Gbogbo Wa Ló Yẹ Ká Máa Fúnra Wa Níṣìírí
1. Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ wo ni ìbẹ̀wò àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò máa ń ṣe fún wa?
1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ tó wà ní Róòmù pé: “Aáyun ń yun mí láti rí yín, kí n lè fi ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀ fún yín, kí a lè fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in; tàbí, kí a kúkú wí pé, kí pàṣípààrọ̀ ìṣírí lè wà láàárín yín, láti ọ̀dọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ẹnì kejì, tiyín àti tèmi.” (Róòmù 1:11, 12) Ìbẹ̀wò àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò lóde òní máa ń fún wa nírú àǹfààní kan náà láti máa fúnra wa níṣìírí.
2. Kí nìdí tá a fi máa ń ṣèfilọ̀ ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká kó tó di pó bẹ ìjọ wò?
2 Ìjọ: Tó bá ku nǹkan bí oṣù mẹ́ta la ti sábà máa ń ṣèfilọ̀ ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká fún ìjọ. Èyí máa ń mú ká lè ṣètò àkókò wa dáadáa ká bàa lè jàǹfààní látinú ìbẹ̀wò náà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. (Éfé. 5:15, 16) Tó o bá ń ṣiṣẹ́ oṣù, bóyá á ṣeé ṣe fún ẹ láti tọrọ àyè níbi iṣẹ́, kó o lè lọ sóde ẹ̀rí láàárín ọ̀sẹ̀ yẹn. Àwọn kan ti ṣètò láti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù tí alábòójútó àyíká máa bẹ ìjọ wọn wò. Bó o bá ti ṣètò tẹ́lẹ̀ láti rìnrìn àjò lọ́sẹ̀ yẹn, ṣó o lè yí ètò tó o ti ṣe pa dà, kó o bàa lè kọ́wọ́ ti ọ̀sẹ̀ ìbẹ̀wò lẹ́yìn?
3. Kí lẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe lọ́sẹ̀ ìbẹ̀wò ká bàa lè rí ìṣírí gbà?
3 Ìdí pàtàkì tí alábòójútó àyíká fi ń bẹ ìjọ wò ni láti fún wa níṣìírí lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, kó sì tún kọ́ wa báa ṣe lè mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sunwọ̀n sí i. Ṣé wàá forúkọ ẹ sílẹ̀ kó o lè bá a ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí? O sì tún lè láǹfààní láti bá ìyàwó rẹ̀ ṣiṣẹ́, ìyẹn bó bá ti ṣègbéyàwó. Inú alábòójútó àyíká máa ń dùn láti bá onírúurú akéde ṣiṣẹ́, títí kan àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù tàbí àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ lápá ibì kan nínú iṣẹ́ ìwàásù. Gbogbo wa la lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú bó ṣe ń gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ lóde ẹ̀rí, ká sì fi àwọn àbá tó bá fìfẹ́ fún wa sílò. (1 Kọ́r. 4:16, 17) Bó o bá ní kó wá jẹun nílé ẹ, wàá tún láǹfààní láti rí ìṣírí tí ń gbéni ró gbà látọ̀dọ̀ rẹ̀. (Héb. 13:2) Fetí sílẹ̀ dáadáa sáwọn àsọyé tó máa sọ, torí pé ó máa fún àwọn ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ láfiyèsí.
4. Báwo la ṣe lè máa fún alábòójútó àyíká wa níṣìírí?
4 Alábòójútó Àyíká: Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ò yàtọ̀ sí àwọn ará tó bẹ̀ wò ní ti pé òun pàápàá kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro, ó ṣàníyàn nítorí ìjọ, ó sì mọyì ìṣírí táwọn ará fún un. (2 Kọ́r. 11:26-28) Nígbà táwọn ará tó wà ní Róòmù gbọ́ pé Pọ́ọ̀lù ń bọ̀ níbẹ̀ lásìkò tó ń ṣẹ̀wọ̀n, àwọn kan lára wọn rìnrìn àjò lọ sí Ibi Ọjà Ápíọ́sì láti lọ pàdé rẹ̀. Ìrìn àjò kìlómítà mẹ́rìnléláàádọ́rin tan-n-tán! “Bí Pọ́ọ̀lù sì ti tajú kán rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mọ́kànle.” (Ìṣe 28:15) Ẹ̀yin náà lè fún alábòójútó àyíká yín nírú ìṣírí bẹ́ẹ̀. Ẹ máa fún un ní “ọlá ìlọ́po méjì” nípa fífi ìtara ṣètìlẹ́yìn fún ìbẹ̀wò rẹ̀. (1 Tím. 5:17) Ẹ máa fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìwà yín pé ẹ mọrírì akitiyan rẹ̀ lórí yín. Inú òun àti ìyàwó rẹ̀ á dùn bí wọ́n ti ń rí ìgbàgbọ́, ìfẹ́ àti ìfaradà yín.—2 Tẹs. 1:3, 4.
5. Kí nìdí tí gbogbo wa fi nílò ìṣírí lásìkò tá à ń gbé yìí?
5 Ta ló lè sọ pé òun ò nílò ìṣírí ‘láwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò’ tá à ń gbé yìí? (2 Tím. 3:1) Pinnu nísinsìnyí pé ìwọ náà ò ní gbẹ́yìn nígbà tí alábòójútó àyíká bá bẹ ìjọ yín wò lọ́sẹ̀ ìgbòkègbodò alárinrin yẹn. Gbogbo wa pátá, látorí àwọn alábòójútó-arìnrìn àjò tó fi dórí àwa akéde, la lè jọ máa fọ̀yàyà fúnra wa níṣìírí. Bá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò tún ‘máa tu ara wa nínú, a óò sì máa gbé ara wa ró.’—1 Tẹs. 5:11.