Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ni Bíbélì sọ nípa ìfìyà-ikú-jẹni, fún àwọn ọ̀daràn?
A lóye pé, ẹnì kọ̀ọ̀kan wá lè ní ojú ìwòye tirẹ̀ lórí ọ̀ràn yí, nítorí ìrírí tí a ti ní nínú ìgbésí ayé tàbí nítorí ipò wa. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a gbọ́dọ̀ là kàkà láti mú èrò wa bá èrò Ọlọ́run mu lórí ìfìyà-ikú-jẹni, tí a óò sì wà láìdásí tọ̀tún tòsì ní ti ojú ìwòye òṣèlú tí ọ̀pọ̀ ní lórí ọ̀ràn yí.
Kí a sọ ojú abẹ níkòó, nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a kọ sílẹ̀, Ọlọ́run kò fi hàn pé ìfìyà-ikú-jẹni lòdì.
Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìtàn ènìyàn, Jèhófà sọ èrò rẹ̀ lórí ọ̀ràn náà, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kà á nínú Jẹ́nẹ́sísì orí 9. Èyí ní í ṣe pẹ̀lú Nóà àti ìdílé rẹ̀, tí wọ́n di baba ńlá gbogbo ìdílé ìran ènìyàn. Lẹ́yìn tí wọ́n jáde kúrò nínú ọkọ̀ áàkì, Ọlọ́run sọ pé wọ́n lè jẹ ẹran—ìyẹn ni pé, wọ́n lè pa ẹran, kí wọ́n ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, kí wọ́n sì jẹ ẹ́. Lẹ́yìn náà, ní Jẹ́nẹ́sísì 9:5, 6, Ọlọ́run sọ pé: “Ní tòótọ́ ẹ̀jẹ̀ yín àní ẹ̀mí yín ni èmi ó sì béèrè; lọ́wọ́ gbogbo ẹranko ni èmi óò béèrè rẹ̀, àti lọ́wọ́ ènìyàn, lọ́wọ́ arákùnrin olúkúlùkù ènìyàn ni èmi óò béèrè ẹ̀mí ènìyàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀, láti ọwọ́ ènìyàn ni a óò sì ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀: nítorí pé ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá ènìyàn.” Lọ́nà yìí, Jèhófà fi àṣẹ sí ìfìyà-ikú-jẹni nínú ọ̀ràn ti àwọn tí ó bá pànìyàn.
Nígbà tí Ọlọ́run ń bá Ísírẹ́lì lò gẹ́gẹ́ bí ènìyàn rẹ̀, wọ́n ń fi ìyà ikú jẹ ènìyàn nítorí onírúurú ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo mìíràn tí ó lòdì sí òfin àtọ̀runwá. Nínú Númérì 15:30, a ka àlàyé tí ó kó gbogbo rẹ̀ pọ̀ yí pé: “Ọkàn náà tí ó bá fi ìkùgbù ṣe ohun kan, ì báà ṣe ìbílẹ̀ tàbí àlejò, ó sọ̀rọ̀ búburú sí OLÚWA; ọkàn náà ni a óò sì ké kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.”
Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn tí a dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ ńkọ́? Ó dára, a mọ̀ pé Jèhófà yọ̀ǹda fún ìjọba ènìyàn láti máa wà nìṣó, ó sì pè wọ́n ní aláṣẹ onípò gíga. Ní ti gidi, lẹ́yìn tí ó rọ àwọn Kristẹni láti ṣègbọràn sí irú àwọn aláṣẹ ìjọba bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ pé irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ń sìn gẹ́gẹ́ bí “òjíṣẹ́ Ọlọ́run . . . sí ọ fún ire rẹ. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń ṣe ohun tí ó burú, wà nínú ìbẹ̀rù: nítorí kì í ṣe láìsí ète ni ó gbé idà; nítorí òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni, olùgbẹ̀san láti fi ìrunú hàn jáde sí ẹni tí ń fi ohun tí ó burú ṣèwà hù.”—Róòmù 13:1-4.
Ìyẹn ha túmọ̀ sí pé, a fún ìjọba láṣẹ láti gba ẹ̀mí àwọn tí wọ́n jẹ̀bi ìwà ọ̀daràn lílé kenkà bí? Lójú ìwòye ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú Pétérù Kíní 4:15, a lè dé ìparí èrò pé, bẹ́ẹ̀ ni. Nínú àyọkà náà, àpọ́sítélì náà gba àwọn ará rẹ̀ níyànjú pé: “Kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe jìyà gẹ́gẹ́ bí òṣìkàpànìyàn tàbí olè tàbí aṣebi tàbí gẹ́gẹ́ bí olùyọjúràn sí ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn.” Ǹjẹ́ o kíyè sí i pé ó sọ pé, “kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe jìyà gẹ́gẹ́ bí òṣìkàpànìyàn”? Pétérù kò sọ pé ìjọba kò ní ẹ̀tọ́ láti jẹ òṣìkàpànìyàn kan níyà, nítorí ìwà ọ̀daràn rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi hàn pé a lè fi ìyà tí ó tọ́ jẹ òṣìkàpànìyàn náà. Ìyẹn ha ní ìyà ikú nínú bí?
Ó ṣeé ṣe. Èyí ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù, tí a rí nínú Ìṣe orí 25. Àwọn Júù ti fẹ̀sùn títàpá sí Òfin ilẹ̀ wọn kan Pọ́ọ̀lù. Nígbà tí ọ̀gágun náà ń rán Pọ́ọ̀lù tí ó fi sẹ́wọ̀n lọ sí ọ̀dọ̀ gómìnà Róòmù, ó sọ nínú Ìṣe 23:29 pé: “Mo rí i pé wọ́n fẹ̀sùn kàn án lórí àwọn ọ̀ràn Òfin wọn, ṣùgbọ́n wọn kò fi í sùn fún ẹyọ ohun kan tí ó yẹ fún ikú tàbí àwọn ìdè.” Lẹ́yìn ọdún méjì, Pọ́ọ̀lù bá ara rẹ̀ níwájú Gómìnà Fẹ́sítọ́ọ̀sì. A kà nínú Ìṣe 25:8 pé: “Pọ́ọ̀lù wí ní ìgbèjà pé: ‘Emi kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan sí Òfin àwọn Júù tàbí sí tẹ́ńpìlì tàbí sí Késárì.’” Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, pọkàn pọ̀ sórí ohun tí ó sọ nípa ìfìyàjẹni, àní ìfìyà-ikú-jẹni pàápàá. A kà á nínú Ìṣe 25:10, 11 pé:
“Pọ́ọ̀lù wí pé: ‘Mo dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́ Késárì, níbi tí ó yẹ kí a ti ṣèdájọ́ mi. Èmi kò ṣe àìtọ́ kankan sí àwọn Júù, gẹ́gẹ́ bí ìwọ pẹ̀lú ti ń rídìí òtítọ́ rẹ̀ dáadáa. Ní ọwọ́ kan, bí mo bá jẹ́ oníwà àìtọ́ ní ti tòótọ́ tí mo sì ti ṣe ohunkóhun tí ó yẹ fún ikú, èmi kò tọrọ gáfárà láti má ṣe kú; ní ọwọ́ kejì, bí ìkankan lára àwọn ohun wọnnì tí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ń fẹ̀sùn rẹ̀ kàn mí kò bá sí, ènìyàn kankan kò lè fi mí lé wọn lọ́wọ́ láti fi wá ojú rere. Mo ké gbàjarè sí Késárì!’”
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà níwájú aláṣẹ tí a yàn sípò, ó gbà pé Késárì ní ẹ̀tọ́ láti fìyà jẹ àwọn oníwà àìtọ́, kí ó tilẹ̀ pa wọ́n pàápàá. Kò sọ pé kí wọ́n má fìyà jẹ òun, bí òun bá jẹ̀bi. Ní àfikún sí i, kò sọ pé kìkì àwọn òṣìkàpànìyàn nìkan ni Késárì ní ẹ̀tọ́ láti fìyà ikú jẹ.
Òtítọ́ ni pé, ètò ìdájọ́ àwọn ará Róòmù kò pé pérépéré; bẹ́ẹ̀ náà sì ni ètò ilé ẹjọ́ ènìyàn lónìí. Àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ kan ni a ti dẹ́bi fún tí a sì ti fìyà jẹ, nígbà náà lọ́hùn-ún àti lóde òní. Pílátù pàápàá sọ nípa Jésù pé: “Èmi kò rí nǹkan kan nínú rẹ̀ tí ó yẹ fún ikú; nítorí náà dájúdájú èmi yóò nà án n óò sì tú u sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, bí aláṣẹ ìjọba náà tilẹ̀ gbà pé Jésù kò mọwọ́ mẹsẹ̀, a pa ọkùnrin aláìmọwọ́mẹsẹ̀ yí.—Lúùkù 23:22-25.
Irú àìṣèdájọ́ òdodo bẹ́ẹ̀ kò mú kí Pọ́ọ̀lù tàbí Pétérù jiyàn pé ìfìyà-ikú-jẹni jẹ́ ìwà búburú gbáà. Kàkà bẹ́ẹ̀, èrò Ọlọ́run lórí ọ̀ràn náà ni pé, níwọ̀n bí àwọn aláṣẹ onípò gíga ti Késárì bá ṣì wà, wọ́n ‘gbé idà láti fi ìrunú hàn jáde sí ẹni tí ń fi ohun tí ó burú ṣèwà hù.’ Ìyẹn sì kan lílo idà, ní èrò ìtumọ̀ fífi ìyà ikú jẹni. Ṣùgbọ́n, ní ti ìbéèrè aláwuyewuye ti bóyá ó yẹ kí ìjọba èyíkéyìí nínú ayé yìí lo ẹ̀tọ́ tí ó ní láti pa àwọn òṣìkàpànìyàn, àwọn ojúlówó Kristẹni ń lo ìṣọ́ra láti má ṣe dá sí tọ̀tún tòsì. Láìdà bí àwọn àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù, wọ́n ń yẹra fún ọ̀ràn iyàn jíjà èyíkéyìí lórí kókó yìí.