Ẹ̀KỌ́ 23
Ìrìbọmi Ṣe Pàtàkì!
Jésù kọ́ wa pé ó pọn dandan káwọn tó bá fẹ́ di Kristẹni ṣèrìbọmi. (Ka Mátíù 28:19, 20.) Àmọ́, kí ni ìrìbọmi? Kí sì ni ẹnì kan gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè ṣèrìbọmi?
1. Kí ni ìrìbọmi?
Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí ìrìbọmi túmọ̀ sí “rì bọ” inú omi. Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, Jòhánù rì í bọ inú Odò Jọ́dánì. Lẹ́yìn náà, ó “jáde látinú omi.” (Máàkù 1:9, 10) Lọ́nà kan náà, tí àwa Kristẹni tòótọ́ bá fẹ́ ṣèrìbọmi, ńṣe la máa ń ri ẹni náà bọ inú omi pátápátá.
2. Kí lẹni tó ṣèrìbọmi ń fi hàn?
Tẹ́nì kan bá ṣèrìbọmi, ńṣe lonítọ̀hún ń fi hàn pé òun ti ya ara òun sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run. Báwo la ṣe ń ṣe ìyàsímímọ́? Kẹ́nì kan tó ṣèrìbọmi, ó máa kọ́kọ́ gbàdúrà sí Jèhófà lóun nìkan, á sì sọ fún un pé ó wu òun láti máa sìn ín títí ayé. Ó máa ṣèlérí pé Jèhófà nìkan lòun á máa sìn àti pé ìfẹ́ Jèhófà lòun á fi sí ipò àkọ́kọ́ láyé òun. Ó máa pinnu pé ‘òun á sẹ́ ara òun, òun á sì máa tẹ̀ lé’ àwọn ẹ̀kọ́ àti àpẹẹrẹ Jésù. (Mátíù 16:24) Ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi yìí máa jẹ́ kó lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin.
3. Àwọn nǹkan wo ló yẹ kẹ́nì kan ṣe kó tó lè ṣèrìbọmi?
Tó o bá fẹ́ ṣèrìbọmi, ó ṣe pàtàkì pé kó o kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kó o sì ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú rẹ̀. (Ka Hébérù 11:6.) Bí ìmọ̀ rẹ ṣe ń pọ̀ sí i, tí ìgbàgbọ́ rẹ sì ń lágbára sí i, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ó dájú pé á máa wù ẹ́ láti sọ fún àwọn èèyàn nípa Jèhófà, wàá sì fẹ́ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ. (2 Tímótì 4:2; 1 Jòhánù 5:3) Tó o bá ti ń gbé ìgbé ayé rẹ “lọ́nà tó yẹ Jèhófà láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní kíkún,” o lè pinnu láti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà kó o sì ṣèrìbọmi.—Kólósè 1:9, 10.a
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Wo ohun tó o lè kọ́ nínú ìrìbọmi Jésù àtàwọn nǹkan tó yẹ kẹ́nì kan ṣe tó bá fẹ́ ṣèrìbọmi.
4. Ohun tá a rí kọ́ nínú ìrìbọmi Jésù
Ka Mátíù 3:13-17 kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ìrìbọmi Jésù. Lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Ṣé ọmọ ọwọ́ ni Jésù nígbà tó ṣèrìbọmi?
Báwo ni wọ́n ṣe ṣèrìbọmi fún Jésù? Ṣé wọ́n kàn wọ́n omi lé e lórí ni?
Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pàtàkì tí Jèhófà gbé fún un. Ka Lúùkù 3:21-23 àti Jòhánù 6:38, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi, iṣẹ́ wo ni Jésù fi sípò àkọ́kọ́ láyé rẹ̀?
5. Má bẹ̀rù láti ṣe ìrìbọmi
Ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi lè kọ́kọ́ dẹ́rù bà ẹ́. Àmọ́ bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i, ọkàn rẹ á túbọ̀ máa balẹ̀ láti gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì yìí. Kó o lè rí àpẹẹrẹ àwọn tó ti ṣe bẹ́ẹ̀, Wo FÍDÍÒ yìí.
Ka Jòhánù 17:3 àti Jémíìsì 1:5, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí ló lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ táá fi múra tán láti ṣèrìbọmi?
Tá a bá ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, ńṣe là ń sọ fún un pé ó wù wá láti máa sìn ín títí ayé
Tá a bá ń ṣèrìbọmi, ńṣe là ń sọ fáwọn tó wà níbẹ̀ pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run
6. Tẹ́nì kan bá ti ṣèrìbọmi, ó ti di ara ìdílé Jèhófà nìyẹn
Tá a bá ti ṣèrìbọmi, a ti di ara ìdílé kan tó wà níṣọ̀kan kárí ayé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la ti wá, bí wọ́n sì ṣe tọ́ wa dàgbà yàtọ̀ síra, síbẹ̀ ohun kan náà la gbà gbọ́, ìlànà ìwà rere kan náà la sì ń tẹ̀ lé. Ka Sáàmù 25:14 àti 1 Pétérù 2:17, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Tẹ́nì kan bá ti ṣèrìbọmi, báwo ni àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn tá a jọ ń sin Jèhófà ṣe máa rí?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Mi ò tíì ṣe tán láti ṣèrìbọmi.”
Ṣó o rò pé ó yẹ kéèyàn máa fi ìrìbọmi falẹ̀? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Jésù kọ́ wa pé ó pọn dandan káwọn tó bá fẹ́ di Kristẹni ṣèrìbọmi. Kí ẹnì kan tó lè ṣèrìbọmi, ó gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà, kó máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀, kó sì ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà.
Kí lo rí kọ́?
Kí ni ìrìbọmi, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì?
Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi?
Àwọn nǹkan wo ló yẹ kẹ́nì kan ṣe kó tó lè ṣe ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi?
ṢÈWÁDÌÍ
Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìrìbọmi.
Ka ìwé yìí kó o lè mọ àwọn nǹkan tó yẹ kẹ́nì kan ṣe kó tó lè ṣèrìbọmi.
“Tó O Bá Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Tó O sì Mọyì Rẹ̀, Wàá Ṣèrìbọmi” (Ilé Ìṣọ́, March 2020)
Ka ìwé yìí kó o lè rí i pé ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí ọkùnrin kan ní sí Ọlọ́run ló mú kó ṣèrìbọmi.
“Wọ́n Fẹ́ Kí Èmi Fúnra Mi Wádìí Láti Mọ Ohun Tí Bíbélì Sọ” (Ilé Ìṣọ́, February 1, 2013)
Ka ìwé yìí kó o lè rí i pé ìgbésẹ̀ pàtàkì ni ìrìbọmi. Wàá tún rí bó o ṣe lè múra sílẹ̀ fún ìrìbọmi.
a Tẹ́nì kan bá ti ṣèrìbọmi nínú ẹ̀sìn tó ń ṣe tẹ́lẹ̀, ńṣe la máa tún ìrìbọmi ṣe fún ẹni náà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ẹ̀sìn yẹn kò kọ́ni ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì.—Wo Ìṣe 19:1-5 àti Ẹ̀kọ́ 13.