16 Èèyàn lè gbèrò ohun kan lọ́kàn ara rẹ̀,
Àmọ́ ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìdáhùn rẹ̀ ti máa wá.+
2 Gbogbo ọ̀nà èèyàn máa ń tọ́ lójú ara rẹ̀,+
Àmọ́ Jèhófà máa ń ṣàyẹ̀wò èrò ọkàn.+
3 Fi gbogbo ohun tí o bá ń ṣe lé Jèhófà lọ́wọ́,+
Ohun tí o fẹ́ ṣe á sì yọrí sí rere.
4 Jèhófà ti mú kí gbogbo nǹkan rí bó ṣe fẹ́,
Kódà láti pa ẹni burúkú run ní ọjọ́ àjálù.+
5 Jèhófà kórìíra gbogbo ẹni tó ń gbéra ga.+
Ó dájú pé wọn ò ní lọ láìjìyà.
6 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ máa ń mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò,+
Ìbẹ̀rù Jèhófà sì máa ń mú kéèyàn yẹra fún ohun búburú.+
7 Tí inú Jèhófà bá dùn sí ọ̀nà èèyàn,
Ó máa ń mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ̀.+
8 Ó sàn kéèyàn ní díẹ̀ àmọ́ kó jẹ́ olóòótọ́+
Ju kéèyàn fi èrú kó èrè púpọ̀ jọ.+
9 Èèyàn lè ro bí ọ̀nà rẹ̀ ṣe máa rí lọ́kàn rẹ̀,
Àmọ́ Jèhófà ló ń darí ìṣísẹ̀ rẹ̀.+
10 Ìpinnu tó ní ìmísí ló yẹ kó máa wà lẹ́nu ọba;+
Kò gbọ́dọ̀ dá ẹjọ́ lọ́nà tí kò tọ́.+
11 Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìwọ̀n àti òṣùwọ̀n pípé ti wá;
Gbogbo òkúta ìwọ̀n tó wà nínú àpò jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.+
12 Àwọn ọba kórìíra ìwà burúkú,+
Nítorí òdodo ló ń fìdí ìtẹ́ múlẹ̀ gbọn-in.+
13 Ọ̀rọ̀ òdodo jẹ́ ìdùnnú àwọn ọba.
Wọ́n fẹ́ràn ẹni tó bá ń sọ òótọ́.+
14 Ìbínú ọba dà bí òjíṣẹ́ ikú,+
Àmọ́ ọlọ́gbọ́n ló ń tù ú lójú.+
15 Ẹni tó bá rí ojú rere ọba, ayé onítọ̀hún á ládùn;
Ojú rere rẹ̀ dà bíi ṣíṣú òjò ìgbà ìrúwé.+
16 Ó mà sàn kéèyàn ní ọgbọ́n ju kó ní wúrà o!+
Ó sì dára kéèyàn ní òye ju kó ní fàdákà.+
17 Láti yẹra fún ohun búburú ni ọ̀nà àwọn adúróṣinṣin.
Ẹni tó bá ń ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀ ń dáàbò bo ẹ̀mí rẹ̀.+
18 Ìgbéraga ló ń ṣáájú ìparun,
Ẹ̀mí ìgbéraga ló sì ń ṣáájú ìkọ̀sẹ̀.+
19 Ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ láàárín àwọn oníwà pẹ̀lẹ́+
Ju kéèyàn pín nínú ẹrù tí àwọn agbéraga kó.
20 Ẹni tó ń lo ìjìnlẹ̀ òye nínú ọ̀ràn yóò ṣàṣeyọrí,
Aláyọ̀ sì ni ẹni tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.
21 Ẹni tó ní ọkàn ọgbọ́n ni a ó pè ní olóye,+
Ẹni tó sì ń sọ̀rọ̀ rere ń yíni lérò pa dà.+
22 Ìjìnlẹ̀ òye jẹ́ kànga ìyè fún àwọn tó ni ín,
Àmọ́ ìwà ẹ̀gọ̀ àwọn òmùgọ̀ ló ń bá wọn wí.
23 Ọkàn ọlọ́gbọ́n ń fún ẹnu rẹ̀ ní ìjìnlẹ̀ òye+
Ó sì ń fi ìyíniléròpadà kún ọ̀rọ̀ rẹ̀.
24 Ọ̀rọ̀ dídùn jẹ́ afárá oyin,
Ó dùn mọ́ ọkàn, ó sì ń wo egungun sàn.+
25 Ọ̀nà kan wà tó dà bíi pé ó tọ́ lójú èèyàn,
Àmọ́ nígbẹ̀yìn, á yọrí sí ikú.+
26 Ikùn lébìrà ló ń mú kó ṣiṣẹ́ kára,
Ebi tó ń pa á sì ń mú kó tẹpá mọ́ṣẹ́.+
27 Èèyàn tí kò ní láárí máa ń hú ohun tí kò dáa jáde;+
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ dà bí iná tó ń jóni.+
28 Oníwàhálà máa ń dá ìyapa sílẹ̀,+
Abanijẹ́ sì máa ń tú àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ká.+
29 Oníwà ipá máa ń tan ọmọnìkejì rẹ̀
Á sì kó o ṣìnà.
30 Bó ṣe ń ṣẹ́jú ló ń gbèrò ibi.
Ó fún ètè rẹ̀ pọ̀ bó ṣe ń ṣe iṣẹ́ ibi.
31 Ewú orí jẹ́ adé ẹwà+
Nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.+
32 Ẹni tí kì í tètè bínú+ sàn ju akíkanjú ọkùnrin,
Ẹni tó sì ń kápá ìbínú rẹ̀ sàn ju ẹni tó ṣẹ́gun ìlú.+
33 Orí itan ni à ń ṣẹ́ kèké lé,+
Àmọ́ ọ̀dọ̀ Jèhófà ni gbogbo ìpinnu tí ó bá ṣe ti wá.+