Atóbilọ́lá Amọ̀kòkò Náà Àti Iṣẹ́ Rẹ̀
“[Ẹ di] ohun èlò fún ète ọlọ́lá, . . . tí a múra sílẹ̀ fún gbogbo iṣẹ́ rere.”—2 TÍMÓTÌ 2:21.
1, 2. (a) Báwo ni dídá tí Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin ṣe jẹ́ iṣẹ́ tó pabanbarì? (b) Ète wo ni Atóbilọ́lá Amọ̀kòkò náà fi dá Ádámù àti Éfà?
JÈHÓFÀ ni Atóbilọ́lá Amọ̀kòkò náà. Ádámù, òbí wa àkọ́kọ́, sì jẹ́ àgbàyanu nínú àwọn iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀. Bíbélì sọ fún wa pé: “Jèhófà Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ̀dá ọkùnrin náà láti inú ekuru ilẹ̀, ó sì fẹ́ èémí ìyè sínú ihò imú rẹ̀, ọkùnrin náà sì wá di alààyè ọkàn,” ìyẹn ni pé ó di “ẹ̀dá tí ń mí.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:7, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, New World Translation of the Holy Scriptures—With References) Ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ jẹ́ ẹni pípé, a dá a ní àwòrán Ọlọ́run, èyí fi hàn pé Ọlọ́run fi ọgbọ́n Rẹ̀ àti ìfẹ́ tí ó ní fún òdodo àti ìdájọ́ òdodo jíǹkí rẹ̀.
2 Nípa lílo èròjà láti inú egungun ìhà Ádámù, Ọlọ́run dá àṣekún àti olùrànlọ́wọ́ fún ọkùnrin náà—ìyẹn ni obìnrin. Ẹwà Éfà kò kù síbì kan rárá, kódà kò sí ẹwà ẹni táa lè fi wé tirẹ̀ nínú àwọn obìnrin tó lẹ́wà jù lọ lóde òní. (Jẹ́nẹ́sísì 2:21-23) Ní àfikún sí i, a fún tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ ní ẹran ara àti òye tí a ṣe lọ́nà pípé, èyí tí yóò mú kí wọ́n ṣiṣẹ́ tí a yàn fún wọn yọrí, iṣẹ́ sísọ ilẹ̀ ayé di párádísè. A tún fún wọn ní agbára láti mú àṣẹ tí Ọlọ́run pa nínú Jẹ́nẹ́sísì 1:28 ṣẹ, wí pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.” Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, a pète pé kí ọgbà àgbáyé yìí kún fún ẹgbàágbèje àwọn ènìyàn aláyọ̀, tí ìfẹ́ tó jẹ́ “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé” so wọ́n pọ̀.—Kólósè 3:14.
3. Báwo ni àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ṣe di ohun èlò tí kò ní ọlá, kí ló sì yọrí sí?
3 Ó mà bani lọ́kàn jẹ́ o, pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ mọ̀ọ́mọ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí ọlá àṣẹ Atóbilọ́lá Amọ̀kòkò náà, Ẹlẹ́dàá wọn, Ọba Aláṣẹ. Ipa ọ̀nà wọ́n wá rí bí a ti ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Aísáyà 29:15, 16 pé: “Ègbé ni fún àwọn tí ń lọ jinlẹ̀-jinlẹ̀ nínú fífi ète pa mọ́ kúrò lójú Jèhófà tìkára rẹ̀, àti àwọn tí iṣẹ́ wọn ti wáyé ní ibi tí ó ṣókùnkùn, nígbà tí wọ́n ń sọ pé: ‘Ta ní ń rí wa, ta sì ni ó mọ̀ nípa wa?’ . . . Ṣé ó yẹ kí a ka amọ̀kòkò sí ọ̀kan náà pẹ̀lú amọ̀? Nítorí pé, ṣé ó yẹ kí ohun tí a ṣe sọ nípa ẹni tí ó ṣe é pé: ‘Òun kọ́ ni ó ṣe mí’? Ṣé ohun náà tí a ṣẹ̀dá yóò sì sọ ní tòótọ́ nípa ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ pé: ‘Kò fi òye hàn’?” Ìwàkiwà wọn fa jàǹbá wá sórí wọn—ìyẹn ni ìyà ikú ayérayé. Kò tán síbẹ̀ yẹn, àní gbogbo ìran ènìyàn tó wá láti ọ̀dọ̀ wọn jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 5:12, 18) Bí àbùkù ńláǹlà ṣe bá ẹwà iṣẹ́ ọwọ́ Atóbilọ́lá Amọ̀kòkò náà nìyẹn.
4. Ète ọlọ́lá wo ni a lè wúlò fún?
4 Àmọ́ ṣá o, nínú ipò àìpé tí a wà nísinsìnyí pàápàá, àwa àtọmọdọ́mọ Ádámù ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣì lè fi àwọn ọ̀rọ̀ Sáàmù 139:14 yin Jèhófà, èyí tó sọ pé: “Èmi yóò gbé ọ lárugẹ, nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu. Àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, bí ọkàn mi ti mọ̀ dáadáa.” Áà, ó mà ṣe o, pé àbùkù burúkú bẹ́ẹ̀ bá iṣẹ́ ọwọ́ Atóbilọ́lá Amọ̀kòkò náà!
Amọ̀kòkò Náà Mú Iṣẹ́ Rẹ̀ Gbòòrò Sí I
5. Báwo ni Atóbilọ́lá Amọ̀kòkò náà yóò ṣe lo òye iṣẹ́ rẹ̀?
5 Ó dùn mọ́ni pé, Ẹlẹ́dàá wa kò fi òye iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Amọ̀kòkò mọ sórí lílò ó láti fi mọ ènìyàn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ nìkan. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún wa pé: “Ìwọ ènìyàn, ta wá ni ọ́ ní ti gidi, tí o fi ń ṣú Ọlọ́run lóhùn? Ǹjẹ́ ohun tí a mọ yóò ha sọ fún ẹni tí ó mọ ọ́n pé, ‘Èé ṣe tí o fi ṣe mí lọ́nà yìí?’ Kínla? Amọ̀kòkò kò ha ní ọlá àṣẹ lórí amọ̀ láti ṣe nínú ìṣùpọ̀ kan náà ohun èlò kan fún ìlò ọlọ́lá, òmíràn fún ìlò aláìlọ́lá?”—Róòmù 9:20, 21.
6, 7. (a) Báwo ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ lónìí ṣe yàn láti di ohun èlò tí a mọ fún ìlò aláìlọ́lá? (b) Báwo ni àwọn olódodo ṣe di ohun èlò tí a mọ fún ìlò ọlọ́lá?
6 Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn kan lára iṣẹ́ ọwọ́ Atóbilọ́lá Amọ̀kòkò náà wà tí a óò mọ fún ìlò ọlọ́lá, a óò sì mọ àwọn mìíràn fún ìlò àìlọ́lá. Àwọn tí wọ́n bá yàn láti máa bá ayé lọ bó ti túbọ̀ ń rì wọnú ẹrẹ̀ ìwà burúkú ni a ń mọ lọ́nà tí yóò fi wọ́n hàn ní ẹni ìparun. Nígbà tí Kristi Jésù, Ọba ológo náà, bá wá ṣèdájọ́, àwọn ohun èlò àìlọ́lá bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ gbogbo àwọn ẹ̀dá ènìyàn olóríkunkun, àwọn ẹni bí ewúrẹ́ tí wọn yóò “lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun” gẹ́gẹ́ bí Mátíù 25:46 ti sọ. Ṣùgbọ́n, “àwọn olódodo,” ìyẹn ni àwọn ẹni bí àgùntàn, tí a mọ fún ìlò “ọlọ́lá,” yóò jogún “ìyè àìnípẹ̀kun.”
7 Lọ́nà tó fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn, àwọn olódodo wọ̀nyí ti ní láti gbà láìjanpata pé, kí Ọlọ́run mọ wọ́n. Wọ́n ti ń tọ ọ̀nà ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́. Wọ́n ti tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn tí a rí nínú 1 Tímótì 6:17-19 pé: “Má ṣe gbé ìrètí [rẹ] lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa.” Wọ́n ti fi ara wọn fún ‘ṣíṣe rere, jíjẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà, jíjẹ́ aláìṣahun, mímúratán láti ṣe àjọpín, fífi àìséwu to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wọn de ẹ̀yìn ọ̀la, kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.’ Òtítọ́ Ọlọ́run ni a fi mọ wọ́n, wọ́n sì ti lo ìgbàgbọ́ tó dúró gbọn-in nínú ìpèsè Jèhófà nípasẹ̀ Kristi Jésù, ẹni tó “fi ara rẹ̀ fúnni ní ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí,” kí ó bàa lè mú gbogbo ohun tí a pàdánù nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù padà bọ̀ sípò. (1 Tímótì 2:6) Nígbà náà, ẹ wo bó ti dára tó láti fínnúfíndọ̀ ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù pé “[kí a] fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara [wa] láṣọ, èyí tí a ń sọ di tuntun [èyí tí a mọ] nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán Ẹni tí ó dá a”!—Kólósè 3:10.
Irú Ohun Èlò Wo Ni O Fẹ́ Dà?
8. (a) Kí ní ń pinnu irú ohun èlò tí ẹnì kan yóò dà? (b) Àwọn kókó méjì wo ni ó ń darí irú ohun èlò tí a óò fi ẹnì kan mọ?
8 Kí ní ń pinnu irú ohun èlò tí ẹnì kan fẹ́ dà? Ẹ̀mí ìrònú àti ìwà rẹ̀ ni. Ìfẹ́-ọkàn àti ìtẹ̀sí ọkàn-àyà ni ó kọ́kọ́ ń darí èyí. Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba sọ pé: “Ọkàn-àyà ará ayé lè gbìrò ọ̀nà ara rẹ̀, ṣùgbọ́n Jèhófà fúnra rẹ̀ ni ó ń darí àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀.” (Òwe 16:9) Ohun kejì tó tún ń darí ẹ̀mí ìrònú àti ìwà ẹnì kan ni, ohun tó ń gbọ́, tó ń rí, àwọn tó ń bá rìn àti ìrírí tó ní. Nígbà náà, ẹ ò wá rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí a kọbi ara sí ìmọ̀ràn náà pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Gẹ́gẹ́ bí 2 Pétérù 1:16 ti kìlọ̀ fún wa, a gbọ́dọ̀ yẹra fún títẹ́tí sí “àwọn ìtàn èké àdọ́gbọ́nhùmọ̀ lọ́nà àrékendá,” tàbí gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀ ti Roman Kátólíìkì látọwọ́ Knox ti pè é, “àwọn ìtàn àròsọ tí ènìyàn gbé kalẹ̀.” Ìwọ̀nyí yóò ní ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ àti ayẹyẹ Kirisẹ́ńdọ̀mù apẹ̀yìndà nínú.
9. Báwo ni a ṣe lè dáhùn padà lọ́nà rere sí bí Atóbilọ́lá Amọ̀kòkò ṣe fẹ́ mọ wá?
9 Nítorí náà, báa bá ṣe dáhùn padà ni yóò pinnu ohun tí Ọlọ́run yóò fi wá mọ. Tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ níwájú Jèhófà, a lè tún àdúrà Dáfídì yìí gbà pé: “Yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, Ọlọ́run, kí o sì mọ ọkàn-àyà mi. Wádìí mi wò, kí o sì mọ àwọn ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè, kí o sì rí i bóyá ọ̀nà èyíkéyìí tí ń roni lára wà nínú mi, kí o sì ṣamọ̀nà mi ní ọ̀nà àkókò tí ó lọ kánrin.” (Sáàmù 139:23, 24) Jèhófà ń mú kí a wàásù iṣẹ́ Ìjọba náà. Ọkàn-àyà wa ti fi ìmọrírì dáhùn sí ìhìn rere náà àti àwọn ọ̀nà mìíràn tí Jèhófà ń gbà darí wa. Nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀, ó ń nawọ́ onírúurú àǹfààní tí ó jẹ mọ́ wíwàásù ìhìn rere náà sí wa; ẹ jẹ́ kí a di ìwọ̀nyí mú, kí a sì ṣìkẹ́ wọn.—Fílípì 1:9-11.
10. Báwo ló ṣe yẹ kí a tiraka tó ní títẹ̀lé àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹ̀mí?
10 Ó ṣe pàtàkì gidigidi pé kí a fiyè sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáradára, kí a máa tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà ojoojúmọ́, kí a sì jẹ́ kí Ìwé Mímọ́ àti iṣẹ́ ìsìn Jèhófà jẹ́ lájorí ìjíròrò nínú ìdílé wa àti láàárín àwọn ọ̀rẹ́ wa. Ètò ìjọsìn òwúrọ̀ tí a máa ń ṣe nígbà oúnjẹ àárọ̀ nínú ìdílé Bẹ́tẹ́lì gbogbo àti nínú ilé àwọn míṣọ́nnárì ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń ní, kíka ẹsẹ Bíbélì díẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan nínú, wọn ó sì fi ọ̀sẹ̀ tó bá tẹ̀ lé e ka àyọkà láti inú ìwé Yearbook. Ǹjẹ́ ìdílé rẹ lè ní irú ètò bẹ́ẹ̀? Ẹ tún wo bí àwọn àǹfààní tí gbogbo wa ń rí nínú ìfararora nínú ìjọ Kristẹni, nínú àwọn ìpàdé tí a ń ṣe, àti ní pàtàkì nípa lílóhùnsí ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ti pọ̀ tó!
A Ń Mọ Wá Láti Lè Kojú Àdánwò
11, 12. (a) Báwo ni a ṣe lè fi ìmọ̀ràn Jákọ́bù nípa àdánwò sílò nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́? (b) Báwo ni ìrírí Jóòbù ṣe ń fún wa níṣìírí láti pa ìwà títọ́ mọ́?
11 Nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́, Ọlọ́run ń yọ̀ǹda kí àwọn ipò kan dìde, àwọn kan nínú wọn sì lè ṣòro fara dà. Ojú wo ló yẹ ká fi wo àwọn nǹkan wọ̀nyí? Gẹ́gẹ́ bí Jákọ́bù 4:8 ti fi hàn, ẹ máà jẹ́ ká bọkàn jẹ́ rárá, kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká sún mọ́ Ọlọ́run, ká fi gbogbo ọkàn-àyà wa gbẹ́kẹ̀ lé e, ká nígbàgbọ́ pé bí a ti ‘ń sún mọ́ ọn, òun pẹ̀lú yóò máa sún mọ́ wa.’ Òótọ́ ni pé a óò ní láti fara da ìṣòro àti àdánwò, ṣùgbọ́n a yọ̀ǹda wọn kí wọ́n bàa lè kópa nínú mímọ tí a ń mọ wá ni, kí ó lè yọrí sí ayọ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Jákọ́bù 1:2, 3 mú un dá wa lójú pé: “Ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ìdùnnú, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá ń bá onírúurú àdánwò pàdé, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ ní tòótọ́ pé ìjójúlówó ìgbàgbọ́ yín yìí tí a ti dán wò ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ìfaradà.”
12 Jákọ́bù tún sọ pé: “Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá wà lábẹ́ àdánwò, kí ó má ṣe sọ pé: ‘Ọlọ́run ni ó ń dán mi wò.’ Nítorí a kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ nípasẹ̀ ìfẹ́-ọkàn òun fúnra rẹ̀.” (Jákọ́bù 1:13, 14) Àdánwò wa lè pọ̀, ó sì lè jẹ́ onírúurú, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ti Jóòbù, gbogbo wọn ń kópa tiwọn nínú mímọ tí a ń mọ wá ni. Ẹ ò wá rí i bí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nínú Jákọ́bù 5:11 ti fini lọ́kàn balẹ̀ tó, ó wí pé: “Wò ó! Àwọn tí wọ́n lo ìfaradà ni a ń pè ní aláyọ̀. Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù, ẹ sì ti rí ìyọrísí tí Jèhófà mú wá, pé Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, ó sì jẹ́ aláàánú.” Gẹ́gẹ́ bí ìkòkò ní ọwọ́ Atóbilọ́lá Amọ̀kòkò náà, ǹjẹ́ kí a lè máa pa ìwà títọ́ mọ́ nígbà gbogbo, kí a sì ní ìgbọ́kànlé bíi ti Jóòbù pé, àtúbọ̀tán wa yóò dára!—Jóòbù 2:3, 9, 10; 27:5; 31:1-6; 42:12-15.
Bí A Ṣe Ń Mọ Àwọn Èwe Wa
13, 14. (a) Ìgbà wo ló yẹ kí àwọn òbí bẹ̀rẹ̀ sí mọ ọmọ wọn, àbájáde wo sì ni wọn yóò rí? (b) Àbájáde aláyọ̀ wo ni o lè mú wa bí àpẹẹrẹ?
13 Àwọn òbí lè nípìn-ín nínú mímọ àwọn èwe wọn láti ìgbà tí wọ́n bá ti wà ní ọmọdé jòjòló, ẹ sì wo irú èwe olùpàwàtítọ́mọ́ tó ṣeé fi yangàn tí wọ́n lè dà! (2 Tímótì 3:14, 15) Bí ọ̀ràn ti máa ń rí nìyẹn, àní nígbà tí àdánwò náà bá tilẹ̀ dójú ẹ̀ pàápàá. Ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, nígbà tí inúnibíni gbóná janjan ní ilẹ̀ Áfíríkà kan, ìdílé kan tó ṣeé fọkàn tán ló ń bójú tó títẹ Ilé Ìṣọ́ ní bòókẹ́lẹ́ nínú búkà kan lẹ́yìnkùlé wọn. Lọ́jọ́ kan, àwọn sójà wá sádùúgbò náà, bí wọ́n ti ń wọnú ilé kan bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń bọ́ sì ìkejì, wọ́n ń wá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọn yóò mú wọnú iṣẹ́ ológun. Àyè wà fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin méjì tí wọ́n jẹ́ apá kan ìdílé yìí láti fara pamọ́, àmọ́ bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, ibi tí àwọn sójà bá ti ń tú ilé wò ni wọn yóò ti rí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé náà. Èyí lè yọrí sí fífìyà pá wọn lórí tàbí kí wọ́n pa gbogbo ìdílé náà. Kí wá ni ṣíṣe? Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà fọhùn, wọ́n fi ìgboyà sọ ohun tó wà nínú Jòhánù 15:13 jáde: “Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” Wọ́n láwọn ò ní jáde nínú yàrá náà sẹ́. Àwọn sójà á mà rí wọn, wọ́n á mà fìyà tó tó ìyà jẹ wọ́n tàbí kí wọ́n tilẹ̀ pa wọ́n tí wọ́n bá kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Ṣùgbọ́n, bí àwọn sójà bá ṣe ìyẹn tán, wọn ò ní yẹ ilé wọn wò. Wọn ò ní lè rí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé náà, ẹ̀mí àwọn mẹ́ńbà ìdílé yòókù kò sì ní sí nínú ewu. Ṣùgbọ́n, ìyọrísí rẹ̀ kàmàmà. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé, àwọn sójà ré ilé kan ṣoṣo yìí kọjá, wọ́n sì forí lé ilé àwọn ẹlòmíràn! Àwọn ẹ̀dá ènìyàn, àwọn ohun èlò tí a mọ fún ìlò ọlọ́lá wọ̀nyẹn yè é bọ́, ẹ̀rọ ìtẹ̀wé náà wà níbi tó wà, wọ́n sì ń lò ó láti máa fi tẹ oúnjẹ tẹ̀mí jáde. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin méjèèjì yẹn àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì báyìí; èyí ọkùnrin yẹn ṣì ń fi ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ògbólógbòó yẹn ṣiṣẹ́ di bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí.
14 A lè kọ́ àwọn èwe ni bí wọ́n ṣe lè gbàdúrà, Ọlọ́run wa sì máa ń gbọ́ àdúrà wọn. Àpẹẹrẹ kan tó pabanbarì nípa èyí wáyé nígbà ìpakúpa tó ṣẹlẹ̀ ní Rwanda. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ fẹ́ fi bọ́ǹbù àfọwọ́jù pa ọmọ ọdún mẹ́fà kan àti àwọn òbí rẹ̀, ọmọbìnrin náà fìtara gbàdúrà sókè, ó gbàdúrà pé kí wọ́n má pa àwọn, kí wọ́n bàa lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Orí àwọn tó fẹ́ pa wọ́n náà wú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọ́n fi dá wọn sí, wọ́n sọ pé: “Nítorí ọmọdébìnrin yìí, a ò ní pa yín.”—1 Pétérù 3:12.
15. Àwọn ohun tó lè ní ipa búburú lórí ẹni wo ni Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ nípa rẹ̀?
15 Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èwe wa ni kò ní láti dojú kọ irú ipò tí ó nira bí èyí táa sọ tán yìí, ṣùgbọ́n onírúurú àdánwò ni wọ́n ń bá pàdé nílé ẹ̀kọ́ àti nínú àwùjọ oníwà ìbàjẹ́ tí a ń gbé lónìí: ọ̀rọ̀ rírùn, àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè, eré ìnàjú tí ń bani jẹ́, kí àwọn ojúgbà ẹni súnni hùwà àìdáa, gbogbo ìwọ̀nyí ló ń peléke sí i ní ibi púpọ̀. Léraléra ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ nípa àwọn ohun tó lè nípa búburú lórí ẹni wọ̀nyí.—1 Kọ́ríńtì 5:6; 15:33, 34; Éfésù 5:3-7.
16. Báwo ni ẹnì kan ṣe lè di ohun èlò fún ìlò ọlọ́lá?
16 Lẹ́yìn tó tọ́ka sí àwọn ohun èlò tí a tọ́jú “fún ète ọlọ́lá ṣùgbọ́n àwọn mìíràn fún ète tí kò ní ọlá,” Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá yẹra fún àwọn ti ìkẹyìn yìí, òun yóò jẹ́ ohun èlò fún ète ọlọ́lá, tí a sọ di mímọ́, tí ó wúlò fún ẹni tí ó ni ín, tí a múra sílẹ̀ fún gbogbo iṣẹ́ rere.” Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká rọ àwọn èwe wa kí wọ́n ṣọ́ra nípa irú ẹgbẹ́ tí wọ́n ń kó. Ẹ jẹ́ kí wọ́n “sá fún àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn, ṣùgbọ́n [kí wọ́n] máa lépa òdodo, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àlàáfíà, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ń ké pe Olúwa láti inú ọkàn-àyà tí ó mọ́.” (2 Tímótì 2:20-22) Ètò ìdílé tí a ṣe fún ‘gbígbé ara ẹni ró lẹ́nì kìíní-kejì’ lè ṣeyebíye púpọ̀ fún mímọ àwọn èwe wa. (1 Tẹsalóníkà 5:11; Òwe 22:6) Kíka Bíbélì lójoojúmọ́ àti kíkẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀, nípa lílo àwọn ìtẹ̀jáde Society tó lè yanjú ìṣòro wọn lè jẹ́ ìrànwọ́ àtàtà.
Mímọ Gbogbo Wa
17. Báwo ni ìbáwí ṣe lè mọ wá, àbájáde aláyọ̀ wo sì ni yóò jẹ́?
17 Kí Jèhófà bàa lè mọ wá, ó ń fún wa nímọ̀ràn láti inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀. Má ṣe kọ etí ikún sí irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá láé! Ṣàmúlò rẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, sì jẹ́ kí ó sọ ẹ́ di ohun èlò ọlá fún Jèhófà. Òwe 3:11, 12 gbani nímọ̀ràn pé: “Ìwọ ọmọ mi, má kọ ìbáwí Jèhófà; má sì fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ìbáwí àfitọ́nisọ́nà rẹ̀, nítorí pé ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà, àní gẹ́gẹ́ bíi baba ti ń tọ́ ọmọ tí ó dunnú sí.” Ní àfikún sí i, a tún pèsè ìmọ̀ràn bí ti baba nínú Hébérù 12:6-11, ìmọ̀ràn náà rèé: “Ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó máa ń bá wí . . . Lóòótọ́, kò sí ìbáwí tí ó dà bí ohun ìdùnnú nísinsìnyí, bí kò ṣe akó-ẹ̀dùn-ọkàn-báni; síbẹ̀ nígbà tí ó bá yá, fún àwọn tí a ti kọ́ nípasẹ̀ rẹ̀, a máa so èso ẹlẹ́mìí àlàáfíà, èyíinì ni, òdodo.” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a mí sí ni ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀nà pàtàkì fún irú ìbáwí bẹ́ẹ̀.—2 Tímótì 3:16, 17.
18. Ní ti ìrònúpìwàdà, kí la rí kọ́ nínú Lúùkù orí 15?
18 Aláàánú ni Jèhófà. (Ẹ́kísódù 34:6) Táa bá fi ìrònúpìwàdà àtọkànwá hàn kódà lórí ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo jù lọ pàápàá, ó ń nawọ́ ìdáríjì síni. Àní ó lè tún ‘àwọn ọmọ onínàákúnàá’ ti òde òní pàápàá mọ, kí wọ́n sì di ohun èlò fún ìlò ọlọ́lá. (Lúùkù 15:22-24, 32) Ẹ̀ṣẹ̀ wa lè má burú tó ti ọmọ onínàákúnàá. Ṣùgbọ́n fífi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ ṣàmúlò ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ yóò jẹ́ kí a di ẹni tí a tún mọ, tí ó di ohun èlò fún ìlò ọlọ́lá.
19. Báwo ni a ṣe lè máa bá a nìṣó ní jíjẹ́ ohun èlò ọlọ́lá lọ́wọ́ Jèhófà?
19 Nígbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, a pinnu pé a ti múra tán láti jẹ́ kí Jèhófà máa darí wa. A fi àwọn ọ̀nà ayé sílẹ̀, a bẹ̀rẹ̀ sí gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, a sì ṣe ìyàsímímọ́, lẹ́yìn náà, a di Kristẹni tí a batisí. A ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Éfésù 4:20-24, pé ‘kí a bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà wa àtijọ́ ṣe déédéé, pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ atannijẹ, kí a sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.’ Ǹjẹ́ kí àwa fúnra wa máa bá a nìṣó láti jẹ́ ẹni tí Atóbilọ́lá Amọ̀kòkò náà, Jèhófà, lè mọ, kí a lè máa fìgbà gbogbo jẹ́ ohun èlò rẹ̀ fún ìlò ọlọ́lá!
Àtúnyẹ̀wò
◻ Kí ni ète Atóbilọ́lá Amọ̀kòkò náà fún ilẹ̀ ayé wa?
◻ Báwo ni a ṣe lè mọ ẹ́ fún ìlò ọlọ́lá?
◻ Ọ̀nà wo ni a lè gbà mọ àwọn ọmọ wa?
◻ Ojú wo ló yẹ ká fi wo ìbáwí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ṣé a óò mọ ọ́ fún ìlò ọlọ́lá ni tàbí a óò pa ọ́ tì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Àwọn èwe ṣeé mọ láti ìgbà ọmọdé jòjòló