ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 14
Ìgbéjàkò Láti Apá Àríwá!
“Orílẹ̀-èdè kan ti gòkè wá sí ilẹ̀ mi.”—JÓẸ́LÌ 1:6.
ORIN 95 Ìmọ́lẹ̀ Náà Ń Mọ́lẹ̀ Sí I
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Ọ̀nà wo ni Arákùnrin Russell àtàwọn yòókù rẹ̀ ń gbà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn, kí sì nìdí tí ọ̀nà yẹn fi dáa?
NÍ OHUN tó lé lọ́gọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, Arákùnrin C. T. Russell àtàwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bíi tiẹ̀ máa ń kóra jọ láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n máa ń ṣèwádìí kí wọ́n lè mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an nípa Jèhófà, Jésù Kristi, ipò táwọn òkú wà àtohun tí Bíbélì sọ nípa ìràpadà. Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣèwádìí náà kò ṣòro rárá. Ẹnì kan á béèrè ìbéèrè, lẹ́yìn náà gbogbo wọn á wo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ṣàlàyé kókó náà. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n á ṣàkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n ṣàwárí. Pẹ̀lú ìtìlẹyìn ẹ̀mí Jèhófà, àwọn arákùnrin olóòótọ́ yẹn ṣàwárí àwọn òtítọ́ pàtàkì kan nínú Bíbélì, a sì mọyì àwọn òtítọ́ yẹn títí dòní olónìí.
2. Kí ló lè mú kéèyàn ṣi àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì lóye?
2 Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn wá rí i pé ohun kan ni kéèyàn lóye ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa ẹ̀kọ́ òtítọ́, àmọ́ nǹkan ọ̀tọ̀ gbáà ni kéèyàn ní òye tó péye nípa àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì torí pé kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé a sábà máa ń lóye àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ní kíkún nígbà tó bá ń nímùúṣẹ tàbí lẹ́yìn tó bá ti nímùúṣẹ. Ìdí míì ni pé kéèyàn tó lè lóye àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì dáadáa, ó ṣe pàtàkì kéèyàn lóye ọ̀rọ̀ náà látòkèdélẹ̀, kì í ṣe lápá kan. Tó bá jẹ́ pé apá kan àsọtẹ́lẹ̀ náà la wò, a lè má fi bẹ́ẹ̀ lóye ẹ̀, kódà a lè ṣì í lóye. Nígbà tá a tún àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Jóẹ́lì yẹ̀ wò, a rí i pé ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Torí náà ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ náà, ká sì jíròrò ìdí tó fi yẹ ká tún èrò wa ṣe nípa ẹ̀.
3-4. Àlàyé wo la máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì 2:7-9?
3 Ka Jóẹ́lì 2:7-9. Wòlíì Jóẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn eéṣú máa ya bo ilẹ̀ Ísírẹ́lì, wọ́n á sì jẹ ilẹ̀ náà run. Bíbélì ròyìn pé eyín wọn àti páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ wọn dà bíi ti kìnnìún, gbogbo ohun tí wọ́n bá sì rí ni wọ́n á jẹ ní àjẹrun! (Jóẹ́lì 1:4, 6) Àlàyé tá a ti máa ń ṣe láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ni pé àwa èèyàn Jèhófà tá à ń fìtara wàásù, tá ò sì jẹ́ kí ohunkóhun dá wa dúró bíi tàwọn eéṣú yẹn ni àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ sí lára. A ṣàlàyé pé ìwàásù tá à ń ṣe ń fa ìparun fún “ilẹ̀” kan, ìyẹn àwọn èèyàn tó wà lábẹ́ àkóso àwọn olórí ẹ̀sìn.b
4 Tó bá jẹ́ pé Jóẹ́lì 2:7-9 nìkan la kà tàbí pé òun nìkan la fẹ́ ṣàlàyé, a lè sọ pé òye tá a ní tọ̀nà. Àmọ́ tá a bá ka àsọtẹ́lẹ̀ náà látòkèdélẹ̀, àá rí i pé ó yẹ ká tún òye wa ṣe. Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò ìdí mẹ́rin tá a fi sọ bẹ́ẹ̀.
KÓKÓ MẸ́RIN TÓ MÚ KÁ ṢÀTÚNṢE
5-6. Ìbéèrè wo ló jẹ yọ lẹ́yìn tá a ṣàgbéyẹ̀wò (a) Jóẹ́lì 2:20? (b) Jóẹ́lì 2:25?
5 Kókó àkọ́kọ́ ni ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa àwọn eéṣú tó bo ilẹ̀ náà, ó ní: “Màá lé àwọn ará àríwá [ìyẹn àwọn eéṣú náà] jìnnà sí yín.” (Jóẹ́lì 2:20) Tó bá jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń pa àṣẹ Jésù mọ́ pé kí wọ́n wàásù kí wọ́n sì sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn ni eéṣú náà ṣàpẹẹrẹ, kí nìdí tí Jèhófà fi ṣèlérí pé òun máa lé wọn jìnnà? (Ìsík. 33:7-9; Mát. 28:19, 20) Èyí fi hàn pé kì í ṣe àwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà ni Jèhófà máa lé jìnnà bí kò ṣe ohun kan tàbí àwọn kan tó kórìíra àwọn èèyàn rẹ̀.
6 Kókó kejì lohun tó wà nínú Jóẹ́lì 2:25. Nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, Jèhófà sọ pé: “Màá . . . san àwọn ohun tí ẹ ti pàdánù láwọn ọdún yẹn fún yín. Àwọn ọdún tí ọ̀wọ́ eéṣú, eéṣú tí kò níyẹ̀ẹ́, ọ̀yánnú eéṣú àti eéṣú tó ń jẹ nǹkan run fi jẹ irè oko yín, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọmọ ogun mi tí mo rán sáàárín yín.” Ẹ kíyè sí pé Jèhófà lóun máa ‘san àsanpadà’ ohun tí àwọn eéṣú náà jẹ run. Tó bá jẹ́ pé àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run làwọn eéṣú náà ṣàpẹẹrẹ, a jẹ́ pé àdánù ni ìwàásù wọn ń fà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìhìn tó ń gbẹ̀mí là ni wọ́n ń polongo, kódà ó mú káwọn èèyàn búburú yí ìwà wọn pa dà. (Ìsík. 33:8, 19) Ẹ ò rí i pé èrè ńlá nìyẹn!
7. Kí ló gbàfiyèsí nípa ọ̀rọ̀ náà, “lẹ́yìn ìyẹn” tó wà nínú Jóẹ́lì 2:28, 29?
7 Ka Jóẹ́lì 2:28, 29. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí kókó kẹta, ìyẹn bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe sọ pé àwọn nǹkan máa ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra. Ẹ kíyè sóhun tí Jèhófà sọ pé: “Lẹ́yìn ìyẹn, èmi yóò tú ẹ̀mí mi.” Ìyẹn ni pé ó máa tú ẹ̀mí rẹ̀ jáde lẹ́yìn táwọn eéṣú náà bá ti ṣe iṣẹ́ wọn parí. Tó bá jẹ́ pé àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run làwọn eéṣú náà ṣàpẹẹrẹ, kí nìdí tó fi jẹ́ pé ẹ̀yìn tí wọ́n parí iṣẹ́ ìwàásù wọn ni Jèhófà máa tú ẹ̀mí rẹ̀ sára wọn? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé láìsí ìtìlẹyìn ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, wọn ò ní lè wàásù rárá, bẹ́ẹ̀ sì rèé ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n fi wàásù, tí wọn ò sì rẹ̀wẹ̀sì láìka àtakò àti ìfòfindè sí.
8. Àwọn wo ni eéṣú inú Ìfihàn 9:1-11 ṣàpẹẹrẹ? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
8 Ka Ìfihàn 9:1-11. Ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ lórí kókó kẹrin. Tẹ́lẹ̀, a gbà pé iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe ni àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì nípa àwọn eéṣú tó bo ilẹ̀ kan ṣàpẹẹrẹ nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ náà jọ èyí tó wà nínú ìwé Ìfihàn. Àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Ìfihàn yẹn sọ nípa àwọn eéṣú tí ojú wọn dà bíi ti èèyàn, tí wọ́n sì dé “ohun tó dà bí adé tí wọ́n fi wúrà ṣe.” (Ìfi. 9:7) Bíbélì sọ pé “àwọn èèyàn [àwọn ọ̀tá Ọlọ́run] tí kò ní èdìdì Ọlọ́run ní iwájú orí wọn nìkan” ni wọ́n dá lóró fún oṣù márùn-ún gbáko, ìyẹn iye àkókò tí eéṣú máa ń lò láyé. (Ìfi. 9:4, 5) Àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ yìí jẹ́ ká rí i pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ ẹni àmì òróró ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣàpẹẹrẹ. Wọ́n ń fìgboyà kéde ìdájọ́ Jèhófà sórí ayé èṣù yìí, ìyẹn ò sì bá àwọn èèyàn ayé lára mu.
9. Àwọn ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín eéṣú inú àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì àtèyí tí Jòhánù sọ nínú ìwé Ìfihàn?
9 Òótọ́ ni pé àwọn nǹkan kan wà tí àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Ìfihàn fi jọra pẹ̀lú ti ìwé Jóẹ́lì. Bó ti wù kó rí, wọ́n yàtọ̀ síra gan-an. Ẹ wò ó báyìí ná: Nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì, àwọn eéṣú yẹn jẹ àwọn nǹkan ọ̀gbìn àti igi run. (Jóẹ́lì 1:4, 6, 7) Nínú ìran tí Jòhánù rí, a sọ fún àwọn eéṣú yẹn pé “kí wọ́n má pa koríko ayé lára.” (Ìfi. 9:4) Apá àríwá làwọn eéṣú tí Jóẹ́lì rí ti wá. (Jóẹ́lì 2:20) Àtinú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ lèyí tí Jòhánù rí ti wá. (Ìfi. 9:2, 3) Jèhófà lé àwọn eéṣú tí Jóẹ́lì rí jìnnà. Nínú ìwé Ìfihàn, Jèhófà ò lé àwọn eéṣú ibẹ̀ rárá, ó jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ wọn parí. Kò sí àkọsílẹ̀ kankan nínú Bíbélì tó fi hàn pé Jèhófà bínú sí àwọn eéṣú inú ìwé Ìfihàn.—Wo àpótí náà “Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Eéṣú—Wọ́n Jọra, àmọ́ Nǹkan Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Ni Wọ́n Ṣàpẹẹrẹ.”
10. Sọ àpẹẹrẹ kan látinú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé nǹkan ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn eéṣú tí Jóẹ́lì àti Jòhánù rí ṣàpẹẹrẹ.
10 Àwọn ìyàtọ̀ tó wà láàárín àsọtẹ́lẹ̀ méjèèjì yìí jẹ́ kó túbọ̀ yé wa pé wọn kì í ṣe ohun kan náà. Ṣé ohun tá à ń sọ ni pé eéṣú tí wòlíì Jóẹ́lì rí kì í ṣe ọ̀kan náà pẹ̀lú eéṣú tó wà nínú ìwé Ìfihàn? Ohun tá à ń sọ gan-an nìyẹn. Nínú Bíbélì, kì í ṣe ohun àjèjì pé kí wọ́n lo ohun kan ṣoṣo láti ṣàpẹẹrẹ nǹkan ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Bí àpẹẹrẹ, nínú Ìfihàn 5:5, Bíbélì pe Jésù ní “Kìnnìún ẹ̀yà Júdà” nígbà tí 1 Pétérù 5:8 pe Èṣù ní “kìnnìún tó ń ké ramúramù.” Àwọn kókó mẹ́rin tá a jíròrò tán yìí àtàwọn ìbéèrè tó jẹ yọ mú kó pọn dandan pé ká ṣàtúnṣe sí òye tá a ní nípa àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì. Kí wá ni òye tuntun tá a ní báyìí?
KÍ LÓ TÚMỌ̀ SÍ?
11. Báwo lọ̀rọ̀ tó wà nínú Jóẹ́lì 1:6 àti 2:1, 8, 11 ṣe jẹ́ ká mọ ẹni táwọn eéṣú náà ṣàpẹẹrẹ?
11 Tá a bá kíyè sí àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì látòkèdélẹ̀, àá rí i pé ṣe ni wòlíì náà ń sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ọmọ ogun kan máa gbéjà ko ilẹ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Jóẹ́lì 1:6; 2:1, 8, 11) Jèhófà sọ pé òun máa lo “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ọmọ ogun” òun (ìyẹn àwọn ọmọ ogun Bábílónì) láti fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìgbọràn. (Jóẹ́lì 2:25) Bíbélì pe àwọn ọmọ ogun náà ní “àwọn ará àríwá” torí pé apá àríwá làwọn ará Bábílónì máa gbà wá gbéjà ko ilẹ̀ Ísírẹ́lì. (Jóẹ́lì 2:20) Bíbélì fi àwọn ọmọ ogun náà wé ọ̀wọ́ eéṣú tí wọ́n tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́. Jóẹ́lì sọ nípa àwọn ọmọ ogun náà pé: “Kálukú wọn ń tọ ọ̀nà tirẹ̀. . . . Wọ́n rọ́ wọnú ìlú, wọ́n sáré lórí ògiri. Wọ́n gun orí àwọn ilé, wọ́n sì gba àwọn ojú fèrèsé wọlé bí olè.” (Jóẹ́lì 2:8, 9) Ṣé ẹ lè fojú inú wo bó ṣe máa rí? Ibi yòówù kéèyàn yíjú sí, àwọn ọmọ ogun yẹn ló máa rí. Kò síbi téèyàn lè forí pa mọ́ sí tí ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Bábílónì kò ní tẹ̀ ẹ́.
12. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì nípa àwọn eéṣú ṣe nímùúṣẹ?
12 Bí ìgbà tí eéṣú bá ya bo ìlú làwọn ará Bábílónì (ìyẹn àwọn ará Kálídíà) ṣe ya wọ ìlú Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Bíbélì sọ pé: “Ọba àwọn ará Kálídíà dìde sí wọn, ẹni tó fi idà pa àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn . . . , kò ṣàánú ọ̀dọ́kùnrin tàbí ọ̀dọ́bìnrin, arúgbó tàbí aláàárẹ̀. Ohun gbogbo ni Ọlọ́run fi lé e lọ́wọ́. Ó sun ilé Ọlọ́run tòótọ́ kanlẹ̀, ó wó ògiri Jerúsálẹ́mù lulẹ̀, ó sun gbogbo àwọn ilé gogoro tó láàbò, ó sì ba gbogbo ohun tó ṣeyebíye jẹ́.” (2 Kíró. 36:17, 19) Lẹ́yìn táwọn ọmọ ogun Bábílónì run ilẹ̀ náà tán, ṣe làwọn èèyàn ń sọ pé: “Ahoro ni, tí kò sí èèyàn àti ẹranko lórí rẹ̀, a sì ti fi í lé ọwọ́ àwọn ará Kálídíà.”—Jer. 32:43.
13. Ṣàlàyé ohun tí ọ̀rọ̀ inú Jeremáyà 16:16, 18 túmọ̀ sí.
13 Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún méjì (200) lẹ́yìn tí Jóẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, Jèhófà lo wòlíì Jeremáyà láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ míì nípa ìgbéjàkò náà. Ó sọ pé àwọn ará Bábílónì máa fara balẹ̀ wá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń hùwà burúkú kàn, wọ́n á sì mú wọn nígbèkùn. Ó ní: “‘Wò ó, màá ránṣẹ́ pe ọ̀pọ̀ apẹja,’ ni Jèhófà wí, ‘wọ́n á sì mú wọn bí ẹja. Lẹ́yìn ìyẹn, màá ránṣẹ́ pe ọ̀pọ̀ ọdẹ, wọ́n á sì máa dọdẹ wọn kiri lórí gbogbo òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèké àti nínú àwọn pàlàpálá àpáta. . . . Màá san ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó yẹ wọ́n nítorí àṣìṣe wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn.’” Kódà báwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí kò ronú pìwà dà yẹn bá sá lọ sísàlẹ̀ alagbalúgbú omi òkun tàbí tí wọ́n fara pa mọ́ sáàárín igbó kìjikìji, ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Bábílónì máa tẹ̀ wọ́n.—Jer. 16:16, 18.
WỌ́N PA DÀ BỌ̀ SÍPÒ
14. Ìgbà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì 2:28, 29 ṣẹ?
14 Àmọ́ o, wòlíì Jóẹ́lì ní ìròyìn ayọ̀ fáwọn èèyàn náà. Ó sọ fún wọn pé nǹkan máa pa dà bọ̀ sípò. (Jóẹ́lì 2:23-26) Ó tún jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé tó bá tó àsìkò kan lọ́jọ́ iwájú, wọ́n á ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí. Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò tú ẹ̀mí mi sára onírúurú èèyàn, àwọn ọmọ yín lọ́kùnrin àti lóbìnrin yóò sì máa sọ tẹ́lẹ̀ . . . Kódà, ní àwọn ọjọ́ náà, èmi yóò tú ẹ̀mí mi sára àwọn ẹrúkùnrin mi àti sára àwọn ẹrúbìnrin mi.” (Jóẹ́lì 2:28, 29) Jèhófà kò tú ẹ̀mí rẹ̀ sórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní gbàrà tí wọ́n ti ìgbèkùn Bábílónì dé. Kàkà bẹ́ẹ̀, Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ló ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọdún lẹ́yìn tí wọ́n ti ìgbèkùn dé. Báwo la ṣe mọ̀?
15. Bó ṣe wà nínú Ìṣe 2:16, 17, gbólóhùn tó yàtọ̀ wo ni Pétérù lò nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ inú Jóẹ́lì 2:28, kí nìyẹn sì fi hàn?
15 Ẹ̀mí mímọ́ mú kí Pétérù so ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní Pẹ́ńtíkọ́sì mọ́ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Jóẹ́lì 2:28, 29. Nǹkan bí aago mẹ́sàn-án àárọ̀ ni ẹ̀mí mímọ́ bà lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lọ́nà ìyanu, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ “nípa àwọn ohun àgbàyanu Ọlọ́run.” (Ìṣe 2:11) Lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́, Pétérù lo gbólóhùn kan tó yàtọ̀ sí èyí tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì. Ǹjẹ́ o kíyè sí gbólóhùn náà? (Ka Ìṣe 2:16, 17.) Kàkà kí Pétérù fi gbólóhùn náà “lẹ́yìn ìyẹn” bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sọ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” Ọjọ́ ìkẹyìn wo ni Pétérù ní lọ́kàn? Tá a bá fojú àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ wò ó, ó túmọ̀ sí ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn Júù. Lédè míì, ó sọ pé ìgbà yẹn ni Jèhófà máa tú ẹ̀mí rẹ̀ sára “onírúurú èèyàn.” Èyí jẹ́ kó yé wa pé ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá kí apá yìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì tó ṣẹ.
16. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe mú kí iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, báwo ló sì ṣe ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí?
16 Lẹ́yìn táwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní rí ẹ̀mí mímọ́ gbà lọ́nà ìyanu, wọ́n túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù náà, wọ́n sì rí i pé ó délé dóko. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi máa kọ lẹ́tà rẹ̀ sáwọn ará nílùú Kólósè, ìyẹn ní nǹkan bí ọdún 61 Sànmánì Kristẹni, ó sọ pé ìhìn rere náà ti dé ọ̀dọ̀ “gbogbo ẹ̀dá tó wà lábẹ́ ọ̀run.” (Kól. 1:23) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé “gbogbo ẹ̀dá,” ohun tó ní lọ́kàn ni gbogbo ibi tóun àtàwọn míì bíi tiẹ̀ wàásù dé. Lónìí, ẹ̀mí mímọ́ ti mú kí iṣẹ́ ìwàásù náà gbòòrò gan-an, àní dé “gbogbo ayé”!—Ìṣe 13:47; wo àpótí náà, “Èmi Yóò Tú Ẹ̀mí Mi” Sára Àwọn Ìránṣẹ́ Mi.
KÍ LÓ YÍ PA DÀ?
17. Òye tuntun wo la ní báyìí nípa àwọn eéṣú inú àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì?
17 Kí ló yí pa dà nínú òye tá a ní? Ní báyìí, òye tá a ní nípa àsọtẹ́lẹ̀ inú Jóẹ́lì 2:7-9 ti túbọ̀ ṣe kedere. Ní kúkúrú, kì í ṣe iṣẹ́ ìwàásù tá à ń fìtara ṣe ni àsọtẹ́lẹ̀ náà ń sọ, kàkà bẹ́ẹ̀ ó ń tọ́ka sí báwọn ọmọ ogun Bábílónì ṣe gbéjà ko Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n sì pa á run lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni.
18. Kí ni kò yí pa dà nípa àwa èèyàn Jèhófà?
18 Kí ni kò yí pa dà? Àwa èèyàn Jèhófà ṣì ń bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ ní pẹrẹu, ibi gbogbo la ti ń wàásù fáwọn èèyàn, onírúurú ọ̀nà la sì ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀. (Mát. 24:14) Kò sí ìfòfindè ìjọba èyíkéyìí tó lè mú ká ṣíwọ́ àtimáa wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Torí pé Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn, ṣe la túbọ̀ ń tẹra mọ́ iṣẹ́ yìí, a ò sì ní yé fìgboyà sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáráyé gbọ́! A nígbàgbọ́ nínú Jèhófà pé ó máa mú ká túbọ̀ lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì. Torí náà, à ń fìrẹ̀lẹ̀ dúró dè é, ó sì dá wa lójú pé tó bá tó àsìkò lójú rẹ̀, á mú ká lóye “gbogbo òtítọ́”!—Jòh. 16:13.
ORIN 97 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ló Ń Mú Ká Wà Láàyè
a Ọjọ́ pẹ́ tá a ti gbà pé iṣẹ́ ìwàásù táwa ìránṣẹ́ Jèhófà ń ṣe lóde òní ni Jóẹ́lì orí kìíní àti kejì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ẹ̀. Àmọ́, kókó mẹ́rin kan wà tó jẹ́ ká rídìí tó fi yẹ ká ṣàtúnṣe sí òye tá a ní nípa àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú orí méjèèjì yìí. Kí làwọn kókó mẹ́rin náà?
b Bí àpẹẹrẹ, wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ìṣẹ̀dá Jèhófà Ń Fi Ọgbọ́n Rẹ̀ Hàn” nínú Ilé Ìṣọ́ April 15, 2009, ojú ìwé 18, ìpínrọ̀ 14 sí 16.