ORÍ 8
Ìjọ “Wọnú Àkókò Àlàáfíà”
Sọ́ọ̀lù alátakò tó burú gan-an di òjíṣẹ́ onítara
Ó dá lórí Ìṣe 9:1-43
1, 2. Kí ni Sọ́ọ̀lù fẹ́ lọ ṣe ní Damásíkù?
ÀWỌN arìnrìn àjò náà ti ń sún mọ́ Damásíkù, níbi tí wọ́n ti fẹ́ lọ ṣiṣẹ́ ibi tó wà lọ́kàn wọn. Wọ́n fẹ́ lọ fipá mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n kórìíra nínú ilé wọn, kí wọ́n dè wọ́n, kí wọ́n dójú tì wọ́n, kí wọ́n sì wọ́ wọn lọ sọ́dọ̀ ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn ní Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n lè fìyà jẹ wọ́n.
2 Sọ́ọ̀lù tó jẹ́ aṣáájú wọn ti lọ́wọ́ sí ikú ẹnì kan tẹ́lẹ̀.a Kò tíì pẹ́ sígbà yẹn táwọn agbawèrèmẹ́sìn bíi tiẹ̀ sọ Sítéfánù tó jẹ́ olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù lókùúta pa níṣojú ẹ̀. (Ìṣe 7:57–8:1) Síbẹ̀, inú ṣì ń bí i sáwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù, Sọ́ọ̀lù wá sọ ara rẹ̀ di irinṣẹ́ Èṣù láti tan inúnibíni kálẹ̀. Ó fẹ́ pa ẹ̀sìn tó kà sí eléwu, tí wọ́n ń pè ní “Ọ̀nà Náà” run.—Ìṣe 9:1, 2; wo àpótí náà, “Sọ́ọ̀lù Gbàṣẹ Láti Lọ Mú Àwọn Kristẹni ní Damásíkù.”
3, 4. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Sọ́ọ̀lù? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?
3 Lójijì ni ìmọ́lẹ̀ kan tàn yòò yí Sọ́ọ̀lù ká. Àwọn tó ń bá a rìnrìn àjò rí ìmọ́lẹ̀ náà, àmọ́ wọn ò lè sọ̀rọ̀ torí pé ẹ̀rù bà wọ́n. Ìmọ́lẹ̀ náà fọ́ Sọ́ọ̀lù lójú, ló bá ṣubú lulẹ̀. Sọ́ọ̀lù ò ríran mọ́, àmọ́ ó gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run tó sọ pé: “Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, kí nìdí tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi?” Ẹ̀rù ba Sọ́ọ̀lù, ó sì béèrè pé: “Ta ni ọ́, Olúwa?” Ó dájú pé ìdáhùn tí Sọ́ọ̀lù gbọ́ á mú kí ẹ̀rù túbọ̀ bà á, ohùn yẹn sọ pé: “Èmi ni Jésù, ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí.”—Ìṣe 9:3-5; 22:9.
4 Kí la lè rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù kọ́kọ́ sọ fún Sọ́ọ̀lù yìí? Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Sọ́ọ̀lù di Kristẹni? Kí la sì lè rí kọ́ látinú bí ìjọ ṣe lo àkókò àlàáfíà tí wọ́n ní lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù di Kristẹni?
“Kí Nìdí Tí O Fi Ń Ṣe Inúnibíni sí Mi?” (Ìṣe 9:1-5)
5, 6. Kí la rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún Sọ́ọ̀lù?
5 Nígbà tí Jésù dá Sọ́ọ̀lù dúró lójú ọ̀nà Damásíkù, kò béèrè pé: “Kí ló dé tó o fi ń ṣe inúnibíni sáwọn ọmọ ẹ̀yìn mi?” Bá a ṣe sọ lókè, ohun tí Jésù sọ ni pé: “Kí nìdí tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi?” (Ìṣe 9:4) Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù fúnra ẹ̀ mọ ìyà tó ń jẹ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ lára.—Mát. 25:34-40, 45.
6 Bí wọ́n bá ń ni ẹ́ lára torí ìgbàgbọ́ ẹ nínú Kristi, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà àti Jésù mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ. (Mát. 10:22, 28-31) Jèhófà lè má mú ìṣòro náà kúrò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Rántí pé Jésù rí bí Sọ́ọ̀lù ṣe lọ́wọ́ nínú ikú Sítéfánù, Jésù tún rí bó ṣe fipá mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ olóòótọ́ látinú ilé wọn ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 8:3) Síbẹ̀, Jésù ò dá sí i lákòókò náà. Àmọ́, Jèhófà tipasẹ̀ Kristi fún Sítéfánù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù lókun kí wọ́n lè jẹ́ olóòótọ́.
7. Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o ṣe kó o lè fara da inúnibíni?
7 Ìwọ náà lè fara da inúnibíni tó o bá ṣe àwọn nǹkan yìí: (1) Pinnu pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, wàá máa bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́. (2) Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Fílí. 4:6, 7) (3) Má ṣe gbẹ̀san, jẹ́ kí Jèhófà dá sọ̀rọ̀ náà. (Róòmù 12:17-21) (4) Fọkàn balẹ̀ pé Jèhófà máa fún ẹ lókun láti fara da inúnibíni títí dìgbà tó fi máa mú ìṣòro náà kúrò.—Fílí. 4:12, 13.
“Sọ́ọ̀lù, Arákùnrin, Jésù Olúwa . . . Ló Rán Mi” (Ìṣe 9:6-17)
8, 9. Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Ananáyà nígbà tí Jésù gbéṣẹ́ fún un?
8 Lẹ́yìn tí Jésù ti dáhùn ìbéèrè Sọ́ọ̀lù pé, “Ta ni ọ́, Olúwa?” Jésù sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Dìde, kí o sì wọnú ìlú, wọ́n á sọ ohun tí o máa ṣe fún ọ.” (Ìṣe 9:6) Sọ́ọ̀lù ò ríran mọ́ nígbà yẹn, torí náà àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ mú un lọ sí ilé tó fẹ́ dé sí ní Damásíkù. Ó sì gba ààwẹ̀ àti àdúrà níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. Láàárín àsìkò yẹn, Jésù ti sọ̀rọ̀ nípa Sọ́ọ̀lù fún ọmọ ẹ̀yìn kan tó ń jẹ́ Ananáyà. Ìlú Damásíkù ni ọmọ ẹ̀yìn náà ń gbé, “àwọn Júù tó ń gbé ibẹ̀ [sì] ròyìn rẹ̀ dáadáa.”—Ìṣe 22:12.
9 Ronú nípa bọ́rọ̀ náà ṣe máa rí lára Ananáyà! Jésù Kristi tó ti jíǹde, tó sì jẹ́ Orí ìjọ ló ń bá a sọ̀rọ̀, ó tún yàn án pé kó lọ ṣe iṣẹ́ pàtàkì kan. Àǹfààní ńlá mà nìyẹn o, àmọ́ iṣẹ́ kékeré kọ́! Nígbà tí Ananáyà gbọ́ pé òun máa lọ bá Sọ́ọ̀lù, ó sọ pé: “Olúwa, mo ti gbọ́ nípa ọkùnrin yìí lẹ́nu ọ̀pọ̀ èèyàn, mo ti gbọ́ gbogbo jàǹbá tó ṣe sí àwọn ẹni mímọ́ rẹ ní Jerúsálẹ́mù. Ní báyìí, ó ti gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn olórí àlùfáà láti mú gbogbo àwọn tó ń ké pe orúkọ rẹ.”—Ìṣe 9:13, 14.
10. Kí la rí kọ́ nínú bí Jésù ṣe bá Ananáyà sọ̀rọ̀?
10 Jésù ò bá Ananáyà wí torí pé ó sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀. Àmọ́, ó sọ ohun tó máa ṣe fún un lọ́nà tó ṣe kedere. Ó tún pọ́n ọn lé, torí ó sọ ìdí tó fi fẹ́ kó jẹ́ iṣẹ́ tó ṣàjèjì náà. Jésù sọ nípa Sọ́ọ̀lù pé: “Ohun èlò tí a ti yàn ni ọkùnrin yìí jẹ́ fún mi láti mú orúkọ mi lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nítorí màá fi hàn án ní kedere bí ìyà tó máa jẹ nítorí orúkọ mi ṣe máa pọ̀ tó.” (Ìṣe 9:15, 16) Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Ananáyà ṣe ohun tí Jésù sọ. Ó wá Sọ́ọ̀lù tó ń ṣenúnibíni sáwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ, nígbà tó sì rí i, ó sọ fún un pé: “Sọ́ọ̀lù, arákùnrin, Jésù Olúwa tó fara hàn ọ́ lójú ọ̀nà tí ò ń gbà bọ̀ ló rán mi kí o lè tún máa ríran, kí o sì kún fún ẹ̀mí mímọ́.”—Ìṣe 9:17.
11, 12. Kí la rí kọ́ nínú ìtàn yìí nípa Jésù, Ananáyà àti Sọ́ọ̀lù?
11 Ọ̀pọ̀ nǹkan la rí kọ́ nínú ìtàn yìí nípa Jésù, Ananáyà àti Sọ́ọ̀lù yìí. Bí àpẹẹrẹ, Jésù rí i pé òun ń darí iṣẹ́ ìwàásù bó ṣe ṣèlérí pé òun máa ṣe. (Mát. 28:20) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù kì í bá ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sọ̀rọ̀ ní tààràtà lóde òní, ó ń darí iṣẹ́ ìwàásù náà nípasẹ̀ ẹrú olóòótọ́ tó yàn láti máa bójú tó àwọn ará ilé rẹ̀. (Mát. 24:45-47) Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń bójú tó bí àwọn akéde àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà ṣe ń wá àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Kristi. Bá a ṣe rí i nínú orí tó ṣáájú, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn tá à ń wá lọ yìí ti gbàdúrà pé kí Ọlọ́run tọ́ àwọn sọ́nà, tí Jèhófà sì máa darí àwọn èèyàn rẹ̀ sọ́dọ̀ wọn.—Ìṣe 9:11.
12 Tọkàntọkàn ni Ananáyà fi gbà láti ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé fún un, Jèhófà sì bù kún un. Ṣéwọ náà máa ń ṣègbọràn sí àṣẹ tó sọ pé ká máa jẹ́rìí kúnnákúnná, tí ò bá tiẹ̀ rọrùn láti máa ṣe bẹ́ẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, ó lè má rọrùn fáwọn kan láti wàásù fún ẹni tí wọn ò mọ̀ rí, ẹ̀rù sì lè máa bà wọ́n tí wọ́n bá ń wàásù láti ilé dé ilé. Kì í rọrùn fáwọn míì láti wàásù fáwọn èèyàn níbi iṣẹ́, ní òpópónà, lórí tẹlifóònù tàbí nípasẹ̀ lẹ́tà. Ananáyà borí ẹ̀rù tó ń bà á, torí náà ó ran Sọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láti rí ẹ̀mí mímọ́ gbà.b Ó ṣàṣeyọrí torí pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jésù, ó sì gbà pé Sọ́ọ̀lù lè di arákùnrin òun. Bíi ti Ananáyà, àwa náà lè borí ẹ̀rù tó ń bà wá, tá a bá gbà pé Jésù ló ń darí iṣẹ́ ìwàásù, tá à ń fọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ro ara wa wò, tá a sì gbà pé àwọn tó burú gan-an ṣì lè di Kristẹni.—Mát. 9:36.
“Ó Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Wàásù Nípa Jésù” (Ìṣe 9:18-30)
13, 14. Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ tó ò tíì ṣèrìbọmi, kí lo lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Sọ́ọ̀lù?
13 Ojú ẹsẹ̀ ni Sọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́ lórí ohun tó kọ́. Lẹ́yìn tó pa dà ríran, ó ṣèrìbọmi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà ní Damásíkù. Àmọ́ ó ṣe jùyẹn lọ. “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nípa Jésù nínú àwọn sínágọ́gù, pé ẹni yìí ni Ọmọ Ọlọ́run.”—Ìṣe 9:20.
14 Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àmọ́ tó ò tíì ṣèrìbọmi, ṣé wàá pinnu láti fi ohun tó ò ń kọ́ sílò bíi ti Sọ́ọ̀lù? Òótọ́ ni pé iṣẹ́ ìyanu tí Kristi ṣe fún Sọ́ọ̀lù wà lára ohun tó mú kó pinnu láti di Kristẹni, tó sì ṣèrìbọmi. Àwọn míì náà rí iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Farisí kan wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù mú ọkùnrin kan tọ́wọ́ ẹ̀ rọ lára dá, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló sì mọ̀ pé Jésù jí Lásárù dìde. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ lára wọn ò ka iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe sí, àwọn kan tiẹ̀ ta kò ó. (Máàkù 3:1-6; Jòh. 12:9, 10) Àmọ́ ti Sọ́ọ̀lù yàtọ̀, ojú ẹsẹ̀ ló ronú pìwà dà, tó sì di ọmọ ẹ̀yìn. Kí ló mú kò di ọmọ ẹ̀yìn nígbà táwọn kan kọ̀ láti ṣẹ bẹ́ẹ̀? Ohun tó mú kó ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó bẹ̀rù Ọlọ́run ju èèyàn lọ, ó sì mọyì bí Kristi ṣe ṣàánú òun. (Fílí. 3:8) Tíwọ náà bá ṣe bíi ti Sọ́ọ̀lù, o ò ní jẹ́ kí ohunkóhun dí ẹ lọ́wọ́ láti máa wàásù, kó o sì ṣèrìbọmi.
15, 16. Kí ni Sọ́ọ̀lù ṣe nínú sínágọ́gù, kí làwọn Júù tó wà ní Damásíkù sì ṣe?
15 Fojú inú wo bí ẹnu ṣe máa ya àwọn èèyàn àti bínú á ṣe máa bí wọn nígbà tí wọ́n rí Sọ́ọ̀lù tó ń wàásù nípa Jésù nínú sínágọ́gù. Wọ́n sọ pé: “Ọkùnrin yìí kọ́ ló ń kó àwọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n ń ké pe orúkọ yìí ni?” (Ìṣe 9:21) Nígbà tí Sọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó mú kó yí èrò ẹ̀ pa dà nípa Jésù, ó “fi ẹ̀rí tó bọ́gbọ́n mu hàn pé Jésù ni Kristi náà.” (Ìṣe 9:22) Àmọ́, Sọ́ọ̀lù gbọ́dọ̀ ṣe ju pé kó fún àwọn èèyàn ní ẹ̀rí tó bọ́gbọ́n mu lọ. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ ẹ̀ ò nítumọ̀ sáwọn tí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àti ìgbéraga ti wọ̀ lẹ́wù. Síbẹ̀, Sọ́ọ̀lù ò jẹ́ kó sú òun.
16 Ní ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, àwọn Júù tó wà ní Damásíkù ṣì ń ta ko Sọ́ọ̀lù. Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n ṣe máa pa á. (Ìṣe 9:23; 2 Kọ́r. 11:32, 33; Gál. 1:13-18) Àmọ́, nígbà tí Sọ́ọ̀lù mọ̀ pé wọ́n fẹ́ pa òun, ó rọra fi ìlú náà sílẹ̀, ó jẹ́ kí wọ́n fi apẹ̀rẹ̀ gbé òun gba ojú ihò kan tó wà lára ògiri ìlú náà sọ̀ kalẹ̀. Lúùkù pe àwọn tó ran Sọ́ọ̀lù lọ́wọ́ láti jáde kúrò nílùú náà lálẹ́ ọjọ́ yẹn ní “àwọn ọmọ ẹ̀yìn [Sọ́ọ̀lù].” (Ìṣe 9:25) Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé, ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára àwọn tó gbọ́ ìwàásù Sọ́ọ̀lù ní Damásíkù yíwà pa dà, kí wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn Kristi.
17. (a) Kí làwọn kan máa ń ṣe tí wọ́n bá wàásù ìhìn rere fún wọn? (b) Kí ló yẹ ká máa ṣe, kí sì nìdí?
17 Nígbà tó o bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tó ò ń kọ́ fáwọn ìdílé ẹ, ọ̀rẹ́ ẹ àtàwọn ẹlòmíì, ó ṣeé ṣe kó o rò pé wọ́n máa tẹ́wọ́ gbà á torí pé ẹ̀kọ́ Bíbélì bọ́gbọ́n mu. Àwọn kan ti lè tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ẹ, àwọn míì sì lè má ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà, àwọn ará ilé ẹ kan ti lè sọ ẹ́ dọ̀tá. (Mát. 10:32-38) Àmọ́, tó o bá ń bá wọn fèròwérò látinú Ìwé Mímọ́, tó o sì ń hùwà tó dáa, èyí lè mú káwọn tó ń ta kò ẹ́ yí èrò wọn pa dà.—Ìṣe 17:2; 1 Pét. 2:12; 3:1, 2, 7.
18, 19. (a) Kí ni ìrànlọ́wọ́ tí Bánábà ṣe fún Sọ́ọ̀lù yọrí sí? (b) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Bánábà àti Sọ́ọ̀lù?
18 Nígbà tí Sọ́ọ̀lù dé Jerúsálẹ́mù, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ò gbà pé ó ti di ọmọ ẹ̀yìn torí pé ẹ̀rù ń bà wọ́n. Àmọ́, nígbà tí Bánábà jẹ́rìí sí i pé òótọ́ ni Sọ́ọ̀lù sọ, àwọn àpọ́sítélì tẹ́wọ́ gbà á, ó sì wà pẹ̀lú wọn fúngbà díẹ̀. (Ìṣe 9:26-28) Sọ́ọ̀lù máa ń kíyè sára, síbẹ̀ kò tijú ìhìn rere. (Róòmù 1:16) Ó fìgboyà wàásù ní Jerúsálẹ́mù, ìyẹn ìlú tóun fúnra ẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í ta ko àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi. Ẹ̀rù ba àwọn Júù tó wà ní Jerúsálẹ́mù nígbà tí wọ́n rí i pé ọkùnrin tó ń múpò iwájú láti fòpin sí ẹ̀sìn Kristẹni ti yí pa dà, wọ́n sì ń gbìmọ̀ láti pa á. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: Nígbà tí àwọn ará gbọ́ nípa èyí, wọ́n mú [Sọ́ọ̀lù] wá sí Kesaríà, wọ́n sì rán an lọ sí Tásù.” (Ìṣe 9:30) Sọ́ọ̀lù ò kọ ọ̀rọ̀ sí àwọn ará náà lẹ́nu, ó tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ohun tí Jésù fẹ́, ìyẹn sì ṣe òun àti ìjọ láǹfààní.
19 Kíyè sí i pé ńṣe ni Bánábà lo ìdánúṣe láti ran Sọ́ọ̀lù lọ́wọ́. Ó dájú pé èyí túbọ̀ mú kí okùn ọ̀rẹ́ àwọn arákùnrin onítara méjèèjì yìí lágbára sí i. Bíi ti Bánábà, ṣé tinútinú ni ìwọ náà fi máa ń ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dara pọ̀ mọ́ wa lọ́wọ́? Ṣé o máa ń bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, tó o sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí? Wàá rí èrè púpọ̀ níbẹ̀ tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀. Tó o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde ìhìn rere, ṣéwọ náà máa ń ṣiṣẹ́ lórí ìrànlọ́wọ́ tó o bá rí gbà bíi ti Sọ́ọ̀lù? Bó o ṣe ń bá àwọn akéde tó túbọ̀ nírìírí ṣiṣẹ́, ọ̀nà tó ò ń gbà wàásù á máa dáa sí i, ayọ̀ ẹ á máa pọ̀ sí i, wàá tún láwọn ọ̀rẹ́ àtàtà tẹ́ ẹ jọ máa wà pẹ́ títí.
“Ọ̀pọ̀ Èèyàn . . . Di Onígbàgbọ́” (Ìṣe 9:31-43)
20, 21. Báwo làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé àtijọ́ àti lóde òní ṣe lo àwọn “àkókò àlàáfíà”?
20 Lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù ti di Kristẹni, tó sì ti bọ́ lọ́wọ́ ewu, “ìjọ tó wà jákèjádò Jùdíà àti Gálílì àti Samáríà wọnú àkókò àlàáfíà.” (Ìṣe 9:31) Báwo làwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe lo “àkókò tó rọrùn” yìí? (2 Tím. 4:2) Àkọsílẹ̀ náà sọ pé “à ń gbé [wọ́n] ró.” Àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin ń fún ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn lókun, wọ́n sì ń ṣàbójútó ìjọ láti máa “rìn nínú ìbẹ̀rù Jèhófà àti nínú ìtùnú ẹ̀mí mímọ́.” Bí àpẹẹrẹ, Pétérù lo àkókò yìí láti fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà nílùú Lídà ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣárónì lókun. Èyí mú kí ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń gbé lágbègbè náà “yíjú sọ́dọ̀ Olúwa.” (Ìṣe 9:32-35) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ò jẹ́ kí nǹkan míì gbà wọ́n lọ́kàn, ńṣe ni wọ́n ń ran ara wọn lọ́wọ́ tí wọ́n sì ń wàásù ìhìn rere. Ohun tí èyí yọrí sí ni pé ìjọ “ń gbèrú sí i.”
21 Ní nǹkan bí ọdún 1990, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè náà wọnú irú “àkókò àlàáfíà” bẹ́ẹ̀. Lójijì ni òpin dé bá àwọn ìjọba tó ti ń ni àwọn èèyàn Ọlọ́run lára láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, ó sì ti wá rọrùn láti wàásù láwọn orílẹ̀-èdè táwọn ìjọba ti ṣòfin pé ká má wàásù mọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló sì ń lo àǹfààní yìí láti wàásù ní gbangba, tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì wá ń sin Jèhófà.
22. Báwo lo ṣe lè lo òmìnira tó o ní lọ́nà tó dáa?
22 Ṣé ò ń lo òmìnira tó o ní báyìí lọ́nà tó dáa? Tó o bá ń gbé ní orílẹ̀-èdè táwọn èèyàn ti lómìnira láti máa ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n, Sátánì á fẹ́ kó o máa lépa nǹkan tara, kó o sì pa ìjọsìn Jèhófà tì. (Mát. 13:22) Má ṣe jẹ́ kí ohun míì gbà ẹ́ lọ́kàn. Máa lo àkókò àlàáfíà tó o ní báyìí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Máa wò ó bí àkókò tí wàá fi jẹ́rìí kúnnákúnná àti láti gbé ìjọ ró. Má gbàgbé pé, ipò ẹ lè yí pa dà lójijì.
23, 24. (a) Kí la rí kọ́ nínú ìtàn Tàbítà? (b) Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?
23 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ ẹ̀yìn náà Tàbítà tó tún ń jẹ́ Dọ́káàsì. Ó ń gbé ní ìlú Jópà nítòsí ìlú Lídà. Arábìnrin adúróṣinṣin yìí lo àkókò àti owó rẹ̀ lọ́nà tó dáa, ó jẹ́ ẹnì kan tí “iṣẹ́ rere àti ọrẹ àánú” rẹ̀ pọ̀ gan-an. Àmọ́ lójijì ló bẹ̀rẹ̀ àìsàn, ó sì kú.c Ikú rẹ̀ fa ìbànújẹ́ tó pọ̀ gan-an láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà ní Jópà, ní pàtàkì jù fáwọn opó tó ti ṣe lóore. Nígbà tí Pétérù dé sílé tí wọ́n ti ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa sin òkú rẹ̀, ó ṣe iṣẹ́ ìyanu tí kò ṣẹlẹ̀ rí láàárín àwọn àpọ́sítélì Jésù Kristi. Pétérù gbàdúrà, ó sì jí Tàbítà dìde! Fojú inú wo bí ayọ̀ àwọn opó náà àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù á ṣe pọ̀ tó nígbà tí Pétérù pè wọ́n wọlé tó sì fa Tàbítà lé wọn lọ́wọ́ láàyè. Ó dájú pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí á fún wọn lókun láti kojú àwọn ìṣòro tó ń bọ̀! Iṣẹ́ ìyanu yìí “tàn káàkiri Jópà, ọ̀pọ̀ èèyàn sì di onígbàgbọ́ nínú Olúwa”—Ìṣe 9:36-42.
24 Ohun pàtàkì méjì la rí kọ́ látinú ìtàn Tàbítà. (1) Ẹ̀mí àwa èèyàn kúrú. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká ní orúkọ rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà tá a ṣì láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀! (Oníw. 7:1) (2) Ìrètí àjíǹde dájú. Jèhófà kíyè sí gbogbo nǹkan rere tí Tàbítà ti ṣe, ó sì san án lẹ́san. Kò ní gbàgbé àwọn iṣẹ́ àṣekára wa, tá a bá sì kú kí Amágẹ́dọ́nì tó dé, ó máa jí wa dìde. (Héb. 6:10) Torí náà, bóyá à ń fara da “àkókò tí kò rọrùn” ni o tàbí a wà ní “àkókò àlàáfíà,” ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa bá a nìṣó láti máa jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Kristi.—2 Tím. 4:2.
a Wo àpótí náà, “Sọ́ọ̀lù Tó Jẹ́ Farisí.”
b Àwọn àpọ́sítélì ni Ọlọ́run sábà máa ń lò láti fún àwọn èèyàn ní ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́. Àmọ́ nínú ọ̀rọ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí, ó jọ pé Jésù fún Ananáyà láṣẹ láti fún Sọ́ọ̀lù ní ẹ̀mí mímọ́. Lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù di Kristẹni, ó pẹ́ díẹ̀ kó tó láǹfààní láti rí àwọn àpọ́sítélì méjìlá náà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ó jọ pé ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ní gbogbo àkókò yẹn. Torí náà, Jésù rí i dájú pé Sọ́ọ̀lù ní okun tó tó láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù tó gbé lé e lọ́wọ́ nìṣó.
c Wo àpótí náà, “Tàbítà—‘Àwọn Iṣẹ́ Rere àti Ọrẹ Àánú Tó Ń Fúnni Pọ̀ Gidigidi.’”