Àwọn Ìbùyẹ̀rì Ìmọ́lẹ̀ Ní Àkókò Àwọn Aposteli
“Ìmọ́lẹ̀ fúnra rẹ̀ ti bùyẹ̀rì fún àwọn olódodo, àní ìhó-ayọ̀ pàápàá fún àwọn ọlọ́kàn-àyà dídúró ṣánṣán.”—ORIN DAFIDI 97:11, NW.
1. Báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lónìí ṣe farajọ àwọn Kristian ìjímìjí?
ẸWO bí àwa, gẹ́gẹ́ bí Kristian tòótọ́, ṣe mọrírì àwọn ọ̀rọ̀ Orin Dafidi 97:11 yìí tó! ‘Ìmọ́lẹ̀ ti bùyẹ̀rì’ fún wa léraléra. Níti tòótọ́, àwọn kan lára wa ti rí ìmọ́lẹ̀ Jehofa tí ń bùyẹ̀rì fún àwọn ẹ̀wádún. Gbogbo èyí rán wa létí Owe 4:18, tí ó kà pé: “Ipa-ọ̀nà àwọn olóòótọ́ dàbí títàn ìmọ́lẹ̀, tí ó ń tàn síwájú àti síwájú títí di ọ̀sángangan.” Nítorí a mọrírì Ìwé Mímọ́ ju àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ lọ, àwa Ẹlẹ́rìí Jehofa dàbíi àwọn Kristian ìjímìjí. A lè rí ìhùwàsí wọn kedere nínú àwọn ìwé ìtàn ti Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki àti láti inú àwọn lẹ́tà rẹ̀, tí a kọ lábẹ́ ìmísí àtọ̀runwá.
2. Àwọn ohun wo ni ó wà lára àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu rí gbà?
2 Lára àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu Kristi ní ìjímìjí kọ́kọ́ rí gbà ni àwọn wọnnì tí ó níí ṣe pẹ̀lú Messia náà. Anderu sọ fún Simoni Peteru arákùnrin rẹ̀ pé: “Awa ti rí Messia naa.” (Johannu 1:41) Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn náà, Bàbá tí ń bẹ ní ọ̀run mú kí ó ṣeé ṣe fún aposteli Peteru láti jẹ́rìí sí i ní ọ̀nà tí ó bá ojú-ìwòye yẹn mu nígbà tí ó sọ fún Jesu Kristi pé: “Iwọ ni Kristi naa, Ọmọkùnrin Ọlọrun alààyè.”—Matteu 16:16, 17; Johannu 6:68, 69.
Ìmọ́lẹ̀ Tí Ó Níí Ṣe Pẹ̀lú Iṣẹ́ Ìwàásù Tí A Paláṣẹ fún Wọn
3, 4. Lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀, ìlàlóye wo ni Jesu fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa ìgbòkègbodò ọjọ́-ọ̀la wọn?
3 Lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀, Jesu Kristi fúnni ní àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ nípa iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe tí ó já lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ léjìká. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé àwọn 500 ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n péjọ ní Galili ni ó sọ fún pé: “Nitori naa ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ awọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba ati ti Ọmọkùnrin ati ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn lati máa pa gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún yín mọ́. Sì wò ó! mo wà pẹlu yín ní gbogbo awọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ awọn nǹkan.” (Matteu 28:19, 20; 1 Korinti 15:6) Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi gbọ́dọ̀ di oníwàásù, iṣẹ́ ìwàásù tí a paláṣẹ fún wọn kò sì gbọ́dọ̀ mọ sọ́dọ̀ “awọn àgùtàn ilé Israeli tí wọ́n sọnù.” (Matteu 10:6) Bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò níláti ṣe ìbatisí irú èyí ti Johannu ṣe gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n níláti batisí àwọn ènìyàn “ní orúkọ Baba ati ti Ọmọkùnrin ati ti ẹ̀mí mímọ́.”
4 Gẹ́rẹ́ ṣáájú kí Jesu tó gòkè lọ sí ọ̀run, àwọn aposteli rẹ̀ 11 olùṣòtítọ́ béèrè pé: “Oluwa, iwọ ha ń mú ìjọba padàbọ̀sípò fún Israeli ní àkókò yii bí?” Dípò dídáhùn ìbéèrè yẹn, Jesu fún wọn ní ìtọ́ni síwájú síi nípa iṣẹ́ ìwàásù tí a paláṣẹ fún wọn, ní sísọ pé: “Ẹ̀yin yoo gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá dé sórí yín, ẹ óò sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerusalemu ati ní gbogbo Judea ati Samaria ati títí dé apá ibi jíjìnnà jùlọ ní ilẹ̀-ayé.” Títí di àkókò yẹn, wọ́n ti ń jẹ́rìí nípa Jehofa nìkan, ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọn yóò tún jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Kristi.—Ìṣe 1:6-8.
5, 6. Àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ wo ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu rí gbà ní Pentekosti?
5 Ọjọ́ mẹ́wàá péré lẹ́yìn náà, ẹ wo irú àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ títànyòò tí àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu rí gbà! Ní ọjọ́ Pentekosti 33 C.E., fún ìgbà àkọ́kọ́, wọ́n mọrírì ìjẹ́pàtàkì Joeli 2:28, 29 tí ó sọ pé: “Èmi [Jehofa] óò tú ẹ̀mí mi jáde sí ara ènìyàn gbogbo; àti àwọn ọmọ yin ọkùnrin, àti àwọn ọmọ yin obìnrin yóò máa sọtẹ́lẹ̀, àwọn arúgbó yin yóò máa lá àlá, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yin yóò máa ríran. Àti pẹ̀lú sí ara àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ọkùnrin, àti sí ara àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ obìnrin, ni èmi óò tú ẹ̀mí mí jáde ní ọjọ́ wọnnì.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu rí ẹ̀mí mímọ́, ní ìrísí ahọ́n bí iná, tí ó bà lé orí gbogbo wọn—nǹkan bí 120 ọkùnrin àti obìnrin—tí wọ́n péjọ ní Jerusalemu.—Ìṣe 1:12-15; 2:1-4.
6 Bákan náà ní ọjọ́ Pentekosti, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kọ́kọ́ lóye pé àwọn ọ̀rọ̀ Orin Dafidi 16:10 ń tọ́ka sí Jesu Kristi tí ó ti jíǹde. Onipsalmu náà sọ pé: “Ìwọ [Jehofa Ọlọrun] kì yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ ní ipò-òkú; bẹ́ẹ̀ni ìwọ kì yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ kí ó rí ìdibàjẹ́.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn kò lè máa tọ́ka sí Ọba Dafidi, nítorí pé ibojì rẹ̀ wà pẹ̀lú wọn títí di ọjọ́ yẹn. Abájọ ti àwọn bíi 3,000 lára àwọn tí wọ́n gbọ́ bí a ṣe ṣàlàyé ìmọ́lẹ̀ titun yìí fi gbàgbọ́ dájú tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ṣe batisí ní ọjọ yẹn gan-an!—Ìṣe 2:14-41.
7. Ìmọ́lẹ̀ títànyòò wo ni aposteli Peteru rí gbà nígbà ìbẹ̀wò rẹ̀ sọ́dọ̀ Korneliu ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Romu?
7 Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, àwọn ọmọ Israeli mọrírì ohun tí Ọlọrun sọ nípa wọn pé: “Ẹ̀yin nìkan ni mo mọ̀ nínú gbogbo ìdílé ayé.” (Amosi 3:2) Nítorí náà ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ títànyòò níti tòótọ́ ni aposteli Peteru àti àwọn wọnnì tí wọ́n bá a lọ sí ilé ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Romu náà Korneliu rí gbà nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bà lé àwọn Kèfèrí aláìkọlà aláìgbàgbọ́ fún ìgbà àkọ́kọ́. Ó yẹ fún àfiyèsí pé èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí a óò fúnni ní ẹ̀mí mímọ́ ṣáájú ìbatisí. Ṣùgbọ́n èyí pọndandan. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, Peteru kì bá má ti mọ̀ pé àwọn Kèfèrí aláìkọlà wọ̀nyí tóótun fún ìbatisí. Níwọ̀n bí ó ti mọrírì ìjẹ́pàtàkì ohun mériyìírí yìí, Peteru béèrè pé: “Ẹnikẹ́ni ha lè ka omi léèwọ̀ tí ó fi jẹ́ pé a kò ní batisí awọn wọnyi [àwọn Kèfèrí] tí wọ́n ti rí ẹ̀mí mímọ́ gbà àní gẹ́gẹ́ bí awa ti rí i gbà?” Dájúdájú, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó wà níbẹ̀ tí ó lè fi pẹ̀lú ẹ̀tọ́ lòdìsí i, nítorí náà ìbatisí àwọn Kèfèrí wọ̀nyí sì wáyé.—Ìṣe 10:44-48; fiwé Ìṣe 8:14-17.
Ìkọlà Kò Sí Mọ́
8. Èéṣe tí ó fi ṣòro fún àwọn kan lára àwọn Kristian ìjímìjí láti pa ẹ̀kọ́ nípa ìkọlà tì?
8 Ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ títànyòò síwájú síi ti òtítọ́ jẹyọ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìbéèrè lórí ìkọlà. Àṣà ìkọlà ní ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní 1919 B.C.E. pẹ̀lú májẹ̀mú Jehofa pẹ̀lú Abrahamu. Ọlọrun pàṣẹ fún Abrahamu nígbà náà pé òun àti gbogbo ọmọkùnrin mìíràn nínú agbo-ilé rẹ̀ gbọ́dọ̀ kọlà. (Genesisi 17:9-14, 23-27) Nítorí náà ìkọlà di àmì ìdánimọ̀ fún àwọn àtọmọdọ́mọ Abrahamu. Ẹ sì wo bí wọ́n ṣe ń fi àṣà yìí yangàn tó! Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí, “aláìkọlà” wá di ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn. (Isaiah 52:1; 1 Samueli 17:26, 27) Ó rọrùn láti rí ìdí tí àwọn Kristian ìjímìjí kan tí wọ́n jẹ́ Júù ṣe fẹ́ láti jẹ́ kí àmì yìí máa wà títí lọ. Àwọn kan lára wọn ní ìjíròrò púpọ̀ pẹ̀lú Paulu àti Barnaba lórí ọ̀ràn yìí. Láti lè yanjú rẹ̀, Paulu àti àwọn mìíràn lọ sí Jerusalemu láti fi ọ̀ràn náà lọ ẹgbẹ́ olùṣàkóso Kristian.—Ìṣe 15:1, 2.
9. Àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ wo ni a ṣípayá fún ẹgbẹ́ olùṣàkóso ìjímìjí, gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Ìṣe orí 15.
9 Nínú ọ̀ràn yìí, kì í ṣe nípasẹ̀ iṣẹ́-ìyanu híhàn gbangba ni àwọn Kristian ìjímìjí wọ̀nyẹn fi rí ìmọ́lẹ̀ náà gbà pé ìkọlà kì í ṣe ohun tí a béèrè fún mọ́ lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ Jehofa. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n gba ìmọ́lẹ̀ tí ó mọ́lẹ̀ síi yẹn nípa yíyẹ inú Ìwé Mímọ́ wò, gbígbíyèlé ẹ̀mí mímọ́ fún ìtọ́sọ́nà, àti gbígbọ́ àwọn ìrírí Peteru àti Paulu nípa yíyí àwọn Kèfèrí aláìkọlà lọ́kàn padà. (Ìṣe 15:6-21) Ìpinnu náà ni a gbé jáde nínú lẹ́tà kan tí apákan rẹ̀ kà pé: “Ẹ̀mí mímọ́ ati awa fúnra wa ti faramọ́ ṣíṣàì tún fi ẹrù-ìnira kankan kún un fún yín, àyàfi awọn nǹkan pípọndandan wọnyi, lati máa takété sí awọn ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà ati sí ẹ̀jẹ̀ ati sí ohun tí a lọ́ lọ́rùn pa ati sí àgbèrè.” (Ìṣe 15:28, 29) Nípa báyìí a tú àwọn Kristian ìjímìjí sílẹ̀ lómìnira kúrò lọ́wọ́ àṣẹ náà láti kọlà àti kúrò lọ́wọ́ àwọn ohun mìíràn tí Òfin Mose béèrè fún. Nípa báyìí, Paulu lè sọ fún àwọn Kristian ní Galatia pé: “Fún irúfẹ́ òmìnira bẹ́ẹ̀ ni Kristi dá wa sílẹ̀ lómìnira.”—Galatia 5:1.
Ìmọ́lẹ̀ Nínú Àwọn Ìròyìnrere
10. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí a ṣípayá nínú Ìròyìnrere Matteu?
10 Kò sí iyèméjì kankan pé Ìròyìnrere Matteu, tí a kọ ní nǹkan bí 41 C.E., ní ọ̀pọ̀ ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ nínú fún àǹfààní àwọn tí ń kà á. Ìwọ̀nba díẹ̀ ní ìfiwéra lára àwọn Kristian ọ̀rúndún kìn-ìnní ti fetí ara wọn gbọ́ bí Jesu ṣe ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ní pàtàkì, Ìròyìnrere Matteu tẹnumọ́ ọn pé Ìjọba náà ni ẹṣin-ọ̀rọ̀ ìwàásù Jesu. Ẹ sì wo bí Jesu ṣe fi tagbára tagbára tẹnumọ́ ìjẹ́pàtàkì níní ète ìsúnniṣe tí ó tọ̀nà tó! Ẹ wo irú àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí ó wà nínú Ìwàásù rẹ̀ Lorí Òkè, nínú òwe àkàwé rẹ̀ (irú àwọn wọnnì tí a kọsílẹ̀ ní orí 13), àti nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ńláǹlà ní orí 24 àti 25! Gbogbo èyí ni a mú wá sí àfiyèsí àwọn Kristian ìjímìjí nínú àkọsílẹ̀ Ìròyìnrere Matteu, tí a kọ ní ọdún mẹ́jọ péré lẹ́yìn Pentekosti 33 C.E.
11. Kí ni a lè sọ nípa àwọn tí ó wà nínú àwọn Ìròyìnrere Luku àti Marku?
11 Ní nǹkan bí ọdún 15 lẹ́yìn náà, Luku kọ Ìròyìnrere rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé púpọ̀ nínú rẹ̀ farajọ àkọsílẹ̀ Matteu, ìpín 59 nínú ọgọ́rùn-ún jẹ́ àfikún. Luku ṣàkọsílẹ̀ mẹ́fà nínú àwọn iṣẹ́-ìyanu Jesu àti èyí tí ó ju ìlọ́po méjì ọ̀pọ̀ àkàwé Rẹ̀ tí àwọn akọ̀wé Ìròyìnrere mìíràn kò mẹ́nukàn. Ó hàn gbangba pé ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, Marku kọ Ìròyìnrere rẹ̀, tí ó tẹnumọ́ Jesu Kristi gẹ́gẹ́ bí alákíkanjú ọkùnrin, oníṣẹ́ ìyanu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Marku kọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Matteu àti Luku ti ṣàkọsílẹ̀ tẹ́lẹ̀, ó ṣàkọsílẹ̀ òwe àkàwé kan tí àwọn kò mẹ́nukàn. Nínú àpèjúwe yẹn, Jesu fi Ìjọba Ọlọrun wé irúgbìn tí ó hù, tí ó dàgbà, tí ó sì so èso ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀.a—Marku 4:26-29.
12. Dé àyè wo ni Ìròyìnrere Johannu fi pèsè ìlàlóye síwájú síi?
12 Ìròyìnrere Johannu tún wà níbẹ̀, tí a kọ ní ohun tí ó lè ní 30 ọdún lẹ́yìn tí Marku kọ àkọsílẹ̀ tirẹ̀. Ẹ wo irú ìmọ́lẹ̀ tí ń mọ́lẹ̀ síi tí Johannu tàn sórí iṣẹ́-òjíṣẹ́ Jesu, pàápàá ní pàtàkì nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtọ́ka sí ìwàláàyè Rẹ̀ ṣáájú dídi ènìyàn! Johannu nìkan ni ó pèsè àkọsílẹ̀ àjíǹde Lasaru, òun nìkan ni ó sì fún wa ní ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ àkíyèsí àtàtà tí Jesu sọ fún àwọn aposteli rẹ̀ olùṣòtítọ́ àti àdúrà amọ́kànyọ̀ rẹ̀ ní òru ọjọ́ tí a dà á, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní orí 13 sí 17. Ní tòótọ́, wọ́n sọ pé ìpín 92 nínú ọgọ́rùn-ún Ìròyìnrere Johannu tayọlọ́lá.
Àwọn Ìbùyẹ̀rì Ìmọ́lẹ̀ Nínú Lẹ́tà Paulu
13. Èéṣe tí àwọn kan fi wo lẹ́tà Paulu sí àwọn ara Romu gẹ́gẹ́ bíi pé ó jẹ́ ìwé Ìròyìnrere?
13 A lo aposteli Paulu ní pàtàkì láti mú àwọn ìbùyẹ̀rì òtítọ́ wá fún àwọn Kristian tí wọ́n gbé ní àkókò àwọn aposteli. Fún àpẹẹrẹ, lẹ́tà Paulu sí àwọn ará Romu wà níbẹ̀, tí ó kọ ní nǹkan bí 56 C.E.—tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ àkókò kan náà tí Luku kọ Ìròyìnrere tirẹ̀. Nínú lẹ́tà yìí Paulu tẹnumọ́ òkodoro òtítọ́ náà pé a lè sọ pé a ní ìwà òdodo gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọrun àti nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi. Ìtẹnumọ́ Paulu lórí apá ìhìnrere yìí náà ti mú kí àwọn kan fojú wo lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ara Romu gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó jẹ́ Ìròyìnrere karùn-ún.
14-16. (a) Nínú lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí àwọn Kristian ní Korinti, ìmọ́lẹ̀ wo ni Paulu tàn sórí àìní náà fún ìṣọ̀kan? (b) Ìmọ́lẹ̀ síwájú síi níti ìṣarasíhùwà wo ni Korinti Kìn-ínní ní nínú?
14 Paulu kọ̀wé nípa àwọn ọ̀ràn kan tí ó ń kó ìdààmú bá àwọn Kristian ní Korinti. Lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará Korinti ní nínú ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn tí a mí sí tí ó ti ṣàǹfààní fún àwọn Kristian títí di ọjọ́ wa. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó níláti la àwọn ara Korinti lóye nípa àṣìṣe tí wọ́n ń ṣe nípa ìdásílẹ̀ ẹgbẹ́ akésáàfúlà fún àwọn ènìyàn kan ní pàtó. Aposteli náà tún èrò-orí wọn ṣe, ní fífi tìgboyà tìgboyà sọ fún wọn pé: “Mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, nípasẹ̀ orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi pé kí gbogbo yín máa sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan, ati pé kí ìpínyà máṣe sí láàárín yín, ṣugbọn kí a lè so yín pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí ninu èrò-inú kan naa ati ninu ìlà ìrònú kan naa.”—1 Korinti 1:10-15.
15 A ti fàyègba ìwà pálapàla tí ó burú lékenkà ní ìjọ Kristian ní Korinti. Ọkùnrin kan níbẹ̀ ti gba aya bàbá rẹ̀, tí ó sì tipa báyìí ṣe ‘irúfẹ́ àgbèrè tí a kò tilẹ̀ rí láàárín awọn orílẹ̀-èdè.’ Láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ mú ènìyàn burúkú naa kúrò láàárín ara yín.” (1 Korinti 5:1, 11-13) Ohun titun kan ni ìyẹn jẹ́ fún ìjọ Kristian nígbà náà lọ́hùn-ún—ìyọlẹ́gbẹ́. Ọ̀ràn mìíràn tí ìjọ Korinti nílò ìlàlóye lé lórí níí ṣe pẹ̀lú òkodoro òtítọ́ náà pé àwọn kan lára àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ ń fa arákùnrin wọn nípa tẹ̀mí lọ sí ilé-ẹjọ́ ayé láti lè yanjú aáwọ̀. Paulu bá wọn wí gidigidi fún ṣíṣe èyí.—1 Korinti 6:5-8.
16 Síbẹ̀ ọ̀ràn mìíràn tí ń yọ ìjọ tí ó wà ní Korinti lẹ́nu níí ṣe pẹ̀lú ọ̀ràn ìbálòpọ̀. Ní 1 Korinti orí 7, Paulu fi hàn pé nítorí ìwà pálapàla takọtabo tí ó gbilẹ̀, yóò dára bí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan bá ní aya tirẹ̀ kí obìnrin kọ̀ọ̀kan sì ní ọkọ tirẹ̀. Paulu fi hàn pẹ̀lú pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe fún àwọn kòlọ́kọ-kòláya láti ṣiṣẹ́sin Jehofa pẹ̀lú ìpínyà ọkàn tí ó dínkù, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ó ní ẹ̀bùn dídúró láìlọ́kọ-láìláya. Bí ọkọ obìnrin kan bá sì kú, òun yóò ní òmìnira láti tún ṣe ìgbéyàwó ṣùgbọ́n “kìkì ninu Oluwa.”—1 Korinti 7:39.
17. Ìmọ́lẹ̀ wo ni Paulu tàn sórí ẹ̀kọ́ nípa àjíǹde?
17 Ẹ wo irú àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí Oluwa lo Paulu láti tàn sórí àjíǹde! Pẹ̀lú irú ara wo ni a óò fi jí àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró dìde? Paulu kọ̀wé pé: “A gbìn ín ní ara ìyára, a gbé e dìde ní ara ti ẹ̀mí.” Kò sí ara ẹlẹ́ran-ara kankan tí a óò gbé lọ sí òkè ọ̀run, nítorí pé “ẹran-ara ati ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún ìjọba Ọlọrun.” Paulu fikún un pé kì í ṣe gbogbo àwọn ẹni-àmì-òróró ni yóò sùn nínú ikú ṣùgbọ́n pé nígbà wíwà níhìn-ín Jesu a óò jí àwọn kan lára wọn dìde sí ìyè àìleèkú ní ìpajúpẹ́.—1 Korinti 15:43-53.
18. Ìmọ́lẹ̀ wo nípa ọjọ́-ọ̀la ni lẹ́tà Paulu àkọ́kọ́ sí àwọn ará Tessalonika ní nínú?
18 Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn Kristian ní Tessalonika, a lo Paulu láti tan ìmọ́lẹ̀ sí ọjọ́-ọ̀la. Ọjọ́ Jehofa yóò dé gẹ́gẹ́ bí olè ní òru. Paulu tún ṣàlàyé pé: “Ìgbà yòówù tí ó jẹ́ tí wọ́n bá ń wí pé: ‘Àlàáfíà ati ààbò!’ nígbà naa ni ìparun òjijì yoo dé lọ́gán sórí wọn gan-an gẹ́gẹ́ bí ìroragógó wàhálà lórí aboyún; wọn kì yoo sì yèbọ́ lọ́nàkọnà.”—1 Tessalonika 5:2, 3.
19, 20. Àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ wo ni àwọn Kristian ní Jerusalemu àti Judea rí gbà nínú lẹ́tà Paulu sí àwọn Heberu?
19 Nípa kíkọ lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn Heberu, Paulu tàtaré àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ sí àwọn Kristian ìjímìjí ní Jerusalemu àti Judea. Ẹ wo bí ó ṣe fi bí ọ̀nà ìgbàjọ́sìn àwọn Kristian ṣe galọ́lá ju ọ̀nà ìgbàjọ́sìn ti Mose lọ hàn! Dípò títẹ̀lé Òfin tí àwọn áńgẹ́lì tàtaré rẹ̀, àwọn Kristian ní ìgbàgbọ́ nínú ìgbàlà tí ó jẹ́ pé Ọmọkùnrin Ọlọrun ni ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹni tí ó galọ́lá fíìfíì ju irú àwọn áńgẹ́lì òjíṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ. (Heberu 2:2-4) Ìránṣẹ́ onítọ̀ọ́jú lásán ni Mose jẹ́ ní ilé Ọlọrun. Bí ó ti wù kí ó rí, Jesu Kristi ń darí gbogbo odidi ilé náà. Kristi ni olórí àlùfáà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ìṣètò pàtàkì ti Melkisedeki, ó ní ipò kan tí ó galọ́lá fíìfíì ju ti ipò àlùfáà Aaroni lọ. Paulu tún tọ́ka sí i pé kò ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ Israeli láti wọnú ìsinmi Ọlọrun nítorí àìní ìgbàgbọ́ àti àìṣègbọràn, ṣùgbọ́n àwọn Kristian wọnú rẹ̀ nítorí ìṣòtítọ́ àti ìgbọràn wọn.—Heberu 3:1-4, 11.
20 Lẹ́yìn náà, májẹ̀mú titun, pẹ̀lú galọ́lá fíìfíì ju májẹ̀mú Òfin lọ. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ní 600 ọdún ṣáájú ní Jeremiah 31:31-34, àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú májẹ̀mú titun ni a kọ òfin Ọlọrun sí ọkàn-àyà wọn wọ́n sì ń gbádùn ìdáríjì tòótọ́ fún ẹ̀ṣẹ̀. Dípò níní olórí àlùfáà kan tí ó níláti máa rú ẹbọ lọ́dọọdún fún ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀ àti ti àwọn ènìyàn, àwọn Kristian ní Jesu Kristi gẹ́gẹ́ bí Olórí Àlùfáà wọn, ẹni tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan tí ó sì rú ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ láìní padà tún un ṣe mọ́. Dípò wíwọnú ibi mímọ́ tí a fi ọwọ́ ṣe lọ láti gbé ìrúbọ rẹ̀ kalẹ̀ ó wọnú ọ̀run gan-an lọ, láti lè fara hàn níwájú Jehofa fúnra rẹ̀. Jù gbogbo rẹ̀ lọ, fífi ẹran rúbọ lábẹ́ májẹ̀mú Òfin Mose kò lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò pátápátá, bí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni wọn kì bá tí máa rú u lọ́dọọdún. Ṣùgbọ́n ẹbọ ti Kristi, tí ó rú láìní tún un ṣe mọ́, ń mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò. Gbogbo èyí tan ìmọ́lẹ̀ sórí tẹ́ḿpìlì ńlá tẹ̀mí, nínú àgbàlá èyí tí àwọn àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró àti “awọn àgùtàn mìíràn” ti ń ṣiṣẹ́sìn lónìí.—Johannu 10:16; Heberu 9:24-28.
21. Kí ni ohun tí ìjíròrò yìí ti fi hàn nípa ìmúṣẹ Orin Dafidi 97:11 àti Owe 4:18 ní àkókò àwọn aposteli?
21 Àyè kò tó láti fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ púpọ̀ síi, irú àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí a rí nínú àwọn lẹ́tà aposteli Peteru àti ti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jakọbu àti Juda. Ṣùgbọ́n àwọn tí a ti mẹ́nukàn wọ̀nyí yẹ kí ó tó láti fi hàn pé Orin Dafidi 97:11 àti Owe 4:18 ní ìmúṣẹ tí ó pe àfiyèsí ní àkókò àwọn aposteli. Òtítọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀síwájú láti orí àwọn irú-oríṣi àti àwọn òjìji sí àwọn ìmúṣẹ àti òtítọ́ ìṣẹ̀lẹ̀.—Galatia 3:23-25; 4:21-26.
22. Kí ni ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú àwọn aposteli, kí sì ni ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e yóò fi hàn?
22 Lẹ́yìn ikú àwọn aposteli Jesu àti ìbẹ̀rẹ̀ ìpẹ̀yìndà tí a sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ náà jó réúréú. (2 Tessalonika 2:1-11) Ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí Jesu, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún Ọ̀gá náà padà dé ó sì rí “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” tí ń fún “awọn ará ilé” ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, Jesu Kristi yan ẹrú náà sípò “lórí gbogbo awọn nǹkan ìní rẹ̀.” (Matteu 24:45-47) Irú àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ wo ni ó tẹ̀lé e? Èyí ni a óò jíròrò nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ilẹ̀ níhìn-ín ń tọ́ka sí àyíká náà níbi tí Kristian ti yàn láti mú àwọn ànímọ́ ipò jíjẹ́ ẹnìkan dàgbà.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, December 15, 1980, ojú-ìwé 22 sí 23.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Àwọn ẹsẹ̀ Bibeli wo ni ó fi hàn pé lílóye òtítọ́ jẹ́ lọ́nà tí ń tẹ̀síwájú?
◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ tí a ṣàkọsílẹ̀ nínú ìwé Ìṣe?
◻ Ìmọ́lẹ̀ wo ni a rí nínú àwọn ìwé Ìròyìnrere?
◻ Àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ wo ni àwọn lẹ́tà Paulu ní?