ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | RÓÒMÙ 7-8
Ṣé Ò Ń Fojú Sọ́nà Pẹ̀lú Ìháragàgà?
“Ìṣẹ̀dá”: aráyé tó ń fojú sọ́nà láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé
“Ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run”: nígbà tí àwọn ẹni àmì òróró bá dara pọ̀ mọ́ Kristi láti pa ètò àwọn nǹkan búburú Sátánì run
“Nítorí ìrètí”: ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa dá wa sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú àti ẹ̀ṣẹ̀, nípasẹ̀ ikú àti àjíǹde Jésù
‘Dá sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́’: ìdáǹdè lọ́wọ́ ipa tí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ti ní lórí wa