Ẹ Máa “Fi Ẹnu Kan” Yin Ọlọ́run Lógo
“Ẹ . . . fi ẹnu kan yin Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi lógo.”—Róòmù 15:6.
1. Ẹ̀kọ́ wo ni Pọ́ọ̀lù kọ́ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ nípa ohun tí wọ́n lè ṣe tí wọ́n bá ní èrò tó yàtọ̀ síra lórí ọ̀ràn kan?
GBOGBO Kristẹni ò lè nífẹ̀ẹ́ sí ohun kan náà tàbí kí ohun kan náà máa wù wọ́n. Síbẹ̀, gbogbo Kristẹni ní láti jọ máa rìn pọ̀ lójú ọ̀nà ìyè. Ǹjẹ́ ìyẹn ṣeé ṣe? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe, tá ò bá sọ ọ̀ràn tí ò tó nǹkan di ńlá mọ ara wa lọ́wọ́. Ẹ̀kọ́ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ní ọ̀rúndún kìíní nìyẹn. Báwo ló ṣe ṣàlàyé kókó pàtàkì yìí? Báwo la sì ṣe lè fi ìmọ̀ràn onímìísí yìí sílò lóde òní?
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Káwọn Kristẹni Wà Níṣọ̀kan
2. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe tẹnu mọ ìjẹ́pàtàkì wíwà níṣọ̀kan?
2 Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn Kristẹni wà níṣọ̀kan, ìdí nìyẹn tó fi gbà wọ́n nímọ̀ràn rere tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa fi ìfẹ́ bá ara wọn gbé. (Éfésù 4:1-3; Kólósè 3:12-14) Síbẹ̀, lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti fìdí ọ̀pọ̀ ìjọ múlẹ̀ tó sì ti bẹ àwọn ìjọ mìíràn wò fún ohun tó lé ní ogún ọdún, ó mọ̀ pé ó lè ṣòro fáwọn ará láti wà níṣọ̀kan. (1 Kọ́ríńtì 1:11-13; Gálátíà 2:11-14) Ìdí rèé tó fi gba àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ní Róòmù níyànjú pé: “Kí Ọlọ́run tí ń pèsè ìfaradà àti ìtùnú yọ̀ǹda fún yín . . . pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, kí ẹ lè fi ẹnu kan yin Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi lógo.” (Róòmù 15:5, 6) Lónìí, àwa náà tá a jẹ́ èèyàn Ọlọ́run tá a sì wà níṣọ̀kan ní láti máa “fi ẹnu kan” yin Jèhófà Ọlọ́run lógo. Báwo la ṣe ń ṣe sí nínú ọ̀ràn yìí?
3, 4. (a) Irú èèyàn wo làwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù jẹ́? (b) Báwo làwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù ṣe lè dẹni tó ń “fi ẹnu kan” sin Jèhófà?
3 Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tí ń bẹ ní Róòmù ló jẹ́ ọ̀rẹ́ Pọ́ọ̀lù. (Róòmù 16:3-16) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tí wọ́n ti wá yàtọ̀ síra, síbẹ̀ Pọ́ọ̀lù gba àwọn arákùnrin rẹ̀ tọwọ́tẹsẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún Ọlọ́run.” Ó kọ ọ́ pé: “Mo fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run mi nípasẹ̀ Jésù Kristi nítorí gbogbo yín, nítorí a ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ yín jákèjádò ayé.” Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ọ̀nà làwọn ará Róòmù gbà jẹ́ àpẹẹrẹ rere. (Róòmù 1:7, 8; 15:14) Síbẹ̀, àwọn kan nínú ìjọ ṣì ní èrò tó yàtọ̀ lórí àwọn ọ̀ràn kan. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kì í ṣe ibì kan náà làwọn Kristẹni tó wà lóde òní ti wá, tí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn sì yàtọ̀ síra, kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀ràn onímìísí tí Pọ́ọ̀lù fúnni nípa ohun tó yẹ kéèyàn ṣe lórí ọ̀ràn èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa “fi ẹnu kan” sọ̀rọ̀.
4 Àwọn onígbàgbọ́ tó jẹ́ Júù àtàwọn onígbàgbọ́ tí kì í ṣe Júù ló wà ní Róòmù. (Róòmù 4:1; 11:13) Ó jọ pé àwọn Kristẹni kan tó jẹ́ Júù kò lè ṣaláì tẹ̀ lé àwọn àṣà kan tí wọ́n ń tẹ̀ lé tẹ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n wà lábẹ́ Òfin Mósè, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí wọ́n ti mọ̀ pé kò dìgbà téèyàn bá tẹ̀ lé irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ kó tó rí ìgbàlà. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn Kristẹni bíi mélòó kan tí wọ́n jẹ́ Júù gbà pé ẹbọ ìràpadà Kristi ti mú àwọn kúrò lábẹ́ àwọn òfin tí wọ́n ń pa mọ́ kí wọ́n tó di Kristẹni. Èyí ni kò jẹ́ kí wọ́n máa hu àwọn ìwà kan tí wọ́n ń hù tẹ́lẹ̀ mọ́, tí wọ́n sì jáwọ́ nínú àwọn àṣà kan tí wọ́n ń tẹ̀ lé tẹ́lẹ̀. (Gálátíà 4:8-11) Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ, “olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún Ọlọ́run” ni gbogbo wọn. Gbogbo wọn lè wá máa “fi ẹnu kan” yin Ọlọ́run lógo, tí wọ́n bá ní èrò tó dáa nípa ara wọn. Èrò àwa náà lónìí lè máà dọ́gba lórí àwọn ọ̀ràn kan, abájọ to fi yẹ ka fara balẹ̀ gbé àlàyé tí Pọ́ọ̀lù ṣe lórí ìlànà pàtàkì yìí yẹ̀ wò.—Róòmù 15:4.
“Ẹ Fi Inú Dídùn Tẹ́wọ́ Gba Ara Yín Lẹ́nì Kìíní-kejì”
5, 6. Kí ló fà á tí èrò àwọn tó wà nínú ìjọ Róòmù fi yàtọ̀ síra?
5 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù, ó sọ pé àwọn ìgbà kan wà tí èrò wọn ò ní bára mu. Ó kọ ọ́ pé: “Ẹnì kan ní ìgbàgbọ́ láti jẹ ohun gbogbo, ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ aláìlera ń jẹ àwọn ọ̀gbìn oko.” Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé kò sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ jẹ ẹlẹ́dẹ̀ lábẹ́ Òfin Mósè. (Róòmù 14:2; Léfítíkù 11:7) Àmọ́ lẹ́yìn ikú Jésù, Òfin náà ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ mọ́. (Éfésù 2:15) Lẹ́yìn ìyẹn, ní nǹkan bí ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ lẹ́yìn tí Jésù kú, áńgẹ́lì kan sọ fún àpọ́sítélì Pétérù pé kò sí oúnjẹ kankan tí Ọlọ́run kà sí aláìmọ̀. (Ìṣe 11:7-12) Nítorí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, àwọn Kristẹni kan tí wọ́n jẹ́ Júù lè máa rò pé àwọn lè jẹ ẹlẹ́dẹ̀ ní tàwọn, tàbí kí wọ́n gbà pé àwọn lè jẹ àwọn oúnjẹ mìíràn kan tí Òfin sọ pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ jẹ tẹ́lẹ̀.
6 Àmọ́ ṣá o, bí àwọn mìíràn lára àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù bá rántí pé àwọn oúnjẹ tí wọ́n kà sí àìmọ́ tẹ́lẹ̀ làwọn kan wá ń jẹ nísinsìnyí, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í kó wọn nírìíra. Inú sì lè bẹ̀rẹ̀ sí í bí àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọ́n gbẹgẹ́ yìí nígbà tí wọ́n bá rí i pé àwọn Júù tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni ń jẹ irú àwọn oúnjẹ bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ní ti àwọn Kristẹni tí kì í ṣe Júù tí ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀ kò ṣòfin kankan nípa oúnjẹ, ó lè jẹ́ ìyàlẹ́nu fún wọn pé àwọn kan ń ṣawuyewuye lórí ọ̀rọ̀ oúnjẹ. Lóòótọ́, kò sóhun tó burú tẹ́nì kan bá lóun ò jẹ irú oúnjẹ kan níwọ̀n bí onítọ̀hún ò bá ti rin kinkin mọ́ ọn pé ẹni tí kò bá kọ irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ pátápátá kò lè rí ìgbàlà. Èrò tó yàtọ̀ síra táwọn èèyàn ní yìí lè tètè dá èdèkòyédè sílẹ̀ nínú ìjọ. Torí náà, ó yẹ káwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù ṣọ́ra kí irú àwọn èrò tó yàtọ̀ yìí má lọ dí wọn lọ́wọ́ fífi “ẹnu kan” yin Ọlọ́run lógo.
7. Èrò tó yàtọ̀ síra wo làwọn èèyàn ní lórí ọ̀rọ̀ pípa ọjọ́ pàtàkì kan mọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀?
7 Pọ́ọ̀lù sọ àpẹẹrẹ kejì, ó ní: “Ẹnì kan ka ọjọ́ kan sí èyí tí ó ga ju òmíràn lọ; ẹlòmíràn ka ọjọ́ kan sí bí gbogbo àwọn yòókù.” (Róòmù 14:5a) Òfin Mósè ò gba ẹnikẹ́ni láyè láti ṣíṣẹ lọ́jọ́ Sábáàtì. Kódà, kì í ṣe gbogbo ibi lèèyàn lè lọ lọ́jọ́ náà. (Ẹ́kísódù 20:8-10; Mátíù 24:20; Ìṣe 1:12) Àmọ́, nígbà tá a mú Òfin Mósè kúrò, gbogbo òfin tó wà nínú rẹ̀ ni kò wúlò mọ́. Síbẹ̀, ọkàn àwọn Kristẹni kan tó jẹ́ Júù lè má balẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tàbí kí wọ́n lọ sọ́nà jíjìn ní ọjọ́ tí wọ́n gbà tẹ́lẹ̀ pé ó jẹ́ ọjọ́ mímọ́. Àní lẹ́yìn tí wọ́n di Kristẹni pàápàá, wọ́n ti lè ya ọjọ́ keje yẹn sọ́tọ̀ fún nǹkan tẹ̀mí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé lójú Ọlọ́run, òfin Sábáàtì ti kásẹ̀ nílẹ̀. Àmọ́, ṣé wọ́n jẹ̀bi tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀? Rárá o, níwọ̀n bí wọn ò bá ti yọ ẹlòmíràn lẹ́nu pé Ọlọ́run sọ pé èèyàn gbọ́dọ̀ pa òfin Sábáàtì mọ́. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi gba ti ẹ̀rí ọkàn àwọn Kristẹni arákùnrin rẹ̀ rò, tó wá kọ̀wé pé: “Kí olúkúlùkù gbà gbọ́ ní kíkún nínú èrò inú òun fúnra rẹ̀.”—Róòmù 14:5b.
8. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù lè gba ti ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíràn rò, kí ni kò yẹ káwọn Kristẹni náà ṣe?
8 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù gba àwọn arákùnrin rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n máa ṣe sùúrù fún àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn gbẹgẹ́, síbẹ̀ ó dẹ́bi fáwọn tó ń fagbára mú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn láti pa Òfin Mósè mọ́ bíi pé ohun ló máa mú kí wọ́n rí ìgbàlà. Bí àpẹẹrẹ, ní nǹkan bí ọdún 61 Sànmánì Tiwa, Pọ́ọ̀lù kọ ìwé Hébérù, tó jẹ́ lẹ́tà alágbára kan sí àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Júù. Pọ́ọ̀lù fi lẹ́tà náà ṣàlàyé yékéyéké pé kò sí àǹfààní kankan nínú pípa Òfin Mósè mọ́ nítorí pé àwọn Kristẹni ní ìrètí tó ga jùyẹn lọ nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù.—Gálátíà 5:1-12; Títù 1:10, 11; Hébérù 10:1-17.
9, 10. Kí ni kò yẹ káwọn Kristẹni máa ṣe? Ṣàlàyé.
9 Gẹ́gẹ́ bá a ti rí i, Pọ́ọ̀lù fi yé wọn pé kò yẹ kí ọ̀rọ̀ èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́ da àárín wọn rú níwọ̀n bí ọ̀ràn náà ò bá ti ta ko ìlànà Kristẹni. Ìdí rèé tí Pọ́ọ̀lù fi béèrè lọ́wọ́ àwọn Kristẹni tí ẹ̀rí ọkàn wọn gbẹgẹ́ pé: “Èé ṣe tí o ń dá arákùnrin rẹ lẹ́jọ́?” Ó wá béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn lágbára (bóyá àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn gbà wọ́n láyè láti jẹ irú àwọn oúnjẹ kan tí Òfin ò gba ẹnikẹ́ni láyè láti jẹ tẹ́lẹ̀ tàbí tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ní ọjọ́ Sábáàtì) pé: “Èé ṣe tí o tún ń fojú tẹ́ńbẹ́lú arákùnrin rẹ?” (Róòmù 14:10) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Pọ́ọ̀lù wí, àwọn Kristẹni tí ẹ̀rí ọkàn wọn gbẹgẹ́ kò gbọ́dọ̀ máa dẹ́bi fáwọn arákùnrin wọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn lágbára ju tiwọn lọ. Bẹ́ẹ̀ náà ni kò yẹ káwọn Kristẹni tí ẹ̀rí ọkàn wọn lágbára máa fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ṣì gbẹgẹ́ láwọn apá ibì kan. Ńṣe ló yẹ kí gbogbo wa máa fara mọ́ èrò rere tí àwọn ẹlòmíràn bá ní, ká má ṣe máa “ro ara [wa] ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.”—Róòmù 12:3, 18.
10 Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàlàyé èrò tó yẹ ká ní rèé, ó ní: “Kí ẹni tí ń jẹ má fojú tẹ́ńbẹ́lú ẹni tí kò jẹ, kí ẹni tí kò sì jẹ má ṣèdájọ́ ẹni tí ń jẹ, nítorí Ọlọ́run ti fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba ẹni yẹn.” Ó tún wá sọ pé: “Kristi pẹ̀lú ti fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà wá, pẹ̀lú ògo fún Ọlọ́run ní iwájú.” Níwọ̀n bí Ọlọ́run àti Kristi ti tẹ́wọ́ gba àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn lágbára àtàwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn gbẹgẹ́, ó yẹ káwa náà ní irú ẹ̀mí yẹn, ká sì “fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba ara” wa. (Róòmù 14:3; 15:7) Ta ló máa wá sọ pé ohun tó yẹ ká ṣe kọ́ nìyẹn?
Ìfẹ́ Ará Ń Mú Káwọn Èèyàn Wà Níṣọ̀kan Lóde Òní
11. Irú ọ̀ràn tó yàtọ̀ wo ló wáyé nígbà ayé Pọ́ọ̀lù?
11 Ọ̀ràn kan tó yàtọ̀ ni Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Róòmù. Kò tíì pẹ́ tí Jèhófà mú májẹ̀mú kan kúrò tó sì dá májẹ̀mú mìíràn. Àmọ́, ó ṣòro fáwọn kan láti máa tẹ̀ lé májẹ̀mú tuntun yìí. Irú nǹkan yẹn gan-an ò sí lóde òní, àmọ́ àwọn nǹkan tó jọ ọ́ máa ń wáyé nígbà mìíràn.
12, 13. Irú àwọn ipò wo làwọn Kristẹni lóde òní ti lè máa gba ti ẹ̀rí ọkàn àwọn arákùnrin wọn rò?
12 Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀sìn tí obìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni ń ṣe tẹ́lẹ̀ lè jẹ́ èyí tó fẹ́ káwọn ọmọ ìjọ wọn máa múra láìlo ohun èlò ìṣaralóge kankan. Nígbà tí irú obìnrin bẹ́ẹ̀ bá wá sínú òtítọ́, ó lè ṣòro fún un láti fara mọ́ èrò tuntun náà pé kó sóhun tó burú nínú kéèyàn máa wọ aṣọ tó bójú mu, tó ní oríṣiríṣi àwọ̀, láwọn àkókò yíyẹ tàbí kéèyàn máa lo àwọn ohun èlò ìṣaralóge níwọ̀nba. Níwọ̀n bí èyí kò bá ti ta ko ìlànà Bíbélì kankan, kò ní dáa kí ẹnì kan wá máa sọ fún irú obìnrin Kristẹni yìí pé kó ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ sọ fún un pé ó lòdì. Òun náà sì gbọ́dọ̀ mọ̀ pé kò yẹ kóun máa ṣàríwísí àwọn obìnrin Kristẹni tí ẹ̀rí ọkàn wọn gbà wọ́n láyè láti lo irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀.
13 Gbé àpẹẹrẹ mìíràn yẹ̀ wò. Ó lè jẹ́ àdúgbò táwọn èèyàn ti gbà pé kò dáa kéèyàn máa mutí ni ọkùnrin Kristẹni kan gbé dàgbà. Lẹ́yìn tó ti wá gba ìmọ̀ òtítọ́, ó wá lóye ohun tí Bíbélì sọ nípa wáìnì, ìyẹn ni pé ó jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti pé èèyàn lè mú un níwọ̀nba. (Sáàmù 104:15) Ó fara mọ́ èrò yẹn. Àmọ́ ṣá o, nítorí ibi tó ti wá, kì í mutí rárá, ṣùgbọ́n kì í ṣàríwísí àwọn tó ń mutí níwọ̀nba. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ló fi ń ṣèwà hù, èyí tó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà àti àwọn ohun tí ń gbéni ró fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.”—Róòmù 14:19.
14. Àwọn ipò wo làwọn Kristẹni ti lè fi ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará Róòmù sílò?
14 Àwọn ipò mìíràn gba pé kéèyàn máa fi ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nínú ìmọ̀ràn tó fún àwọn ará Róòmù ṣèwà hù. Onírúurú èèyàn ló wà nínu ìjọ Kristẹni, ohun tó sì wu kálukú yàtọ̀ síra. Nítorí náà, ohun tẹ́nì kan fẹ́ lè yàtọ̀ sí tẹlòmíràn, àpẹẹrẹ kan ni ti aṣọ wíwọ̀ àti ọ̀nà ìgbàmúra. Àmọ́, Bíbélì ṣe àwọn ìlànà kan tí gbogbo Kristẹni tòótọ́ ń tẹ̀ lé. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tó yẹ kó máa wọ aṣọ tí kò bójú mu tàbí kó máa ṣe irun tí kò yẹ ọmọlúwàbí tàbí èyí tó máa fi hàn pé à ń kó àṣà ayé. (1 Jòhánù 2:15-17) Àwọn Kristẹni ò gbàgbé pé gbogbo ìgbà làwọn jẹ́ òjíṣẹ́ tó ń ṣojú fún Ọba Aláṣẹ Ayé òun Ọ̀run, àní ní àsìkò tọ́wọ́ wọn bá dilẹ̀ pàápàá. (Aísáyà 43:10; Jòhánù 17:16; 1 Tímótì 2:9, 10) Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ nǹkan tó dáa ló wà tó jẹ́ pé àwọn Kristẹni lè yan èyí tó wù wọ́n lára wọn.a
Má Ṣe Mú Àwọn Ẹlòmíràn Kọsẹ̀
15. Irú ipò wo ló lè mú kí Kristẹni kan má ṣe ohun tó wù ú?
15 Ìlànà pàtàkì kan tún rèé tí Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ nínú ìmọ̀ràn tó gba àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù. Nígbà míì, Kristẹni kan tó ní ẹ̀rí ọkàn tó dáa lè pinnu pé òun ò ní ṣe ohun kan bó tilẹ̀ jé pé ohun náà kó burú. Kí nìdí? Ìdí ni pé, ó mọ̀ pé ohun tóun bá ṣe lè ṣàkóbá fáwọn ẹlòmíì. Kí lohun tó yẹ ká ṣe ní irú ipò yẹn? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ó dára láti má ṣe jẹ ẹran tàbí mú wáìnì tàbí ṣe ohunkóhun tí yóò mú arákùnrin rẹ kọsẹ̀.” (Róòmù 14:14, 20, 21) Nípa bẹ́ẹ̀, “ó yẹ kí àwa tí a ní okun máa ru àìlera àwọn tí kò lókun, kí a má sì máa ṣe bí ó ti wù wá. Kí olúkúlùkù wa máa ṣe bí ó ti wu aládùúgbò rẹ̀ nínú ohun rere fún gbígbé e ró.” (Róòmù 15:1, 2) Nígbà tá a bá rí i pé nǹkan tá a fẹ́ ṣe lè ṣàkóbá fún ẹ̀rí ọkàn ẹnì kan tá a jọ jẹ́ Kristẹni, ó yẹ kí ìfẹ́ ará mú ká gba tirẹ̀ rò, kà pa ohun tá a fẹ́ ṣe náà tì. Àpẹẹrẹ kan lè jẹ́ ọ̀rọ̀ nípa ọtí mímu. Kò sóhun tó burú tí Kristẹni kan bá mu wáìnì níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Àmọ́ tí wáìnì náà bá máa mú ẹlòmíràn kọsẹ̀, kò ní sọ pé òun máa mu ún dandan.
16. Báwo la ṣe lè máa gba tàwọn tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ wa rò?
16 A tún lè lo ìlànà yìí nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn tí kì í ṣe ara ìjọ Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, a lè máa gbé ní àgbègbè kan tí ìsìn táwọn tó pọ̀ jù lọ níbẹ̀ ń ṣe ti máa ń sọ fáwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ pé kí wọ́n ya ọjọ́ kan láàárín ọ̀sẹ̀ sọ́tọ̀ fún ìsinmi. Nítorí èyí, ká má bàa mú wọn kọsẹ̀, kó má sì dí iṣẹ́ ìwàásù lọ́wọ́, a ò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa bí wọn nínú nírú ọjọ́ bẹ́ẹ̀. Àpẹẹrẹ mìíràn ni pé, Kristẹni kan tó jẹ́ olówó lè ṣí lọ síbi táwọn Ẹlẹ́rìí kò ti pọ̀ tó, kó lọ má gbé láàárín àwọn tálákà. Ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í gba tàwọn ẹlòmíràn rò nípa mímúra níwọ̀ntúnwọ̀nsì tàbí kó má máa lo àwọn nǹkan olówó ńlá.
17. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká gba tàwọn ẹlòmíràn rò nígbà tá a bá fẹ ṣe ohun kan tó wù wá?
17 Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu pé káwọn “tí [ó] ní okun” ṣe irú ìyípadà yẹn? Ronú nípa àpèjúwe yìí: Ká ní pé à ń wakọ̀ lọ lójú títì, tá a wá rí àwọn ọmọdé kan tó ń rìn sún mọ́ títì. Ṣé a óò ṣì máa fọkọ̀ sáré ní ìwọ̀n tí àṣẹ gbà wá láyè dé nítorí pé òfin sọ pé a lè ṣe bẹ́ẹ̀? Rárá o, ńṣe la máa tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́ ká má bàa ṣe àwọn ọmọ náà léṣe. Nígbà mìíràn, ó gba pé ká ṣe sùúrù nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ àtàwọn ẹlòmíràn. A lè máa ṣe ohun kan tá a lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe, tí kò tẹ ìlànà Bíbélì kankan lójú. Síbẹ̀, tí èyí bá máa mú ká ṣẹ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn gbẹgẹ́ tàbí tó bá máa ṣàkóbá fún wọn, ìfẹ́ Kristẹni yóò mú ká ṣọ́ra. (Róòmù 14:13, 15) Ìṣọ̀kan Kristẹni àti gbígbé ire Ìjọba Ọlọ́run lárugẹ ṣe pàtàkì ju ṣíṣe ohun tá a lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe.
18, 19. (a) Báwo la ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú gbígba tàwọn ẹlòmíràn rò? (b) Nínú àwọn ọ̀ràn wo ni gbogbo wa ti máa ń ṣe ohun tí kò yàtọ̀ síra, kí sì ni a óò gbè yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
18 Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àpẹẹrẹ tó dára jù lọ là ń tẹ̀ lé yẹn. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kristi pàápàá kò ṣe bí ó ti wu ara rẹ̀; ṣùgbọ́n gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ti ṣubú lù mí.’” Jésù tiẹ̀ ṣe tán láti fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ nítorí wa. Ó dájú pé, àwa náà ṣe tán láti yááfì lára àwọn ohun tá a lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe tí ìyẹn bá máa jẹ́ kí àwa àtàwọn “tí kò lókun” jùmọ̀ máa fi ògo fún Ọlọ́run. Ní ti tòótọ́, gbígbà tá a bá ń gba tàwọn Kristẹni tí ẹ̀rí ọkàn wọn gbẹgẹ́ rò tàbí tá à ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìṣe àwọn ohun tó wù wá, tá ò sì rin kinkin mọ́ ẹ̀tọ́ wa, èyí fi hàn pé a ní irú “ẹ̀mí ìrònú kan náà tí Kristi Jésù ní.”—Róòmù 15:1-5.
19 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èrò wa lè yàtọ̀ síra nínú àwọn ọ̀ràn kan tí kò sí ìlànà Ìwé Mímọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, àmọ́ èrò wa kò yàtọ̀ síra tó bá kan ọ̀ràn ìjọsìn. (1 Kọ́ríńtì 1:10) Bí àpẹẹrẹ, ohun tá a máa ń ṣe kì í yàtọ̀ síra nígbà táwọn kan bá ta ko ìjọsìn tòótọ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pe àwọn alátakò bẹ́ẹ̀ ní àjèjì, ó sì tún kìlọ̀ fún wa pé ká ṣọ́ra fun “ohùn àwọn àjèjì.” (Jòhánù 10:5) Báwo la ṣe lè dá àwọn àjèjì wọ̀nyí mọ̀? Báwo ló ṣe yẹ ká hùwà sí wọn? A ó gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn òbí ọmọ tí ò tíì tójúúbọ́ ló ń pinnu irú aṣọ táwọn ọmọ wọn máa wọ̀ fún wọn.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí nìdí tí èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tá a bá ní lórí àwọn ọ̀ràn kan kò ní ká máa wà níṣọ̀kan?
• Kí nìdí tó fi yẹ kí àwa tá a jẹ́ Kristẹni máa fìfẹ́ gba ti ara wa rò?
• Kí ni àwọn ọ̀nà mélòó kan tá a lè gbà tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù nípa ìṣọ̀kan lónìí, kí sì ni yóò sún wa ṣe bẹ́ẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù nípa ìṣọ̀kan ṣe pàtàkì fún ìjọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn Kristẹni wà níṣọ̀kan bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi tí wọ́n ti wá àti irú ẹni tí wọ́n jẹ́ tẹ́lẹ̀ yàtọ̀ síra
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Kí ló yẹ kí awakọ̀ yìí ṣe báyìí?