Ohun Táá Jẹ́ Kí Tọkọtaya Bára Wọn Kalẹ́
“Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; . . . kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”—ÉFÉ. 5:33.
1. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tọkọtaya máa ń láyọ̀ lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn, kí ni Bíbélì sọ pé wọ́n máa ní? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
TÍ ỌKỌ ìyàwó bá rí ìyàwó rẹ̀ lọ́jọ́ ìgbéyàwó wọn, inú àwọn méjèèjì á dùn débi pé téèyàn bá gẹṣin nínú wọn, kò lè kọsẹ̀ láé. Àtìgbà tí wọ́n ti ń fẹ́ra wọn sọ́nà ni ìfẹ́ wọn ti lágbára débi pé wọ́n ṣe tán láti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn ò ní dalẹ̀ ara wọn. Bó ti wù kó rí, kí ìdílé tuntun náà tó lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa, àwọn méjèèjì á ní láti ṣe àwọn àyípadà kan kí wọ́n lè mọwọ́ ara wọn. Torí pé Jèhófà ní ire àwọn tọkọtaya lọ́kàn, ó fún wọn ní ìmọ̀ràn tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú Bíbélì. Tí wọ́n bá tẹ̀ lé e, ìgbéyàwó wọn á dùn bí oyin, wọ́n á sì bára wọn kalẹ́. (Òwe 18:22) Síbẹ̀, Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo àwọn tó ṣègbéyàwó máa “ní ìpọ́njú nínú ẹran ara.” (1 Kọ́r. 7:28) Àmọ́, báwo ni wọ́n ṣe lè dín ìpọ́njú náà kù? Kí ló sì máa jẹ́ káwọn tọkọtaya bára wọn kalẹ́?
2. Irú ìfẹ́ wo ló yẹ káwọn tọkọtaya máa fi hàn síra wọn?
2 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ ṣe pàtàkì gan-an láàárín tọkọtaya. Ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ (phi·liʹa lédè Gíríìkì) pọn dandan nínú ìgbéyàwó. Ìfẹ́ tó máa ń wà láàárín ọkùnrin àtobìnrin (eʹros) máa ń máyọ̀ wá, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́ tó máa ń wà láàárín ìdílé (stor·geʹ) ṣe kókó, pàápàá tí wọ́n bá ti ní ọmọ. Àmọ́ ìfẹ́ tá a gbé karí ìlànà (a·gaʹpe) ló máa ń jẹ́ kí ìgbéyàwó yọrí sí rere. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ yìí, ó sọ pé: “Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”—Éfé. 5:33.
OJÚṢE ỌKỌ ÀTÌYÀWÓ NÍNÚ ILÉ
3. Báwo ló ṣe yẹ kí ìfẹ́ tó wà láàárín tọkọtaya lágbára tó?
3 Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” (Éfé. 5:25) Tá a bá fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù lóòótọ́, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wa bí Jésù náà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa. (Ka Jòhánù 13:34, 35; 15:12, 13.) Ìfẹ́ tó wà láàárín àwọn tọkọtaya Kristẹni gbọ́dọ̀ lágbára débi pé wọ́n á ṣe tán láti kú fún ara wọn tó bá gbà bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ìyẹn kì í rọrùn tí èdèkòyédè bá wáyé. Síbẹ̀, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ a·gaʹpe “máa mú ohun gbogbo mọ́ra, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fara da ohun gbogbo.” Ìfẹ́ yìí “kì í kùnà láé.” (1 Kọ́r. 13:7, 8) Báwọn tọkọtaya tó bẹ̀rù Jèhófà bá ń rántí pé àwọn jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn á nífẹ̀ẹ́ ara wọn, àwọn ò sì ní dalẹ̀ ara wọn, wọ́n á jọ máa fi ìlànà Bíbélì yanjú ìṣòro èyíkéyìí tó bá yọjú.
4, 5. (a) Kí ni ojúṣe ọkọ nínú ilé? (b) Báwo ló ṣe yẹ kí ìyàwó máa ṣe sí ọkọ rẹ̀? (d) Àwọn àyípadà wo ni tọkọtaya kan ṣe?
4 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó yẹ kí tọkọtaya máa ṣe, ó sọ pé: “Kí àwọn aya wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa, nítorí pé ọkọ ni orí aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti jẹ́ orí ìjọ.” (Éfé. 5:22, 23) Èyí ò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ń bu àwọn obìnrin kù o, kàkà bẹ́ẹ̀ ìlànà yìí máa jẹ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ láṣeyanjú. Ọlọ́run mẹ́nu kan iṣẹ́ yìí nígbà tó sọ pé: “Kò dára kí ọkùnrin náà [Ádámù] máa wà nìṣó ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.” (Jẹ́n. 2:18) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ àwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni pé kí wọ́n máa fìfẹ́ lo ipò orí wọn bí Kristi tó jẹ́ “orí ìjọ” ṣe ń fìfẹ́ hàn sí ìjọ. Tí ọkọ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á rọrùn fún ìyàwó rẹ̀ láti bọ̀wọ̀ fún un, á máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, á sì máa tì í lẹ́yìn.
5 Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Cathy[1] gbà pé èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe àwọn àyípadà kan tó bá ṣègbéyàwó, ó sọ pé: “Kí n tó ṣègbéyàwó, mi ò kì í dúró de ẹnikẹ́ni kí n tó ṣèpinnu, mo sì máa ń tọ́jú ara mi. Nǹkan ti yàtọ̀ báyìí, ó ti di pé kí n máa dúró de ọkọ mi kí n tó ṣèpinnu. Kì í rọrùn nígbà míì, àmọ́ torí pé ohun tí Jèhófà fẹ́ là ń ṣe, a ti túbọ̀ mọ ara wa sí i.” Fred ọkọ rẹ̀ sọ pé: “Nígbà tó jẹ́ èmi nìkan, kì í rọrùn fún mi láti ṣèpinnu rárá. Ní báyìí tí mo ti gbéyàwó, ó tún ti wá ṣòro sí i torí pé mo gbọ́dọ̀ ro ti ìyàwó mi nígbà tí mo bá ń ṣèpinnu. Àmọ́, bí mo ṣe ń bẹ Jèhófà pé kó máa tọ́ mi sọ́nà, tí mo sì ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí ìyàwó mi, ṣe ló túbọ̀ ń rọrùn fún mi láti ṣèpinnu lójoojúmọ́. Àwa méjèèjì ti wá mọwọ́ ara wa gan-an báyìí.”
6. Báwo ni ìfẹ́ ṣe lè jẹ́ kí tọkọtaya yanjú èdèkòyédè tí wọ́n bá ní?
6 Kí àárín tọkọtaya tó lè gún, ó ṣe pàtàkì káwọn méjèèjì gbà pé àwọn lè ṣàṣìṣe. Torí bẹ́ẹ̀, wọ́n á máa ‘fara dà á fún ara wọn, wọ́n á sì máa dárí ji ara wọn ní fàlàlà.’ Ó dájú pé àwọn méjèèjì á máa ṣàṣìṣe. Àmọ́ tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe wọn, kí wọ́n dárí ji ara wọn, kí wọ́n sì máa fi ìfẹ́ tó jẹ́ “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé” ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe. (Kól. 3:13, 14) Yàtọ̀ síyẹn, “ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. . . . Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe.” (1 Kọ́r. 13:4, 5) Ó yẹ kẹ́ ẹ tètè máa yanjú èdèkòyédè tẹ́ ẹ bá ní kíákíá. Ọjọ́ yẹn ni kẹ́ ẹ yanjú ẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ kó dọjọ́ kejì. (Éfé. 4:26, 27) Tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ẹnì kejì rẹ tó o bá ṣẹ̀ ẹ́, o lè sọ pé: “Jọ̀ọ́ má bínú, ohun tí mo ṣe yẹn dùn mí gan-an.” Èyí gba pé kéèyàn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìgboyà, àmọ́ tẹ́ ẹ bá lè tọrọ àforíjì, ẹ̀ẹ́ lè yanjú ìṣòro kíá, ìyẹn á sì jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ mọwọ́ ara yín dáadáa.
Ẹ MÁA BÁRA YÍN LÒ LỌ́NÀ JẸ̀LẸ́ŃKẸ́
7, 8. (a) Ìmọ̀ràn wo ni Bíbélì fún tọkọtaya tó bá dọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí tọkọtaya máa bá ara wọn lò lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́?
7 Bíbélì ní àwọn ìmọ̀ràn tí tọkọtaya lè fi sílò tó bá kan ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀. (Ka 1 Kọ́ríńtì 7:3-5.) Ó ṣe pàtàkì kí tọ̀tún-tòsì máa gba tara wọn rò. Tí ọkọ bá fẹ́ kí ìyàwó òun gbádùn ìbálòpọ̀, ó ṣe pàtàkì pé kí ọkọ máa fọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú ìyàwó rẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gba àwọn ọkọ níyànjú pé kí wọ́n mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwọn aya wọn. (1 Pét. 3:7) Àjọgbà ló yẹ kí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ jẹ́, kì í ṣe èyí tá à ń fipá múni ṣe tàbí èyí tẹ́nì kan á máa ro tiẹ̀ nìkan ṣáá. Ohun kan ni pé ara ọkùnrin sábà máa ń tètè wà lọ́nà ju tobìnrin lọ tó bá dọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀, àmọ́ ó ṣe pàtàkì kí wọ́n jọ mọ àsìkò tó máa gbádùn mọ́ àwọn méjèèjì.
8 Lóòótọ́, tó bá dọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ láàárín tọkọtaya, Bíbélì ò ṣòfin nípa onírúurú ọ̀nà tí tọkọtaya lè gbà ṣeré ìfẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni kò díwọ̀n bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe é tó, síbẹ̀ ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa fìfẹ́ hàn síra wọn. (Orin Sól. 1:2; 2:6) Bíbélì sọ pé kí tọkọtaya máa bá ara wọn lò lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́.
9. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa fa ojú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wa mọ́ra tàbí ká máa bá a tage?
9 Torí pé ẹ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ẹ sì nífẹ̀ẹ́ ara yín, ẹ ò ní gba ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun láyé láti wọ àárín yín. Àwọn kan ti jẹ́ kí ìwòkuwò da ìgbéyàwó wọn rú. Ẹ má ṣe fàyè gba irú ẹ̀, ẹ má sì jẹ́ kí ọkàn yín máa fà sẹ́ni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya yín. Kódà, kò yẹ ká ṣe ohunkóhun tó máa jẹ́ kó dà bíi pé à ń fa ojú ẹlòmíì mọ́ra, bẹ́ẹ̀ sì ni kò yẹ ká máa bá ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wa tage. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò fi hàn pé ẹni náà nífẹ̀ẹ́ ọkọ tàbí aya rẹ̀. Tá a bá ń rántí pé arínúróde ni Jèhófà, a ò ní ṣe ohunkóhun tó máa ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́, àá sì tipa bẹ́ẹ̀ máa múnú rẹ̀ dùn.—Ka Mátíù 5:27, 28; Hébérù 4:13.
TÍ ÌṢÒRO BÁ DÉ ŃKỌ́?
10, 11. (a) Báwo ni ìkọ̀sílẹ̀ ṣe gbòde kan tó? (b) Kí ni Bíbélì sọ nípa ìpínyà? (d) Kí ló máa ran tọkọtaya lọ́wọ́ tí wọn ò fi ní pínyà?
10 Táwọn tọkọtaya kan bá níṣòro, tí ìṣòro ọ̀hún ò sì yanjú, wọ́n máa ń ronú pé á dáa káwọn pínyà tàbí káwọn kọ ara wọn sílẹ̀. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ohun tó ju márùn-ún nínú ìgbéyàwó mẹ́wàá ló ń yọrí sí ìkọ̀sílẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú èyí ṣọ̀wọ́n láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, síbẹ̀ bí ìṣòro ṣe túbọ̀ ń jẹyọ nínú àwọn ìdílé Kristẹni ń kọni lóminú.
11 Bíbélì sọ pé: “Kí aya má lọ kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀; ṣùgbọ́n bí ó bá lọ ní ti gidi, kí ó wà láìlọ́kọ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kí ó parí aáwọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀; kí ọkọ má sì fi aya rẹ̀ sílẹ̀.” (1 Kọ́r. 7:10, 11) Ìpínyà kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré. Tọkọtaya kan lè máa ronú pé ìpínyà ló máa yanjú ìṣòro wọn, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ṣe ló tún máa ń bí àwọn ìṣòro míì. Jésù mẹ́nu ba ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ pé ọkùnrin máa fi bàbá àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, á sì fà mọ́ ìyàwó rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó fi kún un pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mát. 19:3-6; Jẹ́n. 2:24) Ohun tí Jésù ń sọ ni pé ọkọ tàbí aya kò gbọ́dọ̀ ya ohun tí Ọlọ́run ti sọ pọ̀. Jèhófà fẹ́ káwọn tọkọtaya máa bára wọn gbé títí lọ gbére, ikú nìkan ló sì lè yà wọ́n. (1 Kọ́r. 7:39) Tí tọkọtaya bá ń rántí pé gbogbo wa la máa jíhìn fún Jèhófà, àwọn méjèèjì á máa sapá láti yanjú èdèkòyédè tó bá wáyé láàárín wọn kí ìṣòro náà tó di ńlá.
12. Kí ló lè mú kí ẹnì kan máa ronú àtipínyà pẹ̀lú ọkọ tàbí aya rẹ̀?
12 Ohun kan tó máa ń fa èdèkòyédè láàárín àwọn tọkọtaya ni pé ibi tí wọ́n fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀. Ẹnì kan lè rò pé bóun bá ti lọ́kọ tàbí láya, kóun máa gbádùn ló kù. Àmọ́ tí nǹkan ò bá rí bó ṣe rò lẹ́yìn tó ṣègbéyàwó, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í kanra, kó máa bínú sẹ́nì kejì rẹ̀, ó tiẹ̀ lè ronú pé ìbágbé àwọn kò ni wọ̀ mọ́. Ohun míì tó tún lè fa èdèkòyédè ni pé ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn méjèèjì dàgbà sí, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wọn yàtọ̀ síra, ẹnu wọn sì lè má kò tó bá dọ̀rọ̀ owó. Bákan náà, èrò wọn lè yàtọ̀ ní ti bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe sáwọn àna wọn àti bó ṣe yẹ kí wọ́n tọ́ àwọn ọmọ. Àmọ́, inú wa dùn pé púpọ̀ lára àwọn tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni máa ń yanjú irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ láìsì wàhálà torí pé wọ́n ń jẹ́ kí Ọlọ́run tọ́ àwọn sọ́nà.
13. Àwọn nǹkan wo ló lè mú kí tọkọtaya pínyà?
13 Bó ti wù kó rí, àwọn nǹkan kan wà tó lè mú kẹ́nì kan pinnu pé òun á pínyà pẹ̀lú ẹnì kejì òun. Bí àpẹẹrẹ, tí ọkọ kan bá mọ̀ọ́mọ̀ kọ̀ láti pèsè fún ìdílé rẹ̀ tàbí tó ń lu ìyàwó rẹ̀ ní ìlubàrà tàbí tí kò jẹ́ kó sin Jèhófà, aya kan lè pinnu pé òun á pínyà. Bí àwọn Kristẹni tọkọtaya kan bá níṣòro tó kọjá agbára wọn, ó yẹ kí wọ́n lọ bá àwọn alàgbà kí wọ́n lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Àwọn alàgbà yìí á jẹ́ kí wọ́n rí bí wọ́n ṣe lè fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. Tá a bá fẹ́ yanjú ìṣòro láàárín àwa àti ẹnì kejì wa, ó yẹ ká gbàdúrà pé kí Jèhófà fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fi ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò ká sì máa fi èso tẹ̀mí ṣèwà hù.—Gál. 5:22, 23.[2]
14. Ìmọ̀ràn wo ni Bíbélì fún àwọn tí ọkọ tàbí aya wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
14 Láwọn ìdílé míì, ó lè jẹ́ ìyàwó nìkan ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà, nígbà míì ó sì lè jẹ́ ọkọ. Tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, Bíbélì mú kó ṣe kedere pé wọ́n ṣì lè máa gbé pọ̀. (Ka 1 Kọ́ríńtì 7:12-14.) Yálà ọkọ tàbí aya tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà mọ̀ tàbí kò mọ̀, a ti sọ ọ́ “di mímọ́” torí pé ìránṣẹ́ Jèhófà ló fẹ́. Àwọn ọmọ wọn náà jẹ́ “mímọ́,” tó túmọ̀ sí pé àwọn náà ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Aya, báwo ni o ṣe mọ̀ bóyá ìwọ yóò gba ọkọ rẹ là? Tàbí, ọkọ, báwo ni o ṣe mọ̀ bóyá ìwọ yóò gba aya rẹ là?” (1 Kọ́r. 7:16) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ti máa ń rí àwọn tọkọtaya tó jẹ́ pé ọ̀kan lára wọn ni Ẹlẹ́rìí tẹ́lẹ̀, àmọ́ tó wá ran ẹnì kejì lọ́wọ́ láti di ìránṣẹ́ Jèhófà.
15, 16. (a) Ìmọ̀ràn wo ni Bíbélì fáwọn aya tí ọkọ wọn kì í ṣe ìránṣẹ́ Jèhófà? (b) Kí ló yẹ kí Kristẹni kan ṣe tí “ẹni tí kò gbà gbọ́ náà bá tẹ̀ síwájú láti lọ”?
15 Àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn aya Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n máa tẹrí ba fún àwọn ọkọ wọn, “kí ó lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn, nítorí fífi tí wọ́n fi ojú rí ìwà mímọ́ yín pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” Tí aya kan bá ń ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tó sì ní “ìwà tútù, èyí tí ó níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run,” á jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọkọ rẹ̀ láti wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ìyẹn sì máa gbéṣẹ́ ju kó kàn máa wàásù fún un nípa àwọn ohun tá a gbà gbọ́.—1 Pét. 3:1-4.
16 Tí ọkọ tàbí aya tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí náà bá pinnu pé òun fẹ́ pínyà ńkọ́? Bíbélì sọ pé: “Bí ẹni tí kò gbà gbọ́ náà bá tẹ̀ síwájú láti lọ, jẹ́ kí ó lọ; arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan kò sí ní ipò ìsìnrú lábẹ́ irúfẹ́ àwọn ipò bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti pè yín sí àlàáfíà.” (1 Kọ́r. 7:15) Ìtọ́ni yìí kò fàyè gba Ẹlẹ́rìí náà láti fẹ́ ẹlòmíì, síbẹ̀ ìyẹn ò ní kó wá fi dandan mú ẹni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí náà pé kó má ṣe pínyà. Ohun kan ni pé ìpínyà náà lè mú ìtura díẹ̀ wá. Ọkọ tàbí aya tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí lè ronú pé tó bá yá, ẹni tó pínyà náà lè tún inú rò, kó pa dà wá, kí wọ́n sì tún ṣe ara wọn lọ́kan. Kódà, onítọ̀hún lè wá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
OHUN TÓ YẸ KÁ FI SÍPÒ ÀKỌ́KỌ́
17. Kí ló yẹ káwọn tọkọtaya Kristẹni máa fi sípò àkọ́kọ́?
17 Torí pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé yìí, à ń kojú “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (2 Tím. 3:1-5) Tá a bá jẹ́ kí ọwọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ayé búburú yìí ò ní kó èèràn ràn wá. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù. Láti ìsinsìnyí lọ, kí àwọn tí wọ́n ní aya dà bí ẹni pé wọn kò ní, . . . àti àwọn tí ń lo ayé bí àwọn tí kò lò ó dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (1 Kọ́r. 7:29-31) Pọ́ọ̀lù ò sọ pé káwọn tó ti ṣègbéyàwó pa ẹnì kejì wọn tì o, ohun tó ń sọ ni pé kí wọ́n máa fi ìjọsìn Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ torí pé àkókò tó ṣẹ́ kù ti dín kù.—Mát. 6:33.
18. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé ìgbéyàwó àwa Kristẹni lè ládùn kó sì lóyin?
18 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àkókò tó le gan-an là ń gbé, tí ọ̀pọ̀ ìdílé sì ń tú ká, síbẹ̀ ìgbéyàwó wa lè ládùn kó sì lóyin. Táwọn tọkọtaya tó jẹ́ Kristẹni bá ń bá ètò Ọlọ́run rìn, tí wọ́n ń fi ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò tí wọ́n sì ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà máa darí wọn, wọn ò ní tú “ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀” ká.—Máàkù 10:9.
^ [1] (ìpínrọ̀ 5) A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.
^ [2] (ìpínrọ̀ 13) Wo àkòrí náà “Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìkọ̀sílẹ̀ àti Ìpínyà” nínú àfikún tó wà nínú ìwé “Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run,” ojú ìwé 219 sí 221..”