Ìrètí Tí Ó Dájú
“Gbàrà tí a bá ti bíni ni ó ti máa ń hàn lemọ́lemọ́ pé ìgbàkígbà ni ó ṣeé ṣe kí ènìyàn kú; láìṣeéyẹ̀, ènìyàn a sì kú nígbẹ̀yìn gbẹ́yín.”—ARNOLD TOYNBEE, ÒPÌTÀN, ỌMỌ ILẸ̀ BRITAIN.
1. Òkodoro òtítọ́ wo ni aráyé ní láti gba kámú lé lórí, tí ó mú kí àwọn ìbéèrè wo jẹyọ?
TA NÍ lè jiyàn òtítọ́ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn bí a ti fi hàn lókè yìí? Ńṣe ni aráyé kàn máa ń gba kámú nígbà gbogbo lórí òtítọ́ kíkorò náà pé ikú wà. Ẹ sì wo bí a kì í ti í lè ṣe ohunkóhun rárá nígbà tí olólùfẹ́ wa kan bá kú! Àdánù yẹn a sì wá dà bí èyí tí kò látùn-únṣe rárá. Ó ha ṣeé ṣe láti tún wà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ wa tí wọ́n ti kú bí? Ìrètí wo ni Bíbélì nawọ́ rẹ̀ sí àwọn òkú? Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí.
‘Ọ̀rẹ́ Wa Ti Kú’
2-5. (a) Nígbà tí Lásárù ọ̀rẹ́ Jésù kú, báwo ní Jésù ṣe fi fífẹ́ tí ó fẹ́ láti jí i dìde àti agbára rẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀ hàn? (b) Yàtọ̀ sí mímú kí Lásárù padà wà láàyè, kí ni iṣẹ́ ìyanu àjíǹde náà tún ṣàṣeyọrí rẹ̀?
2 Ọdún 32 Sànmánì Tiwa ni. Lásárù àti àwọn arábìnrin rẹ̀ Màtá òun Màríà ń gbé inú ìlú kékeré náà, Bẹ́tánì, tí ó jẹ́ kìlómítà mẹ́ta sí Jerúsálẹ́mù. Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni wọ́n jẹ́ sí Jésù. Lọ́jọ́ kan, àìsàn líle kan kọlu Lásárù. Kíá ni àwọn arábìnrin rẹ̀ tí ọ̀ràn náà ká lára ránṣẹ́ sọ fún Jésù, ẹni tí ó wà ní òdì-kejì Odò Jọ́dánì. Jésù fẹ́ràn Lásárù àti àwọn arábìnrin rẹ̀, nítorí náà, láìpẹ́, ó gbéra, ó ń lọ sí Bẹ́tánì. Lójú ọ̀nà, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti lọ sinmi, ṣùgbọ́n mo ń rìnrìn àjò lọ sí ibẹ̀ láti jí i kúrò lójú oorun.” Bí gbólóhùn yìí kò ti tètè yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, Jésù bá là á mọ́lẹ̀ pé: “Lásárù ti kú.”—Jòhánù 11:1-15.
3 Bí Màtá ṣe gbọ́ pé Jésù ń bọ̀ ní Bẹ́tánì, ó sáré lọ pàdé rẹ̀. Bí ìrora rẹ̀ ti mú kí àánú ṣe Jésù, ó mú kí ó dá a lójú pé: “Arákùnrin rẹ yóò dìde.” Màtá dáhùn pé: “Mo mọ̀ pé yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” Jésù bá sọ fún un pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè.”—Jòhánù 11:20-25.
4 Jésù wá lọ síbi ibojì rẹ̀, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n gbé òkúta tí wọ́n gbé dí ẹnu ọ̀nà rẹ̀ kúrò. Lẹ́yìn gbígbàdúrà sókè, ó pàṣẹ pé: “Lásárù, jáde wá!” Bí gbogbo ojú sì ṣe dà bo ibojì náà, ni Lásárù bá jáde wá lóòótọ́. Jésù mà jí Lásárù dìde—ó dá ìwàláàyè padà sínú ọkùnrin tí ó ti kú fọ́jọ́ mẹ́rin!—Jòhánù 11:38-44.
5 Màtá ti gba ìrètí àjíǹde gbọ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀. (Jòhánù 5:28, 29; 11:23, 24) Iṣẹ́ ìyanu mímú tí a mú Lásárù padà wá sí ìyè tún fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun tí ó sì mú kí àwọn ẹlòmíràn gbà gbọ́. (Jòhánù 11:45) Ṣùgbọ́n kí tilẹ̀ ni ọ̀rọ̀ náà, “àjíǹde,” túmọ̀ sí gan-an?
“Yóò Dìde”
6. Kí ni ọ̀rọ̀ náà “àjíǹde” túmọ̀ sí?
6 Ọ̀rọ̀ náà “àjíǹde” ni a túmọ̀ láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, a·naʹsta·sis, ní ṣáńgílítí tí ó túmọ̀ sí “dídìde dúró lẹ́ẹ̀kan sí i.” Àwọn tí ó túmọ̀ èdè Gíríìkì yìí sí Hébérù túmọ̀ a·naʹsta·sis sí ọ̀rọ̀ Hébérù náà, techi·yathʹ ham·me·thimʹ, tí ó túmọ̀ sí “mímú òkú sọjí.”a Nípa báyìí, gbígbé ènìyàn díde kúrò nínú ipò òkú—ní dídá ọ̀nà ìgbésí ayé onítọ̀hún padà—ni ohun tí àjíǹde ní nínú.
7. Èé ṣe tí àjíǹde ẹnì kọ̀ọ̀kan kì yóò fi jẹ́ ìṣòro fún Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi?
7 Ó rọrùn fún Jèhófà Ọlọ́run láti jí ènìyàn dìde níwọ̀n bí ọgbọ́n rẹ̀ kò ti lópin, tí agbára ìrántí rẹ̀ sì jẹ́ pípé. Rírántí ọ̀nà ìgbé ìgbésí ayé àwọn tí ó ti kú—ìṣarasíhùwà wọn, ìtàn ìgbésí ayé wọn, àti gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ìdánimọ̀ wọn—kì í ṣe ìṣòro fún un. (Jóòbù 12:13; fi wé Aísáyà 40:26.) Jèhófà tún ni Olùpilẹ̀ṣẹ̀ ìwàláàyè. Nítorí náà, wẹ́rẹ́ ni ó lè mú ẹni yẹn kan náà padà wá sí ìyè, kí ó fún un ní ànímọ́ kan náà nínú ara ìyára tuntun. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí ìrírí Lásárù ṣe fi hàn, Jésù Kristi lè jí àwọn òkú dìde, ó sì fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Fi wé Lúùkù 7:11-17; 8:40-56.
8, 9. (a) Èé ṣe tí àjíǹde àti èrò ti àìleèkú ọkàn kò fi bára mu? (b) Kí ni oògùn ikú?
8 Àmọ́, ẹ̀kọ́ àjíǹde, tí a gbé karí Ìwé Mímọ́, kò bá ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn mu. Ká ní pé ọkàn ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú ni, kì bá tún sí ẹnikẹ́ni tí ì bá yẹ kí a jí dìde tàbí tí à bá tún mú padà wá sí ìyè mọ́. Ní tòótọ́, Màtá kò sọ nǹkan kan nípa ọkàn aláìleèkú tí ó lọ ń gbé níbì kan lẹ́yìn ikú. Kò gbà gbọ́ pé ṣe ni Lásárù lọ sí ayé ẹ̀mí kan láti máa bá ìwàláàyè rẹ̀ lọ lọ́hùn-ún. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi ìgbàgbọ́ tí ó ní nínú ètè Ọlọ́run láti mú ipá tí ikú ní lórí ẹni kúrò, hàn. Ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” (Jòhánù 11:23, 24) Bákan náà, Lásárù alára kò sọ ìrírí kankan nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú. Kò ní ohunkóhun láti sọ.
9 Ní kedere, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, ọkàn ń kú, àjíǹde sì ni oògùn ikú. Àmọ́ ṣá, ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ènìyàn ló ti kú láti ìgbà tí Ádámù, ènìyàn àkọ́kọ́ ti dé ayé. Nítorí náà, ta ni a óò jí dìde, àti sí ibo?
‘Gbogbo Àwọn Tí Wọ́n Wà Nínú Ibojì Ìrántí’
10. Ìlérí wo ni Jésù ṣe nípa àwọn tí ó wà nínú ibojì ìrántí?
10 Jésù Kristi sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀ [Jésù], wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù Kristi ṣèlérí pé gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ìrántí Jèhófà ni a óò jí dìde. Ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ènìyàn ni wọ́n ti gbé láyé tí wọ́n sì ti kú. Nínú wọn, àwọn wo ni ó wà nínú ìrántí Ọlọ́run, tí wọ́n ń retí àjíǹde?
11. Ta ni a óò jí dìde?
11 A óò jí àwọn tí wọ́n ti rìn ní ipa ọ̀nà òdodo gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà dìde. Ṣùgbọ́n àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn mìíràn ni wọ́n ti kú láìfihàn bóyá àwọn yóò gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà òdodo Ọlọ́run. Ó lè jẹ́ pé wọn kò mọ ohun tí Jèhófà ń béèrè tàbí pé àkókò kò tó fún wọn láti ṣe àwọn àyípadà tí ó yẹ kí wọ́n ṣe. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú wà nínú ìrántí Ọlọ́run, nípa bẹ́ẹ̀ a óò jí wọn dìde, nítorí Bíbélì ṣèlérí pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Ìṣe 24:15.
12. (a) Ìran wo ni a fi han àpọ́sítélì Jòhánù nípa àjíǹde? (b) Kí ni a fi “sọ̀kò sínú adágún iná,” kí sì ni gbólóhùn yẹn túmọ̀ sí?
12 Àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran amọ́kànyọ̀ kan pé àwọn tí a jí dìde dúró níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run. Ní ṣíṣe àpèjúwe rẹ̀, ó kọ̀wé pé: “Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́, ikú àti Hédíìsì sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú wọn lọ́wọ́, a sì ṣèdájọ́ wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn. A sì fi ikú àti Hédíìsì sọ̀kò sínú adágún iná. Èyí túmọ̀ sí ikú kejì, adágún iná náà.” (Ìṣípayá 20:12-14) Ronú nípa ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ná! A óò tú gbogbo òkú tí ó wà ní ìrántí Ọlọ́run sílẹ̀ kúrò nínú Hédíìsì, tàbí Ṣìọ́ọ̀lù, sàréè gbogbo aráyé. (Sáàmù 16:10; Ìṣe 2:31) Lẹ́yìn náà, a óò sọ “ikú àti Hédíìsì” sínú ohun tí a pè ní “adágún iná,” tí ó ṣàpẹẹrẹ ìparun yán-ányán. Kò ní sí sàréè gbogbo aráyé mọ́.
Ibo Ni A Óò Jí Wọn Dìde Sí?
13. Èé ṣe tí Ọlọ́run fi ṣètò pé kí a jí àwọn kan dìde sí ọ̀run, irú ara wo sì ni Jèhófà yóò fi fún wọn?
13 Ìwọ̀nba kéréje àwọn ọkùnrin àti obìnrin ní a óò jí dìde sí ìyè ti ọ̀run. Àwọn wọ̀nyí yóò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Kristi, wọn yóò sì nípìn-ín nínú mímú gbogbo ìyọrísí ikú tí ìran ènìyàn jogún láti ọ̀dọ̀ ọkùnrin àkọ́kọ́, Ádámù, kúrò. (Róòmù 5:12; Ìṣípayá 5:9, 10) Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, iye wọn jẹ́ 144,000 péré, a sì yàn wọ́n láti inú àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi, bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn àpọ́sítélì olùṣòtítọ́. (Lúùkù 22:28-30; Jòhánù 14:2, 3; Ìṣípayá 7:4; 14:1, 3) Jèhófà yóò fún olúkúlùkù àwọn tí a jí dìde wọ̀nyí ní ara tẹ̀mí kí wọ́n lè gbé ní ọ̀run.—1 Kọ́ríńtì 15:35, 38, 42-45; 1 Pétérù 3:18.
14, 15. (a) Irú ayé wo ni a óò jí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ó ti kú sí? (b) Àwọn ìbùkún wo ni aráyé onígbọràn yóò gbádùn rẹ̀?
14 Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí wọ́n ti kú ni a óò jí dìde sí ìyè lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:29; Mátíù 6:10) Irú ayé wo? Lónìí, ayé kún fún gbọ́nmisi-omi-òto, ìtàjẹ̀sílẹ̀, ìbàyíkájẹ́ àti ìwà ipá. Bí ó bá jẹ́ inú irú ayé bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó ti kú yóò padà wá, ó dájú pé ayọ̀ yòówù tí ó bá wà yóò jẹ́ fún ìgbà kúkúrú. Ṣùgbọ́n Ẹlẹ́dàá ti ṣèlérí pé láìpẹ́ òun yóò mú òpin dé bá àwùjọ ayé òde òní tí ó wà lábẹ́ ìdarí Sátánì. (Òwe 2:21, 22; Dáníẹ́lì 2:44) Àwùjọ ènìyàn tuntun, olódodo—“ilẹ̀ ayé tuntun”—yóò wá wáyé lóòótọ́. (2 Pétérù 3:13) Ní àkókò náà, “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Kódà, làásìgbò tí ikú ń fà ni a óò ti mú kúrò, nítorí Ọlọ́run yóò “nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4.
15 Nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, àwọn ọlọ́kàn tútù yóò “rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:11) Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìjọba ọ̀run ti Kristi Jésù àti àwọn 144,000 alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ yóò mú aráyé onígbọràn padà wá sí ìjẹ́pípé tí àwọn òbí wa àtètèkọ́ṣe, Ádámù àti Éfà, pàdánù. Àwọn tí a óò jí dìde yóò wà lára àwọn olùgbé ayé.—Lúùkù 23:42, 43.
16-18. Irú ayọ̀ wo ni àjíǹde yóò mú wá fún àwọn ìdílé?
16 Bíbélì jẹ́ kí a rí fìrí lára ayọ̀ tí àjíǹde yóò mú wá fún àwọn ìdílé. Fojú inú wo ayọ̀ opó Náínì yẹn, nígbà tí Jésù dá ìtọ́wọ̀ọ́rìn àwọn olóòkú dúró, tí ó sì jí ọmọ kan ṣoṣo tí ó bí dìde! (Lúùkù 7:11-17) Lẹ́yìn náà, lẹ́bàá Òkun Gálílì, nígbà tí Jésù mú kí ọmọbìnrin ẹni ọdún 12 kan tún padà wà láàyè, àwọn òbí rẹ̀ “kò mọ ohun tí wọn ì bá ṣe, nítorí tí ayọ̀ náà pọ̀ jọjọ.”—Máàkù 5:21-24, 35-42; tún wo 1 Àwọn Ọba 17:17-24; 2 Àwọn Ọba 4:32-37.
17 Ní ti àwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí ń sùn nínú ikú báyìí, ìwàláàyè nínú ayé tuntun alálàáfíà ni àjíǹde tiwọn yóò já sí. Ro ohun tí ó wà níwájú fún Tommy àti oníṣòwò tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ ìwé pẹlẹbẹ yìí wò ná! Nígbà tí Tommy bá fi máa jí sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé, Tommy kan náà tí ìyá rẹ̀ mọ̀ ni yóò jẹ́—àmọ́ láìsí àìlera kankan. Ìyá rẹ̀ yóò lè fọwọ́ kàn án, yóò lè gbá a mọ́ra, yóò sì lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bákan náà, kàkà tí oníṣòwò ti Íńdíà náà ì bá fi há sínú ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ àyípo àbítúnbí tí kò lópin, ìrètí àgbàyanu tí ó ń dúró dè é ni pé yóò la ojú rẹ̀ nínú ayé tuntun Ọlọ́run, yóò sì rí àwọn ọmọ rẹ̀.
18 Mímọ òtítọ́ nípa ọkàn, nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tí a bá kú, àti nípa ìrètí àjíǹde tún lè ní ipa tí ó bùáyà lórí àwọn tí ń bẹ láàyè nísinsìnyí. Ẹ jẹ́ kí a wo bí ìyẹn ṣe jẹ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà, “àjíǹde,” kò fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, kedere ni a sọ ìrètí àjíǹde nínú Jóòbù 14:13, Dáníẹ́lì 12:13, àti Hóséà 13:14.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àjíǹde yóò mú ayọ̀ tí ó wà pẹ́ títí wá