Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Báwo la ṣe ń yan àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sípò nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan?
Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn alàgbà tí wọ́n wà ní ìjọ Éfésù pé: “Ẹ kíyè sí ara yín àti gbogbo agbo, láàárín èyí tí ẹ̀mí mímọ́ yàn yín ṣe alábòójútó, láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run, èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà.” (Ìṣe 20:28) Ipa wo ni ẹ̀mí mímọ́ ń kó nínú yíyan àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sípò lóde òní?
Àkọ́kọ́, ẹ̀mí mímọ́ mú káwọn tó kọ Bíbélì ṣàkọsílẹ̀ àwọn ohun tá a béèrè lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ di alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Àwọn nǹkan mẹ́rìndínlógún tá a béèrè lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ di alàgbà wà nínú 1 Tímótì 3:1-7. Àwọn ohun míì tá a béèrè wà nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Títù 1:5-9 àti Jákọ́bù 3:17, 18. Àwọn ohun tá a béèrè lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wà nínú 1 Tímótì 3:8-10, 12, 13. Èkejì, àwọn tó ń dábàá àwọn tó máa sìn àtàwọn tó ń yàn wọ́n sípò máa ń dìídì gbàdúrà pé kí ẹ̀mí Jèhófà darí àwọn báwọn ṣe ń gbé arákùnrin kan yẹ̀ wò bóyá ó kúnjú ìwọ̀n ohun tá a béèrè nínú Ìwé Mímọ́ dé ìwọ̀n tó yẹ. Ẹ̀kẹta, ẹni tí wọ́n ń dábàá náà ní láti máa fi èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣèwà hù nínú ìgbésí ayé rẹ̀. (Gál. 5:22, 23) Nítorí náà, ẹ̀mí Ọlọ́run ń kópa nínú gbogbo apá ìyànsípò náà.
Àmọ́, àwọn wo gan-an ló ń yan àwọn arákùnrin náà sípò? Ohun tá a máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ ni pé tá a bá dábàá àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún ìyànsípò, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa la máa ń fi gbogbo irú ìdábàá bẹ́ẹ̀ ránṣẹ́ sí. Àwọn arákùnrin tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí yàn wà níbẹ̀ tí wọ́n máa gbé àwọn ìdábàá náà yẹ̀ wò tí wọ́n á sì wá yan àwọn arákùnrin náà sípò. Lẹ́yìn náà, ẹ̀ka ọ́fíìsì á sọ fún ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà pé àwọn ti fọwọ́ sí ìyànsípò náà. Àwọn alàgbà á wá sọ fún àwọn ọkùnrin tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn náà pé wọ́n ti yàn wọ́n sípò, wọ́n á béèrè lọ́wọ́ wọn bóyá wọ́n fẹ́ láti sìn àti bóyá ohunkóhun wà tí kò ní jẹ́ kí wọ́n lè sìn. Níkẹyìn, wọ́n á ṣe ìfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ.
Ṣùgbọ́n, báwo ni wọ́n ṣe ń yan àwọn èèyàn sípò ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní? Nígbà míì, àwọn àpọ́sítélì máa ń yan àwọn èèyàn sípò kan ní pàtó, irú bí ìgbà tí wọ́n yan àwọn ọkùnrin méje sípò láti máa bójú tó pípín oúnjẹ fún àwọn opó lójoojúmọ́. (Ìṣe 6:1-6) Àmọ́, ó ṣeé ṣe kí àwọn ọkùnrin yẹn ti máa sìn nípò alàgbà kí wọ́n tó wá yàn wọ́n láti bójú tó iṣẹ́ pípín oúnjẹ.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ kò ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa bí wọ́n ṣe ń yan àwọn ọkùnrin sípò nígbà yẹn, àwọn ohun kan wà tó jẹ́ ká mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe é. Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ń pa dà sílé lẹ́yìn ìrìn àjò míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ tí wọ́n lọ, “wọ́n yan àwọn àgbà ọkùnrin sípò fún wọn nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan àti pé, ní gbígba àdúrà pẹ̀lú àwọn ààwẹ̀, wọ́n fi wọ́n lé Jèhófà lọ́wọ́, ẹni tí wọ́n ti di onígbàgbọ́ nínú rẹ̀.” (Ìṣe 14:23) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Títù tí wọ́n jọ máa ń rìnrìn àjò, ó ní: “Ìdí yìí ni mo fi fi ọ́ sílẹ̀ ní Kírétè, kí o lè ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí ó ní àbùkù, kí o sì lè yan àwọn àgbà ọkùnrin sípò láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá, gẹ́gẹ́ bí mo ti fún ọ ní àwọn àṣẹ ìtọ́ni.” (Títù 1:5) Bákan náà, ó jọ pé Pọ́ọ̀lù fún Tímótì tó ti rìnrìn àjò káàkiri pẹ̀lú rẹ̀ ní irú ọlá àṣẹ kan náà. (1 Tím. 5:22) Torí náà, ó ṣe kedere pé àwọn alábòójútó arìnrìn àjò ló ń yan àwọn ọkùnrin sípò nígbà yẹn, kì í ṣe àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin tó wà ní Jerúsálẹ́mù.
Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì yìí ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní lọ́kàn tó fi ṣe àtúnṣe sí ọ̀nà tá à ń gbà yan àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sípò. Bẹ̀rẹ̀ láti September 1, 2014, ọ̀nà tá à ń gbà yan àwọn èèyàn sípò rèé: Alábòójútó àyíká á fara balẹ̀ ṣàgbéyẹ̀wò ìdábàá táwọn alàgbà ìjọ tó wà nínú àyíká rẹ̀ ṣe. Nígbà ìbẹ̀wò tó ń ṣe sáwọn ìjọ, á gbìyànjú láti mọ àwọn tí wọ́n dábàá náà, á sì bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tó bá ṣeé ṣe. Lẹ́yìn tí òun àtàwọn alàgbà bá ti jíròrò nípa àwọn tí wọ́n dábàá náà, iṣẹ́ alábòójútó àyíká ni láti yan àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sípò nínú àwọn ìjọ tó wà nínú àyíká tó ń bójú tó. Lọ́nà yìí, ìṣètò náà túbọ̀ jọ ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní.
Ta ló ń bójú tó apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí yíyan àwọn èèyàn sípò pín sí? Bó ṣe rí látẹ̀yìn wá, iṣẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ni láti máa bọ́ àwọn ará ilé Ọlọ́run. (Mát. 24:45-47) Èyí kan wíwá inú Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ láti pèsè ìtọ́sọ́nà nípa bá a ṣe lè lo àwọn ìlànà Bíbélì tó dá lórí ṣíṣètò àwọn ìjọ kárí ayé. Ẹrú olóòótọ́ tún ń yan gbogbo àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. Ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ̀ọ̀kan á wá pèsè ìrànwọ́ tó gbéṣẹ́ káwọn ará lè máa tẹ̀ lé ìtọ́ni tí wọ́n rí gbà. Ojúṣe pàtàkì tí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà kọ̀ọ̀kan ní ni láti gbé àwọn arákùnrin tí wọ́n fẹ́ dábàá yẹ̀ wò kínníkínní bóyá wọ́n kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìyànsípò nínú ìjọ Ọlọ́run. Ojúṣe pàtàkì tí alábòójútó àyíká kọ̀ọ̀kan ní ni láti fara balẹ̀ ṣàgbéyẹ̀wò ìdábàá tí àwọn alàgbà ṣe, kó sì ṣe bẹ́ẹ̀ tàdúràtàdúrà. Lẹ́yìn náà, kó yan àwọn ọkùnrin tó bá kúnjú ìwọ̀n sípò.
Tá a bá lóye ọ̀nà tá à ń gbà yanni sípò nínú ìjọ, àá túbọ̀ mọyì ipa tí ẹ̀mí mímọ́ ń kó nínú bá a ṣe ń yan àwọn èèyàn sípò. Ìyẹn á jẹ́ ká lè fọkàn tán àwọn tá a yàn sípò nínú ìjọ ká sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn.—Heb. 13:7, 17.
Àwọn wo ni ẹlẹ́rìí méjì tí ìwé Ìṣípayá orí 11 sọ̀rọ̀ nípa wọn?
Ìwé Ìṣípayá 11:3 sọ nípa àwọn ẹlẹ́rìí méjì tí wọ́n á fi ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà [1,260] ọjọ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀. Lẹ́yìn náà ni àkọsílẹ̀ yìí sọ pé ẹranko ẹhànnà náà á “ṣẹ́gun wọn, yóò sì pa wọ́n.” Àmọ́ lẹ́yìn “ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀,” a jí àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà dìde, èyí sì ya gbogbo àwọn tó ń wò wọ́n lẹ́nu.—Ìṣí. 11:7, 11.
Àwọn wo ni ẹlẹ́rìí méjì yìí? Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ inú àkọsílẹ̀ náà jẹ́ ká mọ̀ wọ́n. Ohun àkọ́kọ́ tó sọ fún wa ni pé “a fi igi ólífì méjì àti ọ̀pá fìtílà méjì ṣàpẹẹrẹ” wọn. (Ìṣí. 11:4) Èyí rán wa létí àlàyé tí Sekaráyà ṣe nípa ọ̀pá fìtílà àti igi ólífì méjì nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Ó sọ pé àwọn igi ólífì yẹn ṣàpẹẹrẹ “àwọn ẹni àmì òróró méjì,” ìyẹn, Gómìnà Serubábélì àti Jóṣúà Àlùfáà Àgbà, tí wọ́n “ń dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ Olúwa gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Sek. 4:1-3, 14) Ohun kejì tó sọ ni pé àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà ń ṣiṣẹ́ àmì tó jọ èyí tí Mósè àti Èlíjà ṣe.—Fi Ìṣípayá 11:5, 6 wé Númérì 16:1-7, 28-35 àti 1 Àwọn Ọba 17:1; 18:41-45.
Kí ni ohun tí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí fi jọra? Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kọ̀ọ̀kan sọ nípa àwọn ẹni àmì òróró Ọlọ́run tí wọ́n ń mú ipò iwájú ni àkókò àdánwò tó le gan-an. Nítorí náà, nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ Ìṣípayá orí 11 ń ṣẹ, àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n ń mú ipò iwájú nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run fìdí múlẹ̀ lọ́run lọ́dún 1914, wàásù nínú “aṣọ àpò ìdọ̀họ” fún ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀.
Nígbà tí àkókò tí wọ́n fi wàásù nínú aṣọ àpò ìdọ̀họ náà parí, wọ́n pa àwọn ẹni àmì òróró náà lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nígbà tí wọ́n jù wọ́n sẹ́wọ̀n fún àkókò kúkúrú, èyí tó dúró fún ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀. Lójú àwọn ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run yìí, ńṣe ló dà bíi pé wọ́n ti pa iṣẹ́ àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà run, èyí sì mú inú àwọn ọ̀tá náà dùn gan-an.—Ìṣí. 11:8-10.
Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ti wí, nígbà tí ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ náà parí, a jí àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà dìde. Kì í ṣe pé wọ́n dá àwọn ẹni àmì òróró náà sílẹ̀ kúrò lẹ́wọ̀n nìkan ni, Ọlọ́run tún yan àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sípò pàtàkì kan nípasẹ̀ Olúwa wọn, Jésù Kristi. Lọ́dún 1919, wọ́n wà lára àwọn tí Ọlọ́run yàn láti jẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti máa bojú tó àwọn nǹkan tẹ̀mí táwọn èèyàn Ọlọ́run nílò ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.—Mát. 24:45-47; Ìṣí. 11:11, 12.
Kódà Ìṣípayá 11:1, 2 sọ pé àwọn nǹkan yìí máa wáyé ní igbà kan náà tí wọ́n máa wọn tẹ́ńpìlì tẹ̀mí tàbí tí wọ́n máa yẹ̀ ẹ́ wò. Málákì orí 3 náà sọ nípa irú àyẹ̀wò tẹ́ńpìlì tẹ̀mí yẹn, lẹ́yìn náà ni àkókò ìfọ̀mọ́ á wáyé. (Mál. 3:1-4) Báwo ni àkókò àyẹ̀wò àti ìfọ̀mọ́ yìí ṣe gùn tó? Ó bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1914 sí apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1919. Àkókò yìí jẹ́ àpapọ̀ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀fà [1,260] ọjọ́ (ìyẹn oṣù 42) àti ọjọ́ ìṣàpẹẹrẹ mẹ́ta àti ààbọ̀ tí Ìṣípayá orí 11 sọ̀rọ̀ rẹ̀.
Ẹ wo bí inú wa ṣe dùn tó pé Jèhófà ṣètò iṣẹ́ ìyọ́mọ́ nípa tẹ̀mí láti wẹ àwọn èèyàn tó jẹ́ àkànṣe mọ́ fún iṣẹ́ àtàtà! (Títù 2:14) A tún mọrírì àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró tí wọ́n mú ipò iwájú nígbà àdánwò náà, tí wọ́n sì wá tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ àwọn ẹlẹ́rìí méjì náà.a
a Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo Ilé Ìṣọ́ July 15, 2013, ojú ìwé 22, ìpínrọ̀ 12.