Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
“Ìwọ ni ìrètí mi, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìgbọ́kànlé mi láti ìgbà èwe mi wá.”—SÁÀMÙ 71:5.
1. Ìpèníjà wo ni Dáfídì ọ̀dọ́mọkùnrin tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn náà dojú kọ?
ỌKÙNRIN náà rí fìrìgbọ̀n, ó ga ju ẹsẹ̀ bàtà mẹ́sàn-án lọ dáadáa. Abájọ tí gbogbo àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì kò fi láyà láti kò ó lójú! Ní òròòwúrọ̀ àti ní alaalẹ́ ni Gòláyátì, òmìrán ará Filísínì náà ń ṣáátá àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì, tó ń sọ pé kí wọ́n jẹ́ kí akọni àárín wọn wá ko òun lójú, ó sì ṣe èyí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀. Nígbà tó yá, ẹnì kan lóun á lọ kò ó lójú. Ẹni yìí kì í ṣe jagunjagun o, ọ̀dọ́mọkùnrin kan ni. Dáfídì ọ̀dọ́mọkùnrin tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn yìí kò ju jáńjálá lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tá rẹ̀ náà. Àní sẹ́, tá a bá gbé e sórí ìwọ̀n, ó lè máà wọ̀n tó ohun ìjà Gòláyátì. Síbẹ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin yìí kojú òmìrán náà, ìgboyà rẹ̀ sì tipa bẹ́ẹ̀ di àwòfiṣàpẹẹrẹ. Òkìkí rẹ̀ sì kàn kárí ayé.—1 Sámúẹ́lì 17:1-51.
2, 3. (a) Kí nìdí tí Dáfídì fi láyà láti kojú Gòláyátì? (b) Àwọn ohun méjì wo la máa gbé yẹ̀ wò ká bàá lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?
2 Kí ló mú kí Dáfídì ní irú ìgboyà bẹ́ẹ̀? Gbé àwọn ọ̀rọ̀ kan tí ẹ̀rí fi hàn pé Dáfídì kọ nígbà tó dàgbà tán yẹ̀ wò. Ó sọ pé: “Ìwọ ni ìrètí mi, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìgbọ́kànlé mi láti ìgbà èwe mi wá.” (Sáàmù 71:5) Dájúdájú látìgbà èwe ni Dáfídì ti gbọ́kàn lé Jèhófà pátápátá. Nígbà tó kojú Gòláyátì, ohun tó sọ ni pé: “Ìwọ ń bọ̀ lọ́dọ̀ mi pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ àti ẹ̀ṣín, ṣùgbọ́n èmi ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run àwọn ìlà ogun Ísírẹ́lì, ẹni tí ìwọ ti ṣáátá.” (1 Sámúẹ́lì 17:45) Gòláyátì gbọ́kàn lé agbára tó ní àtàwọn ohun ìjà rẹ̀, àmọ́ Dáfídì ní tirẹ̀ gbọ́kàn lé Jèhófà. Kí nìdí tí Dáfídì á fi máa bẹ̀rù èèyàn lásánlàsàn, bó ti wù kónítọ̀hún ṣe fìrìgbọ̀n kó sì dì káká dì kuku tó, nígbà tí Olúwa Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run wà pẹ̀lú rẹ̀?
3 Bó o ṣe ń kà nípa ìtàn Dáfídì, ǹjẹ́ ó ń wu ìwọ náà pé kí ìgbọ́kànlé rẹ nínú Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i? Ọ̀pọ̀ lára wa ló máa fẹ́ bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tá a lè ṣe láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Lákọ̀ọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ borí àwọn ohun tó lè jin ìgbẹ́kẹ̀lé wa lẹ́sẹ̀. Ìkejì, a gbọ́dọ̀ mọ ohun tí gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà túmọ̀ sí gan-an.
Bíborí Àwọn Ohun Tó Lè Jin Ìgbẹ́kẹ̀lé Wa Nínú Jèhófà Lẹ́sẹ̀
4, 5. Kí nìdí tó fi ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run?
4 Kí ni kì í jẹ́ káwọn èèyàn lè gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run? Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn èèyàn kì í lóye ìdí táwọn nǹkan búburú fi ń ṣẹlẹ̀. Ohun tí wọ́n fi kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé Ọlọ́run ló ń fa ìjìyà. Nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì lè sọ fáwọn èèyàn pé ńṣe ni Ọlọ́run “mú” àwọn tó kàgbákò náà lọ sí ọ̀run. Kò tán síbẹ̀ o, ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń kọ́ àwọn èèyàn pé ohunkóhun yòówù kó ṣẹlẹ̀ jẹ́ àyànmọ́ látọwọ́ Ọlọ́run títí kan àjálù èyíkéyìí àtàwọn ìwà ibi tó ń ṣẹlẹ̀ láyé yìí. Ó máa ṣòro gan-an láti gbẹ́kẹ̀ lé irú Ọlọ́run aláìláàánú bẹ́ẹ̀. Sátánì, tó ti fọ́ ojú inú àwọn aláìgbàgbọ́, ló ń gbé gbogbo “àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù” bẹ́ẹ̀ lárugẹ.—1 Tímótì 4:1; 2 Kọ́ríńtì 4:4.
5 Sátánì kò fẹ́ káwọn èèyàn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ọ̀tá Ọlọ́run yìí kò fẹ́ ká mọ ohun tó ń fà á tí ẹ̀dá ènìyàn fi ń jìyà. Tá a bá sì ti mọ àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ pé ó ń fa ìjìyà, Sátánì máa fẹ́ ká gbàgbé wọn. Nítorí náà, ohun tó dára ni pé ká máa ṣàyẹ̀wò lóòrèkóòrè ìdí mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ìyà fi ń jẹ èèyàn nínú ayé. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, à óò lè mú un dá ara wa lójú pé Jèhófà kọ́ ló ń fa àwọn ìṣòro tá a ń dojú kọ nínú ìgbésí ayé.—Fílípì 1:9, 10.
6. Kí ni 1Pétérù 5:8 sọ pé ó ń fa ìjìyà ẹ̀dá èèyàn?
6 Ọ̀kan lára àwọn ìdí tí ẹ̀dá èèyàn fi ń jìyà ni pé Sátánì fẹ́ ba ìṣòtítọ́ àwọn adúróṣinṣin sí Jèhófà jẹ́. Ó tiẹ̀ gbìyànjú láti ba ìṣòtítọ́ Jóòbù jẹ́ pàápàá. Sátánì kò rí i ṣe nígbà yẹn, àmọ́ kò dẹ̀yìn. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé òun ni olùṣàkóso ayé, ó ń wá ọ̀nà láti ‘pa’ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ‘jẹ’. (1 Pétérù 5:8) Ìyẹn ẹnì kọ̀ọ̀kan wa! Sátánì fẹ́ ká ṣíwọ́ sísin Jèhófà. Ìdí rèé tó fi ń fa inúnibíni lọ́pọ̀ ìgbà. Bó ti wù kí irú ìjìyà bẹ́ẹ̀ pọ́n wa lójú tó, ohun tó tọ́ ni pé ká fara dà á. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì èyí á sì máa múnú Jèhófà dùn. (Jóòbù 2:4; Òwe 27:11) Bí Jèhófà ṣe ń fún wa lókun láti fara da inúnibíni, ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú rẹ̀ á túbọ̀ máa pọ̀ sí i.—Sáàmù 9:9, 10.
7. Kí ni nǹkan tó ń fa ìjìyà gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Gálátíà 6:7?
7 Ìdí kejì téèyàn fi ń jìyà wá látinú ìlànà tó sọ pé: “Ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.” (Gálátíà 6:7) Irúgbìn táwọn èèyàn máa ń fún nígbà mìíràn ni yíyan ohun tí kò bọ́gbọ́n mu, tí wọ́n á sì ká ìjìyà. Wọ́n lè wakọ̀ níwàkuwà, èyí sì lè fa ìjàǹbá ọkọ̀. Ọ̀pọ̀ ló ń mu sìgá, èyí tó ń fa àrùn ọkàn tàbí àrùn jẹjẹrẹ. Àwọn tó ń ṣèṣekúṣe lè ba àjọṣe inú ìdílé wọn jẹ́, wọ́n á di ẹni yẹ̀yẹ́ láwùjọ, wọ́n sì lè kó àrùn táwọn èèyàn ń kó nípasẹ̀ ìbálòpọ̀, tàbí kí wọ́n rí oyún he. Àwọn èèyàn lè bẹ̀rẹ̀ sí dá Ọlọ́run lẹ́bi fún irú ìjìyà báwọ̀nyí, àmọ́ ní ti gidi àfọwọ́fà ara wọn ni.—Òwe 19:3.
8. Gẹ́gẹ́ bí Oníwàásù 9:11 ṣe wí, kí nìdí táwọn èèyàn fi ń jìyà?
8 Ìdí kẹta tá a fi ń jìyà wà nínú Oníwàásù 9:11, èyí tó sọ pé: “Mo padà láti rí i lábẹ́ oòrùn pé eré ìje kì í ṣe ti ẹni yíyára, bẹ́ẹ̀ ni ìjà ogun kì í ṣe ti àwọn alágbára ńlá, bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kì í ṣe ti àwọn ọlọ́gbọ́n pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni ọrọ̀ kì í ṣe ti àwọn olóye pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni ojú rere kì í ṣe ti àwọn tí ó ní ìmọ̀ pàápàá; nítorí pé ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.” Nígbà mìíràn, ńṣe làwọn èèyàn kàn máa ń ṣe kòńgẹ́ àgbákò. Yálà a jẹ́ alágbára tàbí aláìlera, ìjìyà àti ikú lè dé bá wa láìròtẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà ayé Jésù, ilé gogoro kan wó lulẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù ó sì pa èèyàn méjìdínlógún. Jésù sọ pé kì í ṣe pé ńṣe ni wọ́n dẹ́ṣẹ̀ kan tẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run wá fìyà rẹ̀ jẹ wọ́n. (Lúùkù 13:4) Rárá o, Jèhófà kọ́ ló lẹ̀bi irú ìjìyà bẹ́ẹ̀.
9. Kí ni ọ̀pọ̀ èèyàn ò lóye nípa ìyà tó ń jẹ ẹ̀dá èèyàn?
9 Ó ṣe pàtàkì gan-an kéèyàn lóye díẹ̀ lára àwọn ohun tó ń fa ìjìyà. Àmọ́ ṣá, ohun kan wà nípa ọ̀ràn náà tí kò yé ọ̀pọ̀ èèyàn. Ohun náà ni pé: Kí nìdí tí Jèhófà Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà?
Kí Nìdí Tí Jèhófà Fi Fàyè Gba Ìjìyà?
10, 11. (a) Gẹ́gẹ́ bí Róòmù 8:19-22 ṣe sọ, kí ló ṣẹlẹ̀ sí “gbogbo ìṣẹ̀dá”? (b) Báwo la ṣe lè mọ ẹni tó tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo?
10 Apá kan lára lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù túbọ̀ tànmọ́lẹ̀ sórí kókó pàtàkì yìí. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà ìṣẹ̀dá ń dúró de ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run. Nítorí a tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo, kì í ṣe nípasẹ̀ ìfẹ́ òun fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹni tí ó tẹ̀ ẹ́ lórí ba, nítorí ìrètí pé a óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run. Nítorí àwa mọ̀ pé gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.”—Róòmù 8:19-22.
11 Tá a bá fẹ́ lóye àwọn ẹsẹ wọ̀nyí, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì kan. Bí àpẹẹrẹ, Ta ló tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo? Àwọn kan sọ pé Sátánì ni; àwọn mìíràn sì sọ pé Ádámù ni. Àmọ́ kò lè jẹ́ èyíkéyìí lára àwọn méjèèjì. Kí nìdí? Ìdí ni pé ẹni náà tó tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo ṣe bẹ́ẹ̀ ó sì tún fúnni ní “ìrètí.” Dájúdájú, ó fún wa nírètí pé bópẹ́ bóyá ‘a óò dá àwọn olóòótọ́ sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́.’ Ádámù tàbí Sátánì kò lè fúnni nírú ìrètí yìí. Jèhófà nìkan ló lè ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ó ti wá ṣe kedere báyìí pé òun ló tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo.
12. Irú ìbéèrè wo ló ti dìde nípa ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “gbogbo ìṣẹ̀dá,” báwo la sì ṣe lè dáhùn ìbéèrè náà?
12 Àmọ́ o, kí ni “gbogbo ìṣẹ̀dá” tá a mẹ́nu bà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí? Àwọn kan sọ pé “gbogbo ìṣẹ̀dá” túmọ̀ sí gbogbo nǹkan tó wà láyé títí kan àwọn ẹranko àti ewéko. Àmọ́, ǹjẹ́ àwọn ẹranko àtàwọn ewéko ní ìrètí láti ní “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run”? Rárá o. (2 Pétérù 2:12) Nígbà náà, àwọn ẹ̀dá èèyàn nìkan ni gbólóhùn náà “gbogbo ìṣẹ̀dá” lè túmọ̀ sí. Ìṣẹ̀dá yìí ni ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ń hàn léèmọ̀ nítorí ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì, ó sì wá nílò ìrètí gan-an báyìí.—Róòmù 5:12.
13. Ipa wo ni ọ̀tẹ̀ tó wáyé ní Édẹ́nì ní lórí ẹ̀dá èèyàn?
13 Ọṣẹ́ wo gan-an ni ọ̀tẹ̀ náà ti ṣe fún ẹ̀dá ènìyàn? Ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo ni Pọ́ọ̀lù fi pe àbájáde rẹ̀, ọ̀rọ̀ náà ni: ìmúlẹ̀mófo.a Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ ti sọ, ọ̀rọ̀ yìí ṣàpèjúwe “bó ṣe jẹ́ àṣedànù bí irin iṣẹ́ kan kò bá lè ṣe iṣẹ́ tá a ṣe é fún.” A dá èèyàn láti wà láàyè títí láé, kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan tó pé, tó wà níṣọ̀kan, kí wọ́n sì máa bojú tó ilẹ̀ ayé tó jẹ́ ọgbà ẹlẹ́wà. Àmọ́ dípò èyí, ẹ̀mí wọn kì í gùn, ìrora ni ṣáá, ìgbésí ayé wọn sì kún fún ìṣòro. Ńṣe ló rí gẹ́gẹ́ bí Jóòbù ṣe sọ ọ́ pé: “ènìyàn, tí obìnrin bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ṣìbáṣìbo.” (Jóòbù 14:1) Áà, ìmúlẹ̀mófo gbáà ni lóòótọ́!
14, 15. (a) Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé ìdájọ́ tí Jèhófà ṣe fún ẹ̀dá èèyàn bẹ́tọ̀ọ́ mu? (b) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé ‘kì í ṣe nípasẹ̀ ìfẹ́ ìṣẹ̀dá fúnra rẹ̀’ la fi tẹ̀ ẹ́ lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo?
14 A ti wá débi ìbéèrè tó ṣe kókó jù lọ wàyí, ìbéèrè náà ni: Kí nìdí tí “Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé” fi tẹ ẹ̀dá lórí ba báyìí tí ìgbésí ayé wọn sì kún fún ìrora? (Jẹ́nẹ́sísì 18:25) Ṣé ohun tó tọ́ ló ṣe yìí? Ó dára, rántí ohun táwọn òbí wa àkọ́kọ́ ṣe. Nípa ṣíṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, ńṣe ni wọ́n lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Sátánì, ẹni tó fàáké kọ́rí pé Jèhófà kò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ. Nípa ìwà wọn, wọ́n ti èrò náà lẹ́yìn pé ìgbésí ayé ẹ̀dá èèyàn á lójú láìfi ti Jèhófà ṣe, kí ẹ̀dá ẹ̀mí kan tó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sì máa darí wọn. Ohun táwọn ọlọ̀tẹ̀ yìí ń fẹ́ ni Jèhófà fún wọn ní ti bó ṣe fìyà jẹ wọ́n. Ó gba ẹ̀dá èèyàn láyè láti ṣàkóso ara rẹ̀ lábẹ́ ìdarí Sátánì. Nínú irú ipò báwọ̀nyí, ìpinnu wo ló tún lè dára ju títẹ̀ tí Ọlọ́run tẹ ẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo lọ, àmọ́ to wá fún wọn nírètí?
15 Lóòótọ́, kì í ṣe ‘nípasẹ̀ ìfẹ́ ìṣẹ̀dá fúnra rẹ̀’ lèyí fi ṣẹlẹ̀ o. Ńṣe la bí wa gẹ́gẹ́ bí ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ àti ìdíbàjẹ́ láìsí ohunkóhun tá a lè ṣe sí i. Àmọ́ nínú àánú Jèhófà, ó jẹ́ kí Ádámù àti Éfà lo ọdún tó ṣẹ́ kù nínú ìgbésí ayé wọn kí wọ́n sì bímọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti tẹ àwa tá a jẹ́ àtọmọdọ́mọ wọn lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, a láǹfààní láti ṣe ohun tí Ádámù àti Éfà kùnà láti ṣe. A lè fetí sí Jèhófà ká sì kẹ́kọ̀ọ́ pé jíjẹ́ tó jẹ́ ọba aláṣẹ bẹ́tọ̀ọ́ mu, pé kìkì ohun tí ìṣàkóso èèyàn láìfi ti Jèhófà ṣe máa ń mú wá ni ìrora, ìjákulẹ̀ àti ìmúlẹ̀mófo. (Jeremáyà 10:23; Ìṣípayá 4:11) Ńṣe ni ìṣàkóso Sátánì sì tún máa ń mú kí ọ̀ràn náà túbọ̀ burú sí i. Ìtàn ẹ̀dá èèyàn jẹ́rìí sí i pé òtítọ́ lèyí.—Oníwàásù 8:9.
16. (a) Kí nìdí tó fi lè dá wa lójú pé Jèhófà kọ́ ló ń fa ìjìyà tó wà láyé lónìí? (b) Ìrètí wo ni Jèhófà ti fún àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́?
16 Ó wá hàn kedere báyìí pé ohun tó tọ́ ni Jèhófà ṣe bó ṣe tẹ ẹ̀dá èèyàn lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo. Àmọ́, ǹjẹ́ èyí wá túmọ̀ sí pé Jèhófà ló ń fa ìmúlẹ̀mófo àti ìjìyà tó ń han ẹnì kọ̀ọ̀kan wa léèmọ̀ lónìí? Ó dára, ronú nípa adájọ́ kan tó ṣèdájọ́ tó tọ́ tó sì yẹ fún ọ̀daràn kan. Ọ̀daràn náà lè jìyà gan-an nígbà tó bá ń ṣẹ̀wọ̀n, àmọ́ ṣé ó lè wá máa dá adájọ́ náà lẹ́bi pé òun ló fa ìjìyà fún òun? Kò le ṣe bẹ́ẹ̀! Dájúdájú, Jèhófà kọ́ ló ń fa ìwà ibi. Jákọ́bù 1:13 sọ pé: “A kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” Ẹ jẹ́ ká tún rántí pé Jèhófà ṣe ìdájọ́ yìí ‘pẹ̀lú ìrètí.’ Ó ti ṣètò tìfẹ́tìfẹ́ fún ìrandíran Ádámù àti Éfà tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ láti rí òpin ìmúlẹ̀mófo náà kí wọ́n lè máa yọ̀ nítorí “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” Títí ayérayé, ẹ̀rù ò tún ní máa ba ẹ̀dá èèyàn olóòótọ́ mọ́ pé a tún máa tẹ ẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo tó ń kó ìrora bá wọn. Ọ̀nà tó tọ́ tó sì yẹ tí Jèhófà gbà bójú tó ọ̀ràn náà yóò ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí ayé pé jíjẹ́ tó jẹ́ ọba aláṣẹ bẹ́tọ̀ọ́ mu.—Aísáyà 25:8.
17. Kí ló yẹ kí àyẹ̀wò tá a ń ṣe nípa àwọn ìdí tí ìjìyà fi wà nínú ayé lónìí mú ká ṣe?
17 Bá a ṣe ń ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó ń fa ìjìyà ẹ̀dá èèyàn, ǹjẹ́ a rí ìdí kankan tá a lè fi dá Jèhófà lẹ́bi fún ìwà ibi tó ń ṣẹlẹ̀ tàbí ìdí tí kò fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé e? Rárá o, ńṣe ni irú ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí túbọ̀ ń jẹ́ ká fara mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí Mósè sọ pé: “Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; olódodo àti adúróṣánṣán ni.” (Diutarónómì 32:4) Ẹ jẹ́ ká máa ṣàyẹ̀wò látìgbàdégbà nípá bí àwa fúnra wa ṣe lóye kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀ràn náà tó, kí a máa ṣàṣàrò lórí wọn. Lọ́nà yìí, tá a bá kojú àdánwò àá lè ṣẹ́gun Sátánì tó ń fẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyèméjì. Ìgbésẹ̀ kejì tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ wá ń kọ́ o? Kí ni gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà túmọ̀ sí?
Ohun Tí Gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà Túmọ̀ Sí
18, 19. Àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí wo ni Bíbélì fún wa tó lè mú ka gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, àmọ́ èrò tí kò tọ̀nà wo làwọn kan ń ní nípa èyí?
18 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ń tuni lára gan-an wọ́n sì ń fini lọ́kàn balẹ̀. Ó dájú pé kò sí ẹlòmíràn láyé lọ́run tó ṣeé gbíyè lé bí kò ṣe Baba wa ọ̀run. Àmọ́ ṣá, ó rọrùn gan-an láti ka àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn nínú ìwé Òwe ṣùgbọ́n ó lè ṣòro láti wá mú wọn lò.
19 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ní èrò tí kò tọ̀nà nípa ohun tó túmọ̀ sí láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Àwọn kan rò pé ó wulẹ̀ jẹ́ bí nǹkan ṣe rí lára ẹni, tàbí ayọ̀ tó ti ọkàn ẹni wá. Àwọn mìíràn gbà gbọ́ pé tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run àá máa retí pé kó dáàbò bò wá kí ibi kankan máà ṣẹlẹ̀ sí wa, kí ó yanjú gbogbo ìṣòro wa pátá, kó yanjú ìṣòro tá a ń bá pàdé lójoojúmọ́, kó sì ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tá a fẹ́ gan-an ní kíákíá! Àmọ́ irú èrò yìí kò tọ̀nà. Ìgbẹ́kẹ̀lé kọjá bí nǹkan ṣe rí lára ẹni, kò sì túmọ̀ sí ríretí ohun tí ọwọ́ kò lè tẹ̀. Fún àwọn tó ti dàgbà, ìgbẹ́kẹ̀lé kan kéèyàn ronú jinlẹ̀ kó sì fara balẹ̀ ṣe ìpinnu.
20, 21. Kí ni gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà túmọ̀ sí? Ṣàpèjúwe.
20 Tún ṣàkíyèsí ohun tí ìwé Òwe 3:5 sọ. Ó sọ pé gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà yàtọ̀ pátápátá sí gbígbára lé òye tiwa fúnra wa, pé a kò lè ṣe méjèèjì pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà. Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé a ò yọ̀ǹda fún wa láti lo agbára òye wa ni? Rárá o, nítorí pé Jèhófà tó fún wa ní agbára yìí retí pé ká fi sin òun. (Róòmù 12:1) Àmọ́ ta la máa ń gbára lé nígbà tá a bá ń ṣèpinnu? Tó bá ṣẹlẹ̀ pé èrò wa yàtọ̀ sí ti Jèhófà, ǹjẹ́ àá lè sọ pé a fara mọ́ ọgbọ́n rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èyí tó ga ju tiwa lọ? (Aísáyà 55:8, 9) Gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà túmọ̀ sí pé ká jẹ́ kí èrò rẹ̀ máa darí èrò wa.
21 Àpẹẹrẹ kan rèé: Ronú nípa ọmọ kékeré kan tó jókòó sápá ẹ̀yìn nínú ọkọ̀, àwọn òbí rẹ̀ jókòó síwájú. Bàbá rẹ̀ ló ń wa ọkọ̀ náà. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn ohun kan wáyé bí wọ́n ṣe ń lọ—bóyá ọ̀nà dà rú mọ́ wọn lójú tàbí ojú ọjọ́ ò rí bó ṣe yẹ kó rí tàbí kí ọ̀nà máà dáa—kí ló yẹ kí ọmọ tó jẹ́ onígbọràn, tó gbẹ́kẹ̀ lé àwọn òbí rẹ̀ ṣe? Ṣé ńṣe ló máa pariwo látẹ̀yìn pé ọ̀nà báyìí ló yẹ káwọn gbà, kó sì máa sọ fún bàbá rẹ̀ pé báyìí báyìí ló ṣe yẹ kó wakọ̀? Ṣé ó bọ́gbọ́n mu kó máa ṣiyèméjì nípa ìpinnu àwọn òbí rẹ̀ tàbí kó fàáké kọ́rí tí wọ́n bá sọ fún un pé ńṣe ni kó jókòó jẹ́ẹ́ sórí àga rẹ̀ lẹ́yìn? Rárá, kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Ńṣe ló máa fọkàn tán àwọn òbí rẹ̀ pé wọ́n tóótun láti wá ojútùú sáwọn ìṣòro náà bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wọ́n. Baba pípé ni Jèhófà ní tiẹ̀. Ǹjẹ́ kò wá yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá, àgàgà lákòókò tí nǹkan kò bá rọgbọ?—Aísáyà 30:21.
22, 23. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tá a bá níṣòro, báwo la sì ṣe lè ṣe èyí? (b) Ki la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
22 Àmọ́ ṣá o, Òwe 3:6 sọ pé a gbọ́dọ̀ ‘ṣàkíyèsí Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà wa,’ kì í ṣe kìkì ìgbà tí ìṣòro bá dé. Nítorí náà, àwọn ìpinnu tá a ń ṣe nínú ìgbésí ayé wa lójoojúmọ́ gbọ́dọ̀ fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Bí ìṣòro bá dé, a kò gbọ́dọ̀ sọ̀rètí nù, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò wá, a sì gbọ́dọ̀ gbé ìlànà Jèhófà yẹ̀ wò lórí ọ̀nà tó dára jù lọ láti bójú tó àwọn ọ̀ràn náà. A gbọ́dọ̀ ka àdánwò sí àǹfààní láti ṣètìlẹ́yìn fún ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, láti fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì, àti láti jẹ́ onígbọràn ká sì ní àwọn ànímọ́ mìíràn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí.—Hébérù 5:7, 8.
23 A lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà láìfi ìṣòro èyíkéyìí tó lè máa dẹ́rù bà wá pè. A ń ṣe èyí nípasẹ̀ àwọn àdúrà tá a ń gbà àti nípa bá a ṣe ń wá ìtọ́sọ́nà nínú Ọ̀rọ̀ Jèhófà àti nínú ètò àjọ rẹ̀. Àmọ́ báwo la ṣe lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà táwọn ìṣòro tó wà nínú ayé lónìí bá dé bá wa? Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò jíròrò kókó yìí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan náà tí Pọ́ọ̀lù lò fún “ìmúlẹ̀mófo” ni wọ́n lò nínú Bíbélì Gíríìkì ti ìtumọ̀ Septuagint láti fi túmọ̀ ọ̀rọ̀ kan tí Sólómọ́nì lò léraléra nínú ìwé Oníwàásù, ọ̀rọ̀ náà sì ni “asán ni gbogbo rẹ̀!”—Oníwàásù 1:2, 14; 2:11, 17; 3:19; 12:8.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Báwo ni Dáfídì ṣe fi hàn pé Jèhófà lòun gbẹ́kẹ̀ lé?
• Ohun mẹ́ta wo ló ń fa ìjìyà ẹ̀dá èèyàn lónìí, kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa gbé wọn yẹ̀ wò látìgbàdégbà?
• Ìdájọ́ wo ni Jèhófà ṣe fún ẹ̀dá èèyàn, kí sì nìdí tí ìdájọ́ náà fi tọ́ tó sì yẹ?
• Kí ni gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà túmọ̀ sí?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Dáfídì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Jésù fi hàn pé ilé gogoro kan tó wó ní Jerúsálẹ́mù kì í ṣe àmúwá Jèhófà