Kí La Lè Rí Kọ́ Látinú Àpẹẹrẹ Jòánà?
Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló mọ̀ pé méjìlá ni àwọn àpọ́sítélì Jésù. Àmọ́, wọ́n lè má mọ̀ pé àwọn obìnrin wà lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó sún mọ́ ọn jù lọ. Jòánà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn obìnrin náà.—Mát. 27:55; Lúùkù 8:3.
Ipa wo ni Jòánà kó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, kí la sì lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ rẹ̀?
TA NI JÒÁNÀ?
Jòánà jẹ́ “aya Kúsà, ọkùnrin tí Hẹ́rọ́dù fi ṣe alámòójútó.” Ó ṣeé ṣe kí Kúsà jẹ́ ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ilé Hẹ́rọ́dù Áńtípà. Jòánà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn obìnrin mélòó kan tí Jésù wò sàn. Jòánà àti àwọn obìnrin mìíràn máa ń bá Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ rìnrìn-àjò.—Lúùkù 8:1-3.
Àwọn rábì Júù máa ń kọ́ àwọn èèyàn pé àwọn obìnrin ò gbọ́dọ̀ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí kì í ṣe ẹbí wọn ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé kí wọ́n bá wọn rìnrìn-àjò. Kódà, àwọn ọkùnrin Júù ò gbọ́dọ̀ bá àwọn obìnrin sọ̀rọ̀ púpọ̀. Láìka gbogbo òfin àtọwọ́dọ́wọ́ yìí sí, Jésù gbà kí Jòánà àti àwọn obìnrin onígbàgbọ́ míì máa bá òun àti àwọn ọmọlẹ́yìn òun rìnrìn-àjò.
Jòánà ò ka ohun tó máa ná òun sí lọ́dọ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn, àwọn ẹbí tàbí àwọn ọ̀rẹ́, ńṣe ló ń ṣe ìránṣẹ́ fún Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Gbogbo àwọn tó bá ń tẹ̀ lé Jésù gbọ́dọ̀ múra tán láti ṣe àwọn ìyípadà nínú ìgbésí ayé wọn. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa irú àwọn ọmọlẹ́yìn yẹn, ó ní: “Ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni àwọn wọ̀nyí tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń ṣe é.”(Lúùkù 8:19-21; 18:28-30) Ǹjẹ́ kò fún ẹ ní ìṣírí láti mọ̀ pé Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń fi nǹkan du ara wọn torí kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ òun?
Ó FI ÀWỌN NǸKAN ÌNÍ RẸ̀ ṢÈRÁNṢẸ́
Jòánà àti ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin mìíràn fi “àwọn nǹkan ìní wọn” ṣe ìránṣẹ́ fún Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ Méjìlá. (Lúùkù 8:3) Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Kì í ṣe pé Lúùkù ń sọ fún wa pé àwọn obìnrin náà ni wọ́n ń se oúnjẹ fún wọn, fọ abọ́ tàbí rán aṣọ wọn tó bá ya, wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. . . , àmọ́ ohun tí Lúùkù ń sọ kọ́ nìyẹn.” Ó ṣeé ṣe kí àwọn obìnrin náà lo owó àti àwọn ohun ìní wọn láti ṣèránṣẹ́ fún àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn.
Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ò ṣe iṣẹ́ kankan tí wọ́n lè máa fi gbọ́ bùkátà ara wọn tí wọ́n bá ń rìnrìn-àjò káàkiri láti lọ wàásù. Torí náà, wọ́n lè máà ní owó tó tó láti ra oúnjẹ àti àwọn nǹkan míì tí gbogbo àwọn èèyàn tó tó ogún náà máa nílò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn máa ń gbà wọ́n lálejò, Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ṣì máa ń gbé “àpótí owó” dání, èyí tó túmọ̀ sí pé wọn ò retí pé kí àwọn èèyàn máa tọ́jú àwọn nígbà gbogbo. (Jòh. 12:6; 13:28, 29) Ó ṣeé ṣe kí Jòánà àti àwọn obìnrin mìíràn máa mú ọrẹ wá kí wọ́n lè máa fi gbọ́ bùkátà wọn.
Àwọn kan sọ pé obìnrin kan tó jẹ́ Júù ò lè ní dúkìá. Àkọsílẹ̀ kan tó sọ nípa àwọn Júù fi hàn pé onírúurú ọ̀nà ni obìnrin kan tó jẹ́ Júù lè gbà ní dúkìá. Bí àpẹẹrẹ, (1) ohun tó jogún láti ọ̀dọ̀ bàbá rẹ̀ tí bàbá rẹ̀ kò bá ní ọmọkùnrin kankan, (2) ohun ìní tí wọ́n fún un, (3) owó tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún un bí ọkọ rẹ̀ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, (4) owó àti ohun ìní tí ọkọ rẹ̀ fi sílẹ̀ fún un nígbà tó kú tàbí (5) owó tó rí nínú iṣẹ́ tó ṣe.
Láìsí àní-àní àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù. Ó ṣeé ṣe kí àwọn tó rí towó ṣe wà láàárín àwọn obìnrin tó ń tọ Jésù lẹ́yìn. Torí pé Jòánà jẹ́ aya Kúsà tí í ṣe ìránṣẹ́ Hẹ́rọ́dù, àwọn kan sọ pé ó rí já jẹ. Irú èèyàn bíi tiẹ̀ ló lè fún Jésù ní aṣọ tí kò ní ojú rírán tó wọ̀. Òǹkọ̀wé kan sọ pé “irú aṣọ yìí ò lè wá látọ̀dọ̀ ìyàwó àwọn apẹja.”—Jòh. 19:23, 24.
Ìwé Mímọ́ ò sọ ní pàtó pé Jòánà fi owó ṣètọrẹ. Àmọ́, ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe, a sì lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú àpẹẹrẹ rẹ̀. Àwa náà lè pinnu ohun tí a máa fi ti iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run lẹ́yìn, àmọ́ yálà a máa ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀, ọwọ́ wa ló kù sí. Ohun tí Ọlọ́run kà sí pàtàkì ni pé ká máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe tayọ̀tayọ̀.—Mát. 6:33; Máàkù 14:8; 2 Kọ́r. 9:7.
NÍGBÀ TÍ JÉSÙ KÚ ÀTI LẸ́YÌN NÁÀ
Jòánà ti ní láti wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n pa Jésù, bákan náà sì ni àwọn obìnrin míì “tí wọ́n máa ń bá a rìn, tí wọ́n sì máa ń ṣèránṣẹ́ fún un nígbà tó wà ní Gálílì, àti ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin mìíràn tí wọ́n jọ gòkè wá sí Jerúsálẹ́mù.” (Máàkù 15:41) Nígbà tí wọ́n gbé òkú Jésù kúrò lórí òpó igi kí wọ́n lè sin ín, “àwọn obìnrin, tí wọ́n ti bá a wá láti Gálílì, tẹ̀ lé [wọn] lọ, wọ́n sì bojú wo ibojì ìrántí náà àti bí a ti tẹ́ òkú rẹ̀; wọ́n sì padà láti lọ pèsè èròjà atasánsán àti àwọn òróró onílọ́fínńdà sílẹ̀.” Lúùkù sọ pé ‘Màríà Magidalénì, Jòánà àti Màríà ìyá Jákọ́bù,’ ni àwọn obìnrin náà. Wọ́n pa dà wá sí ibi ibojì lẹ́yìn sábáàtì, wọ́n sì rí áńgẹ́lì kan níbẹ̀ tó sọ fún wọn pé Jésù ti jíǹde.—Lúùkù 23:55–24:10.
Màríà ìyá Jésù àti àwọn arákùnrin rẹ̀ wà lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà ní Jerúsálẹ́mù ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ó sì ṣeé ṣe kí Jòánà wà lára wọn. (Ìṣe 1:12-14) Torí pé ọkọ Jòánà ń ṣiṣẹ́ fún Hẹ́rọ́dù, ó ṣeé ṣe kí Lúùkù ti máa rí àwọn ìsọfúnni nípa Hẹ́rọ́dù Áńtípà gbà láti ọ̀dọ̀ Jòánà, bí àwọn kan ṣe ń sọ, ó ṣe tán, Lúùkù nìkan ni òǹkọ̀wé Ìhìn Rere tó dárúkọ Jòánà ní tààràtà.—Lúùkù 8:3; 9:7-9; 23:8-12; 24:10.
Ìtàn Jòánà kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ tó ń múni ronú jinlẹ̀. Ó ṣe ìránṣẹ́ fún Jésù dé ibi tó lè ṣe é dé. Ó dájú pé inú rẹ̀ máa dùn tó bá mọ̀ pé àwọn ohun tí òun fi ṣètìlẹyìn ti ran Jésù, àwọn Méjìlá náà àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù lọ́wọ́ láti fi rìnrìn-àjò kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Jòánà ṣe ìránṣẹ́ fún Jésù ó sì dúró tì í jálẹ̀ gbogbo àdánwò rẹ̀. Ó yẹ kí àwọn Kristẹni tó jẹ́ obìnrin náà máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀mí tó dáa tí Jòánà fi hàn.