ORÍ 122
Àdúrà Tí Jésù Gbà Kẹ́yìn ní Yàrá Tó Wà Lókè
OHUN TÓ MÁA ṢẸLẸ̀ TẸ́NÌ KAN BÁ MỌ ỌLỌ́RUN ÀTI ỌMỌ RẸ̀
ÌṢỌ̀KAN TÓ WÀ LÁÀÁRÍN JÈHÓFÀ, JÉSÙ ÀTÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN
Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ gan-an, ìdí nìyẹn tó fi ń múra ọkàn wọn sílẹ̀ torí pé kò ní pẹ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn. Ó wá gbójú sókè, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Baba rẹ̀, ó sọ pé: “Ṣe ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ lè ṣe ọ́ lógo, bí o ṣe fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ẹran ara, kó lè fún gbogbo àwọn tí o ti fún un ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 17:1, 2.
Kò sí iyèméjì pé Jésù mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn máa darí ògo sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Jésù tún jẹ́ ká mọ nǹkan míì tó lè fi wá lọ́kàn balẹ̀, ìyẹn ni ìyè àìnípẹ̀kun. Torí pé Ọlọ́run ti fún Jésù ní “àṣẹ lórí gbogbo ẹran ara,” ó máa ṣeé ṣe fún gbogbo èèyàn láti gbádùn ìbùkún tí ẹbọ ìràpadà rẹ̀ máa mú wá. Síbẹ̀, díẹ̀ làwọn tó máa rí ìbùkún yẹn gbà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìwọ̀nba àwọn tó bá ṣe ohun tí Jésù sọ tẹ̀ lé e yìí nìkan ló máa jàǹfààní ẹbọ ìràpadà náà, Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, pé kí wọ́n wá mọ ìwọ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo àti Jésù Kristi, ẹni tí o rán.”—Jòhánù 17:3.
Ohun tí Jésù sọ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ mọ Baba àti Ọmọ dáadáa, ká sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú wọn. A tún gbọ́dọ̀ máa wo nǹkan bí Jèhófà àti Jésù ṣe ń wò ó. Bákan náà, a gbọ́dọ̀ sapá láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn méjèèjì nínú ìwà wa. Yàtọ̀ síyẹn, a tún gbọ́dọ̀ gbà pé ó ṣe pàtàkì ká ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, torí pé ìyẹn ló máa mú ká rí ìyè àìnípẹ̀kun. Jésù wá pa dà sórí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Ó ní: “Mo ti yìn ọ́ lógo ní ayé, ní ti pé mo ti parí iṣẹ́ tí o ní kí n ṣe. Torí náà, ní báyìí, Baba, ṣe mí lógo lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ pẹ̀lú ògo tí mo ti ní lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ kí ayé tó wà.” (Jòhánù 17:4, 5) Jésù bẹ Jèhófà pé kó jí òun dìde, kó sì jẹ́ kóun tún pa dà ní irú ògo tóun ní nígbà tóun wà lọ́run.
Síbẹ̀, Jésù ò gbàgbé àṣeyọrí tó ti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ó gbàdúrà pé: “Mo ti fi orúkọ rẹ hàn kedere fún àwọn èèyàn tí o fún mi látinú ayé. Ìwọ lo ni wọ́n, o sì fi wọ́n fún mi, wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.” (Jòhánù 17:6) Kì í ṣe pé Jésù jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jèhófà lorúkọ Ọlọ́run nìkan ni. Ó tún ran àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run àti bó ṣe ń bá àwọn èèyàn lò.
Àwọn àpọ́sítélì yẹn ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, wọ́n ti mọ ohun tí Jésù wá ṣe láyé, Jésù sì ti kọ́ wọn ní ọ̀pọ̀ nǹkan. Síbẹ̀, Jésù ò jẹ́ káwọn nǹkan tóun ṣe yẹn kó sí òun lórí, ó sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ tí o sọ fún mi ni mo ti sọ fún wọn, wọ́n sì ti gbà á, ó dájú pé wọ́n ti wá mọ̀ pé mo wá bí aṣojú rẹ, wọ́n sì ti gbà gbọ́ pé ìwọ lo rán mi.”—Jòhánù 17:8.
Lẹ́yìn náà, Jésù jẹ́ ká rí i pé ìyàtọ̀ máa wà láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn òun àtàwọn èèyàn tó kù, ó ní: “Mo gbàdúrà nípa wọn; kì í ṣe nípa ayé, àmọ́ nípa àwọn tí o fún mi, torí pé ìwọ lo ni wọ́n . . . Baba mímọ́, máa ṣọ́ wọn nítorí orúkọ rẹ, tí o ti fún mi, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan bí àwa ṣe jẹ́ ọ̀kan. . . . Mo ti dáàbò bò wọ́n, ìkankan nínú wọn ò sì pa run àfi ọmọ ìparun,” ìyẹn Júdásì Ìsìkáríọ́tù tó jẹ́ pé bó ṣe máa da Jésù ló ń bá kiri.—Jòhánù 17:9-12.
Jésù ṣì ń bá àdúrà tó ń gbà lọ, ó ní: “Ayé ti kórìíra wọn . . . Mi ò ní kí o mú wọn kúrò ní ayé, àmọ́ kí o máa ṣọ́ wọn torí ẹni burúkú náà. Wọn kì í ṣe apá kan ayé, bí èmi ò ṣe jẹ́ apá kan ayé.” (Jòhánù 17:14-16) Inú ayé tí Èṣù ń darí yìí làwọn àpọ́sítélì yẹn àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù ń gbé, síbẹ̀ wọ́n gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó yàtọ̀ sóhun tí ayé ń ṣe, wọn ò sì gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ìwà burúkú táwọn èèyàn ń hù. Kí ló máa mú kíyẹn ṣeé ṣe?
Ohun tó máa mú kó ṣeé ṣe ni pé wọ́n gbọ́dọ̀ ya ara wọn sọ́tọ̀, kí wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́ láti sin Ọlọ́run. Èyí gba pé kí wọ́n máa ṣe gbogbo ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àtàwọn nǹkan tí Jésù fúnra rẹ̀ kọ́ wọn. Jésù gbàdúrà pé: “Sọ wọ́n di mímọ́ nípasẹ̀ òtítọ́; òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Tó bá yá, Ọlọ́run máa mí sí àwọn kan lára àwọn àpọ́sítélì yẹn láti kọ àwọn ìwé táá di apá kan “òtítọ́” tó máa sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di mímọ́.
Ó dájú pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì máa gba “òtítọ́” yẹn. Torí náà, Jésù gbàdúrà pé: “Kì í ṣe àwọn yìí nìkan [ìyẹn àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn] ni mò ń gbàdúrà nípa wọn, mo tún ń gbàdúrà nípa àwọn tó máa ní ìgbàgbọ́ nínú mi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn.” Kí ni Jésù ń gbàdúrà pé kó ṣẹlẹ̀ sí wọn? Ó sọ pé: “Kí gbogbo wọn lè jẹ́ ọ̀kan, bí ìwọ Baba ṣe wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, tí mo sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ, kí àwọn náà lè wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wa.” (Jòhánù 17:20, 21) Èyí ò túmọ̀ sí pé ẹnì kan ṣoṣo ni Jésù àti Baba rẹ̀. Àmọ́ ọ̀kan ni wọ́n torí pé ohùn wọn máa ń ṣọ̀kan nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe. Jésù wá gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn òun náà máa gbádùn irú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀.
Ṣáájú ìgbà yẹn ni Jésù ti sọ fún Pétérù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù pé òun fẹ́ lọ pèsè ibì kan sílẹ̀ fún wọn ní ọ̀run. (Jòhánù 14:2, 3) Jésù wá fi ọ̀rọ̀ yìí sádùúrà, ó ní: “Baba, mo fẹ́ kí àwọn tí o fún mi wà pẹ̀lú mi níbi tí mo bá wà, kí wọ́n lè rí ògo mi tí o ti fún mi, torí pé o ti nífẹ̀ẹ́ mi ṣáájú kí o tó pilẹ̀ ayé.” (Jòhánù 17:24) Ohun tó sọ yìí jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run ti nífẹ̀ẹ́ Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo yìí, kódà ṣáájú kí Ádámù àti Éfà tó bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ.
Bí Jésù ṣe ń parí àdúrà yẹn, ó tún pa dà sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Baba rẹ̀ àti bí Baba ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn àpọ́sítélì àtàwọn míì tó ṣì máa kẹ́kọ̀ọ́ “òtítọ́” tó bá yá. Ó sọ pé: “Mo ti jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ, màá sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ ọ́n, kí ìfẹ́ tí o ní fún mi lè wà nínú wọn, kí n sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wọn.”—Jòhánù 17:26.