Ẹ̀mí Ń Jẹ́rìí Pẹ̀lú Ẹ̀mí Wa
“Ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wa pé àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run.”—RÓÒMÙ 8:16.
1-3. Kí ló mú kí ọjọ́ àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ṣàrà ọ̀tọ̀, báwo sì làwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ náà ṣe mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ ṣẹ? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
ỌJỌ́ pàtàkì lọjọ́ àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ti ọdún 33 tó wáyé nílùú Jerúsálẹ́mù. Ọjọ́ Sunday ni àjọyọ̀ yìí bọ́ sí. Inú gbogbo èèyàn ń dùn lọ́jọ́ náà bí wọ́n ti ń ṣe àjọyọ̀ tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún wọn pé kí wọ́n máa ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè àlìkámà. Láàárọ̀ ọjọ́ náà, àlùfáà àgbà rú àwọn ẹbọ tó yẹ kó rú nínú tẹ́ńpìlì. Nígbà tó sì di nǹkan bí aago mẹ́sàn-án ó fi ìṣù búrẹ́dì méjì tó ní ìwúkàrà tí a fi àkọ́so ìkórè àlìkámà ṣe rúbọ sí Ọlọ́run. Àlùfáà àgbà fi àwọn ìṣù búrẹ́dì náà sọ́tùn-ún sósì kó lè fi wọ́n rúbọ sí Jèhófà.—Léfítíkù 23:15-20.
2 Láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn ni àlùfáà àgbà ti máa ń rú ọrẹ ẹbọ fífì yìí lọ́dọọdún. Ọrẹ ẹbọ yìí ní í ṣe pẹ̀lú ohun pàtàkì kan tó ṣẹlẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33. Ohun pàtàkì yìí sì ṣẹlẹ̀ sí ọgọ́fà [120] lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù nígbà tí gbogbo wọn ń gbàdúrà pa pọ̀ ní yàrá òkè ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 1:13-15) Ẹgbẹ̀rin [800] ọdún ṣáájú ìgbà yẹn ni wòlíì Jóẹ́lì ti sàsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí. (Jóẹ́lì 2:28-32; Ìṣe 2:16-21) Kí lohun pàtàkì tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ náà?
3 Ka Ìṣe 2:2-4. Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33, Ọlọ́run fún àwọn Kristẹni yẹn ní ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì di ẹni àmì òróró. (Ìṣe 1:8) Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn èrò yí wọn ká, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn ohun àgbàyanu tí wọ́n ti rí tí wọ́n sì ti gbọ́. Àpọ́sítélì Pétérù ṣàlàyé ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ tán fún wọn, ó sì tún sọ ìdì tó fi ṣe pàtàkì gan-an. Ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ ronú pìwà dà, kí a sì batisí olúkúlùkù yín ní orúkọ Jésù Kristi fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ ó sì gba ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ẹ̀mí mímọ́.” Lọ́jọ́ yẹn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta èèyàn ló ṣe batisí, Ọlọ́run sì fún àwọn náà ní ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́.—Ìṣe 2:37, 38, 41.
4. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká ka ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì sí pàtàkì? (b) Ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì míì tó wáyé ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn wo ló ṣeé ṣe kó bọ́ sí ọjọ́ kan náà tí wọ́n ń ṣe àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì? (Wo àfikún àlàyé.)
4 Kí ni àlùfáà àgbà àti ọrẹ ẹbọ tó máa ń rú ní gbogbo Pẹ́ńtíkọ́sì dúró fún? Àlùfáà àgbà dúró fún Jésù. Àwọn ìṣù búrẹ́dì náà dúró fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn. Láàárín aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni Jèhófà ti yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà, àwọn sì ni Bíbélì pè ní “àkọ́so.” (Jákọ́bù 1:18) Ọlọ́run gbà wọ́n ṣọmọ, ó sì yàn wọ́n láti bá Jésù jọba ní ọ̀run nínú Ìjọba Rẹ̀. (1 Pétérù 2:9) Ìjọba yìí ni Jèhófà máa lò láti bù kún àwọn èèyàn tó bá jẹ́ onígbọràn. Torí náà, àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 ṣe pàtàkì gan-an sí gbogbo wa, yálà a wà lára àwọn tó máa bá Jésù jọba lọ́run tàbí a jẹ́ ara àwọn tó máa gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.[1] —Wo àfikún àlàyé.
BÁWO LÓ ṢE MÁA Ń RÍ TẸ́NÌ KAN BÁ DI ẸNI ÀMÌ ÒRÓRÓ?
5. Báwo la ṣe mọ̀ pé kì í ṣe ọ̀nà kan náà ni Jèhófà gbà fẹ̀mí yan gbogbo àwọn ẹni àmì òróró?
5 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà ní yàrá òkè ò jẹ́ gbàgbé ọjọ́ náà. Ohun kan tó dà bí iná yọ sórí olúkúlùkù wọn. Jèhófà fún wọn lágbára láti fi ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀. Èyí mú kó dá gbogbo wọn lójú pé Ọlọ́run ti fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n. (Ìṣe 2:6-12) Àmọ́, àwọn ohun àrà ọ̀tọ̀ yìí kì í ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn Kristẹni tó di ẹni àmì òróró lẹ́yìn náà. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì ò sọ pé ohun kan tó dà bí iná yọ sórí àwọn ẹgbẹ̀rún mélòó kan tí Jèhófà tún fẹ̀mí yàn ní Jerúsálẹ́mù lọ́jọ́ náà. Ìgbà tí wọ́n ṣe batisí ni Jèhófà fẹ̀mí yàn wọ́n. (Ìṣe 2:38) Bákan náà, kì í ṣe gbogbo àwọn Kristẹni tó di ẹni àmì òróró ló jẹ́ pé ìgbà tí wọ́n ṣe batisí ni Jèhófà fẹ̀mí yàn wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí àwọn ará Samáríà ṣe batisí ni Jèhófà tó fẹ̀mí yàn wọ́n. (Ìṣe 8:14-17) Ti Kọ̀nílíù àtàwọn ará ilé ẹ̀ tiẹ̀ tún wá yàtọ̀, kí wọ́n tó ṣe batisí ni Jèhófà ti fẹ̀mí yàn wọ́n.—Ìṣe 10:44-48.
6. Kí ni Jèhófà fún gbogbo àwọn ẹni àmì òróró, kí lèyí sì mú kó dá wọn lójú?
6 Ó ṣe kedere pé kì í ṣe ọ̀nà kan náà ni gbogbo àwọn ẹni àmì òróró gbà mọ̀ pé Jèhófà ti fẹ̀mí yàn wọ́n. Ó lè jẹ́ pé gbàrà tí Jèhófà fẹ̀mí yan àwọn kan lára wọn ni wọ́n ti mọ̀ pé Jèhófà ti fẹ̀mí yan àwọn. Ó sì lè ṣe díẹ̀ káwọn míì tó mọ̀. Àmọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Ó ní: “Nípasẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú, lẹ́yìn tí ẹ gbà gbọ́, a fi èdìdì dì yín pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́ tí a ṣèlérí, èyí tí ó jẹ́ àmì ìdánilójú ṣáájú ogún wa.” (Éfésù 1:13, 14) Torí náà, ẹ̀mí mímọ́ ni Jèhófà ń lò láti mú kó ṣe kedere sí àwọn Kristẹni yìí pé òun ti yàn wọ́n láti lọ sọ́run. Lọ́nà yìí, ẹ̀mí mímọ́ ni “àmì ìdánilójú ṣáájú” tàbí ẹ̀rí tó ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé, lọ́jọ́ iwájú, ọ̀run ni wọ́n á máa gbé títí láé, kì í ṣe orí ilẹ̀ ayé.—Ka 2 Kọ́ríńtì 1:21, 22; 5:5.
Ẹni àmì òróró kankan ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun ṣí òun lọ́wọ́ sísin Jèhófà
7. Kí ni olúkúlùkù ẹni àmì òróró gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n tó lè gba èrè wọn ní ọ̀run?
7 Tí Jèhófà bá ti fẹ̀mí yan ẹnì kan, ṣé ó ti wá dájú pé onítọ̀hún máa gba èrè rẹ̀ nìyẹn? Rárá. Ṣe nìyẹn wulẹ̀ mú kó dá a lójú pé Jèhófà ti pè é láti wá bá Jésù jọba lọ́run. Àmọ́, tó bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀ nìkan ló máa gba èrè yìí. Pétérù ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà yìí, ó ní: “Fún ìdí yìí, ẹ̀yin ará, ẹ túbọ̀ máa sa gbogbo ipá yín láti mú pípè àti yíyàn yín dájú fún ara yín; nítorí bí ẹ bá ń bá a nìṣó ní ṣíṣe nǹkan wọ̀nyí, ẹ kì yóò kùnà lọ́nàkọnà láé. Ní ti tòótọ́, nípa báyìí ni a ó pèsè ìwọlé fún yín lọ́pọ̀ jaburata sínú ìjọba àìnípẹ̀kun ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi.” (2 Pétérù 1:10, 11) Torí náà, ẹni àmì òróró kankan ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun ṣí òun lọ́wọ́ sísin Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti pè é tàbí yàn án láti lọ sọ́run, tí kò bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀, kò ní gba èrè kankan.—Hébérù 3:1; Ìṣípayá 2:10.
BÁWO LẸNÌ KAN ṢE MÁA MỌ̀ PÉ JÈHÓFÀ TI FẸ̀MÍ YAN ÒUN?
8, 9. (a) Kí nìdí tó fi ṣòro fún ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn láti mọ bó ṣe máa ń rí tẹ́nì kan bá di ẹni àmì òróró? (b) Báwo lẹnì kan ṣe máa mọ̀ pé Jèhófà ti yan òun láti lọ sọ́run?
8 Ó lè ṣòro fún ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láti lóye bó ṣe máa ń rí tí Ọlọ́run bá fẹ̀mí yan ẹnì kan. Bó sì ṣe yẹ kó rí nìyẹn, torí pé Ọlọ́run ò tíì fẹ̀mí yan àwọn fúnra wọn. Orí ilẹ̀ ayé yìí ni Ọlọ́run dá káwa èèyàn lè máa gbé títí láé lórí rẹ̀, kì í ṣe ọ̀run. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; Sáàmù 37:29) Àmọ́, Jèhófà ti yan àwọn kan láti jẹ́ ọba àti àlùfáà lọ́run. Torí náà, nígbà tí Jèhófà fẹ̀mí yàn wọ́n, ìrètí wọn àti bí wọ́n ṣe ń ronú yí pa dà, tó fi jẹ́ pé ọ̀run ni wọ́n ń retí láti gbé.—Ka Éfésù 1:18.
9 Àmọ́ báwo lẹnì kan á ṣe mọ̀ pé Jèhófà ti yan òun láti lọ sọ́run? Gbọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ẹni àmì òróró tó wà ní Róòmù, ìyẹn àwọn “tí a pè láti jẹ́ ẹni mímọ́.” Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé: “Ẹ kò gba ẹ̀mí ìsìnrú tí ó tún ń fa ìbẹ̀rù, ṣùgbọ́n ẹ̀yin gba ẹ̀mí ìsọdọmọ, ẹ̀mí tí ń mú kí a ké jáde pé: ‘Ábà, Baba!’ Ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wa pé àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 1:7; 8:15, 16) Ọlọ́run ló ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ mú kó dá ẹnì kan lójú pé òun ti yàn án láti wá bá Jésù jọba lọ́run.—1 Tẹsalóníkà 2:12.
10. Kí lohun tó wà nínú 1 Jòhánù 2:27 pé ẹni àmì òróró kan ò nílò kí ẹnì kan ṣẹ̀ṣẹ̀ máa kọ́ ọ túmọ̀ sí?
10 Àwọn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn ò nílò kẹ́nì kan ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ fún wọn pé Ọlọ́run ti yàn wọ́n. Jèhófà ló ń mú kó dá wọn lójú. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé: ‘Ẹ ní ìfòróróyàn láti ọ̀dọ̀ ẹni mímọ́ náà; gbogbo yín ní ìmọ̀. Ní tiyín, ìfòróróyàn tí ẹ gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ dúró nínú yín, ẹ kò sì nílò ẹnikẹ́ni láti máa kọ́ yín; ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ìfòróróyàn náà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ti ń kọ́ yín nípa ohun gbogbo, tí ó sì jẹ́ òótọ́, tí kì í sì í ṣe irọ́, àti pé gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ yín, ẹ dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.’ (1 Jòhánù 2:20, 27) Àwọn ẹni àmì òróró náà ní láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà bíi tàwa tó kù. Àmọ́, kò dìgbà tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún wọn kí wọ́n tó mọ̀ pé Jèhófà ti fẹ̀mí yan àwọn. Jèhófà fúnra rẹ̀ ti fi ẹ̀rí tó lágbára jù lọ, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, mú kó ṣe kedere sí wọn pé ẹni àmì òróró ni wọ́n!
WỌ́N TI DI ÀTÚNBÍ
11, 12. Kí ló lè máa ṣe ẹni àmì òróró kan ní kàyéfì, àmọ́ kí ni kò jẹ́ ṣiyè méjì lé lórí?
11 Nígbà tí Jèhófà bá fẹ̀mí yan àwọn Kristẹni, ìyípadà tó wáyé náà máa ń pọ̀ gan-an. Kódà, Jésù sọ pé a ti “tún” wọn “bí” tàbí lédè míì, “a ti bí wọn láti òkè wá.” (Jòhánù 3:3, 5) Jésù wá ṣàlàyé pé: “Kí ẹnu má ṣe yà ọ́ nítorí mo sọ fún ọ pé, A gbọ́dọ̀ tún yín bí. Ẹ̀fúùfù ń fẹ́ síbi tí ó wù ú, ìwọ sì ń gbọ́ ìró rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ kò mọ ibi tí ó ti wá àti ibi tí ó ń lọ. Bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí a ti bí láti inú ẹ̀mí.” (Jòhánù 3:7, 8) Ó ṣe kedere nígbà náà pé kò sí bí ẹni àmì òróró kan ṣe lè ṣàlàyé bó ṣe máa ń rí tẹ́nì kan bá di ẹni àmì òróró fún ẹni tí kì í ṣe ẹni àmì òróró kó sì yé e.[2]—Wo àfikún àlàyé.
Ẹni tí Ọlọ́run ti fẹ̀mí yàn láti lọ sọ́run kì í ṣiyè méjì bóyá Jèhófà ti yan òun
12 Ẹnì kan tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn lè máa ronú pé, ‘Ó ṣe jẹ́ èmi ni Jèhófà yàn?’ Ó tiẹ̀ lè máa ronú pé ṣé irú òun yìí ni irú àǹfààní bẹ́ẹ̀ tọ́ sí ṣá. Àmọ́, kò jẹ́ ṣiyè méjì láé pé bóyá Jèhófà yan òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú ẹ̀ á dùn gan-an, á sì mọyì irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀. Bọ́rọ̀ ṣe rí lára Pétérù náà ló rí lára gbogbo àwọn ẹni àmì òróró. Àpọ́sítélì Pétérù ní: “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi, nítorí ní ìbámu pẹ̀lú àánú ńlá rẹ̀, ó fún wa ní ìbí tuntun sí ìrètí tí ó wà láàyè nípasẹ̀ àjíǹde Jésù Kristi kúrò nínú òkú, sí ogún tí ó jẹ́ aláìlè-díbàjẹ́ àti aláìlẹ́gbin àti aláìlèṣá. A fi í pa mọ́ ní ọ̀run de ẹ̀yin.” (1 Pétérù 1:3, 4) Bí àwọn ẹni àmì òróró bá ń ka ibí yìí, wọ́n á mọ̀ dájú pé àwọn ni Jèhófà Baba wọn ń bá sọ̀rọ̀ níbí yìí.
13. Báwo ni ìrònú ẹnì kan ṣe máa ń yí pa dà nígbà tí Ọlọ́run bá fi ẹ̀mí mímọ́ yàn án, kí ló sì fà á?
13 Kí Jèhófà tó fẹ̀mí yan àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yìí láti lọ sọ́run, wọ́n ti nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé. Wọ́n ń retí ìgbà tí Jèhófà máa mú gbogbo ìwà ibi kúrò táá sì sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè. Wọ́n tiẹ̀ ti lè máa fojú inú yàwòrán bí wọ́n á ṣe kí ẹbí tàbí ọ̀rẹ́ wọn kan tó jíǹde káàbọ̀ sínú ayé tuntun. Wọ́n lè ti máa fojú inú wo ara wọn bíi pé àwọn ti ń kọ́ ilé, àwọn sì ti ń gbé inú rẹ̀, tàbí pé àwọn ti ń gbin igi àwọn sì ti ń jẹ èso rẹ̀. (Aísáyà 65:21-23) Àmọ́ kí ló dé tí ìrònú wọn fi wá yí pa dà? Ṣé torí pé nǹkan tojú sú wọn ni àbí torí pé wọ́n ti fìyà jẹ wọ́n jù? Ṣé wọ́n kàn ṣàdéédéé pinnu pé ayé yìí ò dùn mọ́ ni àti pé á sú àwọn táwọn bá ń gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé? Àbí ṣe ló kàn bẹ̀rẹ̀ sí í wù wọ́n láti lọ wo bí nǹkan á ṣe rí táwọn bá ń gbé lọ́run? Rárá, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀! Ọlọ́run ló yàn fún wọn, àwọn kọ́ ló yàn fúnra wọn. Nígbà tí Ọlọ́run yàn wọ́n, ó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ yí bí wọ́n ṣe ń ronú pa dà, ó sì tún yí èrè tí wọ́n á máa fojú sọ́nà fún pa dà.
14. Báwo ló ṣe rí lára àwọn ẹni àmì òróró pé àwọn ṣì ń gbé lórí ilẹ̀ ayé báyìí?
14 Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé ó máa ń wu àwọn ẹni àmì òróró pé káwọn kú? Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwọn ẹni àmì òróró. Ó fi ẹran ara tí wọ́n ṣì gbé wọ̀ báyìí wé “àgọ́,” ó wá sọ pé: “Ní ti tòótọ́, àwa tí a wà nínú àgọ́ yìí ń kérora, níwọ̀n bí a ti dẹrù pa wá; nítorí pé àwa kò fẹ́ láti bọ́ ọ kúrò, bí kò ṣe láti gbé èkejì wọ̀, kí ìyè lè gbé èyí tí ó jẹ́ kíkú mì.” (2 Kọ́ríńtì 5:4) Àwọn Kristẹni yìí ò fẹ́ kú. Wọ́n fẹ́ máa wà láàyè, kí àwọn àtàwọn èèyàn wọn lè jọ máa sin Jèhófà lójoojúmọ́. Àmọ́ ohun yòówù kí wọ́n máa ṣe, wọn ò jẹ́ gbàgbé ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa ṣe fún wọn láìpẹ́.—1 Kọ́ríńtì 15:53; 2 Pétérù 1:4; 1 Jòhánù 3:2, 3; Ìṣípayá 20:6.
ṢÉ JÈHÓFÀ TI YÀN Ẹ́?
15. Kí ni kò fi hàn pé Ọlọ́run ti fi ẹ̀mí mímọ́ yan ẹnì kan?
15 Àbí ò ń ronú pé Jèhófà ti yàn ẹ́ láti lọ sọ́run? Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé Jèhófà ti yàn ẹ́, ronú nípa àwọn ìbéèré pàtàkì yìí ná: Ṣó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé kò sí iṣẹ́ míì tó o kúndùn bí iṣẹ́ ìwàásù? Ṣé o fẹ́ràn láti máa ka Bíbélì gan-an tó sì máa ń wù ẹ́ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run”? (1 Kọ́ríńtì 2:10) Ṣé ò ń wò ó pé Jèhófà ti jẹ́ kó o ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti wá sínú òtítọ́? Ṣé kò sí nǹkan míì tó máa ń wù ẹ́ bíi kó o ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́? Ṣé o nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú tó o sì ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá sin Jèhófà? Ṣó o ti rí ọ̀pọ̀ ọ̀nà tí Jèhófà ti gbà ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbèésí ayé rẹ? Bí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni sí gbogbo ìbéèrè yìí, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé Jèhófà ti yàn ẹ́ láti lọ sọ́run? Rárá, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé Jèhófà ti fẹ̀mí yàn ẹ́ láti lọ sọ́run. Kí nìdí? Ìdí ni pé gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lè dáhùn bẹ́ẹ̀ ni sí gbogbo ìbéèrè yìí, yálà wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró tàbí wọn kì í ṣe ẹni àmì òróró. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà lè fún èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ẹ̀mí mímọ́ tí wọ́n á fi ṣàṣeyọrí láwọn ọ̀nà yìí, bóyá ọ̀run ni èrè wọn wà o àbí ilẹ̀ ayé. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, tó o bá ń ṣiyè méjì bóyá o wà lára àwọn tó ń lọ sọ́run, a jẹ́ pé Jèhófà ò tíì yàn ẹ́ nìyẹn. Àwọn tí Jèhófà yàn kì í ṣiyè méjì nípa ẹ̀! Ó dá wọn lójú hán-únhán-ún!
16. Báwo la ṣe mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó rí ẹ̀mí mímọ́ gbà ni Ọlọ́run ti yàn láti lọ sọ́run?
16 Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ èèyàn tí Jèhófà fún ní ẹ̀mí mímọ́ àmọ́ tí wọn ò lọ sọ́run wà nínú Bíbélì. Ọ̀kan lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ni Jòhánù Oníbatisí. Jésù sọ pé kò sí ẹnì kankan tó tóbi ju Jòhánù lọ, àmọ́ ó tún wá sọ pé Jòhánù ò ní bá òun jọba lọ́run. (Mátíù 11:10, 11) Dáfídì ni ẹlòmíì tí Jèhófà tún fún ní ẹ̀mí mímọ́. (1 Sámúẹ́lì 16:13) Ẹ̀mí mímọ́ mú kó mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jèhófà, ó sì tún darí rẹ̀ láti kọ àwọn apá kan lára Ìwé Mímọ́. (Máàkù 12:36) Síbẹ̀, àpọ́sítélì Pétérù sọ pé Dáfídì “kò gòkè lọ sí ọ̀run.” (Ìṣe 2:34) Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yìí lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe àwọn ohun àrà ọ̀tọ̀, àmọ́ kò fi yàn wọ́n láti lọ sọ́run. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé wọn ò pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́ délẹ̀délẹ̀ àbí pé wọn ò tẹ́ni tó ń bá Jésù jọba lọ́run? Rárá. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé Jèhófà máa jí wọn dìde sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15.
17, 18. (a) Ìrètí wo ni ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí ní? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
17 Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí kò ní lọ sọ́run. Bíi ti Ábúráhámù, Dáfídì, Jòhánù Oníbatisí àti ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà míì lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n gbáyé nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn náà ń fojú sọ́nà fún gbígbé lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run. (Hébérù 11:10) Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] máa bá Jésù jọba lọ́run. Àmọ́ Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa “àwọn tí ó ṣẹ́ kù” lára àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n ṣì máa wà láyé lákòókò òpin yìí. (Ìṣípayá 12:17) Torí náà, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] yìí ti kú, wọ́n sì ti wà lọ́run báyìí.
18 Àmọ́ bí ẹnì kan bá sọ pé ẹni àmì òróró lòun, ojú wo ló yẹ káwọn tó nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé máa fi wo onítọ̀hún? Bí ẹnì kan nínú ìjọ rẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìrántí Ikú Kristi, báwo ló ṣe yẹ kó o máa ṣe sí irú ẹni bẹ́ẹ̀? Bí iye àwọn tó sọ pé ẹni àmì òróró làwọn bá sì ń pọ̀ sí i lọ́dọọdún, ṣó yẹ kíyẹn kó ìdààmú ọkàn bá ẹ? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
^ [1] (ìpínrọ̀ 4) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọjọ́ kan náà tí Jèhófà fún Mósè ní ìwé Òfin lórí òkè Sínáì ni Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì bọ́ sí. (Ẹ́kísódù 19:1) Torí náà, ó ṣeé ṣe kí ọjọ́ tí Mósè mú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì wọnú májẹ̀mú Òfin bọ́ sí ọjọ́ kan náà pẹ̀lú ọjọ́ tí Jésù mú àwọn ẹni àmì òróró wọnú májẹ̀mú tuntun.
^ [2] (ìpínrọ̀ 11) Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tó túmọ̀ sí láti di àtúnbí, wo Ilé Ìṣọ́ April 1, 2009, ojú ìwé 3 sí 11.