Ìyè Àìnípẹ̀kun Ha Ṣeé Ṣe Lóòótọ́ Bí?
“Olùkọ́, ohun rere wo ni mo gbọ́dọ̀ ṣe láti rí ìyè àìnípẹ̀kun?”—MÁTÍÙ 19:16.
1. Kí la lè sọ nípa bí ìwàláàyè ènìyàn ṣe kúrú tó?
SÁSÍTÀ Kìíní, Ọba Páṣíà, ẹni táa mọ̀ sí Ahasuwérúsì nínú Bíbélì, ń ṣàyẹ̀wò àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kí wọ́n tó lọ sójú ogun lọ́dún 480 ṣááju Sànmánì Tiwa. (Ẹ́sítérì 1:1, 2) Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn Herodotus, tí í ṣe ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì ti sọ, ọba náà dami lójú nígbà tó ń yẹ àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wọ̀nyí wò. Èé ṣe? Sásítà wí pé: “Nígbàkúùgbà tí mo bá ronú kan bí ìgbésí ayé ọmọ ẹ̀dá ti kúrú tó, ó máa ń dùn mí gan-an. Nítorí pé, tó bá fi máa tó ọgọ́rùn-ún ọdún sígbà táa wà yìí, kò síkan nínú gbogbo àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tó máa wà láàyè.” Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti ṣàkíyèsí pé ìwàláàyè ẹ̀dá kúrú jọjọ lọ́nà tí ń bani lọ́kàn jẹ́, ó sì ṣeé ṣe kóo ti kíyè sí i pẹ̀lú pé kò sẹ́ni tó fẹ́ darúgbó kùjọ́kùjọ́, kò sẹ́ni tó fẹ́ ṣàìsàn, kò sẹ́ni tó fẹ́ kú. Ẹ wo bí ì bá ti dára tó, ká ní a lè fi gbogbo sáà ìwàláàyè wa máa wà lọ́dọ̀ọ́, ká máa ta kébékébé, ká máa láyọ̀ nígbà gbogbo!—Jóòbù 14:1, 2.
2. Ìrètí wo ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní, èé sì ti ṣe?
2 Lọ́nà tó gba àfiyèsí, ìwé ìròyìn náà, The New York Times Magazine, ti September 28, 1997, gbé àpilẹ̀kọ kan jáde tó kà pé “Wọ́n Ò Fẹ́ Kú.” Ó fa ọ̀rọ̀ olùwádìí kan yọ, ẹni tó sọ pé: “Ó dá mi lójú gbangba pé ìran wa ni yóò jẹ́ àkọ́kọ́ tí yóò wà láàyè títí láé”! Bóyá ìwọ náà gbà gbọ́ pé ìyè àìnípẹ̀kun ṣeé ṣe. O lè gbà bẹ́ẹ̀ nítorí tí Bíbélì ṣèlérí pé a lè wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé níhìn-ín. (Sáàmù 37:29; Ìṣípayá 21:3, 4) Síbẹ̀, àwọn èèyàn kan gbà gbọ́ pé, yàtọ̀ sí àwọn ìdí tí a lè rí nínú Bíbélì tó fi hàn pé ìyè àìnípẹ̀kun ṣeé ṣe, àwọn ìdí mìíràn ń bẹ. Ṣíṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ìdí wọ̀nyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti gbà pé lóòótọ́, ìyè àìnípẹ̀kun ṣeé ṣe.
A Ṣẹ̀dá Wa Láti Wà Láàyè Títí Láé
3, 4. (a) Èé ṣe tí àwọn kan fi gbà gbọ́ pé ó yẹ kí a lè wà láàyè títí láé? (b) Kí ni Dáfídì sọ nípa bí a ṣe ṣẹ̀dá rẹ̀?
3 Ìdí kan tí ọ̀pọ̀ fi gbà gbọ́ pé ó yẹ kí àwa èèyàn lè wà láàyè títí láé ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀nà àgbàyanu tí a gbà ṣẹ̀dá wa. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀nà táa gbà ṣẹ̀dá wa nínú ọlẹ̀ inú ìyá wa yani lẹ́nu púpọ̀. Ọ̀gá àgbà kan nínú ìmọ̀ nípa ọjọ́ ogbó kọ̀wé pé: “Lẹ́yìn tí ọba adẹ́dàá ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tó gbé wa láti inú oyún dé ìgbà tí a bí wa, tó tún ṣe àwọn èyí tó gbé wa títí táa fi bàlágà, táa di géńdé, ó yàn láti má ṣe hùmọ̀ ohun ìyanu kékeré kan tí yóò jẹ́ kí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu wọ̀nyí máa bá a nìṣó títí láé.” Òótọ́ ni pé, báa bá ronú nípa ọ̀nà àgbàyanu tí a gbà dá wa, ìbéèrè náà yóò máa jà rànyìn lọ́kàn wa pé, Èé ṣe táa fi ń kú?
4 Ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, Dáfídì, ẹni tó kọ díẹ̀ lára Bíbélì ṣàṣàrò lórí àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò lè rí inú ọlẹ̀, bí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti lè rí i gan-an lóde òní. Dáfídì kọ háà nípa ọ̀nà tí a gbà dá òun alára, nígbà tó kọ̀wé pé, ‘a ti ya òun sọ́tọ̀ nínú ikùn ìyá òun.’ Ó wí pé, nígbà yẹn ni ‘a ṣe àwọn kíndìnrín òun.’ Ó tún sọ nípa báa ṣe ṣe “egungun” òun, nígbà tó sọ pé ‘a ṣẹ̀dá òun ní ìkọ̀kọ̀.’ Dáfídì tún sọ nípa “ọlẹ̀ mi,” nígbà tí ó sì ń sọ nípa ọlẹ̀ tó wà nínú ilé ọmọ ìyá rẹ̀, ó wí pé: “Gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀.”—Sáàmù 139:13-16.
5. Àwọn iṣẹ́ ìyanu wo ló wé mọ́ báa ṣe ṣẹ̀dá wa nínú ilé ọlẹ̀?
5 Lọ́nà tó ṣe kedere, kò sí àkọsílẹ̀ gidi kan tó ṣàlàyé bí Dáfídì yóò ṣe rí nínú ilé ọlẹ̀ ìyá rẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí Dáfídì ń ronú nípa báa ṣe ṣe “àwọn kíndìnrín” rẹ̀, “àwọn egungun” rẹ̀, àti àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ mìíràn, lójú tirẹ̀, ṣe ló dà bíi pé a ti wéwèé ọ̀nà tí àwọn nǹkan wọ̀nyí gbà ń dàgbà—bíi pé gbogbo rẹ̀, “wà ní àkọsílẹ̀” kan ní ti gidi. Ṣe ló dà bíi pé ẹyin tó fẹ́ra kù nínú ìyá rẹ̀ ní yàrá gbàràmù-gbaramu kan tí ìwé kún fọ́fọ́, tí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni lórí bí a ṣe lè ṣẹ̀dá ọmọ kékeré jòjòló kan sì wà nínú àwọn ìwé wọ̀nyí, tí a sì wá tàtaré ìsọfúnni dídíjú wọ̀nyí sí àwọn sẹ́ẹ̀lì mìíràn bí wọ́n ti ń jẹ yọ lọ́kọ̀ọ̀kan. Nípa báyìí, ìwé ìròyìn Science World lo àfiwé náà pé ‘ọ̀kọ̀ọ̀kan sẹ́ẹ̀lì tí ń bẹ nínú ọlẹ̀ tí ń dàgbà ló ní odindi àkójọ ìwé tó kún fún ìsọfúnni nípa bí ọmọ náà yóò ṣe rí.’
6. Gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ti kọ̀wé, ẹ̀rí wo ló wà pé, “a ṣẹ̀dá [wa] tìyanu-tìyanu”?
6 Ǹjẹ́ o tilẹ̀ ti fìgbà kan rí jókòó, kóo ronú nípa ọ̀nà àgbàyanu tí ara wa gbà ń ṣiṣẹ́? Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè, Jared Diamond, sọ pé: “Àwọn sẹ́ẹ̀lì tó tẹ́ inú ìfun máa ń pààrọ̀ ara wọn lẹ́ẹ̀kan láàárín ọjọ́ bíi mélòó kan, àwọn sẹ́ẹ̀lì tó tẹ́ inú àpò ìtọ̀ máa ń pààrọ̀ ara wọn lẹ́ẹ̀kan láàárín oṣù méjìméjì, ti àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa wa sì jẹ́ ẹ̀ẹ̀kan lóṣù mẹ́rinmẹ́rin.” Ìparí èrò tó dé ni pé: “Bí ọba adẹ́dàá ṣe ń tú ẹ̀yà ara wa palẹ̀ lójoojúmọ́, bẹ́ẹ̀ ló tún ń tò ó papọ̀.” Kí ni gbólóhùn yìí túmọ̀ sí? Ohun tó túmọ̀ sí ni pé, láìka iye ọdún tí a ti lò lórí ilẹ̀ alààyè yìí sí—ì báà jẹ́ ọdún mẹ́jọ, ọgọ́rin ọdún, kódà ká ti lo ẹgbẹ̀rin ọdún pàápàá—ṣe ló yẹ kára wa máa jà yọ̀yọ̀ bíi tọmọdé. Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan fojú díwọ̀n nígbà kan pé: “Láàárín ọdún kan, nǹkan bí ìpín méjìdínlọ́gọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ohun tín-ín-tìn-ìn-tín tó wà nínú ara wa ni àwọn ohun tín-ín-tìn-ìn-tín mìíràn máa ń rọ́pò, ìwọ̀nyí sì ń wọnú ara wa nípasẹ̀ atẹ́gùn táà ń mí símú, oúnjẹ táà ń jẹ, àti omi táà ń mu.” Lóòótọ́, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ti gbé Olúwa lárugẹ, “a ṣẹ̀dá [wa] tìyanu-tìyanu.”—Sáàmù 139:14.
7. Nípa báa ṣe ṣẹ̀dá ara wa, orí ìparí èrò wo làwọn kan ti dé?
7 Nígbà tí ògbógi kan nípa ọjọ́ ogbó ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà táa gbà ṣẹ̀dá ara wa, ó wí pé: “Ìdí tí ọjọ́ ogbó fi ń dé síni gan-an kò kúkú yéèyàn rárá.” Ká sòótọ́, ṣe ló dà bíi pé ká máa wà láàyè títí láé. Ìdí sì nìyẹn tí ènìyàn fi ń fẹ́ lo ìmọ̀ tí wọ́n ní nínú iṣẹ́ ẹ̀rọ láti lè lé góńgó yìí bá. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, Ọ̀mọ̀wé Alvin Silverstein fi ìdánilójú kọ ọ̀rọ̀ yìí sínú ìwé rẹ̀, Conquest of Death, ó ní: “A óò mú kí ìdí táa fi wà láàyè ṣe kedere. A óò mọ . . . ìdí tí èèyàn fi ń darúgbó.” Kí wá ni àbájáde rẹ̀ yóò jẹ́? Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Kò ní sí àwọn ‘arúgbó’ mọ́, torí pé ìmọ̀ tí yóò mú kí a lè ṣẹ́gun ikú yóò tún fún wa láǹfààní láti lè máa wà lọ́dọ̀ọ́ títí ayérayé.” Bí a bá ṣàgbéyẹ̀wò ìwádìí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lóde òní nípa ọ̀nà tí a gbà ṣẹ̀dá ènìyàn, èrò nípa ìyè àìnípẹ̀kun ha dà bí ohun kan tí kò ṣeé ṣe bí? Ìdí pàtàkì mìíràn pàápàá ṣì wà tí a fi lè gbà gbọ́ pé ìyè àìnípẹ̀kun ṣeé ṣe.
Ìfẹ́-Ọkàn Láti Wà Láàyè Títí Láé
8, 9. Ìfẹ́ àdámọ́ni wo ni àwọn èèyàn ti ní jálẹ̀ ìtàn?
8 Ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti ṣàkíyèsí pé ìfẹ́-ọkàn láti wà láàyè títí láé jẹ́ ohun táa dá mọ́ èèyàn? Nínú ìwé ìròyìn ilẹ̀ Germany kan, dókítà kan sọ pé: “Ó jọ pé látọjọ́ téèyàn ti dáyé ni èrò nípa ìyè àìnípẹ̀kun ti wà.” Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ àwọn ará Yúróòpù ìgbàanì kan, ìwé náà, The New Encyclopædia Britannica, sọ pé: “Àwọn èèyàn rere yóò wà láàyè títí láé nínú ilé ńlá tí ń dán gbinrin, ilé táa fi wúrà ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.” Áà, ẹ sì wá wo báwọn èèyàn ti rìn jìnnà tó nínú akitiyan wọn láti tẹ́ olórí ìfẹ́-ọkàn wọn yẹn lọ́rùn, ìyẹn ni ìfẹ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun!
9 Ìwé náà, The Encyclopedia Americana, sọ pé ní China, ní ohun tó ju ẹgbàá ọdún [2,000] sẹ́yìn, “tọba tìjòyè, lábẹ́ ìdarí àwọn abọrẹ̀ Tao, pa iṣẹ́ gidi tì, wọ́n ń wá oògùn àjídèwe kiri”—oògùn tí wọ́n sọ pé kì í jẹ́ kéèyàn ó darúgbó. Lóòótọ́, jálẹ̀ ìtàn, àwọn èèyàn ti gbà gbọ́ pé nípa fífi onírúurú àgbo wẹ̀, tàbí nípa mímu irú omi kan pàápàá, ó ṣeé ṣe kí wọn má darúgbó, kí wọ́n ṣì máa ta kébékébé.
10. Akitiyan wo làwọn èèyàn ti ṣe lóde òní láti lè mú kí ìwàláàyè gùn sí i?
10 Lọ́nà kan náà, akitiyan òde òní láti tẹ́ àìní tí a dá mọ́ ènìyàn lọ́rùn, ìyẹn ti ìyè àìnípẹ̀kun, kò kẹ̀rẹ̀ rárá. Àpẹẹrẹ pàtàkì kan ni ti gbígbé àwọn tí àìsàn kan bá pa sínú yìnyín. Ìrètí wọn fún ṣíṣe èyí ni pé wọ́n lè dá ẹ̀mí náà padà sí onítọ̀hún nínú lọ́jọ́ ọ̀la, nígbà tí wọ́n bá rí ẹ̀rọ̀ àìsàn tó pa á. Abẹnugan kan nínú ìṣègùn yìí, ìṣègùn táà ń pè ní sísọ òkú di yìnyín, kọ̀wé pé: “Bí nǹkan bá rí báa ti rò ó, tí a sì kọ́ báa ṣe lè wo àrùn náà sàn tàbí báa ṣe lè tún àwọn ẹ̀yà tó bà jẹ́ ṣe—títí kan ìṣòro ọjọ́ ogbó pàápàá—nígbà náà yóò ṣeé ṣe kí àwọn tí wọ́n ti ‘kú’ nísinsìnyí wà láàyè títí kánrin lọ́jọ́ ọ̀la.”
11. Èé ṣe tí àwọn ènìyàn fi ń fẹ́ láti wà láàyè títí láé?
11 O lè béèrè pé, kí ló fà á tí ìfẹ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun yìí fi jinlẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ nínú wa? Ó ha jẹ́ nítorí pé “[Ọlọ́run] ti fi ayérayé sínú ìrònú ènìyàn”? (Oníwàásù 3:11, Revised Standard Version) Ọ̀ràn yìí gba àròjinlẹ̀ gidigidi! Tiẹ̀ rò ó wò ná: Èé ṣe tí a óò fi ní ìfẹ́ àdámọ́ni láti wà láàyè títí ayérayé—àní títí láé—bí kò bá jẹ́ pé Ẹlẹ́dàá wa ní in lọ́kàn pé kí a tẹ́ ìfẹ́ yẹn lọ́rùn? Ǹjẹ́ a lè sọ pé ó nífẹ̀ẹ́ wa tó bá jẹ́ pé ó dá ìfẹ́ láti wà láàyè títí láé mọ́ wa, tó sì wá já wa kulẹ̀ nípa ṣíṣàì jẹ́ kí a lè mú ìfẹ́ náà ṣẹ bí?—Sáàmù 145:16.
Ta Ló Yẹ Ká Gbẹ́kẹ̀ Lé?
12. Ìgbọ́kànlé wo ni àwọn kan ní, ṣùgbọ́n, ṣé o gbà pé ó fìdí múlẹ̀ dáradára?
12 Níbo ló yẹ ká fi ìgbẹ́kẹ̀lé wa sí láti lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun, tàbí ká sọ ọ́ lédè mìíràn, ta ló yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé? Ṣé ìmọ̀ ẹ̀rọ tí ẹ̀dá ènìyàn ṣàwárí ní ọ̀rúndún ogún tàbí ọ̀rúndún kọkànlélógún ni? Àpilẹ̀kọ tó wà nínú ìwé ìròyìn, The New York Times Magazine, èyí tó sọ pé, “Wọn Ò Fẹ́ Kú,” sọ nípa “òrìṣà àkúnlẹ̀bọ náà: ìmọ̀ ẹ̀rọ,” ó tún sọ nípa “ìtara tí àwọn ènìyàn ní fún agbára tí ìmọ̀ ẹ̀rọ ní.” A tilẹ̀ gbọ́ pé olùwádìí kan “ní ìdánilójú gbangba . . . pé tó bá ṣe díẹ̀ sí i, yóò ṣeé ṣe láti máa fọgbọ́n ìmọ̀ ẹ̀rọ darí apilẹ̀ àbùdá èyí tí yóò lè fòpin sí ọjọ́ ogbó, tàbí tí kò ní jẹ́ kó nípa lórí aráyé mọ́.” Àmọ́ ṣá o, ó ti wá hàn gbangba pé gbogbo ìsapá ènìyàn láti fòpin sí ọjọ́ ogbó tàbí láti ṣẹ́gun ikú ti já sí òtúbáńtẹ́ pátápátá.
13. Báwo ni ọ̀nà tí a gbà ṣètò ọpọlọ wa ṣe fi hàn pé ṣe ni a dá wa láti wà láàyè títí láé?
13 Èyí ha túmọ̀ sí pé kò sí ọ̀nà àtijèrè ìyè àìnípẹ̀kun? Rárá o! Ọ̀nà àtijèrè rẹ̀ ń bẹ dáadáa! Ọ̀nà tí a gbà ṣètò ọpọlọ wa, pẹ̀lú agbára tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ àìlópin tó ní láti kọ́ nǹkan yẹ kí ó mú èyí dá wa lójú. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè tín-ín-tìn-ìn-tín, James Watson, pe ọpọlọ wa ní “ohun tó díjú jù lọ tí a tí ì ṣàwárí ní gbogbo àgbáyé wa.” Onímọ̀ nípa ètò àti àrùn iṣan ara, Richard Restak, wí pé: “Kò sí ibì kankan lágbàáyé tí a ti lè rí aláfijọ rẹ̀.” Bó bá jẹ́ pé a kò dá wa láti gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun, kí la wá ní ọpọlọ tó lágbára láti kó ìsọfúnni tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ aláìlópin pamọ́ fún, ọpọlọ tó jẹ́ pé ó lè lo gbogbo ìsọfúnni yìí, tí a sì tún wá ní ara tí a dá láti lè máa ṣíṣẹ lọ títí láé?
14. (a) Ìparí èrò wo nípa ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn ni àwọn tó kọ Bíbélì tọ́ka sí? (b) Èé ṣe tó fi yẹ ká fi ìgbẹ́kẹ̀lé wa sínú Ọlọ́run, ká má ṣe fi sínú ènìyàn?
14 Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí wá ni ìparí èrò kan ṣoṣo tó bọ́gbọ́n mu, tó sì múná dóko tí a gbọ́dọ̀ dé? Kò ha yẹ kó jẹ́ ìparí èrò náà pé Adẹ́dàá kan, tó jẹ́ alágbára gbogbo, tí òye rẹ̀ kò sì láfiwé, ló mọ wá, tó sì dá wa kí a bàa lè wà láàyè títí láé? (Jóòbù 10:8; Sáàmù 36:9; 100:3; Málákì 2:10; Ìṣe 17:24, 25) Nítorí náà, kò ha yẹ kí ọgbọ́n sún wa láti kọbi ara sí àṣẹ onímìísí ti onísáàmù inú Bíbélì náà pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀”? Èé ṣe tí kò fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ léèyàn? Nítorí, gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà ti kọ̀wé, “ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.” Ní tòótọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a dá agbára láti lè wà láàyè títí láé mọ́ wa, èèyàn ò lágbára kankan tó lè sà bíkú bá dé. Onísáàmù náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí . . . ìrètí rẹ̀ ń bẹ nínú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.”—Sáàmù 146:3-5.
Ṣé Ète Ọlọ́run Ni Lóòótọ́?
15. Kí ló fi hàn pé ète Ọlọ́run ni pé ká wà láàyè títí láé?
15 Ṣùgbọ́n, o lè béèrè pé, Ṣé ète Jèhófà ni lóòótọ́ pé ká gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun? Bẹ́ẹ̀ ni, ète rẹ̀ nìyẹn! Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìgbà ni Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣèlérí rẹ̀. Bíbélì mú un dá wa lójú pé: “Ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun.” Jòhánù, ìránṣẹ́ Ọlọ́run kọ̀wé pé: “Èyí ni ohun ìlérí tí [Ọlọ́run] fúnra rẹ̀ ṣèlérí fún wa, ìyè àìnípẹ̀kun.” Abájọ tí ọ̀dọ́mọkùnrin kan fi béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Olùkọ́, ohun rere wo ni mo gbọ́dọ̀ ṣe láti rí ìyè àìnípẹ̀kun?” (Róòmù 6:23; 1 Jòhánù 2:25; Mátíù 19:16) Àní, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa “ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí kò lè purọ́, ti ṣèlérí tipẹ́tipẹ́.”—Títù 1:2.
16. Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run ti lè gbà ṣèlérí ìyè àìnípẹ̀kun “tipẹ́tipẹ́”?
16 Kí ló túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ṣèlérí ìyè àìnípẹ̀kun “tipẹ́tipẹ́”? Àwọn kan rò pé ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé ṣáájú kí a tó dá tọkọtaya àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, ni Ọlọ́run ti pète pé kí àwọn ẹ̀dá ènìyàn wà láàyè títí láé. Bó ti wù kó rí, bó bá jẹ́ pé àkókò kan lẹ́yìn tí a ti dá ènìyàn tán, nígbà tí Jèhófà sọ ète rẹ̀, ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí, síbẹ̀síbẹ̀ ó ṣe kedere nígbà náà pé ìfẹ́ Ọlọ́run wé mọ́ ìyè àìnípẹ̀kun fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn.
17. Èé ṣe tí a fi lé Ádámù àti Éfà jáde nínú ọgbà Édẹ́nì, èé sì ti ṣe tí a fi fàwọn kérúbù sẹ́nu ọ̀nà?
17 Bíbélì sọ pé nínú ọgbà Édẹ́nì, ‘Jèhófà Ọlọ́run mú kí igi ìyè hù láti inú ilẹ̀.’ Ìdí rẹ̀ tí a fi lé Ádámù jáde nínú ọgbà náà ni pé “kí ó má bàa na ọwọ́ rẹ̀ jáde, kí ó sì tún mú èso ní ti tòótọ́, láti ara igi ìyè, kí ó sì jẹ kí ó sì wà láàyè”—bẹ́ẹ̀ ni, kí ó sì wà láàyè títí láé! Lẹ́yìn tí Jèhófà ti lé Ádámù àti Éfà dànù nínú ọgbà Édẹ́nì, ló bá fi “àwọn kérúbù . . . àti abẹ idà tí ń jó lala, tí ń yí ara rẹ̀ láìdáwọ́ dúró” síbẹ̀ “láti máa ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ síbi igi ìyè náà.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:9; 3:22-24.
18. (a) Kí ni jíjẹ èso igi ìyè náà yóò túmọ̀ sí fún Ádámù àti Éfà? (b) Kí ni jíjẹ èso igi náà dúró fún?
18 Ká ní a ti lọ gba Ádámù àti Éfà láyè láti jẹ nínú igi ìyè yẹn ni, kí ni ìyẹn ì bá ti túmọ̀ sí fún wọn? Họ́wù, àǹfààní wíwà láàyè títí láé nínú Párádísè ì bá kàn tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ lọ́fẹ̀ẹ́ lófò ni! Ọ̀mọ̀wé kan tí ó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nínú Bíbélì ronú lọ́nà yìí, ó ní: “Àfàìmọ̀ ni igi ìyè náà kò ní agbára kíkàmàmà kan èyí tó lè gba ara ènìyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ hẹ́gẹhẹ̀gẹ tí ọjọ́ ogbó ń sọni dà, tàbí kó jẹ́ pé ó lè gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ kùjọ́kùjọ́ tí ń yọrí sí ikú lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.” Ó tilẹ̀ sọ pé “egbòogi ajẹ́bíidán kan ń bẹ nínú párádísè náà tó lágbára láti mú gbogbo ohun tí ọjọ́ ogbó ń fà kúrò.” Àmọ́ ṣá o, Bíbélì kò sọ pé igi ìyè náà fúnra rẹ̀ ní agbára tí ń fúnni ní ìyè. Kàkà bẹ́ẹ̀, igi ìyè yẹn dúró fún ìdánilójú tí Ọlọ́run fún àwọn tó bá yọ̀ǹda fún láti jẹ nínú èso igi náà pé ìyè àìnípẹ̀kun yóò jẹ́ tiwọn.—Ìṣípayá 2:7.
Ète Ọlọ́run Kò Yí Padà
19. Èé ṣe tí Ádámù fi kú, èé sì ti ṣe tí àwa pẹ̀lú táa jẹ́ àtọmọdọ́mọ rẹ̀ pẹ̀lú fi ń kú?
19 Nígbà tí Ádámù ṣẹ̀, ó pàdánù ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti wà láàyè títí láé, ó tún pàdánù irú ẹ̀tọ́ náà tí gbogbo àtọmọdọ́mọ rẹ̀ tí kò tí ì bí yóò ní. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Nígbà tó di ẹlẹ́ṣẹ̀ nítorí àìgbọràn rẹ̀, ó di alábààwọ́n, ó di aláìpé. Láti ìgbà yẹn lọ, ara Ádámù di èyí tí ó gbọ́dọ̀ kú. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì sì ti sọ, “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” (Róòmù 6:23) Kò tán síbẹ̀ yẹn o, àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù pẹ̀lú, tí àwọn náà jẹ́ aláìpé tún di ẹni tó lè kú, wọn kì í ṣe ẹni tó lè wà láàyè títí láé. Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan [Ádámù] wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”—Róòmù 5:12.
20. Kí ló fi hàn pé a dá ènìyàn láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé?
20 Ṣùgbọ́n o, ká ní Ádámù ò dẹ́ṣẹ̀ ńkọ́? Ká ní kò ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run ńkọ́, tó sì ti yọ̀ǹda fún un láti jẹ nínú èso igi ìyè náà? Ibo ni ì bá ti gbádùn ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun tó wà lọ́wọ́ Ọlọ́run? Ṣé lájùlé ọ̀run ni? Rárá o! Ọlọ́run kò sọ ohunkóhun nípa mímú Ádámù lọ sọ́run. Orí ilẹ̀ ayé níhìn-ín ni iṣẹ́ táa yàn fún un wà. Bíbélì ṣàlàyé pé “Jèhófà Ọlọ́run mú kí olúkúlùkù igi tí ó fani mọ́ra ní wíwò, tí ó sì dára fún oúnjẹ hù láti inú ilẹ̀,” ó sọ síwájú sí i pé: “Jèhófà Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti mú ọkùnrin náà, ó sì mú un tẹ̀ dó sínú ọgbà Édẹ́nì láti máa ro ó àti láti máa bójú tó o.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:9, 15) Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá Éfà fún Ádámù, kó lè máa ṣe aya rẹ̀, àwọn méjèèjì ló fún ní àfikún iṣẹ́ lórí ilẹ̀ ayé níhìn-ín. Ọlọ́run wí fún wọn pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.
21. Ìfojúsọ́nà àgbàyanu wo ni àwọn ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ ní?
21 Fojú inú wo ìrètí àgbàyanu orí ilẹ̀ ayé tí àwọn ìtọ́ni wọnnì láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ṣí sílẹ̀ fún Ádámù àti Éfà! Wọ́n láǹfààní láti tọ́ àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹni pípé, tí ara wọn tún jí pépé dàgbà nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Bí àwọn ọmọ wọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ gidigidi yìí ti ń dàgbà, àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú yóò máa bá wọn lọ́wọ́ nínú síso èso àti nínú ṣíṣe iṣẹ́ aláyọ̀ nínú ọgbà náà láti bàa lè mú kí ẹwà Párádísè náà máa pọ̀ sí i. Ìgbà tó sì jẹ́ pé gbogbo ẹranko pátá ni yóò wà lábẹ́ wọn, èyí ì bá tẹ́ aráyé lọ́rùn gidigidi. Ronú nípa ayọ̀ mímú kí àwọn ààlà ọgbà Édẹ́nì gbòòrò sí i, kó bàa lè jẹ́ pé ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ gbogbo ilẹ̀ ayé ni yóò jẹ́ párádísè! Ǹjẹ́ o kò ní fẹ́ láti gbádùn ìwàláàyè pípé nínú irú ilé ẹlẹ́wà bẹ́ẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, láìsí pé ò ń ṣàníyàn nípa dídarúgbó tàbí kíkú? Jọ̀wọ́ dáhùn ìbéèrè yẹn nínú ọkàn rẹ.
22. Èé ṣe tí a fi lè ní ìdánilójú pé Ọlọ́run kò yí ète rẹ̀ fún ilẹ̀ ayé padà?
22 Ó dáa, nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn, tí a sì lé wọn kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì, ǹjẹ́ Ọlọ́run yí ète rẹ̀ fún ẹ̀dá ènìyàn láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé padà bí? Rárá o! Bí Ọlọ́run bá lọ ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ́rẹ́n, ṣe ló máa dà bí ẹni pé ó gbà pé òun kò fẹ̀ẹ̀kan lágbára láti mú ète tí òun ní nípilẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ. Ẹ jẹ́ ká ní ìdánilójú pé awíbẹ́ẹ̀-ṣebẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí òun alára ti kéde pé: “Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde yóò já sí. Kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.”—Aísáyà 55:11.
23. (a) Kí ló jẹ́ kó túbọ̀ dáni lójú pé ète Ọlọ́run ni pé kí àwọn èèyàn olódodo máa wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé? (b) Kí la óò jíròrò tẹ̀ lé èyí?
23 Bíbélì mú un ṣe kedere pé ète Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé kò yí padà, Ọlọ́run ṣèlérí nínú rẹ̀ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, Wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” Kódà Jésù Kristi sọ ọ́ nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè pé, àwọn ọlọ́kàntútù ni yóò jogún ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:29; Mátíù 5:5) Síbẹ̀, báwo ni ọwọ́ wa ṣe lè tẹ ìyè àìnípẹ̀kun, kí la sì gbọ́dọ̀ ṣe láti gbádùn irú ìwàláàyè bẹ́ẹ̀? A óò jíròrò èyí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
◻ Èé ṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi gbà gbọ́ pè ìyè àìnípẹ̀kun ṣeé ṣe?
◻ Kí ló mú kí a ní ìdánilójú pé a dá wa láti wà láàyè títí láé?
◻ Kí ni ète Ọlọ́run ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún aráyé àti ilẹ̀ ayé?
◻ Èé ṣe tí a fi lè ní ìdálójú pé Ọlọ́run yóò mú ète rẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ?