Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
NOVEMBER 5-11
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÒHÁNÙ 20-21
“Ìwọ Ha Nífẹ̀ẹ́ Mi Ju Ìwọ̀nyí Lọ Bí?”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 21:15, 17
Jésù wí fún Símónì Pétérù pé: Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Pétérù sẹ́ Jésù lẹ́ẹ̀mẹ́ta ni ìjíròrò yìí wáyé láàárín àwọn méjèèjì. Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jésù béèrè lọ́wọ́ Pétérù bóyá ó nífẹ̀ẹ́ òun, ìyẹn sì kó “ẹ̀dùn-ọkàn bá Pétérù.” (Jo 21:17) Jòhánù lo oríṣi ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì méjì nígbà tó ń kọ ìtàn yìí sílẹ̀ nínú Jo 21:15-17, àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe tó lò ni: a·ga·paʹo, tó túmọ̀ sí ìfẹ́ àti phi·leʹo, ìyẹn ní ìfẹ́ni. Ẹ̀ẹ̀méjì ni Jésù bi Pétérù pé: “Ìwọ ha nífẹ̀ẹ́ mi?” Pétérù sì fi dá Jésù lójú pé òun ní “ìfẹ́ni” fún un. Níkẹyìn, Jésù béèrè pé: “Ìwọ ha ní ìfẹ́ni fún mi bí?” Lẹ́ẹ̀kan sí i, Pétérù fi dá Jésù lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Gbogbo ìgbà tí Pétérù ń sọ fún Jésù pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣe ni Jésù fẹ́ tẹnu mọ́ ọ fún Pétérù pé ìfẹ́ àti ìfẹ́ni ló yẹ kó sún un láti bọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Òun, kó sì ṣe “olùṣọ́ àgùntàn” wọn nípa tẹ̀mí, ìyẹn àwọn tí Jésù pè ní àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn tàbí “àwọn àgùntàn mi kéékèèké.” (Jo 21:16, 17; 1Pe 5:1-3) Ẹ̀ẹ̀mẹta ni Jésù jẹ́ kí Pétérù fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó fẹ́ràn òun, ẹ̀yìn ìyẹn ló wá sọ fún un pé kó máa bójú tó àwọn àgùntàn òun. Jésù tipa báyìí fi hàn pé òun ti dárí ji Pétérù fún bó ṣe sẹ́ òun lẹ́ẹ̀mẹta.
ìwọ ha nífẹ̀ẹ́ mi ju ìwọ̀nyí lọ bí?: Tá a bá ní ká tú u yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́, gbólóhùn náà “ju ìwọ̀nyí lọ” lè ní ìtumọ̀ tó pọ̀ díẹ̀. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan gbà pé òun tó túmọ̀ sí ni pé “ìwọ ha nífẹ̀ẹ́ mi ju bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn yòókù?” tàbí “ìwọ ha nífẹ̀ẹ́ mi ju bí àwọn ọmọlẹ́yìn yòókù ṣe nífẹ̀ẹ́ mi?” Bó ti wù kó rí, ó ní láti jẹ́ pé ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ni “ìwọ ha nífẹ̀ẹ́ mi ju àwọn nǹkan yìí?” ìyẹn àwọn ẹja tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa àti àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ iṣẹ́ apẹja. Torí náà, ohun tí Jésù ń béèrè nínú ẹsẹ yẹn ni pé: ‘Ìwọ ha nífẹ̀ẹ́ mi ju àwọn nǹkan tara lọ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, máa bọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké.’ Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yẹn máa yé Pétérù dáadáa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pétérù wà lára àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọlẹ́yìn Jésù (Jo 1:35-42), kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé Jésù pátápátá. Ṣe ló pa dà sídìí iṣẹ́ apẹja. Láwọn oṣù díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn, Jésù ní kí Pétérù fi iṣẹ́ apẹja tó ń ṣe lójú méjèèjì sílẹ̀, kó sì wá di “apẹja ènìyàn.” (Mt 4:18-20; Lk 5:1-11) Kò pẹ́ rárá lẹ́yìn tí Jésù kú, Pétérù sọ pé òun fẹ́ máa lọ pẹja, àwọn àpọ́sítélì yòókù sì dara pọ̀ mọ́ ọn. (Jo 21:2, 3) Torí náà, ó jọ pé Jésù fẹ́ kí Pétérù mọ̀ pé ṣe ló yẹ kó yan ohun tó fẹ́ fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe: Ṣé iṣẹ́ ẹja pípa ló máa fi sípò àkọ́kọ́, ìyẹn àwọn ẹja tó wà níwájú wọn tàbí ohun tí Pétérù máa jẹ́ kó gbawájú ni bó ṣe máa bọ́ àwọn àgùntàn, ìyẹn àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù?—Jo 21:4-8.
ní ìgbà kẹta: Pétérù ti sẹ́ Olúwa rẹ̀ nígbà mẹ́ta; Jésù wá fún un láyè láti fi dá òun lójú lẹ́ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pé lóòótọ́ ló ní ìfẹ́ni fún òun. Lẹ́yìn tí Pétérù ṣe bẹ́ẹ̀, Jésù sọ fún un pé ìgbà tó bá fi iṣẹ́ ìsìn mímọ́ sípò àkọ́kọ́ ló máa tó fi hàn pé ó ní ìfẹ́ àti ìfẹ́ni fún òun. Pétérù àti àwọn arákùnrin yòókù á máa bọ́ àwọn tó ń fi tinútinú tẹ̀ lé Jésù, wọ́n á máa fún wọn lókun, wọ́n á sì máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni àmì òróró ni àwọn tí Jésù fi sí ìkáwọ́ Pétérù, síbẹ̀ wọ́n ṣì nílò oúnjẹ tẹ̀mí.—Lk 22:32.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 20:17
Dẹ́kun dídìrọ̀ mọ́ mi: Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà haʹpto·mai lè túmọ̀ sí “láti fọwọ́ kàn” tàbí “láti dìrọ̀ mọ́; láti dì mọ́.” Àwọn kan túmọ̀ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí sí: “Má fọwọ́ kàn mí.” Jésù ò sọ pé kí Màríà Magidalénì má fọwọ́ kan òun, torí pé kò sọ bẹ́ẹ̀ fún àwọn obìnrin tó rí i lẹ́yìn tó jíǹde, Bíbélì sọ pé wọ́n “di ẹsẹ̀ rẹ̀ mú.” (Mt 28:9) Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé Màríà Magidalénì ń ṣàníyàn pé Jésù ti fẹ́ pa dà sí ọ̀run. Ìdí nìyẹn tó fi dìrọ̀ mọ́ Jésù, torí kò fẹ́ kó fi òun sílẹ̀, gbogbo ìgbà ló fẹ́ máa wà pẹ̀lú rẹ̀. Jésù fẹ́ jẹ́ kó mọ̀ pé òun ò tíì lọ, ìdí nìyẹn tó fi sọ fún Màríà pé kó yéé dìrọ̀ mọ́ òun, ó ní kí Màríà lọ sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn tó kù pé òun ti jíǹde.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 20:28
Olúwa mi àti Ọlọ́run mi!: Lédè Gíríìkì, “Olúwa tèmi àti Ọlọ́run [ho the·osʹ] tèmi!” Àwọn ọ̀mọ̀wé kan gbà pé ọ̀rọ̀ ìyanu lọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ fún Jésù yìí, àmọ́ Ọlọ́run gan-an ni wọ́n ń darí rẹ̀ sí, ìyẹn Bàbá Jésù. Àwọn míì sọ pé Jésù gan-an ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò yẹn ń tọ́ka sí. Tó bá tìẹ jẹ́ pé ohun tó jọ nìyẹn, a máa túbọ̀ lóye ọ̀rọ̀ náà “Olúwa mi àti Ọlọ́run mi” lọ́nà tó kún rẹ́rẹ́ tá a bá wo àyíká ọ̀rọ̀ yẹn nínú Ìwé Mímọ́. Àkọ́sílẹ̀ yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù ti kọ́kọ́ sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé, “Èmi ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi àti Baba yín àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi àti Ọlọ́run yín,” fún ìdí yìí, kò sídìí tí Tọ́másì á fi máa rò pé Jésù ni Ọlọ́run Olódùmarè, alágbára ńlá. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 20:17.) Tọ́másì náà gbọ́ nígbà tí Jésù ń gbàdúrà sí “Baba” rẹ̀, tó sì pè é ní “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.” (Jo 17:1-3) Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdí tí Tọ́másì fi pe Jésù ní “Ọlọ́run mi” ni pé: Ó ń wo Jésù bí “ọlọ́run kan” kì í ṣe Ọlọ́run Olódùmarè. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 1:1.) Ó tún lè jẹ́ pé bó ṣe pe Jésù yẹn, ṣe ló ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ohun tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan ṣe nígbà tí wọ́n rí áńgẹ́lì Jèhófà, bó ṣe wà nínu Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ó dájú pé Tọ́másì náà máa mọ àwọn apá kan nínú Ìwé Mímọ́, níbi tí àwọn kan tàbí àwọn tó kọ Bíbélì ti bá áńgẹ́lì Jèhófà sọ̀rọ̀ bíi pé áńgẹ́lì yẹn ni Jèhófà Ọlọ́run. (Fi wé Jẹ 16:7-11, 13; 18:1-5, 22-33; 32:24-30; Ond 6:11-15; 13:20-22.) Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdí tí Tọ́másì fi pe Jésù ní “Ọlọ́run mi” ni pé òun náà gbà pé Jésù ni aṣojú tí Ọlọ́run rán wá, òun sì ni agbọ̀rọ̀sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ náà.
Àwọn kan sọ pé bí Bíbélì ṣe lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó ṣe pàtó fún “olúwa” àti “ọlọ́run” jẹ́ kó ṣe kedere pé Ọlọ́run Olódùmarè ló ń tọ́ka sí. Àmọ́ ní àyíká ọ̀rọ̀ yìí, gírámà èdè Gíríìkì ló jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà rí bẹ́ẹ̀. Àwọn ibì kan wà tí wọ́n ti lo ọ̀rọ̀ orúkọ tó jẹ́ atọ́ka, papọ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìṣáájú fún ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó jẹ́ ọ̀rọ̀ orúkọ tàbí ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ, a máa rí àpẹẹrẹ díẹ̀ nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Lk 12:32 (ní Gíríìkì, “agbo kékeré náà”) àti Kol 3:18–4:1 (ní Gíríìkì, “ẹ̀yin aya náà”; “ẹ̀yin ọkọ náà”; “ẹ̀yin ọmọ náà”; “ẹ̀yin baba náà”; “ẹ̀yin ẹrú náà”; “ẹ̀yin ọ̀gá náà”). Lọ́nà kan náà, tá a bá túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú 1Pe 3:7 ní tààràtà, ohun tó máa jẹ́ ni: “Ẹ̀yin ọkọ náà.” Torí náà, lóòtọ́, wọ́n lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó ń tọ́ka sí ohun kan níbí, àmọ́ ìyẹn kọ́ la fi máa mọ ohun tó wà lọ́kàn Tọ́másì nígbà tó sọ̀rọ̀ yìí.
Bíbélì Kíkà
NOVEMBER 12-18
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌṢE 1-3
“Ọlọ́run Tú Ẹ̀mí Mímọ́ Sórí Ìjọ Kristẹni”
w86 12/1 22 ¶4-5, 7
Awọn Ọrẹ Tí Nmú Ọkàn-àyà Láyọ̀
Ní ọjọ akọkọ ìbí ijọ Kristain ní ọdun 33 C.E., “ṣiṣajọpin pẹlu araawọn ẹnikinni ẹnikeji, lati jẹ awọn ounjẹ ati lati gbadura” ni a sọ dàṣà laarin 3,000 awọn ọmọ-ẹhin tí a ṣẹṣẹ baptisi. Fun idi rere wo? Lati lè mú ki ó ṣeeṣe fun wọn lati ṣe itilẹhin fun igbagbọ wọn tí ó ṣẹṣẹ ndagbasoke nipa ‘bíbáa niso lati yà araawọn sọtọ patapata fun ẹkọ awọn apostle.’—Iṣe 2:41, 42, NW.
Awọn Jew ati awọn aláwọ̀ṣe ti wá sí Jerusalem tí wọn sì wéwèé lati duro fun kìkì sáà akoko ajọ-ariya Pentecost. Ṣugbọn awọn wọnni tí wọn di Kristian ní ifẹ-ọkan lati duro pẹ́ sii ki wọn sí kọ́ pupọ sii lati lè fun igbagbọ wọn titun lókun. Eyi ṣẹ̀dá ọran-iṣoro ounjẹ ati ile-gbigbe pajawiri kan. Pupọ ninu awọn alejo naa kò ní owónàá tí ó pọ̀ tó pẹlu wọn, nigba tí awọn miiran ní àníṣẹ́kù. Nitori naa ìdájọpọ̀ ohun-ìní ṣẹlẹ fun igba diẹ ati ipinkiri awọn nkan ti ara fun awọn wọnni tí wọn wà ninu aini.—Iṣe 2:43-47.
Títà awọn dúkìá-ìní gidi ati ṣiṣajọpin gbogbo nkan papọ jẹ́ pẹlu ìfínnúfíndọ̀ ní gbogbo ọna. Kò si ẹni tí a mú un ní dandan fun lati tà tabi tọrẹ. Eyi kii sìí ṣe ìgbégasíwájú ipo òṣì. Ero-ọkan tí a sọjade kii ṣe pe ki awọn memba tí wọn jẹ́ ọlọ́rọ̀ jù tà gbogbo dúkìá wọn nipa bayii ki wọn sì di òtòṣì. Kaka bẹẹ, lati inu ìyọ́nú fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn tí wọn wà labẹ awọn ayika-ipo naa ní akoko yẹn, wọn tà dúkìá wọn sì fi owó tí ó ti inu rẹ̀ jade tọrẹ lati lè pese ohun tí a nilo fun itẹsiwaju anfaani ire Ijọba.—Fiwe 2 Corinth 8:12-15.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 61 ¶1
Jésù Kristi
“Olórí Aṣojú ìyè.” Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ pípé lélẹ̀ láti fi rúbọ, èyí sì ń jẹ́ ká rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Bàbá rẹ̀ fi hàn sí wa. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù kan láti wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú Ìjọba rẹ̀ lọ́run, ó sì tún mú kó ṣeé ṣe fún àwọn míì láti gbádùn Ìjọba yẹn lórí ilẹ̀ ayé níbí. (Mt 6:10; Jo 3:16; Ef 1:7; Heb 2:5) Ó tipa bẹ́ẹ̀ di “Olórí Aṣojú ìyè” fún gbogbo èèyàn. (Iṣe 3:15) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Bíbélì lò níbí sábà máa ń túmọ̀ sí “olórí aṣáájú,” wọ́n lo ọ̀rọ̀ tó jọ èyí fún Mósè (Iṣe 7:27, 35) gẹ́gẹ́ bí “olùṣàkóso” ní Ísírẹ́lì.
Ọlọ́run Tó “Ṣe Tán Láti Dárí Jini”
14 Nínú Ìṣe 3:19, Bíbélì tún ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe ń dárí jini. Ó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì yí padà, kí a lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́.” Gbólóhùn náà ‘pa rẹ́’ tí a lò yìí tú ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì kan tó lè túmọ̀ sí “láti nu nǹkan nù, . . . láti fagi lé nǹkan tàbí láti pa nǹkan run.” Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ti sọ, èrò tó mú wá síni lọ́kàn ni pípa ohun téèyàn fọwọ́ kọ rẹ́. Báwo ni èyí ṣe lè ṣeé ṣe? Àpòpọ̀ èédú, oje igi àti omi ni wọ́n sábà fi ń ṣe yíǹkì láyé àtijọ́. Tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ fi irú yíǹkì bẹ́ẹ̀ kọ̀wé tán, ó lè fi kànrìnkàn tí ó ti rẹ sínú omi pa ohun tí ó kọ rẹ́. Àpèjúwe alárinrin yìí bá àánú Jèhófà mu wẹ́kú. Nígbà tó bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, ṣe ló dà bíi pé ó fi kànrìnkàn nù ún nù.
it-1 129 ¶2-3
Ta ló rọ́pò Júdásì Ísíkáríótù, tí àwọn àpọ́sítélì fi pé méjìlá pa dà?
Lẹ́yìn tí Júdásì Ísíkáríótù hùwà àìṣòótọ́, tó da Jésù tó sì kù, àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá (11) ló ṣẹ́ kù. Nínú gbogbo ogójì (40) ọjọ́ tí Jésù lò lẹ́yìn tó jíǹde kó tó lọ sọ́run, kò yan ẹlòmíì rọ́pò Júdásì. Ìgbà kan láàárín ọjọ́ mẹ́wàá kí Jésù tó lọ sí ọ̀run tó fi di ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé ó yẹ kí ẹlòmíì rọ́pò Júdásì, àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí Pétérù fa ọ̀rọ̀ yọ nínú wọn fi hàn pé kì í ṣe torí pé Júdásì kú ni wọ́n ṣe fi ẹlòmíì rọ́pò rẹ̀, àmọ́ ó jẹ́ torí pé ó hùwà ọ̀dàlẹ̀. (Iṣe 1:15-22; Sm. 69:25; 109:8; fi wé Iṣi 3:11.) Torí nígbà tí Jákọ́bù tó jẹ́ àpọ́sítélì olóòótọ́ kú, kò sí ẹ̀rí èyíkéyìí tó fi hàn pé wọ́n ronú láti yan ẹnikẹ́ni tó máa gba ipò rẹ̀.—Iṣe 12:2.
Ó hàn gbangba nínú ọ̀rọ̀ tí Pétérù sọ pé, wọ́n gbé e yẹ̀ wò pé ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá máa yàn láti rọ́pò àpọ́sítélì èyíkéyìí gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n àwọn nǹkan kan. Ẹni náà gbọ́dọ̀ mọ Jésù dáadáa nígbà tó wà láyè, ó gbọ́dọ̀ fojú ara rẹ̀ rí àwọn iṣẹ́ tó ṣe, iṣẹ́ ìyanu tó ṣe àti ní pàtàkì, àjíǹde Jésù. Torí náà, pẹ̀lú àwọn ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n rẹ̀ yìí, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ kò ní sí ẹni tó lè kúnjú ìwọ̀n láti rọ́pò àpọ́sítélì èyíkéyìí àfi tí Ọlọ́run bá dìídì yan onítọ̀hún. Ṣáájú ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, a rí àwọn kan tó kúnjú ìwọ̀n láti di àpọ́sítélì, torí náà, wọ́n mú méjì lára wọn wá, tí wọ́n lè fi rọ́pò Júdásì tó di aláìṣòótọ́. Ó dájú pé ohun tó wà nínú Òwe 16:33 ni wọ́n tẹ̀ lé, wọ́n ṣẹ́ kèké, wọ́n sì yan Mátíásì, lẹ́yìn náà “a sì kà á kún àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá” yòókù. (Iṣe 1:23-26) Òun náà wà lára “àwọn méjìlá” tó yanjú ìṣòro tó wáyé láàárín àwọn Júù tó ń sọ èdè Gíríìkì (Iṣe 6:1, 2), ẹ̀rí sì fi hàn pé Pọ́ọ̀lù kà á mọ́ ara “àwọn méjìlá” tí Jésù fara hàn lẹ́yìn tó jíǹde nínú 1 Kọ́ríńtì 15:4-8. Torí náà, ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, àwọn àpọ́sítélì méjìlá ti pé, àwọn ló sì máa jẹ́ ìpìlẹ̀ fún Ísírẹ́lì tẹ̀mí tí wọ́n dá sílẹ̀ nígbà yẹn.
Bíbélì Kíkà
NOVEMBER 19-25
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌṢE 4-5
“Wọ́n Ń Fi Àìṣojo Sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”
w08 9/1 15, àpótí
Ọ̀rọ̀ Tí Jésù Sọ Ni Wọ́n Kọ Sínú Ìwé Mímọ́—Bá A Ṣe Mọ̀ Pé Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Mọ̀wé Kọ
Ṣé Púrúǹtù Làwọn Àpọ́sítélì?
Nígbà táwọn alákòóso àtàwọn àgbà ọkùnrin Jerúsálẹ́mù “rí àìfọ̀rọ̀-bọpo-bọyọ̀ Pétérù àti Jòhánù, tí wọ́n sì róye pé wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì.” (Ìṣe 4:13) Ṣé àwọn tí kò mọ̀wé tàbí púrúǹtù làwọn àpọ́sítélì lóòótọ́? Nígbà tí Bíbélì The New Interpreter’s Bible ń sọ̀rọ̀ lórí ohun tí wọ́n sọ yìí, ó sọ pé: “Ó dà bíi pé kò yẹ ká gbà pé bọ́rọ̀ yẹn ṣe rí ni wọ́n ṣe sọ ọ́ yẹn, bíi pé Pétérù [àti Jòhánù] kò kàwé kankan àti pé [wọn] ò mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Ohun tí wọ́n kàn ń fi gbólóhùn yẹn sọ ni pé ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ló wà nínú ipò táwọn tó ń gbẹ́jọ́ yẹn àtàwọn àpọ́sítélì wà láwùjọ.”
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìṣe
4:13—Ṣé èèyàn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù ni Pétérù àti Jòhánù? Rárá o. Ìdí táwọn kan fi pè wọ́n ní “ènìyàn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù” ni pé wọn ò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àwọn rábì láti lọ gba ẹ̀kọ́ ìsìn.
it-1 128 ¶3
Àpọ́sítélì
Iṣẹ́ Wọn Nínú Ìjọ Kristẹni. Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ sórí ìjọ ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, ìyẹn sì fún àwọn àpọ́sítélì lókun. Orí márùn-ún àkọ́kọ́ nínú ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì jẹ́ ká ríi pé àwọn àpọ́sítélì fi ìgboyà wàásù ìhìn rere, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde Jésù láìṣojo bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso ń jù wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n ń nà wọ́n lẹ́gba, wọ́n sì tún ń fi ikú halẹ̀ mọ́ wọn. Torí pé ẹ̀mí mímọ́ ló ń darí àwọn àpọ́sítélì tó ń múpò iwájú, èyí mú kí ìbísí dé bá ìjọ Kristẹni lọ́nà tó kàmàmà lẹ́yìn àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì. (Iṣe 2:41; 4:4) Jerúsálẹ́mù ni wọ́n ti kọ́kọ́ ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù wọn, lẹ́yìn náà Samáríà, nígbà tó yá, ó dé ibi gbogbo láyé.—Iṣe 5:42; 6:7; 8:5-17, 25; 1:8.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 514 ¶4
Òkúta Igun Ilé
Sáàmù 118:22 jẹ́ ká mọ̀ pé òkúta tí àwọn akọ́lé kọ̀ sílẹ̀ máa di “olórí igun ilé” (lédè Hébérù, roʼsh pin·nahʹ). Jésù yá ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí lò, ó sì sọ pé òun ni “olórí igun ilé” (lédè Gíríìkì, ke·pha·leʹ go·niʹas, olórí igun ilé náà). (Mt 21:42; Mk 12:10, 11; Lk 20:17) Òkúta tó wà ní orí ilé kì í fara sin, lọ́nà kan náà, Jésù Kristi ni òléwájú nínú ìjọ Kristẹni tí àwọn ẹni àmì òróró wà, èyí tá a tún lè pè ní tẹ́ńpìlì tẹ̀mí. Pétérù náà sọ pé Kristi ni Sáàmù 118:22 ṣe sí lára, ó jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù, “òkúta” ti àwọn èèyàn kọ̀ sílẹ̀ ni Ọlọ́run fi ṣe “olórí igun ilé.”—Iṣe 4:8-12; tún wo 1Pe 2:4-7.
Pétérù Parọ́, Ananíà Náà Parọ́—Ẹ̀kọ́ Wo Ni Èyí Kọ́ Wa?
Ananíà àti ìyàwó rẹ̀ ta ilẹ̀ wọn kan, kí wọ́n lè fi owó rẹ̀ ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi lọ́wọ́. Nígbà tí Ananíà kó owó ilẹ̀ tí ó tà náà wá fún àwọn àpọ́sítélì, ó sọ pé gbogbo rẹ̀ ni òun kó wá. Àmọ́ irọ́ ló pa! Ó ti tọ́jú díẹ̀ pa mọ́ nínú rẹ̀! Ọlọ́run wá jẹ́ kí Pétérù mọ ohun tí Ananíà ṣe yìí. Torí náà Pétérù sọ fún un pé: “Kì í ṣe ènìyàn ni o ṣèké sí, bí kò ṣe Ọlọ́run.” Bí Ananíà ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó ṣubú lulẹ̀ ó sì kú! Ní nǹkan bí wákàtí mẹ́tà lẹ́yìn ìyẹn, ìyàwó rẹ̀ wọlé wá sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì. Torí kò tíì gbọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkọ rẹ̀, òun náà parọ́. Ló bá ṣubú lulẹ̀, ó sì kú.
Bíbélì Kíkà
NOVEMBER 26–DECEMBER 2
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌṢE 6-8
“Ìjọ Kristẹni Tuntun Kojú Ìṣòro”
“Àwa Gbọ́dọ̀ Ṣègbọràn sí Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Olùṣàkóso”
17 Ewu kan fẹ́ yọ́ kẹ́lẹ́ wọlé sínú ìjọ táwọn àpọ́sítélì ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀. Ewu wo nìyẹn? Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi ló jẹ́ àlejò ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i kí wọ́n tó pa dà sílé. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù wá fínnú fíndọ̀ fowó ṣètìlẹyìn kí wọ́n lè ra oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì táwọn àlejò wọ̀nyí nílò. (Ìṣe 2: 44-46; 4: 34-37) Ọ̀rọ̀ kan tó gbẹgẹ́ wá ṣẹlẹ̀. Wọ́n ‘gbójú fo àwọn opó’ tó ń sọ èdè Gíríìkì “dá nínú ìpín-fúnni ojoojúmọ́.” (Ìṣe 6:1) Àmọ́ wọn kò gbójú fo àwọn opó tó ń sọ èdè Hébérù dá. Ó jọ pé kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ láàárín wọn. Ìyapa sì nirú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń fà.
“Àwa Gbọ́dọ̀ Ṣègbọràn sí Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Olùṣàkóso”
18 Àwọn àpọ́sítélì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìgbìmọ̀ olùdarí láti máa bójú tó àwọn ìjọ tó túbọ̀ ń gbòòrò sí i mọ̀ pé kò bọ́gbọ́n mu pé káwọn “fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀ lọ máa pín oúnjẹ.” (Ìṣe 6:2) Ohun tí wọ́n ṣe láti yanjú ọ̀rọ̀ náà ni pé, wọ́n sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé kí wọ́n ṣàwárí àwọn ọkùnrin méje “tí wọ́n kún fún ẹ̀mí àti ọgbọ́n” táwọn àpọ́sítélì lè yàn sípò “àmójútó tí ó pọndandan” yìí. (Ìṣe 6:3) Àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n ló lè ṣe iṣẹ́ yìí, nítorí pé iṣẹ́ yẹn ju pé kí wọ́n kàn fún àwọn èèyàn lóúnjẹ lọ, ó tún kan bíbójútó ọ̀ràn owó, ríra àwọn nǹkan tí wọ́n nílò àti fífi ìṣọ́ra ṣe àwọn àkọsílẹ̀ kan. Gbogbo àwọn ọkùnrin tí wọ́n yàn yìí ló ní orúkọ Gíríìkì, ó sì ṣeé ṣe kí inú àwọn opó tí wọ́n gbójú fò dá yẹn dùn sí èyí. Lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì ti gbàdúrà lórí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n yan àwọn ọkùnrin méje náà láti bójú tó “iṣẹ́ àmójútó tí ó pọndandan” yìí.”
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Sítéfánù—“Kún fún Oore Ọ̀fẹ́ àti Agbára”
2 Ohun kan wà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ìrísí ojú Sítéfánù lákòókò yìí. Àwọn adájọ́ náà tẹjú mọ́ ọn, wọ́n sì rí i pé ojú rẹ rí “bí ojú áńgẹ́lì.” (Ìṣe 6:15) Iṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run làwọn áńgẹ́lì máa ń jẹ́, torí náà kò sídìí fún wọn láti bẹ̀rù, ọkàn wọn sì máa ń balẹ̀. Pẹ̀sẹ̀ lọkàn Sítéfánù náà balẹ̀, àwọn adájọ́ tí wọ́n kórìíra rẹ̀ gidigidi náà sì rí i bẹ́ẹ̀. Kí ló mú kí ọkàn ẹ̀ balẹ̀ bẹ́ẹ̀?
Pípolongo “Ìhìn Rere Nípa Jésù”
16 Lóde òní, àwọn Kristẹni láǹfààní láti ṣe irú iṣẹ́ tí Fílípì ṣe yìí. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń ṣeé ṣe fún wọn láti sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn tí wọ́n bá bá pàdé, bíi nígbà tí wọ́n bá ń rìnrìn àjò. Ó sì dájú pé wọn kì í ṣàdédé bá àwọn tó mọyì òtítọ́ pàdé. Bó ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn, torí Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn kí ìhìn rere náà lè dé ọ̀dọ̀ “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn.” (Ìṣí. 14:6) Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí àwọn áńgẹ́lì á ṣe máa darí iṣẹ́ ìwàásù náà. Nínú àkàwé tí Jésù ṣe nípa àwọn èpò àti àlìkámà, ó ní, nígbà ìkórè, ìyẹn ní ìparí ètò àwọn nǹkan, “àwọn áńgẹ́lì sì ni akárúgbìn.” Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yìí á “kó gbogbo ohun tí ń fa ìkọ̀sẹ̀ jáde kúrò nínú ìjọba rẹ̀ àti àwọn ènìyàn tí ń hu ìwà àìlófin.” (Mát. 13:37-41) Lẹ́sẹ̀ kan náà, àwọn áńgẹ́lì á kó àwọn ajogún Ìjọba náà jọ, àti lẹ́yìn náà “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti àwọn “àgùntàn mìíràn,” àwọn tí Jèhófà fẹ́ fà wá sínú ètò rẹ̀.—Ìṣí. 7:9; Jòh. 6:44, 65; 10:16.
Bíbélì Kíkà