Jóòbù
12 Jóòbù wá fèsì pé:
2 “Ó dájú pé ẹ̀yin lẹ ní ìmọ̀,*
Ọgbọ́n sì máa bá yín kú!
3 Àmọ́ èmi náà ní òye.*
Mi ò kéré sí yín,
Ta ni ò mọ àwọn nǹkan yìí?
Ẹni tó jẹ́ olódodo àti aláìlẹ́bi ni wọ́n fi ń ṣe ẹlẹ́yà.
5 Ẹni tí ara máa ń tù kórìíra àjálù,
Ó rò pé àwọn tí ẹsẹ̀ wọn ò múlẹ̀* nìkan ló máa ń dé bá.
6 Àgọ́ àwọn olè wà ní àlàáfíà,+
Àwọn tó sì ń mú Ọlọ́run bínú wà láìséwu,+
Àwọn tí ọlọ́run wọn wà ní ọwọ́ wọn.
7 Àmọ́ jọ̀ọ́, bi àwọn ẹranko, wọ́n á sì kọ́ ọ;
Àti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, wọ́n á sì sọ fún ọ.
8 Tàbí kí o fiyè sí ayé,* ó sì máa kọ́ ọ;
Àwọn ẹja inú òkun sì máa kéde rẹ̀ fún ọ.
9 Èwo nínú gbogbo àwọn yìí ni kò mọ̀
Pé ọwọ́ Jèhófà ló ṣe èyí?
14 Tó bá ya nǹkan lulẹ̀, kò ṣeé tún kọ́;+
Tó bá ti nǹkan pa, èèyàn kankan ò lè ṣí i.
16 Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni agbára àti ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ wà;+
Òun ló ni ẹni tó ń ṣìnà àti ẹni tó ń kóni ṣìnà;
17 Ó ń mú kí àwọn agbani-nímọ̀ràn lọ láìwọ bàtà,*
Ó ń sọ àwọn adájọ́ di òmùgọ̀.+
18 Ó ń tú ìdè tí àwọn ọba fi deni,+
Ó sì ń de àmùrè mọ́ ìgbáròkó wọn.
19 Ó ń mú kí àwọn àlùfáà rìn láìwọ bàtà,+
Ó sì ń gbàjọba lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n fìdí múlẹ̀ gbọn-in nípò agbára;+
20 Ó ń pa àwọn agbani-nímọ̀ràn tí wọ́n fọkàn tán lẹ́nu mọ́,
Ó sì ń gba làákàyè àwọn àgbà ọkùnrin;*
21 Ó ń rọ̀jò àbùkù sórí àwọn èèyàn pàtàkì,+
Ó sì ń mú kó rẹ àwọn alágbára;*
22 Ó ń tú àwọn ohun tó jinlẹ̀ síta látinú òkùnkùn,+
Ó sì ń tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn biribiri;
23 Ó ń mú kí àwọn orílẹ̀-èdè di ńlá, kó lè pa wọ́n run;
Ó ń mú kí àwọn orílẹ̀-èdè tóbi sí i, kó lè kó wọn lọ sí ìgbèkùn.