Pọ́ọ̀lù Ṣètò Ọrẹ Àfiṣèrànwọ́ Fáwọn Ẹni Mímọ́
IRE tẹ̀mí ló jẹ àwọn Kristẹni tòótọ́ lógún jù lọ. Síbẹ̀síbẹ̀, àníyàn nípa àlàáfíà àwọn ẹlòmíràn tún ṣe pàtàkì sí wọn pẹ̀lú. Wọ́n sábà máa ń pèsè fáwọn tó níṣòro. Ìfẹ́ ará ló ń mú kí àwọn Kristẹni ṣèrànwọ́ fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹ́gbẹ́ wọn tó jẹ́ aláìní.—Jòhánù 13:34, 35.
Ìfẹ́ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní sí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ̀ nípa tẹ̀mí ló mú kó ṣètò ìdáwó láàárín àwọn ìjọ tó wà ní Ákáyà, Gálátíà, Makedóníà, àti àgbègbè Éṣíà. Kí ló mú kí èyí pọndandan? Báwo ló ṣe ṣètò ọrẹ àfiṣèrànwọ́ náà? Ẹ̀mí wo làwọn èèyàn fi gbà á? Èé sì ti ṣe tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó ṣẹlẹ̀?
Ipò Tí Ìjọ Jerúsálẹ́mù Wà
Lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe tó ti ibòmíràn wá di ọmọ ẹ̀yìn ní Pẹ́ńtíkọ́sì dúró ní Jerúsálẹ́mù fúngbà díẹ̀ láti túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀sìn tòótọ́. Níbi tí àwọn tó dúró fúngbà díẹ̀ bẹ́ẹ̀ bá ti nílò ìrànlọ́wọ́, àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn fi tayọ̀tayọ̀ gbọ́ bùkátà wọn. (Ìṣe 2:7-11, 41-44; 4:32-37) Ó lè jẹ́ rúkèrúdò tó bẹ́ sílẹ̀ ní ìgboro ló mú kí àìní náà túbọ̀ pọ̀ sí i, níwọ̀n bí àwọn Júù tó nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè wọn ti máa ń dá ọ̀tẹ̀ àti rògbòdìyàn sílẹ̀. Wọ́n ṣètò ìpínfúnni ojoojúmọ́ fún àwọn opó, kí ebi má bàa pa ẹnikẹ́ni tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi. (Ìṣe 6:1-6) Hẹ́rọ́dù ń ṣe inúnibíni líle koko sí ìjọ náà, nígbà tó sì di nǹkan bí ọdún 44 sí 46 Sànmánì Tiwa, ìyàn bẹ́ sílẹ̀ ní Jùdíà. Ní ti àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, gbogbo èyí lè yọrí sí ohun tí Pọ́ọ̀lù pè ní “ìjìyà,” “ìpọ́njú,” àti “pípiyẹ́ àwọn nǹkan ìní [wọn].”—Hébérù 10:32-34; Ìṣe 11:27-12:1.
Ipò náà ṣì burú jáì ní nǹkan bí ọdún 49 Sànmánì Tiwa. Nípa bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn tí Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánù ti fohùn ṣọ̀kan pé kí Pọ́ọ̀lù lọ máa wàásù láàárín àwọn Kèfèrí, wọ́n rọ̀ ọ́ pé kí ó “fi àwọn òtòṣì sọ́kàn.” Ohun tí Pọ́ọ̀lù sì ń tiraka láti ṣe nìyẹn.—Gálátíà 2:7-10.
Ṣíṣètò Ìdáwó Náà
Pọ́ọ̀lù bójú tó owó tí wọ́n dá fún àwọn Kristẹni tó jẹ́ aláìní ní Jùdíà. Ó sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì ní nǹkan bí ọdún 55 Sànmánì Tiwa pé: “Ní ti àkójọ tí ó wà fún àwọn ẹni mímọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pa àṣẹ ìtọ́ni fún àwọn ìjọ Gálátíà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin tìkára yín ṣe pẹ̀lú. Ní gbogbo ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín ní ilé ara rẹ̀ ya ohun kan sọ́tọ̀ gedegbe ní ìpamọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti lè máa láásìkí . . . [Lẹ́yìn náà] àwọn ọkùnrin yòówù tí ẹ bá tẹ́wọ́ gbà nípasẹ̀ àwọn lẹ́tà, àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò rán láti gbé ẹ̀bùn inú rere yín lọ sí Jerúsálẹ́mù.” (1 Kọ́ríńtì 16:1-3) Ọdún kan lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù sọ pé Makedóníà àti Ákáyà ń lọ́wọ́ sí i. Nígbà tí wọ́n sì kó gbogbo rẹ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù, bí àwọn aṣojú láti àgbègbè Éṣíà ṣe wà níbẹ̀ fi hàn pé àwọn ìjọ tó wà lágbègbè yẹn náà ti dáwó.—Ìṣe 20:4; 2 Kọ́ríńtì 8:1-4; 9:1, 2.
Kò sẹ́ni tí wọ́n fagbára mú láti ṣe ju agbára rẹ̀ lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, kí nǹkan lè bára dọ́gba ni, kí àṣẹ́kùsílẹ̀ èyíkéyìí lè dí àìní àwọn ẹni mímọ́ tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà. (2 Kọ́ríńtì 8:13-15) Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.”—2 Kọ́ríńtì 9:7.
Àpọ́sítélì náà jẹ́ kí àwọn ará Kọ́ríńtì mọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n jẹ́ ọ̀làwọ́. Jésù ‘di òtòṣì nítorí wọn, kí wọ́n lè di ọlọ́rọ̀’ nípa tẹ̀mí. (2 Kọ́ríńtì 8:9) Ó dájú pé wọ́n á fẹ́ fara wé ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tó ní. Síwájú sí i, níwọ̀n bí Ọlọ́run ti ń sọ wọ́n di ọlọ́rọ̀ “fún gbogbo onírúurú ìwà ọ̀làwọ́,” ó yẹ kí àwọn náà ṣèrànwọ́ láti bójú tó àìní àwọn ẹni mímọ́.—2 Kọ́ríńtì 9:10-12.
Ẹ̀mí Tí Àwọn Tó Kópa Ní
A lè kọ́ ohun púpọ̀ nípa ọrẹ àtinúwá táa bá ronú nípa ìṣarasíhùwà àwọn tó kópa nínú ètò àfiṣèrànwọ́ tí wọ́n ṣe fún àwọn ẹni mímọ́ ní ọ̀rúndún kìíní. Ìdáwó náà kọjá kìkì àníyàn fún àwọn aláìní tí wọ́n jọ jẹ́ olùjọsìn Jèhófà. Ó fi hàn pé ìdè ẹgbẹ́ àwọn ará wà láàárín àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí tó jẹ́ Kristẹni. Fífi ẹ̀bùn ránṣẹ́ àti títẹ́wọ́ gbà á fi hàn pé ìṣọ̀kan àti ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wà láàárín àwọn Kèfèrí àtàwọn Júù wọ̀nyí. Wọ́n jọ ń ṣàjọpín nǹkan ti ara àti ti ẹ̀mí ni.—Róòmù 15:26, 27.
Ó ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù máà pe àwọn Kristẹni tó wà ní Makedóníà láti kópa—nítorí pé àwọn náà wà ní ipò àìnílọ́wọ́ rárá. Àmọ́, wọ́n ‘ń bẹ̀bẹ̀ ṣáá fún àǹfààní ìfúnni.’ Họ́wù, àní bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n wà nínú “ìdánwò ńlá lábẹ́ ìṣẹ́níṣẹ̀ẹ́,” síbẹ̀ wọ́n fi tayọ̀tayọ̀ fúnni “ré kọjá agbára wọn gan-an”! (2 Kọ́ríńtì 8:1-4) Ó hàn gbangba pé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n pé wọ́n ń ṣe ẹ̀sìn tó lòdì sí òfin àwọn ará Róòmù wà lára ohun tó mú kí wọ́n wà lábẹ́ ìdánwò ńlá. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò fún àwọn arákùnrin wọn tó dojú kọ irú ìpọ́njú bẹ́ẹ̀ ní Jùdíà.—Ìṣe 16:20, 21; 17:5-9; 1 Tẹsalóníkà 2:14.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ti lo ìtara tí àwọn ará Kọ́ríńtì ní sí ọrẹ náà níbẹ̀rẹ̀ láti gba àwọn ará Makedóníà níyànjú, ìtara àwọn ará Kọ́ríńtì ti wá ń jó rẹ̀yìn. Ẹ̀mí ọ̀làwọ́ àwọn ará Makedóníà ni àpọ́sítélì náà wá ń tọ́ka sí báyìí láti mú kí àwọn ará Kọ́ríńtì ṣe ohun tó yẹ. Ó rí i pé ó pọndandan láti rán wọn létí pé àkókò ti tó fún wọn láti parí ohun tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ láti ọdún kan sẹ́yìn. Kí ló ti ṣẹlẹ̀ ná?—2 Kọ́ríńtì 8:10, 11; 9:1-5.
Títù ló ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ gbígba ìdáwó náà ní Kọ́ríńtì, àmọ́ àwọn ìṣòro kan dìde tó jọ pé kò jẹ́ kí gbogbo ìsapá rẹ̀ kẹ́sẹ járí. Lẹ́yìn tí Títù lọ rí Pọ́ọ̀lù ní Makedóníà, òun àtàwọn méjì mìíràn ni wọ́n jọ padà wá láti wá ta ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì jí pé kí wọ́n parí ìdáwó náà. Àwọn kan ti lè ronú pé ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ń gbìyànjú àtikó àwọn ará Kọ́ríńtì nífà. Bóyá ìdí nìyí tó fi rán àwọn ọkùnrin mẹ́ta sí wọn láti parí ìdáwó náà, tó sì sọ̀rọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní rere. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “A ń yẹra fún jíjẹ́ kí ẹnikẹ́ni rí àléébù kà sí wa lọ́rùn ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ọrẹ aláìṣahun tí a óò pín fúnni. Nítorí àwa ‘ń ṣe ìpèsè aláìlábòsí, kì í ṣe níwájú Jèhófà nìkan, ṣùgbọ́n níwájú àwọn ènìyàn pẹ̀lú.’”—2 Kọ́ríńtì 8:6, 18-23; 12:18.
Fífi Ọrẹ Náà Jíṣẹ́
Ní ìgbà ìrúwé ọdún 56 Sànmánì Tiwa, owó tí wọ́n dá náà ti wà ní sẹpẹ́ láti kó lọ sí Jerúsálẹ́mù. Pọ́ọ̀lù àtàwọn aṣojú tí àwọn tó ṣe ìdáwó náà yàn ló máa lọ. Ìṣe 20:4 sọ pé: “Àwọn tí ń bá a lọ ni Sópátérì ọmọkùnrin Párù ará Bèróà, Àrísítákọ́sì àti Sẹ́kúńdù àwọn ará Tẹsalóníkà, àti Gáyọ́sì ará Déébè, àti Tímótì, àti láti àgbègbè Éṣíà Tíkíkù àti Tírófímù.” Ó hàn gbangba pé Lúùkù wà lára wọn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ló wá ṣojú fún àwọn Kristẹni tó wà ní Fílípì. Nípa bẹ́ẹ̀, ó kéré tán àwọn ọkùnrin mẹ́sàn-án ló lọ fún iṣẹ́ yìí.
Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nì, Dieter Georgi, sọ pé: “Àpapọ̀ owó tí wọ́n rí kó jọ ní láti pọ̀ gan-an, nítorí akitiyan tí wọ́n ṣe níkẹyìn tó kan Pọ́ọ̀lù àti ọ̀pọ̀ aṣojú wọ̀nyẹn, àti wàhálà àti ìnáwó tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ kì bá ti sí rárá tó bá jẹ́ pé owó kékeré ni.” Kì í ṣe tìtorí ààbò nìkan ni àwọn aṣojú wọ̀nyẹn ṣe lọ, bí kò ṣe kí wọ́n tún lè jẹ́rìí gbe Pọ́ọ̀lù tí a bá rí ẹnikẹ́ni tó fẹ́ fi ẹ̀sùn àìṣòótọ́ kàn án. Àwọn tí wọ́n rán náà ṣojú fún àwọn ìjọ Kèfèrí níwájú àwọn ẹni mímọ́ ní Jerúsálẹ́mù.
Bí àwọn aṣojú wọ̀nyí ti gbéra láti Kọ́ríńtì tí wọ́n forí lé Síríà, ìgbà Ìrékọjá ni wọn ì bá dé Jerúsálẹ́mù. Àmọ́, wọ́n ní láti yí ètò tí wọ́n ṣe padà nígbà tí wọ́n gbọ́ pé àwọn kan fẹ́ pa Pọ́ọ̀lù. (Ìṣe 20:3) Bóyá àwọn ọ̀tá rẹ̀ ń pète láti pa á sójú òkun.
Pọ́ọ̀lù tún ń ṣe àwọn àníyàn mìíràn. Kó tó gbéra, ó kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí òun ‘lè rí ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ ní Jùdíà àti kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun tí ó wà fún Jerúsálẹ́mù lè já sí ìtẹ́wọ́gbà fún àwọn ẹni mímọ́.’ (Róòmù 15:30, 31) Bó tilẹ̀ dájú pé àwọn ẹni mímọ́ máa fi ìmọrírì tó jinlẹ̀ hàn fún ọrẹ náà, síbẹ̀ Pọ́ọ̀lù lè máa ṣàníyàn nípa wàhálà tí dídé òun máa dá sílẹ̀ láàárín àwọn Júù lápapọ̀.
Ó dájú pé àpọ́sítélì náà ní àwọn aláìní lọ́kàn. Bí Ìwé Mímọ́ ò tiẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí wọ́n fi ọrẹ náà jíṣẹ́, síbẹ̀ nígbà tí wọ́n fi jíṣẹ́, ó fi kún ìṣọ̀kan tó wà láàárín wọn, ó sì jẹ́ kí àwọn Kristẹni tó jẹ́ Kèfèrí fi ìmoore hàn fún àwọn ọrọ̀ tẹ̀mí tí wọ́n rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn ará Jùdíà tó jẹ́ onígbàgbọ́ bíi ti wọn. Fífi tí Pọ́ọ̀lù fara hàn ní tẹ́ńpìlì láìpẹ́ sí àkókò tó dé sí Jerúsálẹ́mù ló fa ìjà ìgboro àti mímú tí wọ́n mú un. Àmọ́ èyí ló wá fún un láǹfààní nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín láti jẹ́rìí fún àwọn gómìnà àtàwọn ọba.—Ìṣe 9:15; 21:17-36; 23:11; 24:1-26:32.
Àwọn Ọrẹ Tiwa Lóde Òní
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ti yí padà láti ọ̀rúndún kìíní—àmọ́ àwọn ìlànà táa ti là sílẹ̀ kò tíì yí padà. A ń jẹ́ kí àwọn Kristẹni mọ̀ nípa owó táa nílò. Ọrẹ èyíkéyìí tí wọ́n bá fún àwọn aláìní gbọ́dọ̀ jẹ́ àtinúwá, tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run àtàwọn ènìyàn ẹlẹ́gbẹ́ wọn ń sún wọn ṣe.—Máàkù 12:28-31.
Ètò ìpèsè ìrànwọ́ tí wọ́n ṣe nítorí àwọn ẹni mímọ́ ní ọ̀rúndún kìíní fi hàn pé pípín irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ fúnni gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí a ṣètò rẹ̀ dáadáa, táa sì bójú tó lọ́nà tí kò lábòsí rárá. Dájúdájú, Jèhófà Ọlọ́run mọ àwọn àìní wa, ó sì ń pèsè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kí wọ́n lè máa bá sísọ̀rọ̀ nípa ìhìn rere Ìjọba náà fún àwọn ẹlòmíràn nìṣó láìfi àwọn ìṣòro pè. (Mátíù 6:25-34) Síbẹ̀, gbogbo wa lè ṣe ipa tiwa, bó ti wù kí ipò ìṣúnná owó wa rí. Nípa bẹ́ẹ̀, ‘ẹni tí ó ní púpọ̀, ohun tó ní kò ní pọ̀ jù, ẹni tí ó sì ní díẹ̀, ohun tó ní kò ní kéré jù.’—2 Kọ́ríńtì 8:15.