Jẹ́nẹ́sísì
4 Ádámù bá Éfà ìyàwó rẹ̀ ní àṣepọ̀, ó sì lóyún.+ Nígbà tó bí Kéènì,+ ó sọ pé: “Jèhófà ti mú kí n ní* ọmọkùnrin kan.” 2 Lẹ́yìn náà, ó tún bí Ébẹ́lì,+ àbúrò rẹ̀.
Ébẹ́lì di olùṣọ́ àgùntàn, àmọ́ Kéènì di àgbẹ̀. 3 Nígbà tó yá, Kéènì mú àwọn èso kan wá, ó fi ṣe ọrẹ fún Jèhófà. 4 Àmọ́ Ébẹ́lì mú lára àwọn àkọ́bí ẹran+ rẹ̀ wá, pẹ̀lú ọ̀rá wọn. Jèhófà ṣojúure sí Ébẹ́lì, ó sì gba ọrẹ+ rẹ̀, 5 àmọ́ kò ṣojúure sí Kéènì rárá, kò sì gba ọrẹ rẹ̀. Torí náà, Kéènì bínú gan-an, inú rẹ̀ ò sì dùn.* 6 Jèhófà wá sọ fún Kéènì pé: “Kí ló dé tí inú ń bí ọ tó báyìí, tí inú rẹ ò sì dùn? 7 Tí o bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe rere, ṣé o ò ní pa dà rí ojúure ni?* Àmọ́ tí o ò bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe rere, ẹ̀ṣẹ̀ lúgọ sí ẹnu ọ̀nà, ó sì fẹ́ jọba lé ọ lórí; àmọ́ ṣé o máa kápá rẹ̀?”
8 Lẹ́yìn náà, Kéènì sọ fún Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀ pé: “Jẹ́ ká lọ sí oko.” Nígbà tí wọ́n sì wà nínú oko, Kéènì lu Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀, ó sì pa á.+ 9 Lẹ́yìn náà, Jèhófà bi Kéènì pé: “Ibo ni Ébẹ́lì arákùnrin rẹ wà?” Ó fèsì pé: “Mi ò mọ̀. Ṣé èmi ni olùṣọ́ arákùnrin mi ni?” 10 Ọlọ́run wá sọ pé: “Kí lo ṣe yìí? Tẹ́tí kó o gbọ́ mi! Ẹ̀jẹ̀ àbúrò rẹ ń ké jáde sí mi láti inú ilẹ̀.+ 11 Ní báyìí, ègún wà lórí rẹ, màá sì lé ọ kúrò lórí ilẹ̀ tó la ẹnu láti mu ẹ̀jẹ̀ àbúrò rẹ tí o ta sílẹ̀.+ 12 Tí o bá dá oko, ilẹ̀ ò ní mú èso* rẹ̀ jáde fún ọ. O sì máa di alárìnká àti ìsáǹsá ní ayé.” 13 Kéènì wá sọ fún Jèhófà pé: “Ìyà ẹ̀ṣẹ̀ mi ti pọ̀ jù fún mi. 14 Lónìí, ò ń lé mi kúrò ní ilẹ̀,* èmi yóò sì kúrò níwájú rẹ; èmi yóò di alárìnká àti ìsáǹsá ní ayé, ó sì dájú pé ẹnikẹ́ni tó bá rí mi yóò pa mí.” 15 Jèhófà wá sọ fún un pé: “Kí ìyẹn má bàa ṣẹlẹ̀, ẹnikẹ́ni tó bá pa Kéènì yóò jìyà ìlọ́po méje.”
Jèhófà wá ṣe àmì kan* fún Kéènì kí ẹnikẹ́ni tó bá rí i má bàa pa á. 16 Lẹ́yìn náà, Kéènì kúrò níwájú Jèhófà, ó sì lọ ń gbé ní ilẹ̀ Ìgbèkùn,* ní apá ìlà oòrùn Édẹ́nì.+
17 Kéènì wá bá ìyàwó+ rẹ̀ ní àṣepọ̀, ó lóyún, ó sì bí Énọ́kù. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ìlú kan, ó sì fi orúkọ ọmọ rẹ̀ Énọ́kù pe ìlú náà. 18 Énọ́kù wá bí Írádì. Írádì bí Mèhújáélì, Mèhújáélì bí Mètúṣáélì, Mètúṣáélì sì bí Lámékì.
19 Lámékì fẹ́ ìyàwó méjì. Orúkọ àkọ́kọ́ ni Ádà, orúkọ ìkejì sì ni Síláhì. 20 Ádà bí Jábálì. Òun ni ẹni àkọ́kọ́ tó gbé inú àgọ́ tó sì ní ẹran ọ̀sìn. 21 Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Júbálì. Òun ni ẹni àkọ́kọ́ tó lo háàpù àti fèrè ape. 22 Bákan náà, Síláhì bí Tubali-kéénì, ẹni tó ń rọ onírúurú irinṣẹ́ tí wọ́n fi bàbà àti irin ṣe. Náámà sì ni arábìnrin Tubali-kéénì. 23 Lámékì ń sọ fún àwọn ìyàwó rẹ̀, Ádà àti Síláhì, pé:
“Ẹ gbọ́ ohùn mi, ẹ̀yin ìyàwó Lámékì;
Ẹ fetí sí mi:
Mo pa ọkùnrin kan torí ó ṣe mí léṣe,
Àní ọ̀dọ́kùnrin kan, torí ó lù mí.
24 Tí ẹni tó bá pa Kéènì bá máa jìyà ní ìlọ́po méje,+
Ẹni tó bá pa Lámékì máa jìyà ní ìgbà àádọ́rin ó lé méje (77).”
25 Ádámù tún bá ìyàwó rẹ̀ ní àṣepọ̀, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Ó pe orúkọ rẹ̀ ní Sẹ́ẹ̀tì*+ torí ó sọ pé: “Ọlọ́run ti fi ọmọ* míì rọ́pò Ébẹ́lì fún mi, torí Kéènì pa á.”+ 26 Sẹ́ẹ̀tì náà bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ ọ́ ní Énọ́ṣì.+ Ìgbà yẹn ni àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í pe orúkọ Jèhófà.