Fi Ojú Pàtàkì Wo Ẹ̀bùn Ìwàláàyè Rẹ
“Ẹ̀jẹ̀ Kristi, yóò wẹ ẹ̀rí-ọkàn wa mọ́ kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́ kí a lè ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run alààyè.”—HÉBÉRÙ 9:14.
1. Kí ni ẹ̀rí tó fi hàn pé ẹ̀mí wa jọ wá lójú gan-an?
TÍ WỌ́N bá ní kó o díye lé ìwàláàyè rẹ, èló ni wàá dá lé e? Ìwàláàyè ṣe pàtàkì sí wa gan-an, ẹ̀mí wa jọ wá lójú bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ̀mí àwọn ẹlòmíràn jọ wá lójú pẹ̀lú. Ẹ̀rí kan tó fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn ni pé, a máa ń lọ sọ́dọ̀ dókítà láti lọ gbàtọ́jú nígbà tára wa ò bá yá tàbí ká lọ máa ṣe àyẹ̀wò ara wa látìgbàdégbà. Kò sẹ́ni tó fẹ́ kú, gbogbo wa la sì fẹ́ kí ara wa le. Kódà, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ti dàgbà tàbí tí wọ́n jẹ́ aláàbọ̀ ara pàápàá ò fẹ́ kú; wọ́n fẹ́ máa wà láàyè nìṣó.
2, 3. (a) Ojúṣe wo ni Òwe 23:22 sọ pé a ní? (b) Báwo ni ọ̀rọ̀ nípa ojúṣe tí Òwe 23:22 mẹ́nu kan yìí ṣe kan Ọlọ́run?
2 Ojú tó o fi ń wo ìwàláàyè yóò nípa lórí bí wàá ṣe bá àwọn ẹlòmíràn lò. Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Fetí sí baba rẹ tí ó bí ọ, má sì tẹ́ńbẹ́lú ìyá rẹ kìkì nítorí pé ó ti darúgbó.” (Òwe 23:22) Ohun tí ọ̀rọ̀ náà “fetí sí” túmọ̀ sí ju pé kó o kàn gbọ́ ọ̀rọ̀ lọ; òwe yìí túmọ̀ sí pé kó o gbọ́ kó o sì ṣègbọràn. (Ẹ́kísódù 15:26; Diutarónómì 7:12; 13:18; 15:5; Jóṣúà 22:2; Sáàmù 81:13) Àmọ́, kí nìdí tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi sọ pé kó o máa fetí sí bàbá àti ìyá rẹ? Kì í kàn án ṣe nítorí pé bàbá àti ìyá rẹ dàgbà jù ọ́ lọ tàbí pé wọ́n mọ nǹkan jù ọ́ lọ. Ìdí tó fi ní kó o máa fetí sí wọn ni pé, àwọn ló “bí ọ.” Bí àwọn Bíbélì kan ṣe túmọ̀ ẹsẹ yìí rèé: “Fetí sí bàbá rẹ tí ó fún ọ ní ìwàláàyè.” Bẹ́ẹ̀ ni o, tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni ẹ̀mí rẹ jọ ọ́ lójú, wàá fẹ́ ṣe nǹkan kan fẹ́ni tó fún ọ ní ìwàláàyè náà.
3 Dájúdájú, tó bá jẹ́ pé Kristẹni tòótọ́ ni ọ́, wàá mọ̀ pé Jèhófà ni Orísun ìwàláàyè. Òun lẹni tó fún ọ “ní ìwàláàyè;” o lè “rìn,” o sì lè ṣe nǹkan gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá olóye; àti pé o “wà” o sì lè ronú nípa ọjọ́ iwájú tàbí kó o wéwèé nípa ọjọ́ ọ̀la títí kan ìyè ayérayé. (Ìṣe 17:28; Sáàmù 36:9; Oníwàásù 3:11) Gẹ́gẹ́ bí Òwe 23:22 ṣe wí, ó tọ̀nà pé ká “fetí sí” Ọlọ́run nípa ṣíṣe ìgbọràn, kí á fẹ́ láti mọ irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìwàláàyè, kí á sì máa fi irú ojú yẹn wò ó dípò tí a ó fi tẹ́wọ́ gba èrò èyíkéyìí táwọn èèyàn ní nípa ìwàláàyè.
Má Ṣe Fojú Kékeré Wo Ìwàláàyè
4. Níbẹ̀rẹ̀ ìtàn ẹ̀dá èèyàn, báwo ni a ṣe fojú pàtàkì wo ẹ̀mí èèyàn?
4 Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí Jèhófà dá èèyàn, ó mú kó ṣe kedere pé òun kò fàyè gba aráyé láti lo ẹ̀mí èèyàn fún ohunkóhun (tàbí kí wọ́n ṣe é níṣekúṣe.) Owú gba Kéènì lọ́kàn débi pé ó gbẹ̀mí Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀ láìṣẹ̀ láìrò. Ṣé ìwọ rò pé Kéènì láṣẹ láti ṣe irú nǹkan tó ṣe yẹn sí ẹ̀mí èèyàn? Ọlọ́run ò rò bẹ́ẹ̀ o. Ó ní kí Kéènì wá jíhìn, ó sọ pé: “Kí ni ìwọ ṣe? Fetí sílẹ̀! Ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ ń ké jáde sí mi láti inú ilẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:10) Kíyè sí pé ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì tó wà lórí ilẹ̀ dúró fún ẹ̀mí rẹ̀ tí Kéènì gbà láìtọ́jọ́, ó sì ń ké pe Ọlọ́run fún ẹ̀san.—Hébérù 12:24.
5. (a) Òfin wo ní Ọlọ́run ṣe nígbà ayé Nóà, àwọn wo sì ni òfin náà kàn? (b) Ọ̀nà wo ni òfin yìí gbà jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì kan?
5 Lẹ́yìn Ìkún Omi, èèyàn mẹ́jọ péré ló bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé tuntun. Nígbà tí Ọlọ́run sọ̀rọ̀ tó kan gbogbo ẹ̀dá èèyàn, ó jẹ́ ká túbọ̀ mọ irú ojú tí òun fi ń wo ìwàláàyè àti ẹ̀jẹ̀. Ó sọ pé èèyàn lè máa jẹ ẹran àmọ́ ó wá ṣòfin kan pẹ̀lú rẹ̀ pé: “Gbogbo ẹran tí ń rìn, tí ó wà láàyè, lè jẹ́ oúnjẹ fún yín. Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ti ewéko tútù yọ̀yọ̀, mo fi gbogbo rẹ̀ fún yín ní ti gidi. Kìkì ẹran pẹ̀lú ọkàn rẹ̀—ẹ̀jẹ̀ rẹ̀—ni ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ.” (Jẹ́nẹ́sísì 9:3, 4) Àwọn Júù kan sọ pé ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí ni pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ ẹranko tí kò tíì kú. Àmọ́ bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó wá hàn kedere pé òfin tí Ọlọ́run ṣe nínú ẹsẹ yẹn ni pé a ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ láti fi gbẹ́mìí ró. Kò tán síbẹ̀ o, òfin tí Ọlọ́run tipa Nóà ṣe jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì kan láti mú ète Rẹ̀ gígalọ́lá nípa ẹ̀jẹ̀ ṣẹ, ìyẹn ète tó máa mú kí aráyé rí ìyè àìnípẹ̀kun.
6. Báwo ni Ọlọ́run ṣe tipa Nóà tẹnu mọ́ ojú pàtàkì tóun fi ń wo ìwàláàyè?
6 Ọlọ́run ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ẹ̀jẹ̀ yín ti ọkàn yín ni èmi yóò béèrè padà. Lọ́wọ́ olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè ni èmi yóò ti béèrè rẹ̀ padà; àti lọ́wọ́ ènìyàn, lọ́wọ́ olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ́ arákùnrin rẹ̀, ni èmi yóò ti béèrè ọkàn ènìyàn padà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀, láti ọwọ́ ènìyàn ni a ó ti ta ẹ̀jẹ̀ tirẹ̀ sílẹ̀, nítorí ní àwòrán Ọlọ́run ni ó ṣe ènìyàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 9:5, 6) A lè wá rí i látinú ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ fún gbogbo ẹ̀dá èèyàn yìí pé, lójú Ọlọ́run, ẹ̀jẹ̀ dúró fún ìwàláàyè ènìyàn. Ẹlẹ́dàá ló fún olúkúlùkù ní ìwàláàyè, kò sì sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ gba ẹ̀mí èèyàn tí ẹ̀jẹ̀ dúró fún yìí. Tẹ́nì kan bá pààyàn bíi ti Kéènì, Ẹlẹ́dàá lẹ́tọ̀ọ́ láti “béèrè” ẹ̀mí apààyàn náà.
7. Kí nìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ fún Nóà nípa ẹ̀jẹ̀?
7 Ọlọ́run tipa ọ̀rọ̀ tó sọ yìí ṣòfin pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ lo ẹ̀jẹ̀ nílòkulò. Ǹjẹ́ ìdí tí Ọlọ́run fi ṣòfin yẹn ti ṣe ọ́ ní kàyéfì rí? Àti pé kí nìdí tí Ọlọ́run fi ń fi irú ojú yẹn wo ẹ̀jẹ̀? Ní ti gidi, ìdáhùn sí ìbéèrè náà ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú Bíbélì. Ẹ̀kọ́ yìí ṣe pàtàkì gan-an nínú ẹ̀kọ́ Kristẹni, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ni kò ka ẹ̀kọ́ náà sí. Kí ni ẹ̀kọ́ náà, báwo sì ni ìwàláàyè rẹ, ìpinnu rẹ àti ìṣe rẹ ṣe wé mọ́ ẹ̀kọ́ náà?
Báwo La Ṣe Lè Máa Lo Ẹ̀jẹ̀ Lọ́nà Tó Tọ́?
8. Kí ni Jèhófà sọ nípa ìlò ẹ̀jẹ̀ nínú Òfin tó fún Mósè?
8 Jèhófà túbọ̀ ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ìwàláàyè àti ẹ̀jẹ̀ nígbà tó fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin. Fífún tí Jèhófà fún wọn ní òfin yẹn jẹ́ ìgbésẹ̀ mìíràn láti mú ète rẹ̀ ṣẹ. Ó ṣeé ṣe kó o mọ̀ pé Òfin náà sọ pé kí wọ́n máa mú ọrẹ ẹbọ wá fún Ọlọ́run, irú bí ọkà, òróró àti wáìnì. (Léfítíkù 2:1–4; 23:13; Númérì 15:1–5) Wọ́n tún máa ń fi ẹran rúbọ pẹ̀lú. Ọlọ́run sọ nípa ìyẹn pé: “Nítorí ọkàn ara ń bẹ nínú ẹ̀jẹ̀, èmi tìkára mi sì ti fi sórí pẹpẹ fún yín láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín, nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni ó ń ṣe ètùtù nípasẹ̀ ọkàn tí ń bẹ nínú rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Ọkàn kankan lára yín kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀.’” Jèhófà wá fi kún un pé tí ẹnikẹ́ni, bí ọdẹ tàbí àgbẹ̀ bá pa ẹran kan fún jíjẹ, ó gbọ́dọ̀ da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ jáde kí ó sì fi ekuru bò ó. Ilẹ̀ ayé jẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run, nítorí náà tí ẹnì kan bá jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ ẹran náà dà jáde sórí ilẹ̀, ó túmọ̀ sí pé onítọ̀hún gbà pé ìwàláàyè náà ti padà sọ́dọ̀ Ẹni tí ó fi í fúnni nìyẹn.—Léfítíkù 17:11–13; Aísáyà 66:1.
9. Kí ni ohun kan ṣoṣo tá à ń lo ẹ̀jẹ̀ fún lábẹ́ Òfin, kí sì ni ohun tí ìyẹn wà fún?
9 Kì í ṣe pé Òfin yẹn kàn jẹ́ ààtò ìsìn kan lásán láìsí nǹkan gbòógì kan tó túmọ̀ sí fún wa o. Ǹjẹ́ o kíyè sí ìdí tá a fi ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì má ṣe jẹ ẹ̀jẹ̀? Ọlọ́run sọ pé: “Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Ọkàn kankan lára yín kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀.’” Kí nìdí? “Èmi tìkára mi sì ti fi [ẹ̀jẹ̀] sórí pẹpẹ fún yín láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín.” Ṣé o wá rí i pé èyí jẹ́ ká mọ ìdí tí Ọlọ́run fi sọ fún Nóà pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀? Ẹlẹ́dàá ka ẹ̀jẹ̀ sí ohun tó ṣe pàtàkì gan-an, ó yà á sọ́tọ̀ fún ìlò pàtàkì kan tí yóò gba ọ̀pọ̀ èèyàn là. Ẹ̀jẹ̀ yóò kó ipa pàtàkì láti bo ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀ (ìyẹn láti fi ṣe ètùtù). Nítorí náà, orí pẹpẹ nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run fọwọ́ sí lábẹ́ òfin pé ká ti máa lo ẹ̀jẹ̀, láti fi ṣe ètùtù fún ìwàláàyè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó bá tọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ Jèhófà.
10. Kí nìdí tí ẹ̀jẹ̀ ẹran kò fi lè mú ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ pátápátá wá, kí sì ni ohun tí ẹbọ tá à ń rú lábẹ́ Òfin ránni létí rẹ̀?
10 Ọ̀rọ̀ pé à ń fi ẹ̀jẹ̀ ṣe ètùtù kì í ṣe tuntun fún àwọn Kristẹni. Nígbà tí Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ètò tí Ọlọ́run ṣe sínú Òfin yìí, ó kọ̀wé pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ohun gbogbo ni a fi ẹ̀jẹ̀ wẹ̀ mọ́ ní ìbámu pẹ̀lú Òfin, bí kò sì ṣe pé a tú ẹ̀jẹ̀ jáde, ìdáríjì kankan kì í wáyé.” (Hébérù 9:22) Pọ́ọ̀lù mú kó ṣe kedere pé àwọn ẹbọ tí òfin là kalẹ̀ kò sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di ẹni pípé tàbí aláìlẹ́ṣẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Nípasẹ̀ ẹbọ wọ̀nyí, ìránnilétí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wà láti ọdún dé ọdún, nítorí kò ṣeé ṣe fún ẹ̀jẹ̀ àwọn akọ màlúù àti ti àwọn ewúrẹ́ láti mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.” (Hébérù 10:1–4) Síbẹ̀ àwọn ẹbọ náà wúlò. Ó ń rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n àti pé wọ́n nílò ohun kan tó ju ẹbọ lọ kí a lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n pátápátá. Àmọ́, bí ẹ̀jẹ̀ tí ó dúró fún ìwàláàyè ẹran kò bá lè mú ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn kúrò pátápátá, ṣé ẹ̀jẹ̀ mìíràn máa lè mú un kúrò?
Ojútùú Látọwọ́ Olùfúnni-ní-Ìyè
11. Báwo la ṣe mọ̀ pé nǹkan míì ni fífi ẹ̀jẹ̀ ẹran ṣe ìrúbọ ń tọ́ka sí?
11 Ní ti gidi, ohun kan tó gbéṣẹ́ gan-an láti mú ète Ọlọ́run ṣẹ ni Òfin náà ń tọ́ka sí. Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Ti Òfin ti wá jẹ́?” Òun fúnra rẹ̀ dáhùn pé: “A fi kún un láti mú kí àwọn ìrélànàkọjá fara hàn kedere, títí irú-ọmọ tí a ṣe ìlérí fún yóò fi dé; a sì ta á látaré nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì láti ọwọ́ alárinà kan [ìyẹn Mósè].” (Gálátíà 3:19) Bákan náà, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Òfin ti ní òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀, ṣùgbọ́n tí kì í ṣe kókó inú àwọn ohun náà gan-an.”—Hébérù 10:1.
12. Báwo la ṣe lè lóye ète Ọlọ́run tá a ṣí payá lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀?
12 Níbi tá a bọ́rọ̀ dé yìí, rántí pé nígbà ayé Nóà, Ọlọ́run sọ pé àwọn èèyàn lè máa jẹ ẹran àmọ́ ó ṣòfin pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Nígbà tó yá, Ọlọ́run sọ pé “ọkàn ara ń bẹ nínú ẹ̀jẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run ka ẹ̀jẹ̀ sí ohun tó dúró fún ìwàláàyè, ó sọ pé: “Èmi tìkára mi sì ti fi [ẹ̀jẹ̀] sórí pẹpẹ fún yín láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín.” Àmọ́ ṣá o, ohun àgbàyanu kan ṣì wà tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe tó máa ṣí payá nígbà tó bá yá. Òfin náà ṣàpẹẹrẹ àwọn ohun rere tó ń bọ̀. Kí ni àwọn nǹkan ọ̀hún?
13. Kí nìdí tí ikú Jésù fi ṣe pàtàkì?
13 Ikú Jésù Kristi ni àwọn nǹkan ọ̀hún dá lé lórí. Ẹ mọ̀ pé wọ́n dá Jésù lóró, wọ́n tún kàn án mọ́gi. Bí ọ̀daràn ló ṣe kú. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nígbà tí àwa ṣì jẹ́ aláìlera, Kristi kú fún àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ní àkókò tí a yàn kalẹ̀. . . . Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Róòmù 5:6, 8) Ikú tí Kristi kú nítorí wa ló pèsè ẹbọ ìràpadà fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ẹbọ ìràpadà náà ni lájorí ohun táwọn Kristẹni ń wàásù rẹ̀. (Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16; 1 Kọ́ríńtì 15:3; 1 Tímótì 2:6) Kí wá ni èyí ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ àti ìwàláàyè, báwo sì ni èyí ṣe kan ìwàláàyè rẹ?
14, 15. (a) Báwo ni ọ̀nà tí wọ́n gbà túmọ̀ Éfésù 1:7 nínú àwọn Bíbélì kan ṣe tẹnu mọ́ ikú Jésù? (b) Kí ni kókó kan tó wà nínú Éfésù 1:7 tó ṣeé ṣe kí wọ́n ti gbójú fò dá?
14 Àwọn ìsìn kan ò yéé sọ̀rọ̀ nípa ikú Jésù, àwọn ọmọ ìjọ wọn sì máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ bíi “Jésù kú fún mi.” Wo bí àwọn Bíbélì kan ṣe túmọ̀ Éfésù 1:7, wọ́n ní: “Nínú rẹ̀ àti nípasẹ̀ ikú rẹ̀ la ní ìdáǹdè, ìyẹn ni, mímú àwọn àṣìṣe wa kúrò.” (The American Bible, látọwọ́ Frank Scheil Ballentine, 1902) “Nípasẹ̀ ikú Kristi ni wọ́n dá wa nídè, a sì rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.” (Today’s English Version, 1966) “Nínú Kristi àti nípasẹ̀ rẹ̀ àti nípa ìwàláàyè rẹ̀ tí ó fi ṣe ìrúbọ la fi ní ìtúsílẹ̀, èyí sì ni ìtúsílẹ̀ tí ó túmọ̀ sí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.” (The New Testament, látọwọ́ William Barclay, 1969) “Nípasẹ̀ ikú Kristi la fi rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa tí wọ́n sì dá wa nídè.” (The Translator’s New Testament, 1973) Ṣẹ́ ẹ rí i pé ikú Jésù ni àwọn ìtumọ̀ Bíbélì wọ̀nyí tẹnu mọ́. ‘Àmọ́,’ àwọn kan lè sọ pé, ikú ‘Jésù ṣe pàtàkì lóòótọ́. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló wá kù díẹ̀ káàtó nínú àwọn ìtumọ̀ wọ̀nyẹn?’
15 Ní tòótọ́, tó bá jẹ́ pé ìtumọ̀ Bíbélì wọ̀nyẹn nìkan lo ní, o lè máà rí kókó kan tó ṣe pàtàkì, nítorí náà ohun tí Bíbélì yẹn sọ lè má yé ọ dáadáa. Àwọn ìtumọ̀ wọ̀nyẹn ò jẹ́ ká mọ̀ ní ti tòótọ́ pé Éfésù 1:7 lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tó túmọ̀ sí “ẹ̀jẹ̀.” Nítorí náà, ọ̀pọ̀ Bíbélì, irú bí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, túmọ̀ ẹsẹ yẹn lọ́nà tó bá ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ mu, ó sọ pé: “Nípasẹ̀ rẹ̀ àwa ní ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ẹni yẹn, bẹ́ẹ̀ ni, ìdáríjì àwọn àṣemáṣe wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀.”
16. Kí ló yẹ kí ìtumọ̀ náà “ẹ̀jẹ̀ ẹni yẹn” gbé sí wá lọ́kàn?
16 Àwọn ọ̀rọ̀ náà tá a tú sí “ẹ̀jẹ̀ ẹni yẹn” ṣe pàtàkì gan-an ni, ó sì yẹ kó gbé ohun pàtàkì kan sí wá lọ́kàn. Ohun tá a nílò ju pé kéèyàn kú lọ, kódà ó ju pé kí Jésù ọkùnrin pípé náà kú pàápàá. Àwọn ohun tí Òfin Mósè ṣàpẹẹrẹ rẹ̀ ṣẹ sí i lára, pàápàá àwọn ohun tó máa ń wáyé ní Ọjọ́ Ètùtù. Ní ọjọ́ pàtàkì yìí, wọ́n á fi àwọn ẹran tí Òfin là kalẹ̀ rúbọ. Lẹ́yìn náà, àlùfáà àgbà á gbé lára ẹ̀jẹ̀ ẹran wọnú Ibi Mímọ́ Jù Lọ tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn tàbí tẹ́ńpìlì, ibẹ̀ ló ti máa fi ẹ̀jẹ̀ náà rúbọ sí Ọlọ́run bí ẹni pé àlùfáà àgbà náà wà níwájú Ọlọ́run ní ti gidi.—Ẹ́kísódù 25:22; Léfítíkù 16:2–19.
17. Báwo ni Jésù ṣe mú ohun tí Ọjọ́ Ètùtù ṣàpẹẹrẹ rẹ̀ ṣẹ?
17 Gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí Pọ́ọ̀lù ṣe, Jésù ni ohun tí Ọjọ́ Ètùtù ṣàpẹẹrẹ rẹ̀ ṣẹ sí lára. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó sọ pé àlùfáà àgbà ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì máa ń wọ Ibi Mímọ́ Jù Lọ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún láti fi ẹ̀jẹ̀ rúbọ “fún ara rẹ̀ àti fún ẹ̀ṣẹ̀ àìmọ̀ àwọn ènìyàn náà.” (Hébérù 9:6, 7) Gẹ́gẹ́ bó ti ṣe máa ń rí ní Ọjọ́ Ètùtù yìí, Jésù wọ ọ̀run lọ lẹ́yìn tá a ti jí i dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí. Nítorí pé ó ti di ẹ̀dá ẹ̀mí, tí kì í ṣe ẹlẹ́ran ara àti ẹ̀jẹ̀, ó ṣeé ṣe fún un láti dé iwájú “Ọlọ́run fúnra rẹ̀ fún wa.” Kí ni ohun tó gbé wá fún Ọlọ́run? Kì í ṣe nǹkan tá a lè fojú rí àmọ́ ó jẹ́ nǹkan tó nítumọ̀ pàtàkì. Pọ́ọ̀lù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Nígbà tí Kristi dé gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà . . . , ó wọlé sínú ibi mímọ́, rárá, kì í ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ àwọn ewúrẹ́ àti ti àwọn ẹgbọrọ akọ màlúù, bí kò ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀, lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé, ó sì gba ìdáǹdè àìnípẹ̀kun fún wa. Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ àwọn ewúrẹ́ àti ti àwọn akọ màlúù . . . bá ń sọni di mímọ́ dé àyè ìmọ́tónítóní ara, mélòómélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, ẹni tí ó tipasẹ̀ ẹ̀mí àìnípẹ̀kun fi ara rẹ̀ rúbọ sí Ọlọ́run láìní àbààwọ́n, yóò wẹ ẹ̀rí-ọkàn wa mọ́ kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́ kí a lè ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run alààyè?” Bẹ́ẹ̀ ni o, Jésù gbé ìtóye ìwàláàyè rẹ̀ wá fún Ọlọ́run.—Hébérù 9:11–14, 24, 28; 10:11–14; 1 Pétérù 3:18.
18. Kí nìdí tó fi yẹ kí ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀jẹ̀ ṣe pàtàkì lójú àwọn Kristẹni lónìí?
18 Òtítọ́ tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá yìí jẹ́ ká lóye gbogbo nǹkan ìyanu tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀jẹ̀, ìyẹn ohun tó mú kí Ọlọ́run máa fi irú ojú tó fi ń wo ẹ̀jẹ̀ wò ó, irú ojú tá a gbọ́dọ̀ máa fi wo ẹ̀jẹ̀ àti ìdí tá a fi gbọ́dọ̀ pa òfin tí Ọlọ́run ṣe nípa ìlò ẹ̀jẹ̀ mọ́. Nígbà tó o bá ń ka Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, wàá rí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ẹsẹ tó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀jẹ̀ Kristi. (Wo àpótí.) Àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí fi hàn ní kedere pé olúkúlùkù Kristẹni ní láti ní ìgbàgbọ́ “nínú ẹ̀jẹ̀ [Jésù].” (Róòmù 3:25) Àyàfi “nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ tí ó [Jésù] ta sílẹ̀” nìkan la fi lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ká sì tún wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run. (Kólósè 1:20) Èyí ṣeé ṣe fún àwọn tí Jésù bá dá májẹ̀mú àkànṣe pé wọn yóò bá òun ṣàkóso ní ọ̀run. (Lúùkù 22:20, 28–30; 1 Kọ́ríńtì 11:25; Hébérù 13:20) Ó tún ṣeé ṣe fún àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” náà lónìí, ìyẹn àwọn tí yóò la “ìpọ́njú ńlá” já, tí wọn yóò sì ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Lọ́nà àfiṣàpèjúwe, wọ́n ti ‘fọ aṣọ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.’—Ìṣípayá 7:9, 14.
19, 20. (a) Kí nìdí tí Ọlọ́run fi ṣòfin lórí ìlò ẹ̀jẹ̀, báwo ló sì ṣe yẹ kí èyí rí lára wa? (b) Kí lohun tó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ àtimọ̀?
19 Ó ṣe kedere pé ẹ̀jẹ̀ ní ìtumọ̀ pàtàkì lójú Ọlọ́run. Ó yẹ kó ṣe pàtàkì lójú tiwa náà pẹ̀lú. Ẹlẹ́dàá, tó nífẹ̀ẹ́ sí ìwàláàyè lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣòfin fún èèyàn nípa ìlò ẹ̀jẹ̀. Ìwàláàyè wa jẹ Ọlọ́run lógún gan-an, ìdí nìyẹn tó fi ya ẹ̀jẹ̀ sọ́tọ̀ fún ìlò kan tó ṣe pàtàkì gan-an, ìyẹn sì ni ọ̀nà kan ṣoṣo tó mú kí ìyè àìnípẹ̀kun ṣeé ṣe. Ọ̀nà kan ṣoṣo náà wé mọ́ ẹ̀jẹ̀ iyebíye ti Jésù. A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà Ọlọ́run wá ire wa nípa lílo ẹ̀jẹ̀, àní ẹ̀jẹ̀ Jésù fún iṣẹ́ ìgbàlà yìí! Ẹ ò ri pé ó yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Jésù fún dídà tó da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ jáde láti fi ṣe ìrúbọ fún wa! Ní tòótọ́, a lè wá lóye ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Fún ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ wa, tí ó sì tú wa kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀—ó sì mú kí a jẹ́ ìjọba kan, àlùfáà fún Ọlọ́run àti Baba rẹ̀—bẹ́ẹ̀ ni, òun ni kí ògo àti agbára ńlá jẹ́ tirẹ̀ títí láé. Àmín.”—Ìṣípayá 1:5, 6.
20 Ó ti pẹ́ gan-an tó ti wà lọ́kàn Ọlọ́run, ọlọ́gbọ́n gbogbo àti Olùfúnni-ní-ìyè láti gbà wá là. Nígbà náà, a lè wá béèrè pé, ‘Ipa wo ló yẹ kí èyí ní lórí àwọn ìpinnu wa àti ìṣe wa?’ Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò dáhùn ìbéèrè yẹn.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Kí la lè rí kọ látinú ìtàn Ébẹ́lì àti Nóà nípa irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ẹ̀jẹ̀?
• Nínú Òfin Mósè, kí ni Ọlọ́run fi ìlò ẹ̀jẹ̀ mọ sí, kí sì nìdí tó fi ṣòfin yẹn?
• Báwo ni àwọn ohun tí Ọjọ́ Ètùtù ṣàpẹẹrẹ rẹ̀ ṣe ṣẹ sára Jésù?
• Báwo ni ẹ̀jẹ̀ Jésù ṣe lè gba ẹ̀mí wa là?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 18]
Ẹ̀JẸ̀ TA LÓ Ń GBANI LÀ?
“Ẹ kíyè sí ara yín àti gbogbo agbo, láàárín èyí tí ẹ̀mí mímọ́ yàn yín ṣe alábòójútó, láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run, èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà.”—Ìṣe 20:28.
“Mélòómélòó, nígbà náà, níwọ̀n bí a ti polongo wa ní olódodo nísinsìnyí nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ni a ó tipasẹ̀ rẹ̀ gbà wá là kúrò nínú ìrunú.”—Róòmù 5:9.
“Ẹ kò sì ní ìrètí kankan, ẹ sì wà ní ayé láìní Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù, ẹ̀yin tí ẹ jìnnà réré nígbà kan rí ti wá wà nítòsí nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Kristi.”—Éfésù 2:12, 13.
“Ọlọ́run rí i pé ó dára pé kí ẹ̀kún gbogbo máa gbé inú rẹ̀, àti láti tún tipasẹ̀ rẹ̀ mú gbogbo ohun mìíràn padà rẹ́ pẹ̀lú ara rẹ̀ nípa mímú àlàáfíà wá nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ lórí òpó igi oró.”—Kólósè 1:19, 20.
“Nítorí náà, ẹ̀yin ará, . . . a ti ní àìṣojo fún ọ̀nà ìwọlé sínú ibi mímọ́ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù.”—Hébérù 10:19.
“Kì í ṣe pẹ̀lú àwọn ohun tí ó lè díbàjẹ́, . . . ni a fi dá yín nídè kúrò nínú ọ̀nà ìwà yín aláìléso, tí ẹ gbà nípasẹ̀ òfin àtọwọ́dọ́wọ́ láti ọwọ́ àwọn baba ńlá yín. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bí ti ọ̀dọ́ àgùntàn aláìlábààwọ́n àti aláìléèérí, àní ti Kristi.”—1 Pétérù 1:18, 19.
“Bí a bá ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun fúnra rẹ̀ ti wà nínú ìmọ́lẹ̀, àwa ní àjọpín pẹ̀lú ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ̀jẹ̀ Jésù Ọmọ rẹ̀ sì ń wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀.”—1 Jòhánù 1:7.
“Ìwọ ni ó yẹ láti gba àkájọ ìwé náà, kí o sì ṣí àwọn èdìdì rẹ̀, nítorí pé a fikú pa ọ́, o sì fi ẹ̀jẹ̀ rẹ ra àwọn ènìyàn fún Ọlọ́run láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè.”—Ìṣípayá 5:9.
“Olùfisùn àwọn arákùnrin wa ni a ti fi sọ̀kò sísàlẹ̀, . . . Wọ́n sì ṣẹ́gun rẹ̀ nítorí ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà àti nítorí ọ̀rọ̀ ìjẹ́rìí wọn.”—Ìṣípayá 12:10, 11.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ọlọ́run mú kó ṣe kedere nípasẹ̀ Òfin Mósè pé ẹ̀jẹ̀ lè kó ipa nínú ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ọ̀pọ̀ èèyàn lè tipasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù rí ìgbàlà