Jóòbù
10 “Mo* kórìíra ayé mi gidigidi.+
Mi ò ní pa bó ṣe ń ṣe mi mọ́ra.
Màá sọ̀rọ̀ látinú ẹ̀dùn ọkàn* tó bá mi!
2 Màá sọ fún Ọlọ́run pé: ‘Má ṣe dá mi lẹ́bi.
Jẹ́ kí n mọ ìdí tí o fi ń bá mi jà.
3 Ṣé ó máa ṣe ọ́ láǹfààní tí o bá fìyà jẹni,
Tí o bá kórìíra iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,+
Tí o sì fara mọ́ ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú?
4 Ṣé ojú rẹ dà bíi ti èèyàn ni,
Àbí o máa ń wo nǹkan bíi ti ẹni kíkú?
5 Ṣé bí ọjọ́ àwọn ẹni kíkú ni àwọn ọjọ́ rẹ rí,
Àbí àwọn ọdún rẹ dà bíi ti èèyàn,+
6 Tí o fi ń wá àṣìṣe mi,
Tí o sì ń wá ẹ̀ṣẹ̀ mi?+
8 Ọwọ́ rẹ lo fi mọ mí tí o sì fi dá mi,+
Àmọ́ ní báyìí, o fẹ́ pa mí run pátápátá.
10 Ṣebí o dà mí jáde bíi wàrà
Tí o sì mú kí n dì bíi wàràkàṣì?
11 O fi awọ àti ẹran bò mí,
O sì fi egungun àti iṣan hun mí pọ̀.+
13 Àmọ́ o gbèrò ní bòókẹ́lẹ́ láti ṣe àwọn nǹkan yìí.*
Mo mọ̀ pé ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn nǹkan yìí ti wá.
14 Tí mo bá ṣẹ̀, o máa ṣọ́ mi,+
O ò sì ní dá mi láre.
15 Tí mo bá jẹ̀bi, mo gbé!
16 Tí mo bá gbé orí mi sókè, o máa dọdẹ mi bíi ti kìnnìún,+
O sì tún máa fi agbára rẹ bá mi jà.
17 O mú àwọn ẹlẹ́rìí míì wá láti ta kò mí,
O sì túbọ̀ bínú sí mi,
Bí mo ṣe ń tinú ìnira kan bọ́ sínú ìnira míì.
18 Torí náà, kí ló dé tí o mú mi jáde látinú ikùn?+
Ó yẹ kí n ti kú kí ojú kankan tó rí mi.
19 Ṣe ni ì bá dà bíi pé mi ò gbé ayé rí;
Mi ò bá kàn ti inú ikùn lọ sí sàréè.’