Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì
22 “Ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin ará àti ẹ̀yin bàbá, ẹ gbọ́ ẹjọ́ tí mo fẹ́ rò fún yín.”+ 2 Tóò, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ó ń bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Hébérù, wọ́n túbọ̀ dákẹ́, ó sì sọ pé: 3 “Júù+ ni mí, ìlú Tásù ní Sìlíṣíà+ ni wọ́n ti bí mi, àmọ́ ìlú yìí ni mo ti gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀* Gàmálíẹ́lì,+ wọ́n fi Òfin àwọn baba ńlá ìgbàanì dá mi lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà àìgbagbẹ̀rẹ́,+ mo sì jẹ́ onítara fún Ọlọ́run bí gbogbo yín ṣe jẹ́ lónìí yìí.+ 4 Mo ṣe inúnibíni sí àwọn tó ń tẹ̀ lé Ọ̀nà yìí tí wọ́n fi kú, bí mo ṣe ń de tọkùnrin tobìnrin tí mo sì ń jù wọ́n sẹ́wọ̀n,+ 5 àlùfáà àgbà àti gbogbo àpéjọ àwọn àgbààgbà náà lè jẹ́rìí sí i. Mó tún gba àwọn lẹ́tà látọwọ́ wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn ará ní Damásíkù, mo sì bọ́ sójú ọ̀nà kí n lè lọ mú àwọn tó wà níbẹ̀ wá sí Jerúsálẹ́mù ní dídè láti fìyà jẹ wọ́n.
6 “Àmọ́ bí mo ṣe ń rin ìrìn àjò lọ, tí mo sì ń sún mọ́ Damásíkù, ní ọ̀sán gangan, ìmọ́lẹ̀ ńlá kan láti ọ̀run kọ mànà lójijì yí mi ká,+ 7 mo bá ṣubú lulẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn kan tó sọ fún mi pé: ‘Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, kí nìdí tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi?’ 8 Mo fèsì pé: ‘Ta ni ọ́, Olúwa?’ Ó wá sọ fún mi pé: ‘Èmi ni Jésù ará Násárẹ́tì, ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí.’ 9 Lákòókò yìí, àwọn tó wà pẹ̀lú mi rí ìmọ́lẹ̀ náà, àmọ́ wọn ò gbọ́ ohùn ẹni tó ń bá mi sọ̀rọ̀. 10 Ni mo bá sọ pé: ‘Kí ni kí n ṣe, Olúwa?’ Olúwa sọ fún mi pé: ‘Dìde, lọ sínú Damásíkù, ibẹ̀ ni wọ́n á ti sọ ohun gbogbo tí a ti yàn fún ọ láti ṣe.’+ 11 Àmọ́ nítorí pé ògo ìmọ́lẹ̀ náà kò jẹ́ kí n rí nǹkan kan, ṣe ni àwọn tó wà pẹ̀lú mi fà mí lọ́wọ́ dé Damásíkù.
12 “Ni ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ananáyà, onífọkànsìn tó ń pa Òfin mọ́, tí gbogbo àwọn Júù tó ń gbé ibẹ̀ ròyìn rẹ̀ dáadáa, 13 bá wá sọ́dọ̀ mi. Ó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, ó sì sọ fún mi pé: ‘Sọ́ọ̀lù, arákùnrin, pa dà ríran!’ Ní àkókò yẹn gan-an, mo gbójú sókè, mo sì rí i.+ 14 Ó sọ pé: ‘Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa ti yàn ọ́ láti wá mọ ìfẹ́ rẹ̀, láti rí olódodo náà+ àti láti gbọ́ ohùn ẹnu rẹ̀, 15 torí o máa jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀ láti sọ ohun tí o ti rí, tí o sì ti gbọ́+ fún gbogbo èèyàn. 16 Ní báyìí, kí lò ń dúró dè? Dìde, kí o ṣèrìbọmi, kí o sì wẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ+ nù nípa kíké pe orúkọ rẹ̀.’+
17 “Àmọ́ nígbà tí mo pa dà sí Jerúsálẹ́mù,+ tí mo sì ń gbàdúrà nínú tẹ́ńpìlì, mo bọ́ sójú ìran, 18 mo sì rí i tí ó sọ fún mi pé: ‘Ṣe kíá, kí o sì tètè jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù, torí pé wọn ò ní gba ẹ̀rí tí o máa jẹ́ nípa mi.’+ 19 Mo wá sọ pé: ‘Olúwa, àwọn fúnra wọn mọ̀ dáadáa pé mo máa ń ju àwọn tó gbà ọ́ gbọ́ sẹ́wọ̀n, mo sì máa ń nà wọ́n lẹ́gba láti sínágọ́gù kan dé òmíràn;+ 20 nígbà tí wọ́n ń ta ẹ̀jẹ̀ Sítéfánù ẹlẹ́rìí rẹ sílẹ̀, mo wà níbẹ̀, mo fọwọ́ sí i, mo sì ń ṣọ́ aṣọ àwọ̀lékè àwọn tí ó pa á.’+ 21 Síbẹ̀, ó sọ fún mi pé: ‘Lọ, nítorí màá rán ọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tó jìnnà réré.’”+
22 Wọ́n ń fetí sí i títí dórí ọ̀rọ̀ yìí. Wọ́n sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n ní: “Ẹ mú irú ọkùnrin yìí kúrò láyé, torí kò yẹ kó wà láàyè!” 23 Nítorí pé wọ́n ń kígbe, wọ́n ń ju aṣọ àwọ̀lékè wọn káàkiri, wọ́n sì ń da iyẹ̀pẹ̀ sókè,+ 24 ọ̀gágun náà pàṣẹ pé kí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù wá sí ibùdó àwọn ọmọ ogun, ó sì ní kí wọ́n nà án láti wádìí lọ́wọ́ rẹ̀, kí ó lè mọ ohun tó fà á gan-an tí wọ́n fi ń pariwo lé Pọ́ọ̀lù lórí lọ́nà yìí. 25 Àmọ́ nígbà tí wọ́n ti na Pọ́ọ̀lù tàntàn láti nà án lẹ́gba, ó sọ fún ọ̀gá ọmọ ogun tó dúró níbẹ̀ pé: “Ṣé ó bófin mu fún yín láti na ará Róòmù* tí wọn ò tíì dá lẹ́bi lẹ́gba?”*+ 26 Tóò, nígbà tí ọ̀gá ọmọ ogun náà gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó lọ bá ọ̀gágun, ó sì ròyìn fún un pé: “Kí lo fẹ́ ṣe yìí? Ará Róòmù mà ni ọkùnrin yìí.” 27 Ni ọ̀gágun náà bá sún mọ́ Pọ́ọ̀lù, ó ní: “Sọ fún mi, Ṣé ará Róòmù ni ọ́?” Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.” 28 Ọ̀gágun náà wá sọ pé: “Owó gọbọi ni mo fi ra ẹ̀tọ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù.” Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Wọ́n bí èmi síbẹ̀ ni.”+
29 Torí náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn tó fẹ́ fi ìdálóró wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ fi í sílẹ̀; ẹ̀rù sì ba ọ̀gágun náà nígbà tí ó mọ̀ pé ará Róòmù ni, torí pé ó ti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè é.+
30 Ní ọjọ́ kejì, ó tú u sílẹ̀ nítorí ó fẹ́ rí àrídájú ohun tó fà á tí àwọn Júù fi ń fẹ̀sùn kàn án, ó pàṣẹ pé kí àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo Sàhẹ́ndìrìn pé jọ. Lẹ́yìn náà, ó mú Pọ́ọ̀lù sọ̀ kalẹ̀, ó sì mú un dúró láàárín wọn.+