọ rẹ̀. 49 Tí ẹ bá máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ọ̀gá mi, tí ẹ sì fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí i, ẹ sọ fún mi; àmọ́ tí ẹ ò bá ní ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ sọ fún mi, kí n lè mọ ibi tí màá yà sí.”*+
50 Lábánì àti Bẹ́túẹ́lì fèsì pé: “Jèhófà ló mú kí èyí ṣẹlẹ̀. A ò lè sọ fún ọ pé bẹ́ẹ̀ ni àbí bẹ́ẹ̀ kọ́.* 51 Rèbékà ló wà níwájú rẹ yìí. Mú un, kí o máa lọ, kó sì di ìyàwó ọmọ ọ̀gá rẹ, bí Jèhófà ṣe sọ.” 52 Nígbà tí ìránṣẹ́ Ábúráhámù gbọ́ ohun tí wọ́n sọ, ojú ẹsẹ̀ ló tẹrí ba mọ́lẹ̀ níwájú Jèhófà. 53 Ìránṣẹ́ náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn nǹkan tí wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe àti aṣọ, ó kó wọn fún Rèbékà, ó sì fún arákùnrin rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ ní àwọn nǹkan iyebíye. 54 Lẹ́yìn náà, òun àti àwọn ọkùnrin tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ jẹun, wọ́n mu, wọ́n sì sun ibẹ̀ mọ́jú.
Nígbà tó jí ní àárọ̀, ó ní: “Ẹ jẹ́ kí n máa lọ sọ́dọ̀ ọ̀gá mi.” 55 Arákùnrin obìnrin náà àti ìyá rẹ̀ sọ pé: “Jẹ́ kí ọmọbìnrin náà ṣì wà lọ́dọ̀ wa fún ọjọ́ mẹ́wàá, ó kéré tán. Lẹ́yìn náà, ó lè máa lọ.” 56 Àmọ́ ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe dá mi dúró, torí ó hàn pé Jèhófà ti mú kí ohun tí mo bá wá yọrí sí rere. Ẹ jẹ́ kí n máa lọ, kí n lè lọ bá ọ̀gá mi.” 57 Wọ́n wá sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká pe ọmọbìnrin náà, ká sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” 58 Wọ́n pe Rèbékà, wọ́n sì bi í pé: “Ṣé wàá bá ọkùnrin yìí lọ?” Ó fèsì pé: “Màá bá a lọ.”
59 Torí náà, wọ́n jẹ́ kí Rèbékà+ arábìnrin wọn àti olùtọ́jú*+ rẹ̀ tẹ̀ lé ìránṣẹ́ Ábúráhámù àti àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ wá. 60 Wọ́n súre fún Rèbékà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Arábìnrin wa, wàá di ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún,* àtọmọdọ́mọ* rẹ yóò sì gba ẹnubodè* àwọn tó kórìíra wọn lọ́wọ́ wọn.”+ 61 Rèbékà àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ wá dìde, wọ́n gun ràkúnmí, wọ́n sì tẹ̀ lé ọkùnrin náà. Bí ìránṣẹ́ náà ṣe mú Rèbékà nìyẹn, ó sì mú un lọ.
62 Ísákì ti dé láti agbègbè Bia-laháí-róì,+ torí ilẹ̀ Négébù+ ló ń gbé. 63 Ísákì sì ń rìn nínú pápá lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ kó lè ṣe àṣàrò.+ Nígbà tó gbójú sókè, ó rí àwọn ràkúnmí tó ń bọ̀! 64 Nígbà tí Rèbékà gbójú sókè, ó rí Ísákì, ó sì yára sọ̀ kalẹ̀ látorí ràkúnmí. 65 Ó wá bi ìránṣẹ́ náà pé: “Ta ni ọkùnrin yẹn tó ń rìn bọ̀ wá pàdé wa látinú pápá?” Ìránṣẹ́ náà fèsì pé: “Ọ̀gá mi ni.” Rèbékà wá mú ìborùn rẹ̀, ó sì fi bo ara rẹ̀. 66 Ìránṣẹ́ náà sì sọ gbogbo ohun tí òun ṣe fún Ísákì. 67 Lẹ́yìn náà, Ísákì mú Rèbékà wá sínú àgọ́ Sérà ìyá rẹ̀.+ Ó fi Rèbékà ṣe aya; ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀+ gan-an, Ísákì sì rí ìtùnú lẹ́yìn tí ìyá+ rẹ̀ kú.