Ṣọ́ Àwọn Tó Ò Ń Bá Kẹ́gbẹ́ ní Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Yìí
“Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.”—1 KỌ́R. 15:33.
1. Àkókò wo là ń gbé báyìí?
ÀWỌN àkókò tó nira là ń gbé báyìí. Bíbélì pe àwọn àkókò tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1914 yìí ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” Látìgbà tí “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” náà sì ti bẹ̀rẹ̀ ni àwọn nǹkan búburú tá ò tíì rí irú rẹ̀ rí ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀. (2 Tím. 3:1-5) Síbẹ̀, ṣe ni ayé yìí á máa burú sí i, torí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé “àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.”—2 Tím. 3:13.
2. Irú àwọn eré ìnàjú wo ló wà nínú ayé? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
2 Bíbélì sọ pé ìwà ipá, ìṣekúṣe, ìbẹ́mìílò àti àwọn ìwà míì tí kò múnú Ọlọ́run dùn kò dára. Ṣùgbọ́n eré tó ń gbé àwọn nǹkan yìí lárugẹ ni ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń najú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìkannì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ètò orí tẹlifíṣọ̀n, àwọn fíìmù, ìwé ìtàn àti àwọn ìwé ìròyìn máa ń mú kí àwọn èèyàn rí ìwà ipá àti ìṣekúṣe bí ohun tí kò burú. Wọ́n ti sọ àwọn ìwà táwọn èèyàn kórìíra tẹ́lẹ̀ di ohun tó bófin mu láwọn orílẹ̀-èdè kan. Síbẹ̀, ìyẹn ò ní kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀.—Ka Róòmù 1:28-32.
3. Ojú wo làwọn èèyàn fi ń wo àwọn tó ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì?
3 Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù kọ̀ láti lọ́wọ́ sí àwọn eré ìnàjú tí kò dára. Nítorí èyí àti ìwà tó ń múnú Ọlọ́run dùn tí wọ́n ń hù, àwọn èèyàn ṣáátá wọn, wọ́n sì ṣe inúnibíni sí wọn. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Nítorí ẹ [àwọn Kristẹni] kò bá a lọ ní sísáré pẹ̀lú wọn ní ipa ọ̀nà yìí sínú kòtò ẹ̀gbin jíjìnwọlẹ̀ kan náà tí ó kún fún ìwà wọ̀bìà, ó rú wọn lójú, wọ́n sì ń bá a lọ ní sísọ̀rọ̀ yín tèébútèébú.” (1 Pet. 4:4) Bákan náà lónìí, ojú ẹni tó dá yàtọ̀ làwọn èèyàn fi ń wo àwọn tó ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run. Láfikún síyẹn, Bíbélì sọ pé: “Gbogbo àwọn tí ń ní ìfẹ́-ọkàn láti gbé pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú Kristi Jésù ni a ó ṣe inúnibíni sí pẹ̀lú.”—2 Tím. 3:12.
“ẸGBẸ́ BÚBURÚ A MÁA BA ÌWÀ RERE JẸ́”
4. Kí ni Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé a kò gbọ́dọ̀ ṣe?
4 Bíbélì kìlọ̀ fún àwọn tó bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run pé kí wọ́n má ṣe nífẹ̀ẹ́ ayé àti àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ inú rẹ̀. (Ka 1 Jòhánù 2:15, 16.) Abẹ́ ìdarí Sátánì Èṣù, “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan” yìí ni gbogbo ètò ẹ̀sìn èké, ètò òṣèlú, ètò ìṣòwò ayé yìí àti àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n tó ń gbé wọn sáfẹ́fẹ́ wà. (2 Kọ́r. 4:4; 1 Jòh. 5:19) Torí náà, àwa Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ ṣọ́ àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí sọ òtítọ́ tí kò ṣe é já ní koro náà pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.”—1 Kọ́r. 15:33.
5, 6. Àwọn wo ni kò yẹ ká bá kẹ́gbẹ́, kí sì nìdí?
5 Kí ìwà rere wa má bàa bà jẹ́, a kò gbọ́dọ̀ máa bá àwọn tó ń hùwà búburú kẹ́gbẹ́. Kì í ṣe àwọn oníwà àìtọ́ tí kì í ṣe Kristẹni nìkan ni kò yẹ ká máa bá kẹ́gbẹ́ o, kò tún yẹ ká máa kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó pera wọn ní ìránṣẹ́ Jèhófà ṣùgbọ́n tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ń ṣàìgbọràn sí àwọn òfin rẹ̀. Bí irú àwọn tó pera wọn ní Kristẹni bẹ́ẹ̀ bá lọ́wọ́ sí ìwà àìtọ́ tó burú jáì tí wọn kò sì ronú pìwà dà, a gbọ́dọ̀ dẹ́kun bíbá wọn kẹ́gbẹ́.—Róòmù 16:17, 18.
6 Tá a bá ń bá àwọn tí kì í ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run kẹ́gbẹ́, àá fẹ́ máa ṣe bíi tiwọn, kí wọ́n lè gba tiwa. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn oníṣekúṣe, ó lè máa wu àwa náà pé ká ṣèṣekúṣe. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn Kristẹni kan tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ nìyẹn, wọ́n sì yọ àwọn kan lára wọn lẹ́gbẹ́ torí pé wọn kò ronú pìwà dà. (1 Kọ́r. 5:11-13) Bí wọn kò bá ronú pìwà dà, ọ̀rọ̀ wọn lè dà bíi ti àwọn tí Pétérù mẹ́nu kàn nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Ka 2 Pétérù 2:20-22.
7. Àwọn wo ló yẹ ká yàn lọ́rẹ̀ẹ́?
7 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ ká máa hùwà tó dáa sí gbogbo èèyàn, a kò gbọ́dọ̀ máa bá àwọn tí kì í pa òfin Ọlọ́run mọ́ kẹ́gbẹ́ tàbí ká jẹ́ ọ̀rẹ́ wọn tímọ́tímọ́. Torí náà, kò tọ́ kí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa fẹ́ ẹni tí kò ya ara rẹ̀ sí mímọ́, tí kì í ṣèfẹ́ Ọlọ́run, tí kì í sì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká pa ìwà títọ́ Kristẹni wa mọ́ ju ká gbayì lọ́dọ̀ àwọn tí kì í pa òfin Jèhófà mọ́. Àwọn tó ń ṣèfẹ́ Ọlọ́run ló yẹ ká yàn lọ́rẹ̀ẹ́. Jésù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ẹni yìí ni arákùnrin àti arábìnrin àti ìyá mi.”—Máàkù 3:35.
8. Ipa wo ni ẹgbẹ́ búburú ní lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́?
8 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jìyà àbájáde búburú torí pé wọ́n kó ẹgbẹ́ búburú. Nígbà tí Jèhófà dá wọn nídè kúrò lóko ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì tó sì ń darí wọn lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí, ó sọ irú àjọṣe tó yẹ kí wọ́n ní pẹ̀lú àwọn tó ń gbé níbẹ̀. Ó ní: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún àwọn ọlọ́run wọn, tàbí kí a sún ọ láti sìn wọ́n, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe ohunkóhun tí ó dà bí iṣẹ́ wọn, bí kò ṣe kí o wó wọn palẹ̀ láìkùnà, kí o sì wó àwọn ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ wọn lulẹ̀ láìkùnà. Kí ẹ sì sin Jèhófà Ọlọ́run yín.” (Ẹ́kís. 23:24, 25) Ṣíbẹ̀ náà, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ṣègbọràn sí àwọn ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún wọn. (Sm. 106:35-39) Torí pé wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run, Jésù sọ fún wọn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé: “Wò ó! A pa ilé yín tì fún yín.” (Mát. 23:38) Jèhófà fawọ́ ìbùkún rẹ̀ sẹ́yìn lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì fi sórí ìjọ Kristẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀.—Ìṣe 2:1-4.
MÁA ṢỌ́ OHUN TÓ Ò Ń KÀ ÀTI OHUN TÓ Ò Ń WÒ
9. Kí nìdí tí ohun táwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ń gbé jáde fi léwu?
9 Ọ̀pọ̀ ohun táwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ayé yìí ń gbé jáde lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Àwọn ohun tí wọ́n ń gbé jáde náà kì í mú kéèyàn ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àti àwọn ìlérí rẹ̀. Ńṣe ni wọ́n ń gbé ayé búburú Sátánì àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ lárugẹ. Torí náà, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra gidigidi kó má lọ jẹ́ pé àwọn ohun táá mú kí “àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ayé” ru sókè lọ́kàn wa la máa yàn.—Títù 2:12.
10. Kí ló máa gbẹ̀yìn àwọn ìwé àti àwọn fíìmù burúkú tí ayé yìí ń gbé jáde?
10 Láìpẹ́, àwọn ìwé àti àwọn fíìmù burúkú tí ayé ń gbé jáde ò ní sí mọ́. Gbogbo ẹ̀ á di àwátì nígbà tí Jèhófà bá pa ayé Sátánì tí wọ́n ń gbé lárugẹ run. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòh. 2:17) Bákan náà, onísáàmù sọ pé: “Àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò, ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà ni yóò ni ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” Fún ọdún mélòó? Ó ní: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sm. 37:9, 11, 29.
11. Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ fún àwọn èèyàn rẹ̀?
11 Ohun tí ètò Jèhófà ń pèsè fún wa yàtọ̀ sí àwọn nǹkan tí ayé yìí ń gbé jáde. Ohun tó máa jẹ́ ká jogún ìyè ayérayé ni ètò Ọlọ́run ń kọ́ wa ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà sí Jèhófà, ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòh. 17:3) Baba wa ọ̀run ń tipasẹ̀ ètò rẹ̀ pèsè ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí tí ń gbéni ró fún wa. Àfi ká máa dúpẹ́ pé a ní àwọn ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ, ìwé ńlá, àwọn fídíò àti ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó ń gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ! Ètò Ọlọ́run tún ṣètò àwọn ìpàdé tá à ń ṣe déédéé ní àwọn ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́fà [110,000] kárí ayé. Ní àwọn ìpàdé, àpéjọ àyíká àti àpéjọ àgbègbè, a máa ń jíròrò àwọn ìsọfúnni látinú Bíbélì, èyí tó ń gbé ìgbàgbọ́ ró nínú Ọlọ́run àti àwọn ìlérí rẹ̀.—Héb. 10:24, 25.
ṢÈGBÉYÀWÓ “KÌKÌ NÍNÚ OLÚWA”
12. Ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí láti ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.”
12 Ó túbọ̀ ṣe pàtàkì pé kí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni tó sì fẹ́ ṣègbéyàwó ṣọ́ àwọn tó ń bá kẹ́gbẹ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa ní ìkìlọ̀ tó ṣe kedere pé: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́. Nítorí àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà àìlófin ní? Tàbí àjọpín wo ni ìmọ́lẹ̀ ní pẹ̀lú òkùnkùn?” (2 Kọ́r. 6:14) Bíbélì gba àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó bá fẹ́ ṣègbéyàwó nímọ̀ràn pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ “kìkì nínú Olúwa,” ìyẹn ni pé olùjọ́sìn Jèhófà tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, tó ti ṣèrìbọmi, tó sì ń fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò nìkan ni wọ́n gbọ́dọ̀ fẹ́. (1 Kọ́r. 7:39) Bí àwọn Kristẹni tòótọ́ bá ń fẹ́ ará bíi tiwọn, wọ́n á máa ní àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, èyí á sì jẹ́ kí wọ́n lè pa ìwà títọ́ wọn mọ́.
13. Àṣẹ wo ni Ọlọ́run pa fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ìgbéyàwó?
13 Jèhófà mọ ohun tó máa ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láǹfààní jù lọ, kò sì yé tipasẹ̀ ètò rẹ̀ sọ ojú tó fi ń wo ìgbéyàwó fún wa. Kíyè sí àṣẹ kedere tó pa fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nígbà tí Jèhófà ń gbẹnu Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa àwọn orílẹ̀-èdè tí kò sin Ọlọ́run tó yí wọn ká, ó sọ pé: “Ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ bá wọn dána. Ọmọbìnrin rẹ ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi fún ọmọkùnrin rẹ̀, ọmọbìnrin rẹ̀ sì ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ mú fún ọmọkùnrin rẹ. Nítorí òun yóò yí ọmọ rẹ padà láti má ṣe tọ̀ mí lẹ́yìn, dájúdájú, wọn yóò sì máa sin àwọn ọlọ́run mìíràn; ní tòótọ́, ìbínú Jèhófà yóò sì ru sí yín, dájúdájú, òun yóò sì pa ọ́ rẹ́ ráúráú ní wéréwéré.”—Diu. 7:3, 4.
14, 15. Nígbà tí Sólómọ́nì ò tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà mọ́, kí ló ṣẹlẹ̀ sí i?
14 Ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn tí Sólómọ́nì, ọmọ Dáfídì di ọba, ó gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún òun ní ọgbọ́n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì kéré lọ́jọ́ orí, Ọlọ́run fún un ni ọgbọ́n lọ́pọ̀ yanturu. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn wá mọ Sólómọ́nì sí ọlọgbọ́n ọba tó ń ṣàkóso ilẹ̀ tó láásìkí. Kódà, nígbà tí ọbabìnrin Ṣébà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Sólómọ́nì, ohun tó rí yà á lẹ́nu. Ó ní: “Èmi kò sì ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ náà títí mo fi wá kí ojú èmi fúnra mi lè rí i; sì wò ó! a kò sọ ìdajì wọn fún mi. Ìwọ ta yọ ní ọgbọ́n àti aásìkí ré kọjá àwọn ohun tí a gbọ́ èyí tí mo fetí sí.” (1 Ọba 10:7) Àmọ́, àpẹẹrẹ tí kò dára ni Sólómọ́nì fi lélẹ̀. Ìyẹn sì jẹ́ ká rí ohun tó lè ṣẹlẹ̀ bí ẹnì kan bá ṣàìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run tó ní ká má ṣe fẹ́ aláìgbàgbọ́.—Oníw. 4:13.
15 Láìka gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run ti ṣe fún Sólómọ́nì sí, ó ṣàìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run pé kí wọ́n má ṣe fẹ́ àwọn tí kì í ṣe olùjọ́sìn Jèhófà látinú àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. Sólómọ́nì “nífẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ aya ilẹ̀ òkèèrè” débi tó fi wá ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] aya àti ọ̀ọ́dúnrún [300] àlè. Ibo lọ̀rọ̀ rẹ̀ wá já sí? Nígbà tí Sólómọ́nì darúgbó, àwọn aya abọ̀rìṣà tó fẹ́ “tẹ ọkàn-àyà rẹ̀ láti tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn, . . . Sólómọ́nì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà.” (1 Ọba 11:1-6) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sólómọ́nì gbọ́n, ẹgbẹ́ búburú mú kó hùwà òmùgọ̀, ó sì fi ìjọsìn tòótọ́ sílẹ̀. Ìkìlọ̀ lèyí jẹ́ fún àwọn Kristẹni tí wọ́n lè máa ronú láti fẹ́ ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.
16. Ìlànà Ìwé Mímọ́ wo ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó fẹ́ aláìgbàgbọ́ lè fi sílò?
16 Bó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan ti fẹ́ aláìgbàgbọ́ kó tó di olùjọ́sìn Ọlọ́run ńkọ́? Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ tiyín, kí ó lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn.” (1 Pét. 3:1) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aya tó jẹ́ Kristẹni la darí ọ̀rọ̀ yìí sí, ọ̀rọ̀ náà kan ọkọ kan tó ti fẹ́ aláìgbàgbọ́ kó tó di olùjọ́sìn Jèhófà. Ìkìlọ̀ Bíbélì yìí ṣe kedere, ìyẹn sì ni pé kó o jẹ́ ọkọ tàbí aya rere, kó o sì máa tẹ̀ lé ìlànà tí Ọlọ́run fún àwọn tó ti ṣègbéyàwó. Ọ̀pọ̀ ọkọ tàbí aya aláìgbàgbọ́ ló ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé wọ́n kíyè sí ìyípadà tó wáyé nígbà tí ẹnì kejì wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ìlànà Ọlọ́run sílò.
ÀWỌN TÓ NÍFẸ̀Ẹ́ JÈHÓFÀ NI KÓ O MÁA BÁ ṢỌ̀RẸ́
17, 18. Kí ló mú kí Nóà àti àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní la òpin ètò àwọn nǹkan já nígbà ayé wọn?
17 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ búburú máa ń ba ìwà rere jẹ́, ẹgbẹ́ rere máa ń nípa tó dáa lórí ẹni. Ronú nípa Nóà tó gbé nínú ayé búburú, tí kò sì ronú pé òun máa bá àwọn tó ń hùwà tí kò dáa ṣọ̀rẹ́. Nígbà yẹn, “Jèhófà rí i pé ìwà búburú ènìyàn pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ ayé, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ́ kìkì búburú ní gbogbo ìgbà.” (Jẹ́n. 6:5) Torí náà, Ọlọ́run pinnu pé òun máa pa ayé búburú ìgbà yẹn àtàwọn olubi inú rẹ̀ run nínú àkúnya omi tó kárí ayé. Àmọ́, “Nóà jẹ́ olódodo. Ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìní-àléébù láàárín àwọn alájọgbáyé rẹ̀. Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.”—Jẹ́n. 6:7-9.
18 Ó dájú pé Nóà ò wá bó ṣe máa bá àwọn èèyàn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run dọ́rẹ̀ẹ́. Òun, aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àtàwọn aya wọn mú kí ọwọ́ wọ́n dí lẹ́nu iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́, tó fi mọ́ kíkan ọkọ̀ áàkì. Bí ìyẹn ṣe ń lọ lọ́wọ́, Nóà tún ń wàásù. Bíbélì pè é ní “oníwàásù òdodo.” (2 Pét. 2:5) Iṣẹ́ ìwàásù tí Nóà ṣe, ọkọ̀ áàkì tó kàn àti àjọṣe tó wà láàárín òun àti ìdílé rẹ̀ mú kí ọwọ́ rẹ̀ dí, kó sì máa ṣe àwọn nǹkan tó múnú Ọlọ́run dùn. Látàrí èyí, Nóà àti ìdílé rẹ̀ la Ìkún-omi náà já. Àfi ká máa dúpẹ́ pé Nóà àti ìdílé rẹ̀ sin Jèhófà, torí pé àtọmọdọ́mọ wọn ni gbogbo àwa tá à ń gbé lórí ilẹ̀ ayé lónìí. Bákan náà, àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin àti onígbọràn kò bá àwọn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run kẹ́gbẹ́ wọ́n sì la ìparun Jerúsálẹ́mù àti ti ètò àwọn nǹkan àwọn Júù já ní ọdún 70 Sànmánì Kristẹni.—Lúùkù 21:20-22.
19. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè rí ojúure Ọlọ́run?
19 Torí pé a jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Nóà àti ìdílé rẹ̀ àti àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tí wọ́n jẹ́ onígbọràn. A gbọ́dọ̀ ya ara wa sọ́tọ̀ kúrò nínú ètò àwọn nǹkan búburú yìí, ká sì máa yan àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tó ń gbéni ró lọ́rẹ̀ẹ́ láàárín àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa olóòótọ́ tí wọ́n ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ báyìí. Tá a bá fara mọ́ àwọn tí ọgbọ́n Ọlọ́run ń darí, èyí á mú ká “dúró gbọn-in gbọn-in nínú ìgbàgbọ́” ní àwọn àkókò líle koko yìí. (1 Kọ́r. 16:13; Òwe 13:20) Tá a bá ń ṣọ́ àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, a lè ní àǹfààní láti la ètò àwọn nǹkan búburú yìí já sínú ayé tuntun òdodo tí Jèhófà ṣèlérí, tó sì ti sún mọ́lé báyìí. Ẹ ò rí i pé ohun àgbàyanu nìyẹn jẹ́ láti máa fojú sọ́nà fún!